Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Book of Common Prayer

Daily Old and New Testament readings based on the Book of Common Prayer.
Duration: 861 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 70-71

Fún adarí orin. Ti Dafidi. Ẹ̀bẹ̀.

70 (A)Yára, Ọlọ́run, láti gbà mí là,
    Olúwa, wá kánkán láti ràn mí lọ́wọ́.

Kí àwọn tí ń wá ọkàn mi
    kí a dójútì wọ́n, kí wọn sì dààmú;
kí àwọn tó ń wá ìparun mi
    yí ẹ̀yìn padà nínú ìtìjú.
Kí a pa wọ́n ní ẹ̀yìn dà fún èrè
    ìtìjú àwọn tí ń wí pé, “Háà! Háà!”
Ṣùgbọ́n kí àwọn tí ó ń wá ọ ó máa yọ̀
    kí inú wọn kí ó sì máa dùn nípa rẹ,
kí àwọn tí ó ń fẹ́ ìgbàlà rẹ máa wí pé,
    “Jẹ́ kí a gbé Ọlọ́run ga!”

Ṣùgbọ́n mo jẹ́ òtòṣì àti aláìní;
    wa kánkán sí ọ̀dọ̀ mi, Ọlọ́run.
Ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ àti olùdáǹdè mi;
    Olúwa, má ṣe dúró pẹ́.
71 Nínú rẹ, Olúwa, ni mo ní ààbò;
    Má ṣe jẹ́ kí ojú kí ó tì mí.
Gbà mí kí o sì tú mi sílẹ̀ nínú òdodo rẹ;
    dẹ etí rẹ sí mi, kí o sì gbà mí.
Jẹ́ àpáta ààbò mi,
    níbi tí èmi lè máa lọ,
pa àṣẹ láti gbà mí,
    nítorí ìwọ ni àpáta àti odi agbára mi.
Gbà mí, Ọlọ́run mi, lọ́wọ́ àwọn olùṣe búburú,
    ní ọwọ́ aláìṣòdodo àti ìkà ọkùnrin.

Nítorí ìwọ jẹ́ ìrètí mi, Olúwa Olódùmarè,
    ìwọ ni ìgbẹ́kẹ̀lé mi láti ìgbà èwe.
Mo gbẹ́kẹ̀lé ọ láti ìgbà ìbí mi;
    Ìwọ mú mi jáde láti inú ìyá mi wá
èmi ó máa yìn ọ́ títí láé.
Mo di ààmì fún ọ̀pọ̀ ènìyàn,
    ṣùgbọ́n ìwọ ni ààbò mi tí ó lágbára.
Ìyìn rẹ̀ kún ẹnu mi,
    ó ń sọ ti ọlá rẹ ní ọjọ́ gbogbo.

Má ṣe ta mí nù ní ọjọ́ ogbó mi
    Má ṣe kọ̀ mí sílẹ̀ nígbà tí kò sí okun mọ́
10 Nítorí àwọn ọ̀tá mi ń sọ̀rọ̀-òdì sí mi,
    àwọn tí wọn dúró láti pa mí gbìmọ̀ pọ̀.
11 Wọ́n wí pé, “Ọlọ́run ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀;
    lépa rẹ̀ kí ẹ sì mu,
    nítorí kò sí ẹni tí yóò gbà á.”
12 Má ṣe jìnnà sí mi, Ọlọ́run;
    wa kánkán, Ọlọ́run mi, láti ràn mí lọ́wọ́.
13 Jẹ́ kí wọn kí ó dààmú,
    kí a sì run àwọn tí ń ṣe ọ̀tá ọkàn mi
kí a sì fi ẹ̀gàn àti àbùkù
    bo àwọn tí ń wá ìpalára mi.

14 Ṣùgbọ́n ní tèmi, ìgbà gbogbo ní ìrètí mi;
    èmi ó yìn ọ́ síwájú àti síwájú sí i.

15 Ẹnu mi yóò sọ nípa ti òdodo rẹ,
ti ìgbàlà rẹ, ni gbogbo ọjọ́,
lóòtítọ́, èmi kò mọ iye rẹ̀.
16 Èmi ó wá láti wá kéde agbára,
    Olúwa Olódùmarè;
    èmi ó kéde òdodo rẹ̀ nìkan.
17 Láti ìgbà èwe, Ọlọ́run ni ìwọ ti kọ́ mi
    títí di òní ni mo ń sọ ti iṣẹ́ ìyanu rẹ.
18 Pẹ̀lúpẹ̀lú, nígbà tí èmi di arúgbó tán tí mo sì hewú,
    Má ṣe kọ̀ mí sílẹ̀, Ọlọ́run mi,
títí èmi ó fi ipá rẹ han ìran tí ń bọ̀,
    àti agbára rẹ fún gbogbo àwọn tí ń bọ̀ lẹ́yìn.

19 Ọlọ́run, òdodo rẹ dé ọ̀run,
    ìwọ tí o ti ṣe ohun ńlá
    Ta ni ó dàbí rẹ, Ọlọ́run?
20 Pẹ̀lúpẹ̀lú ìwọ ti mú mi rí ìdààmú, tí ó pọ̀ tí ó sì korò,
    ìwọ yóò tún sọ ayé mi jí
ìwọ yóò sì tún mú mi sọ sókè
    láti ọ̀gbun ilẹ̀ wá.
Ìwọ yóò sọ ọlá mi di púpọ̀
21 Ìwọ yóò fi kún ọwọ́ mi
    ìwọ yóò tù mí nínú ní ha gbogbo.

22 Èmi yóò fi dùùrù mi yìn
    fún òtítọ́ rẹ, Ọlọ́run mi;
èmi ó kọrin ìyìn sí ọ pẹ̀lú dùùrù
    ìwọ ẹni mímọ́ Israẹli.
23 Ètè mi yóò kígbe fún ìyìn
    nígbà tí mo bá kọrin ìyìn sí ọ:
    èmi, ẹni tí o rà padà.
24 Ahọ́n mi yóò sọ ti òdodo rẹ ní gbogbo ọjọ́,
    fún àwọn tí ó fẹ́ pa mí lára,
    a sì dójúti àwọn tí ń wá ìdààmú mi.

Saamu 74

Maskili ti Asafu.

74 Ọlọ́run, èéṣe tí ìwọ fi kọ̀ wá sílẹ̀ títí láé?
    Èéṣe tí ìbínú rẹ̀ fi dìde sí àwọn àgùntàn pápá rẹ?
Rántí àwọn ènìyàn tí ìwọ ti rà nígbà àtijọ́,
    ẹ̀yà ilẹ̀ ìní rẹ, tí ìwọ ti rà padà
    Òkè Sioni, níbi tí ìwọ ń gbé.
Yí ẹsẹ̀ rẹ padà sí ìparun ayérayé wọn,
    gbogbo ìparun yìí tí ọ̀tá ti mú wá sí ibi mímọ́.

Àwọn ọ̀tá rẹ ń bú ramúramù
    láàrín ènìyàn rẹ,
wọ́n ń gbé àsíá wọn sókè fún ààmì;
Wọ́n ń rí bí ọkùnrin tí ó gbé àáké rẹ̀ sókè
    láti gé igi igbó dídí.
Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, iṣẹ́ ọnà fínfín,
    ni wọ́n fi àáké wó lulẹ̀ ní ẹ̀ẹ̀kan náà.
Wọ́n sun ibi mímọ́ rẹ lulẹ̀
    wọ́n ba ibùgbé orúkọ rẹ jẹ́
Wọ́n wí ní ọkàn wọn. “Àwa ó run wọ́n pátápátá!”
    Wọ́n sun gbogbo ibi ìjọ́sìn Ọlọ́run ní ilẹ̀ náà.

A kò fún wa ní ààmì iṣẹ́ ìyanu kankan;
    kò sí wòlíì kankan
    ẹnìkankan wa kò mọ ìgbà tí eléyìí yóò dà.
10 Àwọn ọ̀tá yóò ti kùn sí ọ pẹ́ tó, Ọlọ́run?
    Àwọn ọ̀tá yóò ha ba orúkọ rẹ jẹ́ títí láé?
11 Èéṣe tí ìwọ fi dá ọwọ́ rẹ dúró, ọwọ́ ọ̀tún rẹ?
    Mú un kúrò nínú ìṣẹ́po aṣọ rẹ kí o sì run wọ́n!

12 Ṣùgbọ́n ìwọ Ọlọ́run ni ọba mi láti ìgbà pípẹ́;
    Ó mú ìgbàlà wá sórí ilẹ̀ ayé.

13 Ìwọ ni ó la Òkun sílẹ̀ nípa agbára rẹ;
    Ìwọ fọ́ orí ẹ̀mí búburú nínú omi
14 Ìwọ fọ́ orí Lefitani túútúú, o sì fi ṣe oúnjẹ fun àwọn ẹ̀dá tí ń gbé inú ijù
    Tìrẹ ni ọ̀sán, tìrẹ sì ni alẹ́ pẹ̀lú;
    ìwọ fi ìdí oòrùn àti òṣùpá lélẹ̀.
15 Ìwọ ya orísun omi àti ìṣàn omi;
    Ìwọ mú kí odò tó ń sàn gbẹ
16 Tìrẹ ni ọ̀sán, tìrẹ ni òru pẹ̀lú;
    ìwọ yà oòrùn àti òṣùpá.
17 Ìwọ pààlà etí ayé;
    Ìwọ dá ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn àti ìgbà òtútù.

18 Rántí bí àwọn ọ̀tá ń kẹ́gàn rẹ, Olúwa
    bí àwọn aṣiwèrè ènìyàn ti ń ba orúkọ rẹ jẹ́.
19 Má ṣe fi ẹ̀mí àdàbà rẹ fún ẹranko igbó búburú;
    Má ṣe gbàgbé ẹ̀mí àwọn ènìyàn rẹ tí a ń pọ́n lójú títí láé.
20 Bojú wo májẹ̀mú rẹ,
    nítorí ibi òkùnkùn ayé kún fún ibùgbé ìkà.
21 Má ṣe jẹ́ kí àwọn aninilára padà sẹ́yìn nínú ìtìjú
    jẹ́ kí àwọn aláìní àti tálákà yin orúkọ rẹ.
22 Dìde, Ọlọ́run, gba ẹjọ́ ara rẹ rò;
    rántí bí àwọn aṣiwèrè ti ń kẹ́gàn rẹ ní gbogbo ọjọ́.
23 Má ṣe gbàgbé ohùn àwọn ọ̀tá rẹ,
    bíbú àwọn ọ̀tá rẹ, tí ó ń pọ̀ sí i nígbà gbogbo.

1 Ọba 22:29-45

A pa Ahabu ní Ramoti Gileadi

29 Bẹ́ẹ̀ ni ọba Israẹli àti Jehoṣafati ọba Juda gòkè lọ sí Ramoti Gileadi. 30 Ọba Israẹli sì wí fún Jehoṣafati pé, “Èmi yóò pa aṣọ dà, èmi yóò sì lọ sí ojú ìjà, ṣùgbọ́n ìwọ yóò wọ aṣọ ìgúnwà rẹ.” Bẹ́ẹ̀ ni ọba Israẹli pa aṣọ dà, ó sì lọ sí ojú ìjà.

31 Ọba Aramu ti pàṣẹ fún àwọn olórí kẹ̀kẹ́ rẹ̀ méjìlélọ́gbọ̀n wí pé, “Ẹ má ṣe bá ẹnìkankan jà, ẹni kékeré tàbí ẹni ńlá, bí kò ṣe ọba Israẹli nìkan.” 32 Nígbà tí àwọn olórí kẹ̀kẹ́ sì rí Jehoṣafati, wọ́n sì wí pé, “Dájúdájú ọba Israẹli ni èyí.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n yípadà láti bá a jà, ṣùgbọ́n nígbà tí Jehoṣafati sì kígbe sókè, 33 àwọn olórí kẹ̀kẹ́ sì rí i pé kì í ṣe ọba Israẹli, wọ́n sì padà kúrò lẹ́yìn rẹ̀.

34 Ṣùgbọ́n ẹnìkan sì fa ọrun rẹ̀ láìròtẹ́lẹ̀, ó sì ta ọba Israẹli láàrín ìpàdé ẹ̀wù irin. Ọba Israẹli sì wí fún olùtọ́jú kẹ̀kẹ́ rẹ̀ pé, “Yí ọwọ́ rẹ dà, kí o sì mú mi jáde kúrò nínú ogun. Èmi ti gbọgbẹ́.” 35 Ogun náà sì le ní ọjọ́ náà, a sì dá ọba dúró nínú kẹ̀kẹ́ kọjú sí àwọn ará Aramu. Ẹ̀jẹ̀ sì sàn jáde láti inú ọgbẹ́ rẹ̀ sí àárín kẹ̀kẹ́ náà, ó sì kú ní àṣálẹ́. 36 A sì kéde la ibùdó já ní àkókò ìwọ̀-oòrùn wí pé, “Olúkúlùkù sí ìlú rẹ̀ àti olúkúlùkù sí ilẹ̀ rẹ̀!”

37 Bẹ́ẹ̀ ni ọba kú, a sì gbé e wá sí Samaria, wọ́n sì sin ín ní Samaria. 38 Wọ́n sì wẹ kẹ̀kẹ́ náà ní adágún Samaria, àwọn ajá sì lá ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, àwọn àgbèrè sì wẹ ara wọn nínú rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa ti sọ.

39 Ní ti ìyókù ìṣe Ahabu, àti gbogbo èyí tí ó ṣe, àti ilé eyín erin tí ó kọ́, àti gbogbo ìlú tí ó tẹ̀dó, a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé ọ̀rọ̀ ọjọ́ àwọn ọba Israẹli? 40 Ahabu sì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀. Ahasiah ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.

Jehoṣafati ọba Juda

41 Jehoṣafati ọmọ Asa, sì bẹ̀rẹ̀ sí ní jẹ ọba lórí Juda ní ọdún kẹrin Ahabu ọba Israẹli. 42 Jehoṣafati sì jẹ́ ẹni ọdún márùn-dínlógójì nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí ń jẹ ọba ní ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ní Jerusalẹmu. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Asuba ọmọbìnrin Silihi. 43 Ó sì rìn nínú gbogbo ọ̀nà Asa baba rẹ̀, kò sì yípadà kúrò nínú rẹ̀; ó sì ṣe èyí tí ó tọ́ ní ojú Olúwa. Kìkì àwọn ibi gíga ni a kò mú kúrò, àwọn ènìyàn sì ń rú ẹbọ, wọ́n sì ń sun tùràrí níbẹ̀. 44 Jehoṣafati sì wà ní àlàáfíà pẹ̀lú ọba Israẹli.

45 Ní ti ìyókù ìṣe Jehoṣafati àti ìṣe agbára rẹ̀ tí ó ṣe, àti bí ó ti jagun sí, a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé ọ̀rọ̀ ọjọ́ àwọn ọba Juda?

1 Kọrinti 2:14-3:15

14 (A)Ṣùgbọ́n ènìyàn nípa ti ara kò gba ohun ti Ẹ̀mí Ọlọ́run wọ̀n-ọ́n-nì, nítorí pé wèrè ni wọ́n jásí fún un, òun kò sì le mọ̀ wọ́n, nítorí nípa tí Ẹ̀mí ní a fi ń wádìí wọn. 15 (B)Ṣùgbọ́n ẹni tí ó wà nípa ti ẹ̀mí ń wádìí ohun gbogbo, ṣùgbọ́n kò sí ẹnikẹ́ni tí í wádìí rẹ̀.

16 (C)“Nítorí ta ni ó mọ ọkàn Olúwa,
    ti yóò fi máa kọ́ Ọ?”

Ṣùgbọ́n àwa ní inú Kristi.

Lórí ìyapa nínú ìjọ

(D)Ará, èmí kò sí le bá yín sọ̀rọ̀ bí àwọn tí í ṣe ti Ẹ̀mí, bí kò ṣe bí àwọn ti í ṣe ti ara, àní bí àwọn ọmọ ọwọ́ nínú Kristi. (E)Wàrà ni mo ti fi bọ́ yín, kì í ṣe oúnjẹ; nítorí ẹ kò í tí le gbà á nísinsin yìí náà, ẹ kò í tí le gbà a. Nítorí ẹ̀yin jẹ́ ti ara síbẹ̀. Nítorí, níwọ̀n bí owú jíjẹ àti ìjà ṣe wà láàrín ara yín, ẹ̀yin kò ha ṣe ti ayé bí? Ẹ̀yin kò ha ṣe bí ènìyàn lásán bí? (F)Ǹjẹ́ ẹ̀yin kì í ṣe ènìyàn lásán bí? Níwọ́n ìgbà tí ẹ ba ń sọ pé, “Èmi ń tẹ̀lé Paulu,” àti ti ẹlòmíràn tún wí pé, “Èmi ń tẹ̀lé Apollo.”

(G)Jú gbogbo rẹ̀ lọ, kí ni Apollo ha jẹ́, kín ni Paulu sì jẹ́, àwọn ìránṣẹ́ lásán, nípasẹ̀ ẹni tí ẹ̀yin gbàgbọ́, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti fi fún olúkúlùkù. (H)Èmi gbìn, Apollo ń bomirin; ṣùgbọ́n Ọlọ́run ni ń mú ìbísí wá. Ǹjẹ́ kì í ṣe ẹni tí ó ń gbìn nǹkan kan, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe ẹni tí ń bomirin; bí kò ṣe Ọlọ́run tí ó ń mú ìbísí wá. Ẹni tí ó ń gbìn àti ẹni tí ó ń bu omi rín ní ìrònú kan àti èrèdí kan, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹnìkọ̀ọ̀kan wa yóò gba èrè tirẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe é kárakára tó. (I)A ń bá Ọlọ́run ṣiṣẹ́ pọ̀ ni, ẹ̀yin pàápàá sì jẹ́ ọgbà ohun ọ̀gbìn fún Ọlọ́run, kì í ṣe fún wa, ilé Ọlọ́run ni yín, kì í ṣe ilé tiwa.

10 (J)Nípa oore-ọ̀fẹ́ tí Ọlọ́run tí fi fún mi, gẹ́gẹ́ bí ọlọ́gbọ́n ọ̀mọ̀lé, mo ti fi ìpìlẹ̀ ilé lélẹ̀, ẹlòmíràn sì ń mọ lé e, ṣùgbọ́n kí olúkúlùkù kíyèsára bí yóò ṣe mọ ọ́n lé e. 11 (K)Nítorí kò sí ẹlòmíràn tó le fi ìpìlẹ̀ tòótọ́ mìíràn lélẹ̀ ju èyí tí a fi lélẹ̀ àní Jesu Kristi ni ìpìlẹ̀ náà. 12 Ǹjẹ́ bí ẹnikẹ́ni bá fi wúrà, fàdákà, òkúta olówó-iyebiye, igi, koríko, àgékù koríko mọ lé orí ìpìlẹ̀ yìí. 13 (L)Iṣẹ́ olúkúlùkù ènìyàn yóò hàn, nítorí ọjọ́ náà yóò fi í hàn, nítorí pé nínú iná ni a ó ti fihàn, iná náà yóò sì dán irú iṣẹ́ èyí tí olúkúlùkù ṣe wò. 14 Bí iṣẹ́ tí ẹnikẹ́ni bá ṣe lórí rẹ̀ bá dúró, òun yóò sì gba èrè rẹ̀. 15 (M)Bí iṣẹ́ ẹnikẹ́ni bá jóná, òun yóò pàdánù: Ṣùgbọ́n òun tìkára rẹ̀ ni a ó gbàlà, ṣùgbọ́n bí ìgbà tí ènìyàn bá la àárín iná kọjá.

Matiu 5:1-10

Ìwàásù orí òkè

(A)Nígbà tí ó rí ọ̀pọ̀ ènìyàn, ó gun orí òkè lọ ó sì jókòó. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ si tọ̀ ọ́ wá. Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ wọn.

Ó wí pé:

(B)“Alábùkún fún ni àwọn òtòṣì ní ẹ̀mí,
    nítorí tiwọn ni ìjọba ọ̀run.
(C)Alábùkún fún ni àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀,
    nítorí a ó tù wọ́n nínú.
(D)Alábùkún fún ni àwọn ọlọ́kàn tútù,
    nítorí wọn yóò jogún ayé.
(E)Alábùkún fún ni àwọn tí ebi ń pa
    tí òǹgbẹ ń gbẹ́ nítorí òdodo, nítorí wọn yóò yó.
Alábùkún fún ni àwọn aláàánú,
    nítorí wọn yóò rí àánú gbà.
(F)Alábùkún fún ni àwọn ọlọ́kàn mímọ́,
    nítorí wọn yóò rí Ọlọ́run.
Alábùkún fún ni àwọn onílàjà,
    nítorí ọmọ Ọlọ́run ni a ó máa pè wọ́n.
10 (G)Alábùkún fún ni àwọn ẹni tí a ṣe inúnibíni sí,
    nítorí tí wọ́n jẹ́ olódodo
    nítorí tiwọn ní ìjọba ọ̀run.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.