Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Old/New Testament

Each day includes a passage from both the Old Testament and New Testament.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 81-83

Fún adarí orin. Gẹ́gẹ́ bí ti gittiti. Ti Asafu.

81 Kọrin sókè sí Ọlọ́run agbára wa
    Ẹ hó ìhó ayọ̀ sí Ọlọ́run Jakọbu!
Ẹ mú orin mímọ́, kí ẹ sì mú ìlù wá,
    tẹ dùùrù dídùn pẹ̀lú ohun èlò orin mímọ́.

Ẹ fún ìpè ní oṣù tuntun
    àní nígbà tí a yàn;
ní ọjọ́ àjọ wa tí ó ní ìrònú.
Èyí ni àṣẹ fún Israẹli,
    àti òfin Ọlọ́run Jakọbu.
Ó fi múlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìlànà fún Josẹfu
    nígbà tí ó la ilẹ̀ Ejibiti já.

    Níbi tí a ti gbọ́ èdè tí kò yé wa.

Ó wí pé, “Mo gbé àjàgà kúrò ní èjìká yín,
    a tú ọwọ́ wọn sílẹ̀ kúrò nínú apẹ̀rẹ̀.
Nínú ìnilára ni ẹ pè mo sì gbà yín là,
    mo dá a yín lóhùn nínú ìkọ̀kọ̀ àrá,
    mo dán an yín wò ní odò Meriba. Sela.

“Gbọ́, ẹ̀yin ènìyàn mi, èmi ó sì kìlọ̀ fún un yín,
    bí ìwọ bá fetí sí mi, ìwọ Israẹli.
Ẹ̀yin kì yóò ní Ọlọ́run ilẹ̀ mìíràn láàrín yín;
    ẹ̀yin kì yóò foríbalẹ̀ fún Ọlọ́run àjèjì.
10 Èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ,
    ẹni tí ó mú un yín jáde láti Ejibiti.
    Ẹ la ẹnu yín gbòòrò, èmi yóò sì kún un.

11 “Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn mi kì yóò gbọ́ tèmi;
    Israẹli kò ní tẹríba fún mi.
12 Nítorí náà ni mo ṣe fi wọ́n fún ọkàn líle wọn
    láti máa rìn ní ọ̀nà ẹ̀tàn wọn.

13 “Bí àwọn ènìyàn mi yóò bá gbọ́ tèmi
    bí Israẹli yóò bá tẹ̀lé ọ̀nà mi,
14 Ní kánkán ni èmi yóò ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá wọn
    kí n sì yí ọwọ́ mi padà sí ọ̀tá wọn!
15 Àwọn tí ó kórìíra Olúwa yóò tẹríba níwájú rẹ̀.
    Ìjìyà wọn yóò sì pẹ́ títí láé
16 Ṣùgbọ́n a ó fi ọkà tí ó dára bọ́ ọ yín
    èmi ó tẹ́ ẹ yín lọ́rùn pẹ̀lú oyin inú àpáta.”

Saamu ti Asafu.

82 Ọlọ́run ń ṣàkóso nínú ìpéjọpọ̀ ńlá,
    ó ṣe ìdájọ́ láàrín àwọn “ọlọ́run òrìṣà”.

“Yóò ti pẹ́ tó tí ìwọ yóò máa gbèjà àwọn aláìṣòdodo
    kí ó sì ṣe ojú ìṣáájú sí àwọn ènìyàn búburú?
Gbèjà àwọn aláìlágbára àti aláìní baba;
    ṣe ìtọ́jú ẹ̀tọ́ àwọn aláìní àti ẹni ìnilára.
Gba àwọn aláìlágbára àti aláìní;
    gbà wọ́n kúrò lọ́wọ́ àwọn ènìyàn búburú.

“Wọn kò mọ̀ ohun kankan,
    wọn kò lóye ohun kankan.
Wọn ń rìn kiri nínú òkùnkùn;
    à si mí gbogbo ìpìlẹ̀ ayé.

(A)“Mo wí pé, ‘Ẹyin ní “Ọlọ́run òrìṣà”;
    ẹ̀yin ní gbogbo ọmọ Ọ̀gá-ògo jùlọ.’
Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ó kú bí ènìyàn lásán;
    ẹ̀yin ó ṣubú bí ọ̀kan nínú ọmọ-aládé.”

Dìde, Ọlọ́run, ṣe ìdájọ́ ayé,
    nítorí gbogbo orílẹ̀-èdè ni ìní rẹ.

Orin. Saamu ti Asafu.

83 Ọlọ́run, má ṣe dákẹ́;
    Má ṣe dákẹ́, Ọlọ́run má ṣe dúró jẹ́ẹ́.
Wo bí àwọn ọ̀tá rẹ ti ń rọ́kẹ̀kẹ̀ lọ,
    bi àwọn ọ̀tá rẹ ti ń gbé ohùn wọn sókè.
Pẹ̀lú àrékérekè ni wọn dìtẹ̀ sí àwọn ènìyàn rẹ;
    wọn sí dìtẹ̀ mọ́ àwọn tí o fẹ́.
Wọn wí pé, “wá, ẹ jẹ́ kí á pa wọ́n run bí orílẹ̀-èdè,
    kí orúkọ Israẹli ma bá a sí ní ìrántí mọ́.”

Wọ́n gbìmọ̀ pọ̀ pẹ̀lú ọkàn kan;
    wọ́n ṣe àdéhùn láti ṣọ̀tẹ̀ sí ọ
Àgọ́ Edomu àti ti àwọn ará Iṣmaeli,
    ti Moabu àti ti Hagari
Gebali, Ammoni àti Amaleki,
    Filistia, pẹ̀lú àwọn ènìyàn Tire.
Asiria pẹ̀lú ti darapọ̀ mọ́ wọn
    láti ran àwọn ọmọ Lọti lọ́wọ́. Sela.

Ṣe sí wọn bí ìwọ ti ṣe sí Midiani
    bí o ti ṣe sí Sisera àti Jabini ní odò Kiṣoni,
10 Ẹni tí ó ṣègbé ní Endori
    tí wọn sì dàbí ààtàn ní orí ilẹ̀.
11 Ṣe àwọn ọlọ́lá wọn bí Orebu àti Seebu,
    àwọn ọmọ-aládé wọn bí Seba àti Salmunna,
12 Tí ó wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a gbà ní ìní
    àní pápá oko tútù Ọlọ́run.”

13 Ìwọ Ọlọ́run, ṣe wọ́n bí ààjà,
    bí ìyàngbò níwájú afẹ́fẹ́.
14 Bí iná ti í jó igbó,
    àti bí ọ̀wọ́-iná ti ń mú òkè ńlá gbiná,
15 Bẹ́ẹ̀ ni kí o fi ẹ̀fúùfù líle rẹ lépa wọn
    dẹ́rùbà wọn lójú pẹ̀lú ìjì rẹ.
16 Fi ìtìjú kún ojú wọn,
    kí àwọn ènìyàn bá à lè ṣe àfẹ́rí orúkọ rẹ àti kí o fi ìjì líle rẹ dẹ́rùbà, ìwọ Olúwa.

17 Jẹ́ kí ojú kí ó tì wọ́n, kí wọ́n sì dààmú láéláé
    kí wọ́n ṣègbé sínú ẹ̀gàn
18 Jẹ́ kí wọn mọ̀ pé ìwọ, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Olúwa:
    pé ìwọ nìkan ní Ọ̀gá-ògo jùlọ lórí gbogbo ayé.

Romu 11:19-36

19 Ǹjẹ́ ìwọ ó wí pé, “A ti fa àwọn ẹ̀ka náà ya, nítorí kí a lè lọ́ mi sínú rẹ̀.” 20 (A)Ó dára; nítorí àìgbàgbọ́ ni a ṣe fà wọn ya kúrò, ìwọ sì dúró nípa ìgbàgbọ́ rẹ. Má ṣe gbé ara rẹ ga, ṣùgbọ́n bẹ̀rù. 21 Nítorí bí Ọlọ́run kò bá dá ẹ̀ka-ìyẹ́ka sí, kíyèsára kí ó má ṣe ṣe àìdá ìwọ náà sí.

22 Nítorí náà wo oore àti ìkáàánú Ọlọ́run; lórí àwọn tí ó ṣubú, ìkáàánú; ṣùgbọ́n lórí ìwọ, oore, bi ìwọ bá dúró nínú oore rẹ̀; kí a má bá ké ìwọ náà kúrò. 23 Àti àwọn pẹ̀lú, bí wọn kò bá jókòó sínú àìgbàgbọ́, a ó lọ́ wọn sínú rẹ̀, nítorí Ọlọ́run le tún wọn lọ́ sínú rẹ̀. 24 Nítorí bí a bá ti ké ìwọ kúrò lára igi òróró igbó nípa ẹ̀dá rẹ̀, tí a sì lọ́ ìwọ sínú igi òróró rere lòdì sí ti ẹ̀dá; mélòó mélòó ni a ó lọ́ àwọn wọ̀nyí, tí í ṣe ẹ̀ka-ìyẹ́ka sára igi òróró wọn?

Gbogbo Israẹli tòótọ́ ni yóò ní ìgbàlà

25 (B)Ará, èmi kò ṣá fẹ́ kí ẹ̀yin kí ó wà ní òpè ní ti ohun ìjìnlẹ̀ yìí, kí ẹ̀yin má ba á ṣe ọlọ́gbọ́n ní ojú ara yín, pé ìfọ́jú bá Israẹli ní apá kan, títí kíkún àwọn Kèfèrí yóò fi dé. 26 (C)Bẹ́ẹ̀ ni a ó sì gba gbogbo Israẹli là, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé:

“Ní Sioni ni Olùgbàlà yóò ti jáde wá,
    yóò sì yìí àìwà-bí-Ọlọ́run kúrò lọ́dọ̀ Jakọbu.
27 (D)Èyí sì ni májẹ̀mú mi pẹ̀lú wọn.
    Nígbà tí èmi yóò mú ẹ̀ṣẹ̀ wọn kúrò.”

28 Nípa ti ìhìnrere, ọ̀tá ni wọ́n nítorí yín; bí ó sì ṣe ti ìyànfẹ́ ni, olùfẹ́ ni wọ́n nítorí ti àwọn baba. 29 Nítorí àìlábámọ̀ ni ẹ̀bùn àti ìpè Ọlọ́run. 30 Nítorí gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin kò ti gba Ọlọ́run gbọ́ rí, ṣùgbọ́n nísinsin yìí tí ẹ̀yin rí àánú gbà nípa àìgbàgbọ́ wọn. 31 Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni àwọn wọ̀nyí tí ó ṣe àìgbọ́ràn nísinsin yìí, kí àwọn pẹ̀lú bá le rí àánú gbà nípa àánú tí a fihàn yín. 32 (E)Nítorí Ọlọ́run sé gbogbo wọn mọ́ pọ̀ sínú àìgbàgbọ́, kí ó le ṣàánú fún gbogbo wọn.

Ìyìn fún Ọlọ́run

33 (F)A! Ìjìnlẹ̀ ọ̀rọ̀ àti ọgbọ́n àti ìmọ̀ Ọlọ́run!
    Àwámárídìí ìdájọ́ rẹ̀ ti rí,
    ọ̀nà rẹ̀ sì jù àwárí lọ!
34 (G)“Nítorí ta ni ó mọ ọkàn Olúwa?
    Tàbí ta ni í ṣe ìgbìmọ̀ rẹ̀?”
35 (H)“Tàbí ta ni ó kọ́ fi fún un,
    tí a kò sì san padà fún un?”
36 (I)Nítorí láti ọ̀dọ̀ rẹ̀, àti nípa rẹ̀, àti fún un ni ohun gbogbo;
    ẹni tí ògo wà fún láéláé! Àmín.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.