Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Old/New Testament

Each day includes a passage from both the Old Testament and New Testament.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Nahumu 1-3

Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ nípa Ninefe. Ìwé ìran Nahumu ará Elkoṣi.

Ìbínú Olúwa sí Ninefe

Ọlọ́run ń jẹ owú, ó sì ń gbẹ̀san.
    Olúwa ń gbẹ̀san, ó sì kún fún ìbínú
Olúwa ń gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá rẹ̀,
    Ìbínú rẹ̀ kò sì yí padà lórí àwọn ọ̀tá rẹ̀
(A)Olúwa lọ́ra láti bínú, ó sì tóbi ní agbára;
    Olúwa kì yóò fi àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ sílẹ̀ láìjìyà.
Ọ̀nà rẹ̀ wà nínú afẹ́fẹ́ àti nínú ìjì,
    Ìkùùkuu sánmọ̀ sì ni eruku ẹsẹ̀ rẹ̀.
Ó bá Òkun wí, ó sì mú kí ó gbẹ;
    Ó sìsọ gbogbo odò di gbígbẹ.
Baṣani àti Karmeli sì rọ,
    Ìtànná Lebanoni sì rẹ̀ sílẹ̀.
Àwọn òkè ńlá wárìrì níwájú rẹ̀,
    àwọn òkè kéékèèkéé sì di yíyọ́,
ilẹ̀ ayé sì jóná níwájú rẹ̀,
    àní ayé àti gbogbo àwọn tí ń gbé inú rẹ̀.
Ta ni ó lé dúró níwájú ìbínú rẹ̀?
    Ta ni ó lé faradà gbígbóná ìbínú rẹ̀?
Ìbínú rẹ̀ tú jáde bí iná;
    àwọn àpáta sì fọ́ túútúú níwájú rẹ̀.

Rere ni Olúwa,
    òun ni ààbò ní ọjọ́ ìpọ́njú.
Òun sì tọ́jú àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé e,
    Ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìkún omi ńlá
ní òun yóò fi ṣe ìparun láti ibẹ̀ dé òpin;
    òkùnkùn yóò sì máa lépa àwọn ọ̀tá rẹ̀.

Kí ni ẹ̀yìn ń gbìmọ̀ lòdì sí Olúwa?
    Òun yóò fi òpin sí i,
    ìpọ́njú kì yóò wáyé ní ìgbà kejì
10 Wọn yóò sì lọ́lù papọ̀ bí ẹ̀gún òṣùṣú
    wọn yóò sì mu àmupara nínú ọtí wáìnì wọn
    a ó sì run wọn gẹ́gẹ́ bi àgékù koríko gbígbẹ
11 Láti ọ̀dọ̀ rẹ, ìwọ Ninefe, ni ẹnìkan ti jáde wá
    tí ó ń gbèrò ibi sí Olúwa
    ti ó sì ń gbìmọ̀ búburú.

12 Báyìí ni Olúwa wí:

“Bí wọ́n tilẹ̀ ni ìfọwọ́sowọ́pọ̀, tí wọ́n sì pọ̀ níye,
    Ṣùgbọ́n, báyìí ní a ó ké wọn lulẹ̀,
nígbà tí òun ó bá kọjá.
    Bí mo tilẹ̀ ti pọ́n ọ lójú ìwọ Juda, èmi kì yóò pọ́n ọ lójú mọ́.
13 Nísinsin yìí ni èmi yóò já àjàgà wọn kúrò ní ọrùn rẹ
    èmi yóò já ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ rẹ dànù.”

14 Olúwa ti fi àṣẹ kan lélẹ̀ nítorí tìrẹ Ninefe:
    “Ìwọ kì yóò ni irú-ọmọ láti máa jẹ́ orúkọ rẹ mọ́,
Èmi yóò pa ère fínfín àti ère dídà run
    tí ó wà nínú tẹmpili àwọn ọlọ́run rẹ.
Èmi yóò wa ibojì rẹ,
    nítorí ẹ̀gbin ni ìwọ.”

15 (B)Wò ó, lórí àwọn òkè,
    àwọn ẹsẹ̀ ẹni tí ó mú ìròyìn ayọ̀ wá,
    ẹni tí ó ń kéde àlàáfíà,
Ìwọ Juda, pa àṣẹ rẹ tí ó ní ìrònú mọ́,
    kí ó sì san àwọn ẹ̀jẹ́ rẹ.
Àwọn ènìyàn búburú kì yóò sì gbóguntì ọ́ mọ́;
    wọn yóò sì parun pátápátá.

Ìṣubú Ninefe

Àwọn apanirun ti dìde sí ọ, ìwọ Ninefe
    pa ilé ìṣọ́ mọ́,
    ṣọ́ ọ̀nà náà
    di àmùrè, ẹ̀gbẹ́ rẹ kí ó le,
    múra gírí.

Olúwa yóò mú ọláńlá Jakọbu padà sípò
    gẹ́gẹ́ bí ọláńlá Israẹli
bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn apanirun ti pa ibẹ̀ run,
    tí wọ́n sì ba ẹ̀ka àjàrà wọn jẹ́.

Asà àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ sì di pupa;
    àwọn ológun wọn sì wọ aṣọ òdòdó.
Idẹ tí ó wà lórí kẹ̀kẹ́ ogun ń kọ mọ̀nàmọ́ná
    ní ọjọ́ tí a bá pèsè wọn sílẹ̀ tán;
    igi firi ni a ó sì mì tìtì.
Àwọn kẹ̀kẹ́ ogun yóò ya bo àwọn pópónà,
    wọn yóò sì máa sáré síwá àti sẹ́yìn ní àárín ìgboro.
Wọn sì dàbí ètùfù iná;
    tí ó sì kọ bí i mọ̀nàmọ́ná.

Ninefe yóò ṣe àṣàrò àwọn ọlọ́lá rẹ̀;
    síbẹ̀ wọ́n ń kọsẹ̀ ní ojú ọ̀nà wọn;
wọn sáré lọ sí ibi odi rẹ̀,
    a ó sì pèsè ààbò rẹ̀.
A ó ṣí ìlẹ̀kùn àwọn odò wọ̀n-ọn-nì sílẹ̀,
    a ó sì mú ààfin náà di wíwó palẹ̀.
A pa á láṣẹ pé ìlú náà, èyí tí a ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀
    ni a ó sì kó ní ìgbèkùn lọ.
A ó sì mú un gòkè wá
    àti àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ yóò kérora bí ti ẹyẹ àdàbà,
    wọn a sì máa lu àyà wọn.
Ninefe dàbí adágún omi,
    tí omi rẹ̀ sì ń gbẹ́ ẹ lọ.
“Dúró! Dúró!” ni wọ́n ó máa kígbe,
    ṣùgbọ́n ẹnìkankan kì yóò wo ẹ̀yìn.
“Ẹ kó ìkógun fàdákà!
    Ẹ kó ìkógun wúrà!
Ìṣúra wọn ti kò lópin náà,
    àti ọrọ̀ kúrò nínú gbogbo ohun èlò ti a fẹ́!”
10 Òun ti ṣòfò, ó si di asán, ó sì di ahoro:
    ọkàn pami, eékún ń lu ara wọn,
    ìrora púpọ̀ sì wà nínú gbogbo ẹgbẹ́
    àti ojú gbogbo wọ́n sì rẹ̀wẹ̀sì.

11 Níbo ni ihò àwọn kìnnìún wà
    àti ibi ìjẹun àwọn ọmọ kìnnìún,
níbi tí kìnnìún, àní abo kìnnìún tí ń rìn,
    àti ọmọ kìnnìún, láìsí ohun ìbẹ̀rù
12 Kìnnìún tipa ọ̀pọ̀lọpọ̀ fún àwọn ọmọ rẹ̀,
    ó sì fún un ẹran ọdẹ ní ọrùn pa fún àwọn abo kìnnìún rẹ̀,
Ó sì fi ohun pípa kún ibùgbé rẹ̀
    àti ihò rẹ̀ fún ohun ọdẹ.

13 “Kíyèsi i èmi dojúkọ ọ́,”
    ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.
“Èmi yóò sì fi kẹ̀kẹ́ rẹ̀ wọ̀n-ọn-nì jóná nínú èéfín,
    idà yóò sì jẹ ọmọ kìnnìún rẹ̀ wọ̀n-ọn-nì run.
    Èmi yóò sì ké ohun ọdẹ rẹ kúrò lórí ilẹ̀ ayé
Ohùn àwọn ìránṣẹ́ rẹ
    ni a kì yóò sì tún gbọ́ mọ́.”

A fi Ninefe bú

Ègbé ni fún ìlú ẹ̀jẹ̀ nì,
    gbogbo rẹ̀ kún fún èké,
ó kún fún olè,
    ìjẹ kò kúrò!
Ariwo pàṣán àti ariwo
    kíkùn kẹ̀kẹ́ ogun
àti jíjó ẹṣin
    àti gbígbọn kẹ̀kẹ́ ogun jìgìjìgì!
Ológun orí ẹṣin ń fi ìgbónára
    ju idà wọn mọ̀nàmọ́ná
    ọ̀kọ̀ rẹ̀ ti ń dán yanran sí òkè!
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ si ní àwọn ẹni tí a pa,
    àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ òkú;
òkú kò sì ni òpin;
    àwọn ènìyàn sì ń kọsẹ̀ lára àwọn òkú.
Nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ panṣágà
    àgbèrè tí ó rójú rere gbà,
Ìyá àjẹ́ tí ó ṣọ́ àwọn orílẹ̀-èdè di ẹrú
    nípa àgbèrè rẹ̀
    àti àwọn ìdílé nípa ìṣe àjẹ́ rẹ̀.

“Èmi dojúkọ ọ́,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.
    “Èmi ó si ká aṣọ àwọ̀tẹ́lẹ̀ rẹ ní ojú rẹ,
Èmi yóò sì fi ìhòhò rẹ̀ han àwọn orílẹ̀-èdè
    àti ìtìjú rẹ̀ han àwọn ilẹ̀ ọba.
Èmi yóò da ẹ̀gbin tí ó ni ìríra sí ọ ní ara,
    èmi yóò sì sọ ọ́ di aláìmọ́,
    èmi yóò sì sọ ọ́ di ẹlẹ́yà.
Gbogbo àwọn tí ó ba sì wò ọ́ yóò sì káàánú fún ọ, wọn yóò sì wí pé,
    ‘Ninefe ṣòfò: Ta ni yóò kẹ́dùn rẹ?’
    Níbo ni èmi o ti wá olùtùnú fún ọ?”

Ǹjẹ́ ìwọ ha sàn ju Tebesi lọ,
    èyí tí ó wà ní ibi odò, Naili
    tí omi sì yí káàkiri?
Odò náà sì jẹ́ ààbò rẹ̀,
    omi si jẹ́ odi rẹ̀.
Etiopia àti Ejibiti ni agbára rẹ, kò sí ní òpin;
    Puti àti Libia ni àwọn olùgbèjà rẹ̀.
10 Síbẹ̀síbẹ̀ a kó o ní ìgbèkùn
    o sì lọ sí oko ẹrú.
Àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ rẹ̀ ni a ó fọ́ mọ́lẹ̀
    ní orí ìta gbogbo ìgboro.
Wọ́n sì di ìbò nítorí àwọn ọlọ́lá rẹ̀ ọkùnrin,
    gbogbo àwọn ọlọ́lá rẹ ni a sì fi ẹ̀wọ̀n dè
11 Ìwọ pẹ̀lú yóò sì mu àmupara;
    a ó sì fi ọ́ pamọ́
    ìwọ pẹ̀lú yóò máa ṣe àfẹ́rí ààbò nítorí ti ọ̀tá náà.

12 Gbogbo ilé ìṣọ́ agbára rẹ yóò dàbí igi ọ̀pọ̀tọ́
    pẹ̀lú àkọ́pọ́n èso wọn;
Nígbà tí wọ́n bá ń gbọ̀n wọ́n,
    ọ̀pọ̀tọ́ yóò sì bọ́ sí ẹnu àwọn ọ̀jẹun.
13 Kíyèsi gbogbo àwọn jagunjagun!
    Obìnrin ni gbogbo wọn.
Ojú ibodè rẹ ní a ó ṣí sílẹ̀ gbagada,
    fún àwọn ọ̀tá rẹ;
    iná yóò jó ọ̀pá ìdábùú ìlẹ̀kùn ibodè rẹ.

14 Pọn omi nítorí ìhámọ́,
    mú ilé ìṣọ́ rẹ lágbára sí i
wọ inú amọ̀
    kí o sì tẹ erùpẹ̀,
    kí ó sì tún ibi tí a ti ń sun bíríkì-amọ̀ ṣe kí ó le.
15 Níbẹ̀ ni iná yóò ti jó ọ́ run;
    idà yóò sì ké ọ kúrò,
    yóò sì jẹ ọ́ bí i kòkòrò,
yóò sì sọ ara rẹ̀ di púpọ̀ bí i tata,
    àní, di púpọ̀ bí eṣú!
16 Ìwọ ti sọ àwọn oníṣòwò rẹ di púpọ̀
    títí wọn yóò fi pọ̀ ju ìràwọ̀ ojú ọ̀run lọ
Ṣùgbọ́n bi eṣú ni wọn yóò sọ ilẹ̀ náà di ahoro, wọn yóò sì fò lọ.
17 Àwọn aládé rẹ̀ dàbí eṣú,
    àwọn ọ̀gágun rẹ dàbí ẹlẹ́ǹgà ńlá,
    èyí tí ń dó sínú ọgbà ni ọjọ́ òtútù,
ṣùgbọ́n nígbà tí oòrùn jáde, wọ́n sálọ
    ẹnìkan kò sì mọ ibi tí wọ́n gbé wà.

18 Ìwọ ọba Asiria,
    àwọn olùṣọ́-àgùntàn rẹ̀ ń tòògbé;
àwọn ọlọ́lá rẹ dùbúlẹ̀ láti sinmi.
    Àwọn ènìyàn rẹ fọ́nká lórí àwọn òkè ńlá,
    tí ẹnikẹ́ni kò sì kó wọn jọ.
19 Kò sì sí ohun tí ó lè wo ọgbẹ́ ẹ̀ rẹ sàn;
    ọgbẹ́ rẹ kún fún ìrora
Gbogbo ẹni tí ó bá sì gbọ́ ìròyìn rẹ
    yóò pàtẹ́wọ́ lé ọ lórí,
nítorí ta ni kò ní pín nínú
    ìwà búburú rẹ ti kò ti lópin.

Ìfihàn 14

Ọ̀dọ́-àgùntàn àti ọ̀kẹ́ méje ó-lé-ẹgbàajì (144,000)

14 (A)Mo sì wo, si kíyèsi i, Ọ̀dọ́-Àgùntàn náà dúró lórí Òkè Sioni, àti pẹ̀lú rẹ̀ ọ̀kẹ́ méje ó-lé-ẹgbàajì (144,000) ènìyàn; wọ́n ní orúkọ rẹ̀, àti orúkọ baba rẹ̀ tí a kọ sí iwájú orí wọn. Mo sì gbọ́ ohùn kan láti ọ̀run wá, bí ariwo omi púpọ̀, àti bí sísán àrá ńlá: mo sì gbọ́ àwọn aludùùrù tí wọn ń lu dùùrù. Wọ́n sì ń kọ bí ẹni pé orin tuntun níwájú ìtẹ́ náà, àti níwájú àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin nnì àti àwọn àgbà náà: kò sì ṣí ẹni tí o lè kọ orin náà, bí kò ṣe àwọn ọ̀kẹ́ méje ó-lé-ẹgbàajì ènìyàn, tí a tí rà padà láti inú ayé wá. Àwọn wọ̀nyí ni a kò fi obìnrin sọ di èérí: nítorí tí wọ́n jẹ́ wúńdíá. Àwọn wọ̀nyí ni o ń tọ Ọ̀dọ́-àgùntàn náà lẹ́yìn níbikíbi tí o bá ń lọ. Àwọn wọ̀nyí ni a rà padà láti inú àwọn ènìyàn wá, wọ́n jẹ́ àkọ́so fún Ọlọ́run àti fún Ọ̀dọ́-Àgùntàn náà. A kò sì rí èké lẹ́nu wọn, wọn jẹ́ aláìlábùkù.

Àwọn angẹli mẹ́ta

Mo sì rí angẹli mìíràn ń fò ní àárín méjì ọ̀run, pẹ̀lú ìhìnrere àìnípẹ̀kun láti wàásù fún àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé, àti fún gbogbo orílẹ̀, àti ẹ̀yà, àti èdè, àti ènìyàn. Ó ń wí ni ohùn rara pé, “Ẹ bẹ̀rù Ọlọ́run, kí ẹ sì fi ògo fún un, nítorí tí wákàtí ìdájọ́ rẹ̀ dé: ẹ sì foríbalẹ̀ fún ẹni tí o dá ọ̀run, àti ayé, àti Òkun, àti àwọn orísun omi!”

(B)Angẹli mìíràn sì tẹ̀lé e, ó ń wí pé, “o ṣubú, Babeli ńlá ṣubú, èyí ti o tí ń mú gbogbo orílẹ̀-èdè mu nínú ọtí wáìnì àìmọ́ àgbèrè rẹ̀!”

Angẹli mìíràn, ẹ̀kẹta, sì tẹ̀lé wọn, ó ń wí ni ohùn rara pé, “Bí ẹnikẹ́ni bá ń foríbalẹ̀ fún ẹranko náà àti àwòrán rẹ̀, tí ó sì gba ààmì sí iwájú orí rẹ̀ tàbí sí ọwọ́ rẹ̀. 10 (C)Òun pẹ̀lú yóò mú nínú ọtí wáìnì ìbínú Ọlọ́run, tí a dà ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ sínú ago ìrunú rẹ̀; a ó sì fi iná sulfuru dá a lóró níwájú àwọn angẹli mímọ́, àti níwájú Ọ̀dọ́-àgùntàn: 11 (D)Èéfín ìdálóró wọn ń lọ sókè títí láéláé wọn kò sì ní ìsinmi ni ọ̀sán àti ní òru, àwọn tí ń foríbalẹ̀ fún ẹranko náà àti fún àwòrán rẹ̀, àti ẹnikẹ́ni tí o ba sì gba ààmì orúkọ rẹ̀.” 12 Níhìn-ín ni sùúrù àwọn ènìyàn mímọ́ gbé wà: àwọn tí ń pa òfin Ọlọ́run àti ìgbàgbọ́ Jesu mọ́.

13 Mo sì gbọ́ ohùn kan láti ọ̀run wá ń wí fún mi pé, “Kọ̀wé rẹ̀: Alábùkún fún ni àwọn òkú tí o kú nínú Olúwa láti ìhín lọ.”

Alábùkún ni wọ́n nítòótọ́, bẹ́ẹ̀ ni, Ẹ̀mí wí, “Nítorí tí wọn yóò sinmi kúrò nínú làálàá wọn, nítorí iṣẹ́ wọn ń tọ̀ wọn lẹ́yìn.”

Ìkórè ayé

14 (E)Mo sì wo, sì kíyèsi i, ìkùùkuu àwọsánmọ̀ funfun kan, àti lórí ìkùùkuu àwọsánmọ̀ náà ẹnìkan jókòó tí o “dàbí Ọmọ ènìyàn,” tí òun ti adé wúrà ní orí rẹ̀, àti dòjé mímú ni ọwọ́ rẹ̀. 15 (F)Angẹli mìíràn sì tí inú tẹmpili jáde wa tí ń ké lóhùn rara sí ẹni tí ó jókòó lórí ìkùùkuu àwọsánmọ̀ náà pé, “Tẹ dòjé rẹ bọ̀ ọ́, kí ó sì máa kórè; nítorí àkókò àti kórè dé, nítorí ìkórè ayé ti gbó tán.” 16 Ẹni tí ó jókòó lórí ìkùùkuu àwọsánmọ̀ náà sì tẹ dòjé rẹ̀ bọ orí ilẹ̀ ayé; a sì ṣe ìkórè ilẹ̀ ayé.

17 Angẹli mìíràn sì tí inú tẹmpili tí ń bẹ ni ọ̀run jáde wá, òun pẹ̀lú sì ní dòjé mímú, kan. 18 Angẹli mìíràn sì tí ibi pẹpẹ jáde wá, tí ó ní agbára lórí iná; ó sì ké ni ohùn rara sí ẹni tí o ni dòjé mímú náà, wí pé, “Tẹ dòjé rẹ mímú bọ̀ ọ́, ki ó sì rẹ́ àwọn ìdì àjàrà ayé, nítorí àwọn èso rẹ̀ tí pọ́n.” 19 Angẹli náà sì tẹ dòjé rẹ̀ bọ ilẹ̀ ayé, ó sì gé àjàrà ilẹ̀ ayé, ó sì kó o lọ sínú ìfúntí, ìfúntí ńlá ìbínú Ọlọ́run. 20 (G)A sì tẹ ìfúntí náà lẹ́yìn òde ìlú náà, ẹ̀jẹ̀ sì ti inú ìfúntí náà jáde, ó sì ga sókè dé okùn ìjánu ẹṣin, èyí tí ìnàsílẹ̀ rẹ to ẹ̀gbẹjọ̀ ibùsọ̀.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.