Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Complementary)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with thematically matched Old and New Testament readings.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 1

ÌWÉ KÌN-ÍN-NÍ

Saamu 1–41

(A)Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà,
    tí kò rìn ní ìmọ̀ àwọn ènìyàn búburú,
ti kò dúró ní ọ̀nà àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀,
    tàbí tí kò sì jókòó ní ibùjókòó àwọn ẹlẹ́gàn.
Ṣùgbọ́n ayọ̀ inú rẹ̀ wà nínú òfin Olúwa
    àti nínú òfin rẹ̀ ni ó ń ṣe àṣàrò ní ọ̀sán àti òru.
Ó dàbí igi tí a gbìn sí etí odò tí ń sàn,
    tí ń so èso rẹ̀ jáde ní àkókò rẹ̀
tí ewé rẹ̀ kì yóò rẹ̀.
    Ohunkóhun tí ó dáwọ́lé, ni yóò máa yọrí sí rere.

Kò le rí bẹ́ẹ̀ fún àwọn ènìyàn búburú!
    Wọn yóò dàbí ìyàngbò ọkà
    tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ dànù.
Nítorí náà àwọn ènìyàn búburú kì yóò le è dìde dúró ní ìdájọ́,
    bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ kì yóò le è dúró ní àwùjọ àwọn olódodo.

Nítorí Olúwa ń ṣọ́ ọ̀nà àwọn olódodo,
    ṣùgbọ́n ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú ni yóò ṣègbé.

Deuteronomi 29:2-20

Mose pàṣẹ fún gbogbo àwọn ọmọ Israẹli, ó sì wí fún wọn wí pé:

Ojú rẹ ti rí gbogbo ohun tí Olúwa ti ṣe ní Ejibiti sí Farao àti, sí gbogbo àwọn ìjòyè e rẹ̀ àti sí ilẹ̀ ẹ rẹ̀. Pẹ̀lú ojú ara rẹ ni ìwọ rí àwọn ìdánwò ńlá náà, àwọn iṣẹ́ ààmì àti iṣẹ́ ìyanu ńlá. (A)Ṣùgbọ́n títí di àsìkò yìí Olúwa kò fi ọkàn ìmòye tàbí ojú tí ó ń rí tàbí etí tí ó n gbọ́ fún ọ. Nígbà ogójì ọdún tí mò ń tọ́ yín ṣọ́nà ní aginjù, aṣọ ọ̀ rẹ kò gbó tàbí bàtà ẹsẹ̀ rẹ. O kò jẹ oúnjẹ tàbí mu wáìnì kankan tàbí rú ohun mímu mìíràn. Mo ṣe èyí kí o lè mọ̀ pé èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ.

Nígbà tí o dé ibí yìí, Sihoni ọba Heṣboni àti Ogu ọba Baṣani jáde wá láti bá ọ jà, ṣùgbọ́n a ṣẹ́gun wọn. A gba ilẹ̀ wọn a sì fi fún àwọn ọmọ Reubeni, àti àwọn ọmọ Gadi, àti ààbọ̀ ẹ̀yà Manase bí ogún.

Nítorí náà, ẹ pa májẹ̀mú yìí mọ́, kí ẹ sì máa ṣe wọ́n, kí ẹ̀yin kí ó lè máa rí ire nínú gbogbo ohun tí o bá ń ṣe. 10 Gbogbo yín ń dúró lónìí yìí níwájú Olúwa Ọlọ́run rẹ: àwọn olórí yín, àwọn ẹ̀yà yín, àwọn àgbàgbà yín àti àwọn ìjòyè yín, àní gbogbo àwọn ọkùnrin mìíràn ní Israẹli, 11 pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ ọ̀ rẹ àti ìyàwó ò rẹ àti àwọn àjèjì tí wọ́n ń gbé ní àgọ́ ọ̀ rẹ, tí ó ké pópòpó igi rẹ, tí ó sì gbé omi rẹ. 12 O dúró níhìn-ín yìí kí o lè wọ inú májẹ̀mú pẹ̀lú Olúwa Ọlọ́run rẹ, májẹ̀mú tí Olúwa ń ṣe pẹ̀lú rẹ lónìí yìí àti tí òun dè pẹ̀lú ìbúra, 13 láti jẹ́wọ́ rẹ lónìí yìí bí ènìyàn an rẹ̀, pé kí ó lè jẹ́ Ọlọ́run rẹ bí ó ti ṣèlérí àti bí ó ti ṣe ìbúra fún àwọn baba à rẹ Abrahamu, Isaaki àti Jakọbu. 14 Èmi ń ṣe májẹ̀mú yìí, pẹ̀lú ìbúra rẹ̀, kì í ṣe fún ìwọ nìkan 15 tí ó dúró níbí pẹ̀lú wa lónìí níwájú Olúwa Ọlọ́run wa ṣùgbọ́n àti fún gbogbo àwọn tí kò sí níbí lónìí.

16 Ìwọ fúnra à rẹ mọ bí a ṣe gbé ní Ejibiti àti bí a ṣe kọjá láàrín àwọn orílẹ̀-èdè nílẹ̀ ibí yìí. 17 Ìwọ rí láàrín wọn ìríra wọn, àwọn ère àti àwọn òrìṣà igi àti ti òkúta, ti fàdákà àti ti wúrà. 18 (B)Rí i dájú pé kò sí ọkùnrin tàbí obìnrin, ìdílé tàbí ẹ̀yà láàrín yín lónìí tí ọkàn an rẹ̀ yóò yí kúrò lọ́dọ̀ Olúwa Ọlọ́run wa láti lọ àti láti sin àwọn ọlọ́run àwọn orílẹ̀-èdè náà; rí i dájú pé kò sí gbòǹgbò tí ó ń mú irú èso kíkan bẹ́ẹ̀ jáde láàrín yín.

19 Nígbà tí irú ẹni bẹ́ẹ̀ bá gbọ́ ìbúra yìí, kí ó gbàdúrà ìbùkún sórí ara rẹ̀ nígbà náà ni kí ó ronú, “Èmi yóò wà ní àlàáfíà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ti fi àáké kọ́rí nípa lílọ nínú ọ̀nà ti ara à mi.” Èyí yóò mú àjálù wá sórí ilẹ̀ tútù àti sórí ilẹ̀ gbígbẹ bákan náà 20 Olúwa kì yóò ní ìfẹ́ sí àti dáríjì í; ìbínú àti ìtara rẹ̀ yóò jó ọkùnrin náà. Gbogbo àwọn ègún tí a kọ sínú ìwé yìí yóò wá sórí i rẹ̀, Olúwa yóò sì yọ orúkọ rẹ̀ kúrò lábẹ́ ọ̀run.

Matiu 10:34-42

34 (A)“Ẹ má ṣe rò pé mo mú àlàáfíà wá sí ayé, Èmi kò mú àlàáfíà wá bí kò ṣe idà. 35 Nítorí èmi wá láti ya

“ ‘ọmọkùnrin ní ipa sí baba rẹ̀,
    ọmọbìnrin ní ipa sí ìyá rẹ̀,
àti aya ọmọ sí ìyakọ rẹ̀…
36     Ará ilé ènìyàn ni yóò sì máa ṣe ọ̀tá rẹ̀.’

37 (B)“Ẹni tí ó bá fẹ́ baba rẹ̀ tàbí ìyá rẹ̀ jù mí lọ, kò yẹ ní tèmi, ẹni tí ó ba fẹ́ ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin rẹ̀ jù mí lọ, kò yẹ ní tèmi; 38 Ẹni tí kò bá gbé àgbélébùú rẹ̀ kí ó tẹ̀lé mi kò yẹ ní tèmi. 39 Ẹni tí ó bá wa ẹ̀mí rẹ̀ yóò sọ ọ́ nù, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá sọ ẹ̀mí rẹ̀ nú nítorí tèmi ni yóò rí i.

40 (C)“Ẹni tí ó bá gbà yín, ó gbà mí, ẹni tí ó bá sì gbà mí gba ẹni tí ó rán mi. 41 Ẹni tí ó ba gba wòlíì, nítorí pé ó jẹ́ wòlíì yóò jẹ èrè wòlíì, ẹni tí ó bá sì gba olódodo nítorí ti ó jẹ́ ènìyàn olódodo, yóò jẹ èrè olódodo. 42 Ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ago omi tútù fún ọ̀kan nínú àwọn onírẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí mu nítorí tí ó jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn mi, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, kò ní pàdánù èrè rẹ̀.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.