Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Book of Common Prayer

Daily Old and New Testament readings based on the Book of Common Prayer.
Duration: 861 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 148-150

148 Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.

Ẹ fi ìyìn fún Olúwa láti ọ̀run wá,
    Ẹ fi ìyìn fún un níbi gíga.
Ẹ fi ìyìn fún un,
    gbogbo ẹ̀yin angẹli rẹ̀
Ẹ fi ìyìn fún un,
    gbogbo ẹ̀yin ọmọ-ogun rẹ̀
Ẹ fi ìyìn fún un,
    oòrùn àti òṣùpá
Ẹ fi ìyìn fún un,
    gbogbo ẹ̀yin ìràwọ̀ ìmọ́lẹ̀.
Ẹ fi ìyìn fún un,
    ẹ̀yin ọ̀run àti àwọn ọ̀run gíga
    àti ẹ̀yin omi tí ń bẹ ní òkè ọ̀run.

Ẹ jẹ́ kí wọn kí ó yin orúkọ Olúwa
    nítorí ó pàṣẹ a sì dá wọn
Ó fi ìdí wọn múlẹ̀ láé àti láéláé
    ó sì ti ṣe ìlànà kan tí kì yóò já.

Ẹ yin Olúwa láti ilẹ̀ ayé wá
    ẹ̀yin ẹ̀dá inú Òkun títóbi
    àti ẹ̀yin ibú Òkun
Mọ̀nàmọ́ná àti òjò yìnyín
    ìdí omi àti àwọn ìkùùkuu,
    ìjì líle tí ń mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ;
Òkè ńlá àti gbogbo òkè kéékèèkéé,
    igi eléso àti gbogbo igi kedari,
10 Àwọn ẹranko ńlá àti ẹran ọ̀sìn
    gbogbo ohun afàyàfà àti àwọn ẹyẹ abìyẹ́:
11 Àwọn ọba ayé àti ènìyàn ayé gbogbo
    àwọn ọmọ-aládé àti gbogbo àwọn onídàájọ́ ayé,
12 Ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin
    àwọn arúgbó àti àwọn ọmọdé.

13 Ẹ jẹ́ kí wọn kí ó yin orúkọ Olúwa
    nítorí orúkọ rẹ̀ nìkan ni ó ní ọlá
    ògo rẹ̀ kọjá ayé àti ọ̀run
14 Ó sì gbé ìwo kan sókè fún àwọn ènìyàn rẹ̀,
    ìyìn fún gbogbo ènìyàn mímọ́ rẹ̀ àní fún àwọn ọmọ Israẹli,
    àwọn ènìyàn tí ó súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ̀.

Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.
149 Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.

Ẹ kọrin tuntun sí Olúwa.
    Ẹ yìn ín ní àwùjọ àwọn ènìyàn mímọ́.

Jẹ́ kí Israẹli kí ó ní inú dídùn sí ẹni tí ó dá a
    jẹ́ kí àwọn ọmọ Sioni kí ó ní
    ayọ̀ nínú ọba wọn.
Jẹ́ kí wọn kí ó fi ijó yin orúkọ rẹ̀
    jẹ́ kí wọn kí ó fi ohun èlò orin kọrin ìyìn sí i.
Nítorí Olúwa ní inú dídùn sí àwọn ènìyàn rẹ̀
    ó fi ìgbàlà dé àwọn onírẹ̀lẹ̀ ládé
Jẹ́ kí àwọn ènìyàn mímọ́ kí ó yọ̀ nínú ọlá rẹ̀
    kí wọn kí ó máa kọrin fún ayọ̀ ní orí ibùsùn wọn.

Kí ìyìn Ọlọ́run kí ó wà ní ẹnu wọn
    àti idà olójú méjì ní ọwọ́ wọn.
Láti gba ẹ̀san lára àwọn orílẹ̀-èdè,
    àti ìjìyà lára àwọn ènìyàn,
Láti fi ẹ̀wọ̀n de àwọn ọba wọn
    àti láti fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀
irin de àwọn ọlọ́lá wọn.
Láti ṣe ìdájọ́ tí àkọsílẹ̀ rẹ̀ sí wọn
    èyí ni ògo àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀.

Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.
150 Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.

Ẹ fi ìyìn fún Ọlọ́run ní ibi mímọ́ rẹ̀
    Ẹ yìn ín nínú agbára ọ̀run rẹ̀.
Ẹ yìn ín fún iṣẹ́ agbára rẹ̀.
    Ẹ yìn ín fún títóbi rẹ̀ tí ó tayọ̀.
Ẹ fi ohùn ìpè yìn ín.
    Ẹ fi ohun èlò orin yìn ín.
Ẹ fi ohun èlò orin àti ijó yìn ín
    fi ohun èlò orin olókùn àti ìpè yìn ín
Ẹ yìn ín pẹ̀lú aro olóhùn òkè,
    Ẹ yìn ín lára aro olóhùn gooro.

Jẹ́ kí gbogbo ohun tí ó ní ẹ̀mí yin Olúwa.

Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.

Saamu 114-115

114 Nígbà tí Israẹli jáde ní Ejibiti,
    ilé Jakọbu láti inú ènìyàn àjèjì èdè
Juda wà ní ibi mímọ́,
    Israẹli wà ní ìjọba.

(A)Òkun sì rí i, ó sì wárìrì:
    Jordani sì padà sẹ́yìn.
Àwọn òkè ńlá ń fò bí àgbò àti
    òkè kéékèèkéé bí ọ̀dọ́-àgùntàn.

Kí ni ó ṣe ọ́, ìwọ Òkun, tí ìwọ fi wárìrì?
    Ìwọ Jordani, tí ìwọ fi padà sẹ́yìn?
Ẹ̀yin òkè ńlá kí ló dé ti ẹ fi ń fò bí àgbò,
    àti ẹ̀yin òkè kéékèèkéé bí ọ̀dọ́-àgùntàn?

Wárìrì, ìwọ ilẹ̀, níwájú Olúwa;
    ní iwájú Ọlọ́run Jakọbu
tí ó sọ àpáta di adágún omi,
    àti òkúta-ìbọn di orísun omi.
115 Kì í ṣe fún wa, Olúwa kì í ṣe fún wa,
    ṣùgbọ́n fún orúkọ rẹ ni a fi ògo fún,
    fún àánú àti òtítọ́ rẹ.

Torí kí ni àwọn kèfèrí yóò ṣe sọ pé,
    níbo ni Ọlọ́run wa wà.
Ṣùgbọ́n Ọlọ́run wa wà lọ́run:
    tí ó ń ṣe èyí tí ó wù ú.
(B)Fàdákà òun wúrà ni èrè àwọn aláìkọlà,
    iṣẹ́ ọwọ́ ènìyàn ni,
Wọ́n ní ẹnu, ṣùgbọ́n wọn kò le sọ̀rọ̀,
    wọ́n ní ojú, ṣùgbọ́n wọn kò fi ríran.
Wọ́n ní etí, ṣùgbọ́n wọn kò fi gbọ́rọ̀:
    wọ́n ní imú, ṣùgbọ́n wọn kò fi gbóòórùn
Wọ́n ní ọwọ́, ṣùgbọ́n wọn kò lò ó,
    wọ́n ní ẹsẹ̀, ṣùgbọ́n wọn kò rìn;
    bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sọ̀rọ̀ nínú òfin wọn.
Àwọn tí ń ṣe wọ́n dàbí wọn;
    gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni olúkúlùkù ẹni tí ó gbẹ́kẹ̀ rẹ̀ lé wọn.

Ìwọ Israẹli gbẹ́kẹ̀lé Olúwa:
    òun ni ìrànwọ́ àti ààbò wọn
10 Ẹ̀ yin ilé Aaroni, gbẹ́kẹ̀lé Olúwa:
    òun ni ìrànwọ́ àti ààbò wọn
11 Ẹ̀ yin tí ó bẹ̀rù Olúwa, gbẹ́kẹ̀lé Olúwa:
    òun ní ìrànwọ́ àti ààbò wọn.

12 Olúwa tí ń ṣe ìrántí wa; yóò bùkún ilé Israẹli;
    yóò bùkún ilé Aaroni.
13 (C)Ìbùkún ni fún àwọn tí ó bẹ̀rù Olúwa,
    àti kékeré àti ńlá.

14 Olúwa yóò mú ọ pọ̀ sí i síwájú àti síwájú,
    ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ̀.
15 Ẹ fi ìbùkún fún Olúwa
    ẹni tí ó dá ọ̀run òun ayé.

16 Ọ̀run àní ọ̀run ni ti Olúwa:
    ṣùgbọ́n ayé ló fi fún ọmọ ènìyàn.
17 Òkú kò lè yìn Olúwa,
    tàbí ẹni tí ó ti lọ sí ìsàlẹ̀ ìdákẹ́ jẹ́ẹ́.
18 Ṣùgbọ́n àwa ó fi ìbùkún fún Olúwa
    láti ìsinsin yìí lọ àti títí láéláé.

Ẹ yin Olúwa.

Gẹnẹsisi 7:1-10

Nígbà náà ni Ọlọ́run wí fún Noa pé, “Wọ inú ọkọ̀ lọ ìwọ àti gbogbo ìdílé rẹ, nítorí ìwọ nìkan ni mo rí bí olódodo nínú ìran yìí. Mú méje méje nínú àwọn ẹran tí ó mọ́, akọ àti abo, mú méjì méjì takọ tabo nínú àwọn ẹran aláìmọ́. Sì mú méje méje pẹ̀lú nínú onírúurú ẹyẹ, takọ tabo ni kí o mú wọn, wọlé sínú ọkọ̀ pẹ̀lú rẹ, kí á ba à lè pa wọ́n mọ́ láààyè ní gbogbo ayé. Nítorí ní ọjọ́ méje sí ìhín, èmi yóò rọ òjò sórí ilẹ̀ fún ogójì ọ̀sán àti ogójì òru, èmi yóò sì pa gbogbo ohun alààyè tí mo ti dá run kúrò lórí ilẹ̀.”

Noa sì ṣe ohun gbogbo tí Ọlọ́run pàṣẹ fún un.

Noa jẹ́ ọmọ ẹgbẹ̀ta ọdún (600) nígbà tí ìkún omi dé sórí ilẹ̀. (A)Noa àti ìyàwó rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn aya ọmọ rẹ̀ sì wọ inú ọkọ láti sá àsálà fún ìkún omi. Méjì méjì ni àwọn ẹran tí ó mọ́ àti aláìmọ́, ti ẹyẹ àti ti gbogbo àwọn ẹ̀dá afàyàfà, akọ àti abo ni wọ́n wọlé pẹ̀lú Noa sínú ọkọ̀ bí Ọlọ́run ti pàṣẹ fún Noa. 10 Lẹ́yìn ọjọ́ keje, ìkún omi sì dé sí ayé.

Gẹnẹsisi 7:17-23

17 Òjò náà sì rọ̀ ní àrọ̀ìrọ̀dá fún ogójì ọ̀sán àti ogójì òru, ọkọ̀ náà sì ń léfòó lórí omi, kúrò lórí ilẹ̀ bí omi náà ti ń pọ̀ sí i. 18 Bí omi náà ti ń pọ̀ sí i, bẹ́ẹ̀ náà ni ọkọ̀ náà sì ń léfòó lójú omi. 19 Omi náà pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí ó bo gbogbo àwọn òkè gíga tí ó wà lábẹ́ ọ̀run. 20 Omi náà kún bo àwọn òkè, bí ìwọ̀n ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún. 21 Gbogbo ohun alààyè tí ó wà lórí ilẹ̀ parun: ẹyẹ, ohun ọ̀sìn, ẹranko igbó, àwọn ẹ̀dá afàyàfà àti ènìyàn. 22 Gbogbo ohun tí ó wà lórí ìyàngbẹ ilẹ̀ tó ní èémí ìyè ní ihò imú wọn ni ó kú. 23 Gbogbo ohun alààyè tí ó wà lórí ilẹ̀ ayé ni a parẹ́: ènìyàn àti ẹranko, àwọn ohun tí ń rìn nílẹ̀, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run pátápátá ló ṣègbé. Noa àti àwọn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ nínú ọkọ̀ ni ó ṣẹ́kù.

Efesu 4:1-16

Ìṣọ̀kan nínú ara Jesu

Nítorí náà, èmi òǹdè nínú Olúwa ń bẹ̀ yín pé kí ẹ̀yin máa gbé ìgbé ayé tí ó yẹ sí ìpè tí a pè yín sí. (A)Pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ gbogbo àti inú tútù, pẹ̀lú ìpamọ́ra, ẹ máa fi ìfẹ́ faradà fún ẹnìkejì yín. Kí ẹ sì máa làkàkà láti pa ìṣọ̀kan Ẹ̀mí mọ́ ni ìdàpọ̀ àlàáfíà. Ara kan ni ń bẹ, àti Ẹ̀mí kan, àní bí a ti pè yín sínú ìrètí kan nígbà tí a pè yín. Olúwa kan, ìgbàgbọ́ kan àti ìtẹ̀bọmi kan. Ọlọ́run kan àti Baba gbogbo aráyé, ẹni tí ó ṣe olórí ohun gbogbo àti nípá gbogbo àti nínú ohun gbogbo.

Ṣùgbọ́n olúkúlùkù wa ni a fi oore-ọ̀fẹ́ fun gẹ́gẹ́ bi òṣùwọ̀n ẹ̀bùn Kristi. (B)Nítorí náà a wí pé:

“Nígbà tí ó gòkè lọ sí ibi gíga,
    ó di ìgbèkùn ni ìgbèkùn,
    ó sì fi ẹ̀bùn fun ènìyàn.”

(Ǹjẹ́ ní ti pé, “Ó gòkè lọ!” Kín ni ó túmọ̀ sí, bí kò ṣe pé ó kọ́ sọ̀kalẹ̀ pẹ̀lú lọ sí ìsàlẹ̀ ilẹ̀? 10 Ẹni tí ó ti sọ̀kalẹ̀, Òun kan náà ni ó sì ti gòkè rékọjá gbogbo àwọn ọ̀run, kí ó lè kún ohun gbogbo.) 11 Nítorí náà ó sì ti fi àwọn kan fún ni bí aposteli; àti àwọn mìíràn bí i wòlíì; àti àwọn mìíràn bí efangelisti, àti àwọn mìíràn bí olùṣọ́-àgùntàn àti olùkọ́ni. 12 Fún àṣepé àwọn ènìyàn mímọ́ fun iṣẹ́ ìránṣẹ́, fún ìmúdàgbà ara Kristi. 13 Títí gbogbo wa yóò fi dé ìṣọ̀kan ìgbàgbọ́ àti ìmọ̀ Ọmọ Ọlọ́run, títí a ó fi di ọkùnrin, títí a ó fi dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìwọ̀n Kristi.

14 Kí àwa má ṣe jẹ́ èwe mọ́, tí a ń fi gbogbo afẹ́fẹ́ ẹ̀kọ́ tì síwá tì sẹ́yìn, tí a sì fi ń gbá kiri, nípa ìtànjẹ ènìyàn, nípa àrékérekè fun ọgbọ́nkọ́gbọ́n àti mú ni ṣìnà; 15 (C)Ṣùgbọ́n ká a máa sọ òtítọ́ ní ìfẹ́, kí a lè máa dàgbàsókè nínú rẹ̀ ní ohun gbogbo ẹni tí i ṣe orí, àní Kristi. 16 (D)Láti ọ̀dọ̀ ẹni ti ara náà tí a ń so ṣọ̀kan pọ̀, tí ó sì ń fi ara mọ́ra, nípasẹ̀ oríkèé kọ̀ọ̀kan tí a ti pèsè, nígbà tí ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan bá ń ṣiṣẹ́ dáradára, yóò mú ara dàgbà, yóò sì gbé ara òun tìkára rẹ̀ dìde nínú ìfẹ́.

Marku 3:7-19

Ọ̀pọ̀ ènìyàn tẹ̀lé Jesu

(A)Jesu pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ yẹra kúrò níbẹ̀ lọ sí etí Òkun. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn láti Galili àti Judea sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn. (B)Nígbà tí wọ́n gbọ́ ìròyìn iṣẹ́ ìyanu tí ó ṣe, ọ̀pọ̀ ènìyàn sì tọ̀ ọ́ wá láti Judea, Jerusalẹmu àti Idumea, àti láti apá kejì odò Jordani àti láti ìhà Tire àti Sidoni. Nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn, Jesu sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ láti ṣètò ọkọ̀ ojú omi kékeré kan sílẹ̀ fún un láti lọ, láti lé àwọn èrò sẹ́yìn. 10 (C)Nítorí tí ó mú ọ̀pọ̀ ènìyàn láradá, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn aláìsàn ló bí ara wọn lù ú láti fi ọwọ́ kàn án. 11 Ìgbàkúgbà tí àwọn tí ó ni ẹ̀mí àìmọ́ bá ti fojú ri, wọ́n á wólẹ̀ níwájú rẹ̀. Wọn a sì kígbe lóhùn rara wí pé, “Ìwọ ni Ọmọ Ọlọ́run.” 12 (D)Ṣùgbọ́n ó kìlọ̀ fún wọn gidigidi, kí wọn má ṣe fi òun hàn.

Jesu yan àwọn aposteli méjìlá

13 (E)Jesu gun orí òkè lọ, ó sì pe àwọn kan tí ó yàn láti wà pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n sì tọ̀ ọ́ wá. 14 Ó yan àwọn méjìlá, kí wọn kí ó lè wà pẹ̀lú rẹ̀, àti kí ó lè rán wọn lọ láti wàásù 15 àti láti lágbára láti lé àwọn ẹ̀mí Èṣù jáde.

16 (F)Wọ̀nyí ni àwọn méjìlá náà tí ó yàn:

Simoni (ẹni ti ó sọ àpèlé rẹ̀ ní Peteru)

17 Jakọbu ọmọ Sebede àti Johanu arákùnrin rẹ̀ (àwọn ẹni tí Jesu sọ àpèlé wọ́n ní Boanaji, èyí tí ó túmọ̀ sí àwọn ọmọ àrá).

18 Àti Anderu,

Filipi,

Bartolomeu,

Matiu,

Tomasi,

Jakọbu ọmọ Alfeu,

Taddeu,

Simoni tí ń jẹ́ Sealoti (ọ̀kan nínú àwọn ẹgbẹ́ tí o ń ja fun òmìnira àwọn Júù).

19 (G)Àti Judasi Iskariotu, ẹni tí ó fi í hàn níkẹyìn.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.