Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Book of Common Prayer

Daily Old and New Testament readings based on the Book of Common Prayer.
Duration: 861 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 31

Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi.

31 Nínú rẹ̀, Olúwa ni mo ti rí ààbò;
    Má ṣe jẹ́ kí ojú kí ó tì mí;
    gbà mí nínú òdodo rẹ.
Tẹ́ etí rẹ sí mi,
    gbà mí kíákíá;
jẹ́ àpáta ààbò mi,
    jẹ́ odi alágbára láti gbà mí.
Ìwọ pàápàá ni àpáta àti ààbò mi,
    nítorí orúkọ rẹ, máa ṣe olùtọ́ mi, kí o sì ṣe amọ̀nà mi.
Yọ mí jáde kúrò nínú àwọ̀n tí wọ́n dẹ pamọ́ fún mi,
    nítorí ìwọ ni ìsádi mi.
Ní ọwọ́ rẹ ni mo fi ẹ̀mí mi lé;
    ìwọ ni o ti rà mí padà, Olúwa, Ọlọ́run òtítọ́.

Èmi ti kórìíra àwọn ẹni tí ń fiyèsí òrìṣà tí kò níye lórí;
    ṣùgbọ́n èmi gbẹ́kẹ̀lé Olúwa.
Èmi yóò yọ̀, inú mi yóò dùn nínú ìfẹ́ ńlá rẹ,
    nítorí ìwọ ti rí ìbìnújẹ́ mi
    ìwọ ti mọ̀ ọkàn mi nínú ìpọ́njú.
Pẹ̀lú, ìwọ kò sì fà mi lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́
    ìwọ ti fi ẹsẹ̀ mi lé ibi ààyè ńlá.

Ṣàánú fún mi, ìwọ Olúwa, nítorí mo wà nínú ìpọ́njú;
    ojú mi fi ìbìnújẹ́ sùn,
    ọkàn àti ara mi pẹ̀lú.
10 Èmi fi ìbànújẹ́ lo ọjọ́ mi
    àti àwọn ọdún mi pẹ̀lú ìmí ẹ̀dùn;
agbára mi ti kùnà nítorí òsì mi,
    egungun mi sì ti rún dànù.
11 Èmi di ẹni ẹ̀gàn láàrín àwọn ọ̀tá mi gbogbo,
    pẹ̀lúpẹ̀lú láàrín àwọn aládùúgbò mi,
mo sì di ẹ̀rù fún àwọn ojúlùmọ̀ mi;
    àwọn tí ó rí mi ní òde ń yẹra fún mi.
12 Èmi ti di ẹni ìgbàgbé kúrò ní ọkàn gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó ti kú;
    Èmi sì dàbí ohun èlò tí ó ti fọ́.
13 (A)Nítorí mo gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpayà tí ó yí mi ká;
    tí wọn gbìmọ̀ pọ̀ sí mi,
wọ́n sì ṣọ̀tẹ̀ sí mi
    láti gba ẹ̀mí mi.

14 Ṣùgbọ́n èmí gbẹ́kẹ̀lé ọ, ìwọ Olúwa
    Mo sọ wí pé, “Ìwọ ní Ọlọ́run mi.”
15 Ìgbà mi ń bẹ ní ọwọ́ rẹ;
    gbà mí kúrò ní ọwọ́ àwọn ọ̀tá mi
    àti àwọn onínúnibíni.
16 Jẹ́ kí ojú rẹ kí ó tan ìmọ́lẹ̀ sí ìránṣẹ́ rẹ lára;
    Gbà mí nínú ìfẹ́ rẹ tí ó dúró ṣinṣin.
17 Má ṣe jẹ́ kí ojú ki ó tì mí, Olúwa;
    nítorí pé mo ké pè ọ́;
jẹ́ kí ojú kí ó ti ènìyàn búburú;
    jẹ́ kí wọ́n lọ pẹ̀lú ìdààmú sí isà òkú.
18 Jẹ́ kí àwọn ètè irọ́ kí ó dákẹ́ jẹ́ẹ́,
    pẹ̀lú ìgbéraga àti ìkẹ́gàn,
    wọ́n sọ̀rọ̀ àfojúdi sí olódodo.

19 Báwo ni títóbi oore rẹ̀ ti pọ̀ tó,
    èyí tí ìwọ ti ní ní ìpamọ́ fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ,
èyí tí ìwọ rọ̀jò rẹ̀ níwájú àwọn ènìyàn
    tí wọ́n fi ọ́ ṣe ibi ìsádi wọn.
20 Ní abẹ́ ìbòòji iwájú rẹ ni ìwọ pa wọ́n mọ́ sí
    kúrò nínú ìdìmọ̀lù àwọn ènìyàn;
ní ibùgbé rẹ, o mú wọn kúrò nínú ewu
    kúrò nínú ìjà ahọ́n.

21 Olùbùkún ni Olúwa,
    nítorí pé ó ti fi àgbà ìyanu ìfẹ́ tí ó ní sí mi hàn,
    nígbà tí mo wà ní ìlú tí wọ́n rọ̀gbà yíká.
22 Èmí ti sọ nínú ìdágìrì mi,
    “A gé mi kúrò ní ojú rẹ!”
Síbẹ̀ ìwọ ti gbọ́ ẹ̀bẹ̀ mi fún àánú
    nígbà tí mo ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́.

23 Ẹ fẹ́ Olúwa, gbogbo ẹ̀yin ènìyàn rẹ̀ mímọ́!
    Olúwa pa olódodo mọ́,
    ó sì san án padà fún agbéraga ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.
24 Jẹ́ alágbára, yóò sì mú yín ní àyà le
    gbogbo ẹ̀yin tí ó dúró de Olúwa.

Saamu 35

Ti Dafidi.

35 Olúwa, gbógun ti àwọn tí ń gbóguntì mí;
    kí o sì kọ ojú ìjà sí àwọn tí ó ń bá mi í jà!
Di asà àti àpáta mú,
    kí o sì dìde fún ìrànlọ́wọ́ mi!
Fa idà àti ọ̀kọ̀ yọ
    kí o sì dojúkọ àwọn tí ń lé mi.
Sọ fún ọkàn mi pé,
    “Èmi ni ìgbàlà rẹ.”

Kí wọn kí ó dààmú,
    kí a sì ti àwọn tí ń lépa ọkàn mi lójú;
kí a sì mú wọn padà,
    kí a sì dààmú àwọn tí ń gbèrò ìpalára mi.
Jẹ́ kí wọn dàbí ìyàngbò níwájú afẹ́fẹ́,
    kí angẹli Olúwa kí ó máa lé wọn kiri.
Jẹ́ kí ọ̀nà wọn kí ó ṣókùnkùn, kí ó sì máa yọ́,
    kí angẹli Olúwa kí ó máa lépa wọn!

Nítorí pé, ní àìnídìí ni wọ́n dẹ àwọ̀n wọn sílẹ̀ fún mi,
    ní àìnídìí ni wọ́n wa kòtò sílẹ̀ fún ọkàn mi.
Kí ìparun kí ó wá sí orí rẹ̀ ní òjijì.
    Àwọ̀n rẹ̀ tí ó dẹ, kí ó mú òun tìkára rẹ̀;
    kí wọn ṣubú sínú kòtò sí ìparun ara rẹ̀.
Nígbà náà ni ọkàn mi yóò yọ̀ nínú Olúwa,
    àní, yóò sì máa yọ̀ nínú ìgbàlà rẹ̀.
10 Gbogbo egungun mi yóò wí pé,
    “Ta ni ó dàbí ì ìwọ Olúwa?
O gba tálákà lọ́wọ́ àwọn tí ó lágbára jù ú lọ,
    tálákà àti aláìní lọ́wọ́ ẹni tí ń fi ṣe ìkógun?”

11 Àwọn ẹlẹ́rìí èké dìde;
    wọ́n ń bi mi ní ohun tí èmi kò mọ̀.
12 Wọ́n fi búburú san ìre fún mi;
    láti sọ ọkàn mi di òfo.
13 Ṣùgbọ́n bí ó ṣe ti èmi ni, nígbà tí wọn ń ṣe àìsàn, mo wọ aṣọ ọ̀fọ̀;
    mo fi àwẹ̀ pọ́n ara mi lójú.
Mo gba àdúrà pẹ̀lú ìtẹríba ní oókan àyà mi;
14     èmí ń lọ kiri bí ẹni ń ṣọ̀fọ̀
    bí i ẹni wí pé fún ọ̀rẹ́ tàbí ẹ̀gbọ́n mi ni.
Èmí tẹríba nínú ìbànújẹ́
    bí ẹni tí ń ṣọ̀fọ̀ ìyà rẹ̀.
15 Ṣùgbọ́n nínú ìkọ̀sẹ̀ mi wọ́n sì yọ̀, wọ́n sì kó ara wọn jọ;
    wọ́n kó ara wọn jọ sí mi; àní àwọn tí èmi kò mọ̀.
    Wọ́n fà mí ya wọ́n kò sì dákẹ́.
16 Bí àwọn àgàbàgebè tí ń ṣe ẹlẹ́yà ní àpèjẹ
    wọ́n pa eyín wọn keke sí mi.

17 Yóò ti pẹ́ tó Olúwa, tí ìwọ yóò máa wò wọ́n lọ?
    Yọ mí kúrò nínú ìparun wọn,
    àní ẹ̀mí ì mi kúrò lọ́wọ́ kìnnìún.
18 Nígbà náà ni èmi yóò ṣọpẹ́ fún Ọ nínú àjọ ńlá;
    èmi yóò máa yìn Ọ́ ní àwùjọ ọ̀pọ̀ ènìyàn.
19 (A)Má ṣe jẹ́ kí àwọn ọ̀tá mi
    kí ó yọ̀ lórí ì mi;
bẹ́ẹ̀ ni kí o má ṣe àwọn tí ó kórìíra mi
    ní àìnídìí máa ṣẹ́jú sí mi.
20 Nítorí pé wọn kò sọ ọ̀rọ̀ àlàáfíà,
    ṣùgbọ́n wọ́n lóyún ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn
    sí àwọn ènìyàn dídákẹ́ ilẹ̀ náà.
21 Wọ́n ya ẹnu wọn gbòòrò sí mi; wọ́n wí pé, “Háà! Háà!
    Ojú wa sì ti rí i.”

22 Ìwọ́ ti rí i Olúwa; má ṣe dákẹ́!
    Olúwa má ṣe jìnnà sí mi!
23 Dìde! ru ara rẹ̀ sókè fún ààbò mi,
    àti sí ọ̀ràn mi, Ọlọ́run mi àti Olúwa mi!
24 Ṣe ìdájọ́ mi, Olúwa Ọlọ́run mi, gẹ́gẹ́ bí òdodo rẹ,
    kí o má sì ṣe jẹ́ kí wọn kí ó yọ̀ lórí mi!
25 Má ṣe jẹ́ kí wọn wí nínú ara wọn pé, “Háà! A ti rí ohun tí ọkàn wa ń fẹ́!”
    Má ṣe jẹ́ kí wọn kí ó wí pé, “A ti gbé e mì.”

26 Kí ojú kí ó tì wọ́n,
    kí wọn kí ó sì dààmú pọ̀,
àní àwọn tí ń yọ̀ sí ìyọnu mi
    kí a fi ìtìjú àti àbùkù wọ̀ wọ́n ní aṣọ tí ń gbéraga sí mi.
27 Jẹ́ kí àwọn tí ó fẹ́ ìdáláre mi
    fò fún ayọ̀ àti ìdùnnú;
kí wọn máa sọ ọ́ títí lọ, “Pé gbígbéga ni Olúwa,
    sí àlàáfíà ìránṣẹ́ rẹ̀.”

28 Nígbà náà ni ahọ́n mi yóò máa sọ̀rọ̀ òdodo rẹ,
    àti ìyìn rẹ ní gbogbo ọjọ́.

Isaiah 7:10-25

10 Bákan náà Olúwa tún bá Ahasi sọ̀rọ̀, 11 “Béèrè fún ààmì lọ́wọ́ Olúwa Ọlọ́run rẹ, bóyá ní ọ̀gbun tí ó jì jùlọ tàbí àwọn òkè tí ó ga jùlọ.”

12 Ṣùgbọ́n Ahasi sọ pé, “Èmi kì yóò béèrè; Èmi kò ní dán Olúwa wò.”

13 Lẹ́yìn náà Isaiah sọ pé, “Gbọ́ ní ìsinsin yìí, ìwọ ilé Dafidi, kò ha tọ́ láti tán ènìyàn ní sùúrù, ìwọ yóò ha tan Ọlọ́run ní sùúrù bí? 14 (A)Nítorí náà, Olúwa fúnra ara rẹ̀ ni yóò fún ọ ní ààmì kan. Wúńdíá kan yóò lóyún, yóò sì bí ọmọkùnrin kan, yóò sì pe orúkọ rẹ̀ ní Emmanueli. 15 Òun yóò jẹ wàrà àti oyin nígbà tí ó bá ní ìmọ̀ tó láti kọ ẹ̀bi àti láti yan rere. 16 Ṣùgbọ́n kí ọ̀dọ́mọkùnrin náà tó mọ bí a ti ń kọ ẹ̀bi àti láti yan rere, ilẹ̀ àwọn ọba méjèèjì tí ń bà ọ́ lẹ́rù wọ̀nyí yóò ti di ahoro. 17 Olúwa yóò mú àsìkò mìíràn wá fún ọ àti àwọn ènìyàn rẹ àti lórí ilé baba rẹ irú èyí tí kò sí láti ìgbà tí Efraimu ti yà kúrò ní Juda, yóò sì mú ọba Asiria wá.”

18 Ní ọjọ́ náà ni Olúwa yóò súfèé pe àwọn eṣinṣin láti àwọn odò tó jìnnà ní Ejibiti wá, àti fún àwọn oyin láti ilẹ̀ Asiria. 19 Gbogbo wọn yóò sì wá dó sí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè àti pàlàpálá òkúta, lára koríko ẹ̀gún àti gbogbo ibi ihò omi. 20 Ní ọjọ́ náà, Olúwa yóò lo abẹ fífẹ́lẹ́ tí a yá láti ìkọjá odò Eufurate, ọba Asiria, láti fá irun orí àti ti àwọn ẹsẹ̀ ẹ yín, àti láti mú irùngbọ̀n yín kúrò pẹ̀lú. 21 Ní ọjọ́ náà, ọkùnrin kan yóò máa sin ọ̀dọ́ abo màlúù kan àti ewúrẹ́ méjì. 22 Àti nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ wàrà tí wọn yóò máa fún un, yóò ní wàràǹkàṣì láti jẹ. Gbogbo àwọn tí ó bá kù ní ilẹ̀ náà yóò jẹ wàràǹkàṣì àti oyin. 23 Ní ọjọ́ náà, ni gbogbo ibi tí àjàrà tí ó tó ẹgbẹ̀rún ṣékélì fàdákà, ẹ̀gún àti ẹ̀wọ̀n nìkan ni yóò wà níbẹ̀. 24 Àwọn ènìyàn yóò máa lọ síbẹ̀ pẹ̀lú ọrun àti ọfà nítorí pé ẹ̀gún àti ẹ̀wọ̀n ni yóò bo gbogbo ilẹ̀ náà. 25 Àti ní orí àwọn òkè kéékèèkéé tí a ti ń fi ọkọ́ ro nígbà kan rí, ẹ kò ní lọ síbẹ̀ mọ́ nítorí ìbẹ̀rù ẹ̀gún àti ẹ̀wọ̀n, wọn yóò di ibi tí a ń da màlúù lọ, àti ibi ìtẹ̀mọ́lẹ̀ fún àwọn àgùntàn kéékèèkéé.

2 Tẹsalonika 2:13-3:5

Ẹ dúró ṣinṣin

13 (A)Ṣùgbọ́n, ohun tí ó tọ́ fún wa ni láti máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run nígbà gbogbo nítorí yín, ará olùfẹ́ ní ti Olúwa, nítorí láti ìbẹ̀rẹ̀ ni Ọlọ́run ti yàn yín sí ìgbàlà nípa ìsọdimímọ́ ti Ẹ̀mí àti nípa gbígba òtítọ́ gbọ́. 14 Òun ti pè yín sí èyí nípa ìhìnrere wa, kí ẹ̀yin kí ó lè pín nínú ògo Jesu Kristi Olúwa wa.

15 (B)Nítorí náà ará, ẹ dúró ṣinṣin, kí ẹ sì di àwọn ẹ̀kọ́ wọ̀n-ọn-nì tí a kọ́ yín mú, yálà nípa ọ̀rọ̀ ẹnu tàbí lẹ́tà.

16 (C)Ǹjẹ́ kí Jesu Kristi Olúwa wa tìkálára rẹ̀, àti Ọlọ́run baba wa, ẹni to ti fẹ́ wa, tí ó sì ti fi ìtùnú àìnípẹ̀kun àti ìrètí rere nípa oore-ọ̀fẹ́ fún wa. 17 Kí ó mú ọkàn yín le, kí ó sì kún yín pẹ̀lú agbára nínú iṣẹ́ gbogbo àti ọ̀rọ̀ rere gbogbo.

Ẹ̀bẹ̀ àdúrà

(D)Ní àkótán, ará, ẹ máa gbàdúrà fún wa, kí ọ̀rọ̀ Olúwa lè máa tàn káàkiri, kí ó sì jẹ́ èyí tí a bu ọlá fún, gẹ́gẹ́ bí ó ti rí ní ọ̀dọ̀ yín. (E)Kí ẹ sì máa gbàdúrà fún wa kí a lè bọ́ lọ́wọ́ àwọn ìkà àti àwọn ènìyàn búburú, nítorí pé kì í ṣe gbogbo ènìyàn ló ní ìgbàgbọ́. (F)Ṣùgbọ́n olódodo ni Olúwa, ẹni tí yóò fi ẹsẹ̀ yín múlẹ̀, tí yóò sì pa yín mọ́ kúrò nínú ibi. Àwa sì ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa ní ti ohun tí ẹ ń ṣe, àti pé àwọn nǹkan wọ̀n-ọn-nì tí a pàṣẹ fún un yín ni ẹ̀yin ń ṣe. Kí Olúwa máa tọ́ ọkàn yín ṣọ́nà sí ìfẹ́ Ọlọ́run àti sínú sùúrù Kristi.

Luku 22:14-30

14 (A)Nígbà tí àkókò sì tó, ó jókòó àti àwọn aposteli pẹ̀lú rẹ̀. 15 (B)Ó sì wí fún wọn pé, “Tinútinú ni èmi fẹ́ fi bá yín jẹ ìrékọjá yìí, kí èmi tó jìyà: 16 (C)Nítorí mo wí fún yín, Èmi kì yóò jẹ nínú rẹ̀ mọ́, títí a ó fi mú un ṣẹ ní ìjọba Ọlọ́run.”

17 (D)Ó sì gba ago, nígbà tí ó sì ti dúpẹ́, ó wí pé, “Gba èyí, kí ẹ sì pín in láàrín ara yín. 18 (E)Nítorí mo wí fún yín, Èmi kì yóò mu nínú èso àjàrà mọ́, títí ìjọba Ọlọ́run yóò fi dé.”

19 (F)Ó sì mú àkàrà, nígbà tí ó sì ti dúpẹ́ ó bù ú, ó sì fi fún wọn, ó wí pé, “Èyí ni ara mí tí a fi fún yín: ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.”

20 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ lẹ́yìn oúnjẹ alẹ́, ó sì mú ago wáìnì, ó wí pé, “Ago yìí ni májẹ̀mú tuntun nínú ẹ̀jẹ̀ mi, tí a ta sílẹ̀ fún yín. 21 (G)Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsi i, ọwọ́ ẹni tí yóò fi mí hàn wà pẹ̀lú mi lórí tábìlì. 22 Ọmọ Ènìyàn ń lọ nítòótọ́ bí a tí pinnu rẹ̀: ṣùgbọ́n ègbé ni fún ọkùnrin náà nípasẹ̀ ẹni tí a gbé ti fi í hàn.” 23 Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí béèrè láàrín ara wọn, ta ni nínú wọn tí yóò ṣe nǹkan yìí.

24 (H)Ìjà kan sì ń bẹ láàrín wọn, ní ti ẹni tí a kà sí olórí nínú wọn. 25 (I)Ó sì wí fún wọn pé, “Àwọn ọba aláìkọlà a máa fẹlá lórí wọn: a sì máa pe àwọn aláṣẹ wọn ní olóore. 26 (J)Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kì yóò rí bẹ́ẹ̀; ṣùgbọ́n ẹni tí ó ba pọ̀jù nínú yín kí ó jẹ́ bí ẹni tí o kéré ju àbúrò; ẹni tí ó sì ṣe olórí, bí ẹni tí ń ṣe ìránṣẹ́. 27 Nítorí ta ni ó pọ̀jù, ẹni tí ó jókòó tí oúnjẹ, tàbí ẹni tí ó ń ṣe ìránṣẹ́. Ẹni tí ó jókòó ti oúnjẹ kọ́ bí? Ṣùgbọ́n èmi ń bẹ láàrín yín bí ẹni tí ń ṣe ìránṣẹ́. 28 (K)(L)Ẹ̀yin ni àwọn tí ó ti dúró tì mí nínú ìdánwò mi. 29 (M)Mo sì yan ìjọba fún yín, gẹ́gẹ́ bí Baba mi ti yàn fún mi: 30 (N)Kí ẹ̀yin lè máa jẹ, kí ẹ̀yin sì lè máa mu lórí tábìlì mi ní ìjọba mi, kí ẹ̀yin lè jókòó lórí ìtẹ́, àti kí ẹ̀yin lè máa ṣe ìdájọ́ fún àwọn ẹ̀yà Israẹli méjìlá.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.