Book of Common Prayer
Ti Dafidi.
37 Má ṣe ìkanra nítorí àwọn olùṣe búburú,
kí ìwọ má sì ṣe ṣe ìlara nítorí àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀;
2 nítorí pé wọn yóò gbẹ bí i koríko,
wọn yóò sì rẹ̀ dànù bí ewéko tútù.
3 Gbẹ́kẹ̀lé Olúwa, kí o sì máa ṣe rere;
torí pé ìwọ yóò gbé ilẹ̀ náà, kí o sì gbádùn ààbò rẹ̀.
4 Ṣe inú dídùn sí Olúwa;
òun yóò sì fún ọ ní ìfẹ́ inú rẹ̀.
5 Fi ọ̀nà rẹ lé Olúwa lọ́wọ́;
gbẹ́kẹ̀lé pẹ̀lú, òun yóò sì ṣe é.
6 Yóò sì mú kí òdodo rẹ̀ jáde bí ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀,
àti ìdájọ́ rẹ̀ bí ọ̀sán gangan.
7 Ìwọ dákẹ́ jẹ́ẹ́ níwájú Olúwa,
kí o sì fi sùúrù dúró dè é;
má ṣe ṣe ìkanra nítorí àwọn tí ń rí rere ní ọ̀nà wọn,
nítorí ọkùnrin náà ti mú èrò búburú ṣẹ.
8 Fàsẹ́yìn nínú inúbíbí, kí o sì kọ ìkáàánú sílẹ̀,
má ṣe ṣe ìkanra, kí ó má ba à ṣé búburú pẹ̀lú.
9 Nítorí tí á ó gé àwọn olùṣe búburú kúrò,
ṣùgbọ́n àwọn tí ó bá dúró de Olúwa àwọn ni yóò jogún ilẹ̀ náà.
10 Síbẹ̀ nígbà díẹ̀ sí i, àwọn ènìyàn búburú kì yóò sí mọ̀;
nítòótọ́ ìwọ yóò fi ara balẹ̀ wo ipò rẹ̀, wọn kì yóò sí níbẹ̀.
11 Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò jogún ilẹ̀ náà,
wọn yóò sì máa ṣe inú dídùn nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà.
12 Ènìyàn búburú di rìkíṣí sí olóòtítọ́,
wọ́n sì pa eyín wọn keke sí wọn;
13 ṣùgbọ́n Olúwa rẹ́rìn-ín sí àwọn ènìyàn búburú,
nítorí tí ó rí wí pé ọjọ́ wọn ń bọ̀.
14 Ènìyàn búburú fa idà yọ,
wọ́n sì tẹ àwọn ọrun wọn,
láti sọ tálákà àti aláìní kalẹ̀,
láti pa àwọn tí ó dúró ṣinṣin.
15 Idà wọn yóò wọ àyà wọn lọ,
àti wí pé ọrun wọn yóò sì ṣẹ́.
16 Ohun díẹ̀ tí olódodo ní,
sàn ju ọ̀pọ̀ ọrọ̀ ènìyàn búburú;
17 nítorí pé a óò ṣẹ́ ọwọ́ àwọn ènìyàn búburú,
ṣùgbọ́n Olúwa gbé olódodo sókè.
18 Olúwa mọ àwọn ọjọ́ àwọn tó dúró ṣinṣin,
àti wí pé ilẹ̀ ìní wọn yóò wà títí ayérayé;
19 Ojú kì yóò tì wọ́n ní àkókò ibi,
àti ní ọjọ́ ìyàn, a ó tẹ́ wọn lọ́rùn.
20 Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn búburú yóò ṣègbé.
Àwọn ọ̀tá Olúwa yóò dàbí ẹwà oko tútù;
wọn fò lọ; bi èéfín ni wọn yóò fò lọ kúrò.
21 Àwọn ènìyàn búburú yá, wọn kò sì san án padà,
ṣùgbọ́n àwọn olódodo a máa ṣàánú, a sì máa fi fún ni;
22 Nítorí àwọn tí Olúwa bá bùkún ni yóò jogún ilẹ̀ náà,
àwọn tí ó fi bú ni a ó gé kúrò.
23 Ìlànà ìgbésẹ̀ ènìyàn rere wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa wá,
o sì ṣe inú dídùn sí ọ̀nà rẹ̀;
24 Bí ó tilẹ̀ ṣubú a kì yóò ta á nù pátápátá,
nítorí tí Olúwa di ọwọ́ rẹ̀ mú.
25 Èmi ti wà ni èwe, báyìí èmi sì dàgbà;
síbẹ̀ èmi kò ì tí ì ri kí a kọ olódodo sílẹ̀,
tàbí kí irú-ọmọ rẹ̀ máa ṣagbe oúnjẹ.
26 Aláàánú ni òun nígbà gbogbo a máa yá ni;
a sì máa bùsi i fún ni.
27 Lọ kúrò nínú ibi, kí o sì máa ṣe rere;
nígbà náà ni ìwọ yóò gbé ní ilẹ̀ náà títí láéláé.
28 Nítorí pé Olúwa fẹ́ràn ìdájọ́ òtítọ́,
kò sì kọ àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀ sílẹ̀.
Àwọn olódodo ni a ó pamọ́ títí ayérayé,
ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ènìyàn búburú ni a ó ké kúrò.
29 Olódodo ni yóò jogún ilẹ̀ náà,
yóò sì máa gbé ibẹ̀ títí ayérayé.
30 Ẹnu olódodo sọ̀rọ̀ ọgbọ́n,
ahọ́n rẹ̀ a sì máa sọ̀rọ̀ ìdájọ́.
31 Òfin Ọlọ́run rẹ̀ ń bẹ ní àyà wọn;
àwọn ìgbésẹ̀ rẹ̀ kì yóò yẹ̀.
32 Ènìyàn búburú ń ṣọ́ olódodo,
Ó sì ń wá ọ̀nà láti pa á.
33 Olúwa kì yóò fi lé e lọ́wọ́ kì yóò sì dá a lẹ́bi,
nígbà tí a bá ń ṣe ìdájọ́ rẹ̀.
34 Dúró de Olúwa,
kí o sì máa pa ọ̀nà rẹ̀ mọ́.
Yóò sì gbé ọ lékè láti jogún ilẹ̀ náà;
nígbà tí a bá gé àwọn ènìyàn búburú kúrò ìwọ yóò ri.
35 Èmi ti rí ènìyàn búburú tí ń hu ìwà ìkà,
ó sì fi ara rẹ̀ gbilẹ̀ bí igi tútù ńlá,
36 ṣùgbọ́n ní ìṣẹ́jú kan sí i ó kọjá lọ, sì kíyèsi, kò sì sí mọ́;
bi ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé mo wá a kiri, ṣùgbọ́n a kò le è ri.
37 Máa kíyèsi ẹni pípé, kí o sì wo ẹni tó dúró ṣinṣin;
nítorí àlàáfíà ni òpin ọkùnrin náà.
38 Ṣùgbọ́n àwọn olùrékọjá ni a ó parun papọ̀;
ìran àwọn ènìyàn búburú ni a ó gé kúrò.
39 Ìgbàlà àwọn onídùúró ṣinṣin wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa;
òun ni ààbò wọn ní ìgbà ìpọ́njú
40 Olúwa yóò ràn wọ́n lọ́wọ́ yóò sì gbà wọ́n;
yóò gbà wọ́n lọ́wọ́ ènìyàn búburú, yóò sì gbà wọ́n là,
nítorí tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé e.
Àdúrà Habakuku
3 Àdúrà wòlíì Habakuku gẹ́gẹ́ bí sígónótì. Ohun èlò orin.
2 Olúwa mo tí gbọ́ ohùn rẹ;
ẹ̀rù sì ba mi fún iṣẹ́ rẹ Olúwa
sọ wọn di ọ̀tún ní ọjọ́ ti wa,
ní àkókò tiwa, jẹ́ kó di mí mọ̀;
ni ìbínú, rántí àánú.
3 Ọlọ́run yóò wa láti Temani,
ibi mímọ́ jùlọ láti Òkè Parani
ògo rẹ̀ sí bo àwọn ọ̀run,
ilé ayé sì kún fún ìyìn rẹ
4 Dídán rẹ sí dàbí ìmọ́lẹ̀ oòrùn
ìtànṣán ìmọ́lẹ̀ jáde wa láti ọwọ́ rẹ,
níbi tí wọn fi agbára rẹ̀ pamọ́ sí.
5 Àjàkálẹ̀-ààrùn ń lọ ni iwájú rẹ;
ìyọnu sí ń tọ ẹsẹ̀ rẹ lọ.
6 Ó dúró, ó sì mi ayé;
ó wò, ó sì mú àwọn orílẹ̀-èdè wárìrì
a sì tú àwọn òkè ńlá ayérayé ká,
àwọn òkè kéékèèkéé ayérayé sì tẹríba:
ọ̀nà rẹ ayérayé ni.
7 Mo rí àgọ́ Kuṣani nínú ìpọ́njú
àti àwọn ibùgbé Midiani nínú ìrora.
8 Ǹjẹ́ ìwọ ha ń bínú sí àwọn Odò nì, Olúwa?
Ǹjẹ́ ìbínú rẹ wa lórí àwọn odò ṣíṣàn bí?
Ìbínú rẹ ha wá sórí Òkun
tí ìwọ fi ń gun ẹṣin,
àti kẹ̀kẹ́ ìgbàlà rẹ?
9 A ṣí ọrun rẹ sílẹ̀ pátápátá,
gẹ́gẹ́ bí ìbúra àwọn ẹ̀yà, àní ọ̀rọ̀ rẹ,
ìwọ sì fi odò pín ilẹ̀ ayé.
10 Àwọn òkè ńlá ri ọ wọn sì wárìrì
àgbàrá òjò ń sàn án kọjá lọ;
ibú ń ké ramúramù
ó sì gbé irú omi sókè.
11 Òòrùn àti Òṣùpá dúró jẹ́ẹ́jẹ́ ni ibùgbé wọn,
pẹ̀lú ìmọ́lẹ̀ ọfà rẹ ni wọn yára lọ,
àti ni dídán ọ̀kọ̀ rẹ ti ń kọ mànà.
12 Ní ìrunú ni ìwọ rin ilẹ̀ náà já,
ní ìbínú ni ìwọ tí tẹ́ àwọn orílẹ̀-èdè rẹ.
13 Ìwọ jáde lọ láti tú àwọn ènìyàn rẹ sílẹ̀,
àti láti gba ẹni ààmì òróró rẹ là;
Ìwọ ti run àwọn olórí kúrò nínú ilẹ̀ àwọn ènìyàn búburú,
ó sì bọ ìhámọ́ra rẹ láti orí de ẹsẹ̀
14 Pẹ̀lú ọ̀kọ̀ rẹ̀ kí ó fi gún orí rẹ
nígbà tí àwọn jagunjagun rẹ̀
jáde láti tú wá ká:
ayọ̀ wọn sì ni láti jẹ tálákà run ní ìkọ̀kọ̀.
15 Ìwọ fi ẹṣin rẹ rìn Òkun já,
ó sì da àwọn omi ńlá ru.
16 Mo gbọ́, ọkàn mi sì wárìrì,
ètè mi sì gbọ̀n sí ìró náà;
ìbàjẹ́ sì wọ inú egungun mi lọ,
ẹsẹ̀ mi sì wárìrì,
mo dúró ni ìdákẹ́ jẹ́ẹ́ fún ọjọ́ ìdààmú
láti de sórí àwọn ènìyàn tó ń dojúkọ wá.
17 Bí igi ọ̀pọ̀tọ́ ko tilẹ̀ tanná,
tí èso kò sí nínú àjàrà;
tí igi olifi ko le so,
àwọn oko ko sì mú oúnjẹ wá;
tí a sì ké agbo ẹran kúrò nínú agbo,
tí kò sì sí ọwọ́ ẹran ni ibùso mọ́,
18 síbẹ̀, èmi ó láyọ̀ nínú Olúwa,
èmi yóò sí máa yọ nínú Ọlọ́run ìgbàlà mi.
12 Kì í ṣe pé ọwọ́ mi ti tẹ̀ ẹ́ ná, tàbí mo ti di pípé: ṣùgbọ́n èmi ń lépa sí i, bí ọwọ́ mi yóò lè tẹ èrè náà nítorí èyí tí a ti dì mímú pẹ̀lú, láti ọ̀dọ̀ Kristi Jesu wá. 13 Ará, èmi kò kara mi sí ẹni ti ọwọ́ rẹ̀ ti tẹ̀ ẹ́ ná: Ṣùgbọ́n ohun kan yìí ni èmi ń ṣe, èmi ń gbàgbé àwọn nǹkan tí ó ti kọjá. Lẹ́yìn náà mo ń nàgà wo àwọn nǹkan tí ó wà níwájú. 14 Èmi ń lépa láti dé òpin eré ìje náà fún èrè ìpè gíga Ọlọ́run nínú Kristi Jesu.
15 Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí àwa tí a dàgbà nípa ti ẹ̀mí ni èrò yìí; bí ẹ̀yin bá sì ní èrò mìíràn nínú ohunkóhun, èyí náà pẹ̀lú ni Ọlọ́run yóò fihàn yín. 16 Kìkì pé, ki a ma gbe ìgbé ayé gẹ́gẹ́ bi èyí ti a ri gba.
17 (A)Ará, ẹ jùmọ̀ ṣe àfarawé mi, ẹ ṣe àkíyèsí àwọn tí ń rìn bẹ́ẹ̀, àní bí ẹ ti ní wa fún àpẹẹrẹ. 18 Nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ní ń rìn, nípasẹ̀ àwọn ẹni tí mo ti ń wí fún yín nígbàkúgbà, àní, tí mo sì ń sọkún bí mo ti ń wí fún yín nísinsin yìí, pé, ọ̀tá àgbélébùú Kristi ni wọ́n: 19 Ìgbẹ̀yìn wọn ni ìparun, ikùn wọn sì ni Ọlọ́run wọn, wọ́n sì ń ṣògo nínú ìtìjú wọn, àwọn ẹni tí ń tọ́jú ohun ti ayé. 20 Nítorí ìlú ìbílẹ̀ wá ń bẹ̀ ní ọ̀run: láti ibi ti àwa pẹ̀lú gbé ń fojúsọ́nà fún Olùgbàlà, Jesu Kristi Olúwa. 21 (B)Ẹni tí yóò sọ ara ìrẹ̀lẹ̀ wa di ọ̀tún kí ó lè bá ara ògo rẹ̀ mu, nípa agbára tí ó mú kí ó ṣe é ṣe fún un láti tẹ orí ohun gbogbo bá fún ara rẹ̀.
Jesu gbàdúrà fún ara rẹ̀
17 (A)Nǹkan wọ̀nyí ni Jesu sọ, ó sì gbé ojú rẹ̀ sókè ọ̀run, ó sì wí pé:
“Baba, wákàtí náà dé, yin ọmọ rẹ lógo, kí ọmọ rẹ kí ó lè yìn ọ́ lógo pẹ̀lú. 2 Gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti fún un ní àṣẹ lórí ènìyàn gbogbo, kí ó lè fi ìyè àìnípẹ̀kun fún gbogbo àwọn tí ó fi fún un. 3 Ìyè àìnípẹ̀kun náà sì ni èyí, kí wọn kí ó lè mọ ìwọ nìkan Ọlọ́run òtítọ́, àti Jesu Kristi, ẹni tí ìwọ rán. 4 Èmi ti yìn ọ́ lógo ní ayé: èmi ti parí iṣẹ́ tí ìwọ fi fún mi láti ṣe. 5 (B)Ǹjẹ́ nísinsin yìí, Baba, ṣe mí lógo pẹ̀lú ara rẹ, ògo tí mo ti ní pẹ̀lú rẹ kí ayé kí ó tó wà.
Jesu gbàdúrà fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn
6 “Èmi ti fi orúkọ rẹ hàn fún àwọn ènìyàn tí ìwọ ti fún mi láti inú ayé wá: tìrẹ ni wọ́n ti jẹ́, ìwọ sì ti fi wọ́n fún mi; wọ́n sì ti pa ọ̀rọ̀ rẹ mọ́. 7 Nísinsin yìí, wọ́n mọ̀ pé ohunkóhun gbogbo tí ìwọ ti fi fún mi, láti ọ̀dọ̀ rẹ wá ni. 8 Nítorí ọ̀rọ̀ tí ìwọ fi fún mi, èmi ti fi fún wọn, wọ́n sì ti gbà á, wọ́n sì ti mọ̀ nítòótọ́ pé, lọ́dọ̀ rẹ ni mo ti jáde wá, wọ́n sì gbàgbọ́ pé ìwọ ni ó rán mi.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.