Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Old/New Testament

Each day includes a passage from both the Old Testament and New Testament.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 103-104

Ti Dafidi.

103 Yin Olúwa, ìwọ ọkàn mi; àti gbogbo ohun tí ó wà nínú mi, yín orúkọ rẹ̀ mímọ́.
Yin Olúwa, ìwọ ọkàn mi, kí o má ṣe gbàgbé gbogbo oore rẹ̀
Ẹni tí ó dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ jì ọ́
    tí ó sì wo gbogbo ààrùn rẹ̀ sàn,
Ẹni tí ó ra ẹ̀mí rẹ padà kúrò nínú kòtò ikú
    ẹni tí ó fi ìṣeun ìfẹ́ àti ìyọ́nú dé ọ ní adé,
Ẹni tí ó fi ohun dídára tẹ́ ọ lọ́rùn
    kí ìgbà èwe rẹ̀ lè di ọ̀tún bí ti ẹyẹ idì.

Olúwa ń ṣe òdodo àti ìdájọ́ fún
    gbogbo àwọn tí a ni lára.

Ó fi ọ̀nà rẹ̀ hàn fún Mose, iṣẹ́ rẹ̀ fun àwọn ọmọ Israẹli;
(A)Olúwa ni aláàánú àti olóore,
    ó lọ́ra láti bínú, ó sì pọ̀ ní ìfẹ́.
Òun kì í bá ni wí ní ìgbà gbogbo
    bẹ́ẹ̀ ni kì í pa ìbínú rẹ mọ́ láéláé;
10 Òun kì í ṣe sí wa gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ wa
    bẹ́ẹ̀ ni kì í san án fún wa gẹ́gẹ́
bí àìṣedéédéé wa.
11 Nítorí bí ọ̀run ṣe ga sílẹ̀,
    bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ rẹ̀ tóbi sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀.
12 Bí ìlà-oòrùn ti jìnnà sí ìwọ̀-oòrùn
    bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe mú ìrékọjá wá jìnnà sí wa.

13 Bí baba ti ń ṣe ìyọ́nú sí àwọn ọmọ rẹ̀,
    bẹ́ẹ̀ ni Olúwa ń ṣe ìyọ́nú sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀;
14 Nítorí tí ó mọ dídá wa,
    ó rántí pé erùpẹ̀ ni wá.
15 Bí ó ṣe ti ènìyàn ni, ọjọ́ rẹ̀ dàbí koríko,
    ó gbilẹ̀ bí ìtànná ewéko igbó;
16 Afẹ́fẹ́ fẹ́ kọjá lọ lórí rẹ̀,
    kò sì rántí ibùjókòó rẹ̀ mọ́.
17 (B)Ṣùgbọ́n láti ayérayé ni ìfẹ́
    Olúwa ti wà pẹ̀lú àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀,
    àti òdodo rẹ̀ wà láti ọmọdọ́mọ
18 Sí àwọn tí ó pa májẹ̀mú rẹ̀ mọ́
    àti àwọn tí ó rántí òfin rẹ̀ láti ṣe wọ́n.

19 Olúwa ti pèsè ìtẹ́ rẹ̀ nínú ọ̀run,
    ìjọba rẹ̀ ní ó sì borí ohun gbogbo.

20 Yin Olúwa, ẹ̀yin angẹli rẹ̀,
    tí ó ní ipá, tí ó pa òfin ọ̀rọ̀ rẹ̀ mọ́
21 Yin Olúwa, ẹ̀yin ogun ọ̀run rẹ̀ gbogbo,
    ẹ̀yin ìránṣẹ́ rẹ̀ tí ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀.
22 Yin Olúwa, gbogbo iṣẹ́ rẹ̀ ní
    ibi gbogbo ìjọba rẹ̀.

Yin Olúwa, ìwọ ọkàn mi.
104 Yin Olúwa, ìwọ ọkàn mi.

Olúwa Ọlọ́run mi, ìwọ tóbi jọjọ;
    ọlá àti ọláńlá ni ìwọ wọ̀ ní aṣọ.

Ìwọ fi ìmọ́lẹ̀ bo ara rẹ gẹ́gẹ́ bí aṣọ;
    ó tẹ ọ̀run bí títẹ́ ẹní
Ìwọ tí ó fi omi ṣe ìtì igi àjà ìyẹ̀wù rẹ.
    Ìwọ tí o ṣe àwọsánmọ̀ ní kẹ̀kẹ́ ogun rẹ
    ìwọ tí ó ń rìn lórí apá ìyẹ́ afẹ́fẹ́.
(C)Ó fi ẹ̀fúùfù ṣe àwọn ìránṣẹ́ rẹ,
    Ọ̀wọ́-iná ni àwọn olùránṣẹ́ rẹ.

O fi ayé gúnlẹ̀ lórí àwọn ìpìlẹ̀;
    tí a kò le è mì láéláé.
Ìwọ fi ibú omi bò ó mọ́lẹ̀ bí aṣọ;
    àwọn omi sì dúró lórí àwọn òkè ńlá.
Ṣùgbọ́n nípa ìbáwí rẹ ni àwọn omi lọ,
    nípa ohùn àrá rẹ ni wọ́n sálọ;
Wọ́n sàn kọjá lórí àwọn òkè,
    wọ́n sọ̀kalẹ̀ lọ sí àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀,
    sí ibi tí ìwọ ti yàn fún wọn.
Ìwọ gbé òpin tí wọn kò lè kọjá rẹ̀ kálẹ̀;
    láéláé ni wọ́n kò ní lè bo ayé mọ́lẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i.

10 Ìwọ mú kí ìsun da omi sí àwọn Àfonífojì;
    tí ó ń sàn láàrín àwọn òkè.
11 Wọ́n fún gbogbo àwọn ẹranko igbó ní omi
    àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ń pa òǹgbẹ wọn.
12 Àwọn ẹyẹ ojú òfúrufú tẹ́ ìtẹ́ wọn lẹ́gbẹ̀ẹ́ omi
    wọ́n ń kọrin láàrín àwọn ẹ̀ka.
13 Ó bu omi rin àwọn òkè láti ìyẹ̀wù rẹ̀ wá;
    a tẹ́ ayé lọ́rùn nípa èso iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.
14 Ó mú kí koríko hù jáde fún àwọn ẹranko láti jẹ
    àti àwọn ewébẹ̀ fún ènìyàn láti lò
    kí ó lè mú oúnjẹ jáde láti ilẹ̀ wá:
15 Ọtí wáìnì tí ó ń mú ọkàn ènìyàn yọ̀,
    òróró láti mú ojú rẹ̀ tan,
    àti àkàrà láti ra ọkàn rẹ̀ padà.
16 Àwọn igi Olúwa ni a bu omi rin dáradára,
    kedari ti Lebanoni tí ó gbìn.
17 Níbẹ̀ ní àwọn ẹyẹ ṣe ìtẹ́ wọn
    bí ó ṣe tí àkọ̀ ni, orí igi gíga ni ilé rẹ̀.
18 Àwọn òkè gíga ni ààbò fún àwọn ewúrẹ́ igbó;
    àti àwọn àlàpà jẹ́ ààbò fún àwọn ehoro.

19 Òṣùpá jẹ́ ààmì fún àkókò
    oòrùn sì mọ ìgbà tí yóò wọ̀.
20 Ìwọ mú òkùnkùn wá, ó sì di òru,
    nínú èyí tí gbogbo ẹranko igbó ń rìn kiri.
21 Kìnnìún ń bú ramúramù fún ohun ọdẹ wọn
    wọ́n sì ń wá oúnjẹ wọn láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.
22 Oòrùn ràn, wọ́n sì kó ara wọn jọ,
    wọn padà lọ dùbúlẹ̀ sí ihò wọn.
23 Ọkùnrin jáde lọ sí iṣẹ́ wọn,
    àti sí làálàá rẹ̀ títí di àṣálẹ́.

24 Iṣẹ́ rẹ ti pọ̀ tó, Olúwa!
    Nínú ọgbọ́n ni ìwọ ṣe gbogbo wọn:
    ayé kún fún àwọn ìṣẹ̀dá á rẹ.
25 Bẹ́ẹ̀ ni Òkun yìí tí ó tóbi, tí ó sì ni ìbú,
    tí ó kún fún àwọn ẹ̀dá alààyè ní ìsàlẹ̀ láìníye
    ohun alààyè tí tóbi àti kékeré.
26 Níbẹ̀ ni ọkọ̀ ń lọ síwá sẹ́yìn,
    àti Lefitani, tí ìwọ dá láti ṣe àríyá nínú rẹ̀.

27 Àwọn wọ̀nyí ń wò ọ́
    láti fún wọn ní oúnjẹ wọn lákòókò rẹ̀.
28 Nígbà tí ìwọ bá fi fún wọn,
    wọn yóò kó jọ;
nígbà tí ìwọ bá la ọwọ́ rẹ̀,
    a tẹ́ wọn lọ́rùn pẹ̀lú ohun rere.
29 Nígbà tí ìwọ bá pa ojú rẹ mọ́
    ara kò rọ̀ wọ́n
nígbà tí ìwọ bá mú ẹ̀mí wọn lọ,
    wọn ó kú, wọn ó sì padà sí erùpẹ̀.
30 Nígbà tí ìwọ rán ẹ̀mí rẹ,
    ni a dá wọn,
    ìwọ sì tún ojú ayé ṣe.

31 Jẹ́ kí ògo Olúwa wà pẹ́ títí láé;
    kí inú Olúwa kí ó dùn ní ti iṣẹ́ rẹ̀
32 Ẹni tí ó wo ayé, tí ó sì wárìrì,
    ẹni tí ó fọwọ́ tọ́ àwọn òkè, tí wọ́n yọ èéfín.

33 Ní gbogbo ayé mi ní n ó kọrin sí Olúwa:
    èmi ó kọrin ìyìn sí Olúwa
níwọ̀n ìgbà tí mo wà láààyè.
34 Jẹ́ kí ẹ̀kọ́ mi kí ó tẹ́ ọ lọ́rùn
    bí mo ti ń yọ̀ nínú Olúwa.
35 Ṣùgbọ́n kí ẹlẹ́ṣẹ̀ kúrò láyé
    kí ènìyàn búburú má sì sí mọ́.

Yin Olúwa, ìwọ ọkàn mi.

Yin Olúwa.

1 Kọrinti 2

(A)Nígba tí èmí tọ̀ yín wá, ẹ̀yin ará, kì í ṣe nípa ọ̀rọ̀ gíga àti ọgbọ́n gíga ni mo fi bá yín sọ̀rọ̀, nígbà tí èmi ń sọ̀rọ̀ ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run fún un yín. (B)Èmi ti pinnu láti má mọ ohunkóhun nígbà ti mo wà láàrín yín bí kò ṣe Jesu Kristi, ẹni tí a kàn mọ́ àgbélébùú. (C)Èmi sì tọ̀ yín wá ni àìlera, àti ní ẹ̀rù, àti ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwárìrì. (D)Ìwàásù mi àti ẹ̀kọ́ mi, kì í ṣe nípa ọgbọ́n ènìyàn àti ọ̀rọ̀ tí a fi ń yí ènìyàn lọ́kàn padà, bí kò ṣe nípa ìfihàn agbára Ẹ̀mí. (E)Kí ìgbàgbọ́ yín kí ó má ṣe dúró lórí ọgbọ́n ènìyàn, ṣùgbọ́n kí ó dúró lórí agbára Ọlọ́run.

Ọgbọ́n láti ọ̀dọ̀ ẹ̀mí wá

(F)Ṣùgbọ́n àwa ń sọ̀rọ̀ ọgbọ́n láàrín àwọn tí a pè; ṣùgbọ́n kì í ṣe ọgbọ́n ti ayé yìí tàbí ti àwọn olórí ayé yìí, èyí tí yóò di asán (G)Bẹ́ẹ̀ kọ́, àwa ń sọ̀rọ̀ ọgbọ́n ti Ọlọ́run tó fi ara sin, ọgbọ́n tí ó ti fi ara pamọ́, èyí tí Ọlọ́run ti lànà sílẹ̀ ṣáájú ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé fún ògo wa. (H)Èyí ti ẹnikẹ́ni nínú àwọn aláṣẹ ayé yìí kò mọ̀. Ìbá ṣe pé wọ́n mọ̀ ọ́n, wọn kì bá tún kan Olúwa ògo mọ́ àgbélébùú. (I)Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé:

“Ojú kò tí ì rí,
    etí kò tí í gbọ́,
kò sì ọkàn ènìyàn tí ó tí í mọ̀
ohun tí Ọlọ́run tí pèsè sílẹ̀ fún àwọn tí o fẹ́ Ẹ.”

10 (J)Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ti fi í hàn fún wa nípasẹ̀ Ẹ̀mí rẹ̀.

Ẹ̀mí á máa wádìí ohun gbogbo, kódà àwọn àṣírí Ọlọ́run tó jinlẹ̀ jùlọ. 11 Ta ni nínú ènìyàn tí ó mọ èrò ọkàn ènìyàn kan, bí kò ṣe ẹ̀mí ènìyàn tí ó wà nínú rẹ̀? Bákan náà, kò sí ẹni ti ó mọ àwọn èrò Ọlọ́run, bí kò ṣe Ẹ̀mí Ọlọ́run fúnrarẹ̀. 12 (K)Àwa kò gbà ẹ̀mí ti ayé yìí, bí kò ṣe Ẹ̀mí ẹni tí ó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wa, kí a lè ní òye ohun tí Ọlọ́run fi fún wa lọ́fẹ̀ẹ́. 13 (L)Èyí ni àwa ń wí, kì í ṣe èyí tí a ń kọ nípa ọ̀rọ̀ ọgbọ́n ènìyàn, ṣùgbọ́n èyí tí Ẹ̀mí Mímọ́ fi ń kọ ènìyàn, èyí tí a ń fi ohun Ẹ̀mí wé ohun Ẹ̀mí. 14 (M)Ṣùgbọ́n ènìyàn nípa ti ara kò gba ohun ti Ẹ̀mí Ọlọ́run wọ̀n-ọ́n-nì, nítorí pé wèrè ni wọ́n jásí fún un, òun kò sì le mọ̀ wọ́n, nítorí nípa tí Ẹ̀mí ní a fi ń wádìí wọn. 15 (N)Ṣùgbọ́n ẹni tí ó wà nípa ti ẹ̀mí ń wádìí ohun gbogbo, ṣùgbọ́n kò sí ẹnikẹ́ni tí í wádìí rẹ̀.

16 (O)“Nítorí ta ni ó mọ ọkàn Olúwa,
    ti yóò fi máa kọ́ Ọ?”

Ṣùgbọ́n àwa ní inú Kristi.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.