Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Book of Common Prayer

Daily Old and New Testament readings based on the Book of Common Prayer.
Duration: 861 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 38

Saamu Dafidi. Ẹ̀bẹ̀.

38 Olúwa, Má ṣe bá mi wí nínú ìbínú rẹ,
    bẹ́ẹ̀ ni kí o má ṣe fi ìyà jẹ mí nínú ìrunú rẹ̀.
Nítorí tí ọfà rẹ kàn mọ́ mi ṣinṣin,
    ọwọ́ rẹ sì kì mí mọ́lẹ̀.
Kò sí ibi yíyè ní ara à mi, nítorí ìbínú rẹ;
    kò sí àlàáfíà nínú egungun mi nítorí i ẹ̀ṣẹ̀ mi.
Nítorí àìṣedéédéé mi ti borí mi mọ́lẹ̀;
    wọ́n tó ìwọ̀n bi àjàgà tí ó wúwo jù fún mi.

Ọgbẹ́ mi ń rùn ó sì díbàjẹ́
    nítorí òmùgọ̀ mi.
Èmi ń jòwèrè, orí mi tẹ̀ ba gidigidi
    èmi ń ṣọ̀fọ̀ rìn kiri ní gbogbo ọjọ́.
Nítorí ẹ̀gbẹ́ mi kún fún ìgbóná tí ń jóni
    kò sì ṣí ibi yíyè ní ara mi,
Ara mi hù, a sì wó mi jẹ́gẹjẹ̀gẹ;
    mo kérora nítorí ìrúkèrúdò àyà mi.

Olúwa, gbogbo ìfẹ́ mi ń bẹ níwájú rẹ;
    ìmí ẹ̀dùn mi kò sápamọ́ fún ọ.
10 Àyà mi ń mí hẹlẹ, agbára mi yẹ̀ mí sílẹ̀;
    bí ó ṣe ti ìmọ́lẹ̀ ojú mi ni, ó ti lọ kúrò lára mi.
11 Àwọn ọ̀rẹ́ mi àti àwọn ẹlẹgbẹ́ mi dúró lókèèrè réré kúrò níbi ìpọ́njú mi,
    àwọn alábágbé mi, dúró lókèèrè.
12 Àwọn tí n wá ẹ̀mí mi dẹ okùn sílẹ̀ fún mi;
    àti àwọn tí ó fẹ́ pa mí lára ń sọ̀rọ̀ nípa ìparun,
    wọ́n sì ń gbèrò ẹ̀tàn ní gbogbo ọjọ́.

13 Ṣùgbọ́n mo dàbí adití odi, èmi kò gbọ́ ọ̀rọ̀;
    àti bí odi, tí kò le sọ̀rọ̀.
14 Nítòótọ́, mo rí bí ọkùnrin tí kò gbọ́rọ̀,
    àti bí ẹnu ẹni tí kò sí ìjiyàn.
15 Ṣùgbọ́n sí ọ Olúwa, ìwọ ni mo dúró dè;
    ìwọ ni, Olúwa Ọlọ́run mi, ẹni tí yóò dáhùn.
16 Nítorí tí mo gbàdúrà, “Gbóhùn mi, kí wọn má ba à yọ̀ mí;
    nígbà tí ẹsẹ̀ mi bá yọ̀ wọn yóò máa gbé ara wọn ga sí mi.”

17 Nítorí tí mo ti ṣetán láti ṣubú,
    ìrora mi sì wà pẹ̀lú mi nígbà gbogbo.
18 Mo jẹ́wọ́ ìrékọjá mi;
    àánú sì ṣe mí fún ẹ̀ṣẹ̀ mi.
19 Àwọn tí ó jẹ́ ọ̀tá mi láìnídìí pàtàkì, wọ́n lágbára púpọ̀,
    ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn tí ó kórìíra mi lọ́nà òdì.
20 Àwọn tí wọn ń fi ibi san rere fún mi
    àwọn ni ọ̀tá mi
    nítorí pé mò ń tọ ìre lẹ́yìn.

21 Má ṣe kọ̀ mí sílẹ̀, ìwọ Olúwa!
    Ọlọ́run mi, Má ṣe jìnnà sí mi.
22 Yára láti ràn mí lọ́wọ́,
    Olúwa, Olùgbàlà mi.

Saamu 119:25-48

Àdúrà láti ní òye ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

25 Ọkàn mí lẹ̀ mọ́ erùpẹ̀;
    ìwọ sọ mí di ààyè gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ.
26 Èmi tún ọ̀nà mi ṣírò ìwọ sì dá mi lóhùn;
    kọ́ mi ní àṣẹ rẹ.
27 Jẹ́ kí n mọ ẹ̀kọ́ ìlànà rẹ:
    nígbà náà ni èmi yóò ṣe àṣàrò iṣẹ́ ìyanu rẹ.
28 Ọkàn mi ń ṣe àárẹ̀ pẹ̀lú ìbànújẹ́;
    fi agbára fún mi gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ.
29 Pa mí mọ́ kúrò nínú ọ̀nà ẹ̀tàn
    fún mi ní oore-ọ̀fẹ́ nípa òfin rẹ.
30 Èmi ti yan ọ̀nà òtítọ́
    èmi ti gbé ọkàn mi lé òfin rẹ.
31 Èmi yára di òfin rẹ mú. Olúwa
    má ṣe jẹ́ kí ojú kí ó tì mí.
32 Èmi sáré ní ipa ọ̀nà àṣẹ rẹ,
    nítorí ìwọ, ti tú ọkàn mi sílẹ̀.

Ìlérí Ọlọ́run fún aláforítì

33 Kọ́ mi, Olúwa, láti tẹ̀lé àṣẹ rẹ;
    nígbà náà ni èmi yóò pa wọ́n mọ́ dé òpin.
34 Fún mi ní òye, èmi yóò sì pa òfin rẹ mọ́
    èmi yóò sì máa kíyèsi i pẹ̀lú ọkàn mi.
35 Fi ipa ọ̀nà àṣẹ rẹ hàn mí,
    nítorí nínú rẹ̀ ni èmi rí inú dídùn.
36 Yí ọkàn mi padà sí òfin rẹ
    kí ó má ṣe sí ojúkòkòrò mọ́.
37 Yí ojú mi padà kúrò láti máa wo ohun asán:
    pa ọ̀nà mi mọ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ.
38 Mú ìlérí rẹ sẹ sí ìránṣẹ́ rẹ,
    nítorí òfin rẹ dára.
39 Yí ẹ̀gàn mi padà tí mo bẹ̀rù
    nítorí tí ìdájọ́ rẹ dára.
40 Kíyèsi i, ọkàn mi ti fà sí ẹ̀kọ́ rẹ!
    Pa ayé mi mọ́ nínú òdodo rẹ.

Ìgbàlà láti inú òfin Ọlọ́run

41 Jẹ́ kí ìfẹ́ rẹ tí kì í kùnà wá bá mi, Olúwa,
    ìgbàlà rẹ gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ;
42 Nígbà náà ni èmi yóò dá
    ẹni tí ń sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí mi lóhùn,
    nítorí èmi gbẹ́kẹ̀lé ọ̀rọ̀ rẹ.
43 Má ṣe gba ọ̀rọ̀ òtítọ́ láti ẹnu mi
    nítorí èmi ti gbé ìrètí mi sínú àṣẹ rẹ
44 Èmi yóò máa gbọ́rọ̀ sí òfin rẹ nígbà gbogbo
    láé àti láéláé.
45 Èmi yóò máa rìn káàkiri ní òmìnira,
    nítorí èmi ti kígbe ẹ̀kọ́ rẹ jáde.
46 Èmi yóò sọ̀rọ̀ òfin rẹ níwájú àwọn ọba
    ojú kì yóò sì tì mí,
47 Nítorí èmi ní inú dídùn nínú àṣẹ rẹ
    nítorí èmi ní ìfẹ́ wọn.
48 Èmi gbé ọwọ́ mi sókè nítorí àṣẹ rẹ, èyí tí èmi fẹ́ràn,
    èmi sì ń ṣe àṣàrò òfin rẹ̀.

Gẹnẹsisi 9:18-29

Àwọn ọmọ Noa

18 Àwọn ọmọ Noa tí ó jáde nínú ọkọ̀ ni Ṣemu, Hamu àti Jafeti. (Hamu ni baba Kenaani). 19 Láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Noa mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí ni gbogbo ènìyàn ti tàn ká gbogbo ilẹ̀ ayé.

20 Noa bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ àgbẹ̀, ó sì gbin ọgbà àjàrà. 21 Ó mu àmupara nínú ọtí wáìnì àjàrà rẹ̀, ó sì tú ara rẹ̀ sí ìhòhò, ó sì sùn nínú àgọ́ rẹ̀. 22 Hamu tí í ṣe baba Kenaani sì rí baba rẹ̀ ní ìhòhò bẹ́ẹ̀ ni ó sì lọ sọ fún àwọn arákùnrin rẹ̀ méjèèjì ní ìta. 23 Ṣùgbọ́n Ṣemu àti Jafeti mú aṣọ lé èjìká wọn, wọ́n sì fi ẹ̀yìn rìn, wọ́n sì bo ìhòhò baba wọn. Wọ́n kọjú sẹ́yìn kí wọn kí ó má ba à rí ìhòhò baba wọn.

24 Nígbà tí Noa kúrò ní ojú ọtí, tí ó sì mọ ohun tí ọmọ rẹ̀ kékeré ṣe sí i. 25 Ó wí pé:

“Ègún ni fún Kenaani.
    Ìránṣẹ́ àwọn ìránṣẹ́ ni yóò máa ṣe
    fún àwọn arákùnrin rẹ̀.”

26 Ó sì tún wí pé;

“Olùbùkún ni Olúwa, Ọlọ́run Ṣemu
    Kenaani yóò máa ṣe ẹrú fún Ṣemu.
27 Ọlọ́run yóò mú Jafeti gbilẹ̀,
    Jafeti yóò máa gbé ní àgọ́ Ṣemu
    Kenaani yóò sì jẹ́ ẹrú fún un.”

28 Noa wà láààyè fún irínwó ọdún ó-dínàádọ́ta (350) lẹ́yìn ìkún omi. 29 Àpapọ̀ ọjọ́ ayé Noa jẹ́ ẹgbẹ̀rún-dín-ní-àádọ́ta ọdún, (950) ó sì kú.

Heberu 6:1-12

Nítorí náà, ó yẹ kí á fi àwọn ẹ̀kọ́ ìgbà tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ gba Kristi sílẹ̀, kí á tẹ̀síwájú nínú àwọn ẹ̀kọ́ tí yóò mú wa dàgbàsókè ní pípé. Láìtún ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ máa tẹnumọ́ ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ bí i ìrònúpìwàdà kúrò nínú òkú iṣẹ́ àti ìgbàgbọ́ nípa ti Ọlọ́run, ti ẹ̀kọ́ àwọn bamitiisi, àti ti ìgbọ́wọ́-léni, ti àjíǹde òkú, àti tí ìdájọ́ àìnípẹ̀kun. Èyí ní àwa yóò sì ṣe bí Ọlọ́run bá fẹ́.

Nítorí pé, kò ṣe é ṣe fún àwọn tí a ti là lójú lẹ́ẹ̀kan, tí wọ́n sì ti tọ́ ẹ̀bùn ọ̀run wò, tí wọn sì ti di alábápín Ẹ̀mí Mímọ́, tí wọn sì tọ́ ọ̀rọ̀ rere Ọlọ́run wò, àti agbára ayé tí ń bọ̀, láti tún sọ wọ́n di ọ̀tun sí ìrònúpìwàdà bí wọn bá ṣubú kúrò; nítorí tí wọ́n tún kan ọmọ Ọlọ́run mọ́ àgbélébùú sí ara wọn lọ́tun, wọ́n sì dójútì í ní gbangba. Nítorí ilẹ̀ tí ó ń fa omi òjò tí ń rọ̀ sórí rẹ̀ nígbà gbogbo mu, tí ó sì ń hu ewébẹ̀ tí ó dára fún àwọn tí à ń tìtorí wọn ro ó pẹ̀lú, ń gba ìbùkún lọ́wọ́ Ọlọ́run. (A)Ṣùgbọ́n bí ó ba ń hu ẹ̀gún àti òṣùṣú yóò di kíkọ̀sílẹ̀, kò si jìnnà sí fífi gégùn ún, òpin èyí tí yóò wà fún ìjóná.

Ṣùgbọ́n olùfẹ́, àwa ní ohun tí ó dára jù bẹ́ẹ̀ lọ, ní tiyín, àti ohun tí ó fi ara mọ́ ìgbàlà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé à ń ṣe báyìí sọ̀rọ̀. 10 Nítorí Ọlọ́run kì í ṣe aláìṣòdodo tí yóò fi gbàgbé iṣẹ́ yin àti ìfẹ́ tí ẹ̀yin fihàn sí orúkọ rẹ̀, nípa iṣẹ́ ìránṣẹ́ tí ẹ ti ṣe fún àwọn ènìyàn mímọ́, tí ẹ sì tún ń ṣe. 11 Àwa sì fẹ́ kí olúkúlùkù yín máa fi irú àìsimi kan náà hàn, fún ẹ̀kún ìdánilójú ìrètí títí dé òpin: 12 Kí ẹ má ṣe di onílọ̀ra, ṣùgbọ́n aláfarawé àwọn tí wọn ti ipa ìgbàgbọ́ àti sùúrù jogún àwọn ìlérí.

Johanu 3:22-36

Ẹ̀rí Johanu nípa Jesu

22 (A)Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, Jesu pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wá sí ilẹ̀ Judea; ó sì dúró pẹ̀lú wọn níbẹ̀ ó sì ń ṣe ìtẹ̀bọmi fún ni. 23 Johanu pẹ̀lú sì ń ṣe ìtẹ̀bọmi ní Aenoni, ní agbègbè Salimu, nítorí tí omi púpọ̀ wà níbẹ̀: wọ́n sì ń wá, a sì ń tẹ̀ ẹ́ wọn bọ omi. 24 (B)Nítorí tí a kò tí ì sọ Johanu sínú túbú. 25 Nígbà náà ni iyàn kan wà láàrín àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu àti Júù kan nípa ti ìwẹ̀nù. 26 (C)Wọ́n sì tọ Johanu wá, wọ́n sì wí fún un pé, “Rabbi, ẹni tí ó ti wà pẹ̀lú rẹ lókè odò Jordani, tí ìwọ ti jẹ́rìí rẹ̀, wò ó, òun tẹ àwọn ènìyàn bọ omi, gbogbo ènìyàn sì ń tọ̀ ọ́ wá.”

27 (D)Johanu dáhùn ó sì wí pé, “Ènìyàn kò le rí nǹkan kan gbà, bí kò ṣe pé a bá ti fi fún ún láti ọ̀run wá. 28 (E)Ẹ̀yin fúnrayín jẹ́rìí mi pé mo wí pé, ‘Èmi kì í ṣe Kristi náà, ṣùgbọ́n pé a rán mi síwájú rẹ̀.’ 29 (F)Ẹni tí ó bá ni ìyàwó ni ọkọ ìyàwó; ṣùgbọ́n ọ̀rẹ́ ọkọ ìyàwó tí ó dúró tí ó sì ń gbóhùn rẹ̀, ó ń yọ̀ gidigidi nítorí ohùn ọkọ ìyàwó; nítorí náà ayọ̀ mi yí di kíkún. 30 Òun kò lè ṣàì máa pọ̀ sí i, ṣùgbọ́n èmi kò lè ṣàìmá rẹlẹ̀.

31 (G)“Ẹni tí ó ti òkè wá ju gbogbo ènìyàn lọ; ẹni tí ó ti ayé wá ti ayé ni, a sì máa sọ ohun ti ayé. Ẹni tí ó ti ọ̀run wá ju gbogbo ènìyàn lọ. 32 (H)Ohun tí ó ti rí tí ó sì ti gbọ́ èyí náà sì ni òun ń jẹ́rìí rẹ̀; kò sì sí ẹni tí ó gba ẹ̀rí rẹ̀. 33 Ẹni tí ó gba ẹ̀rí rẹ̀ fi èdìdì dì í pé, olóòtítọ́ ni Ọlọ́run. 34 Nítorí ẹni tí Ọlọ́run ti rán ń sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: nítorí tí Ọlọ́run fi Ẹ̀mí fún un láìsí gbèdéke. 35 Baba fẹ́ Ọmọ, ó sì ti fi ohun gbogbo lé e lọ́wọ́ 36 (I)Ẹni tí ó bá gba Ọmọ gbọ́, ó ní ìyè àìnípẹ̀kun: ẹni tí kò bá sì gba Ọmọ gbọ́, kì yóò rí ìyè; nítorí ìbínú Ọlọ́run ń bẹ lórí rẹ̀.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.