Book of Common Prayer
Ti Dafidi.
37 Má ṣe ìkanra nítorí àwọn olùṣe búburú,
kí ìwọ má sì ṣe ṣe ìlara nítorí àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀;
2 nítorí pé wọn yóò gbẹ bí i koríko,
wọn yóò sì rẹ̀ dànù bí ewéko tútù.
3 Gbẹ́kẹ̀lé Olúwa, kí o sì máa ṣe rere;
torí pé ìwọ yóò gbé ilẹ̀ náà, kí o sì gbádùn ààbò rẹ̀.
4 Ṣe inú dídùn sí Olúwa;
òun yóò sì fún ọ ní ìfẹ́ inú rẹ̀.
5 Fi ọ̀nà rẹ lé Olúwa lọ́wọ́;
gbẹ́kẹ̀lé pẹ̀lú, òun yóò sì ṣe é.
6 Yóò sì mú kí òdodo rẹ̀ jáde bí ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀,
àti ìdájọ́ rẹ̀ bí ọ̀sán gangan.
7 Ìwọ dákẹ́ jẹ́ẹ́ níwájú Olúwa,
kí o sì fi sùúrù dúró dè é;
má ṣe ṣe ìkanra nítorí àwọn tí ń rí rere ní ọ̀nà wọn,
nítorí ọkùnrin náà ti mú èrò búburú ṣẹ.
8 Fàsẹ́yìn nínú inúbíbí, kí o sì kọ ìkáàánú sílẹ̀,
má ṣe ṣe ìkanra, kí ó má ba à ṣé búburú pẹ̀lú.
9 Nítorí tí á ó gé àwọn olùṣe búburú kúrò,
ṣùgbọ́n àwọn tí ó bá dúró de Olúwa àwọn ni yóò jogún ilẹ̀ náà.
10 Síbẹ̀ nígbà díẹ̀ sí i, àwọn ènìyàn búburú kì yóò sí mọ̀;
nítòótọ́ ìwọ yóò fi ara balẹ̀ wo ipò rẹ̀, wọn kì yóò sí níbẹ̀.
11 Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò jogún ilẹ̀ náà,
wọn yóò sì máa ṣe inú dídùn nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà.
12 Ènìyàn búburú di rìkíṣí sí olóòtítọ́,
wọ́n sì pa eyín wọn keke sí wọn;
13 ṣùgbọ́n Olúwa rẹ́rìn-ín sí àwọn ènìyàn búburú,
nítorí tí ó rí wí pé ọjọ́ wọn ń bọ̀.
14 Ènìyàn búburú fa idà yọ,
wọ́n sì tẹ àwọn ọrun wọn,
láti sọ tálákà àti aláìní kalẹ̀,
láti pa àwọn tí ó dúró ṣinṣin.
15 Idà wọn yóò wọ àyà wọn lọ,
àti wí pé ọrun wọn yóò sì ṣẹ́.
16 Ohun díẹ̀ tí olódodo ní,
sàn ju ọ̀pọ̀ ọrọ̀ ènìyàn búburú;
17 nítorí pé a óò ṣẹ́ ọwọ́ àwọn ènìyàn búburú,
ṣùgbọ́n Olúwa gbé olódodo sókè.
18 Olúwa mọ àwọn ọjọ́ àwọn tó dúró ṣinṣin,
àti wí pé ilẹ̀ ìní wọn yóò wà títí ayérayé;
19 Ojú kì yóò tì wọ́n ní àkókò ibi,
àti ní ọjọ́ ìyàn, a ó tẹ́ wọn lọ́rùn.
20 Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn búburú yóò ṣègbé.
Àwọn ọ̀tá Olúwa yóò dàbí ẹwà oko tútù;
wọn fò lọ; bi èéfín ni wọn yóò fò lọ kúrò.
21 Àwọn ènìyàn búburú yá, wọn kò sì san án padà,
ṣùgbọ́n àwọn olódodo a máa ṣàánú, a sì máa fi fún ni;
22 Nítorí àwọn tí Olúwa bá bùkún ni yóò jogún ilẹ̀ náà,
àwọn tí ó fi bú ni a ó gé kúrò.
23 Ìlànà ìgbésẹ̀ ènìyàn rere wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa wá,
o sì ṣe inú dídùn sí ọ̀nà rẹ̀;
24 Bí ó tilẹ̀ ṣubú a kì yóò ta á nù pátápátá,
nítorí tí Olúwa di ọwọ́ rẹ̀ mú.
25 Èmi ti wà ni èwe, báyìí èmi sì dàgbà;
síbẹ̀ èmi kò ì tí ì ri kí a kọ olódodo sílẹ̀,
tàbí kí irú-ọmọ rẹ̀ máa ṣagbe oúnjẹ.
26 Aláàánú ni òun nígbà gbogbo a máa yá ni;
a sì máa bùsi i fún ni.
27 Lọ kúrò nínú ibi, kí o sì máa ṣe rere;
nígbà náà ni ìwọ yóò gbé ní ilẹ̀ náà títí láéláé.
28 Nítorí pé Olúwa fẹ́ràn ìdájọ́ òtítọ́,
kò sì kọ àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀ sílẹ̀.
Àwọn olódodo ni a ó pamọ́ títí ayérayé,
ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ènìyàn búburú ni a ó ké kúrò.
29 Olódodo ni yóò jogún ilẹ̀ náà,
yóò sì máa gbé ibẹ̀ títí ayérayé.
30 Ẹnu olódodo sọ̀rọ̀ ọgbọ́n,
ahọ́n rẹ̀ a sì máa sọ̀rọ̀ ìdájọ́.
31 Òfin Ọlọ́run rẹ̀ ń bẹ ní àyà wọn;
àwọn ìgbésẹ̀ rẹ̀ kì yóò yẹ̀.
32 Ènìyàn búburú ń ṣọ́ olódodo,
Ó sì ń wá ọ̀nà láti pa á.
33 Olúwa kì yóò fi lé e lọ́wọ́ kì yóò sì dá a lẹ́bi,
nígbà tí a bá ń ṣe ìdájọ́ rẹ̀.
34 Dúró de Olúwa,
kí o sì máa pa ọ̀nà rẹ̀ mọ́.
Yóò sì gbé ọ lékè láti jogún ilẹ̀ náà;
nígbà tí a bá gé àwọn ènìyàn búburú kúrò ìwọ yóò ri.
35 Èmi ti rí ènìyàn búburú tí ń hu ìwà ìkà,
ó sì fi ara rẹ̀ gbilẹ̀ bí igi tútù ńlá,
36 ṣùgbọ́n ní ìṣẹ́jú kan sí i ó kọjá lọ, sì kíyèsi, kò sì sí mọ́;
bi ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé mo wá a kiri, ṣùgbọ́n a kò le è ri.
37 Máa kíyèsi ẹni pípé, kí o sì wo ẹni tó dúró ṣinṣin;
nítorí àlàáfíà ni òpin ọkùnrin náà.
38 Ṣùgbọ́n àwọn olùrékọjá ni a ó parun papọ̀;
ìran àwọn ènìyàn búburú ni a ó gé kúrò.
39 Ìgbàlà àwọn onídùúró ṣinṣin wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa;
òun ni ààbò wọn ní ìgbà ìpọ́njú
40 Olúwa yóò ràn wọ́n lọ́wọ́ yóò sì gbà wọ́n;
yóò gbà wọ́n lọ́wọ́ ènìyàn búburú, yóò sì gbà wọ́n là,
nítorí tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé e.
Ààmì ti Emmanueli
7 Nígbà tí Ahasi ọmọ Jotamu ọmọ Ussiah jẹ́ ọba Juda, ọba Resini ti Aramu àti Peka ọmọ Remaliah ọba Israẹli gòkè wá láti bá Jerusalẹmu jà, ṣùgbọ́n wọn kò sì le è borí i rẹ̀.
2 Báyìí, a sọ fún ilé Dafidi pé, “Aramu mà ti lẹ̀dí àpò pọ̀ mọ́ Efraimu”; fún ìdí èyí, ọkàn Ahasi àti àwọn ènìyàn rẹ̀ wárìrì gẹ́gẹ́ bí igi oko ṣe ń wárìrì níwájú afẹ́fẹ́.
3 Lẹ́yìn èyí, Olúwa sọ fún Isaiah pé, “Jáde, ìwọ àti ọ̀dọ́mọkùnrin rẹ Ṣeari-Jaṣubu láti pàdé Ahasi ní ìpẹ̀kun ìṣàn omi ti adágún òkè, ní òpópó ọ̀nà tí ó lọ sí pápá Alágbàfọ̀. 4 Sọ fún un, ‘Ṣọ́ra à rẹ, fi ọkàn balẹ̀, kí o má ṣe bẹ̀rù. Má ṣe ba ọkàn jẹ́ nítorí kùkùté igi ìdáná méjèèjì yìí, nítorí ìbínú gbígbóná Resini àti Aramu àti ti ọmọ Remaliah. 5 Aramu, Efraimu àti Remaliah ti dìtẹ̀ ìparun rẹ, wọ́n wí pé, 6 “Jẹ́ kí a kọlu Juda; jẹ́ kí a fà á ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, kí a sì pín in láàrín ara wa, kí a sì fi ọmọ Tabeli jẹ ọba lórí i rẹ̀.” 7 Síbẹ̀ èyí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí:
“ ‘Èyí kò ní wáyé
èyí kò le ṣẹlẹ̀,
8 nítorí Damasku ni orí Aramu,
orí Damasku sì ni Resini.
Láàrín ọdún márùnlélọ́gọ́ta
Efraimu yóò ti fọ́ tí kì yóò le jẹ́ ènìyàn mọ́.
9 Orí Efraimu sì ni Samaria,
orí Samaria sì ni ọmọ Remaliah.
Bí ẹ̀yin kí yóò bá gbàgbọ́,
lóòtítọ́, a kì yóò fi ìdí yín múlẹ̀.’ ”
Ọkùnrin aláìlófin náà
2 (A)Ní ti bíbọ̀ Jesu Kristi Olúwa wa, àti ti ìpéjọ wa sọ́dọ̀ rẹ̀, àwa wí fún yín ará, 2 (B)kí ọkàn yín má ṣe àìbalẹ̀, tàbí kí ẹ má ṣe jáyà nípa àsọtẹ́lẹ̀, ìròyìn tàbí lẹ́tà tí ó lè fi ara jọ èyí tí ó le wá láti ọ̀dọ̀ wa, tí yóò máa wí pé ọjọ́ Olúwa ti dé ná. 3 (C)Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni kí ó tàn yín jẹ ní ọ̀nàkọnà, nítorí pé ọjọ́ náà kì yóò dé, bí kò ṣe pé ìṣọ̀tẹ̀ bá kọ́ ṣẹlẹ̀, tí a sì fi ẹni ẹ̀ṣẹ̀ hàn, tí í ṣe ọmọ ègbé. 4 (D)Òun yóò lòdì sí, yóò sì gbé ara rẹ̀ ga sí gbogbo ohun tí a ń pè ní Ọlọ́run tàbí tí a ń sìn, dé ibi pé yóò gbé ara rẹ̀ jókòó nínú tẹmpili Ọlọ́run, tí yóò sì pe ara rẹ̀ ní Ọlọ́run.
5 (E)Ṣé ẹ̀yin kò rántí pé nígbà tí mo wà pẹ̀lú yín, mo ń sọ àwọn nǹkan wọ̀nyí fún un yín. 6 Àti pé nísinsin yìí, ẹ̀yin mọ ohun tí ń dá a dúró, kí a bá a lè fi í hàn ní àkókò rẹ̀ gan an. 7 Nítorí agbára ìkọ̀kọ̀ ẹni ẹ̀ṣẹ̀ ti ń ṣiṣẹ́; ṣùgbọ́n ẹni tí ń dènà yóò máa ṣe bẹ́ẹ̀ títí a ó fi mú un kúrò ní ọ̀nà. 8 (F)Nígbà náà ni a ó fi ẹni ẹ̀ṣẹ̀ hàn, ẹni tí Jesu Olúwa yóò fi èémí ẹnu rẹ̀ pa, tí yóò sì fi ọlá ìpadàbọ̀ rẹ̀ parun. 9 (G)Wíwá ẹni ẹ̀ṣẹ̀ yóò rí bí iṣẹ́ Satani, gbogbo èyí tí a fihàn gẹ́gẹ́ bí àdàmọ̀dì iṣẹ́ ìyanu, àdàmọ̀dì ààmì àti àdàmọ̀dì idán, 10 Ní gbogbo ọ̀nà búburú tí a fi ń tan àwọn tí ń ṣègbé jẹ. Wọ́n ṣègbé nítorí wọ́n kọ̀ láti fẹ́ràn òtítọ́ kí wọn sì di ẹni ìgbàlà. 11 (H)Nítorí ìdí èyí, Ọlọ́run rán ohun tó ń ṣiṣẹ́ ìṣìnà sí wọn kí wọn lè gba èké gbọ́, 12 kí wọn kí ó lè gba ìdálẹ́bi, àní àwọn tí kò gba òtítọ́ gbọ́, ṣùgbọ́n tí wọ́n ní inú dídùn nínú ìwà búburú.
Judasi gbà láti da Jesu
22 (A)Àjọ ọdún àìwúkàrà tí à ń pè ní Ìrékọjá sì kù fẹ́ẹ́rẹ́. 2 Àti àwọn olórí àlùfáà, àti àwọn akọ̀wé ń wá ọ̀nà tí wọn ìbá gbà pa á; nítorí tí wọn ń bẹ̀rù àwọn ènìyàn. 3 Satani sì wọ inú Judasi, tí à ń pè ní Iskariotu, ọ̀kan nínú àwọn méjìlá. 4 Ó sì mú ọ̀nà rẹ̀ pọ̀n, ó lọ láti bá àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olórí ẹ̀ṣọ́ gbèrò pọ̀, bí òun yóò tí fi í lé wọn lọ́wọ́. 5 (B)Wọ́n sì yọ̀, wọ́n sì bá a dá májẹ̀mú láti fún un ní owó. 6 Ó sì gbà; ó sì ń wá àkókò tí ó wọ̀, láti fi í lé wọn lọ́wọ́ láìsí ariwo.
Oúnjẹ alẹ́ Olúwa
7 (C)(D) Ọjọ́ àìwúkàrà pé, nígbà tí wọ́n ní láti pa ọ̀dọ́-àgùntàn ìrékọjá fún ìrúbọ. 8 (E)Ó sì rán Peteru àti Johanu, wí pé, “Ẹ lọ pèsè ìrékọjá fún wa, kí àwa ó jẹ.”
9 Wọ́n sì wí fún un pé, “Níbo ni ìwọ ń fẹ́ kí á pèsè sílẹ̀?”
10 Ó sì wí fún wọn pé, “Kíyèsi i, nígbà tí ẹ̀yin bá ń wọ ìlú lọ, ọkùnrin kan tí ó ru ìkòkò omi yóò pàdé yín, ẹ bá a lọ sí ilé tí ó bá wọ̀, 11 kí ẹ sì wí fún baálé ilé náà pé, ‘Olùkọ́ wí fún ọ pé: Níbo ni gbàngàn àpèjẹ náà gbé wà, níbi tí èmi ó gbé jẹ ìrékọjá pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mi?’ 12 Òun ó sì fi gbàngàn ńlá kan lókè ilé hàn yín, tí a ṣe lọ́ṣọ̀ọ́: níbẹ̀ ni kí ẹ̀yin pèsè sílẹ̀.”
13 Wọ́n sì lọ wọ́n sì bá a gẹ́gẹ́ bí ó tí sọ fún wọn: wọ́n sì pèsè ìrékọjá sílẹ̀.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.