Chronological
Àjàkálẹ̀-ààrùn, ìyàn àti idà
14 Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa sí Jeremiah nípa ti àjàkálẹ̀-ààrùn:
2 “Juda káàánú,
àwọn ìlú rẹ̀ kérora
wọ́n pohùnréré ẹkún fún ilẹ̀ wọn,
igbe wọn sì gòkè lọ láti Jerusalẹmu.
3 Àwọn ọlọ́lá ènìyàn rán àwọn ìránṣẹ́ wọn lọ bu omi,
wọ́n lọ sí ìdí àmù
ṣùgbọ́n wọn kò rí omi.
Wọ́n padà pẹ̀lú ìkòkò òfìfo;
ìrẹ̀wẹ̀sì àti àìnírètí bá wọn,
wọ́n sì bo orí wọn.
4 Ilẹ̀ náà sán
nítorí pé kò sí òjò ní ilẹ̀ náà;
ìrètí àwọn àgbẹ̀ di òfo,
wọ́n sì bo orí wọn.
5 Kódà, abo àgbọ̀nrín tí ó wà lórí pápá
fi ọmọ rẹ̀ tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ bí sílẹ̀,
torí pé kò sí koríko.
6 Àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó dúró lórí òkè òfìfo
wọ́n sì ń mí ẹ̀fúùfù bí ìkookò
ojú wọn kò ríran
nítorí pé kò sí koríko jíjẹ.”
7 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀ṣẹ̀ wa jẹ́rìí lòdì sí wa,
wá nǹkan kan ṣe sí i Olúwa, nítorí orúkọ rẹ.
Nítorí ìpadàsẹ́yìn wa ti pọ̀jù,
a ti ṣẹ̀ sí ọ.
8 Ìrètí Israẹli;
ìgbàlà rẹ lásìkò ìpọ́njú,
èéṣe tí ìwọ dàbí àlejò ní ilẹ̀ náà
bí arìnrìn-àjò tí ó dúró fún bí òru ọjọ́ kan péré?
9 Èéṣe tí ìwọ dàbí ẹni tí a dààmú,
bí jagunjagun tí kò le ran ni lọ́wọ́?
Ìwọ wà láàrín wa, Olúwa,
orúkọ rẹ ni a sì ń pè mọ́ wa;
má ṣe fi wá sílẹ̀.
10 Báyìí ni Olúwa sọ nípa àwọn ènìyàn wọ̀nyí:
“Wọ́n fẹ́ràn láti máa rìn kiri;
wọn kò kó ọkàn wọn ní ìjánu.
Nítorí náà Olúwa kò gbà wọ́n;
yóò wá rántí ìwà búburú wọn báyìí,
yóò sì fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn jẹ wọ́n.”
11 Nígbà náà ni Olúwa sọ fún mi pé, “Má ṣe gbàdúrà fún àlàáfíà àwọn ènìyàn wọ̀nyí. 12 (A)Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n gbààwẹ̀, èmi kò ní tẹ́tí sí igbe wọn. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n rú ẹbọ sísun àti ẹbọ ìyẹ̀fun, èmi ò nígbà wọ́n. Dípò bẹ́ẹ̀, èmi ó fi idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-ààrùn pa wọ́n run.”
13 Ṣùgbọ́n mo sọ pé, “Háà! Olúwa Olódùmarè. Àwọn wòlíì ń sọ fún wọn pé, ‘ẹ kò ni rí idà tàbí ìyàn. Dájúdájú èmi ó fún yín ní àlàáfíà tí yóò tọ́jọ́ níbí yìí?’ ”
14 Nígbà náà Olúwa sọ fún mi pé, “àwọn wòlíì ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké ní orúkọ mi. Èmi kò rán wọn, tàbí yàn wọ́n tàbí bá wọn sọ̀rọ̀. Ìran èké ni wọ́n ń rí sí i yín. Àsọtẹ́lẹ̀ èké ni wọ́n ń sọ fún un yín nípa ìran ìrírí, àfọ̀ṣẹ, ìbọ̀rìṣà àti ìtànjẹ ọkàn wọn. 15 Nítorí náà, èyí ni Olúwa sọ nípa àwọn wòlíì tí wọ́n ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ lórúkọ mi. Èmi kò rán wọn, síbẹ̀ wọ́n sì ń sọ pé, ‘idà kan tàbí ìyàn, kì yóò dé ilẹ̀ yìí.’ Àwọn wòlíì kan náà yóò parẹ́ nípa idà àti ìyàn. 16 Bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ènìyàn tí wọ́n ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún ni a ó lé sí òpópónà Jerusalẹmu torí idà àti ìyàn. Wọn kò ní i rí ẹni tí yóò sìn wọ́n tàbí ìyàwó wọn, àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin wọn. Èmi yóò mú ìdààmú tí ó yẹ bá ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin wọn.
17 “Kí ìwọ kí ó sì sọ ọ̀rọ̀ yìí fún wọn pé:
“ ‘Jẹ́ kí ojú mi kí ó sun omijé
ní ọ̀sán àti ní òru láìdá;
nítorí tí a ti ṣá wúńdíá,
ọmọ ènìyàn mi ní ọgbẹ́ ńlá
pẹ̀lú lílù bolẹ̀.
18 Bí mo bá lọ sí orílẹ̀-èdè náà,
Èmi yóò rí àwọn tí wọ́n fi idà pa.
Bí mo bá lọ sí ìlú ńlá,
èmi rí àwọn tí ìyàn ti sọ di aláàrùn.
Wòlíì àti Àlùfáà
ti lọ sí ilẹ̀ tí wọn kò mọ̀.’ ”
19 Ṣé o ti kọ Juda sílẹ̀ pátápátá ni?
Ṣé o ti ṣá Sioni tì?
Èéṣe tí o fi pọ́n wa lójú
tí a kò fi le wò wá sàn?
A ń retí àlàáfíà
ṣùgbọ́n ohun rere kan kò tí ì wá,
ní àsìkò ìwòsàn
ìpayà là ń rí.
20 Olúwa, a jẹ́wọ́ ìwà ibi wa
àti àìṣedéédéé àwọn baba wa;
lóòótọ́ ni a ti ṣẹ̀ sí ọ.
21 Nítorí orúkọ rẹ má ṣe kórìíra wa;
má ṣe sọ ìtẹ́ ògo rẹ di àìlọ́wọ̀.
Rántí májẹ̀mú tí o bá wa dá
kí o má ṣe dà á.
22 Ǹjẹ́ èyíkéyìí àwọn òrìṣà yẹ̀yẹ́ tí àwọn orílẹ̀-èdè le ṣe kí òjò rọ̀?
Ǹjẹ́ àwọsánmọ̀ fúnrarẹ̀ rọ òjò bí?
Rárá, ìwọ ni, Olúwa Ọlọ́run wa.
Torí náà, ìrètí wa wà lọ́dọ̀ rẹ,
nítorí pé ìwọ lo ń ṣe gbogbo nǹkan wọ̀nyí.
15 Nígbà náà ni Olúwa sọ fún mi pé: “Kódà kí Mose àti Samuẹli dúró níwájú mi, ọkàn mi kì yóò lọ sọ́dọ̀ àwọn ènìyàn wọ̀nyí. Mú wọn kúrò níwájú mi! Jẹ́ kí wọn ó lọ! 2 (B)Tí wọ́n bá sì bi ọ́ pé, ‘Níbo ni kí a lọ?’ Sọ fún wọn pé, ‘Báyìí ni Olúwa wí:
“ ‘Àwọn tí a kọ ikú mọ́, sí ikú;
àwọn tí a kọ idà mọ́, sí idà;
àwọn tí a kọ ìyàn mọ́, sí ìyàn;
àwọn tí a kọ ìgbèkùn mọ́ sí ìgbèkùn.’
3 “Èmi yóò rán oríṣìí ìjìyà mẹ́rin láti kọlù wọ́n,” ni Olúwa wí, “Idà láti pa, àwọn ajá láti wọ́ wọn lọ, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run àti àwọn ẹranko orí ilẹ̀ láti jẹ àti láti parun. 4 N ó sọ wọ́n di ẹni ìkórìíra níwájú gbogbo ìjọba ayé torí ohun tí Manase ọmọ Hesekiah ọba Juda ṣe ní Jerusalẹmu.
5 “Ta ni yóò ṣàánú rẹ, ìwọ Jerusalẹmu?
Ta ni yóò dárò rẹ?
Ta ni yóò dúró béèrè àlàáfíà rẹ?
6 O ti kọ̀ mí sílẹ̀,” ni Olúwa wí
“Ìwọ sì wà nínú ìpadàsẹ́yìn.
Nítorí náà, Èmi yóò dáwọ́lé ọ, èmi ó sì pa ọ́ run;
Èmi kò sì ní fi ojú àánú wò ọ́ mọ́.
7 Èmi kò tún lè fi ìfẹ́ hàn si ọ,
Èmi yóò fi àtẹ fẹ́ wọn sí ẹnu-ọ̀nà ìlú náà.
Èmi yóò mú ìṣọ̀fọ̀ àti ìparun
bá àwọn ènìyàn mi nítorí pé wọn
kò tí ì yípadà kúrò lọ́nà wọn.
8 Èmi yóò jẹ́ kí àwọn opó wọn pọ̀ ju
yanrìn Òkun lọ.
Ní ọjọ́-kanrí ni èmi ó mú apanirun
kọlu àwọn ìyá ọmọkùnrin wọn.
Lójijì ni èmi yóò mú
ìfòyà àti ìbẹ̀rù bá wọn.
9 Ìyá ọlọ́mọ méje yóò dákú, yóò
sì mí ìmí ìgbẹ̀yìn. Òòrùn rẹ
yóò wọ̀ lọ́sàn án gangan, yóò
di ẹni ẹ̀tẹ́ òun àbùkù. Èmi
yóò fi àwọn tí ó bá yè síwájú
àwọn ọ̀tá wọn tí idà wà lọ́wọ́ wọn,”
ni Olúwa wí.
10 Háà! Ó ṣe tí ìyá mi bí mi:
ọkùnrin tí gbogbo ilẹ̀ dojúkọ tí wọ́n sì bá jà,
èmi kò wínni, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò yá lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni
síbẹ̀, gbogbo ènìyàn ló ń fi mí ré.
11 Olúwa sọ pé,
“Dájúdájú èmi ò dá ọ sí fún ìdí kan pàtó.
Dájúdájú mo mú kí àwọn ọ̀tá rẹ
tẹríba níwájú rẹ nígbà ibi àti ìpọ́njú.
12 “Ǹjẹ́ ẹnìkan lè fi ọwọ́ ṣẹ́ irin
irin láti àríwá tàbí idẹ?
13 “Gbogbo ọlá àti ìṣúra rẹ
ni èmi ó fi sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìkógun láìgba
nǹkan kan nítorí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ
jákèjádò orílẹ̀-èdè rẹ.
14 Èmi yóò fi ọ́ ṣẹrú fún àwọn ọ̀tá rẹ
ní ìlú tí ìwọ kò mọ̀ nítorí ìbínú
mi yóò rán iná tí yóò jó ọ.”
15 Ó yé ọ, ìwọ Olúwa rántí mi kí o
sì ṣe ìtọ́jú mi; gbẹ̀san mi lára
àwọn tó dìtẹ̀ mi. Ìwọ ti jìyà fún
ìgbà pípẹ́, má ṣe mú mi lọ, nínú bí
mo ṣe jìyà nítorí tìrẹ.
16 Nígbà tí ọ̀rọ̀ rẹ dé, mo jẹ wọ́n
Àwọn ni ìdùnnú àti ayọ̀ ọkàn mi
Nítorí pé orúkọ rẹ ni a fi ń pè mí
Ìwọ Olúwa Ọlọ́run Alágbára.
17 Èmi kò fìgbà kan jókòó láàrín àwọn ẹlẹ́gàn.
N ko bá wọn yọ ayọ̀ pọ̀;
mo dá jókòó torí pé ọwọ́ rẹ wà
lára mi, ìwọ sì ti fi ìbínú rẹ kún inú mi.
18 Èéṣe tí ìrora mi kò lópin,
tí ọgbẹ́ mi kò sì ṣe é wòsàn?
Ní òtítọ́ ìwọ yóò dàbí kànga ẹ̀tàn sí mi,
gẹ́gẹ́ bí ìsun tó kọ̀ tí kò sun?
19 Nítorí náà báyìí ni Olúwa wí:
“Tí o bá ronúpìwàdà, Èmi ó dá ọ padà
wá kí o lè máa sìn mí. Tí ó bá
sọ ọ̀rọ̀ tó dára ìwọ yóò di agbẹnusọ
mi. Jẹ́ kí àwọn ènìyàn yìí kọjú sí ọ;
ṣùgbọ́n ìwọ kò gbọdọ̀ kọjú sí wọn
20 Èmi fi ọ́ ṣe odi idẹ tí ó lágbára
sí àwọn ènìyàn wọ̀nyí. Wọn ó bá ọ jà
ṣùgbọ́n, wọn kò ní lè borí rẹ
nítorí pé, mo wà pẹ̀lú rẹ láti gbà ọ́ là,
kí n sì dáàbò bò ọ́,”
ni Olúwa wí.
21 “Èmi yóò gbà ọ́ sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn
ìkà ènìyàn, Èmi yóò sì rà ọ́
padà kúrò lọ́wọ́ àwọn ẹni búburú.”
Ọjọ́ àjálù
16 Bákan náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé: 2 “Ìwọ kò gbọdọ̀ ní ìyàwó, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ ní ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin níbí yìí.” 3 Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa wí nípa ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin tí wọ́n bá bí nílẹ̀ yìí, àti ìyá tí ó bí wọn àti baba wọn. 4 “Wọn yóò kú ikú ààrùn, wọn kò ní sin wọ́n tàbí ṣọ̀fọ̀ fún wọn. Wọn ó dàbí ìdọ̀tí lórí ilẹ̀; wọn ó ṣègbé pẹ̀lú idà àti ìyàn. Òkú wọn yóò sì di oúnjẹ fún ẹyẹ ojú ọ̀run àti ẹranko ilẹ̀.”
5 Nítorí báyìí ni Olúwa wí: “Má ṣe wọ ilé tí oúnjẹ ìsìnkú wà, má ṣe lọ síbẹ̀ láti káàánú tàbí ṣọ̀fọ̀, nítorí mo ti mú àlàáfíà, ìfẹ́ àti àánú mi kúrò lórí àwọn ènìyàn wọ̀nyí,” ni Olúwa wí. 6 “Àti ẹni ńlá àti kékeré ni yóò ṣègbé ní ilẹ̀ yìí, wọn kò ní sin wọ́n tàbí ṣọ̀fọ̀ wọn, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹni tí yóò fá irun orí wọn nítorí wọn. 7 Kò sí ẹni tí yóò fi oúnjẹ tu àwọn tí í ṣọ̀fọ̀ nínú, kódà kì í ṣe fún baba tàbí fún ìyá, kì yóò sí ẹni tí yóò fi ohun mímu tù wọ́n nínú.
8 “Ìwọ kò gbọdọ̀ lọ sí ilé tí àjọyọ̀ wà, má ṣe jókòó jẹun tàbí mu ohun mímu. 9 Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run àwọn ọmọ Israẹli wí: Ní ojú yín ní ọjọ́ yín ni òpin yóò dé bá ìró ayọ̀ àti ìdùnnú, àti sí ohùn ìyàwó àti ọkọ ìyàwó ní ibí yìí.
10 “Nígbà tí o bá sọ nǹkan wọ̀nyí fún àwọn ènìyàn yìí, tí wọ́n bá sì bi ọ́ wí pé, ‘Èéṣe tí Olúwa ṣe mú búburú yìí bá wa? Kí ni àṣìṣe tí àwa ṣe? Kín ni ẹ̀ṣẹ̀ tí àwa ṣẹ̀ sí Olúwa Ọlọ́run wa?’ 11 Nígbà náà ni ìwọ yóò sọ fún wọn wí pé, ‘Nítorí tí àwọn baba yín ti kọ̀ mí sílẹ̀,’ ni Olúwa wí, ‘tí wọ́n sì tẹ̀lé àwọn òrìṣà mìíràn tí wọ́n ń bọ, tí wọ́n ń sìn, wọ́n kọ̀ mí sílẹ̀ wọn kò sì tẹ̀lé òfin mi mọ́. 12 Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti ṣe búburú ju ti àwọn baba yín lọ. Wò ó bí gbogbo yín ṣe ń rìn, olúkúlùkù yín nínú agídí ọkàn búburú rẹ̀, dípò kí ẹ fi gbọ́ tèmi. 13 Èmi yóò gbé yin kúrò ní ilẹ̀ yìí lọ sí ilẹ̀ tí baba yín tàbí ẹ̀yin kò mọ̀ rí, níbẹ̀ ni ẹ̀yin yóò ti máa sìn ọlọ́run kéékèèkéé ní ọ̀sán àti òru nítorí èmi kì yóò fi ojúrere wò yín.’
14 “Nítorí náà, ọjọ́ náà ń bọ̀ wá,” ni Olúwa wí, “tí àwọn ènìyàn kò ní sọ pé, ‘Dájúdájú Olúwa wà láààyè Olúwa ń bẹ Ẹni tí ó mú Israẹli jáde kúrò ní Ejibiti.’ 15 Ṣùgbọ́n wọn yóò sọ wí pé, ‘Bí Olúwa ṣe wà nítòótọ́ tí ó mú àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ àríwá àti ní gbogbo orílẹ̀-èdè tí ó ti lé wọn.’ Bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò dá wọn padà sí ilẹ̀ tí mo fún àwọn baba ńlá wọn.
16 “Ṣùgbọ́n báyìí, Èmi yóò ránṣẹ́ sí àwọn apẹja púpọ̀,” ni Olúwa wí. “Wọn ó sì dẹ wọ́n lẹ́yìn èyí yìí èmi yóò ránṣẹ́ sí àwọn ọdẹ púpọ̀, wọn yóò dẹ wọ́n lórí gbogbo òkè ńlá àti òkè gíga, àti ní gbogbo pálapàla àpáta. 17 Ojú mi wà ní gbogbo ọ̀nà wọn, wọn kò pamọ́ fún mi bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀ṣẹ̀ wọn kò fi ara sin lójú mi. 18 Èmi yóò san ẹ̀san ìwà búburú àti ẹ̀ṣẹ̀ wọn fún wọn ní ìlọ́po méjì, nítorí wọ́n ti ba ilẹ̀ mi jẹ́ pẹ̀lú àwọn ère wọn aláìlẹ́mìí, wọ́n sì fi òkú àti ohun ẹ̀gbin àti ìríra wọn kún ilẹ̀ ìní mi.”
19 Olúwa, alágbára àti okun mi,
ẹni ààbò mi ní ọjọ́ ìpọ́njú
Háà! àwọn orílẹ̀-èdè yóò wá láti
òpin ayé wí pé,
“Àwọn baba ńlá wa kò ní ohun kan bí kò ṣe ẹ̀gbin òrìṣà,
ìríra tí kò dára fún wọn nínú rẹ̀.
20 Ṣé àwọn ènìyàn lè dá Ọlọ́run
fún ara wọn bí? Bẹ́ẹ̀ ni,
ṣùgbọ́n àwọn wọ̀nyí kì í ṣe Ọlọ́run.”
21 “Nítorí náà, Èmi yóò kọ́ wọn ní
àkókò yìí, Èmi yóò kọ́ wọn pẹ̀lú
agbára àti títóbi mi; nígbà
náà ni wọn ó mọ orúkọ mi
ní Olúwa.
17 “Ẹ̀ṣẹ̀ Juda ni a fi kálámù irin kọ,
èyí tí a fi ṣóńṣó òkúta adamante gbẹ́ ẹ,
sórí wàláà oókan àyà wọn,
àti sórí ìwo pẹpẹ yín.
2 Kódà àwọn ọmọ wọn rántí pẹpẹ
àti ère Aṣerah lẹ́bàá igi tí ó tẹ́ rẹrẹ
àti àwọn òkè gíga.
3 Àwọn òkè nínú ilẹ̀ àti àwọn ọrọ̀ rẹ̀
àti ọlá rẹ̀ ni èmi yóò fi sílẹ̀ bí ìjẹ
pẹ̀lú àwọn ibi gíga, nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó
pọ̀ káàkiri orílẹ̀-èdè yín.
4 Láti ipasẹ̀ àìṣedéédéé yín ni ẹ̀yin
yóò ti sọ ogún tí mo fún un yín nù.
Èmi yóò fi yín fún ọ̀tá yín
bí ẹrú ní ilẹ̀ tí ẹ̀yin kò mọ̀; nítorí
ẹ̀yin ti mú inú bí mi, èyí tí yóò sì wà títí ayé.”
5 Báyìí ni Olúwa wí:
“Ègbé ni fún àwọn tí ó fi ìgbẹ́kẹ̀lé wọn sínú ènìyàn,
tí ó fi agbára rẹ̀ sínú ẹran-ara,
àti tí ọkàn rẹ̀ kò sí lọ́dọ̀ Olúwa
6 Yóò dàbí igbó tí ó wà ní ilẹ̀ aláìlọ́ràá,
kò ní rí ìre, nígbà tí ó bá dé,
yóò máa gbé ní ibi ìyàngbẹ ilẹ̀ aginjù,
ní ilẹ̀ iyọ̀ tí ẹnikẹ́ni kò gbé.
7 (C)“Ṣùgbọ́n ìbùkún ni fún ọkùnrin
náà tí ó gbẹ́kẹ̀lé Olúwa, tí ó sì fi
Olúwa ṣe ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ̀.
8 Yóò dàbí igi tí a gbìn sí ipadò
tí ó ta gbòǹgbò rẹ̀ ká etí odò
kò sí ìbẹ̀rù fún un nígbà ooru,
gbogbo ìgbà ni èwe rẹ̀ máa ń tutù
kò sí ìjayà fún un ní ọdún ọ̀dá
bẹ́ẹ̀ ni kò ní dẹ́kun láti máa so èso.”
9 Ọkàn ènìyàn kún fún ẹ̀tàn ju ohun
gbogbo lọ, ó kọjá ohun tí a lè
wòsàn, ta ni èyí lè yé?
10 (D)“Èmi Olúwa ń wo ọkàn àti èrò
inú ọmọ ènìyàn láti san èrè
iṣẹ́ rẹ̀ fún un, gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà rẹ̀
àti gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.”
11 Bí àparò tó pa ẹyin tí kò yé ni
ọmọ ènìyàn tí ó kó ọrọ̀ jọ ni
ọ̀nà àìṣòdodo. Yóò di ẹni ìkọ̀sílẹ̀
ní agbede-méjì ayé rẹ̀, àti ní
òpin rẹ̀ yóò wá di aṣiwèrè.
12 Ìtẹ́ ògo; ibi gíga láti ìpilẹ̀ṣẹ̀
ní ibi ilé mímọ́ wa.
13 Olúwa ìwọ ni ìrètí Israẹli;
gbogbo àwọn tí ó kọ̀ ọ́ sílẹ̀ ni ojú ó tì.
Àwọn tí ó padà sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ rẹ
ni a ó kọ orúkọ wọn sínú ekuru,
nítorí wọ́n ti kọ Olúwa,
orísun omi ìyè sílẹ̀.
14 Wò mí sàn Olúwa, èmi yóò di ẹni ìwòsàn,
gbà mí là, èmi yóò di ẹni ìgbàlà,
nítorí ìwọ ni ìyìn mi.
15 Wọ́n sọ fún mi wí pé:
“Níbo ni ọ̀rọ̀ Olúwa wà?
Jẹ́ kí ó di ìmúṣẹ báyìí.”
Ni Olúwa wí.
16 Èmi kò sá kúrò láti máa jẹ́ olùṣọ àgùntàn rẹ,
ìwọ mọ̀ wí pé èmi kò kẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ ìpọ́njú.
Ohun tí ó jáde ní ètè mi jẹ́ èyí tí ó hàn sí ọ.
17 Má ṣe di ìbẹ̀rù fún mi,
ìwọ ni ààbò mi ní ọjọ́ ìpọ́njú.
18 Jẹ́ kí ojú ti àwọn ẹni tí ń lépa mi,
ṣùgbọ́n pa mí mọ́ kúrò nínú ìtìjú,
jẹ́ kí wọn kí ó dààmú.
Mú ọjọ́ ibi wá sórí wọn,
fi ìparun ìlọ́po méjì pa wọ́n run.
Pípa ọjọ́ ìsinmi mọ́
19 Èyí ni ohun tí Olúwa wí fún mi: “Lọ dúró ní ẹnu-ọ̀nà àwọn ènìyàn níbi tí àwọn ọba Juda ń gbà wọlé tí wọ́n ń gbà jáde àti ní gbogbo ẹnu-bodè Jerusalẹmu. 20 Sọ fún wọ́n pé, ‘Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa ẹ̀yin ọba Juda àti gbogbo ẹ̀yin ènìyàn Juda àti gbogbo ẹ̀yin tí ń gbé ní Jerusalẹmu tí ń wọlé láti ẹnu ibodè yìí. 21 Báyìí ni Olúwa wí: Ẹ kíyèsi láti máa ru ẹrù lọ́jọ́ ìsinmi tàbí kí ẹ gbé wọlé láti ẹnu ibodè Jerusalẹmu. 22 Má ṣe gbé ẹrù jáde kúrò nínú ilé yín, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má ṣe ṣe iṣẹ́kíṣẹ́ ní ọjọ́ ìsinmi ṣùgbọ́n kí ẹ pa ọjọ́ ìsinmi mọ́ fún àwọn baba ńlá yín. 23 Síbẹ̀ wọn kò gbọ́ tàbí tẹ́tí sílẹ̀, wọ́n jẹ́ ọlọ́rùn líle; wọn kì í fẹ́ gbọ́ tàbí gba ìbáwí. 24 Ṣùgbọ́n tí ẹ̀yin bá kíyèsi láti gbọ́ tèmi ní Olúwa wí, tí ẹ kò sì gbe ẹrù gba ẹnu-bodè ìlú ní ọjọ́ ìsinmi, ṣùgbọ́n tí ẹ ya ọjọ́ ìsinmi, sí mímọ́, nípa pé ẹ kò ṣe iṣẹ́kíṣẹ́ ní ọjọ́ náà. 25 Nígbà náà ni ọba tí ó jókòó lórí ìtẹ́ Dafidi yóò gba ẹnu ibodè wọlé pẹ̀lú àwọn ìjòyè rẹ̀. Àwọn àti ìjòyè wọn yóò gun ẹṣin àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wá, àwọn ọkùnrin Juda àti àwọn olùgbé Jerusalẹmu yóò tẹ̀lé wọn; ìlú yìí yóò sì di ibi gbígbé títí láéláé. 26 Àwọn ènìyàn yóò wá láti ìlú Juda àti ní agbègbè Jerusalẹmu, láti ilẹ̀ Benjamini, láti pẹ̀tẹ́lẹ̀, àti láti òkè, àti láti gúúsù wá, wọn yóò wá pẹ̀lú ọrẹ ẹbọ sísun, àti ọrẹ ẹran, àti tùràrí, àti àwọn tó mú ìyìn wá sí ilé Olúwa. 27 Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin kò bá pa òfin mi mọ́ láti ya ọjọ́ ìsinmi sí mímọ́, kí ẹ má sì ṣe ru ẹrùkẹ́rù bí ẹ̀yin yóò ṣe máa gba ẹnu ibodè Jerusalẹmu wọlé ní ọjọ́ ìsinmi, nígbà náà ni èmi yóò da iná tí kò ní ṣe é parun ní ẹnu-bodè Jerusalẹmu tí yóò sì jó odi agbára rẹ̀.’ ”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.