Add parallel Print Page Options

Ìgbàyà

(A)Ó ṣe iṣẹ́ ọnà sí ìgbàyà náà iṣẹ́ ọgbọ́n ọlọ́nà. Ó ṣe é bí ẹ̀wù efodu: ti wúrà ti aṣọ aláró, ti elése àlùkò, ti òdòdó àti ti ọ̀gbọ̀ olókùn dáradára. Igun rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rẹ̀ ṣe déédé ìwọ̀n ìka kan ní ìnà rẹ̀, ìwọ̀n ìka kan ní ìbú rẹ̀, ó sì jẹ́ ìṣẹ́po méjì. 10 Ó sì to ipele òkúta oníyebíye mẹ́rin sí i. Ní ipele kìn-ín-ní ní rúbì wà, topasi àti bereli; 11 ní ipele kejì, turikuoṣe, safire, emeradi àti diamọndi; 12 ní ipele kẹta, jasiniti, agate àti ametisiti; 13 ní ipele kẹrin, karisoliti, óníkìsì, àti jasperi. Ó sì tò wọ́n ní ojú ìdè wúrà ní títò wọn. 14 Wọ́n jẹ́ òkúta méjìlá, ọ̀kan fún orúkọ àwọn ọmọ Israẹli kọ̀ọ̀kan, a fín ọ̀kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí èdìdì pẹ̀lú orúkọ ẹnìkọ̀ọ̀kan ẹ̀yà méjèèjìlá.

15 Fún ìgbàyà náà, wọ́n ṣe ẹ̀wọ̀n iṣẹ́ kìkì wúrà, gẹ́gẹ́ bi okùn. 16 Wọ́n sì ṣe ojú ìdè wúrà méjì àti òrùka wúrà méjì, wọ́n sì so àwọn òkúta náà mọ́ igun méjèèjì ìgbàyà náà. 17 Wọ́n sì so ẹ̀wọ̀n wúrà méjèèjì náà mọ́ àwọn òrùka náà ni igun ìgbàyà náà, 18 àti ní àwọn òpin ẹ̀wọ̀n tókù ni wọ́n fi mọ ojú ìdè méjèèjì, wọ́n so wọ́n mọ́ aṣọ èjìká ẹ̀wù efodu náà ní iwájú. 19 Wọ́n ṣe òrùka wúrà méjì, wọ́n sì so wọ́n mọ́ igun méjèèjì ìgbàyà náà ní etí tí ó wà ní inú lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹ̀wù efodu náà. 20 Wọ́n sì túnṣe òrùka wúrà méjì sí i, wọ́n sì so wọ́n mọ́ ìdí aṣọ èjìká ní iwájú ẹ̀wù efodu náà tí ó súnmọ́ ibi tí a ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ ní òkè ìgbànú ẹ̀wù efodu náà. 21 Wọn so àwọn òrùka ìgbàyà mọ́ àwọn òrùka ẹ̀wù efodu ọ̀já aṣọ aláró, kí a pa á pọ̀ mọ́ ìgbànú, nítorí kí ìgbàyà náà má ṣe tú kúrò lára ẹ̀wù efodu náà gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

Read full chapter