Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Book of Common Prayer

Daily Old and New Testament readings based on the Book of Common Prayer.
Duration: 861 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 55

Fún adarí orin. Pẹ̀lú ohun èlò orin olókùn. Maskili ti Dafidi.

55 Fi etí sí àdúrà mi, Ọlọ́run,
    Má ṣe fi ojú pa ẹ̀bẹ̀ mi rẹ́:
    Gbọ́ mi kí o sì dá mi lóhùn.
Èrò mi ń dà mí láàmú, èmi sì ń pariwo.
    Sí ohùn àwọn ọ̀tá ni,
    nítorí igbe àwọn ènìyàn búburú;
nítorí wọ́n mú ìjìyà wá sórí mi,
    wọ́n sì kẹ́gàn mi nínú ìbínú wọn.

Ọkàn mi wà nínú ìrora pẹ̀lú;
    ẹ̀rù ikú kọjú ìjà sí mi.
Ìbẹ̀rù àti ìwárìrì wa sí ara mi;
    ìbẹ̀rù ti bò mí mọ́lẹ̀.
Èmi sọ pé, “Èmi ìbá ní ìyẹ́ bí àdàbà!
    Èmi ìbá fò lọ kí n sì sinmi.
Èmi ìbá sálọ, jìnnà réré,
    kí ń sì dúró sí aginjù;
Èmi ìbá yára lọ́ si ibùgbé mi ní ibi ààbò,
    jìnnà kúrò nínú ìjì àti ẹ̀fúùfù líle.”

Da àwọn ẹni búburú láàmú, Olúwa, da ahọ́n wọn rú,
    nítorí èmi rí ìwà agbára àti ìjà ní ìlú náà.
10 Ọ̀sán àti òru ni wọ́n fi ń rìn gbogbo odi kiri;
    ìwà ìkà àti èébú wà láàrín rẹ̀.
11 Ìwà búburú ń bẹ ní àárín rẹ̀;
    ẹ̀tàn àti èké kò kúrò ní ìgboro rẹ̀.

12 Tí ọ̀tá bá tàbùkù mi,
    èmi yóò fi ara mọ́ ọn;
tí ọ̀tá bá gbé ara rẹ̀ ga sí mi,
    èmi ìbá sápamọ́ fún un.
13 Ṣùgbọ́n tí ó bá ṣe ìwọ, ọkùnrin bí ẹgbẹ́ mi,
    ẹlẹgbẹ́ mi, àti ọ̀rẹ́ tí ó súnmọ́ mi,
14 pẹ̀lú ẹni tí èmi ti jẹ ìgbádùn adùn ìdàpọ̀,
    bí a ṣe ń rìn pẹ̀lú àwùjọ ní ilé Ọlọ́run.

15 Kí ikú kí ó dé bá wọn,
    Kí wọn ó lọ láààyè sí isà òkú,
Jẹ́ kí wọn ó sọ̀kalẹ̀ sí ibojì pẹ̀lú ìpayà,
    nítorí tí ìwà búburú ń bẹ ní ibùjókòó wọn, àti nínú wọn.

16 Ṣùgbọ́n èmi pe Ọlọ́run;
    Olúwa yóò sì gbà mí.
17 Ní alẹ́, ní òwúrọ̀ àti ní ọ̀sán
    èmi sọkún jáde nínú ìpọ́njú,
    o sì gbọ́ ohùn mi.
18 Ó rà mí padà láìléwu
    kúrò nínú ogun tí ó dìde sí mi,
    nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ó dìde sí mi.
19 Ọlọ́run yóò gbọ́, yóò sì pọ́n wọn lójú
    àní, ẹni tí ó ti jókòó láti ìgbàanì—Sela.
Nítorí tí wọn kò ní àyípadà,
    tí wọn kò sì bẹ̀rù Ọlọ́run.

20 Ọ̀rẹ́ mi yìí ti dalẹ̀ èmi ọ̀rẹ́ rẹ̀;
    ó ti ba májẹ̀mú rẹ̀ jẹ́.
21 Ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ kúnná ju òrí-àmọ́,
    ṣùgbọ́n ogun wà ni àyà rẹ̀;
ọ̀rọ̀ rẹ̀ fẹ́lẹ́ ju òróró lọ,
    ṣùgbọ́n idà fífàyọ ní wọn.

22 (A)Gbé ẹrù rẹ lọ sí ọ̀dọ̀ Olúwa
    yóò sì mú ọ dúró;
òun kò ní jẹ́ kí olódodo ṣubú.
23 Ṣùgbọ́n ìwọ, Ọlọ́run, ni yóò mu àwọn ọ̀tá mi
    wá sí ihò ìparun;
Àwọn ẹni tí òǹgbẹ ẹ̀jẹ̀ ń gbẹ àti ẹni ẹ̀tàn,
    kì yóò gbé ààbọ̀ ọjọ́ wọn.

Ṣùgbọ́n fún èmi, èmi gbẹ́kẹ̀lé ọ.

Saamu 138:1-139:23

Ti Dafidi

138 Èmi yóò yìn ọ́ tinútinú mi gbogbo;
    níwájú àwọn òrìṣà ni èmi ó kọrin ìyìn sí ọ.
Èmi ó máa gbàdúrà sí ìhà tẹmpili mímọ́ rẹ̀
    èmi ó sì máa yin orúkọ rẹ
nítorí ìṣeun ìfẹ́ rẹ àti òtítọ́ rẹ;
    nítorí ìwọ gbé ọ̀rọ̀ rẹ ga ju orúkọ rẹ lọ.
Ní ọjọ́ tí mo ké pè é ọ́, ìwọ dá mi lóhùn,
    ìwọ sì fi ipa mú mi lára le ní ọkàn mi.

Gbogbo àwọn ọba ayé yóò yìn ọ́,
    Olúwa, ní ìgbà tí wọn bá gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ
Nítòótọ́, wọn ó máa kọrin ní ipa ọ̀nà Olúwa;
    nítorí pé ńlá ni ògo Olúwa.

Olúwa tilẹ̀ ga, síbẹ̀ ó júbà àwọn onírẹ̀lẹ̀;
    ṣùgbọ́n agbéraga ni ó mọ̀ ní òkèrè réré.
Bí èmi tilẹ̀ ń rìn nínú ìpọ́njú ìwọ ni yóò sọ mi di ààyè;
    ìwọ ó na ọwọ́ rẹ sí àwọn ọ̀tá mi,
    ọwọ́ ọ̀tún rẹ yóò sì gbà mí.
Olúwa yóò ṣe ohun tí ń ṣe tèmi láṣepé;
    Olúwa, àánú rẹ dúró láéláé;
    Má ṣe kọ iṣẹ́ ọwọ́ ara rẹ sílẹ̀.

Fún adarí orin. Ti Dafidi. Saamu.

139 Olúwa, ìwọ tí wádìí mi,
    ìwọ sì ti mọ̀ mí.
Ìwọ mọ̀ ìjókòó mi àti ìdìde mi,
    ìwọ mọ̀ èrò mi ní ọ̀nà jíjìn réré.
Ìwọ yí ipa ọ̀nà mi ká àti ìdùbúlẹ̀ mi,
    gbogbo ọ̀nà mi sì di mí mọ̀ fún ọ.
Nítorí tí kò sí ọ̀rọ̀ kan ní ahọ́n mi,
    kíyèsi i, Olúwa, ìwọ mọ̀ ọ́n pátápátá.
Ìwọ sé mi mọ́ lẹ́yìn àti níwájú,
    ìwọ sì fi ọwọ́ rẹ lé mi.
Irú ìmọ̀ yìí jẹ ohun ìyanu fún mi jù;
    ó ga, èmi kò le mọ̀ ọ́n.

Níbo ní èmi yóò gbé lọ kúrò ni ọwọ́ ẹ̀mí rẹ?
    Tàbí níbo ni èmi yóò sáré kúrò níwájú rẹ?
Bí èmi bá gòkè lọ sí ọ̀run, ìwọ wà níbẹ̀;
    bí èmí ba sì tẹ́ ẹní mi ní ipò òkú,
    kíyèsi i, ìwọ wà níbẹ̀ pẹ̀lú.
Èmi ìbá mú ìyẹ́ apá òwúrọ̀,
    kí èmi sì lọ jókòó ní ìhà òpin Òkun;
10 Àní, níbẹ̀ náà ni ọwọ́ rẹ̀ yóò fà mí
    ọwọ́ ọ̀tún rẹ yóò sì dì mímú.
11 Bí mo bá wí pé, “Ǹjẹ́ kí òkùnkùn kí ó bò mí mọ́lẹ̀;
    kí ìmọ́lẹ̀ kí ó di òru yí mi ká.”
12 Nítòótọ́ òkùnkùn kì í ṣú lọ́dọ̀ rẹ;
    ṣùgbọ́n òru tan ìmọ́lẹ̀ bí ọ̀sán;
    àti òkùnkùn àti ọ̀sán, méjèèjì bákan náà ní fún ọ.

13 Nítorí ìwọ ni ó dá ọkàn mi;
    ìwọ ni ó bò mí mọ́lẹ̀ nínú ìyá mi.
14 Èmi yóò yìn ọ, nítorí tẹ̀rù tẹ̀rù àti tìyanu tìyanu ní a dá mi;
    ìyanu ní iṣẹ́ rẹ;
    èyí nì ni ọkàn mi sì mọ̀ dájúdájú
15 Ẹ̀dá ara mi kò pamọ́ kúrò lọ́dọ̀ rẹ,
    nígbà tí a dá mi ní ìkọ̀kọ̀.
    Tí a sì ń ṣiṣẹ́ ní àràbarà ní ìhà ìsàlẹ̀ ilẹ̀ ayé,
16 ojú rẹ ti rí ohun ara mi
    nígbà tí a kò tí ì ṣe mí pé:
    àti nínú ìwé rẹ ni a ti kọ ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sí,
ní ọjọ́ tí a dá wọn,
    nígbà tí wọn kò tilẹ̀ tí ì sí.
17 Ọlọ́run, èrò inú rẹ tí ṣe iyebíye tó fún mi,
    iye wọn ti pọ̀ tó!
18 Èmi ìbá kà wọ́n,
    wọ́n ju iyanrìn lọ ní iye:
nígbà tí mo bá jí,
    èmi yóò wà lọ́dọ̀ rẹ síbẹ̀.

19 Ọlọ́run ìbá jẹ́ pa àwọn ènìyàn búburú nítòótọ́;
    nítorí náà kúrò lọ́dọ̀ mi ẹ̀yin ọkùnrin ẹlẹ́jẹ̀.
20 Ẹni tí ń fi inú búburú sọ̀rọ̀ sí ọ,
    àwọn ọ̀tá rẹ ń pe orúkọ rẹ ní asán!
21 Olúwa, ǹjẹ́ èmi kò kórìíra àwọn tó kórìíra rẹ?
    Ǹjẹ́ inú mi kò a sì bàjẹ́ sí àwọn tí ó dìde sí ọ?
22 Èmi kórìíra wọn ní àkótán;
    èmi kà wọ́n sí ọ̀tá mi.
23 Ọlọ́run, wádìí mi, kí o sì mọ ọkàn mí;
    dán mi wò, kí o sì mọ ìrò inú mi

Isaiah 10:20-27

Àwọn ìyókù Israẹli

20 Ní ọjọ́ náà, àwọn tí ó ṣẹ́kù ní Israẹli,
    Àwọn tí ó yè ní ilé e Jakọbu,
kò ní gbẹ́kẹ̀lé ẹni náà
    tí ó lù wọ́n bolẹ̀,
ṣùgbọ́n ní òtítọ́ yóò gbẹ́kẹ̀lé Olúwa
    Ẹni Mímọ́ Israẹli.
21 Àwọn ìyókù yóò padà, àwọn ìyókù ti Jakọbu
    yóò padà sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Alágbára.
22 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ènìyàn rẹ, ìwọ Israẹli
    dàbí yanrìn ní Òkun,
ẹni díẹ̀ ni yóò padà.
    A ti pàṣẹ ìparun
    àkúnwọ́sílẹ̀ àti òdodo.
23 Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni yóò mú un ṣẹ,
    ìparun tí a ti pàṣẹ rẹ̀ lórí
    gbogbo ilẹ̀ náà.

24 Nítorí náà, báyìí ni Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí,

    “Ẹ̀yin ènìyàn mi tí ó ń gbé Sioni,
Ẹ má ṣe bẹ̀rù àwọn Asiria,
    tí ó ń fi ọ̀pá lù yín,
tí wọ́n sì ń gbé ọ̀gọ tì yín bí
    Ejibiti ti ṣe.
25 Láìpẹ́, ìbínú mi sí i yín yóò wá sí òpin
    n ó sì dojú ìrunú mi kọ wọ́n,
    fún ìparun wọn.”

26 Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò nà wọ́n ní ẹgba.
    Gẹ́gẹ́ bí ó ṣe lu Midiani
ní òkè Orebu,
    yóò sì gbé ọ̀pá rẹ̀ lé orí omi
    gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ní Ejibiti.
27 Ní ọjọ́ náà, a ó gbé ẹrù wọn kúrò ní èjìká a yín,
    àti àjàgà a wọn kúrò ní ọrùn un yín
a ó fọ́ àjàgà náà,
    nítorí pé ẹ̀yin ó ti sanra.

Juda 17-25

Ìpè fún ìdúró ṣinṣin

17 Ṣùgbọ́n ẹ̀yin olùfẹ́, ẹ rántí àwọn ọ̀rọ̀ tí a ti sọ ṣáájú láti ọwọ́ àwọn aposteli Olúwa wa Jesu Kristi. 18 (A)Bí wọn ti wí fún yín pé, “Nígbà ìkẹyìn àwọn ẹlẹ́gàn yóò wà, tí wọn yóò máa rìn gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àìwà-bí-Ọlọ́run ti ara wọn.” 19 Àwọn ènìyàn wọ̀nyí ni àwọn ẹni tí ń ya ara wọn sí ọ̀tọ̀, àwọn ẹni ti ara, tí wọn kò ni Ẹ̀mí.

20 Ṣùgbọ́n ẹ̀yin, olùfẹ́, ti ẹ ń gbé ara yín ró lórí ìgbàgbọ́ yín tí ó mọ́ jùlọ, ti ẹ ń gbàdúrà nínú Ẹ̀mí Mímọ́. 21 Ẹ máa pa ara yín mọ́ nínú ìfẹ́ Ọlọ́run, bí ẹ̀yin ti ń retí àánú Olúwa wa Jesu Kristi tí yóò mú yín dé ìyè àìnípẹ̀kun.

22 Ẹ máa ṣàánú fún àwọn tí ń ṣe iyèméjì. 23 (B)Ẹ máa gba àwọn ẹlòmíràn là, nípa fífà wọ́n yọ kúrò nínú iná; kí ẹ sì máa ṣàánú pẹ̀lú ìbẹ̀rù kí ẹ sì kórìíra ẹ̀wù tí ara ti sọ di èérí.

Orin ìyìn sí Ọlọ́run

24 Ǹjẹ́ mo fi yín lé ẹni tí o lè pa yín mọ́ kúrò nínú ìkọ̀sẹ̀, tí o sì lè mú yín wá síwájú ògo rẹ̀ láìlábùkù pẹ̀lú ayọ̀ ńlá lọ́wọ́— 25 tí Ọlọ́run ọlọ́gbọ́n nìkan ṣoṣo, Olùgbàlà wa, ní ògo àti ọláńlá, ìjọba àti agbára, nípasẹ̀ Jesu Kristi Olúwa wa, kí gbogbo ayé tó wà, nísinsin yìí àti títí láéláé! Àmín.

Luku 3:1-9

Johanu onítẹ̀bọmi tún ọnà náà ṣe

(A)Ní ọdún kẹ́ẹ̀dógún ìjọba Tiberiu Kesari, nígbà tí Pọntiu Pilatu jẹ́ baálẹ̀ Judea, tí Herodu sì jẹ́ tetrarki Galili, Filipi arákùnrin rẹ̀ sì jẹ́ tetrarki Iturea àti ti Trakoniti, Lisania sì jẹ́ tetrarki Abilene, (B)tí Annasi òun Kaiafa ń ṣe olórí àwọn àlùfáà, nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tọ Johanu ọmọ Sekariah wá ní ijù. (C)Ó sì wá sí gbogbo ilẹ̀ aginjù Jordani, ó ń wàásù ìtẹ̀bọmi ìrònúpìwàdà fún ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀; (D)Bí a ti kọ ọ́ nínú ìwé ọ̀rọ̀ wòlíì Isaiah pé,

“Ohùn ẹni tí ń kígbe ní ijù,
‘ẹ tún ọ̀nà Olúwa ṣe,
    ẹ mú ipa ọ̀nà rẹ̀ tọ́.
Gbogbo ọ̀gbun ni a yóò kún,
    gbogbo òkè ńlá àti òkè kékeré ni a ó tẹ́ pẹẹrẹ;
Wíwọ́ ni a ó ṣe ní títọ́,
    àti ọ̀nà gbọ́ngungbọ̀ngun ni a o sọ di dídán.
(E)Gbogbo ènìyàn ni yóò sì rí ìgbàlà Ọlọ́run.’ ”

(F)Nígbà náà ni ó wí fún ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn tí ó wá láti ṣe ìtẹ̀bọmi lọ́dọ̀ rẹ̀ pé, “Ẹ̀yin ìran paramọ́lẹ̀, ta ni ó kìlọ̀ fún un yín láti sá kúrò nínú ìbínú tí ń bọ̀? (G)Nítorí náà kí ẹ̀yin kí ó so èso tí ó yẹ fún ìrònúpìwàdà, kí ẹ má sì ṣe sí í wí nínú ara yín pé, ‘Àwa ní Abrahamu ní baba.’ Kí èmi kí ó wí fún un yín, Ọlọ́run lè gbé ọmọ dìde fún Abrahamu nínú òkúta wọ̀nyí. (H)Àti nísinsin yìí pẹ̀lú, a fi àáké lé gbòǹgbò igi náà: gbogbo igi tí kò bá so èso rere, a óò ge lulẹ̀, a sì wọ jù sínú iná.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.