Chronological
Aṣọ àlùfáà
28 “Ìwọ sì mú Aaroni arákùnrin rẹ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ, mú un kúrò ni àárín àwọn ọmọ Israẹli, pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀ Nadabu, Abihu, Eleasari, àti Itamari, kí wọn kí ó lè sìn mí gẹ́gẹ́ bí àlùfáà. 2 Ìwọ yóò sì dá aṣọ mímọ́ fún Aaroni arákùnrin rẹ, láti fún un ni ọ̀ṣọ́ àti ọlá. 3 Ìwọ yóò sì sọ fún gbogbo àwọn ọlọ́gbọ́n ènìyàn, àwọn ẹni tí mo fún ní ọgbọ́n, kí wọn kí ó lè dá aṣọ fún Aaroni, fún ìyàsímímọ́ rẹ̀, kí ó lè ba à sìn mí gẹ́gẹ́ bí àlùfáà. 4 Wọ̀nyí ni àwọn aṣọ tí wọn yóò dá: ìgbàyà kan, ẹ̀wù efodu, ọ̀já àmùrè kan, ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ ọlọ́nà, fìlà àti aṣọ ìgúnwà. Kí wọn kí ó dá àwọn aṣọ mímọ́ yìí fún Aaroni arákùnrin rẹ àti àwọn ọmọ rẹ̀, kí wọn kí ó lè sìn mí gẹ́gẹ́ bí àlùfáà. 5 Wọn yóò sì lo wúrà, aṣọ aláró, elése àlùkò àti ti òdòdó àti ti ọ̀gbọ̀ dáradára.
Ẹ̀wù efodu
6 (A)“Wọn yóò sì dá ẹ̀wù efodu ti wúrà, tí aṣọ aláró, elése àlùkò àti ti òdòdó àti ti ọ̀gbọ̀ olókùn wíwẹ́, iṣẹ́ ọlọ́nà. 7 Kí ó ni aṣọ èjìká méjì tí a so mọ́ igun rẹ̀ méjèèjì, kí a lè so ó pọ̀. 8 Àti onírúurú ọnà ọ̀já rẹ̀, tí ó wà ni orí rẹ̀, yóò rí bákan náà, gẹ́gẹ́ bi iṣẹ́ rẹ̀, tí wúrà, ti aṣọ aláró, òdòdó àti ọ̀gbọ̀ olókùn wíwẹ́.
9 “Ìwọ yóò sì mú òkúta óníkìsì méjì, ìwọ yóò sì fín orúkọ àwọn ọmọ Israẹli sára wọn. 10 Ní ti ìbí wọn, orúkọ àwọn mẹ́fà sára òkúta kan àti orúkọ àwọn mẹ́fà tókù sára òkúta kejì. 11 Iṣẹ́ ọnà òkúta fínfín, bí ìfín èdìdì ààmì, ni ìwọ yóò fún òkúta méjèèjì gẹ́gẹ́ bí orúkọ àwọn ọmọ Israẹli: ìwọ yóò sì dè wọ́n sí ojú ìdè wúrà. 12 Ìwọ yóò sì so wọ́n pọ̀ mọ́ èjìká efodu náà ní òkúta ìrántí fún àwọn ọmọ Israẹli. Aaroni yóò sì máa ní orúkọ wọn níwájú Olúwa ní èjìká rẹ̀ méjèèjì fún ìrántí. 13 Ìwọ yóò sì ṣe ojú ìdè wúrà 14 Àti okùn ẹ̀wọ̀n méjì ti kìkì wúrà, gẹ́gẹ́ bí ọ̀já àmùrè kí o sì so ẹ̀wọ̀n náà mọ́ ojú ìdè náà.
Ìgbàyà
15 “Ìwọ yóò fi iṣẹ́ ọgbọ́n ṣe ìgbàyà fún ìpinnu iṣẹ́ ọnà gbẹ́nàgbẹ́nà. Ìwọ yóò ṣe é bí ẹ̀wù efodu ti wúrà, ti aṣọ aláró, ti elése àlùkò, ti òdòdó àti ti ọ̀gbọ̀ olókùn wíwẹ́ dáradára. 16 (B)Kí ìhà mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rẹ̀ ṣe déédé—kí ó jẹ́ ìwọ̀n ìka kan ní ìnà àti ìwọ̀n ìka kan ní ìbú, kí o sì ṣe é ní ìṣẹ́po méjì. 17 Nígbà náà ni ìwọ yóò de òkúta oníyebíye mẹ́rin sára ẹsẹ̀ rẹ̀. Ní ẹsẹ̀ àkọ́kọ́ ni kí rúbì, topasi àti bereli wà; 18 ní ẹsẹ̀ kejì turikuoṣe, emeradi, safire, àti diamọndi; 19 ní ẹsẹ̀ kẹta, jasiniti, agate, àti ametisiti; 20 ní ẹsẹ̀ kẹrin, topasi, àti óníkìsì àti jasperi. A ó sì tò wọ́n sí ojú wúrà ní dìde wọn. 21 Òkúta méjìlá yóò wà, ọ̀kọ̀ọ̀kan fún orúkọ àwọn ọmọ Israẹli olúkúlùkù èdìdì ààmì pẹ̀lú orúkọ ẹnìkọ̀ọ̀kan bí ẹ̀yà Israẹli méjìlá.
22 “Fún ìgbàyà náà, ìwọ yóò ṣe okùn ẹ̀wọ̀n ti kìkì wúrà, gẹ́gẹ́ bí ọ̀já àmùrè. 23 Ìwọ yóò ṣe òrùka wúrà méjì fún un, kí o sì so wọ́n mọ́ igun méjèèjì ìgbàyà náà. 24 Ìwọ yóò so ẹ̀wọ̀n wúrà méjèèjì mọ́ òrùka ní igun ìgbàyà náà, 25 àti etí ẹ̀wọ̀n méje ni kí o so mọ́ ojú ìdè méjèèjì, kí o sì fi sí èjìká ẹ̀wù efodu náà níwájú. 26 Ìwọ yóò ṣe òrùka wúrà méjì, ìwọ yóò sì so wọ́n mọ́ igun méjì ìgbàyà kejì ní ìhà inú tí ó ti ẹ̀wù efodu náà. 27 Ìwọ yóò sì ṣe òrùka wúrà méjì, ìwọ yóò sì fi wọ́n sí èjìká ẹ̀wù efodu méjèèjì ní ìsàlẹ̀, sí ìhà iwájú rẹ̀, tí ó súnmọ́ ojú sí ìránṣọ náà, lókè onírúurú ọnà ọ̀já ẹ̀wù efodu náà. 28 Wọn yóò sì so òrùka ìgbàyà mọ́ òrùka ẹ̀wù efodu pẹ̀lú ọ̀já aláró, pa á pọ̀ mọ́ ìgbànú, kí a má ba à tú ìgbàyà náà kúrò lára ẹ̀wù efodu náà.
29 “Nígbàkúgbà tí Aaroni bá wọ ibi mímọ́, òun yóò ru orúkọ àwọn ọmọ Israẹli ní gbogbo ọ̀kan rẹ̀ ni ìgbàyà ìpinnu bí ìrántí nígbà gbogbo níwájú Olúwa. 30 Bákan náà ìwọ yóò sì mu Urimu àti Tumimu sínú ìgbàyà, kí wọn kí ó wà ní ọkàn Aaroni nígbàkúgbà tí ó bá ń wólẹ̀ níwájú Olúwa. Aaroni yóò sì máa ru ohun ti a ń fi ṣe ìpinnu fún àwọn ọmọ Israẹli ní ọkàn rẹ̀ nígbà gbogbo níwájú Olúwa.
Àwọn aṣọ Àlùfáà mìíràn
31 (C)“Ìwọ yóò ṣì ṣe aṣọ ìgúnwà ẹ̀wù efodu náà ní kìkì aṣọ aláró, 32 pẹ̀lú ojú ọrùn kí ó wà láàrín rẹ̀ fún orí. Kí iṣẹ́ ọ̀nà wà létí rẹ̀ bí ìṣẹ́tí yí i ká bí agbádá, kí ó má ba à ya. 33 Ṣe pomegiranate ti aṣọ aláró, ti elése àlùkò àti ti òdòdó yí ìṣẹ́tí ọ̀já àmùrè náà ká, pẹ̀lú ṣaworo wúrà láàrín wọn. 34 Àwọn ṣaworo wúrà àti àwọn pomegiranate ni kí ó yí ìṣẹ́tí ọ̀já àmùrè náà ká. 35 Aaroni gbọdọ̀ máa wọ̀ ọ́ nígbà tí o bá ń ṣiṣẹ́. A ó sì máa gbọ́ ìró àwọn agogo nígbà tí ó bá ń wọ ibi mímọ́ níwájú Olúwa àti nígbà tí ó bá ń jáde bọ̀, kí ó má ba à kú.
36 (D)“Ìwọ yóò sì ṣe àwo kìkì wúrà, ìwọ yóò sì fín sára rẹ̀ bí, fínfín èdìdì ààmì pé:
mímọ́ sí Olúwa.
37 Ìwọ yóò fi ọ̀já aláró sára rẹ̀ ìwọ yóò sì so ó mọ́ fìlà náà; kí ó sì wà níwájú fìlà náà. 38 Kí ó wà níwájú orí Aaroni, kí ó sì lè máa ru ẹ̀bi tí ó jẹ mọ́ ẹ̀bùn mímọ́ ti àwọn ọmọ Israẹli ti yà sí mímọ́, èyíkéyìí tí ẹ̀bùn wọn lè jẹ́. Yóò máa wà níwájú orí Aaroni nígbà gbogbo, kí wọn lè jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà fún Olúwa.
39 (E)“Ìwọ yóò sì fi ọ̀gbọ̀ dáradára hun ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀, ìwọ yóò sì fi ọ̀gbọ̀ dáradára ṣe fìlà. Ìwọ yóò sì fi iṣẹ́ abẹ́rẹ́ ṣe ọ̀já àmùrè. 40 Ìwọ yóò sì dá ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀, ọ̀já àmùrè àti ìgbàrí fún àwọn ọmọ Aaroni, láti fún wọn ní ọ̀ṣọ́ àti ọlá. 41 Lẹ́yìn tí ìwọ ti fi àwọn aṣọ wọ̀nyí wọ Aaroni arákùnrin rẹ, ìwọ yóò sì fi wọ àwọn ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú, ìwọ ó ta òróró sí wọn ní orí, ìwọ yóò sì ya wọ́n sí mímọ́. Ìwọ yóò sì Sọ wọ́n di mímọ́, kí wọn kí o lè máa ṣe iṣẹ́ àlùfáà.
42 “Ìwọ yóò dá ṣòkòtò ọ̀gbọ̀ fún wọn, kí wọn lè máa fi bo ìhòhò wọn, kí ó dé ìbàdí dé itan. 43 Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ gbọdọ̀ wọ̀ wọ́n nígbàkúgbà tí wọ́n bá wọ àgọ́ àjọ lọ tàbí nígbà tí wọ́n bá súnmọ́ pẹpẹ láti ṣiṣẹ́ ní ibi mímọ́ kí wọn kí ó má ba à dẹ́ṣẹ̀, wọn a sì kú.
“Èyí jẹ́ ìlànà láéláé fún Aaroni àti fún irú-ọmọ rẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀.
Ìyàsímímọ́ àwọn Àlùfáà
29 (F)“Èyí ni ohun tí ìwọ yóò ṣe láti yà wọ́n sí mímọ́, kí wọn lè máa ṣe àlùfáà fún mi: Mú ọ̀dọ́ akọ màlúù kan àti àgbò méjì tí kò ní àbùkù. 2 Láti ara ìyẹ̀fun aláìwú dídùn, ṣe àkàrà àti àkàrà tí a pò pẹ̀lú òróró, àti àkàrà fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ aláìwú tí a da òróró sí. 3 Ìwọ yóò sì kó wọn sínú apẹ̀rẹ̀ kan, ìwọ yóò sì mú wọn wà nínú apẹ̀rẹ̀ náà papọ̀ pẹ̀lú akọ màlúù àti àgbò méjì náà. 4 Nígbà náà ni ìwọ yóò mú Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ wá sí ẹnu-ọ̀nà àgọ́ àjọ, ìwọ yóò sì fi omi wẹ̀ wọ́n. 5 Ìwọ yóò sì fi ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ wọ Aaroni, àti aṣọ ìgúnwà efodu, àti efodu, àti ìgbàyà, kí ó sì fi onírúurú ọnà ọ̀já ẹ̀wù efodu dì í. 6 Ìwọ yóò sì fi fìlà dé e ní orí, ìwọ yóò sì ṣe adé mímọ́ sára fìlà náà. 7 Nígbà náà ni ìwọ yóò sì mú òróró ìtasórí, ìwọ yóò sì yà á sí mímọ́ nípa dída òróró sí i ní orí. 8 Ìwọ yóò sì mú àwọn ọmọ rẹ̀ ìwọ yóò sì fi aṣọ àwọ̀tẹ́lẹ̀ wọ̀ wọ́n 9 ìwọ yóò sì fi fìlà dé wọn ni orí. Nígbà náà fi ọ̀já àmùrè di Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀. Iṣẹ́ àlùfáà yóò máa jẹ́ tiwọn ní ìlànà títí ayé.
“Báyìí ni ìwọ yóò sì ya Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ sí mímọ́.
10 “Ìwọ yóò sì mú akọ màlúù wá síwájú àgọ́ àjọ, Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ yóò sì fi ọwọ́ wọn lé akọ màlúù ní orí. 11 Ìwọ yóò sì pa àwọn akọ màlúù náà níwájú Olúwa ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ àjọ. 12 Ìwọ yóò sì mú nínú ẹ̀jẹ̀ akọ màlúù náà, ìwọ yóò sì fi ìka rẹ tọ́ ọ sára ìwo pẹpẹ náà, kí o sì da gbogbo ẹ̀jẹ̀ tókù sí ìsàlẹ̀ pẹpẹ náà. 13 Kí o mú gbogbo ọ̀rá tí ó yí inú ká, èyí tí ó bo ẹ̀dọ̀ àti ìwé méjèèjì pẹ̀lú ọ̀rá tí ó wà lára wọn, ìwọ yóò sì sun wọ́n lórí pẹpẹ. 14 Ṣùgbọ́n fi iná sun ẹran akọ màlúù, awọ rẹ̀ àti ìgbẹ́ rẹ̀ lẹ́yìn òde. Ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ni.
15 “Ìwọ yóò sì mú àgbò kan, Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ yóò sì gbọ́wọ́ lé orí àgbò náà. 16 Ìwọ yóò sì pa àgbò náà, ìwọ yóò sì mú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, ìwọ yóò sì fi wọ́n pẹpẹ náà yíká. 17 Ìwọ yóò sì gé àgbò náà sí wẹ́wẹ́, ìwọ yóò sì fọ inú àti àwọn ẹsẹ̀ rẹ̀, ìwọ yóò sì tò wọ́n pẹ̀lú orí rẹ̀ lé ara wọn. 18 (G)Nígbà náà ni ìwọ yóò sun àgbò náà lórí pẹpẹ. Ẹbọ sísun ni sí Olúwa, olóòórùn dídùn ni, ẹbọ ti a fi iná ṣe sí Olúwa ni.
19 “Ìwọ yóò mú àgbò kejì, Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ yóò fi ọwọ́ wọn lé àgbò náà lórí. 20 Ìwọ yóò sì pa àgbò náà, ìwọ yóò mú nínú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, ìwọ yóò sì tọ́ ọ sí etí ọ̀tún Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀, sí àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún wọn, àti sí àtàǹpàkò ẹsẹ̀ ọ̀tún wọn. Ìwọ yóò sì fi ẹ̀jẹ̀ wọ́n pẹpẹ náà yíká. 21 Ìwọ yóò mú nínú ẹ̀jẹ̀ tí ó wà lórí pẹpẹ àti nínú òróró ìtasórí, ìwọ yóò sì wọ́n ọn sára Aaroni àti sára aṣọ rẹ̀, sára àwọn ọmọ rẹ àti sára aṣọ wọn. Nígbà náà ni òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ àti aṣọ wọn yóò di mímọ́.
22 “Ìwọ yóò mú lára ọ̀rá àgbò náà, ìrù tí ó lọ́ràá, ọ̀rá tí ó yí inú ká, èyí ti ó bo ẹ̀dọ̀, ìwé méjèèjì pẹ̀lú ọ̀rá tí ó wà lára wọn àti itan ọ̀tún. (Èyí ni àgbò fún ìyàsímímọ́). 23 Láti inú apẹ̀rẹ̀ ìṣù àkàrà aláìwú, èyí tí ó wà níwájú Olúwa, mú ìṣù kan, àkàrà tí a fi òróró dín àti àkàrà fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ kan. 24 Ìwọ yóò fi gbogbo rẹ̀ lé Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́, ìwọ yóò sì fì wọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fífì níwájú Olúwa. 25 Nígbà náà ni ìwọ yóò sì gbà wọ́n ní ọwọ́ wọn, ìwọ yóò sì sun wọ́n lórí pẹpẹ pẹ̀lú ẹbọ sísun fún òórùn dídùn níwájú Olúwa, ẹbọ ti a fi iná sun sí Olúwa. 26 Ìwọ yóò sì mú igẹ̀ àgbò ìyàsímímọ́ Aaroni, ìwọ yóò si fí ì ni ẹbọ fífì níwájú Olúwa; ìpín tìrẹ ni èyí.
27 “Ìwọ yóò sì ya igẹ̀ ẹbọ fífì náà sí mímọ́, àti ìtàn ẹbọ à gbé sọ sókè tí a fì, tí a sì gbé sọ sókè nínú àgbò ìyàsímímọ́ náà, àní nínú èyí tí í ṣe Aaroni àti nínú èyí tí ì ṣe tí àwọn ọmọ rẹ̀. 28 Èyí ni yóò sì máa ṣe ìpín ti Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ láti ọwọ́ àwọn ọmọ Israẹli nígbà gbogbo. Nítorí ẹbọ à gbé sọ sókè ni ẹbọ tí yóò ṣì ṣe èyí ni ẹbọ tí àwọn ọmọ Israẹli yóò máa ṣe sí Olúwa láti inú ẹbọ àlàáfíà wọn.
29 “Aṣọ mímọ́ Aaroni yóò jẹ́ ti irú àwọn ọmọ rẹ̀, nítorí kí a lè máa fi òróró yàn wọ́n kí a sì lè máa yà wọ́n sì mímọ́. 30 Ọmọ rẹ̀ tí ó bá jẹ àlùfáà ní ipò rẹ̀, tí ó bá wọ̀ yóò máa sì wá sí àgọ́ àjọ láti ṣiṣẹ́ ní ibi mímọ́, yóò sì máa wọ̀ wọ́n ní ọjọ́ méje.
31 “Ìwọ yóò sì mú àgbò fún ìyàsímímọ́, ìwọ yóò sì bọ ẹran rẹ̀ ní ibi mímọ́ kan. 32 Ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ àjọ ni Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ yóò ti jẹ ẹran àgbò náà àti àkàrà náà tí ó wà nínú apẹ̀rẹ̀. 33 Wọn yóò sì jẹ nǹkan wọ̀nyí èyí tí a fi ṣe ètùtù náà fún ìyàsímímọ́ àti ìsọdimímọ́ wọn. Ṣùgbọ́n àlejò ni kò gbọdọ̀ jẹ nínú rẹ̀, nítorí pé mímọ́ ni. 34 Bí ohun kan nínú ẹran àgbò ìyàsímímọ́ tàbí nínú àkàrà náà bá kù di òwúrọ̀, nígbà náà ni kí ìwọ fi iná sun wọn. A kò gbọdọ̀ jẹ ẹ́, nítorí mímọ́ ni.
35 “Báyìí ni ìwọ yóò ṣì ṣe fún Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ bí ohun gbogbo ti mo paláṣẹ fún ọ, ọjọ́ méje ni ìwọ yóò fi yà wọ́n sí mímọ́. 36 Ìwọ yóò sì máa pa akọ màlúù kọ̀ọ̀kan ní ojoojúmọ́ bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ láti ṣe ètùtù. Ìwọ yóò sì wẹ pẹpẹ mọ́ nípa ṣíṣe ètùtù fún un, ìwọ yóò sì ta òróró sí i láti sọ ọ́ dí mímọ́. 37 Ní ọjọ́ méje ni ìwọ yóò ṣe ètùtù sí pẹpẹ náà, ìwọ yóò sì sọ ọ́ di mímọ́. Nígbà náà ni pẹpẹ náà yóò jẹ́ mímọ́ jùlọ, àti ohunkóhun tí ó bá fi ọwọ́ kàn án yóò jẹ́ mímọ́.
38 (H)“Èyí ni ìwọ yóò máa fi rú ẹbọ ní orí pẹpẹ náà: Ọ̀dọ́-Àgùntàn méjì ọlọ́dún kan ni ojoojúmọ́ láéláé. 39 Ọ̀dọ́-Àgùntàn kan ni ìwọ yóò fi rú ẹbọ ní òwúrọ̀ àti ọ̀dọ́-àgùntàn èkejì ní àṣálẹ́. 40 Pẹ̀lú ọ̀dọ́-àgùntàn ti àkọ́kọ́ rú ẹbọ ìdámẹ́wàá òṣùwọ̀n ìyẹ̀fun dídára tí a fi ìdámẹ́rin hínì òróró lára olifi tí a gún, àti ìdámẹ́rin hínì wáìnì bí ẹbọ mímu. 41 Ọ̀dọ́-Àgùntàn kejì ni kí ìwọ kí ó pa rú ẹbọ ní àṣálẹ́ ìwọ yóò sì ṣe sí í gẹ́gẹ́ bí ẹbọ jíjẹ àti ẹbọ mímu bí ti òwúrọ̀ fún òórùn dídùn, ẹbọ tí a fi iná ṣe ni sí Olúwa.
42 “Fún ìrandíran tó ń bọ̀, ni ẹ ó máa ṣe ẹbọ sísun nígbà gbogbo ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ àjọ níwájú Olúwa. Níbẹ̀ èmi yóò pàdé yín, èmi yóò sì bá a yín sọ̀rọ̀; 43 níbẹ̀ sì tún ni èmi yóò pàdé àwọn ọmọ Israẹli, a ó sì fi ògo mi ya àgọ́ náà sí mímọ́.
44 “Bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò ya àgọ́ àjọ náà sí mímọ́ àti pẹpẹ náà, èmi yóò sì ya Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ sí mímọ́ láti máa ṣe iṣẹ́ bí àlùfáà fún mi. 45 Nígbà náà ni èmi yóò máa gbé láàrín àwọn ọmọ Israẹli, èmi yóò sì máa ṣe Ọlọ́run wọn. 46 Wọn yóò sì mọ̀ pé èmi ni Olúwa Ọlọ́run wọn, ẹni tí ó mú wọn jáde láti ilẹ̀ Ejibiti wá, nítorí kí èmi lè máa gbé àárín wọn. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run wọn.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.