Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Chronological

Read the Bible in the chronological order in which its stories and events occurred.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Lefitiku 16-18

Ọjọ́ ètùtù ìwẹ̀nùmọ́ ẹ̀ṣẹ̀

16 Olúwa sọ fún Mose lẹ́yìn ikú àwọn ọmọ Aaroni méjèèjì tí wọ́n kú nígbà tí wọ́n súnmọ́ Olúwa. (A)Olúwa sì sọ fún Mose pé “Kìlọ̀ fún Aaroni arákùnrin rẹ pé kí ó má ṣe máa wá nígbà gbogbo sí ibi mímọ́ jùlọ tí ó wà lẹ́yìn aṣọ títa ní ibi tí àpótí ẹ̀rí àti ìtẹ́ àánú wà, kí ó má ba à kú” nítorí pé Èmi ó farahàn nínú ìkùùkuu lórí ìtẹ́ àánú.

(B)Báyìí ni Aaroni yóò ṣe máa wá sí ibi mímọ́ pẹ̀lú ọ̀dọ́ akọ màlúù fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti àgbò fún ẹbọ sísun. Òun yóò sì wọ aṣọ funfun mímọ́ pẹ̀lú àwọ̀tẹ́lẹ̀ funfun, yóò sì fi àmùrè funfun mímọ́ dì í: yóò sì dé fìlà funfun: àwọn aṣọ mímọ́ nìwọ̀nyí: Òun yóò sì fi omi wẹ̀, kí ó tó wọ̀ wọ́n. Òun yóò sì mú ọmọ ewúrẹ́ méjì láti ọ̀dọ̀ gbogbo àgbájọpọ̀ àwọn ọmọ Israẹli láti fi ṣe ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ wọ́n: àti àgbò kan fún ẹbọ sísun.

Aaroni yóò sì fi akọ màlúù rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ èyí tí ṣe ti ara rẹ̀ òun yóò sì ṣe ètùtù fún ara rẹ̀ àti ìdílé rẹ̀. Lẹ́yìn náà yóò sì mú ewúrẹ́ méjì náà wá sí iwájú Olúwa ní ibi ìlẹ̀kùn àgọ́ ìpàdé. Aaroni yóò sì dìbò ní ti àwọn ewúrẹ́ méjèèjì náà, ìbò àkọ́kọ́ fún ti Olúwa, àti èkejì fún ewúrẹ́ ìpààrọ̀. Aaroni yóò sì mú ewúrẹ́ tí ìbò Ọlọ́run mú, yóò sì fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀. 10 Ṣùgbọ́n ewúrẹ́ tí ìbò bá mú gẹ́gẹ́ bí ewúrẹ́ ìpààrọ̀ ni a ó mú wá láààyè síwájú Olúwa láti fi ṣe ètùtù sí i àti láti jẹ́ kí ó lọ lọ́fẹ̀ẹ́, sí aginjù.

Ètùtù fún olórí àlùfáà

11 Aaroni yóò sì mú akọ màlúù fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ wá láti ṣe ètùtù fún ara rẹ̀ àti ìdílé rẹ̀. Yóò sì pa akọ màlúù náà fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ tirẹ̀. 12 Yóò sì mú àwo tùràrí tí ó kún fún èédú tí a ti sun pẹ̀lú iná láti orí pẹpẹ wá síwájú Olúwa: àti ẹ̀kúnwọ́ méjì tùràrí tí a gún kúnná yóò sì mú un wá sí ẹ̀yìn aṣọ títa. 13 Yóò sì fi tùràrí náà lé orí iná níwájú Olúwa: kí èéfín tùràrí náà ba à le bo ìtẹ́ àánú tí ó wà ní orí àpótí ẹ̀rí kí o má ba à kú. 14 Yóò sì mú nínú ẹ̀jẹ̀ ọmọ màlúù náà yóò sì fi ìka rẹ̀ wọ́n ọn, ní iwájú ìtẹ́ àánú, yóò sì fi ìka rẹ̀ wọ́n ọn nígbà méje níwájú ìtẹ́ àánú.

Ètùtù fún àwọn ènìyàn

15 (C)Nígbà yìí ni yóò pa ewúrẹ́ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ tí ó wà fún àwọn ènìyàn yóò sì mú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wá sí ẹ̀yìn aṣọ títa, bí ó ti ṣe ẹ̀jẹ̀ akọ màlúù náà ni yóò ṣe ti ewúrẹ́ yìí, yóò sì wọ́n ọn sórí ìtẹ́ ètùtù àti síwájú ìtẹ́ ètùtù. 16 Báyìí ni yóò ṣe ètùtù fún ibi mímọ́ jùlọ nítorí àìmọ́ àwọn ará Israẹli àti nítorí gbogbo ìrékọjá wọn àti ìṣọ̀tẹ̀ wọn nípa ẹ̀ṣẹ̀ wọn gbogbo, bákan náà ni yóò sì ṣe fún àgọ́ ìpàdé, èyí tí ó wà láàrín wọn nínú àìmọ́ wọn. 17 Kí ó má ṣe sí ẹyọ ènìyàn kan nínú àgọ́ ìpàdé nígbà tí òun bá wọ ibi mímọ́ lọ láti ṣe ètùtù: títí di ìgbà tí yóò fi jáde lẹ́yìn tí ó ba ṣe ètùtù fúnrarẹ̀ fún ìdílé rẹ̀ àti fún gbogbo àgbájọpọ̀ Israẹli.

18 Lẹ́yìn náà òun yóò lọ sí ibi pẹpẹ tí ó wà níwájú Olúwa: yóò sì ṣe ètùtù fún pẹpẹ náà. Yóò sì mú nínú ẹ̀jẹ̀ akọ màlúù àti nínú ẹ̀jẹ̀ ewúrẹ́ náà, yóò sì fi sí orí ọ̀kọ̀ọ̀kan ìwo pẹpẹ náà yíká. 19 Lẹ́yìn náà, òun yóò wọ́n ẹ̀jẹ̀ náà sórí rẹ̀ pẹ̀lú ìka rẹ̀ nígbà méje láti wẹ̀ ẹ́ mọ́ àti láti sọ ọ́ dí mímọ́ kúrò nínú àìmọ́ àwọn ọmọ Israẹli.

20 Lẹ́yìn ti Aaroni ti parí ṣíṣe ètùtù ti ibi mímọ́ jùlọ, ti àgọ́ ìpàdé àti ti pẹpẹ: òun yóò sì mú ààyè ewúrẹ́ wá. 21 Aaroni yóò sì gbé ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì lé orí ààyè ewúrẹ́ náà, yóò sì jẹ́wọ́ gbogbo ìwà búburú àti ìṣọ̀tẹ̀ àwọn ara Israẹli lé e lórí: gbogbo ìrékọjá wọn àti ẹ̀ṣẹ̀ wọn ni yóò sì gbé ka orí ewúrẹ́ náà. Yóò sì rán an lọ sí ijù láti ọwọ́ ẹni tí a yàn fún iṣẹ́ náà. 22 Ewúrẹ́ náà yóò sì ru gbogbo àìṣedéédéé wọn lọ sí ilẹ̀ tí ènìyàn kò gbé. Òun yóò sì jọ̀wọ́ ewúrẹ́ náà lọ́wọ́ lọ sínú ijù.

23 (D)Aaroni yóò sì padà wá sí ibi àgọ́ ìpàdé, yóò sì bọ́ aṣọ ọ̀gbọ̀ wọ̀n-ọn-nì sílẹ̀, tí ó wọ̀ nígbà tí ó lọ sí ibi mímọ́ jùlọ, yóò sì fi wọ́n sílẹ̀ níbẹ̀ 24 Yóò sì fi omi wẹ ara rẹ̀ ní ibi mímọ́ kan: yóò sì wọ aṣọ rẹ̀ yóò sì wá ṣí iwájú: yóò sì rú ẹbọ sísun ti ara rẹ̀ àti ẹbọ sísun ti àwọn ènìyàn láti ṣe ètùtù fún ara rẹ̀ àti fún àwọn ènìyàn: 25 Òun yóò sì sun ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ náà lórí pẹpẹ.

26 Ẹni tí ó tú ewúrẹ́ ìpààrọ̀ náà sílẹ̀ yóò sì fọ aṣọ rẹ̀: yóò sì wẹ ara rẹ̀ nínú omi: lẹ́yìn èyí ó lè wá sí ibùdó. 27 (E)Ọ̀dọ́ akọ màlúù àti ewúrẹ́ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ tí a ti mú ẹ̀jẹ̀ wọn wá sí ibi mímọ́ jùlọ ni kí a gbe jáde kúrò ní ibùdó. Awọ wọn ni a ó fi iná sun bákan náà. 28 Ẹni tí ó sun wọ́n yóò sì fọ aṣọ rẹ̀: yóò sì wẹ ara rẹ̀: lẹ́yìn èyí ni ó tó le wọ ibùdó.

29 (F)Èyí ni yóò jẹ́ ìlànà títí láé fún un yín: pé ní ọjọ́ kẹwàá oṣù keje ni ẹ gbọdọ̀ ṣẹ́ ara yín: kí ẹ má ṣe ṣe iṣẹ́ kankan, yálà onílé tàbí àlejò tí ó ń gbé pẹ̀lú yín. 30 Torí pé ní ọjọ́ yìí ni àlùfáà yóò ṣe ètùtù fún yín láti sọ yín di mímọ́: kí ẹ̀yin bá à le mọ́ níwájú Olúwa yín kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ yín gbogbo. 31 Ọjọ́ yìí yóò jẹ́ ọjọ́ ìsinmi pátápátá fún un yín: ẹ̀yin yóò sì ṣẹ́ ara yín: Èyí yóò sì jẹ́ ìlànà títí láé. 32 Àlùfáà náà tí a ti fi òróró yàn tí a sì ti sọ di mímọ́ láti máa ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ ní ilé ìsìn ní ipò baba rẹ̀: òun ni kí ó ṣe ètùtù: yóò sì wọ aṣọ funfun gbòò àní aṣọ mímọ́ náà: òun yóò sì ṣe ètùtù. 33 Yóò sì ṣe ètùtù fún àgọ́ ìpàdé àti fún pẹpẹ: yóò sì ṣe ètùtù fún àlùfáà àti fún gbogbo àgbájọpọ̀ àwọn ènìyàn náà.

34 “Èyí ni yóò jẹ́ ìlànà ayérayé fún yín: láti máa ṣe ètùtù fún àwọn ará Israẹli fún gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wọn lẹ́ẹ̀kan lọ́dún.”

Ó sì ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

Ẹ̀jẹ̀ jíjẹ jẹ́ èèwọ̀

17 Olúwa sọ fún Mose pé: “Sọ fún Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ Israẹli: ohun tí Ọlọ́run pàṣẹ nìyí: Bí ẹnikẹ́ni nínú ìdílé Israẹli bá pa màlúù tàbí ọ̀dọ́-àgùntàn tàbí àgbò nínú ibùdó tàbí bí ó bá pa á lẹ́yìn ibùdó tí kò sì mú un wá sí ibi àgọ́ ìpàdé láti fi rú ẹbọ sí Olúwa níwájú àgọ́ ìpàdé: ẹ̀bi ìtàjẹ̀ sílẹ̀ ni kí ẹ kà sí ẹni náà lọ́rùn: torí pé ó ti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀: ẹni náà ni a ó sì gé kúrò láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀. Èyí rí bẹ́ẹ̀ kí àwọn ọmọ Israẹli le è máa mú ẹbọ wọn tí wọn ti rú ní ìta gbangba wá sí iwájú Olúwa: wọ́n gbọdọ̀ mú un wá síwájú àlùfáà àní sí Olúwa ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé: kí wọ́n sì rú wọn gẹ́gẹ́ bí ẹbọ àlàáfíà sí Olúwa. Àlùfáà náà yóò sì fi ẹ̀jẹ̀ náà wọ́n ibi pẹpẹ Olúwa ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, yóò sì sun ọ̀rá rẹ̀ ní òórùn dídùn sí Olúwa. Nítorí náà, kí wọn má ṣe rú ẹbọ wọn sí ère ẹranko mọ́, nínú èyí tí wọ́n ti ṣe àgbèrè tọ̀ lọ. Èyí yóò sì jẹ́ ìlànà títí láé láti ìran dé ìran wọn tí ń bọ̀.

“Kí ó sọ fún wọn pé: ‘Ọkùnrin yówù kí ó jẹ́ ní ìdílé Israẹli tàbí ti àwọn àlejò tí ń gbé láàrín wọn tí ó bá rú ẹbọ sísun tàbí ṣe ẹbọ tí kò sì mú un wá sí ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé láti fi rú ẹbọ sí Olúwa irú ẹni bẹ́ẹ̀ ni a ó gé kúrò láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀.

10 (G)“ ‘Bí ẹnikẹ́ni bá jẹ ẹ̀jẹ̀ yálà nínú ìdílé Israẹli tàbí àwọn àlejò tí ń gbé láàrín wọn: Èmi yóò bínú sí irú ẹni náà tí ó jẹ ẹ̀jẹ̀: èmi yóò sì gé e kúrò láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀. 11 Nítorí pé nínú ẹ̀jẹ̀ ni ẹ̀mí ẹ̀dá wà, èmi sì ti fi fún yín lórí pẹpẹ fún ètùtù ọkàn yín: nítorí pé ẹ̀jẹ̀ ni a fi ń ṣe ètùtù fún ẹ̀mí ènìyàn. 12 Ìdí nìyí tí mo fi sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, ọ̀kankan nínú yín kò gbọdọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni àlejò kan tí ń ṣe àtìpó nínú yín kò gbọdọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀.

13 “ ‘Ẹnikẹ́ni yálà nínú àwọn ọmọ Israẹli tàbí àlejò tí ń gbé láàrín wọn, tí ó bá pa ẹranko tàbí ẹyẹ tí ó yẹ fún jíjẹ gbọdọ̀ ro ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sílẹ̀ kí ó sì bò ó mọ́lẹ̀. 14 Torí pé ẹ̀mí gbogbo ẹ̀dá ni ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, torí náà ni mo fi kìlọ̀ fún àwọn ọmọ Israẹli pé wọn kò gbọdọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀ ohun abẹ̀mí kankan: torí pé nínú ẹ̀jẹ̀ ohun abẹ̀mí wọ̀nyí ni ẹ̀mí wọn wà: ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ ẹ́ ni a ó gé kúrò.

15 “ ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ ohun tí ó kú sílẹ̀ fúnrarẹ̀: tàbí èyí tí ẹranko búburú pa kálẹ̀ yálà onílé tàbí àlejò: ó ní láti fọ aṣọ rẹ̀. Kí ó sì fi omi wẹ ara rẹ̀: yóò sì wà ní ipò àìmọ́ títí di àṣálẹ́ lẹ́yìn èyí ni yóò tó di mímọ́. 16 Ṣùgbọ́n bí ó bá kọ̀ láti wẹ ara rẹ̀ tí kò sì fọ aṣọ rẹ̀ náà: ẹ̀bi rẹ̀ yóò wà lórí ara rẹ̀.’ ”

Ìbálòpọ̀ tí kò bá òfin mu

18 Olúwa sọ fún Mose pé: “Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé: ‘èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín. Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe bí wọ́n ti ń ṣe ní Ejibiti níbi tí ẹ ti gbé rí: bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣe bí wọ́n ti ń ṣe ní ilẹ̀ Kenaani níbi tí èmi ń mú yín lọ. Ẹ kò gbọdọ̀ tẹ̀lé ìṣe wọn. Kí ẹ̀yin kí ó sì máa ṣe òfin mi, kí ẹ̀yin sì máa pa ìlànà mi mọ́, láti máa rìn nínú wọn, Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín. (H) Ẹ̀yin ó sì máa pa ìlànà mi mọ́ àti òfin mi; Ẹni tí ó ba ṣe, yóò yè nípa wọn: Èmi ni Olúwa.

“ ‘Ẹnikẹ́ni nínú yín kò gbọdọ̀ súnmọ́ ìbátan rẹ̀ láti bá a lòpọ̀, èmí ni Olúwa.

(I)“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ tàbùkù baba rẹ nípa bíbá ìyá rẹ lòpọ̀, ìyá rẹ̀ ni, ìwọ kò gbọdọ̀ bá a lòpọ̀.

“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ tàbùkù baba rẹ nípa bíbá ìyàwó baba rẹ lòpọ̀: nítorí ìhòhò baba rẹ ni.

(J)“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ bá arábìnrin rẹ tí ó jẹ́ ọmọ ìyá rẹ lòpọ̀, yálà a bí i nílé yín tàbí lóde.

10 “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ bá ọmọbìnrin, ọmọ rẹ ọkùnrin lòpọ̀ tàbí ọmọbìnrin ọmọ rẹ obìnrin lòpọ̀ nítorí pé ìhòhò wọn, ìhòhò ìwọ fúnrarẹ̀ ni.

11 “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ bá ọmọbìnrin aya baba rẹ lòpọ̀; èyí tí a bí fún baba rẹ nítorí pé arábìnrin rẹ ni.

12 (K)“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ bá arábìnrin baba rẹ lòpọ̀ nítorí pé ìbátan baba rẹ ni.

13 “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ bá arábìnrin màmá rẹ lòpọ̀ nítorí pé ìbátan ìyá rẹ ni.

14 (L)“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ tàbùkù arákùnrin baba rẹ: nípa sísún mọ́ aya rẹ̀ láti bá a lòpọ̀ nítorí pé ìyàwó ẹ̀gbọ́n baba rẹ ni.

15 (M)“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ bá ọmọ àna obìnrin rẹ lòpọ̀ nítorí pé aya ọmọ rẹ ni. Má ṣe bá a lòpọ̀.

16 (N)“ ‘Má ṣe bá aya ẹ̀gbọ́n rẹ ọkùnrin lòpọ̀ nítorí pé yóò tàbùkù ẹ̀gbọ́n rẹ.

17 (O)“ ‘Má ṣe bá ìyá àti ọmọ rẹ obìnrin lòpọ̀, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ bá ọmọbìnrin ọmọkùnrin rẹ tàbí ọmọbìnrin ọmọbìnrin rẹ lòpọ̀ nítorí pé ìbátan rẹ tímọ́tímọ́ ni: nítorí àbùkù ni.

18 “ ‘Má ṣe fẹ́ àbúrò ìyàwó rẹ obìnrin ní aya gẹ́gẹ́ bí orogún tàbí bá a lòpọ̀, nígbà tí ìyàwó rẹ sì wà láààyè.

19 (P)“ ‘Má ṣe súnmọ́ obìnrin láti bá a lòpọ̀ nígbà tí ó bá ń ṣe nǹkan oṣù, nítorí àkókò àìmọ́ ni.

20 “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ bá aya aládùúgbò rẹ lòpọ̀, kí ìwọ má ba à ba ara rẹ jẹ́ pẹ̀lú rẹ̀.

21 (Q)“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ fi èyíkéyìí nínú àwọn ọmọ rẹ rú ẹbọ lórí pẹpẹ sí òrìṣà Moleki, kí o sì tipa bẹ́ẹ̀ ba orúkọ Ọlọ́run rẹ jẹ́. Èmi ni Olúwa.

22 (R)“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ bá ọkùnrin lòpọ̀ bí ìgbà tí ènìyàn ń bá obìnrin lòpọ̀: ìríra ni èyí jẹ́.

23 (S)“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ bá ẹranko lòpọ̀ kí ìwọ má ba à ba ara rẹ jẹ́. Obìnrin kò sì gbọdọ̀ jọ̀wọ́ ara rẹ̀ sílẹ̀ fún ẹranko láti bá a lòpọ̀, ohun tó lòdì ni.

24 “ ‘Má ṣe fi àwọn nǹkan wọ̀nyí ba ara rẹ jẹ́, torí pé nínú àwọn nǹkan wọ̀nyí ni àwọn orílẹ̀-èdè tí mo lé kúrò níwájú yín ti ba ara wọn jẹ́. 25 Nítorí pé ilẹ̀ náà di àìmọ́ nítorí náà mo fi ìyà jẹ ẹ́ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. Ilẹ̀ náà sì pọ àwọn olùgbé ibẹ̀ jáde. 26 Ṣùgbọ́n kí ẹ máa pa àṣẹ àti òfin mi mọ́. Onílé tàbí àjèjì tó ń gbé láàrín yín kò gbọdọ̀ ṣe ọ̀kan nínú àwọn ohun ìríra wọ̀nyí. 27 Nítorí pé gbogbo ohun ìríra wọ̀nyí ni àwọn ènìyàn tí wọ́n ti gbé ilẹ̀ náà ṣáájú yín ti ṣe tí ó sì mú kí ilẹ̀ náà di aláìmọ́. 28 Bí ẹ bá sọ ilẹ̀ náà di àìmọ́ yóò pọ̀ yín jáde bí ó ti pọ àwọn orílẹ̀-èdè tí ó ti wá ṣáájú yín jáde.

29 “ ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe ohun ìríra wọ̀nyí, kí ẹ gé irú ẹni náà kúrò láàrín àwọn ènìyàn. 30 Nítorí náà ẹ gbọdọ̀ ṣe ohun tí mo fẹ́, kí ẹ má sì lọ́wọ́ nínú àṣà ìríra wọ̀nyí, tí wọn ń ṣe kí ẹ tó dé. Ẹ má ṣe fi wọ́n ba ara yín jẹ́. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.’ ”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.