Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Chronological

Read the Bible in the chronological order in which its stories and events occurred.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Numeri 8-10

Gbígbé ọ̀pá fìtílà ró

Olúwa sọ fún Mose pé: “Bá Aaroni sọ̀rọ̀ kí o wí fún un pé. ‘Nígbà tí ó bá ń to àwọn fìtílà, àwọn fìtílà méjèèje gbọdọ̀ tan ìmọ́lẹ̀ sí àyíká níwájú ọ̀pá fìtílà.’ ”

Aaroni sì ṣe bẹ́ẹ̀; ó to àwọn fìtílà náà tí wọ́n sì fi kojú síwájú lórí ọ̀pá fìtílà gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose. Bí a ṣe ṣe ọ̀pá fìtílà náà nìyìí: A ṣe é láti ara wúrà lílù: láti ìsàlẹ̀ títí dé ibi ìtànná rẹ̀. Wọ́n ṣe ọ̀pá fìtílà náà gẹ́gẹ́ bí bátànì tí Olúwa fihan Mose.

Ìyàsọ́tọ̀ àwọn ọmọ Lefi

Olúwa sọ fún Mose pé: (A)“Yọ àwọn ọmọ Lefi kúrò láàrín àwọn ọmọ Israẹli yòókù, kí o sì wẹ̀ wọ́n mọ́. Báyìí ni kí o ṣe wẹ̀ wọ́n mọ́: Wọ́n omi ìwẹ̀nùmọ́ sí wọn lára, mú kí wọn ó fá irun ara wọn, kí wọn ó fọ aṣọ wọn, kí wọn ó ba à lè wẹ ara wọn mọ́ nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀. Jẹ́ kí wọn ó mú akọ ọ̀dọ́ màlúù pẹ̀lú ẹbọ ohun jíjẹ rẹ̀ tí í ṣe ìyẹ̀fun ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára tí a fi òróró pò, kí ìwọ náà mú akọ ọ̀dọ́ màlúù kejì fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀. Ìwọ ó sì mú àwọn ọmọ Lefi wá síwájú àgọ́ ìpàdé, kí o sì kó gbogbo àpapọ̀ ọmọ Israẹli jọ síbẹ̀ pẹ̀lú. 10 Báyìí ni kí o mú àwọn ọmọ Lefi wá síwájú Olúwa, gbogbo ọmọ Israẹli yóò sì gbọ́wọ́ lé àwọn ọmọ Lefi lórí. 11 Aaroni yóò sì mú àwọn ọmọ Lefi wá síwájú Olúwa gẹ́gẹ́ bí ọrẹ fífì láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Israẹli wá, kí wọn lè máa ṣiṣẹ́ Olúwa.

12 “Lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Lefi bá gbé ọwọ́ wọn lé orí àwọn akọ ọmọ màlúù náà, ìwọ yóò sì fi ọ̀kan rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti èkejì fún ẹbọ sísun sí Olúwa, láti ṣe ètùtù fún àwọn ọmọ Lefi. 13 Mú kí àwọn ọmọ Lefi dúró níwájú Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ kí ó sì gbé wọn kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ fífì sí Olúwa. 14 Báyìí ni ìwọ yóò ṣe ya ọmọ Lefi sọ́tọ̀, kúrò láàrín àwọn ọmọ Israẹli yòókù, àwọn ọmọ Lefi yóò sì jẹ́ tèmi.

15 “Lẹ́yìn tí ó ti wẹ àwọn ọmọ Lefi mọ́, tí ó sì ti gbé wọn kalẹ̀ bí ẹbọ fífì nígbà náà ni kí wọn ó lọ máa ṣiṣẹ́ nínú àgọ́ ìpàdé. 16 Nítorí pé àwọn ni ó jẹ́ ti Èmi pátápátá nínú àwọn ọmọ Israẹli. Mo ti gbà wọ́n fún ara mi dípò àwọn àkọ́bí àní àkọ́bí ọkùnrin gbogbo Israẹli. 17 Nítorí pé gbogbo àkọ́bí ọmọ lọ́kùnrin ní Israẹli jẹ́ tèmi, ti ènìyàn àti ti ẹranko, láti ọjọ́ tí mo ti pa gbogbo àkọ́bí ní ilẹ̀ Ejibiti ni mo ti yà wọ́n sọ́tọ̀ fún ara mi. 18 (B)Mo sì ti gba àwọn ọmọ Lefi dípò gbogbo àkọ́bí ọmọ ọkùnrin nínú Israẹli 19 Nínú Israẹli, mo fi àwọn ọmọ Lefi fún Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn láti máa ṣiṣẹ́ nínú àgọ́ ìpàdé fun àwọn ọmọ Israẹli àti láti máa ṣe ètùtù fún wọn kí àjàkálẹ̀-ààrùn má ba à kọlu àwọn ọmọ Israẹli nígbà tí wọ́n bá súnmọ́ ibi mímọ́.”

20 Mose, Aaroni àti gbogbo ìjọ ènìyàn Israẹli sì ṣe fún àwọn ọmọ Lefi gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose. 21 Àwọn ọmọ Lefi wẹ ara wọn mọ́, wọ́n sì fọ aṣọ wọn. Aaroni sì mú wọn wá gẹ́gẹ́ bí ọrẹ fífì níwájú Olúwa, Aaroni sì ṣe ètùtù fún wọn láti wẹ̀ wọ́n mọ́. 22 Lẹ́yìn èyí àwọn ọmọ Lefi lọ sínú àgọ́ ìpàdé láti lọ máa ṣiṣẹ́ wọn lábẹ́ àbojútó Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀. Wọ́n ṣe fún àwọn ọmọ Lefi gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

23 Olúwa sọ fún Mose pé, 24 “Èyí ni ohun tó jẹ mọ́ àwọn ọmọ Lefi: Láti ọmọ ọdún kẹẹdọ́gbọ̀n tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ni kí ó máa kópa nínú iṣẹ́ àgọ́ ìpàdé. 25 Ṣùgbọ́n ẹni tó bá ti pé ọmọ àádọ́ta ọdún gbọdọ̀ ṣíwọ́ nínú iṣẹ́ ojoojúmọ́ wọn nínú àgọ́, kí wọ́n sì má ṣiṣẹ́ mọ́ 26 Wọ́n le máa ran àwọn arákùnrin wọn lọ́wọ́ nínú àgọ́ ìpàdé ṣùgbọ́n àwọn fúnrawọn kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan. Báyìí ni kí o ṣe pín iṣẹ́ fún àwọn ọmọ Lefi.”

Àsè ìrékọjá

(C)Olúwa sọ fún Mose nínú aginjù Sinai ní oṣù kìn-ín-ní ọdún kejì lẹ́yìn tí wọ́n kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti wí pé; “Mú kí àwọn ọmọ Israẹli máa pa àjọ ìrékọjá mọ́ ní àsìkò rẹ̀. Ẹ ṣe é ní àsìkò rẹ̀ gan an ní ìdajì ọjọ́ kẹrìnlá oṣù yìí ní ìbámu pẹ̀lú àwọn òfin àti ìlànà rẹ̀.”

Mose sì sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé kí wọ́n máa pa àjọ ìrékọjá mọ́. Wọ́n sì ṣe àjọ ìrékọjá ní aginjù Sinai ní ìdajì ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kìn-ín-ní. Àwọn ọmọ Israẹli ṣe gbogbo nǹkan gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

Àwọn díẹ̀ nínú wọn kò lè ṣe àjọ Ìrékọjá lọ́jọ́ náà nítorí pé wọ́n di aláìmọ́ nítorí òkú ènìyàn. Nítorí èyí wọ́n wá sọ́dọ̀ Mose àti Aaroni lọ́jọ́ náà. Wọ́n sọ fún Mose pé, “A di aláìmọ́ nípa òkú ènìyàn, ṣùgbọ́n kí ló dé tí a kò fi ní í le è fi ọrẹ wa fún Olúwa pẹ̀lú àwọn ará Israẹli yòókù ní àsìkò tí a ti yàn.”

Mose sì dá wọn lóhùn pé, “Ẹ dúró kí n ba lè mọ ohun tí Olúwa yóò pàṣẹ nípa yín.”

Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mose pé, 10 “Sọ fún àwọn ará Israẹli: ‘Bí ẹnìkan nínú yín tàbí nínú ìran yín bá di aláìmọ́ nípa òkú ènìyàn tàbí bí ó bá lọ sí ìrìnàjò síbẹ̀ yóò pa àjọ Ìrékọjá Olúwa mọ́. 11 Wọn yóò ṣe tiwọn ní ìdajì ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kejì. Wọn yóò jẹ ẹran náà, pẹ̀lú àkàrà aláìwú àti ewúro. 12 (D)Wọn kò gbọdọ̀ ṣẹ́ ọ̀kankan kù di àárọ̀, wọn kò sì gbọdọ̀ ṣẹ́ eegun rẹ̀. Wọ́n gbọdọ̀ tẹ̀lé gbogbo ìlànà fún ṣíṣe àjọ Ìrékọjá. 13 Ṣùgbọ́n bí ẹnìkan tó wà ní mímọ́ tí kò sì lọ sí ìrìnàjò bá kọ̀ láti pa àjọ Ìrékọjá mọ́, irú ẹni bẹ́ẹ̀ ni a ó gé kúrò láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀ nítorí pé kò mú ọrẹ Olúwa wá ní àsìkò tí ó yẹ. Ẹni náà yóò sì ru ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.

14 “ ‘Bí àlejò tí ń gbé láàrín yín bá fẹ́ ṣe Àjọ Ìrékọjá Olúwa, ó gbọdọ̀ pa á mọ́ ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà àti òfin rẹ̀. Ìlànà kan náà ni kí ẹ ní fún àlejò àti àwọn ọmọ bíbí ilẹ̀ yín.’ ”

Ìkùùkuu lórí àgọ́

15 (E)Ní ọjọ́ tí wọ́n gbé àgọ́ ró, èyí tí í ṣe àgọ́ ẹ̀rí, dúró, ìkùùkuu àwọsánmọ̀ bò ó mọ́lẹ̀. Ìkùùkuu náà sì dàbí iná ní orí àgọ́ láti ìrọ̀lẹ́ títí di òwúrọ̀. 16 Bẹ́ẹ̀ ni ó sì rí nígbà gbogbo; ìkùùkuu bò ó, àti pé ní alẹ́ ìrísí rẹ̀ sì dàbí iná. 17 Nígbàkígbà tí ìkùùkuu yìí bá ká sókè kúrò lórí àgọ́ ni àwọn ọmọ Israẹli yóò dìde láti máa lọ; ibikíbi tí ìkùùkuu náà bá dúró sí ni àwọn ọmọ Israẹli yóò pa ibùdó wọn sí. 18 Nípa àṣẹ Olúwa ni àwọn ọmọ Israẹli ń jáde lọ, nípa àṣẹ Olúwa náà sì ni wọ́n ń pa ibùdó wọn. Nígbà tí ìkùùkuu bá dúró sórí àgọ́, àwọn náà yóò dúró sí ibùdó. 19 Nígbà tí ìkùùkuu bá dúró sórí àgọ́ fún ìgbà pípẹ́, síbẹ̀ àwọn ọmọ Israẹli gbọ́rọ̀ sí àṣẹ Olúwa wọn kò sì ní gbéra láti lọ. 20 Ìgbà mìíràn ìkùùkuu lè wà lórí àgọ́ fún ọjọ́ díẹ̀; síbẹ̀ ní àṣẹ Olúwa, wọn yóò dúró ní ibùdó, bí ó sì tún yá, ní àṣẹ rẹ̀ náà ni wọn yóò gbéra. 21 Ìgbà mìíràn ìkùùkuu lè dúró láti ìrọ̀lẹ́ di àárọ̀, nígbà tó bá ṣí kúrò ní àárọ̀, wọn ó gbéra. Ìbá à ṣe ní ọ̀sán tàbí òru, ìgbàkígbà tí ìkùùkuu bá tó kúrò náà ni wọn ó tó gbéra. 22 Ìbá à ṣe fún ọjọ́ méjì, oṣù kan tàbí ọdún kan ni ìkùùkuu fi dúró sórí àgọ́, àwọn ọmọ Israẹli yóò dúró ní ibùdó wọn, wọn kò ní gbéra; ṣùgbọ́n nígbà tí ó bá lọ sókè ni wọn ó tó o gbéra. 23 Nípa àṣẹ Olúwa ni wọ́n ń pa ibùdó wọn, nípa àṣẹ Olúwa náà sì ni wọ́n ń gbéra. Wọ́n gbọ́rọ̀ sí àṣẹ Olúwa ní ìbámu pẹ̀lú àṣẹ Olúwa láti ẹnu Mose.

Fèrè ìpè fàdákà

10 Olúwa sọ fún Mose pé: Ṣe fèrè fàdákà méjì pẹ̀lú fàdákà lílù, kí o máa lò ó láti máa fi pe ìjọ ènìyàn àti láti máa fi darí ìrìnàjò lọ sí ibùdó yín. Nígbà tí o bá fọn méjèèjì gbogbo ìjọ ènìyàn yóò pé síwájú rẹ ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé. Bí ó bá jẹ́ ọ̀kan ni o fọn, nígbà náà ni àwọn olórí ẹ̀yà Israẹli yóò péjọ síwájú rẹ. Nígbà tí o bá fun ìpè ìdágìrì, àwọn ẹ̀yà tó pa ibùdó sí ìhà ìlà-oòrùn ni yóò gbéra. Nígbà tí o bá fun ìpè ìdágìrì kejì, ibùdó tó wà ní ìhà gúúsù ni yóò gbéra. Ìpè ìdágìrì yìí ni yóò jẹ́ ààmì fún gbígbéra. Nígbà tí o bá fẹ́ pe ìjọ ènìyàn jọ, fun fèrè nìkan, má ṣe fun ti ìdágìrì pẹ̀lú rẹ̀.

“Àwọn ọmọ Aaroni tí í ṣe àlùfáà ni kí ó máa fun fèrè. Èyí yóò jẹ́ ìlànà láéláé fún yín àti fún ìran tó ń bọ̀. Nígbà tí ẹ bá lọ jagun pẹ̀lú àwọn ọ̀tá tó ń ni yín lára ní ilẹ̀ yín, ẹ fun ìpè ìdágìrì pẹ̀lú fèrè. A ó sì rántí yín níwájú Olúwa, Ọlọ́run yín yóò sì gbà yín lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá yín. 10 Bẹ́ẹ̀ náà ni ní ọjọ́ ayọ̀ yín, ní gbogbo àjọ̀dún tí a yàn àti ní ìbẹ̀rẹ̀ oṣù yín, ni kí ẹ máa fun fèrè lórí ẹbọ sísun àti ọrẹ àlàáfíà yín, wọn yóò sì jẹ́ ìrántí fún yín níwájú Ọlọ́run. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.”

Àwọn ọmọ Israẹli kúrò ní Sinai

11 Ní ogúnjọ́ oṣù kejì, ní ọdún kejì ni ìkùùkuu kúrò lórí tabanaku ẹ̀rí. 12 Àwọn ọmọ Israẹli sì gbéra kúrò ní aginjù Sinai wọ́n sì rin ìrìnàjò wọn káàkiri títí tí ìkùùkuu fi dúró sí aginjù Parani. 13 Wọ́n gbéra nígbà àkọ́kọ́ yìí nípa àṣẹ Olúwa láti ẹnu Mose.

14 Àwọn ìpín ti ibùdó Juda ló kọ́kọ́ gbéra tẹ̀lé wọn lábẹ́ ogun wọn Nahiṣoni ọmọ Amminadabu ni ọ̀gágun wọn. 15 Netaneli ọmọ Ṣuari ni ọ̀gágun ti ẹ̀yà Isakari; 16 Eliabu ọmọ Heloni ni ọ̀gágun ni ìpín ti ẹ̀yà Sebuluni. 17 Nígbà náà ni wọ́n sọ tabanaku kalẹ̀ àwọn ọmọ Gerṣoni àti Merari tó gbé àgọ́ sì gbéra.

18 Àwọn ìpín ti ibùdó ti Reubeni ló gbéra tẹ̀lé wọn, lábẹ́ ọ̀págun wọn. Elisuri ọmọ Ṣedeuri ni ọ̀gágun wọn. 19 Ṣelumieli ọmọ Suriṣaddai ni ọ̀gágun ti ẹ̀yà Simeoni. 20 Eliasafu ọmọ Deueli ni ọ̀gágun ìpín ti ẹ̀yà Gadi. 21 Nígbà náà ni àwọn ọmọ Kohati tí ń ru ohun mímọ́ náà gbéra. Àwọn ti àkọ́kọ́ yóò sì ti gbé tabanaku dúró kí wọn tó dé.

22 Àwọn ìpín tó wà ní ibùdó Efraimu ló tún kàn lábẹ́ ọ̀págun wọn. Eliṣama ọmọ Ammihudu ni ọ̀gágun wọn. 23 Gamalieli ọmọ Pedasuri ni ọ̀gágun ìpín ti ẹ̀yà Manase. 24 Abidani ọmọ Gideoni ni ọ̀gágun ìpín ti ẹ̀yà Benjamini.

25 Lákòótan, àwọn ọmọ-ogun tó ń mójútó ẹ̀yìn ló tún kàn, àwọn ni ìpín ti ibùdó Dani lábẹ́ ọ̀págun wọn. Ahieseri ọmọ Ammiṣaddai ni ọ̀gágun wọn. 26 Pagieli ọmọ Okanri ni ìpín ti ẹ̀yà Aṣeri, 27 Ahira ọmọ Enani ni ọ̀gágun ti ẹ̀yà Naftali; 28 Báyìí ni àwọn ọmọ Israẹli ṣe tò jáde gẹ́gẹ́ bí ogun nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò wọn.

29 Mose sì sọ fún Hobabu ọmọ Reueli ará Midiani tí í ṣe àna rẹ̀ pé, “A ń gbéra láti lọ sí ibi tí Olúwa sọ pé, ‘Èmi ó fi fún un yín.’ Bá wa lọ, àwa ó ṣe ọ́ dáradára nítorí pé Olúwa ti ṣèlérí ohun rere fún Israẹli.”

30 Ó sì dáhùn pé, “Rárá, èmi kò ní bá yín lọ, mò ń padà lọ sí ilẹ̀ mi àti sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn mi.”

31 Mose sì sọ pé, “Jọ̀wọ́ ma fi wá sílẹ̀, ìwọ mọ ibi tí a lè pa ibùdó sí nínú aginjù, ìwọ yóò sì jẹ́ ojú fún wa. 32 Bí o bá bá wa lọ, a ó sì pín fún ọ nínú ohun rere yówù tí Olúwa bá fún wa.”

33 Wọ́n sì gbéra láti orí òkè Olúwa ní ìrìn ọjọ́ mẹ́ta. Àpótí ẹ̀rí Olúwa ń lọ níwájú wọn fún gbogbo ọjọ́ mẹ́ta yìí láti wá ibi ìsinmi fún wọn. 34 Ìkùùkuu Olúwa wà lórí wọn lọ́sàn nígbà tí wọ́n gbéra kúrò ní ibùdó.

35 (F)Nígbàkígbà tí àpótí ẹ̀rí bá gbéra Mose yóò sì wí pé,

“Dìde, Olúwa!
    Kí a tú àwọn ọ̀tá rẹ ká,
    kí àwọn tí ó kórìíra rẹ sì sálọ níwájú rẹ.”

36 Nígbàkígbà tí àpótí ẹ̀rí bá sinmi yóò wí pé;

“Padà, Olúwa,
    Sọ́dọ̀ àwọn àìmoye ẹgbẹẹgbẹ̀rún Israẹli.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.