Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Old/New Testament

Each day includes a passage from both the Old Testament and New Testament.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 110-112

Ti Dafidi. Saamu.

110 (A)Olúwa sọ fún Olúwa mi pé:

“Ìwọ jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi,
    títí èmi yóò fi sọ àwọn ọ̀tá rẹ
    di àpótí ìtìsẹ̀ rẹ.”

Olúwa yóò na ọ̀pá agbára rẹ̀
    láti Sioni wá, ìwọ jẹ ọba láàrín àwọn ọ̀tá rẹ.
Àwọn ènìyàn rẹ jẹ́ ọ̀rẹ́ àtinúwá
    ní ọjọ́ ìjáde ogun rẹ, nínú ẹwà mímọ́,
    láti inú òwúrọ̀ wá ìwọ ni ìrì ẹwà rẹ.

(B)Olúwa ti búra,
    kò sì í yí ọkàn padà pé,
“Ìwọ ni àlùfáà,
    ní ipasẹ̀ Melkisedeki.”

Olúwa, ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ ni
    yóò lu àwọn ọba bolẹ̀ ni ọjọ́ ìbínú rẹ̀
Yóò ṣe ìdájọ́ láàrín kèfèrí,
    yóò kún ibùgbé wọn pẹ̀lú òkú ara;
    yóò fọ́n àwọn olórí ká sí orí ilẹ̀ ayé tí ó gbòòrò.
Yóò mu nínú odò ṣíṣàn ní ọ̀nà:
    nítorí náà ni yóò ṣe gbé orí sókè.
111 Ẹ máa yin Olúwa.

Èmi yóò máa yin Olúwa pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi,
    ní àwùjọ àwọn olóòtítọ́, àti ní ìjọ ènìyàn.

Iṣẹ́ Olúwa tóbi, àwọn tí ó ní inú dídùn, ń ṣe àṣàrò nínú rẹ̀.
Iṣẹ́ rẹ̀ ni ọláńlá àti ògo:
    àti òdodo rẹ̀ dúró láéláé.
Ó ti ṣe iṣẹ́ ìyanu rẹ̀, láti máa rántí:
    Olúwa ni olóore-ọ̀fẹ́ àti pé ó kún fún àánú.
Ó ti fi oúnjẹ fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀:
    òun ń rántí májẹ̀mú rẹ̀.

Ó ti fihan àwọn ènìyàn rẹ̀ agbára iṣẹ́ rẹ̀
    láti fún wọn ní ilẹ̀ ìlérí ní ìní
Iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ jẹ́ òtítọ́ àti ìdájọ́;
    gbogbo òfin rẹ̀ sì dájú.
Wọ́n dúró láé àti láé,
    ní òtítọ́ àti òdodo ni a ṣe wọ́n.
Ó rán ìràpadà sí àwọn ènìyàn rẹ̀:
    ó pàṣẹ májẹ̀mú rẹ̀ títí láé:
    Mímọ́ àti ọ̀wọ̀ ni orúkọ rẹ̀.

10 Ìbẹ̀rù Olúwa ni ìpilẹ̀ṣẹ̀ ọgbọ́n:
    òye dáradára ni yóò máa ṣe òfin rẹ̀,
    ìyìn rẹ̀ dúró láé.
112 Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.

Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run,
    tí ó ní inú dídùn ńlá sí àwọn òfin rẹ̀.

Irú-ọmọ rẹ̀ yóò jẹ́ alágbára ní ayé:
    ìran àwọn olóòtítọ́ ni a ó bùkún fún.
Ọlá àti ọrọ̀ yóò wà nínú ilé rẹ̀;
    òdodo rẹ̀ sì dúró láé.
Fún olóòótọ́ ni ìmọ́lẹ̀ yóò tàn fún ní òkùnkùn:
    olóore-ọ̀fẹ́ àti aláàánú àti òdodo.
Ènìyàn rere fi ojúrere hàn,
    a sì wínni;
    ìmòye ni yóò máa fi la ọ̀nà iṣẹ́ rẹ̀.

Dájúdájú a kì yóò le yí ní ipò padà láéláé:
    olódodo ni a ó máa ṣe ìrántí rẹ láéláé.
Òun kì yóò béèrè ìyìn búburú:
    ọkàn rẹ̀ ti dúró, ó ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa.
Ó ti mú ọkàn rẹ̀ gbilẹ̀, ẹ̀rù kí yóò bà á,
    títí yóò fi rí ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ lórí àwọn ọ̀tá rẹ̀.
(C)Ó ti pín ká, ó ti fi fún àwọn olùpọ́njú;
    Nítorí òdodo rẹ̀ dúró láé;
    ìwo rẹ̀ ní a ó gbé sókè pẹ̀lú ọlá.

10 Ènìyàn búburú yóò ri, inú wọn yóò sì bàjẹ́,
    yóò sì pa eyín keke, yó sì yọ dànù:
    èròǹgbà ọkàn ènìyàn búburú ni yóò ṣègbé.

1 Kọrinti 5

Ẹ yọ alágbèrè ọkùnrin kúrò

(A)Ìròyìn rẹ ń tàn kalẹ̀ pé ìwà àgbèrè wa láàrín yín, irú àgbèrè tí a kò tilẹ̀ gbúròó rẹ̀ láàrín àwọn aláìkọlà pé, ẹnìkan nínú yín ń fẹ́ ìyàwó baba rẹ̀. Ẹ̀yin ń ṣe ìgbéraga! Ẹ̀yin kò kúkú káàánú kí a lè mú ẹni tí ó hu ìwà yìí kúrò láàrín yín? (B)Lóòtítọ́ èmi kò sí láàrín yín nípa ti ara, ṣùgbọ́n mo wà lọ́dọ̀ yín nínú ẹ̀mí àti pé, ní orúkọ Olúwa Jesu Kristi, mo tí ṣe ìdájọ́ lórí irú ẹni bẹ́ẹ̀, bí ẹni pé mo wá láàrín yín. (C)Ní orúkọ Jesu Kristi. Nígbà tí ẹ̀yin bá péjọ, àti ẹ̀mí mi si wa pẹ̀lú yin nínú ẹ̀mí mi àti pẹ̀lú agbára Jesu Kristi Olúwa wa. (D)Kí ẹ fi irú ẹni bẹ́ẹ̀ lé Satani lọ́wọ́ fún ìparun ara, kí ó ba à le gba ẹ̀mí rẹ là ní ọjọ́ Olúwa wa Jesu Kristi.

(E)Ìṣeféfé yín kò dára. Ẹ̀yin kò mọ̀ pé ìwúkàrà díẹ̀ ní mú gbogbo ìyẹ̀fun di wíwú? Nítorí náà ẹ mú ìwúkàrà àtijọ́ kúrò nínú yín, kí ẹ̀yin kí ó lè jẹ ìyẹ̀fun tuntun, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin tí jẹ àkàrà ti kò ní ìwúkàrà. Nítorí à ti fi ìrékọjá wa, àní Kristi ni a ti pa láti fi ṣe ẹbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ wa. (F)Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á pa àjọ náà mọ́, kì í ṣe pẹ̀lú ìwúkàrà àtijọ́ bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe pẹ̀lú ìwúkàrà àrankàn àti ìwà búburú, ṣùgbọ́n pẹ̀lú àkàrà tí kò ní ìwúkàrà, àkàrà òtítọ́ àti òdodo.

(G)Nígbà tí mo kọ̀wé ṣáájú sí i yín, mo sọ fún yín pé, kí ẹ má ṣe darapọ̀ pẹ̀lú àwọn alágbèrè ènìyàn. 10 (H)Nígbà tí mo sọ bẹ́ẹ̀ ń kò sọ̀rọ̀ nípa àwọn tí ayé yìí, tí wọ́n ń gbé ìgbé ayé wọn nínú ẹ̀ṣẹ̀ àgbèrè, àti àwọn olójúkòkòrò tí ń rẹ́ ni jẹ, àwọn olè àti àwọn abọ̀rìṣà. Nítorí ó dájú pé ẹ̀yin gbọdọ̀ kúrò nínú ayé yìí láti yẹra fún wọn. 11 (I)Ṣùgbọ́n nísinsin yìí mo kọ̀wé sí i yín pé, bí ẹnikẹ́ni tí a pe rẹ̀ ni arákùnrin bá jẹ́ àgbèrè, tàbí wọ̀bìà, tàbí abọ̀rìṣà, àti ẹlẹ́gàn, tàbí ọ̀mùtípara, tàbí alọ́nilọ́wọ́gbà. Kí ẹ tilẹ̀ bá irú ẹni bẹ́ẹ̀ jẹun.

12 (J)Nítorí èwo ni tèmi láti máa ṣe ìdájọ́ àwọn tí ń bẹ lóde? Kì í ha ṣe àwọn tí ó wà nínú ni ẹ̀yin ṣe ìdájọ́ wọn? 13 (K)Ọlọ́run yóò ṣe ìdájọ́ àwọn tí ó ń bẹ lóde. “Ẹ lé àwọn ènìyàn búburú náà kúrò láàrín yín.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.