Old/New Testament
Àwọn ẹ̀yà ti ìlà-oòrùn padà sí ilẹ̀ ìní wọn
22 (A)Joṣua sì pe àwọn ẹ̀yà Reubeni, ẹ̀yà Gadi àti ìdajì ẹ̀yà Manase 2 ó sì sọ fún wọn pé, “Ẹ̀yin ti ṣe gbogbo èyí tí Mose ìránṣẹ́ Olúwa pàṣẹ, ẹ sì ti ṣe ìgbọ́ràn sí ohun gbogbo tí mo pàṣẹ. 3 Ẹ kò fi àwọn arákùnrin yín sílẹ̀ láti ìgbà yí títí di òní, ṣùgbọ́n ẹ ti kíyèsára láti pa òfin Olúwa Ọlọ́run yín mọ́. 4 Nísinsin yìí tí Olúwa Ọlọ́run yín ti fún àwọn arákùnrin yín ní ìsinmi gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí, ẹ padà sí ilẹ̀ yín níbi tí Mose ìránṣẹ́ Olúwa fi fún yin ní òdìkejì Jordani. 5 Ṣùgbọ́n ẹ ṣọ́ra gidigidi láti pa àṣẹ àti òfin tí Mose ìránṣẹ́ Olúwa fi fún yin mọ́. Láti fẹ́ràn Olúwa Ọlọ́run yín, láti rìn nínú gbogbo ọ̀nà rẹ̀, láti gbọ́rọ̀ sí àṣẹ rẹ̀, láti dìímú ṣinṣin àti láti sìn ín pẹ̀lú gbogbo ọkàn yín àti gbogbo àyà yín.”
6 Nígbà náà ni Joṣua súre fún wọn, ó sì jẹ́ kí wọn máa lọ sí ilẹ̀ wọn. 7 (Mose ti fi ilẹ̀ fún ìdajì ẹ̀yà Manase ní Baṣani, Joṣua sì ti fún ìdajì ẹ̀yà yòókù ní ilẹ̀ ní ìwọ̀-oòrùn Jordani, pẹ̀lú àwọn arákùnrin wọn). Joṣua súre fún wọn ó sì jẹ́ kí wọn máa lọ sí ilẹ̀ wọn, 8 Ó sì wí pé, “Ẹ padà sí ilẹ̀ ẹ yín pẹ̀lú ọrọ̀ púpọ̀ yín, pẹ̀lú agbo ẹran ọ̀sìn, pẹ̀lú fàdákà, wúrà, idẹ àti irin, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ aṣọ, kí ẹ sì pín ìkógun tí ẹ rí gbà láti ọ̀dọ̀ àwọn ọ̀tá yín pẹ̀lú àwọn arákùnrin yín.”
9 Báyìí ni àwọn ẹ̀yà Reubeni, ẹ̀yà Gadi àti ìdajì ẹ̀yà Manase fi àwọn ará Israẹli sílẹ̀ ní Ṣilo ní Kenaani láti padà sí Gileadi, ilẹ̀ wọn, èyí tí wọ́n ti gbà gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Olúwa láti ẹnu Mose wá.
10 Nígbà tí wọ́n wá dé Geliloti ní ẹ̀bá Jordani ní ilẹ̀ Kenaani, àwọn ẹ̀yà Reubeni, ẹ̀yà Gadi àti ìdajì ẹ̀yà Manase mọ pẹpẹ ńlá tí ó tóbi kan ní ẹ̀bá Jordani. 11 Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli gbọ́ pé àwọn ọmọ Reubeni, àti àwọn ọmọ Gadi àti ìlàjì ẹ̀yà Manase mọ pẹpẹ kan dojúkọ ilẹ̀ Kenaani ní Geliloti ní ẹ̀bá Jordani ní ìhà kejì àwọn ọmọ Israẹli, 12 gbogbo àjọ Israẹli péjọ ní Ṣilo láti lọ bá wọn jagun.
13 Àwọn ọmọ Israẹli rán Finehasi ọmọ Eleasari àlùfáà, sí ilẹ̀ Gileadi, sí Reubeni, sí Gadi àti sí ìdajì ẹ̀yà Manase. 14 Pẹ̀lú rẹ̀ wọ́n rán àwọn ọkùnrin olóyè mẹ́wàá, ẹnìkan fún ẹ̀yà Israẹli kọ̀ọ̀kan, olórí ọ̀kọ̀ọ̀kan tiwọn jẹ́ olórí ìdílé láàrín àwọn ọmọ Israẹli.
15 Nígbà tí wọ́n lọ sí Gileadi—sí Reubeni, Gadi àti ìdajì ẹ̀yà Manase—wọ́n sì sọ fún wọn pé, 16 “Gbogbo àjọ ènìyàn Olúwa wí pe: ‘A fẹ́ mọ ìdí tí ẹ fi sẹ̀ sí Ọlọ́run Israẹli nípa yíyí padà kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ tí ẹ sì kọ́ pẹpẹ ìṣọ̀tẹ̀ ní ìlòdì sí Olúwa? 17 Ẹ̀ṣẹ̀ Peori kò ha tó fún wa bí? Títí di òní yìí àwa kò tí ì wẹ ara wa mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ náà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àjàkálẹ̀-ààrùn ti jà láàrín ènìyàn Olúwa! 18 Ṣé ẹ tún wá ń padà kúrò lẹ́yìn Olúwa ni báyìí?
“ ‘Tí ẹ̀yin bá ṣọ̀tẹ̀ sí Olúwa ní òní, ní ọ̀la ní òun o bínú sí gbogbo ìpéjọpọ̀ Israẹli. 19 Bí ilẹ̀ ìní yín bá di àìmọ́, ẹ wá sí orí ilẹ̀ ìní Olúwa, ní ibi tí àgọ́ Olúwa dúró sí, kí ẹ sì pín ilẹ̀ náà pẹ̀lú wa. Ṣùgbọ́n kí ẹ má ṣe ṣọ̀tẹ̀ sí Olúwa tàbí sí wa nípa mímọ pẹpẹ fún ara yín, lẹ́yìn pẹpẹ Olúwa Ọlọ́run wa. 20 Nígbà tí Akani ọmọ Sera ṣe àìṣòótọ́ nípa ohun ìyàsọ́tọ̀, ǹjẹ́ ìbínú kò wá sí orí gbogbo àjọ ènìyàn Israẹli nítorí rẹ̀ bí? Òun nìkan kọ́ ni ó kú fún ẹ̀ṣẹ̀ ẹ rẹ̀.’ ”
21 Nígbà náà ni Reubeni, Gadi àti ẹ̀yà Manase sọ nínú ìdáhùn wọn fún àwọn olórí Israẹli pé. 22 Olúwa Ọlọ́run àwọn ọlọ́run! Olúwa Ọlọ́run àwọn ọlọ́run, Òun mọ̀, jẹ́ kí Israẹli pẹ̀lú kí ó mọ̀! Bí èyí bá wà ní ìṣọ̀tẹ̀ tàbí àìgbọ́ràn sí Olúwa, ẹ má ṣe gbà wa ní òní yìí. 23 Bí àwa bá ti mọ pẹpẹ wa láti yí padà kúrò ní ọ̀dọ̀ Olúwa àti láti rú ẹbọ sísun àti ẹbọ oúnjẹ jíjẹ, tàbí ẹbọ àlàáfíà ní orí rẹ, kí Olúwa fún ara rẹ̀ gba ẹ̀san.
24 “Bẹ́ẹ̀ kọ́! Àwa ṣe èyí ní ìbẹ̀rù pé ní ọjọ́ tí àwọn ọmọ yín yóò wí fún wa pé, ‘Kí ni ẹ̀yin ní ṣe pẹ̀lú Olúwa, Ọlọ́run Israẹli? 25 Olúwa ti fi Jordani ṣe ààlà láàrín àwa àti ẹ̀yin—àwọn ọmọ Reubeni àti àwọn ọmọ Gadi! Ẹ kò ni ní ìpín nínú Olúwa.’ Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ yín lè mú kí àwọn ọmọ wa dẹ́kun láti máa bẹ̀rù Olúwa.
26 “Nítorí èyí ni àwa ṣe wí pé, ‘Ẹ jẹ́ kí àwa múra láti mọ pẹpẹ kan, Ṣùgbọ́n kì í ṣe fún ẹbọ sísun, tàbí fún àwọn ìrúbọ.’ 27 Ní ọ̀nà mìíràn, yóò jẹ́ ẹ̀rí kan láàrín àwa àti ẹ̀yin àti àwọn ìran tí ń bọ̀, pé àwa yóò jọ́sìn fún Olúwa ní ibi mímọ́ rẹ̀ pẹ̀lú ẹbọ sísun wa, ẹbọ àti ọrẹ àlàáfíà. Nígbà náà ni ẹ̀yìn ọ̀la, àwọn ọmọ yín kò ní lè sọ fún tiwa pé, ‘Ẹ kò ní ìpín nínú ti Olúwa.’
28 “Àwa sì wí pé, ‘Tí wọ́n bá tilẹ̀ sọ èyí fún wa, tàbí sí àwọn ọmọ wa, a ó dáhùn pé: Ẹ wo àpẹẹrẹ pẹpẹ Olúwa, èyí tí àwọn baba wa mọ, kì í ṣe fún ẹbọ sísun àti ẹbọ ṣùgbọ́n fún ẹ̀rí láàrín àwa àti ẹ̀yin.’
29 “Kí Ọlọ́run má jẹ́ kí àwa kí ó ṣọ̀tẹ̀ sí Olúwa, kí àwa sì yípadà kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ ní òní nípa mímọ pẹpẹ ẹbọ sísun, ọrẹ oúnjẹ jíjẹ àti ẹbọ lẹ́yìn pẹpẹ Olúwa Ọlọ́run wa tí ó dúró níwájú àgọ́ rẹ̀.”
30 Nígbà tí Finehasi àlùfáà àti àwọn olórí ìjọ ènìyàn, àwọn olórí ìdílé Israẹli gbọ́ ohun tí Reubeni, Gadi àti Manase ti sọ, ó dùn mọ́ wọn. 31 Finehasi ọmọ Eleasari, àlùfáà wí fún Reubeni, Gadi àti Manase pé, “Ní òní ni àwa mọ̀ pé Olúwa wà pẹ̀lú wa, nítorí tí ẹ̀yin kò hùwà àìṣòótọ́ sí Olúwa ní orí ọ̀rọ̀ yí nísinsin yìí, ẹ̀yin ti yọ àwọn ará Israẹli kúrò ní ọwọ́ Olúwa”.
32 Nígbà náà ni Finehasi ọmọ Eleasari àlùfáà àti àwọn olórí padà sí Kenaani láti ibi ìpàdé wọn pẹ̀lú àwọn ẹ̀yà Reubeni àti ẹ̀yà Gadi ní Gileadi, wọ́n sì mú ìròyìn tọ àwọn ọmọ Israẹli lọ. 33 Inú wọn sì dùn láti gbọ́ ìròyìn náà, wọ́n sì yin Ọlọ́run. Wọn kò sì sọ̀rọ̀ mọ́ nípa lílọ bá wọn jagun láti run ilẹ̀ tí àwọn ẹ̀yà Reubeni àti ẹ̀yà Gadi ń gbé.
34 Ẹ̀yà Reubeni àti ẹ̀yà Gadi sì fún pẹpẹ náà ní orúkọ yìí: “Ẹ̀rí láàrín wa pé Olúwa ni Ọlọ́run.”
Ọ̀rọ̀ ìdágbére Joṣua sí àwọn olórí
23 Lẹ́yìn ọjọ́ pípẹ́, nígbà tí Olúwa sì ti fún Israẹli ní ìsinmi kúrò ní ọwọ́ àwọn ọ̀tá wọn tí ó yí wọn ká, nígbà náà Joṣua sì ti di arúgbó. 2 Ó sì pe gbogbo Israẹli jọ: àgbàgbà wọn, olórí wọn, adájọ́ àti àwọn ìjòyè, ó sì sọ fún wọn pé, “Èmi ti pọ̀ ní ọdún èmi ti di arúgbó. 3 Ẹ̀yin tìkára yín sì ti rí ohun gbogbo tí Olúwa Ọlọ́run yín ti ṣe sí gbogbo orílẹ̀-èdè wọ̀nyí nítorí yín, Olúwa Ọlọ́run yín ni ó jà fún yín. 4 Ẹ rántí bí mo ṣe pín ogún ìní fún àwọn ẹ̀yà yín ní ilẹ̀ orílẹ̀-èdè gbogbo tí ó kù; àwọn orílẹ̀-èdè tí mo ti ṣẹ́gun ní àárín Jordani àti Òkun ńlá ní ìwọ̀-oòrùn. 5 Olúwa Ọlọ́run yín fúnrarẹ̀ yóò lé wọn jáde kúrò ní ọ̀nà yín, yóò sì tì wọ́n jáde ní iwájú yín, ẹ̀yin yóò sì gba ilẹ̀ ìní wọn, gẹ́gẹ́ bí Olúwa Ọlọ́run ti ṣe ìlérí fún yín.
6 “Ẹ jẹ́ alágbára gidigidi, kí ẹ sì ṣọ́ra láti ṣe ìgbọ́ràn sí ohun tí a kọ sí inú Ìwé Ofin Mose, láìyí padà sí ọ̀tún tàbí sí òsì. 7 Ẹ má ṣe ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn orílẹ̀-èdè tí ó ṣẹ́kù láàrín yín; ẹ má ṣe pe orúkọ òrìṣà wọn tàbí kí ẹ fi wọ́n búra. Ẹ kò gbọdọ̀ sìn wọ́n tàbí ki ẹ tẹríba fún wọn. 8 Ṣùgbọ́n ẹ di Olúwa Ọlọ́run yín mú ṣinṣin gẹ́gẹ́ bí ẹ ti ń ṣe tẹ́lẹ̀ títí di àkókò yìí.
9 “Olúwa ti lé àwọn orílẹ̀-èdè ńlá àti alágbára kúrò níwájú yín; títí di òní yìí kò sí ẹnìkan tí ó le dojúkọ yín. 10 Ọ̀kan nínú yín lé ẹgbẹ̀rún ọ̀tá, nítorí tí Olúwa Ọlọ́run yín jà fún yín gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ìlérí. 11 Bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ ṣọ́ra gidigidi láti fẹ́ràn Olúwa Ọlọ́run yín.
12 “Ṣùgbọ́n bí ẹ bá yí padà, tí ẹ sì gba ìmọ̀ pọ̀ pẹ̀lú àwọn tó ṣẹ́kù lára àwọn orílẹ̀-èdè tí ó kù láàrín yín, tí ẹ sì ń fọmọ fún ara yín ní ìyàwó, tí ẹ sì bá wọn ní àjọṣepọ̀, 13 Nígbà náà ni ẹ ó mọ̀ dájú pé Olúwa Ọlọ́run yín kì yóò lé àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí jáde mọ́ kúrò níwájú yín. Dípò èyí, wọn yóò jẹ́ ìkẹ́kùn àti tàkúté fún un yín, pàṣán ní ẹ̀yin yín àti ẹ̀gún ní ojú yín, títí ẹ ó fi ṣègbé kúrò ní ilẹ̀ dáradára yí, èyí tí Olúwa Ọlọ́run yín ti fi fún yín.
14 “Nísinsin yìí èmi ti fẹ́ máa lọ sí ibi tí àwọn àgbà ń rè. Ẹ mọ̀ pẹ̀lú gbogbo ọkàn yín àti àyà yín pé, kò sí ohun kan tí ó kùnà nínú àwọn ìlérí rere gbogbo tí Olúwa Ọlọ́run yín fi fún un yín. Gbogbo ìlérí tó ti ṣe kò sí ọ̀kan tí ó kùnà. 15 Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ìlérí dáradára gbogbo ti Olúwa Ọlọ́run yín ti wá sí ìmúṣẹ, bẹ́ẹ̀ ni Olúwa yóò mú ibi gbogbo tí ó ti kìlọ̀ wá sí orí yín, títí yóò fi pa yín run kúrò ní ilẹ̀ dáradára tí ó ti fi fún un yín. 16 Bí ẹ bá sẹ̀ sí májẹ̀mú Olúwa Ọlọ́run yín, èyí tí ó pàṣẹ fún un yín, tí ẹ bá sì lọ tí ẹ sì sin àwọn òrìṣà tí ẹ sì tẹ orí ba fún wọn, ìbínú gbígbóná Olúwa yóò wá sórí i yín, ẹ̀yin yóò sì ṣègbé kíákíá kúrò ní ilẹ̀ dáradára tí ó ti fi fún un yín.”
Májẹ̀mú di ọ̀tun ní Ṣekemu
24 Nígbà náà ni Joṣua pe gbogbo àwọn ẹ̀yà Israẹli jọ ní Ṣekemu. Ó pe àwọn àgbàgbà, àwọn olórí, onídàájọ́ àti àwọn ìjòyè Israẹli, wọ́n sì fi ara wọn hàn níwájú Ọlọ́run.
2 Joṣua sì sọ fun gbogbo ènìyàn pé, “Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run Israẹli, wí: ‘Nígbà kan rí àwọn baba ńlá yín Tẹra baba Abrahamu àti Nahori ń gbé ní ìkọjá odò Eufurate, wọ́n sì sin àwọn òrìṣà. 3 Ṣùgbọ́n mo mú Abrahamu baba yín kúrò ní ìkọjá odò Eufurate, mo sì ṣe amọ̀nà rẹ̀ ni gbogbo Kenaani, mo sì fún ní àwọn ọmọ púpọ̀. Mo fún ní Isaaki, 4 àti fún Isaaki ni mo fún ní Jakọbu àti Esau, mo sì fún Esau ní ilẹ̀ orí òkè Seiri ní ìní, ṣùgbọ́n Jakọbu àti àwọn ọmọ rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ lọ sí Ejibiti.
5 “ ‘Nígbà náà ni mo rán Mose àti Aaroni, mo sì yọ Ejibiti lẹ́nu ní ti nǹkan tí mo ṣe níbẹ̀, mo sì mú yín jáde. 6 Nígbà tí mo mú àwọn baba yín jáde kúrò ní Ejibiti, ẹ wá sí Òkun, àwọn ará Ejibiti lépa wọn pẹ̀lú kẹ̀kẹ́ ogun àti àwọn ẹlẹ́ṣin títí ó fi dé Òkun Pupa. 7 Ṣùgbọ́n wọ́n ké pe Olúwa fún ìrànlọ́wọ́, ó sì fi òkùnkùn sí àárín yín àti àwọn ará Ejibiti, ó sì mú Òkun wá sí orí wọn; ó sì bò wọ́n mọ́lẹ̀. Ẹ sì fi ojú yín rí ohun tí mo ṣe sí àwọn ará Ejibiti. Lẹ́yìn náà ẹ sì gbé ní aginjù fún ọjọ́ pípẹ́.
8 “ ‘Èmi mú yín wá sí ilẹ̀ àwọn ará Amori tí ó ń gbé ìlà-oòrùn Jordani. Wọ́n bá yín jà, Ṣùgbọ́n mo fi wọ́n lé yín lọ́wọ́. Èmí pa wọ́n run kúrò níwájú u yín, ẹ sì gba ilẹ̀ ẹ wọn. 9 Nígbà tí Balaki ọmọ Sippori, ọba Moabu, múra láti bá Israẹli jà, ó ránṣẹ́ sí Balaamu ọmọ Beori láti fi yín bú. 10 Ṣùgbọ́n èmi kò fetí sí Balaamu, bẹ́ẹ̀ ni ó súre fún un yín síwájú àti síwájú sí i, mo sì gbà yín kúrò ní ọwọ́ rẹ̀.
11 “ ‘Lẹ́yìn náà ni ẹ rékọjá Jordani, tí ẹ sì wá sí Jeriko. Àwọn ará ìlú Jeriko sì bá yín jà, gẹ́gẹ́ bí ará Amori, Peresi, Kenaani, Hiti, Girgaṣi, Hifi àti Jebusi. Ṣùgbọ́n mo fi wọ́n lé e yín lọ́wọ́. 12 Èmi sì rán oyin sí iwájú yín, tí ó lé wọn kúrò ní iwájú yín, àní ọba Amori méjì. Ẹ kò ṣe èyí pẹ̀lú idà yín àti ọrun yín. 13 Bẹ́ẹ̀ ni mo fún un yín ní ilẹ̀ tí ẹ̀yin kò ṣiṣẹ́ fún, àti àwọn ìlú tí ẹ̀ yin kò kọ́; ẹ sì ń gbé inú wọn, ẹ sì ń jẹ nínú ọgbà àjàrà àti ọgbà olifi tí ẹ kò gbìn.’
14 “Nísinsin yìí ẹ bẹ̀rù Olúwa, kí ẹ sì máa sìn ín ní òtítọ́ àti òdodo. Kí ẹ sì mú òrìṣà tí àwọn baba ńlá yín sìn ní ìkọjá odò Eufurate àti ní Ejibiti kúrò, kí ẹ sì máa sin Olúwa. 15 Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin kò bá fẹ́ láti sin Olúwa, nígbà náà ẹ yàn fún ara yín ní òní ẹni tí ẹ̀yin yóò sìn bóyá òrìṣà tí àwọn baba ńlá yín sìn ní ìkọjá odò Eufurate, tàbí òrìṣà àwọn ará Amori, ní ilẹ̀ ẹni tí ẹ̀yin ń gbé. Ṣùgbọ́n ní ti èmi àti ilé mi, Olúwa ni àwa yóò máa sìn.”
16 Àwọn ènìyàn sì dáhùn pé, “Kí a má ri tí àwa yóò fi kọ Olúwa sílẹ̀ láti sin òrìṣà! 17 Nítorí Olúwa Ọlọ́run fúnrarẹ̀ ni ó gba àwọn baba ńlá wa là kúrò ní Ejibiti, ní oko ẹrú. Òun ni Ọlọ́run tí ó ṣe iṣẹ́ ìyanu ńlá níwájú àwọn ọmọ Israẹli. Ó pa wá mọ́ nínú gbogbo ìrìnàjò wa àti ní àárín gbogbo orílẹ̀-èdè tí a là kọjá. 18 Olúwa sì lé gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè jáde kúrò ní iwájú wa, pẹ̀lú àwọn Amori, tí ń gbé ilẹ̀ náà. Àwa náà yóò máa sin Olúwa, nítorí òun ni Ọlọ́run wa.”
19 Joṣua sì wí fún àwọn ènìyàn náà, pé, “Ẹ̀yin kò le sin Olúwa, nítorí Ọlọ́run mímọ́ ni òun; Ọlọ́run owú ni òun, Kì yóò dárí ìrékọjá àti ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín. 20 Bí ẹ bá kọ Olúwa tí ẹ sì sin òrìṣà orílẹ̀-èdè mìíràn òun yóò padà yóò sì mú ibi bá a yín, yóò sì pa yín run, lẹ́yìn ìgbà tí ó ti ṣe rere fún un yín tan.”
21 Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn sọ fún Joṣua pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́! A yàn láti sin Olúwa.”
22 Lẹ́yìn náà ni Joṣua wí pé, “Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí ara yín pé, ẹ ti yàn láti sin Olúwa.”
Wọ́n dáhùn wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, àwa ni ẹlẹ́rìí.”
23 Nígbà náà ni Joṣua dáhùn wí pé, “Ẹ mú òrìṣà orílẹ̀-èdè mìíràn tí ń bẹ ní àárín yín kúrò, ki ẹ sì yí ọkàn yín padà sí Olúwa, Ọlọ́run Israẹli.”
24 Àwọn ènìyàn náà sì wí fún Joṣua pé, “Olúwa Ọlọ́run nìkan ni àwa yóò máa sìn, òun nìkan ni àwa yóò máa ṣe ìgbọ́ràn sí.”
25 Ní ọjọ́ náà Joṣua dá májẹ̀mú fún àwọn ènìyàn, ó sì fi òfin àti ìlànà fún wọn ní Ṣekemu. 26 Joṣua sì kọ gbogbo ìdáhùn àwọn ènìyàn wọ̀nyí sí inú Ìwé Òfin Ọlọ́run. Lẹ́yìn náà ó gbé òkúta ńlá kan, ó gbé e kalẹ̀ ní abẹ́ igi óákù ní ẹ̀bá ibi mímọ́ Olúwa.
27 “E wò ó!” ó wí fún gbogbo ènìyàn pé, “Òkúta yìí ni yóò jẹ́ ẹlẹ́rìí fún wa, nítorí ó ti gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ tí Olúwa ti sọ fún wa. Yóò jẹ́ ẹlẹ́rìí yín tí ẹ bá ṣe àìṣòótọ́ sí Ọlọ́run yín.”
28 Lẹ́yìn náà ni Joṣua jẹ́ kí àwọn ènìyàn lọ, olúkúlùkù sí ilẹ̀ ìní rẹ̀.
Ikú Joṣua àti Eleasari
29 Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, Joṣua ọmọ Nuni ìránṣẹ́ Olúwa, kú ní ẹni àádọ́fà ọdún (110) 30 Wọ́n sì sin ín sí ilẹ̀ ìní rẹ̀, ní Timnati Serah ni ilẹ̀ orí òkè Efraimu, ní ìhà àríwá Òkè Gaaṣi.
31 Israẹli sì sin Olúwa ní gbogbo ọjọ́ ayé Joṣua àti ní gbogbo ọjọ́ àwọn àgbàgbà tí ó wà lẹ́yìn ikú rẹ̀ tí wọ́n sì rí gbogbo iṣẹ́ ńlá tí Olúwa ṣe fún Israẹli.
32 (B)Egungun Josẹfu, èyí tí àwọn ọmọ Israẹli kó kúrò ní Ejibiti, ni wọ́n sin ní Ṣekemu ní ìpín ilẹ̀ tí Jakọbu rà fún ọgọ́ọ̀rún (100) fàdákà ní ọwọ́ Hamori, baba Ṣekemu. Èyí sì jẹ́ ilẹ̀ ìní àwọn ọmọ Josẹfu.
33 Eleasari ọmọ Aaroni sì kú, wọ́n sì sin ín ní Gibeah, tí a ti pín fún ọmọ rẹ̀ Finehasi ní òkè ilẹ̀ Efraimu.
Johanu onítẹ̀bọmi tún ọnà náà ṣe
3 (A)Ní ọdún kẹ́ẹ̀dógún ìjọba Tiberiu Kesari, nígbà tí Pọntiu Pilatu jẹ́ baálẹ̀ Judea, tí Herodu sì jẹ́ tetrarki Galili, Filipi arákùnrin rẹ̀ sì jẹ́ tetrarki Iturea àti ti Trakoniti, Lisania sì jẹ́ tetrarki Abilene, 2 (B)tí Annasi òun Kaiafa ń ṣe olórí àwọn àlùfáà, nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tọ Johanu ọmọ Sekariah wá ní ijù. 3 (C)Ó sì wá sí gbogbo ilẹ̀ aginjù Jordani, ó ń wàásù ìtẹ̀bọmi ìrònúpìwàdà fún ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀; 4 (D)Bí a ti kọ ọ́ nínú ìwé ọ̀rọ̀ wòlíì Isaiah pé,
“Ohùn ẹni tí ń kígbe ní ijù,
‘ẹ tún ọ̀nà Olúwa ṣe,
ẹ mú ipa ọ̀nà rẹ̀ tọ́.
5 Gbogbo ọ̀gbun ni a yóò kún,
gbogbo òkè ńlá àti òkè kékeré ni a ó tẹ́ pẹẹrẹ;
Wíwọ́ ni a ó ṣe ní títọ́,
àti ọ̀nà gbọ́ngungbọ̀ngun ni a o sọ di dídán.
6 (E)Gbogbo ènìyàn ni yóò sì rí ìgbàlà Ọlọ́run.’ ”
7 (F)Nígbà náà ni ó wí fún ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn tí ó wá láti ṣe ìtẹ̀bọmi lọ́dọ̀ rẹ̀ pé, “Ẹ̀yin ìran paramọ́lẹ̀, ta ni ó kìlọ̀ fún un yín láti sá kúrò nínú ìbínú tí ń bọ̀? 8 (G)Nítorí náà kí ẹ̀yin kí ó so èso tí ó yẹ fún ìrònúpìwàdà, kí ẹ má sì ṣe sí í wí nínú ara yín pé, ‘Àwa ní Abrahamu ní baba.’ Kí èmi kí ó wí fún un yín, Ọlọ́run lè gbé ọmọ dìde fún Abrahamu nínú òkúta wọ̀nyí. 9 (H)Àti nísinsin yìí pẹ̀lú, a fi àáké lé gbòǹgbò igi náà: gbogbo igi tí kò bá so èso rere, a óò ge lulẹ̀, a sì wọ jù sínú iná.”
10 Àwọn ènìyàn sì ń bi í pé, “Kí ni kí àwa kí ó ṣe?”
11 Ó dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Ẹni tí ó bá ní ẹ̀wù méjì, kí ó fi ọ̀kan fún ẹni tí kò ní; ẹni tí ó bá sì ní oúnjẹ, kí ó ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú.”
12 Àwọn agbowó òde sì tọ̀ ọ́ wá láti ṣe ìtẹ̀bọmi lọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì bi í pé, “Olùkọ́, kí ni àwa ó ha ṣe?”
13 Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ má ṣe fi agbára gbà jù bí a ti rán yín lọ mọ́.”
14 Àwọn ọmọ-ogun sì béèrè lọ́dọ̀ rẹ̀ pé, “Àti àwa, kí ni àwa ó ṣe?”
Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ má ṣe hùwà ipá sí ẹnikẹ́ni, kí ẹ má sì ṣe ka ẹ̀sùn èké sí ẹnikẹ́ni; kí òwò ọ̀yà yín tó yín.”
15 (I)Bí àwọn ènìyàn sì ti ń retí, tí gbogbo wọn sì ń rò nínú ara wọn nítorí Johanu, bí òun ni Kristi tàbí òun kọ́; 16 (J)Johanu dáhùn ó sì wí fún gbogbo wọn pé, “Lóòótọ́ ni èmi ń fi omi bamitiisi yín; ṣùgbọ́n ẹni tí ó lágbára jù mí lọ ń bọ̀, okùn bàtà ẹsẹ̀ ẹni tí èmi kò tó tú: òun ni yóò fi Ẹ̀mí Mímọ́ àti iná bamitiisi yín: 17 Ẹni tí àtẹ rẹ̀ ń bẹ ní ọwọ́ rẹ̀, láti gbá ilẹ̀ ìpakà rẹ̀ mọ́ tó tó, kí ó sì kó alikama rẹ̀ sínú àká; ṣùgbọ́n ìyàngbò ni yóò fi iná àjóòkú sun.” 18 Johanu lo oríṣìíríṣìí ọ̀rọ̀ púpọ̀ láti gba àwọn ènìyàn níyànjú àti láti wàásù ìhìnrere fún wọn.
19 (K)Ṣùgbọ́n nígbà ti Johanu bú Herodu tetrarki, tí ó bá wí nítorí Herodia aya Filipi arákùnrin rẹ̀, àti nítorí ohun búburú gbogbo tí Herodu tí ṣe, 20 Ó fi èyí parí gbogbo rẹ̀ nígba tí ó fi Johanu sínú túbú.
Ìtẹ̀bọmi àti ìtàn ìdílé Jesu
21 (L)(M) Nígbà tí a ṣe ìtẹ̀bọmi àwọn ènìyàn gbogbo tán, ó sì ṣe, a bamitiisi Jesu pẹ̀lú, bí ó ti ń gbàdúrà, ọ̀run ṣí sílẹ̀, 22 (N)Ẹ̀mí Mímọ́ sì sọ̀kalẹ̀ sí orí rẹ̀ ní àwọ̀ àdàbà, ohùn kan sì ti ọ̀run wá, tí ó wí pé, “Ìwọ ni àyànfẹ́ ọmọ mi; ẹni tí inú mi dùn sí gidigidi.”
23 (O)(P) Jesu tìkára rẹ̀ ń tó bí ẹni ọgbọ̀n ọdún, nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ ó jẹ́ (bí a ti fi pè) ọmọ Josẹfu,
tí í ṣe ọmọ Eli, 24 tí í ṣe ọmọ Mattati,
tí í ṣe ọmọ Lefi, tí í ṣe ọmọ Meliki,
tí í ṣe ọmọ Janai, tí í ṣe ọmọ Josẹfu,
25 tí í ṣe ọmọ Mattatia, tí í ṣe ọmọ Amosi,
tí í ṣe ọmọ Naumu, tí í ṣe ọmọ Esili,
tí í ṣe ọmọ Nagai, 26 tí í ṣe ọmọ Maati,
tí í ṣe ọmọ Mattatia, tí í ṣe ọmọ Ṣimei,
tí í ṣe ọmọ Josẹfu, tí í ṣe ọmọ Joda,
27 Tí í ṣe ọmọ Joana, tí í ṣe ọmọ Resa,
tí í ṣe ọmọ Serubbabeli, tí í ṣe ọmọ Ṣealitieli,
tí í ṣe ọmọ Neri, 28 tí í ṣe ọmọ Meliki,
tí í ṣe ọmọ Adi, tí í ṣe ọmọ Kosamu,
tí í ṣe ọmọ Elmadamu, tí í ṣe ọmọ Eri,
29 Tí í ṣe ọmọ Joṣua, tí í ṣe ọmọ Elieseri,
tí í ṣe ọmọ Jorimu, tí í ṣe Mattati,
tí í ṣe ọmọ Lefi, 30 tí í ṣe ọmọ Simeoni,
tí í ṣe ọmọ Juda, tí í ṣe ọmọ Josẹfu,
tí í ṣe ọmọ Jonamu, tí í ṣe ọmọ Eliakimu,
31 Tí í ṣe ọmọ Melea, tí í ṣe ọmọ Menna,
tí í ṣe ọmọ Mattata, tí í ṣe ọmọ Natani,
tí í ṣe ọmọ Dafidi, 32 tí í ṣe ọmọ Jese,
tí í ṣe ọmọ Obedi, tí í ṣe ọmọ Boasi,
tí í ṣe ọmọ Salmoni, tí í ṣe ọmọ Nahiṣoni,
33 Tí í ṣe ọmọ Amminadabu, tí í ṣe ọmọ Ramu,
tí í ṣe ọmọ Hesroni, tí í ṣe ọmọ Peresi,
tí í ṣe ọmọ Juda. 34 Tí í ṣe ọmọ Jakọbu,
tí í ṣe ọmọ Isaaki, tí í ṣe ọmọ Abrahamu,
tí í ṣe ọmọ Tẹra, tí í ṣe ọmọ Nahori,
35 Tí í ṣe ọmọ Serugu, tí í ṣe ọmọ Reu,
tí í ṣe ọmọ Pelegi, tí í ṣe ọmọ Eberi,
tí í ṣe ọmọ Ṣela. 36 Tí í ṣe ọmọ Kainani,
tí í ṣe ọmọ Arfaksadi, tí í ṣe ọmọ Ṣemu,
tí í ṣe ọmọ Noa, tí í ṣe ọmọ Lameki,
37 Tí í ṣe ọmọ Metusela, tí í ṣe ọmọ Enoku,
tí í ṣe ọmọ Jaredi, tí í ṣe ọmọ Mahalaleli,
tí í ṣe ọmọ Kainani. 38 Tí í ṣe ọmọ Enosi,
tí í ṣe ọmọ Seti, tí í ṣe ọmọ Adamu,
tí í ṣe ọmọ Ọlọ́run.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.