Chronological
41 Ní oṣù keje Iṣmaeli, ọmọ Netaniah ọmọ Eliṣama, nínú irú-ọmọ ọba, àti àwọn ìjòyè ọba, àti àwọn ọkùnrin mẹ́wàá pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n tọ Gedaliah ọmọ Ahikamu wá ní Mispa; níbẹ̀ ni wọ́n jùmọ̀ jẹun ní Mispa. 2 Iṣmaeli ọmọ Netaniah àti àwọn ọkùnrin mẹ́wàá tí wọ́n wà pẹ̀lú rẹ̀, sì dìde wọ́n kọlu Gedaliah ọmọ Ahikamu, ọmọ Ṣafani pẹ̀lú idà. Wọ́n sì pa á, ẹni tí ọba Babeli ti fi jẹ baálẹ̀ lórí ilẹ̀ náà. 3 Iṣmaeli sì tún pa gbogbo àwọn Júù tí wọ́n wà pẹ̀lú Gedaliah ní Mispa, àti gbogbo àwọn ọmọ-ogun Babeli tí wọ́n wà níbẹ̀ bákan náà.
4 Ní ọjọ́ kejì tí wọ́n pa Gedaliah kí ó tó di wí pé ẹnikẹ́ni mọ̀ 5 Àwọn ọgọ́rin ọkùnrin wá láti Ṣekemu, Ṣilo àti Samaria, wọ́n fa irùngbọ̀n wọn, wọ́n ya aṣọ wọn, wọ́n ṣá ara wọn lọ́gbẹ́, wọ́n mú ẹbọ ọpẹ́ àti tùràrí wá sí ilé Olúwa. 6 Iṣmaeli ọmọkùnrin Netaniah jáde kúrò láti Mispa láti lọ pàdé wọn. Ó sì ń sọkún bí ó ti ṣe ń lọ, nígbà tí ó pàdé wọn, ó wí pé, “Ẹ wá sọ́dọ̀ Gedaliah ọmọkùnrin Ahikamu.” 7 Nígbà tí wọ́n dé ìlú náà; Iṣmaeli ọmọkùnrin Netaniah àti àwọn ọkùnrin tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ pa wọ́n, wọ́n sì sọ òkú wọn sínú ihò kan. 8 Ṣùgbọ́n mẹ́wàá nínú wọn sọ fún Iṣmaeli pé, “Má ṣe pa wá! Àwa ní ọkà àti barle, òróró àti oyin ní ìpamọ́ nínú oko.” Nítorí náà, ó fi wọ́n sílẹ̀: kò sì pa wọ́n pẹ̀lú àwọn yòókù. 9 Nísinsin yìí, ihò náà tí ó kó gbogbo ara àwọn ọkùnrin tí ó ti pa pẹ̀lú Gedaliah sí ni ọba Asa ń lò gẹ́gẹ́ bí i ààbò nítorí ọba Baaṣa ti Israẹli. Iṣmaeli ọmọ Netaniah sì ti kó òkú kún inú rẹ̀.
10 Iṣmaeli sì kó gbogbo àwọn ènìyàn tí ó wà ní Mispa nígbèkùn, ọmọbìnrin ọba àti gbogbo àwọn ènìyàn tókù síbẹ̀ lórí àwọn tí Nebusaradani balógun àwọn ẹ̀ṣọ́ ti fi yan Gedaliah ọmọkùnrin Ahikamu ṣe olórí. Iṣmaeli ọmọkùnrin Netaniah kó wọn ní ìgbèkùn, ó sì jáde rékọjá sí ọ̀dọ̀ àwọn Ammoni.
11 Nígbà tí Johanani ọmọkùnrin Karea àti gbogbo àwọn olórí ogun tí wọ́n wà pẹ̀lú rẹ̀ gbọ́ nípa gbogbo ìpànìyàn náà tí Iṣmaeli ọmọ Netaniah ti ṣe. 12 Wọ́n kó gbogbo àwọn ọkùnrin wọn, wọ́n sì, lọ bá Iṣmaeli ọmọ Netaniah jà. Wọ́n pàdé rẹ̀ ní odò kan lẹ́bàá Gibeoni. 13 Nígbà tí gbogbo àwọn ènìyàn Iṣmaeli tí wọ́n wà pẹ̀lú rẹ̀ rí Johanani ọmọkùnrin Karea àti àwọn olórí ogun rẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n sì yọ̀. 14 Gbogbo àwọn ènìyàn tí Iṣmaeli ti kó ní ìgbèkùn ní Mispa yípadà, wọ́n sì lọ sọ́dọ̀ Johanani ọmọ Karea. 15 Ṣùgbọ́n Iṣmaeli ọmọkùnrin Netaniah àti àwọn mẹ́jọ nínú àwọn ọkùnrin rẹ̀ bọ́ lọ́wọ́ Johanani, wọ́n sì sálọ sí Ammoni.
Sísá lọ sí Ejibiti
16 Lẹ́yìn náà Johanani ọmọkùnrin Karea àti gbogbo àwọn ọmọ-ogun tí wọn wà pẹ̀lú rẹ̀ sì kó gbogbo àwọn tí ó kù ní Mispa; àwọn tí ó ti rí gbà lọ́wọ́ Iṣmaeli ọmọkùnrin Netaniah; lẹ́yìn ìgbà tí ó ti pa Gedaliah ọmọ Ahikamu. Àwọn ọmọ-ogun, àwọn obìnrin, àwọn ọmọdé àti àwọn olórí ilé ẹjọ́ tí ó ti kó wa láti Gibeoni. 17 Wọ́n sì kúrò níbẹ̀, wọ́n dúró ní Geruti Kimhamu ní ẹ̀bá Bẹtilẹhẹmu ní ọ́nà ìrìnàjò wọn sí Ejibiti. 18 Láti gba àwọn Babeli sílẹ̀. Wọ́n bẹ̀rù wọn nítorí wí pé, “Iṣmaeli ọmọ Netaniah ti pa Gedaliah ọmọ Ahikamu èyí tí ọba Babeli ti yàn gẹ́gẹ́ bí i gómìnà lórí ilẹ̀ náà.”
42 Nígbà náà ní gbogbo àwọn olórí ogun àti Johanani ọmọkùnrin Karea àti Jesaniah ọmọkùnrin Hoṣaiah àti kékeré títí dé orí ẹni ńlá wá. 2 Sí ọ̀dọ̀ Jeremiah wòlíì náà, wọ́n sì sọ fún un pé, “Jọ̀wọ́ gbọ́ ẹ̀bẹ̀ wa, kí o sì gbàdúrà sí Olúwa Ọlọ́run rẹ fún gbogbo ìyókù yìí. Nítorí gẹ́gẹ́ bi ìwọ ṣe rí i nísinsin yìí pé a pọ̀ níye nígbà kan rí; ṣùgbọ́n báyìí àwa díẹ̀ la ṣẹ́kù 3 Gbàdúrà pé kí Olúwa Ọlọ́run rẹ sọ ibi tí àwa yóò lọ fún wa àti ohun tí àwa yóò ṣe.”
4 Wòlíì Jeremiah sì dáhùn wí pé, “Mo ti gbọ́. Èmi yóò gbàdúrà sí Olúwa Ọlọ́run yín gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin ṣe béèrè. Èmi yóò sọ gbogbo ohun tí Olúwa bá sọ fún un yín, ń kò sì ní fi ohunkóhun pamọ́ fún un yín.”
5 Nígbà náà ni wọ́n sọ fún Jeremiah wí pé, “Kí Olúwa ṣe ẹlẹ́rìí òtítọ́ àti òdodo láàrín wa, bí àwa kò bá ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí Olúwa Ọlọ́run rẹ bá rán ọ láti sọ fún wa. 6 Ìbá à ṣe rere, ìbá à ṣe búburú, àwa yóò gbọ́rọ̀ sí Olúwa Ọlọ́run wa; èyí tí àwa ń rán ọ sí; Kí ó ba à lè dára fún wa. Nítorí pé àwa yóò gbọ́rọ̀ sí Olúwa Ọlọ́run wa.”
7 Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́wàá, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Jeremiah wá wí pé; 8 Nígbà náà ni a ó pa Johanani ọmọkùnrin Karea àti gbogbo àwọn olórí ogun tí wọ́n wà pẹ̀lú rẹ̀; àti gbogbo àwọn ènìyàn láti orí ẹni tí ó kéré dé orí ẹni ńlá. 9 Ó sì wí fún wọn pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run àwọn Israẹli wí: ‘Èyí ni ẹni tí ẹ̀yin ti rán láti gbé ẹ̀bẹ̀ yín lọ síwájú mi. 10 Bí ẹ̀yin bá gbé ní ilẹ̀ yìí, èmi yóò gbé e yín ró, n kò sí ní fà yín lulẹ̀, èmi yóò gbìn yín, n kì yóò fà yín tu nítorí wí pé èmi yí ọkàn padà ní ti ibi tí mo ti ṣe sí i yín. 11 Ẹ má ṣe bẹ̀rù ọba Babeli tí ẹ̀yin ń bẹ̀rù, báyìí ẹ má ṣe bẹ̀rù rẹ̀ ni Olúwa wí; nítorí tí èmi wà pẹ̀lú yín láti pa yín mọ́ àti láti gbà yín ní ọwọ́ rẹ̀. 12 Èmi yóò fi àánú hàn sí i yín, kí ó lè ṣàánú fún un yín, kí ó sì mú un yín padà sí ilẹ̀ yín.’
13 “Ṣùgbọ́n sá, bí ẹ̀yin bá wí pé, ‘Àwa kò ní gbé ilẹ̀ yìí,’ ẹ̀yin ti ṣe àìgbọ́ràn sí Olúwa Ọlọ́run yín. 14 Àti pé bí ẹ̀yin bá wí pé, ‘Bẹ́ẹ̀ kọ́, àwa yóò lọ gbé ní Ejibiti; níbi tí àwa kì yóò rí ìró ogunkógun, tí a kì yóò sì gbọ́ ìró fèrè, tí ebi oúnjẹ kì yóò sì pa wá, níbẹ̀ ni àwa ó sì máa gbé,’ 15 Nítorí náà, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa ẹ̀yin ìyókù Juda èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun Israẹli wí: ‘Bí ẹ̀yin bá pinnu láti lọ sí Ejibiti láti lọ ṣe àtìpó níbẹ̀. 16 Yóò sì ṣe, idà tí ẹ̀yin bẹ̀rù yóò sì lé e yín bá níbẹ̀; àti ìyanu náà tí ẹ̀yin ń bẹ̀rù yóò sì tẹ̀lé yín lọ sí Ejibiti àti pé ibẹ̀ ni ẹ̀yin yóò kú sí. 17 Nítorí náà, gbogbo àwọn tí ó ti pinnu láti ṣe àtìpó ní Ejibiti ni yóò ti ipa idà kú, ìyàn àti àjàkálẹ̀-ààrùn kò sì ní jẹ́ kí ẹnikẹ́ni nínú wọn yè tàbí sá àsálà nínú ibi tí èmi yóò mú wá sórí wọn.’ 18 Báyìí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Israẹli wí: ‘Gẹ́gẹ́ bí èmi ti da ìbínú àti ìrunú síta sórí àwọn tí ó ń gbé ní Jerusalẹmu, bẹ́ẹ̀ ni ìrunú mi yóò dà síta sórí yín, nígbà tí ẹ̀yin bá lọ sí Ejibiti. Ẹ̀yin ó sì di ẹni ègún àti ẹni ẹ̀gàn àti ẹ̀sín, ẹ̀yin kì yóò sì rí ibí yìí mọ́.’
19 “Ẹ̀yin yòókù Juda, Olúwa ti sọ fún un yín pé, ‘Kí ẹ má ṣe lọ sí Ejibiti.’ Ẹ mọ èyí dájú: Èmi kìlọ̀ fún un yín lónìí; 20 Pé àṣìṣe ńlá gbá à ni ẹ̀yin ṣe nígbà tí ẹ̀yin rán mi sí Olúwa Ọlọ́run yín pé, ‘Gbàdúrà sí Olúwa Ọlọ́run wa fún wa; sọ fún wa gbogbo ohun tí ó bá sọ, àwa yóò sì ṣe é.’ 21 Mo ti sọ fún un yín lónìí, ṣùgbọ́n síbẹ̀ ẹ̀yin kò tí ì gbọ́ ohùn Olúwa Ọlọ́run yín, àti gbogbo ohun tí ó rán mi láti sọ fún un yín. 22 Ǹjẹ́ nísinsin yìí ẹ mọ èyí dájú pé: Ẹ̀yin yóò kú nípa idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-ààrùn níbikíbi tí ẹ̀yin bá fẹ́ lọ láti ṣe àtìpó.”
43 Nígbà tí Jeremiah parí sísọ ọ̀rọ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rán an sí wọn tan. 2 Asariah ọmọ Hoṣaiah àti Johanani ọmọ Karea, àti gbogbo àwọn agbéraga ọkùnrin sọ fún Jeremiah pé, “Ìwọ ń pa irọ́! Olúwa Ọlọ́run wa kò rán ọ láti sọ pé, ‘Ẹ má lọ sí Ejibiti láti ṣàtìpó níbẹ̀.’ 3 Ṣùgbọ́n Baruku, ọmọ Neriah, ni ó fi ọ̀rọ̀ sí ọ lẹ́nu sí wa, láti fà wá lé àwọn ará Babeli lọ́wọ́, láti pa wá àti láti kó wa ní ìgbèkùn lọ sí Babeli.”
4 Nítorí náà, Johanani ti Karea àti gbogbo àwọn olórí ogun, àti gbogbo àwọn ènìyàn tàpá sí àṣẹ Olúwa nípa dídúró sí Juda. 5 Dípò bẹ́ẹ̀, Johanani ọmọ Karea àti gbogbo àwọn olórí ogun sì ko àwọn àjẹkù Juda tí wọ́n wá láti gbé ilẹ̀ Juda láti orílẹ̀-èdè gbogbo tí wọ́n ti tú wọn ká. 6 Wọ́n tún kó àwọn ọkùnrin, àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé, àti àwọn ọmọ ọba tí ó jẹ́ obìnrin èyí tí Nebusaradani balógun ẹ̀ṣọ́ ti fi sílẹ̀ pẹ̀lú Gedaliah ọmọ Ahikamu, ọmọ Ṣafani, àti Jeremiah wòlíì náà àti Baruku ọmọ Neriah. 7 Nítorí náà, wọn wọ Ejibiti pẹ̀lú àìgbọ́ràn sí àṣẹ Olúwa, wọ́n sì lọ títí dé Tafanesi.
8 Ní Tafanesi ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Jeremiah wá: 9 “Nígbà tí àwọn Júù ń wòye mú àwọn òkúta pẹ̀lú rẹ, kí o sì rì wọ́n mọ́ inú amọ̀ tí ó wà nínú bíríkì tí ó wà níbi pèpéle ẹnu-ọ̀nà ààfin Farao ní Tafanesi. 10 Báyìí kí o sì sọ fún wọn pé, ‘Èyí ni ohun tí Ọlọ́run alágbára, Ọlọ́run Israẹli wí: Èmi yóò ránṣẹ́ sí ìránṣẹ́ mi Nebukadnessari ọba Babeli Èmi yóò gbé ìjọba rẹ̀ ka orí àwọn òkúta; èyí tí mo ti rì sí ibí yìí, yóò tan ìjọba rẹ̀ jù wọ́n lọ. 11 Yóò gbé ogun sí Ejibiti; yóò mú ikú bá àwọn tí ó yan ikú; ìgbèkùn fún àwọn tí ó ti yan ìgbèkùn, àti idà fún àwọn tí ó yan idà. 12 Yóò dá, iná sun tẹmpili àwọn òrìṣà Ejibiti, yóò sun tẹmpili àwọn òrìṣà Ejibiti, yóò sì mú wọn lọ ìgbèkùn. Gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́-àgùntàn, yóò ró aṣọ rẹ̀ mọ́ra, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni yóò ró Ejibiti òun yóò sì lọ kúrò níbẹ̀ ní àlàáfíà 13 Ní tẹmpili ni yóò ti fọ́ ère ilé oòrùn tí ó wà ní ilẹ̀ Ejibiti túútúú, yóò sì sun àwọn tẹmpili àwọn òrìṣà Ejibiti.’ ”
Àjálù nítorí ṣinṣin òrìṣà
44 Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Jeremiah wá nípa àwọn Júù tí ń gbé ní ìsàlẹ̀ Ejibiti ní Migdoli, Tafanesi àti Memfisi àti ní apá òkè Ejibiti: 2 “Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Israẹli wí: Wo ibi tí mo mú bá Jerusalẹmu àti gbogbo ìlú Juda. Lónìí, wọ́n wà ní ìyapa àti ìparun. 3 Nítorí pé ibi tí wọ́n ti ṣe. Wọ́n mú mi bínú nípa tùràrí fínfín àti nípa bíbọ àwọn òrìṣà, yálà èyí tí ìwọ tàbí àwọn baba rẹ kò mọ̀. 4 Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ní mo rán wòlíì mi, èyí tí ó wí báyìí pé, ‘Má ṣe àwọn ohun ìríra yìí tí èmi kórìíra.’ 5 Ṣùgbọ́n wọn kò fetísílẹ̀ láti fi ọkàn si. Wọn kò sì yípadà kúrò nínú búburú wọn tàbí dáwọ́ ẹbọ sísun sí àwọn òrìṣà dúró. 6 Fún ìdí èyí, ìbínú gbígbóná mi ni èmi yóò yọ sí àwọn ìlú Juda àti òpópó Jerusalẹmu àti sísọ wọ́n di ìparun bí ó ṣe wà lónìí yìí.
7 “Báyìí tún ni Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun Israẹli wí: Kí ló dé tí ẹ fi ń mu ibi ńlá yìí wá sí orí ara yín nípa yíyapa kúrò lára Juda ọkùnrin àti obìnrin, ọmọdé àti èwe, tí ẹ kò sì ku ọ̀kankan? 8 Èéṣe tí ẹ fi mú mi bínú pẹ̀lú ohun tí ọwọ́ yín ṣe pẹ̀lú ẹbọ sísun sí àwọn òrìṣà Ejibiti, níbi tí ẹ wá láti máa gbé? Ẹ̀ ò pa ara yín run, ẹ̀ ó sì sọ ara yín di ẹni ìfiré àti ẹ̀gàn láàrín àwọn orílẹ̀-èdè ayé gbogbo. 9 Ṣé ẹ̀yin ti gbàgbé ibi tí àwọn baba ńlá yín àti àwọn ọba; àwọn ayaba Juda, àti àwọn ibi tí ẹ ti ṣe àti àwọn ìyàwó yín ní ilẹ̀ Juda àti ní òpópó Jerusalẹmu? 10 Láti ìgbà náà sí àkókò yìí, wọn kò rẹ ara wọn sílẹ̀ tàbí fi ìtẹríba hàn tàbí kí wọn ó tẹ̀lé òfin àti àṣẹ tí mo pa fún un yín àti àwọn baba yín.
11 “Fún ìdí èyí, báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run àwọn Israẹli wí: Mo ti pinnu láti mú ibi wá sí orí yín àti láti pa Juda run. 12 Èmi yóò sì mú àwọn èérún tí ó kù ní Juda, tí wọ́n ṣetán láti lọ Ejibiti. Wọn yóò ṣubú pẹ̀lú idà tàbí kí wọn kú pẹ̀lú ìyàn láti orí ọmọdé títí dé àgbà ni wọn yóò kú láti ọwọ́ ìyàn tàbí idà. Wọn yóò di ẹni ìfiré àti ìparun, ẹni ẹ̀kọ̀ àti ẹni ẹ̀gàn. 13 Èmi yóò fi ìyà jẹ ẹni tí ó bá ń gbé ní Ejibiti pẹ̀lú idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-ààrùn bí mo ṣe fi ìyà jẹ Jerusalẹmu. 14 Kò sí èyí tí ó kéré jù nínú Juda tí ó kù, tí ó ń gbé ilẹ̀ Ejibiti tí yóò sá àsálà padà sórí ilẹ̀ Juda, èyí tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ láti padà sí, àti láti máa gbé; àyàfi àwọn aṣàtìpó mélòó kan.”
15 Lẹ́yìn èyí, gbogbo àwọn ọkùnrin tí ẹ bá mọ̀ pé, ìyàwó wọn sun tùràrí sí àwọn òrìṣà pẹ̀lú àwọn obìnrin tí ó bá wá àwọn ènìyàn púpọ̀, pàápàá àwọn ènìyàn tí wọ́n ń gbé ní òkè àti ìsàlẹ̀ Ejibiti, bẹ́ẹ̀ ni a wí fún Jeremiah. 16 “Wọn sì wí pé: Àwa kò ní fetísílẹ̀ ọ̀rọ̀ tí o bá bá wa sọ ní orúkọ Olúwa. 17 Dájúdájú; à ó ṣe gbogbo nǹkan tí a sọ pé à ò ṣe: A ó sun tùràrí sí ayaba ọ̀run; à ó sì da ohun mímu sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ sí àwa àti àwọn baba wa, àwọn ọba àti àwọn aláṣẹ ti ṣe ní àwọn ìlú Juda àti ni àwọn ìgboro Jerusalẹmu. Nígbà naà àwa ní oúnjẹ púpọ̀ a sì ṣe rere a kò sì rí ibi 18 Ṣùgbọ́n láti ìgbà tí a ti dáwọ́ tùràrí sísun sí Ayaba Ọ̀run àti láti da ẹbọ ohun mímu fún un, àwa ti ṣaláìní ohun gbogbo, a sì run nípa idà àti nípa ìyàn.”
19 Àwọn obìnrin náà fi kún un pé, “Nígbà tí à ń jó tùràrí sí ayaba ọ̀run, tí a sì ń fi ohun mímu rú ẹbọ si; ǹjẹ́ àwọn ọkọ wa kò mọ pé àwa ń ṣe àkàrà bí i, àwòrán rẹ, àti wí pé à ń da ọtí si gẹ́gẹ́ bi ohun ìrúbọ?”
20 Wàyí o, Jeremiah sọ fún àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn náà, ọkùnrin àti obìnrin, tí wọn sì ń dáhùn pé, 21 “Ṣe Ọlọ́run kò rántí ẹbọ sísun ní ìlú Juda àti àwọn ìgboro Jerusalẹmu láti ọ̀dọ̀ rẹ àti ọ̀dọ̀ àwọn baba rẹ, àwọn ọba àti àwọn aláṣẹ àti àwọn ènìyàn ìlú. 22 Nígbà tí Ọlọ́run kò lè fi ara da ìwà búburú yín àti àwọn nǹkan ìríra gbogbo tí ẹ ṣe, ilẹ̀ yín sì di ohun ìfiré àti ìkọ̀sílẹ̀, láìsí olùgbé gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe wà lónìí. 23 Nítorí pé ẹ ti sun ẹbọ, tí ẹ sì ti ṣẹ̀ sí Olúwa àti pé ẹ kò gbọ́rọ̀ sí i lẹ́nu, àti pé ẹ kò sì tẹ̀lé òfin rẹ̀ àti àwọn àṣẹ. Ibi náà yóò wá sórí rẹ àti bí o ṣe rí i.”
24 Nígbà náà ni Jeremiah dáhùn pẹ̀lú obìnrin náà pé, “Gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa, ẹ̀yin ọmọ Juda tí ó wà ní Ejibiti. 25 Èyí ni ọ̀rọ̀ tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Israẹli wí: Ìwọ àti àwọn Ìyàwó rẹ fihàn pẹ̀lú àwọn ìhùwà rẹ àti àwọn ohun tí ó ṣèlérí nígbà tí o wí pé, ‘Àwa yóò mú ẹ̀jẹ́ tí a jẹ́ ṣẹ lórí sísun tùràrí àti dída ẹbọ ohun mímu sí orí ère Ayaba Ọ̀run.’
“Tẹ̀síwájú nígbà náà, ṣe ohun tí o sọ, kí o sì mú ẹ̀jẹ́ rẹ ṣẹ. 26 Ṣùgbọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa Olódùmarè, gbogbo ẹ̀yin Júù tí ń gbé ilẹ̀ Ejibiti, mo gégùn ún: ‘Mo búra pẹ̀lú títóbi orúkọ mi,’ bẹ́ẹ̀ ni Olúwa, ‘wí pé, kò sí ẹnikẹ́ni láti Juda tí ń gbé ibikíbi ní Ejibiti ni tí ó gbọdọ̀ ké pe orúkọ mi tàbí búra. “Gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run tí ó dá wa ti wà láààyè.” 27 Nítorí náà, èmi ó ṣọ wọ́n fún ibi, kì í ṣe fún rere. Àti gbogbo àwọn ọkùnrin Juda tí ó wà ní ilẹ̀ Ejibiti ni a ó parun pẹ̀lú idà àti ìyàn títí tí gbogbo wọn yóò fi tán. 28 Àwọn tí ó bá sá àsálà kúrò lọ́wọ́ ìparun idà àti pípadà sí ilẹ̀ Juda láti Ejibiti yóò kéré níye. Gbogbo àwọn tí ó bá kú ní ilẹ̀ Juda, tí ó wá gbé ilẹ̀ Ejibiti yóò mọ ọ̀rọ̀ ẹni tí yóò dúró yálà tèmi tàbí tiyín.
29 “ ‘Èyí ni yóò jẹ́ ààmì fún un yín pé èmi yóò fi ìyà jẹ yín níbi tí Olúwa ti sọ láti lè jẹ́ kí ẹ mọ̀ pé ìjìyà mi tí mo sọ pé ẹ̀ ó jẹ yóò ṣẹ.’ 30 Báyìí ni Olúwa wí: ‘Èmi yóò fi Farao Hofira ọba Ejibiti lé àwọn ọ̀tá rẹ̀ lọ́wọ́, èyí tí ó lè pa ayé rẹ́; gẹ́gẹ́ bí mo ti fi Sedekiah ọba Juda lé Nebukadnessari ọba Babeli lọ́wọ́ ọ̀tá tó ń lépa ẹ̀mí rẹ̀.’ ”
Ìlérí Ọlọ́run fún Baruku
45 Èyí ni ọ̀rọ̀ tí Jeremiah wòlíì sọ fún Baruku ọmọ Neriah ní ọdún kẹrin ti Jehoiakimu ọmọ Josiah ọba Juda. Lẹ́yìn tí Baruku ti kọ sínú ìwé kíká àwọn ọ̀rọ̀ tí Jeremiah ti ń sọ: 2 “Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Israẹli sọ fún ọ, Baruku: 3 Ìwọ wí pé, ‘Ègbé ni fún mi! Olúwa ti fi ìbànújẹ́ kún ìrora mi; Àárẹ̀ mú mi nínú ẹ̀dùn mi, èmi kò sì rí ìsinmi.’ ” 4 Olúwa wí pé sọ èyí fún un, “Èyí ni Ọlọ́run sọ: ‘Èyí tí èmi ti kọ́ ni èmi yóò wò lulẹ̀, àti èyí tí èmi ti gbìn ni èmi yóò fàtu, àní ní orí gbogbo ilẹ̀. 5 Ṣé ìwọ sì ń wá ohun títóbi fún ara rẹ? Nítorí náà, má ṣe wá wọn. Èmi yóò mú ibi wá sí orí àwọn ènìyàn gbogbo ni Olúwa wí, ṣùgbọ́n níbikíbi tí ìwọ bá lọ ni èmi yóò jẹ́ kí o sá àsálà pẹ̀lú ẹ̀mí rẹ.’ ”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.