Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
Fún adarí orin. Fún Jedutuni. Ti Asafu. Saamu.
77 Mó kígbe sí Ọlọ́run fún ìrànlọ́wọ́;
mo kígbe sí Ọlọ́run láti gbọ́ tèmi.
2 Nígbà tí mo wà nínú ìpọ́njú,
mo wá Olúwa;
ní òru ni mo na ọwọ́ mi jáde ní àìkáárẹ̀
ọkàn mí sì kọ̀ láti tù ú nínú.
3 Èmi rántí rẹ, Ọlọ́run,
mo sì kẹ́dùn;
mo ṣe àròyé, ẹ̀mí mi sì rẹ̀wẹ̀sì. Sela.
4 Ìwọ kò fẹ́ kí èmi fi ojú ba oorun,
mo dààmú tó bẹ́ẹ̀ tí ń kò le sọ̀rọ̀.
5 Mo ronú nípa ọjọ́ ìgbàanì;
ọdún pípẹ́ sẹ́yìn;
6 Mo rántí orin mi ní òru.
Èmi ń bá àyà mi sọ̀rọ̀,
ọkàn mi sì ń ṣe àwárí jọjọ.
7 “Olúwa yóò ha kọ̀ títí láé?
Ki yóò ha ṣe ojúrere rẹ̀ mọ́?
8 Ṣe ìfẹ́ rẹ̀ àti àánú rẹ̀ ti kú lọ láéláé?
Ìlérí rẹ̀ ha kùnà títí ayé?
9 Ọlọ́run ha gbàgbé láti máa ṣàánú?
Ní ìbínú rẹ̀, ó ha sé ojúrere rẹ̀ mọ́?” Sela.
10 Èmi wí pé, “Èyí ní ẹ̀dùn ọkàn mi,
pé ọwọ́ ọ̀tún Ọ̀gá-ògo jùlọ ti yípadà”.
11 Èmi ó rántí iṣẹ́ Olúwa:
bẹ́ẹ̀ ni, èmi ó rántí iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ ọjọ́ pípẹ́.
12 Èmi ṣàṣàrò lórí iṣẹ́ rẹ gbogbo
pẹ̀lú, ènìyàn sì máa sọ̀rọ̀ gbogbo iṣẹ́ agbára rẹ.
13 Ọlọ́run, Ọ̀nà rẹ jẹ́ mímọ́.
Ọlọ́run wo ni ó sì tóbi bí Ọlọ́run wa?
14 Ìwọ ni Ọlọ́run tó ń ṣe ìyanu;
ìwọ fi agbára rẹ hàn nínú àwọn ènìyàn.
15 Pẹ̀lú ọwọ́ agbára rẹ ni ìwọ ra àwọn ènìyàn padà,
àwọn ọmọ Jakọbu àti Josẹfu. Sela.
16 Nígbà tí àwọn omi rí Ọlọ́run,
nígbà tí àwọn omi rí ọ,
ẹ̀rù bà wọ́n,
nítòótọ́ ara ibú kò balẹ̀.
17 Àwọn ojú ọ̀run tú omi sílẹ̀,
àwọsánmọ̀ fi àrá dáhùn;
ọfà rẹ̀ ń tàn sẹ́yìn àti síwájú
18 Àrá rẹ̀ ni a gbọ́ nínú ìjì,
ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀ sí gbogbo ayé;
ayé bẹ̀rù, wọ́n sì wárìrì.
19 Ipa rẹ̀ gba Òkun, ọ̀nà rẹ̀ ń bẹ nínú Òkun,
Ọ̀nà la omi alágbára kọjá ipa rẹ̀ ń bẹ nínú líla omi alágbára kọjá,
nítòótọ́ a kò rí ojú ẹsẹ̀ rẹ̀.
20 Ó tọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀wọ́ ẹran
nípa ọwọ́ Mose àti Aaroni.
8 “Ṣùgbọ́n bí ó ṣe tèmi, ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ní èmi yóò ti ṣìpẹ̀,
ní ọwọ́ Ọlọ́run ní èmi yóò máa fi ọ̀rọ̀ mi lé.
9 Ẹni tí ó ṣe ohun tí ó tóbi tí a kò lè ṣe àwárí,
ohun ìyanu láìní iye.
10 Tí ń rọ̀jò sí orí ilẹ̀ ayé
tí ó sì ń rán omi sínú ilẹ̀kílẹ̀.
11 Láti gbé àwọn orílẹ̀-èdè lékè
kí á lè gbé àwọn ẹni ìbànújẹ́ ga sí ibi aláìléwu.
12 (A)Ó yí ìmọ̀ àwọn alárékérekè po,
bẹ́ẹ̀ ní ọwọ́ wọn kò lè mú ìdáwọ́lé wọn ṣẹ.
13 Ó mú àwọn ọlọ́gbọ́n nínú àrékérekè ara wọn,
àti ìmọ̀ àwọn òǹrorò ní ó tì ṣubú ní ògèdèǹgbé.
14 Wọ́n sáré wọ inú òkùnkùn ní ọ̀sán;
wọ́n sì fọwọ́ tálẹ̀ ní ọ̀sán gangan bí ẹni pé ní òru ni.
15 Ṣùgbọ́n ó gba tálákà là ní ọwọ́ idà,
lọ́wọ́ ẹnu wọn àti lọ́wọ́ àwọn alágbára.
16 Bẹ́ẹ̀ ni ìrètí wà fún tálákà,
àìṣòótọ́ sì pa ẹnu rẹ̀ mọ́.
17 “Kíyèsi i, ìbùkún ni fún ẹni tí Ọlọ́run bá wí,
nítorí náà, má ṣe gan ìbáwí Olódùmarè.
18 Nítorí pé òun a máa pa ni lára, síbẹ̀ òun a sì tún dì í ní ìdì ìtura,
ó sá lọ́gbẹ́, a sì fi ọwọ́ rẹ̀ di ojú ọgbẹ̀ náà jiná.
19 Yóò gbà ọ́ nínú ìpọ́njú mẹ́fà,
àní nínú méje, ibi kan kì yóò bá ọ
20 Nínú ìyanu yóò gbà ọ́ lọ́wọ́ ikú
àti nínú ogun, yóò gbà ọ́ lọ́wọ́ idà.
21 A ó pa ọ́ mọ́ kúrò lọ́wọ́ iná ahọ́n,
bẹ́ẹ̀ ní ìwọ kì yóò bẹ̀rù ìparun tí ó bá dé.
22 Ìwọ yóò rẹ́rìn-ín nínú ìparun àti ìyàn,
bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kì yóò bẹ̀rù ẹranko ilẹ̀ ayé.
23 Nítorí pé ìwọ ti bá òkúta igbó mulẹ̀,
àwọn ẹranko igbó yóò wà pẹ̀lú rẹ ní àlàáfíà.
24 Ìwọ ó sì mọ̀ pé àlàáfíà ni ibùjókòó rẹ wà,
ìwọ yóò sì máa ṣe ìbẹ̀wò ibùjókòó rẹ, ìwọ kì yóò ṣìnà.
25 Ìwọ ó sì mọ̀ pẹ̀lú pé irú-ọmọ rẹ ó sì pọ̀
àti àwọn ọmọ ọmọ rẹ yóò rí bí koríko igbó.
26 Ìwọ yóò wọ isà òkú rẹ ní ògbólógbòó ọjọ́,
bí síírí ọkà tí ó gbó tí á sì kó ní ìgbà ìkórè rẹ̀.
27 “Kíyèsi i, àwa ti wádìí rẹ̀ bẹ́ẹ̀ ní ó rí!
Gbà á gbọ́, kí o sì mọ̀ pé fún ìre ara rẹ ni.”
Jíjìyà fún ṣíṣe iṣẹ́ rere
8 Lákòótan, kí gbogbo yín jẹ́ onínú kan, ẹ máa bá ara yín kẹ́dùn, ẹ ní ìfẹ́ ará, ẹ máa ṣe ìyọ́nú, ẹ ni ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ 9 Ẹ má ṣe fi búburú san búburú, tàbí fi èébú san èébú: ṣùgbọ́n kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ máa súre; nítorí èyí ni a pè yín sí, kí ẹ̀yin lè jogún ìbùkún. 10 (A)Nítorí,
“Ẹni tí yóò bá fẹ́ ìyè,
ti yóò sì rí ọjọ́ rere,
kí o pa ahọ́n rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ibi,
àti ètè rẹ̀ mọ́ kúrò nínú sísọ ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn:
11 Kí ó yà kúrò nínú ibi, kí ó sì máa ṣe rere;
kí ó máa wá àlàáfíà, kí ó sì máa lépa rẹ̀.
12 Nítorí ojú Olúwa ń bẹ lára àwọn olódodo,
etí rẹ̀ sì ṣí sí ẹ̀bẹ̀ wọn:
ṣùgbọ́n ojú Olúwa korò sí àwọn tí ń ṣe búburú.”
13 Tá nì yóò sì ṣe yín ní ibi, bí ẹ̀yin bá jẹ́ onítara sí ohun rere? 14 (B)Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá jìyà nítorí òdodo, a ti bùkún yín. “Ẹ má ṣe bẹ̀rù ìhàlẹ̀ wọn, kí ẹ má sì ṣe kọminú.” 15 Ṣùgbọ́n ẹ bọ̀wọ̀ fún Kristi bí Olúwa ní ọkàn yín: kí ẹ sì múra tan nígbà gbogbo láti dá olúkúlùkù lóhùn tí ń béèrè ìrètí tí o ń bẹ nínú yín, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ọkàn tútù àti ìbẹ̀rù. 16 Kí ẹ máa ni ẹ̀rí ọkàn rere bí wọ́n ti ń sọ̀rọ̀ yín ní ibi, kí ojú lè ti àwọn tí ń kẹ́gàn ìwà rere yín nínú Kristi. 17 Nítorí ó sàn, bí ó bá jẹ́ ìfẹ́ Ọlọ́run, kí ẹ jìyà fún ṣíṣe rere ju fún ṣíṣe búburú lọ. 18 Nítorí tí Kristi pẹ̀lú jìyà lẹ́ẹ̀kan nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa, olóòótọ́ fún àwọn aláìṣòótọ́, kí a lè mú wa dé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ẹni tí a pa nínú ara, ṣùgbọ́n tí a sọ di ààyè nínú ẹ̀mí:
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.