Book of Common Prayer
Saamu. Orin. Fún ìyàsímímọ́ Tẹmpili. Ti Dafidi.
30 Èmi yóò kókìkí i rẹ, Olúwa,
nítorí ìwọ ni ó gbé mi lékè
tí ìwọ kò sì jẹ́ kí àwọn ọ̀tá mi kí ó yọ̀ mí.
2 Olúwa Ọlọ́run mi, èmi ké pè ọ́, fún ìrànlọ́wọ́
ìwọ sì ti wò mí sàn.
3 Olúwa, ìwọ ti yọ ọkàn mi jáde kúrò nínú isà òkú,
mú mi padà bọ̀ sípò alààyè kí èmi má ba à lọ sínú ihò.
4 Kọ orin ìyìn sí Olúwa, ẹ̀yin olódodo;
kí ẹ sì fi ọpẹ́ fún orúkọ rẹ̀ mímọ́.
5 Nítorí pé ìbínú rẹ̀ wà fún ìgbà díẹ̀,
ojúrere rẹ̀ wà títí ayérayé;
Ẹkún lè pẹ́ títí di alẹ́,
Ṣùgbọ́n ayọ̀ yóò wá ní òwúrọ̀.
6 Ní ìgbà ayé mi, mo wí pé,
“a kì yóò ṣí mi ní ipò padà.”
7 Nípa ojúrere rẹ, Olúwa,
ìwọ ti gbé mi kalẹ̀ bí òkè tí ó ní agbára;
ìwọ pa ojú rẹ mọ́,
àyà sì fò mí.
8 Sí ọ Olúwa, ni mo ké pè é;
àti sí Olúwa ni mo sọkún fún àánú:
9 “Èrè kí ni ó wà nínú ikú ìparun mi,
nínú lílọ sí ihò mi?
Eruku yóò a yìn ọ́ bí?
Ǹjẹ́ yóò sọ nípa òdodo rẹ?
10 Gbọ́, Olúwa, kí o sì ṣàánú fún mi;
ìwọ Olúwa, jẹ́ olùrànlọ́wọ́ mi.”
11 Ìwọ ti yí ìkáàánú mi di ijó fún mi;
ìwọ sì ti bọ́ aṣọ ọ̀fọ̀ mi, o sì fi aṣọ ayọ̀ wọ̀ mí,
12 nítorí ìdí èyí ni kí ọkàn mi máa yìn ọ́, kí o má sì ṣe dákẹ́.
Ìwọ Olúwa Ọlọ́run mi, èmi yóò máa fi ọpẹ́ fún ọ títí láé.
Ti Dafidi. Maskili.
32 (A)Ìbùkún ni fún àwọn
tí a dárí ìrékọjá wọn jì,
tí a sì bo ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́lẹ̀.
2 Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà
ẹni tí Ọlọ́run kò ka ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ sí i lọ́rùn
àti nínú ẹ̀mí ẹni tí kò sí ẹ̀tàn.
3 Nígbà tí mo dákẹ́,
egungun mi di gbígbó dànù
nípa ìkérora mi ní gbogbo ọjọ́.
4 Nítorí pé ni ọ̀sán àti ní òru
ọwọ́ rẹ̀ wúwo sí mi lára;
agbára mi gbẹ tán
gẹ́gẹ́ bí ooru ẹ̀ẹ̀rùn. Sela.
5 Èmi jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi sí ọ
àti pé èmi kò sì fi àìṣòdodo mi pamọ́.
Èmi wí pé, “Èmi yóò jẹ́wọ́
ẹ̀ṣẹ̀ mi fún Olúwa,”
ìwọ sì dárí
ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ mi jì mí. Sela.
6 Nítorí náà jẹ́ kí gbogbo àwọn olódodo máa gbà àdúrà sí ọ
ní ìgbà tí a lè rí ọ;
nítòótọ́ nígbà tí ìṣàn omi ńlá bá ru sókè,
wọn kì yóò lè dé ọ̀dọ̀ rẹ̀.
7 Ìwọ ni ibi ìpamọ́ mi;
ìwọ yóò pa mí mọ́ kúrò nínú ìyọnu;
ìwọ yóò fi orin ìgbàlà yí mi ka. Sela.
8 Èmi yóò kọ́ ọ, èmi yóò sì fi ẹsẹ̀ rẹ lé ọ̀nà tí ìwọ yóò rìn
èmi yóò máa gbà ọ́ ní ìyànjú, èmi yóò sì máa fi ojú mi tọ́ ọ.
9 Má ṣe dàbí ẹṣin tàbí ìbáaka,
tí kò ní òye
ẹnu ẹni tí a gbọdọ̀ fi ìjánu bọ̀,
kí wọn má ba à súnmọ́ ọ.
10 Ọ̀pọ̀ ìkáàánú ní yóò wà fún ènìyàn búburú,
ṣùgbọ́n ìfẹ́ Olúwa tí ó dúró ṣinṣin
ni yóò yí àwọn tí ó ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa ká.
11 Ẹ yọ̀ nínú Olúwa, kí ẹ sì ní inú dídùn, ẹ̀yìn olódodo;
ẹ sì máa kọrin, gbogbo ẹ̀yìn tí àyà yín dúró ṣinṣin.
ÌWÉ KEJÌ
Saamu 42–72
Fún adarí orin. Maskili ti àwọn ọmọ Kora.
42 Bí àgbọ̀nrín ti ń mí hẹlẹ sí ipa odò omi,
bẹ́ẹ̀ ni ọkàn mi ń mí hẹlẹ sí ọ Ọlọ́run.
2 Òùngbẹ Ọlọ́run ń gbẹ ọkàn mi, fún Ọlọ́run alààyè.
Nígbà wo ni èmi ó lọ bá Ọlọ́run?
3 Oúnjẹ mi ni omijé mi
ní ọ̀sán àti ní òru,
nígbà tí àwọn ènìyàn ń wí fún mi ní gbogbo ọjọ́ pé,
“Ọlọ́run rẹ dà?”
4 Nígbà tí mo bá rántí nǹkan yìí,
èmi tú ọkàn mi jáde nínú mi:
èmi ti bá ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn lọ,
èmi bá wọn lọ sí ilé Ọlọ́run
pẹ̀lú ohùn ayọ̀ àti ìyìn,
pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ń pa ọjọ́ mímọ́ mọ́.
5 Èéṣe tí o fi ń rẹ̀wẹ̀sì, ìwọ ọkàn mi?
Èéṣe tí ara rẹ kò fi lélẹ̀ nínú mi?
Ìwọ ṣe ìrètí ní ti Ọlọ́run,
nítorí èmi yóò sá à máa yìn ín,
Olùgbàlà mi àti Ọlọ́run mi.
6 Ọlọ́run mi, ọkàn mi ń rẹ̀wẹ̀sì nínú mi:
nítorí náà, èmi ó rántí rẹ
láti ilẹ̀ Jordani wá,
láti Hermoni láti òkè Mibsari.
7 Ibú omi ń pe ibú omi
nípa híhó omi ṣíṣàn rẹ̀
gbogbo rírú omi àti bíbì omi rẹ̀
bò mí mọ́lẹ̀.
8 Ní ọ̀sán ní Olúwa ran ìfẹ́ rẹ̀,
àti ni àṣálẹ́ ni orin rẹ̀ wà pẹ̀lú mi
àdúrà sí Ọlọ́run ayé mi.
9 Èmi wí fún Ọlọ́run àpáta mi,
“Èéṣe tí ìwọ fi gbàgbé mi?
Èéṣe tí èmi o fi máa rìn nínú ìbànújẹ́,
nítorí ìnilára ọ̀tá?”
10 Bí ẹni pé idà egungun mi ni ẹ̀gàn tí
àwọn ọ̀tá mi ń gàn mí,
Bí wọn ti ń béèrè ní gbogbo ọjọ́.
“Níbo ni Ọlọ́run rẹ wà?”
11 Èéṣe tí ìwọ fi ń rẹ̀wẹ̀sì, ìwọ ọkàn mi?
Èéṣe tí ara rẹ kò fi lélẹ̀ nínú mi?
Fi ìrètí rẹ sínú Ọlọ́run,
nítorí èmi yóò sì máa yìn ín, Òun ni
Olùgbàlà mi àti Ọlọ́run mi.
43 Dá mi láre, Ọlọ́run mi,
kí o sì gba ọ̀rọ̀ mi rò lọ́dọ̀ àwọn aláìláàánú orílẹ̀-èdè:
yọ mí kúrò lọ́wọ́ ẹlẹ́tàn àti àwọn ènìyàn búburú.
2 Ìwọ ni Ọlọ́run ibi agbára mi.
Èéṣe tí ìwọ fi kọ̀ mi sílẹ̀?
Èéṣe tí èmi yóò máa rìn nínú ìbìnújẹ́,
nítorí ìnilára lọ́dọ̀ àwọn ọ̀tá?
3 Rán ìmọ́lẹ̀ àti òtítọ́ rẹ jáde,
jẹ́ kí wọn ó máa dáàbò bò mí;
jẹ́ kí wọn mú mi wá sí òkè mímọ́ rẹ,
sí ibi tí ìwọ ń gbé.
4 Nígbà náà ni èmi ó lọ sí ibi pẹpẹ Ọlọ́run,
sí Ọlọ́run ayọ̀ mi àti ìdùnnú mi,
èmi yóò yìn ọ́ pẹ̀lú dùùrù,
ìwọ Ọlọ́run, Ọlọ́run mi.
5 Èéṣe tí o fi ń rẹ̀wẹ̀sì, ìwọ ọkàn mí?
Èéṣe tí ó fi ń ru sókè nínú mi?
Fi ìrètí rẹ sínú Ọlọ́run,
nítorí èmi yóò máa yìn ín, Òun ni
Olùgbàlà mi àti Ọlọ́run mi.
Israẹli ṣọ̀tẹ̀ sí Rehoboamu
12 (A)Rehoboamu sì lọ sí Ṣekemu, nítorí gbogbo Israẹli ti lọ síbẹ̀ láti fi í jẹ ọba. 2 Nígbà tí Jeroboamu ọmọ Nebati, tí ó wà ní Ejibiti síbẹ̀ gbọ́, nítorí tí ó ti sá kúrò níwájú Solomoni ọba, ó sì wà ní Ejibiti. 3 Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ránṣẹ́ sí Jeroboamu, òun àti gbogbo ìjọ Israẹli sì lọ sọ́dọ̀ Rehoboamu, wọ́n sì wí fún un pé: 4 “Baba rẹ sọ àjàgà wa di wúwo, ṣùgbọ́n nísinsin yìí, mú kí ìsìn baba rẹ̀ tí ó le, àti àjàgà rẹ̀ tí ó wúwo, tí ó fi sí wa ní ọrùn kí ó fẹ́rẹ̀ díẹ̀, àwa yóò sì sìn ọ́.”
5 Rehoboamu sì wí fún wọn pé, “Ẹ lọ ná títí di ọjọ́ mẹ́ta, nígbà náà ni kí ẹ padà tọ̀ mí wá.” Àwọn ènìyàn náà sì lọ.
6 Nígbà náà ni Rehoboamu ọba fi ọ̀rọ̀ lọ àwọn àgbàgbà tí ń dúró níwájú Solomoni baba rẹ̀ nígbà tí ó wà láààyè. Ó sì béèrè pé, “Ìmọ̀ràn wo ni ẹ̀yin yóò gbà mí láti dá àwọn ènìyàn wọ̀nyí lóhùn?”
7 Wọ́n sì dá a lóhùn pé, “Bí ìwọ yóò bá jẹ́ ìránṣẹ́ fún àwọn ènìyàn wọ̀nyí lónìí, kí o sì sìn wọ́n, àti kí o sì sọ ọ̀rọ̀ rere sí wọn nígbà tí ìwọ bá ń dá wọn lóhùn, wọn yóò máa ṣe ìránṣẹ́ rẹ títí láé.”
8 Ṣùgbọ́n Rehoboamu kọ ìmọ̀ràn tí àwọn àgbàgbà fún un, ó sì fi ọ̀rọ̀ náà lọ àwọn ọmọdé tí wọ́n dàgbà pẹ̀lú rẹ̀, tí wọ́n sì ń sìn ín. 9 Ó sì bi wọ́n pé, “Kí ni ìmọ̀ràn yín? Báwo ni a ó ṣe dá àwọn ènìyàn yí lóhùn, tí wọ́n wí fún mi pé, Ṣé kí àjàgà tí baba rẹ fi sí wa lọ́rùn kí ó fúyẹ́ díẹ̀?”
10 Àwọn ọmọdé tí ó dàgbà pẹ̀lú rẹ̀ dá a lóhùn pé, “Sọ fún àwọn ènìyàn tí wọ́n wí fún ọ pé, ‘Baba rẹ̀ mú kí àjàgà wa wúwo ṣùgbọ́n ìwọ mú kí ó fúyẹ́ díẹ̀ fún wa’; sọ fún wọn pé, ìka ọwọ́ mi kékeré nípọn ju ẹ̀gbẹ́ baba mi lọ. 11 Baba mi ti gbé àjàgà wúwo lé e yín; Èmi yóò sì fi kún àjàgà yín. Baba mi ti fi pàṣán nà yín; Èmi yóò fi àkéekèe nà yín.”
12 Jeroboamu àti gbogbo àwọn ènìyàn náà wá sọ́dọ̀ Rehoboamu ní ọjọ́ kẹta, gẹ́gẹ́ bí ọba ti wí pé, “Ẹ padà tọ̀ mí wá ní ọjọ́ kẹta.” 13 Ọba sì fi ohùn líle dá àwọn ènìyàn lóhùn, ó sì kọ ìmọ̀ràn tí àwọn àgbàgbà fún un, 14 Ó sì tẹ̀lé ìmọ̀ràn àwọn ọmọdé, ó sì wí pé, “Baba mí sọ àjàgà yín di wúwo; Èmi yóò sì jẹ́ kí ó wúwo sí i; Baba mi fi pàṣán nà yín; Èmi yóò fi àkéekèe nà yín.” 15 Bẹ́ẹ̀ ni ọba kò sì fi etí sí ti àwọn ènìyàn, nítorí tí ọ̀ràn náà ti ọwọ́ Olúwa wá láti mú ọ̀rọ̀ tí ó sọ fún Jeroboamu ọmọ Nebati láti ẹnu Ahijah ará Ṣilo ṣẹ.
16 Nígbà tí gbogbo Israẹli rí i pé ọba kọ̀ láti gbọ́ ti àwọn, wọ́n sì dá ọba lóhùn pé:
Ìpín wo ni àwa ní nínú Dafidi,
ìní wo ni àwa ní nínú ọmọ Jese?
Padà sí àgọ́ rẹ, ìwọ Israẹli!
Bojútó ilé ara rẹ, ìwọ Dafidi!
Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ará Israẹli padà sí ilé wọn. 17 Ṣùgbọ́n fún ti àwọn ọmọ Israẹli tí ń gbé nínú ìlú Juda, Rehoboamu jẹ ọba lórí wọn síbẹ̀.
18 Ọba Rehoboamu rán Adoniramu jáde, ẹni tí ó wà ní ìkáwọ́ iṣẹ́ onírúurú, ṣùgbọ́n gbogbo Israẹli sọ ọ́ ní òkúta pa. Ọba Rehoboamu, gbìyànjú láti dé inú kẹ̀kẹ́ rẹ̀ ó sì sálọ sí Jerusalẹmu. 19 Bẹ́ẹ̀ ni Israẹli ṣọ̀tẹ̀ sí ilé Dafidi títí di òní yìí.
20 Nígbà tí gbogbo Israẹli sì gbọ́ pé Jeroboamu ti padà dé, wọ́n ránṣẹ́, wọ́n sì pè é wá sí àjọ, wọ́n sì fi jẹ ọba lórí gbogbo Israẹli. Kò sí ẹnìkan tí ó tọ ilé Dafidi lẹ́yìn bí kò ṣe kìkì ẹ̀yà Juda nìkan.
Sùúrù nínú ìjìyà
7 Nítorí náà ará, ẹ mú sùúrù títí di ìpadà wá Olúwa. Kíyèsi i, àgbẹ̀ a máa retí èso iyebíye ti ilẹ̀, a sì mú sùúrù dè é, títí di ìgbà àkọ́rọ̀ àti àrọ̀kúrò òjò. 8 Ẹ̀yin pẹ̀lú, ẹ mú sùúrù; ẹ fi ọkàn yín balẹ̀: nítorí ìpadà wá Olúwa kù sí dẹ̀dẹ̀. 9 Ẹ má ṣe kùn sí ọmọnìkejì yín, ará, kí a má ba à dá a yín lẹ́bi: kíyèsi i, onídàájọ́ dúró ní ẹnu ìlẹ̀kùn.
10 Ará mi, ẹ fi àwọn wòlíì tí ó ti ń sọ̀rọ̀ ní orúkọ Olúwa ṣe àpẹẹrẹ ìyà jíjẹ, àti sùúrù. 11 (A)Sá à wò ó, àwa a máa ka àwọn tí ó fi ara dà ìyà sí ẹni ìbùkún. Ẹ̀yin ti gbọ́ ti sùúrù Jobu, ẹ̀yin sì rí ìgbẹ̀yìn tí Olúwa ṣe; pé Olúwa kún fún ìyọ́nú, ó sì ní àánú.
12 (B)Ṣùgbọ́n ju ohun gbogbo lọ, ará mi, ẹ má ṣe ìbúra, ìbá à ṣe fífi ọ̀run búra, tàbí ilẹ̀, tàbí ìbúra-kíbúra mìíràn. Ṣùgbọ́n jẹ́ kí “Bẹ́ẹ̀ ni” yín jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni; àti “Bẹ́ẹ̀ kọ́” yín jẹ́ bẹ́ẹ̀ kọ́; kí ẹ má ba à bọ́ sínú ẹ̀bi.
19 Ará, bí ẹnikẹ́ni nínú yín bá ṣìnà kúrò nínú òtítọ́, tí ẹni kan sì yí i padà; 20 Jẹ́ kí ó mọ̀ pé, ẹni tí ó bá yí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan padà kúrò nínú ìṣìnà rẹ̀, yóò gba ọkàn kan là kúrò lọ́wọ́ ikú, yóò sì bo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ mọ́lẹ̀.
Ikú Jesu
33 (A)Nígbà tí ó di wákàtí kẹfà, òkùnkùn bo gbogbo ilẹ̀ títí di wákàtí kẹsànán. 34 (B)Ní wákàtí kẹsànán ni Jesu kígbe sókè ní ohùn rara, ó ní, “Eli, Eli, Lama Sabakitani?” (ìtumọ̀ èyí tí í ṣe, “Ọlọ́run mi, Ọlọ́run mi, èéṣe tí ìwọ fi kọ̀ mí sílẹ̀?”).
35 Nígbà tí àwọn kan nínú àwọn tí wọ́n dúró níbẹ̀ gbọ́, wọ́n sì wí pé, “Wò ó ó ń pe Elijah.”
36 (C)Nígbà náà ni ẹnìkan sáré lọ ki kànìnkànìn bọ inú ọtí kíkan, ó fi lé orí ọ̀pá, ó sì nà án sí Jesu kí ó lè mu ún. Ó wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a máa wò ó, bóyá Elijah yóò wá sọ̀ ọ́ kalẹ̀ wa.”
37 Jesu sì tún kígbe sókè ni ohùn rara, ó jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀ lọ́wọ́.
38 (D)Aṣọ ìkélé tẹmpili sì fàya sí méjì láti òkè dé ìsàlẹ̀. 39 (E)Nígbà tí balógun ọ̀rún tí ó dúró lẹ́gbẹ̀ ọ̀dọ̀ Jesu rí i tí ó kígbe sókè báyìí, tí ó sì jọ̀wọ́ èmí rẹ̀ lọ́wọ́, ó wí pé, “Lóòótọ́ Ọmọ Ọlọ́run ni ọkùnrin yìí í ṣe.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.