Book of Common Prayer
Ti Dafidi
138 Èmi yóò yìn ọ́ tinútinú mi gbogbo;
níwájú àwọn òrìṣà ni èmi ó kọrin ìyìn sí ọ.
2 Èmi ó máa gbàdúrà sí ìhà tẹmpili mímọ́ rẹ̀
èmi ó sì máa yin orúkọ rẹ
nítorí ìṣeun ìfẹ́ rẹ àti òtítọ́ rẹ;
nítorí ìwọ gbé ọ̀rọ̀ rẹ ga ju orúkọ rẹ lọ.
3 Ní ọjọ́ tí mo ké pè é ọ́, ìwọ dá mi lóhùn,
ìwọ sì fi ipa mú mi lára le ní ọkàn mi.
4 Gbogbo àwọn ọba ayé yóò yìn ọ́,
Olúwa, ní ìgbà tí wọn bá gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ
5 Nítòótọ́, wọn ó máa kọrin ní ipa ọ̀nà Olúwa;
nítorí pé ńlá ni ògo Olúwa.
6 Bí Olúwa tilẹ̀ ga, síbẹ̀ ó júbà àwọn onírẹ̀lẹ̀;
ṣùgbọ́n agbéraga ni ó mọ̀ ní òkèrè réré.
7 Bí èmi tilẹ̀ ń rìn nínú ìpọ́njú ìwọ ni yóò sọ mi di ààyè;
ìwọ ó na ọwọ́ rẹ sí àwọn ọ̀tá mi,
ọwọ́ ọ̀tún rẹ yóò sì gbà mí.
8 Olúwa yóò ṣe ohun tí ń ṣe tèmi láṣepé;
Olúwa, àánú rẹ dúró láéláé;
Má ṣe kọ iṣẹ́ ọwọ́ ara rẹ sílẹ̀.
Fún adarí orin. Ti Dafidi. Saamu.
139 Olúwa, ìwọ tí wádìí mi,
ìwọ sì ti mọ̀ mí.
2 Ìwọ mọ̀ ìjókòó mi àti ìdìde mi,
ìwọ mọ̀ èrò mi ní ọ̀nà jíjìn réré.
3 Ìwọ yí ipa ọ̀nà mi ká àti ìdùbúlẹ̀ mi,
gbogbo ọ̀nà mi sì di mí mọ̀ fún ọ.
4 Nítorí tí kò sí ọ̀rọ̀ kan ní ahọ́n mi,
kíyèsi i, Olúwa, ìwọ mọ̀ ọ́n pátápátá.
5 Ìwọ sé mi mọ́ lẹ́yìn àti níwájú,
ìwọ sì fi ọwọ́ rẹ lé mi.
6 Irú ìmọ̀ yìí jẹ ohun ìyanu fún mi jù;
ó ga, èmi kò le mọ̀ ọ́n.
7 Níbo ní èmi yóò gbé lọ kúrò ni ọwọ́ ẹ̀mí rẹ?
Tàbí níbo ni èmi yóò sáré kúrò níwájú rẹ?
8 Bí èmi bá gòkè lọ sí ọ̀run, ìwọ wà níbẹ̀;
bí èmí ba sì tẹ́ ẹní mi ní ipò òkú,
kíyèsi i, ìwọ wà níbẹ̀ pẹ̀lú.
9 Èmi ìbá mú ìyẹ́ apá òwúrọ̀,
kí èmi sì lọ jókòó ní ìhà òpin Òkun;
10 Àní, níbẹ̀ náà ni ọwọ́ rẹ̀ yóò fà mí
ọwọ́ ọ̀tún rẹ yóò sì dì mímú.
11 Bí mo bá wí pé, “Ǹjẹ́ kí òkùnkùn kí ó bò mí mọ́lẹ̀;
kí ìmọ́lẹ̀ kí ó di òru yí mi ká.”
12 Nítòótọ́ òkùnkùn kì í ṣú lọ́dọ̀ rẹ;
ṣùgbọ́n òru tan ìmọ́lẹ̀ bí ọ̀sán;
àti òkùnkùn àti ọ̀sán, méjèèjì bákan náà ní fún ọ.
13 Nítorí ìwọ ni ó dá ọkàn mi;
ìwọ ni ó bò mí mọ́lẹ̀ nínú ìyá mi.
14 Èmi yóò yìn ọ, nítorí tẹ̀rù tẹ̀rù àti tìyanu tìyanu ní a dá mi;
ìyanu ní iṣẹ́ rẹ;
èyí nì ni ọkàn mi sì mọ̀ dájúdájú
15 Ẹ̀dá ara mi kò pamọ́ kúrò lọ́dọ̀ rẹ,
nígbà tí a dá mi ní ìkọ̀kọ̀.
Tí a sì ń ṣiṣẹ́ ní àràbarà ní ìhà ìsàlẹ̀ ilẹ̀ ayé,
16 ojú rẹ ti rí ohun ara mi
nígbà tí a kò tí ì ṣe mí pé:
àti nínú ìwé rẹ ni a ti kọ ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sí,
ní ọjọ́ tí a dá wọn,
nígbà tí wọn kò tilẹ̀ tí ì sí.
17 Ọlọ́run, èrò inú rẹ tí ṣe iyebíye tó fún mi,
iye wọn ti pọ̀ tó!
18 Èmi ìbá kà wọ́n,
wọ́n ju iyanrìn lọ ní iye:
nígbà tí mo bá jí,
èmi yóò wà lọ́dọ̀ rẹ síbẹ̀.
19 Ọlọ́run ìbá jẹ́ pa àwọn ènìyàn búburú nítòótọ́;
nítorí náà kúrò lọ́dọ̀ mi ẹ̀yin ọkùnrin ẹlẹ́jẹ̀.
20 Ẹni tí ń fi inú búburú sọ̀rọ̀ sí ọ,
àwọn ọ̀tá rẹ ń pe orúkọ rẹ ní asán!
21 Olúwa, ǹjẹ́ èmi kò kórìíra àwọn tó kórìíra rẹ?
Ǹjẹ́ inú mi kò a sì bàjẹ́ sí àwọn tí ó dìde sí ọ?
22 Èmi kórìíra wọn ní àkótán;
èmi kà wọ́n sí ọ̀tá mi.
23 Ọlọ́run, wádìí mi, kí o sì mọ ọkàn mí;
dán mi wò, kí o sì mọ ìrò inú mi
147 Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.
Nítorí ohun rere ni láti máa kọrin ìyìn sí Ọlọ́run wa,
ó yẹ láti kọrin ìyìn sí i!
2 Olúwa kọ́ Jerusalẹmu;
Ó kó àwọn Israẹli tí a lé sọnù jọ.
3 Ó wo àwọn tí ọkàn wọ́n bàjẹ́ sàn
ó sì di ọgbẹ́ wọ́n.
4 Ó ka iye àwọn ìràwọ̀
ó sì pe ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní orúkọ
5 Títóbi ni Olúwa wa ó sì pọ̀ ní agbára
òye rẹ̀ kò sì ní òpin.
6 Olúwa wa pẹ̀lú àwọn onírẹ̀lẹ̀
bẹ́ẹ̀ ni ó rẹ̀ àwọn ènìyàn búburú sílẹ̀.
7 Fi ọpẹ́ kọrin sí Olúwa
fi ohun èlò orin olókùn yin Ọlọ́run.
8 Ó fi ìkùùkuu bo àwọ̀ sánmọ̀
ó rọ òjò sí orílẹ̀ ayé
ó mú kí koríko hù lórí àwọn òkè
9 Ó pèsè oúnjẹ fún àwọn ẹranko
àti fún àwọn ọmọ ẹyẹ ìwò ní ìgbà tí wọ́n bá ń ké.
10 Òun kò ní inú dídùn nínú agbára ẹṣin
bẹ́ẹ̀ ni Òun kò ní ayọ̀ sí ẹ̀ṣẹ̀ ọkùnrin
11 Olúwa ni ayọ̀ nínú àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀,
sí àwọn tí ó ní ìrètí nínú àánú rẹ̀.
12 Yin Olúwa, ìwọ Jerusalẹmu
yin Ọlọ́run rẹ, ìwọ Sioni.
13 Nítorí tí ó ti mú ọ̀pá ìdábùú ibodè rẹ̀ lágbára;
Òun sì ti bùkún fún àwọn ọmọ rẹ̀ nínú rẹ
14 Òun jẹ́ kí àlàáfíà wà ní àwọn ẹnu ibodè rẹ̀
òun sì fi jéró dáradára tẹ́ ọ lọ́rùn.
15 Òun sì rán àṣẹ rẹ̀ sí ayé
ọ̀rọ̀ rẹ̀ sáré tete.
16 Ó fi yìnyín fún ni bi irun àgùntàn
ó sì fọ́n ìrì dídì ká bí eérú
17 Ó rọ òjò yìnyín rẹ̀ bí òkúta wẹ́wẹ́
ta ni ó lè dúró níwájú òtútù rẹ̀
18 Ó rán ọ̀rọ̀ rẹ̀ jáde ó sì mú wọn yọ̀
ó mú kí afẹ́fẹ́ rẹ̀ fẹ́
ó sì mú odò rẹ̀ sàn.
19 Ó sọ ọ̀rọ̀ rẹ̀ di mí mọ̀ fún Jakọbu
àwọn òfin àti ìlànà rẹ̀ fún Israẹli
20 Òun kó tí ṣe irú èyí sí orílẹ̀-èdè kan rí, Bí ó ṣe ti ìdájọ́ rẹ̀
wọn ko mọ òfin rẹ̀.
Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.
Ẹ̀ka òtítọ́
23 “Ègbé ni fún àwọn olùṣọ́-àgùntàn tí ń tú agbo ẹran mi ká tí ó sì ń pa wọ́n run!” ni Olúwa wí. 2 Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Israẹli sọ ní ti àwọn olùṣọ́-àgùntàn tí ń darí àwọn ènìyàn mi: “Nítorí tí ẹ̀yin tú agbo ẹran mi ká, tí ẹ lé wọn dànù tí ẹ̀yin kò sì bẹ̀ wọ́n wò. Èmi yóò jẹ yín ní yà nítorí nǹkan búburú tí ẹ ti ṣe,” ni Olúwa wí. 3 “Èmi Olúwa tìkára mi yóò kó ìyókù agbo ẹran mi jọ láti inú gbogbo orílẹ̀-èdè tí mo ti lé wọn, Èmi yóò mú wọn padà sínú pápá oko wọn, níbẹ̀ ni wọn ó ti bí sí i, tí wọn ó sì pọ̀ sí i. 4 Èmi ó wá olùṣọ́-àgùntàn fún wọn, tí yóò darí wọn, wọn kì yóò bẹ̀rù tàbí dààmú, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀kan kì yóò sọnù,” ni Olúwa wí.
5 (A)“Ọjọ́ ń bọ̀,” ni Olúwa wí,
“tí Èmi yóò gbé ẹ̀ka òdodo dìde fún Dafidi,
ọba tí yóò lo ìjọba pẹ̀lú ọgbọ́n
tí yóò sì ṣe òdodo àti ohun tí ó yẹ lórí ilẹ̀ náà.
6 Ní ọjọ́ rẹ̀ ni a ó gba Juda là,
Israẹli yóò sì máa gbé ní aláìléwu
Èyí ni orúkọ tí a ó fi máa pè é:
Olúwa Òdodo wa.
7 Nítorí náà, ọjọ́ ń bọ̀,” ni Olúwa wí, “tí ènìyàn kì yóò tún wí pé, ‘Dájúdájú Olúwa wà láààyè tí ó mú àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti.’ 8 Ṣùgbọ́n wọn yóò máa wí pé, ‘Dájúdájú Olúwa ń bẹ tí ó mú irú-ọmọ ilé Israẹli wá láti ilẹ̀ àríwá àti láti àwọn ilẹ̀ ibi tí mo tí lé wọn lọ,’ wọn ó sì gbé inú ilẹ̀ wọn.”
8 Ẹ rí dájú pé ẹnikẹ́ni kò mú yin ní ìgbèkùn pẹ̀lú ẹ̀kọ́ àròsọ àti ìmọ̀ ẹ̀tàn, èyí tí ó gbára lé ìlànà ti ènìyàn àti àgbékalẹ̀ àwọn ẹ̀mí ayé yìí tí ó yàtọ̀ sí ti Kristi.
9 Nítorí nínú Kristi ni ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìwàláàyè Ọlọ́run gbé ní ara, 10 (A)ẹ̀yin sì ní ohun gbogbo ní kíkún nínú Kristi, ẹni tí i ṣe orí fún gbogbo agbára àti àṣẹ. 11 Nínú ẹni tí a kò fi ìkọlà tí a fi ọwọ́ kọ kọ yín ní ilà, ni bíbọ ara ẹ̀ṣẹ̀ sílẹ̀, nínú ìkọlà Kristi. 12 Bí a ti sin yín pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ nínú ìtẹ̀bọmi, tí a sì ti jí yín dìde pẹ̀lú rẹ̀ nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ yín nínú agbára Ọlọ́run, ẹni tí ó jí dìde kúrò nínú òkú.
13 Àti ẹ̀yin, ẹni tí ó ti kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yín àti àìkọlà ará yín, mo ní, ẹ̀yin ni ó sì ti sọ di ààyè pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀, ó sì ti dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín; 14 Ó sì ti pa ìwé májẹ̀mú nì rẹ́, tí ó lòdì sí wa, tí a kọ nínú òfin, èyí tí o lòdì sí wa: òun ni ó sì ti mú kúrò lójú ọ̀nà, ó sì kàn án mọ àgbélébùú. 15 (B)Ó sì ti gba agbára kúrò lọ́wọ́ àwọn ìjọba ẹ̀mí búburú àti àwọn alágbára gbogbo, ó sì ti dójútì wọn ní gbangba, bí ó ti ń yọ̀ fún ìṣẹ́gun lórí wọn.
16 (C)Nítorí náà ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni ṣe ìdájọ́ yín ní ti jíjẹ, tàbí ní ti mímu, tàbí ní ti ọjọ́ àsè, tàbí oṣù tuntun, àti ọjọ́ ìsinmi: 17 (D)Àwọn tí í ṣe òjìji ohun tí ń bọ̀; ṣùgbọ́n ní ti òtítọ́, nínú Kristi ni àti mu wọn ṣẹ. 18 Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tí ó ní inú dídùn nínú ìrẹ̀lẹ̀ èké àti bíbọ àwọn angẹli lọ́ èrè yín gbà lọ́wọ́ yín, ẹni tí ń dúró lórí nǹkan wọ̀n-ọn-nì tí ó ti rí, tí ó ń ṣe féfé asán nípa èrò ti ọkàn ara rẹ̀. 19 (E)Wọn ti sọ ìdàpọ̀ wọn pẹ̀lú ẹni tí i ṣe orí nu, láti ọ̀dọ̀ ẹni tí a ń ti ipa oríkèé àti iṣan pèsè fún gbogbo ara, ti a sì ń so ó ṣọ̀kan pọ̀, tí ó sì ń dàgbà nípa ìmísí Ọlọ́run.
20 (F)Bí ẹ̀yin bá ti kú pẹ̀lú Kristi si àwọn agbára ìlànà ayé yìí, kín ló dé tí ẹ̀yin ń tẹríba fún òfin bí ẹni pé ẹ̀yin wà nínú ayé, 21 Má ṣe dìímú, má ṣe tọ́ ọ wò, má ṣe fi ọwọ́ bà á, 22 (G)Gbogbo èyí tí yóò ti ipa lílo run, gẹ́gẹ́ bí òfin àti ẹ̀kọ́ ènìyàn? 23 Àwọn nǹkan tí ó ní àfarawé ọgbọ́n nítòótọ́, nípasẹ̀ àdábọwọ́ ìsìn, àti ìrẹ̀lẹ̀, àti ìpọ́nra-ẹni-lójú, ṣùgbọ́n tí kò ni èrè láti di ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara ku.
7 Nítorí náà Jesu tún wí fún wọn pé, “Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Èmi ni ìlẹ̀kùn àwọn àgùntàn. 8 (A)Olè àti ọlọ́ṣà ni gbogbo àwọn tí ó ti wà ṣáájú mi: ṣùgbọ́n àwọn àgùntàn kò gbọ́ tiwọn. 9 Èmi ni ìlẹ̀kùn: bí ẹnìkan bá bá ọ̀dọ̀ mi wọlé, òun ni a ó gbàlà, yóò wọlé, yóò sì jáde, yóò sì rí koríko. 10 Olè kì í wá bí kò ṣe láti jalè, láti pa, àti láti parun: èmi wá kí wọn lè ní ìyè, àní kí wọn lè ní i lọ́pọ̀lọpọ̀.
11 (B)“Èmi ni olùṣọ́-àgùntàn rere: olùṣọ́-àgùntàn rere fi ọkàn rẹ̀ lélẹ̀ nítorí àwọn àgùntàn. 12 Ṣùgbọ́n alágbàṣe, tí kì í ṣe olùṣọ́-àgùntàn, ẹni tí àwọn àgùntàn kì í ṣe tirẹ̀, ó rí ìkookò ń bọ̀, ó sì fi àgùntàn sílẹ̀, ó sì fọ́n wọn ká kiri. 13 Òun sálọ nítorí tí ó jẹ́ alágbàṣe, kò sì náání àwọn àgùntàn.
14 “Èmi ni olùṣọ́-àgùntàn rere, mo sì mọ àwọn tèmi, àwọn tèmi sì mọ̀ mí. 15 (C)Gẹ́gẹ́ bí Baba ti mọ̀ mí, tí èmi sì mọ Baba; mo sì fi ọkàn mi lélẹ̀ nítorí àwọn àgùntàn. 16 (D)Èmi sì ní àwọn àgùntàn mìíràn, tí kì í ṣe agbo yìí: àwọn ni èmi yóò mú wá pẹ̀lú, wọn yóò sì gbọ́ ohùn mi; wọn ó sì jẹ́ agbo kan, olùṣọ́-àgùntàn kan. 17 Nítorí náà ni Baba mi ṣe fẹ́ràn mi, nítorí tí mo fi ẹ̀mí mi lélẹ̀, kí èmi lè tún gbà á.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.