Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Chronological

Read the Bible in the chronological order in which its stories and events occurred.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Ẹkun Jeremiah 3:37-5:22

37 Ta ni yóò sọ̀rọ̀ tí yóò rí bẹ́ẹ̀
    tí Olúwa kò bá fi àṣẹ sí i.
38 Ǹjẹ́ kì í ṣe láti ẹnu Ọ̀gá-ògo jùlọ
    ni rere àti búburú tí ń wá?
39 Kí ló dé tí ẹ̀dá alààyè ṣe ń kùn
    nígbà tí ó bá ń jìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀?

40 Ẹ jẹ́ kí a yẹ ọ̀nà wa, kí a sì dán an wò,
    kí a sì tọ Olúwa lọ.
41 Ẹ jẹ́ kí a gbé ọkàn àti ọwọ́ wa sókè
    sí Ọlọ́run ní ọ̀run, kí a wí pé:
42 “Àwa ti ṣẹ̀ a sì ti ṣọ̀tẹ̀
    ìwọ kò sì fi ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá.

43 “Ìwọ fi ìbínú bo ara rẹ ìwọ sì ń lépa wa;
    ìwọ ń parun láìsí àánú.
44 Ìwọ ti fi àwọsánmọ̀ bo ara rẹ
    pé kí àdúrà wa má ba à dé ọ̀dọ̀ rẹ.
45 Ó ti sọ wá di èérí àti ààtàn
    láàrín orílẹ̀-èdè gbogbo.

46 “Gbogbo àwọn ọ̀tá wa ti la ẹnu wọn
    gbòòrò sí wa.
47 Àwa ti jìyà àti ìparun,
    nínú ìbẹ̀rù àti ewu.”
48 Omijé ń sàn ní ojú mi bí odò
    nítorí a pa àwọn ènìyàn mi run.

49 Ojú mi kò dá fún omijé,
    láì sinmi,
50 títí ìgbà tí Olúwa yóò ṣíjú wolẹ̀
    láti òkè ọ̀run tí yóò sì rí i.
51 Ohun tí mo rí mú ìbẹ̀rù wá ọkàn mi
    nítorí gbogbo àwọn obìnrin ìlú mi.

52 Àwọn tí ó jẹ́ ọ̀tá mi láìnídìí
    dẹ mí bí ẹyẹ.
53 Wọ́n gbìyànjú láti mú òpin dé bá ayé mi nínú ihò
    wọ́n sì ju òkúta lù mí.
54 Orí mi kún fún omi,
    mo sì rò pé ìgbẹ̀yìn dé.

55 Mo pe orúkọ rẹ, Olúwa,
    láti ọ̀gbun ìsàlẹ̀ ihò.
56 Ìwọ gbọ́ ẹ̀bẹ̀ mi: “Má ṣe di etí rẹ
    sí igbe ẹ̀bẹ̀ mi fún ìtura.”
57 O wá tòsí nígbà tí mo ké pè ọ́,
    o sì wí pé, “Má ṣe bẹ̀rù.”

58 Olúwa, ìwọ gba ẹjọ́ mi rò,
    o ra ẹ̀mí mi padà.
59 O ti rí i, Olúwa, búburú tí a ṣe sí mi
    Gbé ẹjọ́ mi ró!
60 Ìwọ ti rí ọ̀gbun ẹ̀san wọn,
    gbogbo ìmọ̀ wọn sí mi.

61 Olúwa ìwọ ti gbọ́ ẹ̀gàn wọn
    àti ìmọ̀ búburú wọn sí mi—
62 Ohun tí àwọn ọ̀tá mi ń sọ
    sí mi ní gbogbo ọjọ́.
63 Wò wọ́n! Ní jíjòkòó tàbí ní dídìde,
    wọ́n ń ṣẹlẹ́yà mi nínú orin wọn.

64 Olúwa san wọ́n lẹ́san ohun tí ó tọ́ sí wọn
    fún ohun tí ọwọ́ wọn ti ṣe.
65 Fi ìbòjú bò wọ́n ní ọkàn,
    kí o sì fi wọ́n ré.
66 Ni wọ́n lára kí o sì pa wọ́n run pẹ̀lú ìbínú,
    lábẹ́ ọ̀run Olúwa.

Báwo ni wúrà ṣe sọ ògo dídán rẹ̀ nù,
    wúrà dídára di àìdán!
Òkúta ibi mímọ́ wá túká
    sí oríta gbogbo òpópó.

Báwo ni àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin Sioni tí ó ṣe iyebíye,
    tí wọ́n fi wúrà dídára ṣe
wá dàbí ìkòkò amọ̀ lásán
    iṣẹ́ ọwọ́ amọ̀kòkò!

Àwọn ajáko pèsè ọmú wọn
    fún ìtọ́jú àwọn ọmọ wọn,
ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn mi wá láì lọ́kàn
    bí ògòǹgò ní aginjù.

Nítorí òǹgbẹ, ahọ́n àwọn ọmọ ọwọ́
    lẹ̀ mọ́ òkè ẹnu wọn;
àwọn ọmọdé bẹ̀bẹ̀ fún oúnjẹ
    Ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí ó fi fún wọn.

Àwọn tí ó ń jẹ ohun dáradára
    di òtòṣì ní òpópó.
Àwọn tí a fi aṣọ dáradára wọ̀
    ni wọ́n sùn ní orí òkìtì eérú.

Ìjìyà àwọn ènìyàn mi
    tóbi ju ti Sodomu lọ,
tí a sí ní ipò ní òjijì
    láìsí ọwọ́ láti ràn án lọ́wọ́.

Ọmọ ọba ọkùnrin wọn mọ́ ju òjò-dídì,
    wọ́n sì funfun ju wàrà lọ
wọ́n ni ìtọ́jú bí iyùn pupa,
    ìrísí wọn dàbí safire.

Ṣùgbọ́n nísinsin yìí wọ́n dúdú ju èédú;
    wọn kò sì dá wọn mọ̀ ní òpópó.
Ara wọn hun mọ́ egungun;
    ó sì gbẹ bí igi gbígbẹ.

Àwọn tí ó kù nípasẹ̀ idà sàn
    ju àwọn tí ìyàn pa;
tí ó wọ àkísà ebi, tí ó ń ṣòfò
    fún àìní oúnjẹ láti inú pápá.

10 Pẹ̀lú ọwọ́ àwọn obìnrin aláàánú
    ni wọ́n ṣe ọmọ wọn jẹ
tí ó di oúnjẹ fún wọn
    nígbà tí a pa àwọn ènìyàn mi run.

11 Olúwa ti fi ihò kíkún fún ìbínú rẹ̀;
    ó sì tú ìbínú gbígbóná rẹ̀ jáde.
Ó da iná ní Sioni
    tí ó jó ìpìlẹ̀ rẹ̀ run.

12 Àwọn ọba ayé kò gbàgbọ́,
    tàbí àwọn ènìyàn ayé,
wí pé àwọn ọ̀tá àti aninilára le wọ
    odi ìlú Jerusalẹmu.

13 Èyí ṣẹlẹ̀ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn wòlíì
    àti àìṣedéédéé àwọn olórí àlùfáà,
tí ó ta ẹ̀jẹ̀ àwọn olódodo
    sílẹ̀ láàrín rẹ̀.

14 Nísinsin yìí wọ́n ń rìn kiri ní òpópó
    bí ọkùnrin tí ó fọ́jú.
Ẹ̀jẹ̀ ara wọn sọ wọ́n di àbàwọ́n
    tí kò sẹ́ni tó láyà láti fọwọ́ kan aṣọ wọn.

15 “Lọ kúrò! Ẹ̀yin di aláìmọ́!” ni àwọn ènìyàn ń kígbe sí wọn.
    “Ẹ lọ! Ẹ lọ! Ẹ má ṣe fọwọ́ kàn wá!”
Àwọn ènìyàn láàrín orílẹ̀-èdè wí pé,
    “Wọn kì yóò tẹ̀dó síbí mọ́.”

16 Olúwa ti tú wọn ká fúnrarẹ̀;
    kò sí bojútó wọn mọ́.
Kò sí ọ̀wọ̀ fún olórí àlùfáà mọ́,
    àti àánú fún àwọn àgbàgbà.

17 Síwájú sí i, ojú wa kùnà
    fún wíwo ìrànlọ́wọ́ asán;
láti orí ìṣọ́ wa ni à ń wò
    fún orílẹ̀-èdè tí kò le gbà wá là.

18 Wọ́n ń ṣọ́ wa kiri,
    àwa kò sì le rìn ní òpópó wa mọ́.
Òpin wa ti súnmọ́, ọjọ́ wa sì níye
    nítorí òpin wa ti dé.

19 Àwọn tí ń lé wa yára
    ju idì ojú ọ̀run lọ;
wọ́n lé wa ní gbogbo orí òkè
    wọ́n sì gẹ̀gùn dè wá ní aginjù.

20 Ẹni ààmì òróró Olúwa, èémí ìyè wa,
    ni wọ́n fi tàkúté wọn mú.
Àwa rò pé lábẹ́ òjìji rẹ̀
    ni àwa yóò máa gbé láàrín orílẹ̀-èdè gbogbo.

21 Ẹ yọ̀ kí inú yín sì dùn, ẹ̀yin ọmọbìnrin Edomu,
    ẹ̀yin tó ń gbé ní ilẹ̀ Usi.
Ṣùgbọ́n, a ó gbé ago náà kọjá sọ́dọ̀ rẹ pẹ̀lú;
    ìwọ yóò yó bí ọ̀mùtí, ìwọ yóò sì rìn ní ìhòhò.

22 Ìwọ ọmọbìnrin Sioni, ìjìyà rẹ yóò dópin;
    kò ní mú ìgbèkùn rẹ pẹ́ mọ́.
Ṣùgbọ́n, ìwọ ọmọbìnrin Edomu, yóò jẹ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ ní yà
    yóò sì fi àìṣedéédéé rẹ hàn kedere.

Rántí, Olúwa, ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí wa;
    wò ó, kí o sì rí ìtìjú wa.
Àwọn ohun ìní wa ti di ti àlejò,
    ilé wa ti di ti àjèjì.
Àwa ti di aláìní òbí àti aláìní baba,
    àwọn ìyá wa ti di opó.
A gbọdọ̀ ra omi tí à ń mu;
    igi wa di títà fún wa.
Àwọn tí ó ń lé wa súnmọ́ wa;
    àárẹ̀ mú wa àwa kò sì rí ìsinmi.
Àwa jọ̀wọ́ ara wa fún Ejibiti àti Asiria
    láti rí oúnjẹ tó tó jẹ.
Àwọn baba wa ti ṣẹ̀, wọn kò sì ṣí mọ́,
    àwa sì ń ru ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn.
Àwọn ẹrú ń jẹ ọba lórí wa,
    kò sì ṣí ẹni tí yóò gbà wá lọ́wọ́ wọn.
Àwa ń rí oúnjẹ wa nínú ewu ẹ̀mí wa
    nítorí idà tí ó wà ní aginjù.
10 Ẹran-ara wa gbóná bí ààrò,
    ebi sì yó wa bí àárẹ̀.
11 Wọ́n ti fipá bá àwọn obìnrin wa lòpọ̀ ní Sioni,
    àti àwọn wúńdíá ti o wa ní ìlú Juda.
12 Àwọn ọmọ ọbakùnrin ti di síso sókè ní ọwọ́ wọn;
    kò sí ìbọ̀wọ̀ fún àgbàgbà mọ́.
13 Àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin wa ru òkúta;
    àwọn ọmọkùnrin sì ń ṣàárẹ̀ lábẹ́ ẹrù igi.
14 Àwọn àgbàgbà ti lọ kúrò ní ẹnu-bodè ìlú;
    àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin sì dákẹ́ orin wọn
15 Ayọ̀ ti ṣáko ní ọkàn wa;
    ọ̀fọ̀ sì ti dúró bí ijó fún wa.
16 Adé ti ṣí kúrò ní orí wa
    ègbé ni fún wa, nítorí a ti ṣẹ̀.
17 Nítorí èyí, àárẹ̀ mú ọkàn wa,
    nítorí èyí, ojú wa sì ṣú.
18 Fún òkè Sioni tí ó ti di ahoro
    lórí rẹ̀ àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ sì ń rìn kiri.

19 Ìwọ, Olúwa, jẹ ọba títí láé;
    ìjọba rẹ dúró láti ìran kan dé ìran mìíràn.
20 Kí ló dé tí o ń gbàgbé wa ní gbogbo ìgbà?
    Kí ló dé tí o fi kọ̀ wá sílẹ̀ fún ọjọ́ pípẹ́?
21 Mú wa padà sí ọ̀dọ̀ rẹ, Olúwa, kí àwa kí ó le padà;
    mú ọjọ́ wa di tuntun bí ìgbàanì
22 Àyàfi tí o bá ti kọ̀ wá sílẹ̀ pátápátá
    tí ìbínú rẹ sí wa sì kọjá ìwọ̀n.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.