Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
2 Ọba 2:1-12

Elijah gun kẹ̀kẹ́ iná lọ sí ọ̀run

Nígbà tí Ọlọ́run ń fẹ́ gbé Elijah lọ sí òkè ọ̀run nínú àjà, Elijah àti Eliṣa wà ní ọ̀nà láti Gilgali. Elijah wí fún Eliṣa pé, “Dúró níbí; Olúwa rán mi lọ sí Beteli.”

Ṣùgbọ́n Eliṣa wí pé, “Gẹ́gẹ́ bí ó ti dájú pé Olúwa wà láyé àti gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ, Èmi kò ní fi ọ́ sílẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sọ̀kalẹ̀ lọ sí Beteli.

Àwọn ọmọ wòlíì ní Beteli jáde wá sí ọ̀dọ̀ Eliṣa wọ́n sì béèrè pé, “Ṣé ìwọ mọ̀ pé Olúwa yóò gba ọ̀gá rẹ kúrò lọ́dọ̀ rẹ lónìí?”

“Bẹ́ẹ̀ ni, Èmi mọ̀,” Eliṣa dáhùn “Ṣùgbọ́n ẹ má ṣe sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.”

Nígbà náà Elijah sì wí fún un pé, “Dúró níbí, Eliṣa: Olúwa ti rán mi lọ sí Jeriko.”

Ó sì dá a lóhùn pé, “Bí ó ti dájú pé Olúwa yè àti tí ìwọ náà yè, Èmi kò ní fi ọ́ sílẹ̀.” Wọ́n sì jọ lọ sí Jeriko.

Àwọn ọmọ wòlíì tí ó wà ní Jeriko sì gòkè tọ Eliṣa wá wọ́n sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Ṣé ìwọ mọ̀ wí pé Olúwa yóò gba ọ̀gá rẹ kúrò lọ́dọ̀ rẹ lónìí?”

“Bẹ́ẹ̀ ni, Èmi mọ̀,” Ó dá wọn lóhùn, “Ṣùgbọ́n ẹ má ṣe sọ nípa rẹ̀.”

Nígbà náà Elijah wí fún un pé, “Dúró níbí; Olúwa rán mi lọ sí Jordani.”

Ó sì dá a lóhùn pé, “Gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́ wí pé, Olúwa yè àti gẹ́gẹ́ bí o ti yè, èmi kò ní fi ọ́ sílẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni àwọn méjèèjì sì jọ ń lọ.

Àádọ́ta àwọn ọkùnrin ọmọ wòlíì sì lọ láti lọ dúró ní ọ̀nà jíjìn, wọ́n sì kọ ojú da ibi tí Elijah àti Eliṣa ti dúró ní Jordani. Elijah sì mú agbádá ó sì ká a sókè ó sì lu omi náà pẹ̀lú rẹ̀. Omi náà sì pín sí ọ̀tún àti sí òsì, àwọn méjèèjì sì rékọjá lórí ilẹ̀ gbígbẹ.

Nígbà tí wọ́n rékọjá, Elijah sì wí fún Eliṣa pé, “Sọ fún mi, kí ni èmi lè ṣe fún ọ kí ó tó di wí pé wọ́n gbà mí kúrò lọ́dọ̀ rẹ?”

“Jẹ́ kí èmi kí ó jogún ìlọ́po méjì ẹ̀mí rẹ.” Ó dá a lóhùn.

10 “Ìwọ ti béèrè ohun tí ó ṣòro,” Elijah wí pé, “Síbẹ̀ tí ìwọ bá rí mi nígbà tí a bá gbà mí kúrò lọ́wọ́ rẹ, yóò jẹ́ tìrẹ bí bẹ́ẹ̀ kọ́ kò ní rí bẹ́ẹ̀.”

11 (A)Gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ń rìn lọ tí wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ pọ̀, lọ́gán kẹ̀kẹ́ iná àti ẹṣin iná yọ sí wọn ó sì ya àwọn méjèèjì nípa, Elijah sì gòkè lọ sí ọ̀run pẹ̀lú àjà. 12 Eliṣa rí èyí ó sì kígbe sókè, “Baba mi! Baba mi! Kẹ̀kẹ́ àti ẹlẹ́ṣin Israẹli!” Eliṣa kò sì rí i mọ́. Ó sì mú aṣọ ara rẹ̀ ó sì fà wọ́n ya sọ́tọ̀.

Saamu 50:1-6

Saamu ti Asafu

50 Olúwa, Ọlọ́run alágbára
    sọ̀rọ̀ kí o sì pe ayé jọ
    láti ìlà-oòrùn títí dé ìwọ̀ rẹ̀.
Láti Sioni wá, pípé ni ẹwà,
    Ọlọ́run tí ń tan ìmọ́lẹ̀
Ọlọ́run ń bọ̀,
    bẹ́ẹ̀ ni kì yóò dákẹ́,
iná yóò máa jó níwájú rẹ̀,
    àti ní àyíká rẹ̀ ni ẹ̀fúùfù líle yóò ti máa jà ká.
Yóò sì pe àwọn ọ̀run láti òkè wá jọ àti ayé,
    kí o le máa ṣe ìdárò àwọn ènìyàn rẹ̀.
“Kó àwọn ènìyàn mímọ́ jọ fún mi
    àwọn tí wọn fi ẹbọ dá májẹ̀mú fún mi.”
Àwọn ọ̀run yóò sì sọ̀rọ̀ òdodo rẹ̀,
    Nítorí Ọlọ́run fúnrarẹ̀ ni onídàájọ́.

2 Kọrinti 4:3-6

Ṣùgbọ́n báyìí, bí Ìhìnrere wa bá sí fi ara sin, ó fi ara sin fún àwọn tí ó ń ṣègbé. (A)Nínú àwọn ẹni tí ọlọ́run ayé yìí ti sọ ọkàn àwọn aláìgbàgbọ́ dí afọ́jú, kí ìmọ́lẹ̀ ìhìnrere Kristi tí ó lógo, ẹni tí í ṣe àwòrán Ọlọ́run, má ṣe mọ́lẹ̀ nínú wọn. Nítorí àwa kò wàásù àwa tìkára wa, bí kò ṣe Kristi Jesu Olúwa; àwa tìkára wa sì jẹ́ ẹrú yín nítorí Jesu. (B)Nítorí Ọlọ́run ni ẹni tí ó wí pé, “Kí ìmọ́lẹ̀ ó tan láti inú òkùnkùn jáde,” òun ní ó ti ń tan mọ́lẹ̀ lọ́kàn wa, láti fún wa ní ìmọ́lẹ̀ ìmọ̀ ògo Ọlọ́run ní ojú Jesu Kristi.

Marku 9:2-9

Ìparadà

(A)(B) Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́fà tí Jesu sọ̀rọ̀ yìí, Jesu mú Peteru, Jakọbu àti Johanu lọ sí orí òkè gíga ní apá kan. Kò sí ẹlòmíràn pẹ̀lú wọn, ara rẹ̀ sì yípadà níwájú wọn. (C)Aṣọ rẹ̀ sì di dídán, ó sì funfun gbòò, tí alágbàfọ̀ kan ní ayé kò lè sọ di funfun bẹ́ẹ̀. Nígbà náà ni Elijah àti Mose farahàn fún wọn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ pẹ̀lú Jesu.

Peteru sì wí fún Jesu pé, “Rabbi, ó dára fún wa láti máa gbé níhìn-ín, si jẹ́ kí a pa àgọ́ mẹ́ta, ọ̀kan fun ọ, ọ̀kan fún Mose, àti ọ̀kan fún Elijah.” Nítorí òun kò mọ ohun tí òun ìbá sọ, nítorí ẹ̀rù bà wọ́n gidigidi.

(D)Ìkùùkuu kan sì bò wọ́n, ohùn kan sì ti inú ìkùùkuu náà wá wí pé: “Èyí ni àyànfẹ́ ọmọ mi: Ẹ máa gbọ́ ti rẹ̀!”

Lójijì, wọ́n wo àyíká wọn, wọn kò sì rí ẹnìkankan mọ́, bí kò ṣe Jesu nìkan ṣoṣo ni ó sì wà pẹ̀lú wọn.

(E)(F) Bí wọ́n ti ń sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè, Jesu kìlọ̀ fún wọn kí wọ́n má ṣe sọ ohun tí wọ́n ti rí fún ẹnikẹ́ni títí Ọmọ Ènìyàn yóò fi jíǹde kúrò nínú òkú.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.