Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Book of Common Prayer

Daily Old and New Testament readings based on the Book of Common Prayer.
Duration: 861 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 148-150

148 Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.

Ẹ fi ìyìn fún Olúwa láti ọ̀run wá,
    Ẹ fi ìyìn fún un níbi gíga.
Ẹ fi ìyìn fún un,
    gbogbo ẹ̀yin angẹli rẹ̀
Ẹ fi ìyìn fún un,
    gbogbo ẹ̀yin ọmọ-ogun rẹ̀
Ẹ fi ìyìn fún un,
    oòrùn àti òṣùpá
Ẹ fi ìyìn fún un,
    gbogbo ẹ̀yin ìràwọ̀ ìmọ́lẹ̀.
Ẹ fi ìyìn fún un,
    ẹ̀yin ọ̀run àti àwọn ọ̀run gíga
    àti ẹ̀yin omi tí ń bẹ ní òkè ọ̀run.

Ẹ jẹ́ kí wọn kí ó yin orúkọ Olúwa
    nítorí ó pàṣẹ a sì dá wọn
Ó fi ìdí wọn múlẹ̀ láé àti láéláé
    ó sì ti ṣe ìlànà kan tí kì yóò já.

Ẹ yin Olúwa láti ilẹ̀ ayé wá
    ẹ̀yin ẹ̀dá inú Òkun títóbi
    àti ẹ̀yin ibú Òkun
Mọ̀nàmọ́ná àti òjò yìnyín
    ìdí omi àti àwọn ìkùùkuu,
    ìjì líle tí ń mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ;
Òkè ńlá àti gbogbo òkè kéékèèkéé,
    igi eléso àti gbogbo igi kedari,
10 Àwọn ẹranko ńlá àti ẹran ọ̀sìn
    gbogbo ohun afàyàfà àti àwọn ẹyẹ abìyẹ́:
11 Àwọn ọba ayé àti ènìyàn ayé gbogbo
    àwọn ọmọ-aládé àti gbogbo àwọn onídàájọ́ ayé,
12 Ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin
    àwọn arúgbó àti àwọn ọmọdé.

13 Ẹ jẹ́ kí wọn kí ó yin orúkọ Olúwa
    nítorí orúkọ rẹ̀ nìkan ni ó ní ọlá
    ògo rẹ̀ kọjá ayé àti ọ̀run
14 Ó sì gbé ìwo kan sókè fún àwọn ènìyàn rẹ̀,
    ìyìn fún gbogbo ènìyàn mímọ́ rẹ̀ àní fún àwọn ọmọ Israẹli,
    àwọn ènìyàn tí ó súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ̀.

Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.
149 Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.

Ẹ kọrin tuntun sí Olúwa.
    Ẹ yìn ín ní àwùjọ àwọn ènìyàn mímọ́.

Jẹ́ kí Israẹli kí ó ní inú dídùn sí ẹni tí ó dá a
    jẹ́ kí àwọn ọmọ Sioni kí ó ní
    ayọ̀ nínú ọba wọn.
Jẹ́ kí wọn kí ó fi ijó yin orúkọ rẹ̀
    jẹ́ kí wọn kí ó fi ohun èlò orin kọrin ìyìn sí i.
Nítorí Olúwa ní inú dídùn sí àwọn ènìyàn rẹ̀
    ó fi ìgbàlà dé àwọn onírẹ̀lẹ̀ ládé
Jẹ́ kí àwọn ènìyàn mímọ́ kí ó yọ̀ nínú ọlá rẹ̀
    kí wọn kí ó máa kọrin fún ayọ̀ ní orí ibùsùn wọn.

Kí ìyìn Ọlọ́run kí ó wà ní ẹnu wọn
    àti idà olójú méjì ní ọwọ́ wọn.
Láti gba ẹ̀san lára àwọn orílẹ̀-èdè,
    àti ìjìyà lára àwọn ènìyàn,
Láti fi ẹ̀wọ̀n de àwọn ọba wọn
    àti láti fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀
irin de àwọn ọlọ́lá wọn.
Láti ṣe ìdájọ́ tí àkọsílẹ̀ rẹ̀ sí wọn
    èyí ni ògo àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀.

Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.
150 Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.

Ẹ fi ìyìn fún Ọlọ́run ní ibi mímọ́ rẹ̀
    Ẹ yìn ín nínú agbára ọ̀run rẹ̀.
Ẹ yìn ín fún iṣẹ́ agbára rẹ̀.
    Ẹ yìn ín fún títóbi rẹ̀ tí ó tayọ̀.
Ẹ fi ohùn ìpè yìn ín.
    Ẹ fi ohun èlò orin yìn ín.
Ẹ fi ohun èlò orin àti ijó yìn ín
    fi ohun èlò orin olókùn àti ìpè yìn ín
Ẹ yìn ín pẹ̀lú aro olóhùn òkè,
    Ẹ yìn ín lára aro olóhùn gooro.

Jẹ́ kí gbogbo ohun tí ó ní ẹ̀mí yin Olúwa.

Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.

Saamu 114-115

114 Nígbà tí Israẹli jáde ní Ejibiti,
    ilé Jakọbu láti inú ènìyàn àjèjì èdè
Juda wà ní ibi mímọ́,
    Israẹli wà ní ìjọba.

(A)Òkun sì rí i, ó sì wárìrì:
    Jordani sì padà sẹ́yìn.
Àwọn òkè ńlá ń fò bí àgbò àti
    òkè kéékèèkéé bí ọ̀dọ́-àgùntàn.

Kí ni ó ṣe ọ́, ìwọ Òkun, tí ìwọ fi wárìrì?
    Ìwọ Jordani, tí ìwọ fi padà sẹ́yìn?
Ẹ̀yin òkè ńlá kí ló dé ti ẹ fi ń fò bí àgbò,
    àti ẹ̀yin òkè kéékèèkéé bí ọ̀dọ́-àgùntàn?

Wárìrì, ìwọ ilẹ̀, níwájú Olúwa;
    ní iwájú Ọlọ́run Jakọbu
tí ó sọ àpáta di adágún omi,
    àti òkúta-ìbọn di orísun omi.
115 Kì í ṣe fún wa, Olúwa kì í ṣe fún wa,
    ṣùgbọ́n fún orúkọ rẹ ni a fi ògo fún,
    fún àánú àti òtítọ́ rẹ.

Torí kí ni àwọn kèfèrí yóò ṣe sọ pé,
    níbo ni Ọlọ́run wa wà.
Ṣùgbọ́n Ọlọ́run wa wà lọ́run:
    tí ó ń ṣe èyí tí ó wù ú.
(B)Fàdákà òun wúrà ni èrè àwọn aláìkọlà,
    iṣẹ́ ọwọ́ ènìyàn ni,
Wọ́n ní ẹnu, ṣùgbọ́n wọn kò le sọ̀rọ̀,
    wọ́n ní ojú, ṣùgbọ́n wọn kò fi ríran.
Wọ́n ní etí, ṣùgbọ́n wọn kò fi gbọ́rọ̀:
    wọ́n ní imú, ṣùgbọ́n wọn kò fi gbóòórùn
Wọ́n ní ọwọ́, ṣùgbọ́n wọn kò lò ó,
    wọ́n ní ẹsẹ̀, ṣùgbọ́n wọn kò rìn;
    bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sọ̀rọ̀ nínú òfin wọn.
Àwọn tí ń ṣe wọ́n dàbí wọn;
    gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni olúkúlùkù ẹni tí ó gbẹ́kẹ̀ rẹ̀ lé wọn.

Ìwọ Israẹli gbẹ́kẹ̀lé Olúwa:
    òun ni ìrànwọ́ àti ààbò wọn
10 Ẹ̀ yin ilé Aaroni, gbẹ́kẹ̀lé Olúwa:
    òun ni ìrànwọ́ àti ààbò wọn
11 Ẹ̀ yin tí ó bẹ̀rù Olúwa, gbẹ́kẹ̀lé Olúwa:
    òun ní ìrànwọ́ àti ààbò wọn.

12 Olúwa tí ń ṣe ìrántí wa; yóò bùkún ilé Israẹli;
    yóò bùkún ilé Aaroni.
13 (C)Ìbùkún ni fún àwọn tí ó bẹ̀rù Olúwa,
    àti kékeré àti ńlá.

14 Olúwa yóò mú ọ pọ̀ sí i síwájú àti síwájú,
    ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ̀.
15 Ẹ fi ìbùkún fún Olúwa
    ẹni tí ó dá ọ̀run òun ayé.

16 Ọ̀run àní ọ̀run ni ti Olúwa:
    ṣùgbọ́n ayé ló fi fún ọmọ ènìyàn.
17 Òkú kò lè yìn Olúwa,
    tàbí ẹni tí ó ti lọ sí ìsàlẹ̀ ìdákẹ́ jẹ́ẹ́.
18 Ṣùgbọ́n àwa ó fi ìbùkún fún Olúwa
    láti ìsinsin yìí lọ àti títí láéláé.

Ẹ yin Olúwa.

Error: Book name not found: Sir for the version: Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
2 Kọrinti 3:7-18

Ògo tó wà nínú májẹ̀mú tuntun

(A)Ṣùgbọ́n bí iṣẹ́ ìránṣẹ́ tí ikú, tí a tí kọ tí a sì ti gbẹ́ sí ara òkúta bá jẹ́ ológo tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn ọmọ Israẹli kò lè tẹjúmọ́ wíwo ojú Mose nítorí ògo ojú rẹ̀ (ògo ti ń kọjá lọ); yóò ha ti rí tí iṣẹ́ ìránṣẹ́ ti ẹ̀mí kì yóò kúkú jẹ́ ògo jù? Nítorí pé bi iṣẹ́ ìránṣẹ́ ìdálẹ́bi bá jẹ́ ológo, mélòó mélòó ni iṣẹ́ ìránṣẹ́ òdodo yóò tayọ jù ú ní ògo. 10 Nítorí, èyí tí a tí ṣe lógo rí, kó lógo mọ́ báyìí, nítorí ògo tí ó tayọ. 11 Nítorí pé bí èyí ti ń kọjá lọ bá lógo, mélòó mélòó ni èyí tí ó dúró kí yóò ní ògo!

12 Ǹjẹ́ nítorí náà bí a tí ní irú ìrètí bí èyí, àwa ń fi ìgboyà púpọ̀ sọ̀rọ̀. 13 Kì í sì í ṣe bí Mose, ẹni tí ó fi ìbòjú bo ojú rẹ̀, ki àwọn ọmọ Israẹli má ba à lè tẹjúmọ́ wíwo òpin èyí tí ń kọjá lọ 14 Ṣùgbọ́n ojú inú wọn fọ́; nítorí pé títí fi di òní olónìí nípa kíka májẹ̀mú láéláé, ìbòjú kan náà ṣì wà láìká kúrò; nítorí pé nínú Kristi ni a tí lè mú ìbòjú náà kúrò. 15 Ṣùgbọ́n títí di òní olónìí, nígbàkúgbà ti a bá ń ka Mose, ìbòjú náà ń bẹ lọ́kàn wọn. 16 Ṣùgbọ́n nígbà ti òun bá yípadà sí Olúwa, a ó mú ìbòjú náà kúrò. 17 (B)Ǹjẹ́ Olúwa ni Ẹ̀mí náà: níbi tí Ẹ̀mí Olúwa bá sì wà, níbẹ̀ ni òmìnira gbé wà 18 Ṣùgbọ́n gbogbo wa ń wo ògo Olúwa láìsí ìbòjú bí ẹni pé nínú àwòjìji, a sì ń pa wa dà sí àwòrán kan náà láti ògo dé ògo, àní bí láti ọ̀dọ̀ Olúwa tí í ṣe Ẹ̀mí.

Luku 9:18-27

Peteru pe Jesu ní ọmọ Ọlọ́run

18 (A)(B) Ó sì ṣe, nígbà tí ó ku òun nìkan ó gbàdúrà, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì wà lọ́dọ̀ rẹ̀: ó sì bi wọ́n pé, “Ta ni àwọn ènìyàn ń fi mí pè?”

19 (C)Wọ́n sì dáhùn wí pé, “Johanu Onítẹ̀bọmi; ṣùgbọ́n ẹlòmíràn ní Elijah ni; àti àwọn ẹlòmíràn wí pé, ọ̀kan nínú àwọn wòlíì àtijọ́ ni ó jíǹde.”

20 Ó sì bi wọ́n pé, “Ṣùgbọ́n ta ni ẹ̀yin ń fi èmi pè?”

Peteru sì dáhùn, wí pe, “Kristi ti Ọlọ́run.”

21 Ó sì kìlọ̀ fún wọn, pé, kí wọn má ṣe sọ èyí fún ẹnìkan. 22 (D)Ó sì wí pé, “Ọmọ ènìyàn yóò jìyà ohun púpọ̀, a ó sì kọ̀ ọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn alàgbà, olórí àlùfáà àti láti ọ̀dọ̀ àwọn akọ̀wé, a ó sì pa á, ní ọjọ́ kẹta a ó sì jí i dìde.”

23 (E)Ó sì wí fún gbogbo wọn pé, “Bí ẹnìkan bá ń fẹ́ láti máa tọ̀ mí lẹ́yìn, kí ó sẹ́ ara rẹ̀, kí ó sì gbé àgbélébùú rẹ̀ ní ọjọ́ gbogbo, kí ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn. 24 (F)Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ gba ọkàn rẹ̀ là, yóò sọ ọ́ nù: ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ ọkàn rẹ̀ nù nítorí mi, òun náà ni yóò sì gbà á là. 25 Nítorí pé èrè kín ni fún ènìyàn, bí ó jèrè gbogbo ayé, tí ó sì sọ ara rẹ̀ nù tàbí kí ó fi ṣòfò. 26 (G)Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá tijú mi, àti ọ̀rọ̀ mi, òun ni ọmọ ènìyàn yóò tijú rẹ̀ nígbà tí ó bá dé inú ògo tirẹ̀, àti ti baba rẹ̀, àti ti àwọn angẹli mímọ́.

27 (H)“Ṣùgbọ́n èmi wí fún yín nítòótọ́, ẹlòmíràn dúró níhìn-ín yìí, tí kì yóò rí ikú, títí wọn ó fi rí ìjọba Ọlọ́run.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.