Book of Common Prayer
Ti Dafidi. Saamu.
24 (A)Ti Olúwa ni ilẹ̀, àti ẹ̀kún rẹ̀,
ayé àti àwọn tí ó tẹ̀dó sínú rẹ̀;
2 Nítorí ó fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ lélẹ̀ lórí Òkun
ó sì gbé e kalẹ̀ lórí àwọn ìṣàn omi.
3 Ta ni yóò gun orí òkè Olúwa lọ?
Ta ni yóò dúró ní ibi mímọ́ rẹ̀?
4 (B)Ẹni tí ó ní ọwọ́ mímọ́ àti àyà funfun,
ẹni tí kò gbé ọkàn rẹ̀ sókè sí asán
tí kò sì búra èké.
5 Òun ni yóò rí ìbùkún gbà láti ọ̀dọ̀ Olúwa,
àti òdodo lọ́wọ́ Ọlọ́run ìgbàlà rẹ̀.
6 Èyí ni ìran àwọn tí ń ṣe àfẹ́rí rẹ̀,
tí ń ṣe àfẹ́rí rẹ̀, Ọlọ́run Jakọbu. Sela.
7 Ẹ gbé orí yín sókè, háà! Ẹ̀yin ọ̀nà;
Kí á sì gbe yín sókè, ẹyin ìlẹ̀kùn ayérayé!
Kí ọba ògo le è wọlé.
8 Ta ni ọba ògo náà?
Olúwa tí ó lágbára tí ó sì le,
Olúwa gan an, tí ó lágbára ní ogun.
9 Gbé orí yín sókè, ẹyin ọ̀nà;
kí a sì gbé e yín sókè, ẹ̀yin ìlẹ̀kùn ayérayé,
kí Ọba ògo le è wọlé wá.
10 Ta ni Ọba ògo náà?
Olúwa àwọn ọmọ-ogun
Òun ni Ọba ògo náà. Sela.
Saamu ti Dafidi.
29 Ẹ fi fún Olúwa, ẹ̀yin ẹ̀dá ọ̀run,
Ẹ fi fún Olúwa, ògo àti alágbára.
2 Fi fún Olúwa, àní ògo orúkọ rẹ̀;
sin Olúwa nínú ẹwà ìwà mímọ́.
3 Ohùn Olúwa n ré àwọn omi kọjá;
Ọlọ́run ògo sán àrá,
Olúwa san ara.
4 Ohùn Olúwa ní agbára;
ohùn Olúwa kún fún ọláńlá.
5 Ohùn Olúwa fa igi kedari;
Olúwa náà ló fọ́ igi kedari Lebanoni ya.
6 Ó mú Lebanoni fo bí i ọmọ màlúù,
àti Sirioni bí ọmọ àgbáǹréré.
7 Ohùn Olúwa ń ya
bí ọwọ́ iná mọ̀nà
8 Ohùn Olúwa ń mi aginjù.
Olúwa mi aginjù Kadeṣi.
9 Ohùn Olúwa ní ó lọ igi óákù, ó n mú abo àgbọ̀nrín bí,
ó sì bọ́ igi igbó sí ìhòhò.
Àti nínú tẹmpili rẹ̀ gbogbo ohùn wí pé “Ògo!”
10 Olúwa jókòó, Ó sì jẹ ọba lórí ìṣàn omi;
Olúwa jókòó lórí ìtẹ́ gẹ́gẹ́ bí Ọba títí láéláé.
11 Kí Olúwa fi agbára fún àwọn ènìyàn rẹ̀;
bùkún àwọn ènìyàn rẹ̀ pẹ̀lú àlàáfíà.
Fún adarí orin. Gẹ́gẹ́ bí ti gittiti. Saamu ti Dafidi.
8 Olúwa, Olúwa wa,
orúkọ rẹ̀ ti ní ìyìn tó ní gbogbo ayé!
Ìwọ ti gbé ògo rẹ ga
ju àwọn ọ̀run lọ.
2 (A)Láti ẹnu ọmọ ọwọ́ àti ọmọ ọmú
ni o ti yan ìyìn nítorí àwọn ọ̀tá rẹ,
láti pa àwọn ọ̀tá àti àwọn olùgbẹ̀san lẹ́nu mọ́.
3 Nígbà tí mo ro ọ̀run rẹ,
iṣẹ́ ìka rẹ,
òṣùpá àti ìràwọ̀,
tí ìwọ tí gbé kalẹ̀,
4 kí ni ènìyàn tí ìwọ ń rò nípa rẹ̀,
àní ọmọ ènìyàn tí ìwọ ń ṣe ìtọ́jú rẹ̀?
5 Ìwọ ṣe é ní onírẹ̀lẹ̀ díẹ̀ ju Ọlọ́run lọ,
ìwọ sì dé e ní adé ògo àti ọlá.
6 Ìwọ mú un jẹ ọba lórí gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ rẹ;
ìwọ sì fi ohun gbogbo sí abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀:
7 àwọn agbo àgùntàn àti àwọn màlúù,
àti ẹranko igbó,
8 ẹyẹ ojú ọrun,
àti ẹja inú Òkun,
àti ohun tí ń wẹ nínú ipa Òkun.
9 Olúwa, Olúwa wa,
Orúkọ rẹ ti ní ìyìn tó ní gbogbo ayé!
Fún adarí orin. Gẹ́gẹ́ bí ti gittiti. Ti àwọn ọmọ Kora. Saamu.
84 Ibùgbé rẹ̀ ti lẹ́wà tó,
Olúwa àwọn ọmọ-ogun!
2 Ọkàn mi ń ṣàfẹ́rí nítòótọ́
ó tilẹ̀ pòǹgbẹ fún àgbàlá Olúwa
àyà mi àti ara mi ń kọrin ayọ̀
sí Ọlọ́run alààyè.
3 Nítòótọ́ ológoṣẹ́ ri ilé,
ẹyẹ alápáǹdẹ̀dẹ̀ tẹ́ ìtẹ́ fún ara rẹ̀,
níbi tí yóò máa pa ọmọ rẹ̀ mọ́ sí:
ibùgbé ní tòsí pẹpẹ rẹ̀,
Olúwa àwọn ọmọ-ogun, ọba mí àti Ọlọ́run mi.
4 Ìbùkún ní fún àwọn tí ó ń gbé inú ilé rẹ;
wọn ó máa yìn ọ́ títí láé.
5 Ìbùkún ni fún àwọn tí agbára wọn wà nínú rẹ
àwọn tí wọ́n gbé ọkàn lé bíbẹ ibi mímọ́ wò.
6 Àwọn tí ń la Àfonífojì omijé lọ
wọn sọ ọ́ di kànga
àkọ́rọ̀ òjò sì fi ìbùkún bò ó;
7 Wọ́n ń lọ láti ipa dé ipá
títí tí ọ̀kọ̀ọ̀kan fi farahàn níwájú Ọlọ́run ní Sioni.
8 Gbọ́ àdúrà mi, Olúwa Ọlọ́run Alágbára;
tẹ́tí sí mi, Ọlọ́run Jakọbu.
9 Wo asà wa, Ọlọ́run;
fi ojú àánú wò àwọn ẹni ààmì òróró rẹ.
10 Dídára ní ọjọ́ kan ní ààfin rẹ
ju ẹgbẹ̀rún ọjọ́ lọ;
èmi o kúkú máa ṣe aṣọ́nà nínú ilé Ọlọ́run mi
jù láti gbé ní àgọ́ àwọn ènìyàn búburú.
11 Nítorí Olúwa Ọlọ́run jẹ́ òòrùn àti asà;
Olúwa fún ni ní ojúrere àti ọlá;
kò sí ohun rere kan tí yóò fàsẹ́yìn
fún àwọn tí ó rìn ní àìlábùkù.
12 Olúwa àwọn ọmọ-ogun,
ìbùkún ni fún ọkùnrin náà tí ó gbẹ́kẹ̀lé ọ.
14 Nítorí náà Farao ránṣẹ́ pe Josẹfu, wọn sì mú un wá kíákíá láti inú ìhámọ́. Nígbà tí ó fá irun rẹ̀, tí ó sì pààrọ̀ aṣọ rẹ̀, ó wá síwájú Farao.
15 Farao wí fún Josẹfu, “Mo lá àlá kan, kò sì sí ẹni tí o le è túmọ̀ rẹ̀. Ṣùgbọ́n mo ti gbọ́ nípa rẹ pé bí o bá ti gbọ́ àlá, o le è túmọ̀ rẹ̀.”
16 Josẹfu dá Farao ní ohùn pé, “Kì í ṣe agbára mi, ṣùgbọ́n, Ọlọ́run ni yóò fi ìdáhùn àlàáfíà fún Farao ní ìtumọ̀ àlá náà.”
17 Nígbà náà ni Farao wí fún Josẹfu pé, “Ní inú àlá mi, mo dúró ni etí bèbè odò Naili, 18 sì kíyèsi i, màlúù méje tí ó sanra tí o sì lẹ́wà jáde wá, wọ́n sì ń jẹ koríko ní tòsí ibẹ̀. 19 Lẹ́yìn wọn, màlúù méje mìíràn jáde wá, wọ́n rù hángógó, wọn kò sì lẹ́wà tó bẹ́ẹ̀ tí n kò tí ì rí irú màlúù tí ó ṣe àìlẹ́wà tó bẹ́ẹ̀ rí ní ilẹ̀ Ejibiti. 20 Àwọn màlúù tí ó rù tí kò sì lẹ́wà sì jẹ àwọn màlúù tí ó sanra tí ó kọ́ jáde nínú odò. 21 Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n jẹ́ wọ́n tan, kò sì ẹni tí ó le mọ̀ pé wọ́n jẹ ohunkóhun, nítorí wọn kò sanra sí i, wọn sì bùrẹ́wà síbẹ̀. Nígbà náà ni mo tají.
22 “Ní ojú àlá mi, mo tún rí síírí ọkà méje tí ó yó ọmọ tí ó sì dára, wọ́n jáde láti ara igi ọkà kan. 23 Lẹ́yìn wọn, àwọn méje mìíràn yọ jáde, tí kò yó ọmọ bẹ́ẹ̀ ni afẹ́fẹ́ ìlà-oòrùn ti rẹ̀ ẹ́ dànù tán. 24 Àwọn síírí ọkà méje tí kò yómọ sì gbé àwọn méje tí ó dára wọ̀nyí mì. Mo sọ àlá yìí fún àwọn onídán mi, ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí ó le túmọ̀ rẹ̀ fún mi.”
25 Nígbà náà ni Josẹfu wí fún Farao, “Ìtumọ̀ kan náà ni àwọn àlá méjèèjì ní. Ọlọ́run fi ohun tí ó fẹ́ ṣe hàn fún Farao. 26 Àwọn màlúù méje ti ó dára jẹ́ ọdún méje, síírí ọkà méje tí ó dára náà sì jẹ́ ọdún méje: ọ̀kan ṣoṣo ni wọn, àlá kan náà ni. 27 Àwọn màlúù méje tí kò sanra, tí kò sì rẹwà tí ó jáde gbẹ̀yìn jẹ́ ọdún méje, bẹ́ẹ̀ náà ni síírí ọkà méje tí kò dára, tí afẹ́fẹ́ ìlà-oòrùn ti rẹ̀ dànù tan: Wọn jẹ́ ọdún méje tí ìyàn yóò fi mú.
28 “Bí mo ti wí fún Farao ní ìṣáájú náà ni: Ọlọ́run fi ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ han Farao. 29 Ọdún méje tí oúnjẹ yóò pọ̀ yanturu ń bọ̀ wà ní Ejibiti. 30 Ṣùgbọ́n ọdún méje mìíràn tí ìyàn yóò mú ń bọ̀, nígbà náà ni a ó tilẹ̀ gbàgbé gbogbo ọ̀pọ̀ ní ilẹ̀ Ejibiti, ìyàn yóò sì run gbogbo ilẹ̀ náà, 31 A kò ní rántí àsìkò ọ̀pọ̀ oúnjẹ yanturu náà mọ́ nítorí pé ìyàn tí yóò tẹ̀lé e yóò pọ̀ púpọ̀. 32 Ìdí tí Ọlọ́run fi fi àlá náà han fún Farao ní ọ̀nà méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni pé, Ọlọ́run ti pinnu pé yóò ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀ dandan, àti pé kò ni pẹ́ tí Ọlọ́run yóò fi ṣe é.
33 “Ìmọ̀ràn mi ni wí pé, jẹ́ kí Farao wá ọlọ́gbọ́n ènìyàn kan ní ilẹ̀ Ejibiti, kí ó sì fi ṣe alákòóso iṣẹ́ àgbẹ̀ ilẹ̀ Ejibiti. 34 Kí Farao sì yan àwọn alábojútó láti máa gba ìdámárùn-ún ìkórè oko ilẹ̀ Ejibiti ní àsìkò ọdún méje ọ̀pọ̀. 35 Kí wọn kó gbogbo oúnjẹ ilẹ̀ náà ni àwọn ọdún méje ọ̀pọ̀ yìí, kí wọn sì kó àwọn ọkà tí wọn jẹ ṣẹ́kù pamọ́ lábẹ́ àṣẹ Farao. Kí a kó wọn pamọ́ ni àwọn ìlú fún jíjẹ. 36 Kí wọn kó oúnjẹ náà pamọ́ fún orílẹ̀-èdè yìí, kí a ba à le lò ó ni ọdún méje tí ìyàn yóò fi jà ní ilẹ̀ Ejibiti, kí ìyàn náà má ba à pa orílẹ̀-èdè yìí run.”
37 Èrò náà sì dára lójú Farao àti àwọn ìjòyè rẹ̀. 38 Farao sì bi wọ́n pé, “Ǹjẹ́ a le rí ẹnikẹ́ni bi ọkùnrin yìí, nínú ẹni tí ẹ̀mí Ọlọ́run ń gbé?”
39 Nígbà náà ni Farao wí fún Josẹfu, “Níwọ́n bí Ọlọ́run ti fi gbogbo èyí hàn ọ́, kò sí ẹni náà tí ó gbọ́n tí ó sì mọ̀ràn bí i tìrẹ ní ilẹ̀ Ejibiti yìí, 40 ìwọ yóò ṣe àkóso ààfin mi gbogbo àwọn ènìyàn gbọdọ̀ tẹríba fún àṣẹ ẹ̀ rẹ. Ìtẹ́ mi nìkan ni èmi yóò fi jù ọ́ lọ.”
Josẹfu di alábojútó ilẹ̀ Ejibiti
41 Farao wí fún Josẹfu pé, “Mo fi ọ́ ṣe alábojútó gbogbo ilẹ̀ Ejibiti.” 42 (A)Farao sì bọ́ òrùka èdìdì ọwọ́ rẹ̀, ó sì fi wọ Josẹfu ó wọ̀ ọ́ ní aṣọ ọ̀gbọ̀ dáradára, ó sì fi ẹ̀gbà tí ó dára sí i lọ́rùn. 43 Ó sì mú un kí ó gun kẹ̀kẹ́-ẹṣin bí igbákejì ara rẹ̀, àwọn ènìyàn sì ń pariwo níwájú rẹ̀ pé, “Ẹ yàgò lọ́nà.” Báyìí ni ó sì fi ṣe alábojútó gbogbo ilẹ̀ Ejibiti.
44 Nígbà náà ni Farao wí fún Josẹfu pé, “Èmi ni Farao. Ṣùgbọ́n láìsí àṣẹ rẹ, ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ ṣe ohunkóhun ní ilẹ̀ Ejibiti.” 45 Farao sì sọ Josẹfu ní orúkọ yìí: Safenati-Panea èyí tí ó túmọ̀ sí, (ẹni tí ó ni agbára ikú àti ìyè ní ìkáwọ́ bí òrìṣà), Ó sì fun un ní Asenati ọmọ Potifẹra, alábojútó òrìṣà Oni, gẹ́gẹ́ bí aya. Josẹfu sì rin gbogbo ilẹ̀ Ejibiti já.
3 (A)Tàbí ẹyin kò mọ pé gbogbo wa ti a ti bamitiisi wa sínú Jesu Kristi ni a ti bamitiisi sínú ikú rẹ. 4 (B)Nítorí náà, a sin wa pẹ̀lú Kristi nípa ìtẹ̀bọmi si ikú, kí ó bá le jẹ́ pe bí a ti jí Kristi dìde pẹ̀lú ògo Baba, àwa pẹ̀lú gbé ìgbé ayé tuntun.
5 (C)Nítorí pé ẹ̀yin ti di ọ̀kan ṣoṣo pẹ̀lú rẹ̀, àti pé ẹ kú pẹ̀lú rẹ̀, nígbà tí òun kú. Nísinsin yìí, ẹ ń pín ìyè tuntun rẹ̀, ẹ̀yin yóò sì jí dìde gẹ́gẹ́ bí òun náà ti jí dìde. 6 (D)Gbogbo èrò búburú ọkàn yín ni a kàn mọ́ àgbélébùú pẹ̀lú rẹ̀. Ẹ̀mí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó sì ń fẹ́ láti máa dẹ́ṣẹ̀ nínú yín ni a ti sọ di aláìlera. Nítorí náà, ara yín tí ó ń fẹ́ láti máa dẹ́ṣẹ̀ kò sí lábẹ́ àkóso ẹ̀ṣẹ̀ mọ́, kò sì ní láti jẹ́ ẹrú fún ẹ̀ṣẹ̀ mọ́. 7 (E)Nítorí pé nígbà tí ẹ ti di òkú fún ẹ̀ṣẹ̀, a ti gbà yín sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ gbogbo agbára ẹ̀ṣẹ̀. Ẹ̀ṣẹ̀ kò ní agbára lórí yín mọ́.
8 (F)Nísinsin yìí, bí àwa bá kú pẹ̀lú Kristi àwa gbàgbọ́ pé àwa yóò wà láààyè pẹ̀lú rẹ̀. 9 (G)Nítorí àwa mọ̀ pé Kristi ti jí dìde kúrò nínú òkú. Òun kò sì ní kú mọ́. Ikú kò sì lè ní agbára lórí rẹ̀ mọ́. 10 Kristi kú lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, láti ṣẹ́gun agbára ẹ̀ṣẹ̀, ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ó wà láààyè títí ayé àìnípẹ̀kun ní ìdàpọ̀ mímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run.
11 (H)Nítorí náà, ẹ ka ara yín bí òkú sí ẹ̀ṣẹ̀, ṣùgbọ́n bí alààyè sí Ọlọ́run nínú Kristi Jesu. 12 Nítorí náà kí ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ jẹ ọba lórí ara kíkú yín kí ó lè ba à máa ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀. 13 (I)Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹ̀yà ara yín kan di ohun èlò ohun búburú, nípa ẹ̀ṣẹ̀ dídá. Ṣùgbọ́n ẹ fi wọn fún Ọlọ́run pátápátá. Wọ́n ti di ààyè, ẹ jẹ́ kí wọn di ohun èlò ní ọwọ́ Ọlọ́run, kí ó lè lò wọ́n fún àwọn ìlànà rẹ̀ tí ó dára. 14 (J)Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ kì yóò tún ní ipá lórí yín mọ́, nítorí ẹ̀yin kò sí lábẹ́ ìdè òfin, bí kò ṣe lábẹ́ oore-ọ̀fẹ́.
19 (A)Nígbà náà ni Jesu dáhùn, ó sì wí fún wọn pé, “Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ọmọ kò lè ṣe ohunkóhun fún ara rẹ̀, bí kò ṣe ohun tí ó bá rí pé Baba ń ṣe: nítorí ohunkóhun tí baba bá ń ṣe, ìwọ̀nyí ni ọmọ náà sì ń ṣe pẹ̀lú. 20 (B)Nítorí Baba fẹ́ràn ọmọ, ó sì ti fi ohun gbogbo tí ó ń ṣe hàn án, òun yóò sì fi iṣẹ́ tí ó tóbi jù wọ̀nyí lọ hàn án, kí ẹnu lè yà yín. 21 (C)Nítorí pé gẹ́gẹ́ bí Baba ti ń jí òkú dìde, tí ó sì ń sọ wọ́n di alààyè: bẹ́ẹ̀ ni ọmọ ń sọ àwọn tí ó fẹ́ di alààyè pẹ̀lú. 22 Nítorí pé Baba kì í ṣe ìdájọ́ ẹnikẹ́ni, ṣùgbọ́n ó ti fi gbogbo ìdájọ́ lé ọmọ lọ́wọ́: 23 (D)Kí gbogbo ènìyàn lè máa fi ọlá fún ọmọ gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ń fi ọlá fún Baba. Ẹnikẹ́ni tí kò bá fi ọlá fún ọmọ, kò fi ọlá fún Baba tí ó ran an.
24 (E)“Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ẹnikẹ́ni tí ó bá gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, tí ó bá sì gba ẹni tí ó rán mi gbọ́, ó ní ìyè tí kò nípẹ̀kun, òun kì yóò sì wá sí ìdájọ́; ṣùgbọ́n ó ti ré ikú kọjá bọ́ sí ìyè.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.