Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Book of Common Prayer

Daily Old and New Testament readings based on the Book of Common Prayer.
Duration: 861 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 41

Fún adarí orin. Saamu Dafidi.

41 Ìbùkún ni fún ẹni tí ó ń ro ti aláìní:
    Olúwa yóò gbà á ní ìgbà ìpọ́njú.
Olúwa yóò dáàbò bò ó yóò sì pa ọkàn rẹ̀ mọ́:
    yóò bùkún fún un ní orí ilẹ̀
kò sì ní fi sílẹ̀ fún ìfẹ́ àwọn ọ̀tá rẹ̀.
Olúwa yóò gbà á lórí àkéte àìsàn rẹ̀
    yóò sì mú un padà bọ̀ sípò kúrò nínú àìsàn rẹ̀.

Ní ti èmi, mo wí pé “Olúwa, ṣàánú fún mi;
    wò mí sàn, nítorí pé mo ti ṣẹ̀ sí ọ”.
Àwọn ọ̀tá mi ń sọ̀rọ̀ mi nínú àrankàn, pé
    “Nígbà wo ni yóò kú, ti orúkọ rẹ̀ yóò sì run?”
Nígbàkígbà tí ẹnìkan bá wá wò mí,
    wọn ń sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn, nígbà tí àyà rẹ̀ bá kó ẹ̀ṣẹ̀ jọ sí ara rẹ̀;
nígbà tí ó bá jáde lọ yóò sì máa tàn án kálẹ̀.

Àwọn ọ̀tá mi gbìmọ̀ papọ̀ nípa mi;
    èmi ni wọ́n ń gbìmọ̀ ibi sí,
wọ́n wí pé, “Ohun búburú ni ó dì mọ́ ọn ṣinṣin
    àti ní ibi tí ó dùbúlẹ̀ sí,
kì yóò dìde mọ́.”
(A)Pàápàá, ọ̀rẹ́ mi tímọ́tímọ́, ẹni tí mo gbẹ́kẹ̀lé,
    ẹni tí ó ń jẹ nínú oúnjẹ mi,
tí gbé gìgísẹ̀ rẹ̀ sókè sí mi.

10 Ṣùgbọ́n ìwọ Olúwa, ṣàánú fún mi;
    gbé mi sókè, kí ń ba lè san fún wọn.
11 Èmi mọ̀ pé inú rẹ̀ dùn sí mi,
    nítorí ọ̀tá mi kò borí mi.
12 Bí ó ṣe tèmi ni
    ìwọ dì mímú nínú ìwà òtítọ́ mi
ìwọ sì gbé mi kalẹ̀ níwájú rẹ títí láé.

13 Olùbùkún ni Olúwa, Ọlọ́run Israẹli
    láé àti láéláé.
Àmín àti Àmín.

Saamu 52

Fún adarí orin. Maskili ti Dafidi. Nígbà tí Doegi ará Edomu tọ Saulu lọ láti sọ fún pé, “Dafidi wà ní ilé Ahimeleki.”

52 Èéṣe tí ìwọ fi ń ṣe féfé nínú ìwà ìkà, ìwọ alágbára ọkùnrin?
    Èéṣe tí ìwọ fi ń gbéraga nígbà gbogbo,
    ìwọ ẹni ẹ̀gàn níwájú Ọlọ́run?
Ahọ́n rẹ̀ ń gbìmọ̀ ìparun;
    ó dàbí abẹ mímú,
    ìwọ ẹni tí ń hùwà ẹ̀tàn.
Ìwọ fẹ́ràn ibi ju ìre lọ,
    àti èké ju kí ó sọ òtítọ́ lọ.
Ìwọ fẹ́ràn ọ̀rọ̀ ìpanilára gbogbo,
    ìwọ ahọ́n ẹ̀tàn!

Ọlọ́run yóò sì lù ọ́ bolẹ̀ láéláé,
    yóò sì dì ọ́ mú,
yóò sì já ọ kúrò ni ibùjókòó rẹ,
    yóò sì fà ọ́ tu kúrò lórí ilẹ̀ alààyè. Sela.
Àwọn olódodo yóò rí, wọn yóò sì bẹ̀rù
    wọn yóò sì rẹ́rìn-ín rẹ̀, wí pé,
“Èyí ni ọkùnrin náà ti kò fi Ọlọ́run ṣe agbára rẹ̀,
    bí kò ṣe ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọrọ̀ rẹ̀ ni ó gbẹ́kẹ̀lé,
    ó sì mu ara rẹ̀ le nínú ìwà búburú rẹ̀.”

Ṣùgbọ́n èmi dàbí igi Olifi
    tí ó gbilẹ̀ nínú ilé Ọlọ́run;
Èmi gbẹ́kẹ̀lé ìfẹ́ Ọlọ́run tí kì í kùnà
    láé àti láéláé.
Èmi yóò yìn ọ títí fún ohun tí ó ti ṣe;
    èmi ní ìrètí nínú orúkọ rẹ,
nítorí orúkọ rẹ dára.
    Èmi yóò yìn ọ́ níwájú àwọn ènìyàn mímọ́.

Saamu 44

Fún adarí orin. Ti àwọn ọmọ Kora. Maskili.

44 À ti fi etí wa gbọ́, Ọlọ́run
    àwọn baba wa tí sọ fún wa
ohun tí ìwọ ṣe ní ọjọ́ wọn,
    ní ọjọ́ pípẹ́ sẹ́yìn.
Ìwọ fi ọwọ́ rẹ lé orílẹ̀-èdè jáde
    Ìwọ sì gbin àwọn baba wa;
Ìwọ run àwọn ènìyàn náà
    Ìwọ sì mú àwọn baba wa gbilẹ̀.
Kì í ṣe nípa idà wọn ni wọ́n gba ilẹ̀ náà,
    bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe apá wọn ní ó gbà wọ́n bí kò ṣe;
ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ àti, apá rẹ;
    àti ìmọ́lẹ̀ ojú rẹ̀, nítorí ìwọ fẹ́ wọn.

Ìwọ ni ọba àti Ọlọ́run mi,
    ẹni tí ó pàṣẹ ìṣẹ́gun fún Jakọbu.
Nípasẹ̀ rẹ ni àwa ó bi àwọn ọ̀tá wa ṣubú;
    nípasẹ̀ orúkọ rẹ ni àwa ó tẹ àwọn ọ̀tá tí ó dìde sí wa mọ́lẹ̀
Èmi kì yóò gbẹ́kẹ̀lé ọrun mi
    idà mi kì yóò mú ìṣẹ́gun lórí àwọn ọ̀tá wá,
Ṣùgbọ́n ìwọ fún wa ní ìṣẹ́gun lórí àwọn ọ̀tá wa,
    ìwọ sì ti dójúti àwọn tí ó kórìíra wa.
Nínú Ọlọ́run àwa ń ṣògo ní gbogbo ọjọ́,
    àwa ó sì yin orúkọ rẹ títí láé. Sela.

Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ìwọ ti kọ̀ wá, ìwọ sì ti dójútì wá;
    Ìwọ kò sì bá àwọn ọmọ-ogun wa jáde mọ́.
10 Ìwọ ti bá wa jà,
    ìwọ sì ti ṣẹ́gun wa níwájú àwọn ọ̀tá wa,
àwọn ọ̀tá wa ti gba ilẹ̀ wa,
    wọ́n sì fi ipá gba oko wa.
11 Ìwọ fi wá fún jíjẹ bí ẹran àgùntàn
    Ìwọ sì ti tú wa ká sí àárín àwọn kèfèrí.
12 Ìwọ ta àwọn ènìyàn rẹ fún owó kékeré,
    Ìwọ kò sì jẹ èrè kankan lórí iye tí ìwọ tà wọ́n.

13 Ìwọ sọ wá di ẹni ẹ̀sín ní ọ̀dọ̀ àwọn aládùúgbò wa,
    ẹlẹ́yà àti ẹni àbùkù sí àwọn tí ó yí wa ká.
14 Ìwọ ti sọ wá di ẹni ìfisọ̀rọ̀ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè;
    àwọn ènìyàn ń mi orí wọn sí wa.
15 Ìdójútì mi ń bẹ pẹ̀lú mi ní gbogbo ọjọ́,
    ìtìjú sì bojú mi mọ́lẹ̀,
16 nítorí ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn àti ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn
    ní ojú àwọn ọ̀tá àti olùgbẹ̀san.

17 Gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí ń ṣẹlẹ̀ sí wa,
    síbẹ̀ àwa kò gbàgbé rẹ
bẹ́ẹ̀ ni a kò ṣèké sí májẹ̀mú rẹ̀.
18 Ọkàn wa kò padà sẹ́yìn;
    bẹ́ẹ̀ ni ẹsẹ̀ wa kò yẹ̀ kúrò ní ọ̀nà rẹ̀.
19 Ṣùgbọ́n wọ́n kọlù wá,
    ìwọ sì sọ wá di ẹran ọdẹ fún àwọn ẹranko búburú,
tí wọn sì fi òkùnkùn biribiri bò wá mọ́lẹ̀.

20 Bí àwa bá ti gbàgbé orúkọ Ọlọ́run wa
    tàbí tí a na ọwọ́ wa sí ọlọ́run àjèjì.
21 Ǹjẹ́ Ọlọ́run kì yóò rí ìdí rẹ̀,
    níwọ̀n ìgbà tí ó mọ ohun ìkọ̀kọ̀ inú ọkàn?
22 (A)Síbẹ̀, nítorí rẹ̀ àwa da àyà kọ ikú, ní ojoojúmọ́
    a ń kà wá sí bí àgùntàn fún pípa.

23 Jí, Olúwa! Èéṣe tí ìwọ ń sùn?
    Dìde fúnrarẹ̀! Má ṣe kọ̀ wá sílẹ̀ láéláé.
24 Èéṣe tí ìwọ ń pa ojú rẹ mọ́
    tí ìwọ sì gbàgbé ìpọ́njú àti ìnira wa?

25 Nítorí a tẹrí ọkàn wa ba sínú eruku;
    ara wa sì dì mọ́ erùpẹ̀ ilẹ̀.
26 Dìde kí o sì ràn wá lọ́wọ́;
    rà wá padà nítorí ìfẹ́ rẹ tí ó dúró ṣinṣin.

Gẹnẹsisi 37:1-11

Àlá Josẹfu

37 Jakọbu sì gbé ilẹ̀ Kenaani ní ibi ti baba rẹ̀ ti gbé.

Èyí ni àwọn ìtàn Jakọbu.

Nígbà tí Josẹfu di ọmọ ọdún mẹ́tà-dínlógún (17), ó ń ṣọ́ agbo ẹran pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ̀, àwọn ọmọ Biliha àti Silipa aya baba rẹ̀ Josẹfu sì ń ròyìn àwọn aburú tí wọ́n ń ṣe fún baba wọn.

Israẹli sì fẹ́ràn Josẹfu ju gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ tókù lọ, nítorí ní ọjọ́ ogbó rẹ̀ ni ó bí i. O sì dá aṣọ aláràbarà tí ó kún fún onírúurú ọnà lára fún un. Nígbà tí àwọn arákùnrin rẹ̀ rí i pé baba àwọn fẹ́ràn rẹ̀ ju gbogbo wọn lọ, wọ́n kórìíra rẹ̀, wọ́n sì ń fi ẹ̀tanú bá a gbé, kò sì sí àlàáfíà láàrín wọn.

Josẹfu lá àlá kan, nígbà tí ó sì sọ fún àwọn arákùnrin rẹ̀, wọ́n túbọ̀ kórìíra rẹ̀ sí i. O wí fún wọn pé, “Ẹ fetí sí àlá tí mo lá: Sá à wò ó, àwa ń yí ìtí ọkà nínú oko, ó sì ṣe ìtí ọkà tèmi sì dìde dúró ṣánṣán, àwọn ìtí ọkà tiyín sì dúró yí ìtí tèmi ká, wọ́n sì ń foríbalẹ̀ fún un.”

Àwọn arákùnrin rẹ̀ wí fún un pé, “Ìwọ ń gbèrò àti jẹ ọba lé wa lórí bí? Tàbí ìwọ ó ṣe olórí wa nítòótọ́?” Wọn sì túbọ̀ kórìíra rẹ̀ sí i, nítorí àlá rẹ̀ àti nítorí ohun tí ó wí.

O sì tún lá àlá mìíràn, ó sì tún sọ ọ́ fún àwọn arákùnrin rẹ̀. Ó wí pé, ẹ tẹ́tí sí mi, “Mo tún lá àlá mìíràn, wò ó, oòrùn, òṣùpá àti ìràwọ̀ mọ́kànlá ń foríbalẹ̀ fún mi.”

10 Nígbà tí ó sọ fún baba rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ pẹ̀lú, baba rẹ̀ bá a wí pé, “irú àlá wo ni ìwọ lá yìí? Ṣé ìyá rẹ, pẹ̀lú èmi àti àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ yóò wá foríbalẹ̀ níwájú rẹ ni?” 11 (A)Àwọn arákùnrin rẹ̀ sì ń ṣe ìlara rẹ̀ ṣùgbọ́n baba rẹ̀ pa ọ̀rọ̀ náà mọ́ lọ́kàn rẹ̀.

1 Kọrinti 1:1-19

(A)Paulu, ẹni ti a pé láti jẹ́ aposteli Kristi Jesu nípa ìfẹ́ Ọlọ́run àti Sostene arákùnrin wa.

(B)Sí ìjọ ènìyàn Ọlọ́run ni Kọrinti, sí àwọn ti a sọ di mímọ́ nínú Kristi Jesu àti àwọn ti a pè láti jẹ́ mímọ́ pẹ̀lú gbogbo ènìyàn ni ibikíbi ti ń pe orúkọ Olúwa wa Jesu Kristi ẹni ti ń ṣe Olúwa tiwọn àti ti àwa náà.

(C)Oore-ọ̀fẹ́ àti àlàáfíà fún yín láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wa àti Olúwa wa tí í ṣe Jesu Kristi.

Ìdúpẹ́

(D)Nígbà gbogbo ni mo ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ tó fi fún un yín nínú Kristi Jesu. Nítorí nínú rẹ̀ ni a ti sọ yín di ọlọ́rọ̀ nínú ọ̀rọ̀ sísọ yín gbogbo àti nínú ìmọ̀ yín gbogbo. Nítorí ẹ̀rí wa nínú Kristi ni a ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ nínú yín. Nítorí náà ẹ̀yin kò ṣe aláìní nínú èyíkéyìí ẹ̀bùn ẹ̀mí, bí ẹ̀yin ṣe ń retí ìfarahàn Olúwa wa Jesu Kristi. (E)Òun yóò sì mú yín dúró títí dé òpin, kí ẹ̀yin kí ó lè jẹ́ aláìlábùkù ní ọjọ́ Olúwa wa Jesu Kristi. (F)Ọlọ́run, nípasẹ̀ ẹni ti a pè yín sínú ìdàpọ̀ pẹ̀lú Ọmọ rẹ̀ Jesu Kristi Olúwa wa, jẹ́ Olóòtítọ́.

Ìyapa nínú ìjọ Ọlọ́run

10 Mo bẹ̀ yín ẹ̀yin ara, ní orúkọ Olúwa wa Jesu Kristi, pé kí gbogbo yín fohùn ṣọ̀kan kí ó máa ṣe sí ìyapa láàrín yín, àti pé kí a lè ṣe yín pé ní inú àti ìmọ̀ kan náà. 11 Ẹ̀yin ará mi, àwọn kan láti ilé Kloe sọ di mí mọ̀ fún mi pé ìjà ń bẹ́ láàrín yín. 12 (G)Ohun tí mo ń sọ ní pé: Olúkúlùkù yín ń wí pé, “Èmí tẹ̀lé Paulu”; “Èmi tẹ̀lé Apollo” òmíràn wí pé “Èmi tẹ̀lé Kefa, Peteru”; àti ẹlòmíràn wí pé “Èmi tẹ̀lé Kristi.”

13 (H)Ǹjẹ́ a ha pín Kristi bí? Ṣé a kan Paulu mọ́ àgbélébùú fún un yín bí? Ǹjẹ́ a tẹ̀ yín bọ omi ní orúkọ Paulu bí? 14 (I)Inú mi dún púpọ̀ pé èmi kò tẹ ẹnikẹ́ni nínú yín bọ omi yàtọ̀ sí Krisipu àti Gaiu. 15 Nítorí náà kò sí ẹni tí ó lè sọ pé òun ṣe ìtẹ̀bọmi ní orúkọ èmi fúnra ara mi. 16 (J)(Bẹ́ẹ̀ ni, mo tún tẹ ìdílé Stefana bọ omi; lẹ́yìn èyí, èmí kò rántí pé mo tẹ ẹnikẹ́ni bọ omi mọ́ níbikíbi). 17 (K)Nítorí Kristi kò rán mi láti máa ṣe ìtẹ̀bọmi, ṣùgbọ́n ó rán mi láti máa wàásù ìhìnrere: kì í ṣe nípa ọgbọ́n ènìyàn, kí a máa ṣe sọ àgbélébùú Kristi dí aláìlágbára.

Kristi ní ọgbọ́n àti agbára Ọlọ́run

18 Nítorí pé òmùgọ̀ ni ọ̀rọ̀ àgbélébùú jẹ́ sí àwọn tí ń ṣègbé, ṣùgbọ́n fún àwa tí a ń gbàlà ó jẹ́ agbára Ọlọ́run. 19 (L)Nítorí a tí kọ ọ́ pé:

“Èmi yóò pa ọgbọ́n àwọn ọlọ́gbọ́n run,
    òye àwọn olóye ni Èmi yóò sọ di asán.”

Marku 1:1-13

Johanu onítẹ̀bọmi tún ọ̀nà ṣe sílẹ̀

Ìbẹ̀rẹ̀ ìhìnrere nípa Jesu Kristi, Ọmọ Ọlọ́run.

(A)(B) Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ nínú ìwé wòlíì Isaiah pé:

“Èmi yóò ran oníṣẹ́ mi síwájú rẹ,
    Ẹni tí yóò tún ọ̀nà rẹ ṣe.”
(C)“Ohùn ẹni tí ń kígbe ní ijù,
    ‘Ẹ tún ọ̀nà Olúwa ṣe,
    ẹ ṣe ojú ọ̀nà rẹ̀ kí ó tọ́.’ ”

(D)Johanu dé, ẹni tí ó ń tẹnibọmi ní aginjù, tí ó sì ń wàásù ìtẹ̀bọmi ìrònúpìwàdà fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀. Gbogbo àwọn tí ń gbé ní agbègbè Judea, àti gbogbo ènìyàn Jerusalẹmu jáde tọ̀ ọ́ lọ, a sì ti ọwọ́ rẹ̀ tẹ gbogbo wọn bọ omi ni odò Jordani, wọ́n ń jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Johanu sì wọ aṣọ irun ìbákasẹ. Ó sì di àmùrè awọ mọ́ ẹ̀gbẹ́ rẹ̀. Eṣú àti oyin ìgàn sì ni oúnjẹ rẹ̀. Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù wí pé, “Ẹnìkan tí ó tóbi jù mí lọ ń bọ̀ lẹ́yìn mi, okùn bàtà ẹsẹ̀ ẹni tí èmi kò tó ẹni tí ń tú. Èmi ń fi omi ṣe ìtẹ̀bọmi yín, ṣùgbọ́n Òun yóò fi Ẹ̀mí Mímọ́ ṣe ìtẹ̀bọmi yín.”

Ìtẹ̀bọmi àti ìdánwò Jesu

(E)Ó sì ṣe ní ọjọ́ kan Jesu ti Nasareti ti Galili jáde wá, a sì ti ọwọ́ Johanu ṣe ìtẹ̀bọmi fún ní odò Jordani. 10 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ tí Jesu ń ti inú omi jáde wá, ó rí ọ̀run tí ó ṣí sílẹ̀, Ẹ̀mí Mímọ́ bí àdàbà sọ̀kalẹ̀ lé e lórí. 11 (F)Ohùn kan sì ti ọ̀run wá wí pé, “Ìwọ ni àyànfẹ́ Ọmọ mi, ẹni tí inú mi dùn sí gidigidi.”

12 (G)Lẹ́sẹ̀kan náà, Ẹ̀mí Mímọ́ sì darí Jesu sí ijù, 13 Ó sì wà ní ogójì ọjọ́ ní aginjù. A sì ti ọwọ́ Satani dán an wò, ó sì wà pẹ̀lú àwọn ẹranko ìgbẹ́. Àwọn angẹli sì ń ṣe ìránṣẹ́ fún un.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.