Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Book of Common Prayer

Daily Old and New Testament readings based on the Book of Common Prayer.
Duration: 861 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 16-17

Miktamu ti Dafidi.

16 Pa mí mọ́, Ọlọ́run,
    nítorí nínú rẹ ni ààbò mi wà.

Mo sọ fún Olúwa, “ìwọ ni Olúwa mi,
    lẹ́yìn rẹ èmi kò ní ìre kan.”
Sí àwọn ènìyàn tí ó wà ní ayé,
    àwọn ni ológo nínú èyí tí ayọ̀ mí wà.
Ìṣòro àwọn wọ̀n-ọn-nì yóò pọ̀ sí i, àní àwọn tí ń tọ ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn.
    Ẹbọ ohun mímu ẹ̀jẹ̀ wọn ni èmi kì yóò ta sílẹ̀,
    bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò dá orúkọ wọn lẹ́nu mi.

Olúwa, ni ìpín ìní mi tí mo yàn àti ago mi,
    ó ti pa ohun tí í ṣe tèmi mọ́.
Okùn ààlà ilẹ̀ ti bọ́ sí ọ̀dọ̀ mi ní ibi dídára;
    nítòótọ́ mo ti ní ogún rere.
Èmi yóò yin Olúwa, ẹni tí ó gbà mí ní ìyànjú;
    ní òru, ọkàn mí ń bá mi sọ̀rọ̀.
(A)Mo ti gbé Ọlọ́run síwájú mi ní ìgbà gbogbo.
    Nítorí tí ó wà ní ọwọ́ ọ̀tún mi, a kì yóò mì mí.

Nítorí èyí, ọkàn mi yọ̀, ahọ́n mi pẹ̀lú ń fò fáyọ̀;
    ara mi pẹ̀lú yóò sinmi ní ààbò,
10 (B)nítorí ìwọ kò ní fi ọ̀kan sílẹ̀ nínú isà òkú,
    tàbí kí ìwọ jẹ́ kí ẹni mímọ́ rẹ kí ó rí ìdíbàjẹ́.
11 Ìwọ ti fi ipa ọ̀nà ìyè hàn mí;
    Ìwọ yóò kún mi pẹ̀lú ayọ̀ ní iwájú rẹ,
    pẹ̀lú ìdùnnú ayérayé ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ.

Àdúrà ti Dafidi

17 Gbọ́, Olúwa, ẹ̀bẹ̀ òtítọ́ mi;
    fi etí sí igbe mi.
Tẹ́tí sí àdúrà mi
    tí kò ti ètè ẹ̀tàn jáde.
Kí ìdáláre mi wá láti ọ̀dọ̀ rẹ;
    kí ojú rẹ kí ó rí ohun tí ó tọ́.

Ìwọ ti dán àyà mi wò,
    ìwọ sì bẹ̀ mí wò ní òru, o sì ti wádìí mi,
ìwọ kì yóò rí ohunkóhun èmi ti pinnu pé,
    ẹnu mi kì yóò ṣẹ̀.
Bí ó ṣe ti iṣẹ́ ènìyàn nípa ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ,
    èmi ti pa ara mi mọ́
    kúrò ní ọ̀nà àwọn ìkà.
Ìrìn mí ti jẹ mọ́ ọ̀nà rẹ;
    ẹsẹ̀ mi kì yóò yọ̀.

Èmi ké pè ọ́, Ọlọ́run, nítorí tí ìwọ yóò dá mi lóhùn
    dẹ etí rẹ sí mi kí o sì gbọ́ àdúrà mi.
Fi ìṣeun ìyanu ìfẹ́ ńlá rẹ hàn
    ìwọ tí ó fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ gba àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé ọ là
    lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá tí ó dìde sí wọn.
Pa mí mọ́ bí ẹyin ojú rẹ;
    fi mí pamọ́ sí abẹ́ òjìji ìyẹ́ apá rẹ,
lọ́wọ́ àwọn ènìyàn búburú tí ń fóròó mi,
    kúrò ní ọwọ́ àwọn ọ̀tá apani tí ó yí mi ká.

10 Wọ́n pa ọkàn aláìláàánú wọn mọ́,
    wọ́n sì fi ẹnu wọn sọ̀rọ̀ ìgbéraga.
11 Wọ́n sì mú mi mọ́lẹ̀, wọ́n sì yí mi ká,
    pẹ̀lú ojú ìṣọ́ra láti ṣọ́ mi sílẹ̀.
12 Wọn dàbí i kìnnìún tí ebi ń pa fún ìjẹ,
    àní bí kìnnìún ńlá tí ó ń ba níbi ìkọ̀kọ̀.

13 Dìde, Olúwa, dojúkọ wọ́n, rẹ̀ wọ́n sílẹ̀;
    gbà mí sílẹ̀ lọ́wọ́ ẹni búburú nípa idà rẹ.
14 Olúwa, nípa ọwọ́ rẹ, gbà mí kúrò lọ́wọ́ irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀,
    kúrò lọ́wọ́ àwọn ènìyàn ayé yìí, tí èrè wọn wà nínú ayé yìí.
Ìwọ ń pa ebi àwọn tí ìwọ fẹ́ràn lẹ́nu mọ́;
    àwọn ọmọ wọn sì ní ọ̀pọ̀lọpọ̀,
    wọ́n sì kó ọrọ̀ jọ fún àwọn ọmọ wọn.

15 Ṣùgbọ́n ní tèmi, èmi yóò máa wo ojú rẹ ní òdodo;
    nígbà tí èmi bá jí, èmi yóò ní ìtẹ́lọ́rùn nígbà tí èmi bá rí àwòrán rẹ.

Saamu 22

Fún adarí orin. Tí ohùn orin “àgbọ̀nrín òwúrọ̀.” Saamu ti Dafidi.

22 (A)Ọlọ́run mi, Ọlọ́run mi, èéṣe tí ìwọ fi kọ̀ mí sílẹ̀?
    Èéṣe tí o fi jìnnà láti gbà mí là,
    àní sí igbe ìkérora mi?
Ọlọ́run mi, ní ọ̀sán gangan ni mo kígbe, ṣùgbọ́n ìwọ kò dá mi ní ohùn:
    àti ní òru èmi kò dákẹ́.

Ṣùgbọ́n síbẹ̀ ẹni mímọ́ ni ìwọ;
    ẹni tí ó tẹ ìyìn Israẹli dó;
Àwọn baba ńlá wa ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú rẹ;
    wọ́n ní ìgbẹ́kẹ̀lé, ìwọ sì gbà wọ́n.
Ìwọ ni wọ́n sun ẹkún sí, wọ́n sì ní ìgbàlà;
    ìwọ ni wọ́n gbẹ́kẹ̀lé, a kò sì dójútì wọ́n.

Ṣùgbọ́n kòkòrò ní mo jẹ́, kì í sì í ṣe ènìyàn;
    mo di ẹlẹ́gàn àwọn ènìyàn, ẹlẹ́yà àwọn ènìyàn
Gbogbo àwọn tí ó rí mí fi mí ṣe ẹlẹ́yà;
    wọ́n yọ ètè ẹ̀gàn wọn sí mi, wọ́n sì ń mi orí wọn pé.
“Ó gbẹ́kẹ̀ rẹ̀ lé Olúwa;
    jẹ́ kí Olúwa gbà á là.
Jẹ́ kí ó gbà á là,
    nítorí pé, ó ní ayọ̀ nínú rẹ̀.”

Síbẹ̀ ìwọ ni ó ti mú mi wá láti inú;
    ìwọ ni ó mú mi wà láìléwu, nígbà tí mo rọ̀ mọ́ ọmú ìyá mi.
10 Ìwọ ni a fi mí lé lọ́wọ́ láti inú ìyá mi wá,
    nígbà tí ìyá mí sì ti bí mi, ìwọ ni Ọlọ́run mi.

11 Má ṣe jìnnà sí mi,
    nítorí pé ìyọnu súnmọ́ tòsí
    kò sì ṣí ẹnìkan tí yóò ṣe ìrànlọ́wọ́.

12 Ọ̀pọ̀ akọ màlúù yí mi ká;
    àwọn màlúù alágbára Baṣani rọ̀gbà yí mi ká.
13 Wọ́n ya ẹnu wọn sì mi bí i kìnnìún tí ń dọdẹ kiri,
    tí ń ké ramúramù.
14 A dà mí jáde gẹ́gẹ́ bí omi,
    gbogbo egungun mi ti yẹ̀ kúrò ní oríkèé rẹ̀.
Ọkàn mi sì dàbí i ìda;
    tí ó yọ́ láàrín inú mi.
15 Agbára mí ti gbẹ bí àpáàdì,
    ahọ́n mí sì tilẹ̀ mọ́ párí ẹ̀rẹ̀kẹ́ ẹ mi;
    ìwọ ti tẹ́ mi sínú eruku ikú.

16 Àwọn ajá yí mi ká;
    ìjọ àwọn ènìyàn ibi ti ká mi mọ́,
    Wọ́n gún mi lọ́wọ́, wọ́n sì gún mi lẹ́sẹ̀
17 Mo lè ka gbogbo àwọn egungun mi;
    àwọn tìkára wọn ń wò, wọ́n dójú lé mi.
18 Wọ́n pín aṣọ mi láàrín ara wọn
    àní lórí aṣọ mi ni wọ́n ṣẹ́ gègé.

19 Ṣùgbọ́n ìwọ, Olúwa, má ṣe jìnnà sí mi;
    Háà! Olùrànlọ́wọ́ ọ̀ mi, yára wá fún àtìlẹ́yìn mi!
20 Gba ọkàn mi sílẹ̀ lọ́wọ́ idà,
    àní ẹ̀mí mi lọ́wọ́ agbára àwọn ajá.
21 Gba ọkàn mi sílẹ̀ lọ́wọ́ kìnnìún;
    Kí o sì gbà mí sílẹ̀ lọ́wọ́ ìwo àgbáǹréré.

22 Èmi yóò kéde orúkọ rẹ láàrín arákùnrin àti arábìnrin mi;
    nínú ìjọ ni èmi yóò máa yìn ọ́.
23 Ẹ̀yin tí ẹ bẹ̀rù Olúwa, ẹ yìn ín!
    Gbogbo ẹ̀yin ìran Jakọbu, ẹ fi ògo fún un!
    Ẹ dìde fún un tẹ̀rù tẹ̀rù, ẹ̀yin irú-ọmọ Israẹli!
24 Nítorí pé òun kò ṣátá, bẹ́ẹ̀ ni kò sì kórìíra
    ìpọ́njú àwọn tí a ni lára;
kò sì fi ojú rẹ̀ pamọ́ fún mi
    ṣùgbọ́n ó gbọ́ nígbà tí mo ké pè é.

25 Láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni ìyìn mi yóò ti wá nínú àjọ ńlá;
    ẹ̀jẹ́ rẹ̀ ni èmi yóò san níwájú àwọn tí o bẹ̀rù rẹ̀
26 tálákà yóò jẹ yóò sì yó;
    àwọn tí n wá Olúwa yóò yin
    jẹ́ kí ẹ̀mí rẹ̀ wà láààyè títí ayérayé!

27 Gbogbo òpin ayé ni yóò rántí
    wọn yóò sì yípadà sí Olúwa,
àti gbogbo ìdílé orílẹ̀-èdè
    ni wọn yóò jọ́sìn níwájú rẹ̀,
28 Nítorí ìjọba ni ti Olúwa.
    Òun ni ó ń pàṣẹ lórí àwọn orílẹ̀-èdè.

29 Bẹ́ẹ̀ náà ni gbogbo àwọn olówó ayé wọn yóò ṣe àsè, wọn yóò sì sìn;
    gbogbo àwọn tí ó wọ inú ilẹ̀ lọ yóò kúnlẹ̀ ní iwájú rẹ̀
    àti ẹni tí kò lè pa ọkàn ara rẹ̀ mọ́ ni ààyè.
30 Irú-ọmọ rẹ̀ yóò sìn ín;
    a ó sọ fún àwọn ìran tí ń bọ̀ nípa Olúwa,
31 Wọn yóò polongo òdodo rẹ̀
    sí àwọn ọmọ tí a kò tí ì bí,
    wí pé, òun ni ó ṣe èyí.

Isaiah 3:8-15

Jerusalẹmu ń ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n
    Juda ń ṣubú lọ,
ọ̀rọ̀ àti ìṣe wọn lòdì sí Olúwa,
    láti mú ojú ògo rẹ̀ bínú.
Ìwò ojú wọn ń jẹ́rìí lòdì sí wọn,
    wọ́n ń polongo ẹ̀ṣẹ̀ wọn bí i Sodomu;
wọn ò fi pamọ́!
    Ègbé ni fún wọn!
    Wọ́n ti mú ìparun wá sórí ara wọn.

10 Ẹ sọ fún olódodo pé yóò dára fún wọn,
    nítorí ní àjẹgbádùn ni wọn yóò jẹ èso iṣẹ́ ẹ wọn.
11 Ègbé ni fún ènìyàn búburú! Ìparun wà lórí i wọn
    A ó sì san èrè iṣẹ́ tí ọwọ́ wọn ti ṣe fún wọn.

12 Àwọn ọ̀dọ́mọdé ni o ń pọ́n àwọn ènìyàn mi lójú
    àwọn obìnrin ń jẹ ọba lé wọn lórí.
Háà! Ènìyàn mi àwọn afinimọ̀nà yín ti ṣì yín lọ́nà,
    wọn sì mú yín kúrò ní ipa ọ̀nà yín.

13 Olúwa bọ sí ipò rẹ̀ ní ìtẹ́ ìdájọ́
    Ó dìde láti dá àwọn ènìyàn lẹ́jọ́.
14 Olúwa dojú ẹjọ́ kọ
    àwọn àgbàgbà àti àwọn olórí àwọn ènìyàn rẹ̀.
“Ẹ̀yin ni ẹ ti run ọgbà àjàrà mi,
    ogún àwọn tálákà ń bẹ̀ nínú ilé yín.
15 Kín ni èrò yín láti máa run àwọn ènìyàn mi túútúú
    tí ẹ sì fojú àwọn tálákà ni gbolẹ̀?”
    ni Olúwa wí, Olúwa àwọn ọmọ-ogun.

1 Tẹsalonika 4:1-12

Gbígbé ìgbé ayé tó wu Ọlọ́run

Ní ìparí, ará, a sọ fún un yín bí ẹ ti ń gbé láti wu Ọlọ́run, àní gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin tí ń ṣe. Nísinsin yìí, a béèrè, a sì ń rọ̀ yín nínú Jesu Olúwa láti ṣe bẹ́ẹ̀ àti bẹ́ẹ̀ sí. Nítorí pé, ẹ̀yin mọ àṣẹ tí a pa fún yín láti ọ̀dọ̀ Olúwa Jesu.

(A)Nítorí ìfẹ́ Ọlọ́run ni pé kí ẹ jẹ́ mímọ́, kí ẹ sì yàgò kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ àgbèrè, (B)kí ẹnìkọ̀ọ̀kan yín kọ́ láti ṣàkóso ara rẹ̀ ní ọ̀nà mímọ́ àti pẹ̀lú ọlá, kì í ṣe ní ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ gẹ́gẹ́ bí àwọn aláìkọlà, ẹni tí kò mọ Ọlọ́run; àti pé nínú ọ̀rọ̀ yìí, kí ẹnikẹ́ni nínú yín máa ṣe rẹ arákùnrin rẹ̀ jẹ nípa ohunkóhun. Olúwa yóò jẹ àwọn ènìyàn ní yà fún gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wọn, gẹ́gẹ́ bí a ti ń sọ fún un yín tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀. Nítorí Ọlọ́run kò pè wá sínú ìwà èérí, bí kò ṣe sínú ìgbé ayé mímọ́. Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó kọ òfin yìí, kì í ṣe òfin ènìyàn ni ẹni náà kọ̀, bí kò ṣe òfin Ọlọ́run ẹni tí ó fi Ẹ̀mí Mímọ́ rẹ̀ fún ni.

Ṣùgbọ́n nípa ìfẹ́ ará, a kò ní láti tún kọ̀wé sí i yín, ìdí ni pé, Ọlọ́run pàápàá ń kọ́ yín láti fẹ́ràn ara yín. 10 Nítòótọ́, ẹ ní ìfẹ́ fún àwọn arákùnrin tí ó wà káàkiri Makedonia. Síbẹ̀síbẹ̀ àwa ń bẹ̀ yín, ará, pé kí ẹ̀yin kí ó máa tẹ̀síwájú nínú rẹ̀. 11 (C)Ẹ jẹ́ kí èyí jẹ́ ìfẹ́ ọkàn yín láti gbé jẹ́ẹ́ àti láti mọ ti ara yín àti kí olúkúlùkù kọjú sí iṣẹ́ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí a ti wí fún yín. 12 Èyí yóò mú kí àwọn tí kì í ṣe onígbàgbọ́ gbẹ́kẹ̀lé yín àti láti bu ọlá fún yín pẹ̀lú. Bí ẹ bá ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ kò ní máa wo ojú ẹnikẹ́ni láti fún yín ni owó tí ẹ ó fi san gbèsè.

Luku 20:41-21:4

Ọmọ ta ni Jesu n ṣe

41 (A)Ó sì wí fún wọn pé, “Èéṣe tí wọ́n fi ń wí pé, Ọmọ Dafidi ni Kristi? 42 Dafidi tìkára rẹ̀ sì wí nínú ìwé Saamu pé:

“ ‘Olúwa sọ fún Olúwa mi pé:
    “Ìwọ jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi
43 títí èmi ó fi sọ àwọn ọ̀tá rẹ
    di àpótí ìtìsẹ̀ rẹ.” ’

44 Ǹjẹ́ bí Dafidi bá pè é ní ‘Olúwa.’ Òun ha sì ti ṣe jẹ́ ọmọ rẹ̀?”

45 (B)Ó sì wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ní etí gbogbo ènìyàn pé, 46 “Ẹ máa kíyèsára lọ́dọ̀ àwọn akọ̀wé, tí wọ́n fẹ́ láti máa rìn nínú aṣọ gígùn, tí wọ́n sì fẹ́ ìkíni ní ọjà, àti ibùjókòó ọlá nínú Sinagọgu, àti ipò ọlá ní ibi àsè; 47 Àwọn tí ó jẹ ilé àwọn opó run, tí wọ́n sì ń gbàdúrà gígùn fún àṣehàn: àwọn wọ̀nyí náà ni yóò jẹ̀bi pọ̀jù.”

Oore opó

21 (C)Nígbà tí ó sì gbé ojú sókè, ó rí àwọn ọlọ́rọ̀ ń fi ẹ̀bùn wọn sínú àpótí ìṣúra. Ó sì rí tálákà opó kan pẹ̀lú, ó ń sọ owó idẹ wẹ́wẹ́ méjì síbẹ̀. Ó sì wí pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, tálákà opó yìí fi sí i ju gbogbo wọn lọ: Nítorí gbogbo àwọn wọ̀nyí fi sínú ẹ̀bùn Ọlọ́run láti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìní wọn; ṣùgbọ́n òun nínú àìní rẹ̀ ó sọ gbogbo ohun ìní rẹ̀ tí ó ní sínú rẹ̀.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.