Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Book of Common Prayer

Daily Old and New Testament readings based on the Book of Common Prayer.
Duration: 861 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 25

Ti Dafidi.

25 Olúwa,
    ìwọ ni mo gbé ọkàn mi sókè sí.

Ọlọ́run, èmi gbẹ́kẹ̀lé ọ;
    Má ṣe jẹ́ kí ojú ó tì mí
    Má ṣe jẹ́ kí àwọn ọ̀tá mi ó yọ̀ mí.
Ẹni tí ó dúró tì ọ́
    ojú kì yóò tì í,
àwọn tí ń ṣẹ̀ láìnídìí
    ni kí ojú kí ó tì.

Fi ọ̀nà rẹ hàn mí, Olúwa,
    kọ mi ní ipa tìrẹ;
ṣe amọ̀nà mi nínú òtítọ́ ọ̀ rẹ, kí o sì kọ́ mi,
    Nítorí ìwọ ni Ọlọ́run ìgbàlà mi;
    ìwọ ni mo dúró tì ní gbogbo ọjọ́.
Rántí, Olúwa àánú àti ìfẹ́ ẹ̀ rẹ̀ ńlá,
    torí pé wọ́n ti wà ní ìgbà àtijọ́
Má ṣe rántí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ìgbà èwe mi
    tàbí ìrékọjá mi;
gẹ́gẹ́ bí i ìfẹ́ ẹ rẹ̀ rántí mi
    nítorí tí ìwọ dára, Ìwọ! Olúwa.

Rere àti ẹni ìdúró ṣinṣin ní Olúwa:
    nítorí náà, ó kọ́ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ni ọ̀nà náà.
Ó ṣe amọ̀nà àwọn onírẹ̀lẹ̀ ni ohun tí ó dára,
    ó sì kọ́ àwọn onírẹ̀lẹ̀ ní ọ̀nà rẹ̀.
10 Gbogbo ipa ọ̀nà Olúwa ni ìfẹ́ àti òdodo tí ó dúró ṣinṣin,
    fún àwọn tí ó pa májẹ̀mú àti ẹ̀rí rẹ̀ mọ́.
11 Nítorí orúkọ rẹ, Olúwa,
    dárí ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ mi jì mí, nítorí tí ó tóbi.

12 Àwọn wo ni ó bẹ̀rù Olúwa?
    Yóò kọ́ wọn ní ọ̀nà èyí tí wọn yóò yàn.
13 Wọn yóò lo ọjọ́ wọn nínú àlàáfíà,
    àwọn ọmọ wọn yóò sì gba ilẹ̀ náà.
14 Olúwa fi ọkàn tán, àwọn tí o bẹ̀rù u rẹ̀;
    ó sọ májẹ̀mú rẹ̀ di mí mọ̀ fún wọn.
15 Ojú mi gbé sókè sọ́dọ̀ Olúwa,
    nítorí pé yóò yọ ẹsẹ̀ mi kúrò nínú àwọ̀n náà.

16 Yípadà sí mi, kí o sì ṣe oore fún mi;
    nítorí pé mo nìkan wà, mo sì di olùpọ́njú.
17 Tì mí lẹ́yìn kúrò nínú ìpọ́njú àyà mi;
    kí o sì fà mí yọ kúrò nínú ìpọ́njú mi.
18 Kíyèsi ìjìyà àti wàhálà mi,
    kí o sì dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi jì.
19 Kíyèsi ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀tá mi,
    tí wọn kórìíra mi pẹ̀lú ìwà ìkà wọn.

20 Pa ọkàn mi mọ́, kí o sì gbà mí sílẹ̀;
    Má ṣe jẹ́ kí a fi mí sínú ìtìjú,
    nítorí pé ìwọ ni ibi ìsádi mi.
21 Jẹ́ kí òtítọ́ inú àti ìdúró ṣinṣin kí ó pa mí mọ́;
    nítorí pé mo dúró tì ọ́.

22 Ra Israẹli padà, Ìwọ Ọlọ́run,
    nínú gbogbo ìṣòro rẹ̀!

Saamu 9

Fún adarí orin. Ní ti ohun orin “Ní ti ikú ọmọ.” Saamu ti Dafidi.

Èmi ó yìn ọ́, Olúwa, pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi;
    Èmi ó sọ ti ìyanu rẹ gbogbo.
Inú mi yóò dùn, èmi yóò sì yọ̀ nínú rẹ;
    Èmi ó kọrin ìyìn sí orúkọ rẹ, Ìwọ Ọ̀gá-Ògo jùlọ.

Àwọn ọ̀tá mi pẹ̀yìndà;
    Wọ́n kọsẹ̀ wọn sì ṣègbé níwájú rẹ.
Nítorí ìwọ ti di òtítọ́ àti ọ̀ràn mi mú;
    ìwọ ti jókòó lórí ìtẹ́ rẹ, láti ṣe ìdájọ́ òdodo.
Ìwọ ti bá orílẹ̀-èdè wí, Ìwọ sì ti pa ẹni búburú run;
    Ìwọ ti yọ orúkọ wọn kúrò láé àti láéláé.
Ìparun àìlópin ti borí àwọn ọ̀tá,
    Ìwọ ti fa àwọn ìlú wọn tu;
    àní ìrántí wọn sì ti ṣègbé.

Olúwa jẹ ọba títí láé;
    ó ti gbé ìtẹ́ rẹ̀ kalẹ̀ fún ìdájọ́.
(A)Òun yóò sì ṣe ìdájọ́ ayé ní òdodo;
    yóò ṣe àkóso ènìyàn pẹ̀lú òdodo.
Olúwa ni ààbò fún àwọn tí a ni lára,
    ibi ìsádi ní àkókò ìpọ́njú.
10 Àwọn tí ó mọ orúkọ rẹ yóò gbẹ́kẹ̀lé ọ,
    nítorí, Olúwa, kò kọ àwọn tó ń wá a sílẹ̀.

11 Kọ orin ìyìn sí Olúwa, tí o ń jẹ ọba ní Sioni;
    kéde láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, ohun tí ó ṣe.
12 Nítorí ẹni tí ó ń gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ rántí;
    òun kò kọ ẹkún àwọn tí a pọ́n lójú.

13 Olúwa, wo bí àwọn ọ̀tá ṣe ń ṣe inúnibíni sí mi!
    Ṣàánú, kí o sì gbé mí sókè kúrò ní ẹnu-ọ̀nà ikú,
14 Kí èmi kí ó lè sọ ti ìyìn rẹ
    ni ẹnu-ọ̀nà àwọn ọmọbìnrin Sioni
    àti láti máa yọ̀ nínú ìgbàlà rẹ.

15 Àwọn orílẹ̀-èdè ti jì sí kòtò tí wọn ti gbẹ́;
    ẹsẹ̀ wọn ni àwọ̀n tí wọ́n dẹ sílẹ̀ kọ́.
16 A mọ Olúwa nípa òdodo rẹ̀;
    àwọn ènìyàn búburú ni a dẹ́kun mú nípa iṣẹ́ ọwọ́ wọn.
17 Àwọn ènìyàn búburú ni a ó dà sí isà òkú,
    àti gbogbo orílẹ̀-èdè tí ó gbàgbé Ọlọ́run.
18 Ṣùgbọ́n àwọn aláìní ni a kò ní gbàgbé láéláé,
    ìrètí àwọn ti ó tálákà ni a kì yóò gbàgbé láéláé.

19 Dìde, Olúwa, má ṣe jẹ́ kí ènìyàn borí;
    Jẹ́ kí a ṣe ìdájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè ni iwájú rẹ.
20 Lù wọ́n pẹ̀lú ìpayà, Olúwa;
    jẹ́ kí àwọn orílẹ̀-èdè mọ̀ pé ènìyàn lásán ni wọ́n. Sela.

Saamu 15

Saamu ti Dafidi

15 Olúwa, ta ni yóò máa ṣe àtìpó nínú àgọ́ rẹ?
    Ta ni yóò máa gbé ní òkè mímọ́ rẹ?

Ẹni tí ń rìn déédé
    tí ó sì ń sọ òtítọ́,
    láti inú ọkàn rẹ̀;
tí kò fi ahọ́n rẹ̀ sọ̀rọ̀ ẹni lẹ́yìn,
    tí kò ṣe ibi sí aládùúgbò rẹ̀
    tí kò sì sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí ẹnìkejì rẹ̀,
ní ojú ẹni tí ènìyànkénìyàn di gígàn
    ṣùgbọ́n ó bọ̀wọ̀ fún àwọn tí ó bẹ̀rù Olúwa,
Ẹni tí ó búra sí ibi ara rẹ̀
    àní tí kò sì yípadà,
tí ó ń yá ni lówó láìsí èlé
    tí kò sì gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ lòdì sí aláìlẹ́ṣẹ̀.

Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe èyí
    ni a kì yóò mì láéláé.

2 Kronika 6:32-7:7

32 “Ní ti àwọn àlejò tí wọn kò sí lára àwọn ènìyàn rẹ Israẹli ṣùgbọ́n tí wọ́n wá láti ọ̀nà jíjìn nítorí orúkọ ńlá rẹ àti ọwọ́ agbára rẹ àti nínà apá rẹ, nígbà tí ó bá wá tí ó sì gbàdúrà pẹ̀lú kíkojú si ilé Olúwa yìí. 33 Nígbà náà, gbọ́ láti ọ̀run àní láti ibi ibùgbé rẹ, kí o sì ṣe ohun tí àwọn àlejò béèrè lọ́wọ́ rẹ. Bẹ́ẹ̀ ni kí gbogbo àwọn ènìyàn ayé kí wọn lè mọ orúkọ rẹ kí wọn sì bẹ̀rù rẹ, gẹ́gẹ́ bí Israẹli ènìyàn rẹ ti ṣe, kí wọn kí ó sì lè mọ̀ wí pé ilé yìí tí èmi ti kọ, orúkọ rẹ ni ó ń jẹ́.

34 “Nígbà tí àwọn ènìyàn rẹ bá lọ sójú ogun lórí àwọn ọ̀tá wọn, nígbàkígbà tí o bá rán wọn, tí wọ́n sì gbàdúrà sí ọ si ìhà ìlú yìí tí ìwọ ti yàn àti ilé Olúwa tí èmi ti kọ́ fún orúkọ rẹ. 35 Nígbà náà gbọ́ àdúrà wọn àti ẹ̀bẹ̀ wọn láti ọ̀run, kí o sì mú ọ̀rọ̀ wọn dúró.

36 “Nígbà tí wọ́n bá sì dẹ́ṣẹ̀ sí ọ—nítorí kò sí ènìyàn kan tí kì í dẹ́ṣẹ̀—bí o bá sì bínú sí wọn tí o bá sì fi wọ́n fún àwọn ọ̀tá, tí wọ́n kó wọn ní ìgbèkùn sí ilẹ̀ tí ó jìnnà réré tàbí nítòsí, 37 Ṣùgbọ́n, nígbà tí wọ́n bá sì yí ọkàn wọn padà ní ilẹ̀ tí wọ́n ti mú wọn ní ìgbèkùn, tí wọ́n sì ronúpìwàdà tí wọ́n sì bẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú rẹ ní ilẹ̀ ìgbèkùn, wọn ó sì wí pé, ‘Àwa ti dẹ́ṣẹ̀, àwa sì ti ṣe ohun tí kò dára, a sì ti ṣe búburú’. 38 Tí wọn bá sì yípadà sí ọ pẹ̀lú gbogbo ọkàn àti ẹ̀mí ní ilẹ̀ ìgbèkùn wọn níbi tí wọ́n ti mú wọn, tí wọ́n sì gbàdúrà wọn, kojú si ìlú tí ìwọ ti yàn àti lórí ilé Olúwa tí mo ti kọ́ fún orúkọ rẹ; 39 Nígbà náà, láti ọ̀run, ibi ibùgbé rẹ, gbọ́ àdúrà wọn àti ẹ̀bẹ̀ wọn, kí o sì mú ọ̀ràn wọn dúró, kí o sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn jì wọn, tí wọn ti dẹ́ṣẹ̀ sí ọ.

40 “Nísinsin yìí, Ọlọ́run mi, jẹ́ kí ojú rẹ kí ó ṣí kí o sì tẹ́ etí rẹ sílẹ̀ fún àdúrà sí ibí yìí.

41 (A)“Ǹjẹ́ nísinsin yìí dìde, Olúwa Ọlọ́run mi, sí ibi ìsinmi rẹ,
    ìwọ àti àpótí ẹ̀rí agbára rẹ.
Jẹ́ kí àwọn àlùfáà, Olúwa Ọlọ́run mi, kí o wọ̀ wọ́n láṣọ pẹ̀lú ìgbàlà,
    jẹ́ kí àwọn àyànfẹ́ kí inú wọn kí ó dùn nínú ilé rẹ.
42 Olúwa Ọlọ́run mi, má ṣe kọ̀ ẹni ààmì òróró rẹ.
    Rántí ìfẹ́ ńlá tí ó ṣe ìlérí fún Dafidi ìránṣẹ́ rẹ.”

Ìyàsímímọ́ ilé Olúwa

Nígbà tí Solomoni sì ti parí àdúrà, iná sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run ó sì jó ẹbọ sísun àti ẹbọ, ògo Ọlọ́run sì kún ilé Olúwa. Àwọn àlùfáà kò sì le wo ilé Olúwa náà nítorí pé ògo Olúwa kún un. Nígbà tí gbogbo àwọn ọmọ Israẹli rí iná tí ó ń sọ̀kalẹ̀ àti ògo Olúwa lórí ilé Olúwa náà, wọ́n sì kúnlẹ̀ lórí eékún wọn pẹ̀lú ojú ni dídàbolẹ̀, wọ́n sì sin Olúwa, wọ́n sì fi ìyìn fún Olúwa wí pé,

“Nítorí tí ó dára;
    àánú rẹ̀ sì dúró títí láéláé.”

(B)Nígbà náà ọba àti gbogbo àwọn ènìyàn sì rú ẹbọ níwájú Olúwa. Ọba Solomoni sì rú ẹbọ ti ẹgbàá-mọ́kànlá (22,000), orí màlúù àti àgùntàn àti ọ̀kẹ́ mẹ́fà àgùntàn àti ẹranko. Bẹ́ẹ̀ ni ọba àti gbogbo àwọn ènìyàn ya ilé Ọlọ́run sí mímọ́. Àwọn àlùfáà dúró ní ààyè wọn, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ Lefi ti ṣe pẹ̀lú ohun èlò orin Olúwa, tí ọba Dafidi ti ṣe fún ìyìn Olúwa àti tí á lò nígbà tí ó dúpẹ́, wí pé, “àánú rẹ̀ sì dúró láéláé,” níwájú àwọn ọmọ Lefi, àwọn àlùfáà sì fọn ìpè, gbogbo àwọn ọmọ Israẹli sì dúró.

Solomoni sì yà àgbàlá níwájú ilé Olúwa sọ́tọ̀, níbẹ̀ sì ni ó ti ṣe ìrúbọ ẹbọ sísun àti ọ̀rá ẹbọ àlàáfíà, nítorí pẹpẹ idẹ tí ó ti ṣe kò lè gba ẹbọ sísun, àti ọrẹ oúnjẹ, àti ọ̀rá náà.

Jakọbu 2:1-13

Ojúsàájú jẹ́ èèwọ̀

Ẹ̀yin ará mi, gẹ́gẹ́ bí onígbàgbọ́ nínú ògo Olúwa wá Jesu Kristi, ẹ máa ṣe ojúsàájú ẹnikẹ́ni. Nítorí bí ọkùnrin kan bá wá sí ìpéjọpọ̀ yín, pẹ̀lú òrùka wúrà àti aṣọ dáradára, tí tálákà kan sì wá pẹ̀lú nínú aṣọ èérí; tí ẹ̀yin sì bu ọlá fún ẹni tí ó wọ aṣọ dáradára tí ẹ sì wí pé, “Ìwọ jókòó níhìn-ín yìí ní ibi dáradára” tí ẹ sì wí fún tálákà náà pé, “Ìwọ dúró níbẹ̀” tàbí “jókòó níhìn-ín lábẹ́ àpótí ìtìsẹ̀ mi,” ẹyin kò ha ń dá ara yín sí méjì nínú ara yín, ẹ̀yin kò sì di onídàájọ́ tí ó ní èrò búburú bí?

Ẹ fi etí sílẹ̀, ẹ̀yin ará mi olùfẹ́: Ọlọ́run kò ha ti yan àwọn tálákà ayé yìí láti jẹ́ ọlọ́rọ̀ nínú ìgbàgbọ́, àti ajogún ìjọba náà, tí ó ti ṣe ìlérí fún àwọn tí ó fẹ́ ẹ? Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti bu tálákà kù. Àwọn ọlọ́rọ̀ kò ha ń pọ́n yin lójú bí; wọn kò ha sì ń wọ́ yín lọ sílé ẹjọ́? Wọn kò ha ń sọ ọ̀rọ̀-òdì sí orúkọ rere nì tí a fi ń pè yín bí?

(A)Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá ń mú olú òfin nì ṣẹ gẹ́gẹ́ bí Ìwé mímọ́, èyí tí ó wí pé, “Ìwọ fẹ́ ẹni kejì rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ,” ẹ̀yin ń ṣe dáradára. Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá ń ṣe ojúsàájú ènìyàn, ẹ̀yin ń dẹ́ṣẹ̀, a sì ń dá yín lẹ́bi nípa òfin bí arúfin. 10 Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá pa gbogbo òfin mọ́, tí ó sì rú ọ̀kan, ó jẹ̀bi rírú gbogbo rẹ̀. 11 (B)Nítorí ẹni tí ó wí pé, “Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe panṣágà,” òun ni ó sì wí pé, “Ìwọ kò gbọdọ̀ pànìyàn.” Ǹjẹ́ bí ìwọ kò ṣe panṣágà, ṣùgbọ́n tí ìwọ pànìyàn, ìwọ jásí arúfin.

12 Ẹ máa sọ̀rọ̀, ẹ sì máa hùwà, bí àwọn tí a ó fi òfin òmìnira dá lẹ́jọ́. 13 Nítorí ẹni tí kò ṣàánú, ni a ó ṣe ìdájọ́ fún láìsí àánú; àánú ń ṣògo lórí ìdájọ́.

Marku 14:53-65

Jesu níwájú ìgbìmọ̀ Sahẹndiri

53 (A)Wọ́n mú Jesu lọ sí ilé olórí àlùfáà, gbogbo àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbàgbà Júù àti àwọn olùkọ́ òfin péjọ síbẹ̀. 54 Peteru tẹ̀lé Jesu lókèèrè, ó sì yọ́ wọ inú àgbàlá olórí àlùfáà, ó sì jókòó pẹ̀lú àwọn ọmọ ọ̀dọ̀, ó ń yáná.

55 Bí ó ti ń ṣe èyí lọ́wọ́, àwọn olórí àlùfáà àti gbogbo ìgbìmọ̀ ilé ẹjọ́ tí ó ga jùlọ ń wá ẹni tí yóò jẹ́rìí èké sí Jesu, èyí tí ó jọjú dáradára láti lè dájọ́ ikú fún un. Ṣùgbọ́n wọn kò rí. 56 Nítorí pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀rí wọ́n ní kò bá ara wọn mu.

57 Níkẹyìn àwọn kan dìde, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ́rìí èké sí i, wọ́n ní 58 (B)“A gbọ́ tí ó wí pé ‘Èmi yóò wó tẹmpili tí ẹ fi ọwọ́ kọ́ yìí, nígbà tí yóò bá sì fi di ọjọ́ kẹta, èmi yóò kọ́ òmíràn ti a kò fi ọwọ́ ènìyàn kọ́.’ ” 59 Síbẹ̀, ẹ̀rí i wọn kò dọ́gba.

60 Nígbà náà ni àlùfáà àgbà dìde, ó bọ́ síwájú. Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í bi Jesu léèrè, ó ní, “Ṣé o kò ní fèsì sí ẹ̀sùn tí wọ́n fi sùn ọ? Kí ni ìwọ gan an ní sọ fúnrarẹ̀?” 61 Ṣùgbọ́n Jesu dákẹ́.

Olórí àlùfáà tún bi í, lẹ́ẹ̀kan sí i, ó ní, “Ṣé ìwọ ni Kristi náà, Ọmọ Olùbùkún un nì?”

62 (C)Jesu wá dáhùn, ó ni, “Èmi ni: Ẹ̀yin yóò sì rí Ọmọ Ènìyàn tí yóò jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún agbára. Ẹ̀yin yóò sì tún rí Ọmọ Ènìyàn tí ó ń bọ̀ láti inú àwọsánmọ̀ ojú ọ̀run.”

63 (D)Nígbà náà ni Olórí àlùfáà fa aṣọ rẹ̀ ya, ó ní, “Kí ló kù tì a ń wá? Kí ni a tún ń wá ẹlẹ́rìí fún? 64 (E)Ẹ̀yin fúnrayín ti gbọ́ ọ̀rọ̀-òdì tí ó sọ. Kí ni ẹ rò pé ó tọ́ kí a ṣe?”

Gbogbo wọ́n sì dáhùn wí pé, “Ó jẹ̀bi ikú.” 65 Àwọn kan sì bẹ̀rẹ̀ sí í tu itọ́ sí i lára. Wọ́n dì í lójú. Wọ́n ń kàn án lẹ́ṣẹ̀ẹ́ lójú. Wọ́n fi ṣe ẹlẹ́yà pé, “Sọtẹ́lẹ̀!” Àwọn olùṣọ́ sì ń fi àtẹ́lẹwọ́ wọn gbá a lójú.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.