Book of Common Prayer
Ti Solomoni
72 Fi ìdájọ́ fún àwọn ọba, Ọlọ́run,
ọmọ-aládé ni ìwọ fi òdodo rẹ fún
2 Yóò ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀ pẹ̀lú òdodo,
yóò sì máa fi ẹ̀tọ́ ṣe ìdájọ́ àwọn tálákà rẹ̀.
3 Àwọn òkè ńlá yóò máa mú àlàáfíà fún àwọn ènìyàn
àti òkè kéékèèkéé nípa òdodo
4 Yóò dáàbò bo àwọn tí a pọ́n lójú láàrín àwọn ènìyàn
yóò gba àwọn ọmọ aláìní;
yóò sì fa àwọn aninilára ya.
5 Àwọn òtòṣì àti aláìní
yóò máa fi ọ̀wọ̀ ńlá fún ọ nígbà gbogbo,
níwọ̀n ìgbà tí oòrùn àti òṣùpá bá ń ràn,
yóò ti pẹ́ tó, láti ìrandíran.
6 Yóò dàbí òjò tí ó ń rọ̀ sórí pápá ìrẹ́mọ́lẹ̀
Bí ọwọ́ òjò tó ń rin ilẹ̀
7 Àwọn olódodo yóò gbilẹ̀ ni ọjọ́ rẹ̀
ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà yóò sì wà;
títí tí òṣùpá kò fi ní sí mọ́.
8 Yóò máa jẹ ọba láti Òkun dé Òkun
àti láti odò Eufurate títí dé òpin ayé.
9 Àwọn tí ó wà ní aginjù yóò tẹríba fún un
àwọn ọ̀tá rẹ̀ yóò máa lá erùpẹ̀ ilẹ̀.
10 Àwọn ọba Tarṣiṣi àti ti erékùṣù
wọn yóò mú ọrẹ wá fún un;
àwọn ọba Ṣeba àti Seba
wọn ó mú ẹ̀bùn wá fún un.
11 Gbogbo ọba yóò tẹríba fún un
àti gbogbo orílẹ̀-èdè yóò sìn ín.
12 Nítorí yóò gba àwọn aláìní
nígbà tí ó bá ń ké,
tálákà àti ẹni tí kò ní olùrànlọ́wọ́.
13 Yóò káàánú àwọn aláìlera àti aláìní
yóò pa aláìní mọ́ kúrò nínú ikú.
14 Yóò ra ọkàn wọn padà lọ́wọ́ ẹ̀tàn àti ipá
nítorí ẹ̀jẹ̀ wọn ṣọ̀wọ́n níwájú rẹ̀.
15 Yóò sì pẹ́ ní ayé!
A ó sì fún un ní wúrà Ṣeba.
Àwọn ènìyàn yóò sì máa gbàdúrà fún un nígbà gbogbo
kí a sì bùkún fún un lójoojúmọ́.
16 Kí ìkúnwọ́ ọkà wà lórí ilẹ̀;
ní orí òkè ni kí ó máa dàgbà
kí èso rẹ̀ kí o gbilẹ̀ bí ti Lebanoni
yóò máa gbá yìn bí i koríko ilẹ̀.
17 Kí orúkọ rẹ̀ kí ó wà títí láé;
orúkọ rẹ̀ yóò máa gbilẹ̀ níwọ̀n bí oòrùn yóò ti pẹ́ tó.
Wọn ó sì máa bùkún fún ara wọn nípasẹ̀ rẹ.
Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ní yóò máa pè mí ní alábùkún fún.
18 Olùbùkún ni Olúwa Ọlọ́run, Ọlọ́run Israẹli,
ẹnìkan ṣoṣo tí ó ń ṣe ohun ìyanu.
19 Olùbùkún ni orúkọ rẹ̀ tí ó lógo títí láé;
kí gbogbo ayé kún fún ògo rẹ̀.
Àmín àti Àmín.
20 Èyí ni ìparí àdúrà Dafidi ọmọ Jese.
Ẹlẹgbẹ́ mi ni àwọn tó mọ òfin Olúwa
73 Ọwọ́ rẹ ni ó dá mi tí ó sì mọ mí;
fún mi ní òye láti kọ́ àṣẹ rẹ.
74 Jẹ́ kí gbogbo àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ máa yọ̀ nígbà tí wọ́n bá rí mi,
nítorí èmi ti mú ìrètí mi sínú ọ̀rọ̀ rẹ.
75 Èmi mọ, Olúwa, nítorí òfin rẹ òdodo ni,
àti ní òtítọ́ ni ìwọ pọ́n mi lójú.
76 Kí ìfẹ́ rẹ tí kì í kùnà jẹ́ ìtùnú mi,
gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ sí ìránṣẹ́ rẹ.
77 Jẹ́ kí àánú rẹ kí ó tọ̀ mí wá, kí èmi kí ó lè yè,
nítorí òfin rẹ jẹ́ ìdùnnú mi.
78 Kí ojú kí ó ti àwọn agbéraga
nítorí wọn pa mí lára láìnídìí
ṣùgbọ́n èmi yóò máa ṣe àṣàrò nínú ẹ̀kọ́ rẹ.
79 Kí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ yí padà sí mi,
àwọn tí ó ní òye òfin rẹ.
80 Jẹ́ kí ọkàn mi wà láìlẹ́bi sí òfin rẹ,
kí ojú kí ó má ṣe tì mí.
Wíwá àlàáfíà
81 Ọkàn mi ń fojú ṣọ́nà nítorí ìgbàlà rẹ,
ṣùgbọ́n èmi ti fi ìrètí mi sínú ọ̀rọ̀ rẹ.
82 Ojú mi kùnà, pẹ̀lú wíwo ìpinnu rẹ;
èmi wí pé, “Nígbà wo ni ìwọ yóò tù mí nínú?”
83 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi dàbí awọ-wáìnì lójú èéfín,
èmi kò gbàgbé ìlànà rẹ.
84 Báwo ni ìránṣẹ́ rẹ̀ yóò ṣe dúró pẹ́ tó?
Nígbà wo ni ìwọ yóò bá àwọn
tí ń ṣe inúnibíni sí mi wí?
85 Àwọn agbéraga wa ihò ìṣubú fún mi,
tí ó lòdì sí òfin rẹ.
86 Gbogbo àṣẹ rẹ yẹ ní ìgbẹ́kẹ̀lé:
ràn mí lọ́wọ́, nítorí ènìyàn
ń ṣe inúnibíni sí mi láìnídìí.
87 Wọ́n fẹ́rẹ pa mí rẹ́ kúrò nínú ayé,
ṣùgbọ́n èmi kò kọ ẹ̀kọ́ rẹ.
88 Pa ayé mi mọ́ gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ,
èmi yóò sì gba ẹ̀rí ẹnu rẹ̀ gbọ́.
Ọ̀rọ̀ Olúwa dúró títí láé
89 Ọ̀rọ̀ rẹ, Olúwa, títí láé ni;
ó dúró ṣinṣin ní ọ̀run
90 Òtítọ́ rẹ̀ ń lọ dé gbogbo ìran dé ìran;
ìwọ ti dá ayé, ó sì dúró ṣinṣin.
91 Òfin rẹ dúró di òní
nítorí ohun gbogbo ń sìn ọ́.
92 Bí òfin rẹ̀ kò bá jẹ́ dídùn inú mi,
èmi ìbá ti ṣègbé nínú ìpọ́njú mi.
93 Èmi kì yóò gbàgbé ẹ̀kọ́ rẹ láé,
nítorí nípa wọn ni ìwọ ti pa ayé mi mọ́
94 Gbà mí, nítorí èmi jẹ́ tìrẹ
èmi ti wá ẹ̀kọ́ rẹ.
95 Àwọn ẹni búburú dúró láti pa mí run,
ṣùgbọ́n èmi yóò kíyèsi ẹ̀rí rẹ.
96 Sí ohun pípé gbogbo èmi ti rí òpin;
ṣùgbọ́n àṣẹ rẹ aláìlópin ni.
18 Ní ọjọ́ kẹta, Josẹfu wí fún wọn pé, “Èyí ni ẹ̀yin yóò ṣe kí ẹ̀yin ba à le yè nítorí mo bẹ̀rù Ọlọ́run: 19 Tí ó bá jẹ́ pé olóòtítọ́ ènìyàn ni yín, ẹ jẹ́ kí ọ̀kan nínú yín dúró ni túbú ní ìhín, nígbà tí àwọn yòókù yín yóò gbé ọkà lọ fún àwọn ará ilé e yín tí ebi ń pa. 20 Ṣùgbọ́n ẹ gbọdọ̀ mú arákùnrin tí ó jẹ́ àbíkẹ́yìn yín wá, kí n ba à le mọ òtítọ́ ohun ti ẹ ń wí, kí ẹ má ba à kú.” Wọn sì gbà láti ṣe èyí.
21 Wọ́n ń sọ ọ́ láàrín ara wọn wí pé, “Àwa jẹ̀bi nítòótọ́ nípa ti arákùnrin wa. A rí ìbànújẹ́ ọkàn rẹ̀ nígbà tí ó ń bẹ̀ wá nítorí ẹ̀mí rẹ̀, ṣùgbọ́n a kò gbẹ́bẹ̀, nítorí náà ni ìdààmú yìí fi dé bá wa.”
22 (A)Reubeni dá wọn ní ohùn pé, “Èmi kò wí fún yín pé kí ẹ má se ṣẹ̀ sí ọmọdékùnrin náà? Ṣùgbọ́n ẹ kò gbọ́! ṣùgbọ́n nísinsin yìí a ń béèrè ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ lọ́wọ́ wa.” 23 Wọn kò sì mọ̀ pé, Josẹfu ń gbọ́ wọn ní àgbọ́yé nítorí ògbufọ̀ ni ó ń lò tẹ́lẹ̀.
24 Ó yípadà kúrò lọ́dọ̀ wọn, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní sọkún. Ó sì tún yí padà sí wọn, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní sọ̀rọ̀. Ó mú Simeoni kúrò láàrín wọn, ó sì dè é ní ojú wọn.
25 Josẹfu pàṣẹ pé kí wọn bu ọkà kún inú àpò wọn, kí wọn sì mú owó ẹnìkọ̀ọ̀kan padà sínú àpò rẹ̀, kí wọn sì fún wọn ní ohun tí wọn yóò lò nírín-àjò wọn padà sílé. Lẹ́yìn ìgbà tí a ti ṣe èyí fún wọn, 26 Wọn gbé ẹrù wọn lé kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, wọn sì padà lọ sí ilé.
27 Níbi tí wọ́n ti dúró láti sùn lóru ọjọ́ náà, ọ̀kan nínú wọn tú àpò rẹ̀ láti mú oúnjẹ fún kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, ó sì rí owó rẹ̀ ní ẹnu àpò rẹ̀. 28 Ó sì wí fún àwọn arákùnrin rẹ̀ pé, “a ti dá owó mi padà, òun nìyí ní ẹnu àpò mi.”
Ẹ̀rù bà wọ́n, wọ́n sì ń gbọ̀n, wọ́n sì wí pé, “Èwo nìyí tí Ọlọ́run ṣe sí wa yìí.”
9 (A)Nígbà tí mo kọ̀wé ṣáájú sí i yín, mo sọ fún yín pé, kí ẹ má ṣe darapọ̀ pẹ̀lú àwọn alágbèrè ènìyàn. 10 (B)Nígbà tí mo sọ bẹ́ẹ̀ ń kò sọ̀rọ̀ nípa àwọn tí ayé yìí, tí wọ́n ń gbé ìgbé ayé wọn nínú ẹ̀ṣẹ̀ àgbèrè, àti àwọn olójúkòkòrò tí ń rẹ́ ni jẹ, àwọn olè àti àwọn abọ̀rìṣà. Nítorí ó dájú pé ẹ̀yin gbọdọ̀ kúrò nínú ayé yìí láti yẹra fún wọn. 11 (C)Ṣùgbọ́n nísinsin yìí mo kọ̀wé sí i yín pé, bí ẹnikẹ́ni tí a pe rẹ̀ ni arákùnrin bá jẹ́ àgbèrè, tàbí wọ̀bìà, tàbí abọ̀rìṣà, àti ẹlẹ́gàn, tàbí ọ̀mùtípara, tàbí alọ́nilọ́wọ́gbà. Kí ẹ tilẹ̀ bá irú ẹni bẹ́ẹ̀ jẹun.
12 (D)Nítorí èwo ni tèmi láti máa ṣe ìdájọ́ àwọn tí ń bẹ lóde? Kì í ha ṣe àwọn tí ó wà nínú ni ẹ̀yin ṣe ìdájọ́ wọn? 13 (E)Ọlọ́run yóò ṣe ìdájọ́ àwọn tí ó ń bẹ lóde. “Ẹ lé àwọn ènìyàn búburú náà kúrò láàrín yín.”
Ìyànjú èdè-àìyedè àwọn onígbàgbọ́
6 (F)Bí ẹnikẹ́ni nínú yín bá ni èdè-àìyedè sí ẹnìkejì rẹ̀, ó ha gbọdọ̀ lọ pè é lẹ́jọ́ níwájú àwọn aláìṣòótọ́ bí, bí kò ṣe níwájú àwọn ènìyàn mímọ́? 2 Ṣé ẹ̀yin kò mọ̀ pé àwọn ẹni mímọ́ ni yóò ṣe ìdájọ́ ayé? Ǹjẹ́ bí ó ba ṣe ìpàṣẹ yín ni a o ti ṣe ìdájọ́ ayé, kín ni ìdí tí ẹ kò fi yanjú àwọn ọ̀rọ̀ kéékèèkéé wọ̀nyí láàrín ara yín. 3 Ẹ kò mọ̀ pé àwa ni a ó ṣe ìdájọ́ àwọn angẹli ní? Mélòó mélòó àwọn nǹkan tó wà nínú ayé yìí. 4 Nítorí náà, bí ẹ̀yin bá ni aáwọ̀ lórí ọ̀rọ̀ yìí, ǹjẹ́ ẹ ó yàn láti gba ìdájọ́ lọ́dọ̀ àwọn tí ìgbé ayé wọn ń di gígàn nínú ìjọ. 5 Mo sọ èyí kí ojú lè tì yín. Ṣé ó ṣe é ṣe kí a máa rín ẹnìkan láàrín yín tí ó gbọ́n níwọ̀n láti ṣe ìdájọ́ èdè-àìyedè láàrín àwọn onígbàgbọ́? 6 Ṣùgbọ́n dípò èyí, arákùnrin kan ń pe arákùnrin kejì lẹ́jọ́ sí ilé ẹjọ́ níwájú àwọn aláìgbàgbọ́.
7 (G)Ǹjẹ́ nísinsin yìí, àbùkù ni fún un yín pátápátá pé ẹ̀yin ń bá ara yín ṣe ẹjọ́. Kín ní ṣe tí ẹ kò kúkú gba ìyà? Kín ló dé tí ẹ kò kúkú gba ìrẹ́jẹ kí ẹ sì fi i sílẹ̀ bẹ́ẹ̀? 8 Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ń jẹ ni ní ìyà, ẹ sì ń rẹ́ ni jẹ. Ẹ̀yin si ń ṣe èyí sí àwọn arákùnrin yín.
Òwe afúnrúgbìn
4 (A)Jesu sì tún bẹ̀rẹ̀ sí ń kọ́ni létí Òkun Àwọn ìjọ ènìyàn tí ó yí i ká pọ̀ jọjọ tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi bọ́ sínú ọkọ̀ ojú omi, tí ó sì jókòó nínú rẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ Òkun, nígbà tí àwọn ènìyàn sì wà ní ilẹ̀ létí Òkun. 2 Ó bẹ̀rẹ̀ sí í fi òwe bá wọn sọ̀rọ̀ nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ pé: 3 “Ẹ fi etí sílẹ̀! Ní ọjọ́ kan, afúnrúgbìn kan jáde lọ láti lọ fúnrúgbìn rẹ̀. 4 Bí ó ti ń fúnrúgbìn, díẹ̀ bọ́ sí ẹ̀bá ọ̀nà, àwọn ẹyẹ sì wá, wọ́n sì ṣà á jẹ. 5 Díẹ̀ bọ́ sórí ilẹ̀ àpáta, níbi tí erùpẹ̀ ko sí púpọ̀. Láìpẹ́ ọjọ́, ó hu jáde. 6 Ṣùgbọ́n nígbà tí oòrùn mú gangan, ó jóná, nítorí tí kò ní gbòǹgbò, ó gbẹ. 7 Àwọn irúgbìn mìíràn sì bọ́ sáàrín ẹ̀gún, nígbà tí ẹ̀gún sì dàgbàsókè, ó fún wọn pa, tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn irúgbìn náà kò le so èso. 8 Ṣùgbọ́n òmíràn bọ́ sí ilẹ̀ ọlọ́ràá, o sì so èso lọ́pọ̀lọpọ̀-òmíràn ọgbọọgbọ̀n, òmíràn ọgọọgọ́ta, àti òmíràn ọgọọgọ́rùn-ún.”
9 Jesu sì wí pé, “Ẹni tí ó bá ní etí láti fi gbọ́, kí ó gbọ́.”
10 (B)Nígbà tí ó ku òun nìkan pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn méjìlá àti àwọn mìíràn, wọ́n bi í léèrè wí pé, “Kí ni ìtumọ̀ òwe rẹ̀?” 11 (C)Ó sì dá wọn lóhùn pé, “Ẹ̀yin ni a gbà láààyè láti mọ ohun ìjìnlẹ̀ nípa ìjọba Ọlọ́run. Èyí tí ó pamọ́ sí àwọn tí ó wà lẹ́yìn agbo ìjọba náà. 12 (D)Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé,
“ ‘wọn yóò rí i, wọn yóò sì gbọ́, kì yóò yé wọn,
bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò sì yípadà sí Ọlọ́run.
Tàbí kí a dárí ẹ̀ṣẹ̀ jì wọ́n!’ ”
13 (E)Ṣùgbọ́n Jesu wí fún wọn pé, “Bí òwe tí ó rọrùn yìí kò bá yé e yín? Báwo ni ẹ̀yin yóò ṣe mọ ìtumọ̀ àwọn mìíràn tí mo ń sọ fún un yín? 14 Afúnrúgbìn ń fúnrúgbìn ọ̀rọ̀ náà. 15 Àwọn èso tó bọ́ sí ojú ọ̀nà, ni àwọn ọlọ́kàn líle tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, lójúkan náà èṣù wá ó sì mú kí wọn gbàgbé ohun tí wọ́n ti gbọ́. 16 Bákan náà, àwọn tí ó bọ́ sórí àpáta, ni àwọn ènìyàn tí wọ́n fi ayọ̀ gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. 17 Ṣùgbọ́n kò ni gbòǹgbò tí ó jinlẹ̀ ní ọkàn wọn. Ṣùgbọ́n wọ́n á wà fún ìgbà díẹ̀, lẹ́yìn náà nígbà ti wàhálà tàbí inúnibíni bá dìde nítorí ọ̀rọ̀ náà, lójúkan náà, wọ́n á kọsẹ̀. 18 Àwọn tí ó bọ́ sáàrín ẹ̀gún ni àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, tí wọn sì gbà á. 19 Ṣùgbọ́n láìpẹ́ jọjọ, àwọn adùn ayé àti inú dídùn, ọrọ̀ àti ìjàkadì fún àṣeyọrí àti ìfẹ́ àwọn ohun mèremère ayé, gba ọkàn wọn, wọ́n sì fún ọ̀rọ̀ náà pa ní ọkàn wọn. Ọ̀rọ̀ náà sì jẹ́ aláìléso. 20 Ṣùgbọ́n àwọn tí ó bọ́ sí ilẹ̀ ọlọ́ràá, ní àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí wọ́n sì gbà á lóòtítọ́, wọ́n sì mú èso púpọ̀ jáde fún Ọlọ́run ní ọgbọọgbọ̀n, ọgọọgọ́ta, àti òmíràn ọgọọgọ́rùn-ún, gẹ́gẹ́ bí a ti gbìn ín sí ọkàn wọn.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.