Book of Common Prayer
Fún adarí orin. Ti Dafidi. Ẹ̀bẹ̀.
70 (A)Yára, Ọlọ́run, láti gbà mí là,
Olúwa, wá kánkán láti ràn mí lọ́wọ́.
2 Kí àwọn tí ń wá ọkàn mi
kí a dójútì wọ́n, kí wọn sì dààmú;
kí àwọn tó ń wá ìparun mi
yí ẹ̀yìn padà nínú ìtìjú.
3 Kí a pa wọ́n ní ẹ̀yìn dà fún èrè
ìtìjú àwọn tí ń wí pé, “Háà! Háà!”
4 Ṣùgbọ́n kí àwọn tí ó ń wá ọ ó máa yọ̀
kí inú wọn kí ó sì máa dùn nípa rẹ,
kí àwọn tí ó ń fẹ́ ìgbàlà rẹ máa wí pé,
“Jẹ́ kí a gbé Ọlọ́run ga!”
5 Ṣùgbọ́n mo jẹ́ òtòṣì àti aláìní;
wa kánkán sí ọ̀dọ̀ mi, Ọlọ́run.
Ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ àti olùdáǹdè mi;
Olúwa, má ṣe dúró pẹ́.
71 Nínú rẹ, Olúwa, ni mo ní ààbò;
Má ṣe jẹ́ kí ojú kí ó tì mí.
2 Gbà mí kí o sì tú mi sílẹ̀ nínú òdodo rẹ;
dẹ etí rẹ sí mi, kí o sì gbà mí.
3 Jẹ́ àpáta ààbò mi,
níbi tí èmi lè máa lọ,
pa àṣẹ láti gbà mí,
nítorí ìwọ ni àpáta àti odi agbára mi.
4 Gbà mí, Ọlọ́run mi, lọ́wọ́ àwọn olùṣe búburú,
ní ọwọ́ aláìṣòdodo àti ìkà ọkùnrin.
5 Nítorí ìwọ jẹ́ ìrètí mi, Olúwa Olódùmarè,
ìwọ ni ìgbẹ́kẹ̀lé mi láti ìgbà èwe.
6 Mo gbẹ́kẹ̀lé ọ láti ìgbà ìbí mi;
Ìwọ mú mi jáde láti inú ìyá mi wá
èmi ó máa yìn ọ́ títí láé.
7 Mo di ààmì fún ọ̀pọ̀ ènìyàn,
ṣùgbọ́n ìwọ ni ààbò mi tí ó lágbára.
8 Ìyìn rẹ̀ kún ẹnu mi,
ó ń sọ ti ọlá rẹ ní ọjọ́ gbogbo.
9 Má ṣe ta mí nù ní ọjọ́ ogbó mi
Má ṣe kọ̀ mí sílẹ̀ nígbà tí kò sí okun mọ́
10 Nítorí àwọn ọ̀tá mi ń sọ̀rọ̀-òdì sí mi,
àwọn tí wọn dúró láti pa mí gbìmọ̀ pọ̀.
11 Wọ́n wí pé, “Ọlọ́run ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀;
lépa rẹ̀ kí ẹ sì mu,
nítorí kò sí ẹni tí yóò gbà á.”
12 Má ṣe jìnnà sí mi, Ọlọ́run;
wa kánkán, Ọlọ́run mi, láti ràn mí lọ́wọ́.
13 Jẹ́ kí wọn kí ó dààmú,
kí a sì run àwọn tí ń ṣe ọ̀tá ọkàn mi
kí a sì fi ẹ̀gàn àti àbùkù
bo àwọn tí ń wá ìpalára mi.
14 Ṣùgbọ́n ní tèmi, ìgbà gbogbo ní ìrètí mi;
èmi ó yìn ọ́ síwájú àti síwájú sí i.
15 Ẹnu mi yóò sọ nípa ti òdodo rẹ,
ti ìgbàlà rẹ, ni gbogbo ọjọ́,
lóòtítọ́, èmi kò mọ iye rẹ̀.
16 Èmi ó wá láti wá kéde agbára,
Olúwa Olódùmarè;
èmi ó kéde òdodo rẹ̀ nìkan.
17 Láti ìgbà èwe, Ọlọ́run ni ìwọ ti kọ́ mi
títí di òní ni mo ń sọ ti iṣẹ́ ìyanu rẹ.
18 Pẹ̀lúpẹ̀lú, nígbà tí èmi di arúgbó tán tí mo sì hewú,
Má ṣe kọ̀ mí sílẹ̀, Ọlọ́run mi,
títí èmi ó fi ipá rẹ han ìran tí ń bọ̀,
àti agbára rẹ fún gbogbo àwọn tí ń bọ̀ lẹ́yìn.
19 Ọlọ́run, òdodo rẹ dé ọ̀run,
ìwọ tí o ti ṣe ohun ńlá
Ta ni ó dàbí rẹ, Ọlọ́run?
20 Pẹ̀lúpẹ̀lú ìwọ ti mú mi rí ìdààmú, tí ó pọ̀ tí ó sì korò,
ìwọ yóò tún sọ ayé mi jí
ìwọ yóò sì tún mú mi sọ sókè
láti ọ̀gbun ilẹ̀ wá.
Ìwọ yóò sọ ọlá mi di púpọ̀
21 Ìwọ yóò fi kún ọwọ́ mi
ìwọ yóò tù mí nínú ní ha gbogbo.
22 Èmi yóò fi dùùrù mi yìn
fún òtítọ́ rẹ, Ọlọ́run mi;
èmi ó kọrin ìyìn sí ọ pẹ̀lú dùùrù
ìwọ ẹni mímọ́ Israẹli.
23 Ètè mi yóò kígbe fún ìyìn
nígbà tí mo bá kọrin ìyìn sí ọ:
èmi, ẹni tí o rà padà.
24 Ahọ́n mi yóò sọ ti òdodo rẹ ní gbogbo ọjọ́,
fún àwọn tí ó fẹ́ pa mí lára,
a sì dójúti àwọn tí ń wá ìdààmú mi.
Maskili ti Asafu.
74 Ọlọ́run, èéṣe tí ìwọ fi kọ̀ wá sílẹ̀ títí láé?
Èéṣe tí ìbínú rẹ̀ fi dìde sí àwọn àgùntàn pápá rẹ?
2 Rántí àwọn ènìyàn tí ìwọ ti rà nígbà àtijọ́,
ẹ̀yà ilẹ̀ ìní rẹ, tí ìwọ ti rà padà
Òkè Sioni, níbi tí ìwọ ń gbé.
3 Yí ẹsẹ̀ rẹ padà sí ìparun ayérayé wọn,
gbogbo ìparun yìí tí ọ̀tá ti mú wá sí ibi mímọ́.
4 Àwọn ọ̀tá rẹ ń bú ramúramù
láàrín ènìyàn rẹ,
wọ́n ń gbé àsíá wọn sókè fún ààmì;
5 Wọ́n ń rí bí ọkùnrin tí ó gbé àáké rẹ̀ sókè
láti gé igi igbó dídí.
6 Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, iṣẹ́ ọnà fínfín,
ni wọ́n fi àáké wó lulẹ̀ ní ẹ̀ẹ̀kan náà.
7 Wọ́n sun ibi mímọ́ rẹ lulẹ̀
wọ́n ba ibùgbé orúkọ rẹ jẹ́
8 Wọ́n wí ní ọkàn wọn. “Àwa ó run wọ́n pátápátá!”
Wọ́n sun gbogbo ibi ìjọ́sìn Ọlọ́run ní ilẹ̀ náà.
9 A kò fún wa ní ààmì iṣẹ́ ìyanu kankan;
kò sí wòlíì kankan
ẹnìkankan wa kò mọ ìgbà tí eléyìí yóò dà.
10 Àwọn ọ̀tá yóò ti kùn sí ọ pẹ́ tó, Ọlọ́run?
Àwọn ọ̀tá yóò ha ba orúkọ rẹ jẹ́ títí láé?
11 Èéṣe tí ìwọ fi dá ọwọ́ rẹ dúró, ọwọ́ ọ̀tún rẹ?
Mú un kúrò nínú ìṣẹ́po aṣọ rẹ kí o sì run wọ́n!
12 Ṣùgbọ́n ìwọ Ọlọ́run ni ọba mi láti ìgbà pípẹ́;
Ó mú ìgbàlà wá sórí ilẹ̀ ayé.
13 Ìwọ ni ó la Òkun sílẹ̀ nípa agbára rẹ;
Ìwọ fọ́ orí ẹ̀mí búburú nínú omi
14 Ìwọ fọ́ orí Lefitani túútúú, o sì fi ṣe oúnjẹ fun àwọn ẹ̀dá tí ń gbé inú ijù
Tìrẹ ni ọ̀sán, tìrẹ sì ni alẹ́ pẹ̀lú;
ìwọ fi ìdí oòrùn àti òṣùpá lélẹ̀.
15 Ìwọ ya orísun omi àti ìṣàn omi;
Ìwọ mú kí odò tó ń sàn gbẹ
16 Tìrẹ ni ọ̀sán, tìrẹ ni òru pẹ̀lú;
ìwọ yà oòrùn àti òṣùpá.
17 Ìwọ pààlà etí ayé;
Ìwọ dá ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn àti ìgbà òtútù.
18 Rántí bí àwọn ọ̀tá ń kẹ́gàn rẹ, Olúwa
bí àwọn aṣiwèrè ènìyàn ti ń ba orúkọ rẹ jẹ́.
19 Má ṣe fi ẹ̀mí àdàbà rẹ fún ẹranko igbó búburú;
Má ṣe gbàgbé ẹ̀mí àwọn ènìyàn rẹ tí a ń pọ́n lójú títí láé.
20 Bojú wo májẹ̀mú rẹ,
nítorí ibi òkùnkùn ayé kún fún ibùgbé ìkà.
21 Má ṣe jẹ́ kí àwọn aninilára padà sẹ́yìn nínú ìtìjú
jẹ́ kí àwọn aláìní àti tálákà yin orúkọ rẹ.
22 Dìde, Ọlọ́run, gba ẹjọ́ ara rẹ rò;
rántí bí àwọn aṣiwèrè ti ń kẹ́gàn rẹ ní gbogbo ọjọ́.
23 Má ṣe gbàgbé ohùn àwọn ọ̀tá rẹ,
bíbú àwọn ọ̀tá rẹ, tí ó ń pọ̀ sí i nígbà gbogbo.
29 Nígbà tí wọ́n padà dé ọ̀dọ̀ Jakọbu baba wọn ní ilẹ̀ Kenaani, wọ́n ròyìn gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún un wí pé, 30 “Ọkùnrin náà tí í ṣe alábojútó ilẹ̀ náà, sọ̀rọ̀ líle sí wa, ó sì fi ẹ̀sùn kàn wá pé a wá yọ́ ilẹ̀ náà wò ni. 31 Ṣùgbọ́n, a wí fún un pé, ‘Rárá o, olóòtítọ́ ènìyàn ni wá, a kì í ṣe ayọ́lẹ̀wò. 32 Arákùnrin méjìlá ni wá, ọmọ baba kan náà, ọ̀kan ti kú, èyí tí ó jẹ́ àbíkẹ́yìn wà lọ́dọ̀ baba wa ni ilẹ̀ Kenaani.’
33 “Nígbà náà ni ọkùnrin tí ó jẹ́ alábojútó ilẹ̀ náà wí fún wa pé, ‘Báyìí ni n ó ṣe mọ̀ bóyá olóòtítọ́ ènìyàn ni yín; Ẹ fi ọ̀kan nínú àwọn arákùnrin yín sílẹ̀ níbí, pẹ̀lú mi, ẹ sì mú oúnjẹ lọ fún àwọn ará ilé yín tí ebi ń pa kú lọ, lọ́wọ́ ìyàn. 34 Ṣùgbọ́n ẹ mú arákùnrin yín tí ó kéré jùlọ wá fún mi kí n le mọ̀ pé dájúdájú ẹ kì í ṣe ayọ́lẹ̀wò bí kò ṣe ènìyàn tòótọ́. Nígbà náà ni n ó mú arákùnrin yín padà fún un yín, lẹ́yìn náà ẹ le máa wá ṣe òwò bí ó ti wù yín ní ilẹ̀ yìí.’ ”
35 Bí wọ́n sì ti ń tú àpò ẹrù wọn, ẹnìkọ̀ọ̀kan bá owó tí ó san fún ọjà náà lẹ́nu àpò rẹ̀! Ẹ̀rù sì bà wọ́n gidigidi, àwọn àti baba wọn. 36 Jakọbu baba wọn wí fún wọn pé, “Ẹ ti mú mi pàdánù àwọn ọmọ mi. N kò rí Josẹfu mọ́, bẹ́ẹ̀ ni n kò sì rí Simeoni náà mọ. Ẹ sì tún fẹ́ mú Benjamini lọ! Èmi ni gbogbo ohun búburú yìí wá ń ṣẹlẹ̀ sí.”
37 Nígbà náà ni Reubeni wí fún baba rẹ̀ pé, “Pa àwọn ọmọ mi méjèèjì bí n kò bá mú Benjamini padà wá fún ọ, èmi ni kí o fà á lé lọ́wọ́, n ó sì mu un padà wá.”
38 Ṣùgbọ́n Jakọbu wí pé, “Ọmọ mi kì yóò bá a yín lọ, ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ti kú, òun nìkan sì ni ó kù nínú àwọn ọmọ ìyá rẹ̀. Bí ohunkóhun bá ṣẹlẹ̀ sí i, ìbànújẹ́ ni yóò sì pa mi kú ni ọjọ́ ogbó mi yìí.”
Ìwà àgbèrè
12 (A)“Ohun gbogbo ní ó tọ́ fún mi,” ṣùgbọ́n kì í ṣe ohun gbogbo ni ó ní èrè; “Ohun gbogbo ni ó yẹ fún mi,” ṣùgbọ́n èmi kì yóò jẹ́ kí ohunkóhun ṣe olórí fun mi. 13 “Oúnjẹ fún inú àti inú fún oúnjẹ,” ṣùgbọ́n Ọlọ́run yóò fi òpin sí méjèèjì, ara kì í ṣe fún ìwà àgbèrè ṣíṣe, ṣùgbọ́n fún Olúwa, àti Olúwa fún ara náà. 14 Nínú agbára rẹ̀, Ọlọ́run jí Olúwa dìde kúrò nínú òkú bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni yóò jí àwa náà dìde. 15 (B)Ṣé ẹ kò tilẹ̀ mọ̀ pé ara yín gan an jẹ́ ẹ̀yà ara Kristi fún ara rẹ̀? Ǹjẹ́ tí ó ba jẹ́ bẹ́ẹ̀, ǹjẹ́ ó yẹ kí ń mú ẹ̀yà ara Kristi kí ń fi ṣe ẹ̀yà ara àgbèrè bí? Kí a má rí i! 16 (C)Tàbí ẹ kò mọ̀ pé bí ẹnìkan bá so ara rẹ̀ pọ̀ mọ́ àgbèrè ó jẹ́ ara kan pẹ̀lú rẹ̀? Nítorí a tí kọ ọ́ wí pé, “Àwọn méjèèjì yóò sì di ara kan.” 17 (D)Ṣùgbọ́n ẹni ti ó dàpọ̀ mọ́ Olúwa di ẹ̀mí kan náà pẹ̀lú rẹ̀.
18 Ẹ máa sá fún àgbèrè. Gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí ènìyàn ń dá wà lóde ara, ṣùgbọ́n ẹni tí ń ṣe àgbèrè ń ṣe sí ara òun tìkára rẹ̀. 19 (E)Tàbí, ẹ̀yin kò mọ̀ pé ara yín ni tẹmpili Ẹ̀mí Mímọ́, ti ń bẹ nínú yín, ti ẹ̀yin ti gbà lọ́wọ́ Ọlọ́run? Ẹ̀yin kì í ṣe ti ara yín, 20 (F)nítorí a ti rà yín ni iye kan; Nítorí náà ẹ yìn Ọlọ́run lógo nínú ara yín, àti nínú ẹ̀mí yín, tì í ṣe ti Ọlọ́run.
Àtùpà lórí ọ̀pá fìtílà
21 (A)Ó sì wí fún wọn pé, “A ha lè gbé fìtílà wá láti fi sábẹ́ òṣùwọ̀n tàbí sábẹ́ àkéte? Rárá o, ki a ṣe pe a o gbé e ka orí ọ̀pá fìtílà? 22 (B)Gbogbo ohun tí ó pamọ́ nísinsin yìí yóò hàn ní gbangba ní ọjọ́ kan, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ohun tí ó wà ní ìkọ̀kọ̀, bí kò ṣe pé kí ó le yọ sí gbangba. 23 (C)Bí ẹnikẹ́ni bá ní etí láti fi gbọ́, kí ó gbọ́.”
24 (D)Ó sì tún tẹ̀síwájú pé, “Ẹ máa kíyèsi ohun tí ẹ bà gbọ́ dáradára, nítorí òṣùwọ̀n tí ẹ̀yin bá fi wọ́n náà ni a ó fi wọ́n fún un yín àti jù bẹ́ẹ̀ lọ. 25 (E)Nítorí ẹni tí ó bá ní, òun ni a ó tún fi fún sí i àti lọ́wọ́ ẹni tí kò bá ní, ni a ó ti gba èyí náà tí ó ní.”
Òwe irúgbìn tó ń dàgbà
26 (F)Ó sì tún sọ èyí pé, “Èyí ni a lè fi ìjọba Ọlọ́run wé. Ọkùnrin kan ń fúnrúgbìn sí ilẹ̀. 27 Lóru àti ní ọ̀sán, bóyá ó sùn tàbí ó dìde, irúgbìn náà hu jáde, ó sì dàgbà, òun kò sì mọ̀ bí ó ti ṣẹlẹ̀. 28 Nítorí tí ilẹ̀ kọ́kọ́ hù èso jáde fún ara rẹ̀, ó mú èéhù ewé jáde, èyí tí ó tẹ̀lé e ní orí ọkà, ní ìparí, ọkà náà gbó. 29 Nígbà tí èso bá gbó tán, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, òun a tẹ dòjé bọ inú ọkà náà, ó sì kórè rẹ̀.”
Òwe musitadi
30 (G)Jesu sì tún wí pé, “Kí ni kí èmi fi ìjọba Ọlọ́run wé? Òwe wo ni kí èmi fi ṣe àkàwé rẹ̀? 31 Ó dàbí èso hóró musitadi kan, lóòótọ́, ó jọ ọ̀kan nínú àwọn èso tí ó kéré jùlọ ti a gbìn sínú ilẹ̀. 32 Síbẹ̀, nígbà tí a gbìn ín, ó dàgbàsókè, ó gbilẹ̀, ó sì di títóbi ju gbogbo ewéko inú ọgbà yòókù lọ. Ó sì yọ ẹ̀ka ńlá níbi tí àwọn ẹyẹ ọ̀run lè kọ́ ìtẹ́ wọn sí, kí wọn sì rí ìdáàbòbò.”
33 Òun lo ọ̀pọ̀ irú òwe wọ̀nyí láti fi kọ́ àwọn ènìyàn, gẹ́gẹ́ bí wọ́n bá ti ń fẹ́ láti ní òye tó. 34 (H)Kìkì òwe ni Jesu fi ń kọ́ àwọn ènìyàn ní ẹ̀kọ́ ìta gbangba rẹ̀. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn èyí, nígbà tí ó bá sì wà pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, òun a sì sọ ìtumọ̀ ohun gbogbo.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.