Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Book of Common Prayer

Daily Old and New Testament readings based on the Book of Common Prayer.
Duration: 861 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 85

Fún adarí orin. Ti àwọn ọmọ Kora. Saamu.

85 Ìwọ fi ojúrere hàn fún ilé rẹ, Olúwa;
    ìwọ mú ohun ìní Jakọbu bọ̀ sí ipò.
Ìwọ dárí àìṣedéédéé àwọn ènìyàn rẹ jì
    ìwọ sì bó ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́lẹ̀. Sela.
Ìwọ fi àwọn ìbínú rẹ sápá kan
    ìwọ sì yípadà kúrò nínú ìbínú gbígbóná rẹ.

Yí wa padà, Ọlọ́run ìgbàlà wa,
    kí o sì yí ìbínú rẹ̀ padà kúrò lọ́dọ̀ wa.
Ìwọ yóò ha máa bínú sí wa títí láé?
    Ìwọ yóò ha mú ìbínú rẹ pẹ́ yí gbogbo ìran ká?
Ìwọ kì yóò ha sọ wá jí padà mọ́,
    pé kí àwọn ènìyàn rẹ lè yọ nínú rẹ?
Fi ìfẹ́ rẹ tí kò le è kùnà hàn wá, Olúwa,
    Kí o sì fún wa ní ìgbàlà rẹ.

Èmi ó gbọ́ ohun tí Olúwa Ọlọ́run yóò wí;
    ó ṣèlérí àlàáfíà fún àwọn ènìyàn rẹ̀, àní ẹni mímọ́ rẹ̀:
Ṣùgbọ́n má ṣe jẹ́ kí wọn padà sí àìmoye.
Nítòótọ́ ìgbàlà rẹ̀ súnmọ́ àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀,
    pé kí ògo rẹ̀ kí ó lè gbé ní ilẹ̀ wa.

10 Ìfẹ́ àti òtítọ́ parapọ̀;
    òdodo àti àlàáfíà fẹnu ko ara wọn.
11 Òtítọ́ ń sun jáde láti ilẹ̀ wá
    òdodo sì bojú wolẹ̀ láti ọ̀run.
12 Olúwa yóò fi ohun dídára fún ni nítòótọ́,
    ilẹ̀ wa yóò sì mú ìkórè rẹ̀ jáde.
13 Òdodo síwájú rẹ lọ
    o sì pèsè ọ̀nà fún ìgbésẹ̀ rẹ̀.

Saamu 87

Ti àwọn ọmọ Kora. Saamu. Orin.

87 Ó ti fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ sọlẹ̀ sórí òkè mímọ́;
Olúwa fẹ́ràn ẹnu-ọ̀nà Sioni
    ju gbogbo ibùgbé Jakọbu lọ.

Ohun ológo ni a sọ nípa rẹ̀,
    ìlú Ọlọ́run;
“Èmi ó dárúkọ Rahabu àti Babeli
    láàrín àwọn tí ó jẹ́wọ́ mi:
Filistia pẹ̀lú, àti Tire, pẹ̀lú Kuṣi
    yóò sọ pé, ‘Èyí ni a bí ní Sioni.’ ”
Nítòótọ́, ti Sioni ni a ó sọ,
    “Eléyìí àti eléyìí ni a bí nínú rẹ̀,
    àti Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo ni yóò fìdí rẹ̀ múlẹ̀.”
Olúwa yóò kọ nínú àkọsílẹ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀:
    “Eléyìí ni a bí ní Sioni.”

Àti àwọn olórin àti àwọn tí ń lu
    ohun èlò orin yóò wí pé,
    “Gbogbo orísun mi ń bẹ nínú rẹ.”

Saamu 136

136 Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa nítorí tí ó ṣeun;
nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
Ẹ fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run àwọn ọlọ́run:
nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa àwọn olúwa,
nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

Fún Òun nìkan tí ń ṣiṣẹ́ ìyanu ńlá;
nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
Fún ẹni tí ó fi ọgbọ́n dá ọ̀run;
nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
(A)Fún ẹni tí ó tẹ́ ilẹ̀ lórí omi;
nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
(B)Fún ẹni tí ó dá àwọn ìmọ́lẹ̀ ńlá;
nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
Òòrùn láti jẹ ọba ọ̀sán;
nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
Òṣùpá àti ìràwọ̀ láti jẹ ọba òru;
nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

10 (C)Fún ẹni tí ó kọlu Ejibiti lára àwọn àkọ́bí wọn;
nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
11 (D)Ó sì mú Israẹli jáde kúrò láàrín wọn;
nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
12 Pẹ̀lú ọwọ́ agbára àti apá nínà;
nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

13 (E)Fún ẹni tí ó pín Òkun pupa ní ìyà;
nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
14 Ó sì mú Israẹli kọjá láàrín rẹ̀
nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
15 Ṣùgbọ́n ó bi Farao àti ogun rẹ̀ ṣubú nínú Òkun pupa;
nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

16 Fún ẹni tí ó sin àwọn ènìyàn rẹ̀ la aginjù já
nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

17 Fún ẹni tí ó kọlu àwọn ọba ńlá;
nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
18 Ó sì pa àwọn ọba olókìkí
nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
19 Sihoni, ọba àwọn ará Amori
nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
20 Àti Ogu, ọba Baṣani;
nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
21 Ó sì fi ilẹ̀ wọn fún ni ní ìní,
nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
22 Ìní fún Israẹli, ìránṣẹ́ rẹ̀,
nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

23 Ẹni tí ó rántí wa ní ìwà ìrẹ̀lẹ̀ wa;
nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
24 Ó sì dá wa ní ìdè lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa;
nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
25 Ẹni tí ó fi oúnjẹ fún àwọn ẹ̀dá gbogbo
nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

26 Ẹ fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run ọ̀run;
nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

Joṣua 3:14-4:7

14 Nígbà tí àwọn ènìyàn gbéra láti ibùdó láti kọjá nínú odò Jordani, àwọn àlùfáà tí ó ru àpótí ẹ̀rí náà ń lọ níwájú wọn. 15 Odò Jordani sì máa ń wà ní kíkún ní gbogbo ìgbà ìkórè. Ṣùgbọ́n bí àwọn àlùfáà tí ó ru àpótí ẹ̀rí ti dé odò Jordani tí ẹsẹ̀ wọn sì kan etí omi, 16 omi tí ń ti òkè sàn wá dúró. Ó sì gbá jọ bí òkìtì ní òkèèrè, ní ìlú tí a ń pè ní Adamu, tí ó wà ní tòsí Saretani; nígbà tí omi tí ń sàn lọ sínú Òkun aginjù, (Òkun Iyọ̀) gé kúrò pátápátá. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ènìyàn kọjá sí òdìkejì ní ìdojúkọ Jeriko. 17 Àwọn àlùfáà tí ó ru àpótí ẹ̀rí Olúwa sì dúró ṣinṣin lórí ilẹ̀ gbígbẹ ní àárín Jordani, nígbà tí gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ń kọjá títí gbogbo orílẹ̀-èdè náà fi rékọjá nínú odò Jordani lórí ilẹ̀ gbígbẹ.

Nígbà tí gbogbo orílẹ̀-èdè náà kọjá nínú odò Jordani tan, Olúwa sọ fún Joṣua pé, “Yan ọkùnrin méjìlá (12) nínú àwọn ènìyàn, ẹnìkan nínú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan, kí o sì pàṣẹ fún wọn pé Ẹ gbé òkúta méjìlá láti àárín odò Jordani ní ibi tí àwọn àlùfáà dúró sí, kí ẹ sì rù wọn kọjá, kí ẹ sì gbé wọn sí ibi tí ẹ̀yin yóò sùn ní alẹ́ yìí.”

Bẹ́ẹ̀ ni Joṣua pe àwọn ọkùnrin méjìlá tí ó ti yàn nínú àwọn ọmọ Israẹli, ẹnìkan nínú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ kọjá lọ ní iwájú àpótí ẹ̀rí Olúwa Ọlọ́run yín sí àárín odò Jordani. Kí olúkúlùkù yín gbé òkúta kọ̀ọ̀kan lé èjìká a rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí iye ẹ̀yà àwọn ọmọ Israẹli, kí ó sì jẹ́ ààmì láàrín yín. Ní ọjọ́ iwájú, nígbà tí àwọn ọmọ yín bá béèrè lọ́wọ́ yín pé, ‘Kí ni òkúta wọ̀nyí dúró fún?’ Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò dá wọn lóhùn pé, nítorí a gé omi odò Jordani kúrò ní iwájú àpótí ẹ̀rí Olúwa. Nígbà tí a rékọjá a Jordani, a gé omi Jordani kúrò. Àwọn òkúta wọ̀nyí yóò sì jẹ́ ìrántí fún àwọn ọmọ Israẹli láéláé.”

Efesu 5:1-20

Nítorí náà, ẹ máa ṣe àfarawé Ọlọ́run bí àwọn olùfẹ́ ọmọ, (A)ẹ sì máa rìn ní ìfẹ́, gẹ́gẹ́ bí Kristi pẹ̀lú ti fẹ́ wa, tí ó sì fi ara rẹ̀ fún wa ní ọrẹ àti ẹbọ fún Ọlọ́run fún òórùn dídùn.

Ṣùgbọ́n àgbèrè àti gbogbo ìwà èérí, tàbí ojúkòkòrò, kí a má tilẹ̀ dárúkọ rẹ̀ láàrín yín mọ́, bí ó ti yẹ àwọn ènìyàn mímọ́; Ìbá à ṣe ìwà ọ̀bùn, àti ìṣọ̀rọ̀ òmùgọ̀, tàbí ìṣẹ̀fẹ̀ àwọn ohun tí kò tọ́; ṣùgbọ́n ẹ kúkú máa dúpẹ́. Nítorí ẹ̀yin mọ èyí dájú pé, kò sí panṣágà, tàbí aláìmọ́ ènìyàn, tàbí wọ̀bìà, (tí í ṣé abọ̀rìṣà) tí yóò ni ìpín kan ni ìjọba Kristi àti Ọlọ́run. Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni fi ọ̀rọ̀ asán tàn yín jẹ: nítorí nípasẹ̀ nǹkan wọ̀nyí ní ìbínú Ọlọ́run fi ń bọ̀ wá sórí àwọn ọmọ aláìgbọ́ràn. Nítorí náà ẹ má ṣe jẹ́ alájọpín pẹ̀lú wọn.

Nítorí ẹ̀yin tí jẹ́ òkùnkùn lẹ́ẹ̀kan ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ẹ̀yin dí ìmọ́lẹ̀, nípa tí Olúwa: Ẹ máa rín gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ ìmọ́lẹ̀: (Nítorí èso Ẹ̀mí ni ìṣoore, àti òdodo àti òtítọ́). 10 Ẹ sì máa wádìí ohun tí í ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún Olúwa. 11 Ẹ má sì ṣe bá àwọn oníṣẹ́ òkùnkùn kẹ́gbẹ́ pọ̀, ṣùgbọ́n ẹ kúkú máa bá wọn wí. 12 Nítorí ìtìjú tilẹ̀ ni láti máa sọ̀rọ̀ nǹkan wọ̀n-ọn-nì tí àwọn aláìgbọ́ràn ń ṣe ní ìkọ̀kọ̀. 13 Ṣùgbọ́n ohun gbogbo tí a tú síta ni ìmọ́lẹ̀ ń fì hàn: nítorí ohunkóhun tí ó bá fi nǹkan hàn, ìmọ́lẹ̀ ni. 14 Nítorí náà ni ó ṣe wí pé,

“Jí, ìwọ̀ ẹni tí ó sun,
    sí jíǹde kúrò nínú òkú
Kristi yóò sì fún ọ ní ìmọ́lẹ̀.”

15 Nítorí náà ẹ kíyèsi láti máa rìn ní ìwà pípé, kì í ṣé bí àwọn òmùgọ̀, ṣùgbọ́n bí àwọn ọlọ́gbọ́n; 16 (B)Ẹ máa ra ìgbà padà, nítorí búburú ní àwọn ọjọ́. 17 Nítorí náà, ẹ má ṣé jẹ aláìlóye, ṣùgbọ́n ẹ máa mòye ohun tí ìfẹ́ Olúwa jásí. 18 Ẹ má sí ṣe mú wáìnì ní àmupara, nínú èyí tí rúdurùdu wà; ṣùgbọ́n ẹ kún fún Ẹ̀mí Mímọ́. 19 (C)Ẹ sì máa bá ara yín sọ̀rọ̀ nínú Saamu, àti orin ìyìn, àti orin Ẹ̀mí, ẹ máa kọrin, kí ẹ sì máa kọrin dídùn ní ọkàn yín sí Olúwa. 20 Ẹ máa dúpẹ́ nígbà gbogbo fún ohun gbogbo lọ́wọ́ Ọlọ́run, àní Baba, ní orúkọ Jesu Kristi Olúwa wá.

Johanu 9:1-12

Jesu la ojú ẹni tí a bí ní afọ́jú

Bí ó sì ti ń kọjá lọ, ó rí ọkùnrin kan tí ó fọ́jú láti ìgbà ìbí rẹ̀ wá. (A)Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì bi í léèrè, pé, “Rabbi, ta ní ó dẹ́ṣẹ̀, ọkùnrin yìí tàbí àwọn òbí rẹ̀, tí a fi bí i ní afọ́jú?”

(B)Jesu dáhùn pé, “Kì í ṣe nítorí pé ọkùnrin yìí dẹ́ṣẹ̀, tàbí àwọn òbí rẹ̀: ṣùgbọ́n kí a ba à lè fi iṣẹ́ Ọlọ́run hàn lára rẹ̀. (C)Èmi ní láti ṣe iṣẹ́ ẹni tí ó rán mi, níwọ̀n ìgbà tí ó bá ti jẹ́ ọ̀sán: òru ń bọ̀ wá nígbà tí ẹnìkan kì yóò lè ṣe iṣẹ́. (D)Níwọ́n ìgbà tí mo wà láààyè, èmi ni ìmọ́lẹ̀ ayé.”

(E)Nígbà tí ó ti wí bẹ́ẹ̀ tan, ó tutọ́ sílẹ̀, ó sì fi itọ́ náà ṣe amọ̀, ó sì fi amọ̀ náà ra ojú afọ́jú náà. (F)Ó sì wí fún un pé, “Lọ wẹ̀ nínú adágún Siloamu!” (Ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ yìí ni “rán”). Nítorí náà ó gba ọ̀nà rẹ̀ lọ, ó wẹ̀, ó sì dé, ó ń ríran.

Ǹjẹ́ àwọn aládùúgbò àti àwọn tí ó rí i nígbà àtijọ́ pé alágbe ni ó jẹ́, wí pé, “Ẹni tí ó ti ń jókòó ṣagbe kọ́ yìí?” Àwọn kan wí pé òun ni.

Àwọn ẹlòmíràn wí pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́, ó jọ ọ́ ni.”

Ṣùgbọ́n òun wí pé, “Èmi ni.”

10 Nígbà náà ni wọ́n wí fún un pé, “Bá wo ni ojú rẹ ṣe là?”

11 Ó dáhùn ó sì wí fún un pé, “Ọkùnrin kan tí a ń pè ní Jesu ni ó ṣe amọ̀, ó sì fi kun ojú mí, ó sì wí fún mi pé, ‘Lọ sí adágún Siloamu, kí o sì wẹ̀,’ èmi sì lọ, mo wẹ̀, mo sì ríran.”

12 Wọ́n sì wí fún un pé, “Òun náà ha dà?”

Ó sì wí pé, “Èmi kò mọ̀.”

Johanu 9:35-38

Ìfọ́jú ẹ̀mí

35 Jesu gbọ́ pé, wọ́n ti tì í sóde; nígbà tí ó sì rí i, ó wí pe, “Ìwọ gba Ọmọ Ọlọ́run, gbọ́ bí?”

36 Òun sì dáhùn wí pé, “Ta ni, Olúwa, kí èmi lè gbà á gbọ́?”

37 Jesu wí fún un pé, “Ìwọ ti rí i, Òun náà sì ni ẹni tí ń bá ọ sọ̀rọ̀ yìí.”

38 (A)Ó sì wí pé, “Olúwa, mo gbàgbọ́,” ó sì wólẹ̀ fún un.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.