Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
Fún adarí orin. Gẹ́gẹ́ bí ti gittiti. Ti àwọn ọmọ Kora. Saamu.
84 Ibùgbé rẹ̀ ti lẹ́wà tó,
Olúwa àwọn ọmọ-ogun!
2 Ọkàn mi ń ṣàfẹ́rí nítòótọ́
ó tilẹ̀ pòǹgbẹ fún àgbàlá Olúwa
àyà mi àti ara mi ń kọrin ayọ̀
sí Ọlọ́run alààyè.
3 Nítòótọ́ ológoṣẹ́ ri ilé,
ẹyẹ alápáǹdẹ̀dẹ̀ tẹ́ ìtẹ́ fún ara rẹ̀,
níbi tí yóò máa pa ọmọ rẹ̀ mọ́ sí:
ibùgbé ní tòsí pẹpẹ rẹ̀,
Olúwa àwọn ọmọ-ogun, ọba mí àti Ọlọ́run mi.
4 Ìbùkún ní fún àwọn tí ó ń gbé inú ilé rẹ;
wọn ó máa yìn ọ́ títí láé.
5 Ìbùkún ni fún àwọn tí agbára wọn wà nínú rẹ
àwọn tí wọ́n gbé ọkàn lé bíbẹ ibi mímọ́ wò.
6 Àwọn tí ń la Àfonífojì omijé lọ
wọn sọ ọ́ di kànga
àkọ́rọ̀ òjò sì fi ìbùkún bò ó;
7 Wọ́n ń lọ láti ipa dé ipá
títí tí ọ̀kọ̀ọ̀kan fi farahàn níwájú Ọlọ́run ní Sioni.
8 Gbọ́ àdúrà mi, Olúwa Ọlọ́run Alágbára;
tẹ́tí sí mi, Ọlọ́run Jakọbu.
9 Wo asà wa, Ọlọ́run;
fi ojú àánú wò àwọn ẹni ààmì òróró rẹ.
10 Dídára ní ọjọ́ kan ní ààfin rẹ
ju ẹgbẹ̀rún ọjọ́ lọ;
èmi o kúkú máa ṣe aṣọ́nà nínú ilé Ọlọ́run mi
jù láti gbé ní àgọ́ àwọn ènìyàn búburú.
11 Nítorí Olúwa Ọlọ́run jẹ́ òòrùn àti asà;
Olúwa fún ni ní ojúrere àti ọlá;
kò sí ohun rere kan tí yóò fàsẹ́yìn
fún àwọn tí ó rìn ní àìlábùkù.
12 Olúwa àwọn ọmọ-ogun,
ìbùkún ni fún ọkùnrin náà tí ó gbẹ́kẹ̀lé ọ.
Solomoni kọ́ ilé náà
6 (A)Ní ìgbà tí ó pe ọ̀rìnlénírinwó ọdún (480) lẹ́yìn ìgbà tí àwọn ọmọ Israẹli ti jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti, ní ọdún kẹrin ìjọba Solomoni lórí Israẹli, ní oṣù Sifi, tí ń ṣe oṣù kejì, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ ilé Olúwa.
2 Ilé náà tí Solomoni ọba kọ́ fún Olúwa sì jẹ́ ọgọ́ta ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, ogún ìgbọ̀nwọ́ ní ìbú àti ọgbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ ní gíga. 3 Ìloro níwájú tẹmpili ilé náà, ogún ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn rẹ̀, ìbú ilé náà, ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá láti iwájú ilé náà. 4 Ó sì ṣe fèrèsé tí kò fẹ̀ fún ilé náà.
21 Solomoni sì fi kìkì wúrà bo inú ilé náà, ó sì tan ẹ̀wọ̀n wúrà dé ojú ibi mímọ́ jùlọ, ó sì fi wúrà bò ó. 22 Gbogbo ilé náà ni ó fi wúrà bò títí ó fi parí gbogbo ilé náà, àti gbogbo pẹpẹ tí ó wà níhà ibi mímọ́ jùlọ, ni ó fi wúrà bò.
10 (A)Nípa oore-ọ̀fẹ́ tí Ọlọ́run tí fi fún mi, gẹ́gẹ́ bí ọlọ́gbọ́n ọ̀mọ̀lé, mo ti fi ìpìlẹ̀ ilé lélẹ̀, ẹlòmíràn sì ń mọ lé e, ṣùgbọ́n kí olúkúlùkù kíyèsára bí yóò ṣe mọ ọ́n lé e. 11 (B)Nítorí kò sí ẹlòmíràn tó le fi ìpìlẹ̀ tòótọ́ mìíràn lélẹ̀ ju èyí tí a fi lélẹ̀ àní Jesu Kristi ni ìpìlẹ̀ náà. 12 Ǹjẹ́ bí ẹnikẹ́ni bá fi wúrà, fàdákà, òkúta olówó-iyebiye, igi, koríko, àgékù koríko mọ lé orí ìpìlẹ̀ yìí. 13 (C)Iṣẹ́ olúkúlùkù ènìyàn yóò hàn, nítorí ọjọ́ náà yóò fi í hàn, nítorí pé nínú iná ni a ó ti fihàn, iná náà yóò sì dán irú iṣẹ́ èyí tí olúkúlùkù ṣe wò. 14 Bí iṣẹ́ tí ẹnikẹ́ni bá ṣe lórí rẹ̀ bá dúró, òun yóò sì gba èrè rẹ̀. 15 (D)Bí iṣẹ́ ẹnikẹ́ni bá jóná, òun yóò pàdánù: Ṣùgbọ́n òun tìkára rẹ̀ ni a ó gbàlà, ṣùgbọ́n bí ìgbà tí ènìyàn bá la àárín iná kọjá.
16 (E)Ṣé ẹ̀yin kò tilẹ̀ mọ̀ pé tẹmpili Ọlọ́run ni ẹ̀yin jẹ́? Àti pẹ̀lú pe Ẹ̀mí Ọlọ́run ń gbé inú yín? 17 Bí ẹnikẹ́ni bá ba tẹmpili Ọlọ́run jẹ́, òun ni Ọlọ́run yóò parun; nítorí pé mímọ́ ni tẹmpili Ọlọ́run, èyí tí ẹ̀yin jẹ́.
18 (F)Kí ẹnikẹ́ni, má ṣe tan ara rẹ̀ jẹ mọ́. Bí ẹnikẹ́ni yín nínú ayé yìí ba rò pé òun gbọ́n, ẹ jẹ́ kí ó di òmùgọ̀ kí ó bá a le è gbọ́n. 19 (G)Nítorí ọgbọ́n ayé yìí jẹ́ òmùgọ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run. Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ nínú Ìwé Mímọ́ pé, “Ẹni ti tí ó mu àwọn ọlọ́gbọ́n nínú àrékérekè wọn”; 20 (H)lẹ́ẹ̀kan sí i, “Olúwa mọ̀ èrò inú àwọn ọlọ́gbọ́n pé asán ní wọn.” 21 (I)Nítorí kí ẹnikẹ́ni má ṣe ṣògo nínú ènìyàn. Nítorí tí yín ni ohun gbogbo. 22 (J)Ìbá ṣe Paulu, tàbí Apollo, tàbí Kefa, tàbí ayé tàbí ìyè, tàbí ikú, tàbí ohun ìsinsin yìí, tàbí ohun ìgbà tí ń bọ̀; tiyín ni gbogbo wọn. 23 Ẹ̀yin sì ni ti Kristi; Kristi sì ni ti Ọlọ́run.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.