Book of Common Prayer
95 Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a kọ orin ayọ̀ sí Olúwa
Ẹ jẹ́ kí a kígbe sókè sí àpáta ìgbàlà wa.
2 Ẹ jẹ́ kí a wá sí iwájú rẹ̀ pẹ̀lú ọpẹ́
kí a sì pòkìkí rẹ̀ pẹ̀lú ohun èlò
orin àti ìyìn.
3 Nítorí Olúwa Ọlọ́run títóbi ni,
ọba tí ó tóbi ju gbogbo òrìṣà lọ.
4 Ní ọwọ́ rẹ̀ ni ọ̀gbun ilẹ̀ wà,
ṣóńṣó orí òkè tirẹ̀ ní ṣe.
5 Tirẹ̀ ni Òkun, nítorí òun ni ó dá a
àti ọwọ́ rẹ̀ ni ó fi dá ìyàngbẹ ilẹ̀.
6 Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a foríbalẹ̀ kí a sìn ín,
Ẹ jẹ́ kí a kúnlẹ̀ níwájú
Olúwa ẹni tí ó dá wa;
7 (A)Nítorí òun ni Ọlọ́run wa
àwa sì ni ènìyàn pápá rẹ̀,
àti ọ̀wọ́ ẹran ni abẹ́ ìpamọ́ rẹ̀.
Lónìí tí ìwọ bá gbọ́ ohùn rẹ̀,
8 “Ẹ má ṣe sé ọkàn yín le gẹ́gẹ́ bí ẹ ti ṣe ní Meriba,
àti bí ẹ ti ṣe ní ọjọ́ náà ní Massa ní aginjù,
9 Nígbà tí àwọn baba yín dán mi wò
tí wọn wádìí mi,
tí wọn sì rí iṣẹ́ mi
10 Fún ogójì ọdún ni èmi fi bínú sí ìran náà;
mo wí pé, ‘Wọ́n jẹ́ ènìyàn tí ọkàn wọn ṣáko lọ
wọn kò sì mọ ọ̀nà mi.’
11 Nítorí náà ni mo kéde ìbúra nínú ìbínú mi
‘Wọn kì yóò wọ ibi ìsinmi mi.’ ”
Orin. Saamu ti àwọn ọmọ Kora. Fún adarí orin. Gẹ́gẹ́ bí ti mahalati leannoti. Maskili ti Hemani ará Esra.
88 Olúwa, Ọlọ́run tí ó gbà mí là,
ní ọ̀sán àti ní òru ni mo kígbe sókè sí Ọ.
2 Jẹ́ kí àdúrà mi kí ó wá sí iwájú rẹ;
dẹ etí rẹ sí igbe mi.
3 Nítorí ọkàn mi kún fún ìpọ́njú
ọkàn mi sì súnmọ́ isà òkú.
4 A kà mí mọ́ àwọn tí wọ́n lọ sí ọ̀gbun ilẹ̀
èmi dàbí ọkùnrin tí kò ni agbára.
5 A yà mí sọ́tọ̀ pẹ̀lú àwọn òkú
bí ẹni tí a pa tí ó dùbúlẹ̀ ní ipò ikú,
ẹni tí ìwọ kò rántí mọ́,
ẹni tí a gé kúrò lára àwọn tí ìwọ ń tọ́jú.
6 Ìwọ tí ó fi mí sí kòtò jíjìn,
ní ibi ọ̀gbun tó ṣókùnkùn.
7 Ìbínú rẹ ṣubú lé mi gidigidi;
ìwọ ti fi àwọn ìjì rẹ borí mi.
8 Ìwọ tí gba ọ̀rẹ́ mi tí ó súnmọ́ mi kúrò lọ́wọ́ mi
ìwọ sì sọ mi di ìríra sí wọn.
A há mi mọ́, èmi kò sì le è jáde;
9 Ojú mi káàánú nítorí ìpọ́njú.
Mo kígbe pè ọ́, Olúwa, ní gbogbo ọjọ́;
mo na ọwọ́ mi jáde sí ọ.
10 Ìwọ ó fi iṣẹ́ ìyanu rẹ hàn fún òkú bi?
Àwọn òkú yóò ha dìde láti yìn ọ́ bí?
11 A ó ha fi ìṣeun ìfẹ́ rẹ hàn ní ibojì bí:
Tàbí òtítọ́ rẹ ní ipò ìparun?
12 A ha lè mọ iṣẹ́ ìyanu rẹ ní òkùnkùn bí
àti òdodo rẹ ní ilẹ̀ ìgbàgbé?
13 Ṣùgbọ́n mo kígbe sí ọ fún ìrànlọ́wọ́, Olúwa;
ní òwúrọ̀ ni àdúrà mí wá sọ́dọ̀ rẹ.
14 Olúwa, èéṣe tí ìwọ fi kọ̀ mí
tí ìwọ fi ojú rẹ pamọ́ fún mi?
15 Láti ìgbà èwe mi, ìṣẹ́ ń ṣẹ́ mi,
èmi múra àti kú;
nígbà tí ẹ̀rù rẹ bá ń bà mí,
èmi di gbére-gbère
16 Ìbínú rẹ ti kọjá lára mi;
ìbẹ̀rù rẹ ti gé mi kúrò
17 Ní gbogbo ọjọ́ ni wọn yí mi ká bí ìkún omi;
wọ́n mù mí pátápátá.
18 Ìwọ ti mú ọ̀rẹ́ àti olùfẹ́ mi kúrò lọ́dọ̀ mi;
òkùnkùn sì jẹ́ ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ mi.
91 Ẹni tí ó gbé ibi ìkọ̀kọ̀ Ọ̀gá-ògo
ni yóò sinmi ní ibi òjìji Olódùmarè.
2 Èmi yóò sọ nípa ti Olúwa pé,
“Òun ni ààbò àti odi mi,
Ọlọ́run mi, ẹni tí èmi gbẹ́kẹ̀lé”.
3 Nítòótọ́ òun yóò gbà mí nínú
ìdẹ̀kùn àwọn pẹyẹpẹyẹ
àti nínú àjàkálẹ̀-ààrùn búburú.
4 Òun yóò fi ìyẹ́ rẹ̀ bò mí,
àti ni abẹ́ ìyẹ́ rẹ̀ ni èmi yóò ti rí ààbò;
òtítọ́ rẹ̀ ni yóò ṣe ààbò àti odi mi.
5 Ìwọ kì yóò bẹ̀rù nítorí ẹ̀rù òru,
tàbí fún ọfà tí ń fò ní ọ̀sán,
6 Tàbí fún àjàkálẹ̀-ààrùn tí ń rìn kiri ní òkùnkùn,
tàbí fún ìparun tí ń rìn kiri ní ọ̀sán gangan.
7 Ẹgbẹ̀rún yóò ṣubú ní ẹ̀gbẹ́ rẹ,
ẹgbàárùn-ún ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ
ṣùgbọ́n kì yóò súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ
8 Ìwọ yóò máa wò ó pẹ̀lú ojú rẹ
àti wo ìjìyà àwọn ẹni búburú.
9 Nítorí ìwọ fi Olúwa ṣe ààbò rẹ,
ìwọ fi Ọ̀gá-ògo ṣe ibùgbé rẹ.
10 Búburú kan ki yóò ṣubú lù ọ́
Bẹ́ẹ̀ ni ààrùnkárùn kì yóò súnmọ́ ilé rẹ.
11 (A)Nítorí yóò fi àṣẹ fún àwọn angẹli nípa tìrẹ
láti pa ọ́ mọ́ ní gbogbo ọ̀nà rẹ;
12 Wọn yóò gbé ọ sókè ní ọwọ́ wọn,
nítorí kí ìwọ má ba à fi ẹsẹ̀ rẹ gún òkúta.
13 (B)Ìwọ yóò rìn lórí kìnnìún àti paramọ́lẹ̀;
ìwọ yóò tẹ kìnnìún ńlá àti ejò ńlá ni ìwọ yóò fi ẹsẹ̀ tẹ̀ mọ́lẹ̀.
14 “Nítorí ti ìfẹ́ rẹ sí mi, èmi yóò gbà ọ́;
èmi yóò pa ọ́ mọ́, nítorí ìwọ jẹ́wọ́ orúkọ mi.
15 Òun yóò pè mí, èmi yóò sì dá a lóhùn;
èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ̀ nínú ìpọ́njú,
èmi yóò gbà á, èmi yóò sì bu ọlá fún un
16 Pẹ̀lú ẹ̀mí gígùn ni èmi yóò fi tẹ́ ẹ lọ́rùn
èmi yóò sì fi ìgbàlà mi hàn án.”
Saamu. Orin. Fún ọjọ́ Ìsinmi
92 Ohun rere ni láti máa fi ọpẹ́ fún Olúwa
àti láti máa kọrin sí orúkọ rẹ̀, Ọ̀gá-ògo,
2 Láti kéde ìfẹ́ rẹ̀ ní òwúrọ̀
àti òtítọ́ rẹ̀ ní alẹ́
3 Lára ohùn èlò orin olókùn mẹ́wàá
àti lára ohun èlò orin haapu.
4 Nítorí ìwọ ni ó mú inú mi dùn
nípa iṣẹ́ rẹ Olúwa;
èmi kọrin ayọ̀ sí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.
5 Báwo ni iṣẹ́ rẹ tí tóbi tó, Olúwa?
Èrò inú rẹ ìjìnlẹ̀ ni!
6 Òpè ènìyàn kò mọ̀ ọ́n,
aṣiwèrè kò sì mọ̀ ọ́n,
7 Nígbà tí àwọn ènìyàn búburú
bá rú jáde bí i koríko
àti gbogbo àwọn olùṣe
búburú gbèrú,
wọn yóò run láéláé.
8 Ṣùgbọ́n ìwọ Olúwa ni a ó gbéga títí láé.
9 Nítorí nítòótọ́ àwọn ọ̀tá rẹ,
Olúwa,
nítòótọ́ àwọn ọ̀tá rẹ yóò ṣègbé;
gbogbo àwọn olùṣe búburú
ni a ó fọ́nká.
10 Ìwọ ti gbé ìwo mi ga bí i ti màlúù igbó;
òróró dídára ni a dà sí mi ní orí.
11 Ojú mi ti rí ìṣubú àwọn ọ̀tá mi;
ìparun sí àwọn ènìyàn búburú
tí ó dìde sí mi.
12 Olódodo yóò gbèrú bí i igi ọ̀pẹ,
wọn yóò dàgbà bí i igi kedari Lebanoni;
13 Tí a gbìn sí ilé Olúwa,
Wọn yóò rúwé nínú àgbàlá Ọlọ́run wa.
14 Wọn yóò máa so èso ní ìgbà ogbó,
wọn yóò dúró ní àkọ̀tun, wọn yóò sì tutù nini,
15 Láti fihàn pé “Ẹni ìdúró ṣinṣin ni Olúwa;
òun ni àpáta mi, kò sì ṣí aburú
kankan nínú rẹ̀.”
47 Josẹfu lọ sọ fún Farao pé, “Baba mi àti àwọn arákùnrin mi, pẹ̀lú agbo ẹran, agbo màlúù àti ohun gbogbo tí wọ́n ní, ti dé láti ilẹ̀ Kenaani, wọ́n sì ti wà ní ilẹ̀ Goṣeni báyìí.” 2 Ó yan márùn-ún àwọn arákùnrin rẹ́, ó sì fi wọ́n han Farao.
3 Farao béèrè lọ́wọ́ àwọn arákùnrin rẹ̀ pé, “Kí ni iṣẹ́ yín?”
Wọ́n sì fèsì pé, “Darandaran ni àwọn ìránṣẹ́ rẹ, gẹ́gẹ́ bí àwọn baba wa ti jẹ́ darandaran” 4 Wọ́n sì tún sọ fun un síwájú sí i pé, “A wá láti gbé ìhín yìí fún ìgbà díẹ̀ nítorí ìyàn náà mú púpọ̀ ní ilẹ̀ Kenaani, àwọn ohun ọ̀sìn àwa ìránṣẹ́ rẹ kò sì rí ewéko jẹ. Nítorí náà jọ̀wọ́ má ṣàì jẹ́ kí àwọn ìránṣẹ́ rẹ tẹ̀dó sí ilẹ̀ Goṣeni.”
5 Farao wí fún Josẹfu pé, “Baba rẹ àti àwọn arákùnrin rẹ tọ̀ ọ́ wá, 6 Ilẹ̀ Ejibiti sì nìyí níwájú rẹ: Mú àwọn arákùnrin rẹ tẹ̀dó sí ibi tí ó dára jù nínú ilẹ̀ náà. Jẹ́ kí wọn máa gbé ní Goṣeni. Bí o bá sì mọ ẹnikẹ́ni nínú wọn tí ó ní ẹ̀bùn ìtọ́jú ẹran, fi wọ́n ṣe olùtọ́jú ẹran ọ̀sìn mi.”
7 Nígbà náà ni Josẹfu mú Jakọbu baba rẹ̀ wọlé wá sí iwájú Farao. Lẹ́yìn ìgbà tí Jakọbu súre fún Farao tán. 8 Farao béèrè lọ́wọ́ Jakọbu pé, “Ọmọ ọdún mélòó ni ọ́?”
9 Jakọbu sì dá Farao lóhùn, “Ọdún ìrìnàjò ayé mi jẹ́ àádóje (130), ọjọ́ mi kò pọ̀, ó sì kún fún wàhálà, síbẹ̀ kò ì tí ì tó ti àwọn baba mi.” 10 Nígbà náà ni Jakọbu tún súre fún Farao, ó sì jáde lọ kúrò níwájú rẹ̀.
11 Josẹfu sì fi baba rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ sí ilẹ̀ Ejibiti, ó sì fún wọn ní ohun ìní ní ibi tí ó dára jù ní ilẹ̀ náà, ní agbègbè Ramesesi bí Farao ti pàṣẹ. 12 Josẹfu sì pèsè oúnjẹ fún baba rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ àti gbogbo ìdílé baba rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi iye àwọn ọmọ wọn.
Josẹfu àti ìyàn ní ilẹ̀ Ejibiti
13 Ṣùgbọ́n kò sí oúnjẹ ní gbogbo ilẹ̀ náà nítorí tí ìyàn náà mú púpọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí ilẹ̀ Ejibiti àti ilẹ̀ Kenaani gbẹ nítorí ìyàn náà. 14 Josẹfu gba gbogbo owó tí ó wà ní ilẹ̀ Ejibiti àti Kenaani ní ìpààrọ̀ fún ti ọkà tí wọn ń rà, ó sì mú owó náà wá sí ààfin Farao. 15 Nígbà tí owó wọn tán pátápátá ní Ejibiti àti Kenaani, gbogbo Ejibiti wá bá Josẹfu, wọ́n wí pé, “Fún wa ní oúnjẹ, èéṣe tí a ó fi kú ní ojú rẹ? Gbogbo owó wa ni a ti ná tán.”
16 Josẹfu wí pé, “Ẹ mú àwọn ẹran ọ̀sìn yín wá, èmi yóò fún un yín ní oúnjẹ ní ìpààrọ̀ fún ẹran ọ̀sìn yín, níwọ̀n bí owó yín ti tan.” 17 Nítorí náà wọ́n mú àwọn ẹran ọ̀sìn wọn tọ Josẹfu wá, ó sì fún wọn ní oúnjẹ ní ìpààrọ̀ fún ẹṣin, àgùntàn, ewúrẹ́, màlúù àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn. Ó sì mú wọn la ọdún náà já, tí ó ń fún wọn ní oúnjẹ ní ìpààrọ̀ fún ẹran ọ̀sìn wọn.
18 Nígbà tí ọdún náà parí, wọn padà tọ̀ ọ́ wá ní ọdún tí ó tẹ̀lé, wọn wí pé, “A kò le fi pamọ́ fun olúwa wa pé níwọ̀n bí owó wa ti tan tí gbogbo ẹran ọ̀sìn wa sì ti di tirẹ̀ pé, kò sí ohunkóhun tókù fún olúwa wa bí kò ṣe ara wa àti ilẹ̀ wa. 19 Èéṣe tí àwa yóò fi parun lójú rẹ, ra àwa tìkára wa àti ilẹ̀ wa ní ìpààrọ̀ fún oúnjẹ, àwa àti ilẹ̀ wa yóò sì wà nínú ìgbèkùn Farao. Fún wa ni oúnjẹ kí àwa kí ó má ba à kú, kí ilẹ̀ wa má ba à di ahoro.”
20 Nítorí náà Josẹfu ra gbogbo ilẹ̀ tí ó wà ní Ejibiti fún Farao, kò sí ẹnìkan tí ó ṣẹ́kù ní Ejibiti tí kò ta ilẹ̀ tirẹ̀ nítorí ìyàn náà mú jù fún wọn. Gbogbo ilẹ̀ náà sì di ti Farao, 21 Josẹfu sì sọ gbogbo ará Ejibiti di ẹrú láti igun kan dé èkejì 22 Ṣùgbọ́n ṣá, kò ra ilẹ̀ àwọn àlùfáà, nítorí wọ́n ń gba ìpín oúnjẹ lọ́wọ́ Farao, wọn sì ní oúnjẹ tí ó tó láti inú ìpín tí Farao ń fún wọn. Ìdí nìyí tí wọn kò fi ta ilẹ̀ wọn.
23 Josẹfu wí fún àwọn ènìyàn náà pé, “Níwọ́n ìgbà tí mo ti ra ẹ̀yin àti ilẹ̀ yín tan lónìí fún Farao, irúgbìn rèé, ẹ lọ gbìn ín sí ilẹ̀ náà. 24 Ṣùgbọ́n nígbà tí ìre oko náà bá jáde, ẹ ó mú ìdákan nínú ìdámárùn-ún rẹ̀ fún Farao. Ẹ le pa ìdámẹ́rin tókù mọ́ fún ara yín àti ìdílé yín àti àwọn ọmọ yín.”
25 Wọ́n dá á lóhùn pé, “O ti gbà wá là, Ǹjẹ́ kí a rí ojúrere níwájú olúwa wa, àwa yóò di ẹrú Farao.”
26 Nítorí náà Josẹfu sọ ọ́ di òfin nípa ọ̀rọ̀ ilẹ̀ ni Ejibiti, ó sì wà bẹ́ẹ̀ di òní olónìí pé, ìdákan nínú ìdámárùn-ún ìre oko jẹ́ ti Farao, ilẹ̀ àwọn àlùfáà nìkan ni kò di ti Farao.
16 Nítorí pé bí mo ti ń wàásù ìhìnrere, kì í ṣe ohun tí mo lè máa ṣògo lè. Èmi kò tilẹ̀ le è ṣe é ní, kí a tilẹ̀ sọ pé mo fẹ́ kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Ègbé ni fún mi tí mo bá kọ̀ láti wàásù ìhìnrere. 17 (A)Tó bá jẹ́ pé mò ń wàásù tinútinú mi, mo ní èrè kan, ṣùgbọ́n tí ń kò bá ṣe tinútinú mi, a ti fi iṣẹ́ ìríjú lé mi lọ́wọ́. 18 (B)Ní irú ipò báyìí, kín ni ẹ rò pé yóò jẹ èrè mi ni láti jẹ́? Èrè mi ní àgbàyanu ayọ̀ tí mo ń rí gbà nípa ìwàásù ìhìnrere láìgba owó lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni, láìbéèrè ẹ̀tọ́ mi lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni.
19 Bí mo ti jẹ́ òmìnira tí ń kò sì darapọ̀ mọ́ ẹnikẹ́ni, mo sọ ara mi di ẹrú lọ́dọ̀ gbogbo ènìyàn, láti lè jèrè ọ̀pọ̀lọpọ̀ sí i. 20 (C)Nígbà tí mó wà lọ́dọ̀ àwọn Júù, mo dàbí ọ̀kan nínú wọn, kí wọn ba à lè tẹ́tí sí ìwàásù ìhìnrere mi àti ki n le jèrè wọn fún Kristi. Nígbà tí mo bá wà láàrín àwọn tó wà lábẹ́ òfin èmi kì í bá wọn jiyàn rárá (bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi kò sí lábẹ́ òfin), kí èmi lè jèrè àwọn ti ń bẹ lábẹ́ òfin. 21 (D)Nígbà tí mo bá wà láàrín àwọn tí kò sí lábẹ́ òfin, èmi náà yóò dàbí ẹni tí kò sí lábẹ́ òfin (èmi kì í ṣe aláìlófin sí Ọlọ́run, ṣùgbọ́n èmí ń bẹ lábẹ́ òfin Kristi), kí èmi le jèrè àwọn tí kò sí lábẹ́ òfin. 22 (E)Nígbà tí mo bá wà láàrín àwọn aláìlera, èmi náà yóò di aláìlera, kí èmi lé jèrè àwọn aláìlera. Mo di ohun gbogbo fún gbogbo ènìyàn, kí èmi ba à lè gba díẹ̀ là lábẹ́ bí ó ti wù kí ó rí. 23 Èmi sì ń ṣe ohun gbogbo nítorí ti ìhìnrere, kí èmi kí ó lè jẹ́ alábápín nínú rẹ̀ pẹ̀lú yín.
24 (F)Ẹ̀yin kò mọ̀ pé, olúkúlùkù ẹni tí ó ní ipa nínú eré ìje ni ó máa ń sáré, ṣùgbọ́n ẹnìkan ṣoṣo ni ń gba ipò ẹ̀bùn tí ó ga jù. Nítorí náà, ẹ sá eré ìje yín kí ẹ ba à le borí. 25 (G)Gbogbo ẹni tí ó ń sáré ìje a máa lọ nínú ìsẹ́ra-ẹni tí ó lágbára. Wọ́n ń ṣe èyí láti gba adé ìdíbàjẹ́. Ṣùgbọ́n àwa ń sá eré ìje tiwa láti fi gba adé ọ̀run àìdíbàjẹ́ láéláé. 26 Nítorí náà, mo ń sá eré ìje lọ sójú ààmì, kì í ṣe bí ẹni ti kò dá lójú. Mò ń jà kí n lè borí, kì í ṣe bí ẹni tí ń bá afẹ́fẹ́ jà. 27 Ṣùgbọ́n èmi ń kó ara mi ní ìjánu, mo sì ń mú un wá sí abẹ́ ìtẹríba, pé lẹ́yìn tí mo ti wàásù fún àwọn ẹlòmíràn, nítorí ohunkóhun, kí èmi fún rara mi má ṣe di ẹni ìtanù fún ẹ̀bùn náà.
47 Nígbà tí ó di alẹ́, ọkọ̀ wà láàrín Òkun, òun nìkan sì wà lórí ilẹ̀. 48 (A)Ó rí i wí pé àwọn ọmọ-ẹ̀yìn wà nínú wàhálà púpọ̀ ní wíwa ọkọ̀ náà nítorí ti ìjì líle ṣe ọwọ́ òdì sí wọn, nígbà tí ó sì dì ìwọ̀n ìṣọ́ kẹrin òru, ó tọ̀ wọ́n wá, ó ń rìn lórí omi Òkun, òun sì fẹ́ ré wọn kọjá, 49 ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n rí i tí ó ń rìn, wọ́n rò pé iwin ni. Wọ́n sì kígbe sókè lóhùn rara, 50 (B)nítorí gbogbo wọn ni ó rí i, tí ẹ̀rù sì bà wọ́n.
Ṣùgbọ́n òun sọ̀rọ̀ sí wọn lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ pé, “Ẹ mú ọkàn le! Èmi ni. Ẹ má bẹ̀rù.” 51 Nígbà náà ni ó gòkè sínú ọkọ̀ pẹ̀lú wọn, ìjì líle náà sì dáwọ́ dúró. Ẹ̀rù sì bà wọ́n rékọjá gidigidi, ẹnu sì yà wọ́n. 52 (C)Wọn kò sá tó ni òye iṣẹ́ ìyanu ti ìṣù àkàrà, nítorí ti ọkàn wọn yigbì.
53 (D)Lẹ́yìn tí wọ́n la Òkun náà kọjá, wọ́n gúnlẹ̀ sí Genesareti. Wọ́n sì so ọkọ̀ sí èbúté. 54 Wọ́n jáde kúrò nínú ọkọ̀. Àwọn ènìyàn tó wà níbẹ̀ rí Jesu, wọ́n sì dá a mọ̀ ọ́n. 55 Wéré, wọ́n ròyìn dídé rẹ̀, gbogbo àwọn ènìyàn sáré gbé gbogbo àwọn aláìsàn lórí àkéte wọn wá pàdé rẹ̀. 56 (E)Ní ibi gbogbo tí ó sì dé, yálà ní abúlé, ìlú ńlá tàbí àrọ́ko, ń ṣe ni wọ́n ń kó àwọn aláìsàn pàdé rẹ̀ ní àárín ọjà. Wọ́n sì ń bẹ̀ ẹ́ kí ó jẹ́ kí wọn fi ọwọ́ kan etí aṣọ rẹ̀, gbogbo àwọn tí wọ́n sì fi ọwọ́ kàn án ni a mú láradá.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.