Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Book of Common Prayer

Daily Old and New Testament readings based on the Book of Common Prayer.
Duration: 861 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 88

Orin. Saamu ti àwọn ọmọ Kora. Fún adarí orin. Gẹ́gẹ́ bí ti mahalati leannoti. Maskili ti Hemani ará Esra.

88 Olúwa, Ọlọ́run tí ó gbà mí là,
    ní ọ̀sán àti ní òru ni mo kígbe sókè sí Ọ.
Jẹ́ kí àdúrà mi kí ó wá sí iwájú rẹ;
    dẹ etí rẹ sí igbe mi.

Nítorí ọkàn mi kún fún ìpọ́njú
    ọkàn mi sì súnmọ́ isà òkú.
A kà mí mọ́ àwọn tí wọ́n lọ sí ọ̀gbun ilẹ̀
    èmi dàbí ọkùnrin tí kò ni agbára.
A yà mí sọ́tọ̀ pẹ̀lú àwọn òkú
    bí ẹni tí a pa tí ó dùbúlẹ̀ ní ipò ikú,
ẹni tí ìwọ kò rántí mọ́,
    ẹni tí a gé kúrò lára àwọn tí ìwọ ń tọ́jú.

Ìwọ tí ó fi mí sí kòtò jíjìn,
    ní ibi ọ̀gbun tó ṣókùnkùn.
Ìbínú rẹ ṣubú lé mi gidigidi;
    ìwọ ti fi àwọn ìjì rẹ borí mi.
Ìwọ tí gba ọ̀rẹ́ mi tí ó súnmọ́ mi kúrò lọ́wọ́ mi
    ìwọ sì sọ mi di ìríra sí wọn.
A há mi mọ́, èmi kò sì le è jáde;
Ojú mi káàánú nítorí ìpọ́njú.

    Mo kígbe pè ọ́, Olúwa, ní gbogbo ọjọ́;
mo na ọwọ́ mi jáde sí ọ.
10 Ìwọ ó fi iṣẹ́ ìyanu rẹ hàn fún òkú bi?
    Àwọn òkú yóò ha dìde láti yìn ọ́ bí?
11 A ó ha fi ìṣeun ìfẹ́ rẹ hàn ní ibojì bí:
    Tàbí òtítọ́ rẹ ní ipò ìparun?
12 A ha lè mọ iṣẹ́ ìyanu rẹ ní òkùnkùn bí
    àti òdodo rẹ ní ilẹ̀ ìgbàgbé?

13 Ṣùgbọ́n mo kígbe sí ọ fún ìrànlọ́wọ́, Olúwa;
    ní òwúrọ̀ ni àdúrà mí wá sọ́dọ̀ rẹ.
14 Olúwa, èéṣe tí ìwọ fi kọ̀ mí
    tí ìwọ fi ojú rẹ pamọ́ fún mi?

15 Láti ìgbà èwe mi, ìṣẹ́ ń ṣẹ́ mi,
    èmi múra àti kú;
nígbà tí ẹ̀rù rẹ bá ń bà mí,
    èmi di gbére-gbère
16 Ìbínú rẹ ti kọjá lára mi;
    ìbẹ̀rù rẹ ti gé mi kúrò
17 Ní gbogbo ọjọ́ ni wọn yí mi ká bí ìkún omi;
    wọ́n mù mí pátápátá.
18 Ìwọ ti mú ọ̀rẹ́ àti olùfẹ́ mi kúrò lọ́dọ̀ mi;
    òkùnkùn sì jẹ́ ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ mi.

Saamu 91-92

91 Ẹni tí ó gbé ibi ìkọ̀kọ̀ Ọ̀gá-ògo
    ni yóò sinmi ní ibi òjìji Olódùmarè.
Èmi yóò sọ nípa ti Olúwa pé,
    “Òun ni ààbò àti odi mi,
    Ọlọ́run mi, ẹni tí èmi gbẹ́kẹ̀lé”.

Nítòótọ́ òun yóò gbà mí nínú
    ìdẹ̀kùn àwọn pẹyẹpẹyẹ
    àti nínú àjàkálẹ̀-ààrùn búburú.
Òun yóò fi ìyẹ́ rẹ̀ bò mí,
    àti ni abẹ́ ìyẹ́ rẹ̀ ni èmi yóò ti rí ààbò;
    òtítọ́ rẹ̀ ni yóò ṣe ààbò àti odi mi.
Ìwọ kì yóò bẹ̀rù nítorí ẹ̀rù òru,
    tàbí fún ọfà tí ń fò ní ọ̀sán,
Tàbí fún àjàkálẹ̀-ààrùn tí ń rìn kiri ní òkùnkùn,
    tàbí fún ìparun tí ń rìn kiri ní ọ̀sán gangan.
Ẹgbẹ̀rún yóò ṣubú ní ẹ̀gbẹ́ rẹ,
    ẹgbàárùn-ún ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ
    ṣùgbọ́n kì yóò súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ
Ìwọ yóò máa wò ó pẹ̀lú ojú rẹ
    àti wo ìjìyà àwọn ẹni búburú.

Nítorí ìwọ fi Olúwa ṣe ààbò rẹ,
    ìwọ fi Ọ̀gá-ògo ṣe ibùgbé rẹ.
10 Búburú kan ki yóò ṣubú lù ọ́
    Bẹ́ẹ̀ ni ààrùnkárùn kì yóò súnmọ́ ilé rẹ.
11 (A)Nítorí yóò fi àṣẹ fún àwọn angẹli nípa tìrẹ
    láti pa ọ́ mọ́ ní gbogbo ọ̀nà rẹ;
12 Wọn yóò gbé ọ sókè ní ọwọ́ wọn,
    nítorí kí ìwọ má ba à fi ẹsẹ̀ rẹ gún òkúta.
13 (B)Ìwọ yóò rìn lórí kìnnìún àti paramọ́lẹ̀;
    ìwọ yóò tẹ kìnnìún ńlá àti ejò ńlá ni ìwọ yóò fi ẹsẹ̀ tẹ̀ mọ́lẹ̀.

14 “Nítorí ti ìfẹ́ rẹ sí mi, èmi yóò gbà ọ́;
    èmi yóò pa ọ́ mọ́, nítorí ìwọ jẹ́wọ́ orúkọ mi.
15 Òun yóò pè mí, èmi yóò sì dá a lóhùn;
    èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ̀ nínú ìpọ́njú,
    èmi yóò gbà á, èmi yóò sì bu ọlá fún un
16 Pẹ̀lú ẹ̀mí gígùn ni èmi yóò fi tẹ́ ẹ lọ́rùn
    èmi yóò sì fi ìgbàlà mi hàn án.”

Saamu. Orin. Fún ọjọ́ Ìsinmi

92 Ohun rere ni láti máa fi ọpẹ́ fún Olúwa
    àti láti máa kọrin sí orúkọ rẹ̀, Ọ̀gá-ògo,
Láti kéde ìfẹ́ rẹ̀ ní òwúrọ̀
    àti òtítọ́ rẹ̀ ní alẹ́
Lára ohùn èlò orin olókùn mẹ́wàá
    àti lára ohun èlò orin haapu.

Nítorí ìwọ ni ó mú inú mi dùn
    nípa iṣẹ́ rẹ Olúwa;
èmi kọrin ayọ̀ sí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.
Báwo ni iṣẹ́ rẹ tí tóbi tó, Olúwa?
    Èrò inú rẹ ìjìnlẹ̀ ni!
Òpè ènìyàn kò mọ̀ ọ́n,
    aṣiwèrè kò sì mọ̀ ọ́n,
Nígbà tí àwọn ènìyàn búburú
    bá rú jáde bí i koríko
àti gbogbo àwọn olùṣe
    búburú gbèrú,
wọn yóò run láéláé.

Ṣùgbọ́n ìwọ Olúwa ni a ó gbéga títí láé.

Nítorí nítòótọ́ àwọn ọ̀tá rẹ,
Olúwa,
    nítòótọ́ àwọn ọ̀tá rẹ yóò ṣègbé;
gbogbo àwọn olùṣe búburú
    ni a ó fọ́nká.
10 Ìwọ ti gbé ìwo mi ga bí i ti màlúù igbó;
    òróró dídára ni a dà sí mi ní orí.
11 Ojú mi ti rí ìṣubú àwọn ọ̀tá mi;
    ìparun sí àwọn ènìyàn búburú
    tí ó dìde sí mi.

12 Olódodo yóò gbèrú bí i igi ọ̀pẹ,
    wọn yóò dàgbà bí i igi kedari Lebanoni;
13 Tí a gbìn sí ilé Olúwa,
    Wọn yóò rúwé nínú àgbàlá Ọlọ́run wa.
14 Wọn yóò máa so èso ní ìgbà ogbó,
    wọn yóò dúró ní àkọ̀tun, wọn yóò sì tutù nini,
15 Láti fihàn pé “Ẹni ìdúró ṣinṣin ni Olúwa;
    òun ni àpáta mi, kò sì ṣí aburú
    kankan nínú rẹ̀.”

2 Ọba 9:17-37

17 Nígbà tí olùṣọ́ kan tí ó dúró ní ilé ìṣọ́ ní Jesreeli, rí ọ̀wọ́ ogun Jehu tí wọ́n ń súnmọ́ tòsí, ó pè jáde, “Mo rí àwọn ọ̀wọ́ ogun tí ó ń bọ̀.”

“Mú ọkùnrin ẹlẹ́ṣin kan,” Joramu pa á láṣẹ. “Rán an lọ sí ọ̀dọ̀ wọn kí o sì béèrè pé, ‘Ṣé ẹ̀yin wá pẹ̀lú àlàáfíà?’ ”

18 Ọkùnrin ẹlẹ́ṣin náà, lọ láti lọ bá Jehu ó sì wí pé, “Èyí ni ohun tí ọba wí: ‘Ṣé ìwọ wá pẹ̀lú àlàáfíà?’ ”

“Kí ni ìwọ ní ṣe pẹ̀lú àlàáfíà?” Jehu sì dáhùn. “Bọ́ sí ẹ̀yìn mi.”

Olùṣọ́ náà sì wí fún un pé, “ìránṣẹ́ náà ti dé ọ̀dọ̀ wọn, ṣùgbọ́n kò tún padà wá mọ́.”

19 Bẹ́ẹ̀ ni, ọba rán ọkùnrin ẹlẹ́ṣin kejì, Nígbà náà ó wá sí ọ̀dọ̀ wọn, ó wí pé, “Èyí ni ohun tí ọba sọ:

“Ṣé ìwọ wá pẹ̀lú àlàáfíà?” Jehu dáhùn, “Dúró sí ẹ̀yìn mi.”

20 Olùṣọ́ náà sì fi sùn. “Ó ti dé ọ̀dọ̀ wọn, ṣùgbọ́n kò tún padà wá mọ́ pẹ̀lú. Wíwá rẹ̀ sì dàbí ti Jehu ọmọ Nimṣi, ó ń wa kẹ̀kẹ́ bí ti aṣiwèrè.”

21 “Fi ìwọ̀ kọ́ kẹ̀kẹ́ ogun mi.” Joramu pa á láṣẹ. Àti nígbà tí a fi kọ́, Joramu ọba Israẹli àti Ahasiah ọba Juda, gun kẹ̀kẹ́ lọ, olúkúlùkù nínú kẹ̀kẹ́ ogun tirẹ̀, láti lọ bá Jehu. Wọ́n bá a pàdé ní ibi oko tí ó ti jẹ́ ti Naboti ará Jesreeli. 22 Nígbà tí Joramu rí Jehu, ó béèrè pé, “Ṣé ìwọ wá pẹ̀lú àlàáfíà, Jehu?”

“Báwo ni àlàáfíà yóò ṣe wà,” Jehu dáhùn, “Ní ìwọ̀n ìgbà tí gbogbo ìbọ̀rìṣà àti iṣẹ́ àjẹ́ ti màmá rẹ Jesebeli di púpọ̀?”

23 Joramu yí ọwọ́ rẹ̀ padà, ó sì sálọ, ó sì ń pe Ahasiah, “ọ̀tẹ̀ dé, Ahasiah!”

24 Nígbà náà, Jehu fa ọrun rẹ̀, ó sì yin Joramu láàrín èjìká méjèèjì. Ọfà náà sì wọ inú ọkàn rẹ̀, ó sì ṣubú lulẹ̀ láti orí kẹ̀kẹ́ rẹ̀. 25 (A)Jehu sọ fún Bidikari, balógun kẹ̀kẹ́ ẹ rẹ̀ pé, “Gbé e sókè kí ó sì jù ú sí orí oko tí ó jẹ́ ti Naboti ará Jesreeli. Rántí bí èmi àti ìwọ ti ń gun kẹ̀kẹ́ papọ̀ lẹ́yìn Ahabu baba à rẹ nígbà tí Olúwa sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀: 26 ‘Ní àná, mo rí ẹ̀jẹ̀ Naboti pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ ọmọ rẹ̀ ọkùnrin, ni Olúwa wí.’ Ǹjẹ́ nítorí náà, ẹ gbé e sókè, kí o sì jù ú sí orí ilẹ̀ oko náà ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Olúwa.”

27 Nígbà tí Ahasiah ọba, Juda rí ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀, ó sálọ sójú ọ̀nà sí Beti-Haggani. Jehu sì lépa rẹ̀, ó ń kígbe, “Pa á pẹ̀lú!” Wọ́n ṣá a ní ọgbẹ́ nínú kẹ̀kẹ́ ẹ rẹ̀ ní ọ̀nà lọ sí Guri lẹ́bàá a Ibleamu, ṣùgbọ́n ó sálọ sí Megido, ó sì kú síbẹ̀. 28 Ìránṣẹ́ rẹ̀ sì gbé e pẹ̀lú kẹ̀kẹ́ lọ sí Jerusalẹmu, ó sì sin ín pẹ̀lú, baba a rẹ̀ nínú ibojì rẹ̀ ní ìlú ńlá ti Dafidi. 29 (Ní ọdún kọkànlá ti Joramu ọmọ Ahabu, Ahasiah ti di ọba Juda.)

A pa Jesebeli

30 Nígbà náà Jehu lọ sí Jesreeli. Nígbà tí Jesebeli gbọ́ nípa rẹ̀, ó kun ojú u rẹ̀, ó to irun rẹ̀, ó sì wò jáde láti ojú fèrèsé. 31 Bí Jehu ti wọ ẹnu ìlẹ̀kùn, ó béèrè, “Ṣé ìwọ wá ní àlàáfíà, Simri, ìwọ olùpa ọ̀gá à rẹ?”

32 Ó gbójú sókè láti wo fèrèsé, ó sì pè jáde, “Ta ni ó wà ní ẹ̀gbẹ́ mi? Ta ni?” Ìwẹ̀fà méjì tàbí mẹ́ta bojú wò ó nílẹ̀. 33 Jehu sọ wí pé, “Gbé e jù sílẹ̀!” Wọ́n sì jù ú sílẹ̀. Díẹ̀ nínú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sì fọ́n sí ara ògiri àti àwọn ẹṣin bí wọ́n ti tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀ lábẹ́ ẹsẹ̀ wọn.

34 Jehu wọ inú ilé lọ, ó jẹ, ó sì mu. “Tọ́jú obìnrin yẹn tí a fi bú,” Ó wí, “Kí o sì sin ín, nítorí ọmọbìnrin ọba ni ó jẹ́.” 35 Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n jáde lọ láti lọ sin ín, wọn kò rí nǹkan kan àyàfi agbárí i rẹ̀, ẹsẹ̀ rẹ̀ méjèèjì àti ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì. 36 (B)Wọ́n padà lọ sọ fún Jehu, ẹni tí ó wí pé, “Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó sọ nípasẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ̀ Elijah ará Tiṣibi wí pé: Ní orí oko Jesreeli ni àwọn ajá yóò ti jẹ ẹran-ara Jesebeli. 37 Òkú Jesebeli yóò dàbí ohun ẹ̀gbin ní orí oko Jesreeli, dé bi pé, ẹnikẹ́ni kì yóò lè sọ pé, ‘Jesebeli ni èyí.’ ”

1 Kọrinti 7:1-9

Ìgbéyàwó

Ní báyìí, nítorí àwọn ohun tí ẹ ṣe kọ̀wé: Ó dára fún ọkùnrin kí ó máa ṣe ni ìdàpọ̀ pẹ̀lú obìnrin. Ṣùgbọ́n nítorí àgbèrè pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ kí ọkùnrin kọ̀ọ̀kan gbéyàwó tirẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni kí obìnrin kọ̀ọ̀kan ní ọkọ tirẹ̀. Kí ọkùnrin kí ó fi gbogbo ẹ̀tọ́ ìyàwó rẹ̀ fún ún, kí ìyàwó fi gbogbo ẹ̀tọ́ ọkọ fún ọkọ rẹ̀. Aya kò láṣẹ lórí ara rẹ̀ mọ́, ara rẹ̀ ti di ti ọkọ rẹ̀. Bákan náà ni ọkùnrin tí ó gbéyàwó kò ní àṣẹ lórí ara rẹ̀ mọ́, ara rẹ̀ ti di ti ìyàwó rẹ̀. (A)Nítorí náà, ẹ má ṣe fi àwọn ẹ̀tọ́ tọkọtaya wọ̀nyí dun ara yín, bí kò ṣe nípa ìfìmọ̀ṣọ̀kan, kí ẹ̀yin lè fi ara yín fún àwẹ̀ àti àdúrà, kí ẹ̀yin sì tún jùmọ̀ pàdé, lẹ́yìn ìgbà náà, wọ́n gbọdọ̀ padà sọ́dọ̀ ara wọn kí Satani má ba à dán wọn wò nítorí àìlèmáradúró wọn. Mo sọ èyí fún un yín bí ìmọ̀ràn ní kì í ṣe bí àṣẹ. (B)Ó wù mí kí olúkúlùkù dàbí èmi, ṣùgbọ́n gbogbo ènìyàn kò le jẹ́ bákan náà, Ọlọ́run fún olúkúlùkù ènìyàn ní ẹ̀bùn tirẹ̀, ọ̀kan bí irú èyí àti èkejì bí irú òmíràn.

Nítorí náà, mo wí fún àwọn àpọ́n àti opó pé, ó sàn kí wọ́n kúkú wà gẹ́gẹ́ bí èmi tí wà. (C)Ṣùgbọ́n bí wọ́n kò bá lè mú ara dúró, kí wọ́n gbéyàwó tàbí kí wọ́n fẹ́ ọkọ, nítorí pé ó sàn láti gbéyàwó jù láti ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ lọ.

Matiu 6:7-15

Ṣùgbọ́n nígbà ti ẹ̀yin bá ń gbàdúrà, ẹ má ṣe àtúnwí asán bí àwọn aláìkọlà, nítorí wọn rò pé a ó tìtorí ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ gbọ́ tiwọn. Ẹ má ṣe dàbí i wọn, nítorí Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run mọ ohun tí ẹ ṣe aláìní, kí ẹ tilẹ̀ tó béèrè lọ́wọ́ rẹ̀.

(A)“Nítorí náà, báyìí ni kí ẹ ṣe máa gbàdúrà:

“ ‘Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run,
ọ̀wọ̀ fún orúkọ yín,
10 Kí ìjọba yín dé,
Ìfẹ́ tiyín ni kí a ṣe
    ní ayé bí ti ọ̀run.
11 Ẹ fún wa ní oúnjẹ òòjọ́ wa lónìí
12 Ẹ dárí gbèsè wa jì wá,
    Bí àwa ti ń dáríji àwọn ajigbèsè wa,
13 (B)Ẹ má ṣe fà wá sínú ìdánwò,
    Ṣùgbọ́n ẹ gbà wá lọ́wọ́ ibi.
    Nítorí ìjọba ni tiyín, àti agbára àti ògo, láéláé, Àmín.’

14 (C)Nítorí náà, bí ẹ̀yin bá dárí jí àwọn tó ṣẹ̀ yín, baba yín ọ̀run náà yóò dáríjì yín. 15 Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá kọ̀ láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn jì wọ́n, baba yín kò ní í dárí ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.