Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Complementary)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with thematically matched Old and New Testament readings.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 119:65-72

Ìpọ́njú mu ni mọ òfin Ọlọ́run

65 Ṣe rere sí ìránṣẹ́ rẹ
    gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ, Olúwa.
66 Kọ́ mi ní ìmọ̀ àti ìdájọ́ rere,
    nítorí mo gbàgbọ́ nínú àṣẹ rẹ.
67 Kí a tó pọ́n mi lójú èmi ti ṣìnà,
    ṣùgbọ́n ni ìsinsin yìí èmi gbọ́rọ̀ sí ọ̀rọ̀ rẹ.
68 Ìwọ dára, ohun tí ìwọ sì ń ṣe rere ni;
    kọ́ mi ní ìlànà rẹ.
69 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn agbéraga ti gbìmọ̀ èké sí mí,
    èmi pa ẹ̀kọ́ rẹ mọ́ pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi.
70 Ọkàn wọn yigbì kò sì ní àánú,
    ṣùgbọ́n èmi ní inú dídùn nínú òfin rẹ.
71 Ó dára fún mi kí a pọ́n mi lójú
    nítorí kí èmi lè kọ́ òfin rẹ.
72 Òfin tí ó jáde láti ẹnu rẹ ju iyebíye sí mi lọ
    ó ju ẹgbẹ̀rún ẹyọ fàdákà àti wúrà lọ.

Isaiah 57:14-21

Ìtùnú fún àwọn oníròbìnújẹ́

14 A ó sì sọ wí pé:

“Tún mọ, tún mọ, tún ọ̀nà náà ṣe!
    Ẹ mú àwọn ohun ìkọ̀sẹ̀ kúrò ní ọ̀nà àwọn ènìyàn mi.”
15 (A)Nítorí èyí ni ohun tí Ẹni gíga àti ọlọ́lá jùlọ wí
    ẹni tí ó wà títí láé, tí orúkọ rẹ̀ jẹ́ mímọ́:
“Mo ń gbé ní ibi gíga àti ibi mímọ́,
    ṣùgbọ́n pẹ̀lú ẹni n nì tí ó ní ìròbìnújẹ́ àti ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀,
láti sọ ẹ̀mí onírẹ̀lẹ̀ náà jí
    àti láti sọ ẹ̀mí oníròbìnújẹ́ n nì jí.
16 Èmi kì yóò fẹ̀sùn kan ni títí láé,
    tàbí kí n máa bínú sá á,
nítorí nígbà náà ni ọkàn ènìyàn yóò
    rẹ̀wẹ̀sì níwájú mi
    èémí ènìyàn tí mo ti dá.
17 Inú bí mi nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ọ̀kánjúwà rẹ̀;
    mo fìyà jẹ ẹ́, mo sì fojú mi pamọ́ ní ìbínú
    síbẹ̀, ó tẹ̀síwájú nínú tinú-mi-ni n ó ṣe ọ̀nà rẹ̀.
18 Èmi ti rí ọ̀nà rẹ̀ gbogbo, ṣùgbọ́n Èmi yóò wò ó sàn;
    Èmi yóò tọ́ ọ ṣọ́nà n ó sì mú ìtùnú tọ̀ ọ́ wá,
19 (B)ní dídá ìyìn sí ètè àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ ní Israẹli.
    Àlàáfíà, àlàáfíà fún àwọn tí ó wà lókèèrè àti nítòsí,”
    ni Olúwa wí, “Àti pé Èmi yóò wo wọ́n sàn.”
20 Ṣùgbọ́n àwọn ìkà dàbí i ríru Òkun
    tí kò le è sinmi,
    tí ìgbì rẹ̀ ń rú pẹ̀tẹ̀pẹ́tẹ̀ àti ẹrọ̀fọ̀ sókè.
21 “Kò sí àlàáfíà,” ni Ọlọ́run mi wí, “fún àwọn ìkà.”

Luku 14:15-24

Òwe nípa àsè ńlá

15 (A)Nígbà tí ọ̀kan nínú àwọn tí wọ́n jọ jókòó gbọ́ nǹkan wọ̀nyí, ó wí fún Jesu pé, “Alábùkún ni fún ẹni tí yóò jẹ oúnjẹ àsè ní ìjọba Ọlọ́run!”

16 (B)Jesu dá a lóhùn pé, “Ọkùnrin kan ṣe àsè alẹ́ ńlá, ó sì pe ènìyàn púpọ̀. 17 Ó sì rán ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ ní wákàtí àsè alẹ́ náà láti sọ fún àwọn tí a ti pè pé, ‘Ẹ wá; nítorí ohun gbogbo ṣetán!’

18 “Gbogbo wọn sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àwáwí ohun kan. ‘Èkínní wí fún un pé, mo ra ilẹ̀ kan, mo sì fẹ́ lọ wò ó wò, mo bẹ̀ ọ́ ṣe gáfárà fún mi.’

19 “Èkejì sì wí pé, ‘Mo ra àjàgà màlúù márùn-ún, mo sì ń lọ wò wọ́n wò: mo bẹ̀ ọ́ ṣe gáfárà fún mi.’

20 (C)“Ẹ̀kẹta sì wí pé, ‘Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ gbéyàwó, nítorí náà ni èmi kò fi lè wá.’

21 (D)“Ọmọ ọ̀dọ̀ náà sì padà dé, ó sọ nǹkan wọ̀nyí fún olúwa rẹ̀. Nígbà náà ni baálé ilé bínú, ó wí fún ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé, ‘Jáde lọ sí ìgboro, àti sí òpópó ọ̀nà, kí o sì mú àwọn tálákà, àti àwọn amúnkùn ún, àti àwọn arọ, àti àwọn afọ́jú wá sí ìhín yìí.’

22 “Ọmọ ọ̀dọ̀ náà sì wí pé, ‘Olúwa a ti ṣe bí o ti pàṣẹ, ààyè sì ń bẹ síbẹ̀.’

23 “Olúwa náà sì wí fún ọmọ ọ̀dọ̀ náà pé, ‘Jáde lọ sí òpópó, àti sí ọ̀nà ọgbà, kí o sì rọ̀ wọ́n láti wọlé wá, kí ilé mi lè kún. 24 Nítorí mo wí fún yín, ẹnikẹ́ni nínú àwọn ènìyàn wọ̀nyí tí a ti pè, kì yóò tọ́wò nínú àsè ńlá mi!’ ”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.