Old/New Testament
Ìpín ti ẹ̀yà Simeoni
19 Kèké kejì jáde fún ẹ̀yà Simeoni, ní agbo ilé, ní agbo ilé. Ìní wọn sì wà ní àárín ilẹ̀ Juda. 2 Lára ìpín wọn ní:
Beerṣeba (tàbí Ṣeba), Molada, 3 Hasari-Ṣuali, Bala, Esemu, 4 Eltoladi, Betuli, Horma, 5 Siklagi, Beti-Markaboti, Hasari Susa, 6 Beti-Lebaoti àti Ṣarueli, ìlú wọn jẹ́ mẹ́tàlá àti ìletò wọn.
7 Aini, Rimoni, Eteri àti Aṣani: Ìlú wọn jẹ́ mẹ́rin àti ìletò wọn: 8 Àti gbogbo àwọn agbègbè ìlú wọ̀nyí títí dé Baalati-Beeri (Rama ní gúúsù).
Èyí ni ilẹ̀ ìní ẹ̀yà àwọn ọmọ Simeoni, agbo ilé, ní agbo ilé. 9 A mú ogún ìní àwọn ọmọ Simeoni láti ìpín Juda, nítorí ìpín Juda pọ̀ ju èyí tí wọ́n nílò lọ. Báyìí ni àwọn ọmọ Simeoni gba ìní wọn ní àárín ilẹ̀ Juda.
Ìpín fún ẹ̀yà Sebuluni
10 Kèké kẹta jáde fún Sebuluni, ní agbo ilé ní agbo ilé:
Ààlà ìní wọn sì lọ títí dé Saridi. 11 Ó sì lọ sí ìwọ̀-oòrùn ní Marala, ó sì dé Dabbeṣeti, ó sì lọ títí dé odo ní ẹ̀bá Jokneamu. 12 Ó sì yípadà sí ìlà-oòrùn láti Saridi sí ìhà ìlà-oòrùn dé ilẹ̀ Kisiloti-Tabori, ó sì lọ sí Daberati, ó sì gòkè lọ sí Jafia. 13 Nígbà náà ní o lọ sí ìhà ìlà-oòrùn lọ sí Gati-Heferi àti Eti-Kaṣini, ó sì jáde ní Rimoni, ó sì yí sí ìhà Nea. 14 Ní ibẹ̀, ààlà sì yíká ní ìhà àríwá lọ sí Hnatoni ó sì pín ní Àfonífojì Ifita-Eli.
15 Lára wọn ni Katati, Nahalali, Ṣimroni, Idala àti Bẹtilẹhẹmu. Wọ́n sì jẹ́ ìlú méjìlá àti ìletò wọn.
16 Ìlú wọ̀nyí àti ìletò wọn jẹ́ ìní Sebuluni, ní agbo ilé agbo ilé.
Ìpín fún ẹ̀yà Isakari
17 Kèké kẹrin jáde fún Isakari, agbo ilé ní agbo ilé. 18 Lára ilẹ̀ wọn ni èyí:
Jesreeli, Kesuloti, Ṣunemu, 19 Hafraimu, Ṣihoni, Anaharati, 20 Rabiti, Kiṣioni, Ebesi, 21 Remeti, Eni-Gannimu, Eni-Hada àti Beti-Pasesi.
22 Ààlà náà sì dé Tabori, Ṣahasuma, àti Beti-Ṣemeṣi, ó sì pin ní Jordani.
Wọ́n sì jẹ́ ìlú mẹ́rìn-dínlógún àti ìletò wọn.
23 Ìlú wọ̀nyí àti ìletò wọn jẹ́ ìní ẹ̀yà Isakari, ní agbo ilé agbo ilé.
Ìpín fún ẹ̀yà Aṣeri
24 Kèké karùn-ún jáde fún ẹ̀yà Aṣeri, ní agbo ilé agbo ilé. 25 Lára ilẹ̀ wọn ni èyí:
Helikati, Hali, Beteni, Akṣafu, 26 Allameleki, Amadi, àti Miṣali. Ní ìhà ìwọ̀-oòrùn ààlà náà dé Karmeli àti Ṣihori-Libinati. 27 Nígbà náà ni o yí sí ìhà ìlà-oòrùn Beti-Dagoni, dé Sebuluni àti Àfonífojì Ifita-Eli, ó sì lọ sí àríwá sí Beti-Emeki àti Neieli, ó sì kọjá lọ sí Kabuli ní apá òsì. 28 Ó sì lọ sí Abdoni, Rehobu, Hammoni àti Kana títí dé Sidoni ńlá. 29 Ààlà náà sì tẹ̀ sí ìhà Rama, ó sì lọ sí ìlú olódi Tire, ó sì yà sí Hosa, ó sì jáde ní Òkun ní ilẹ̀ Aksibu, 30 Uma, Afeki àti Rehobu.
Wọ́n sì jẹ́ ìlú méjìlélógún àti ìletò wọn.
31 Àwọn ìlú wọ̀nyí àti ìletò wọn ní ìní ẹ̀yà Aṣeri, ní agbo ilé agbo ilé.
Ìpín fún ẹ̀yà Naftali
32 Ìpín kẹfà jáde fún Naftali, agbo ilé ní agbo ilé:
33 Ààlà wọn lọ láti Helefi àti igi ńlá ní Saananimu nímù; kọjá lọ sí Adami Nekebu àti Jabneeli dé Lakkumu, ó sì pín ní Jordani. 34 Ààlà náà gba ìhà ìwọ̀-oòrùn lọ sí Asnoti-Tabori ó sì jáde ní Hukoki. Ó sì dé Sebuluni, ní ìhà gúúsù Aṣeri ní ìhà ìwọ̀-oòrùn àti Juda ní Jordani ní ìhà ìlà-oòrùn.
35 Àwọn ìlú olódi sì Siddimu, Seri, Hamati, Rakàti, Kinnereti, 36 Adama, Rama Hasori, 37 Kedeṣi, Edrei, Eni-Aṣọri, 38 Ironi, Migdali-Eli, Horemu, Beti-Anati àti Beti-Ṣemeṣi.
Wọ́n sì jẹ́ ìlú mọ́kàn-dínlógún àti ìletò wọn.
39 Àwọn ìlú wọ̀nyí àti ìletò wọn ní ìní ẹ̀yà Naftali, ní agbo ilé sí agbo ilé.
Ìpín fún ẹ̀yà Dani
40 Ìbò kéje jáde fún ẹ̀yà Dani, ní agbo ilé ní agbo ilé. 41 Ilẹ̀ ìní wọn nìwọ̀nyí:
Sora, Eṣtaoli, Iri-Ṣemesi, 42 Ṣaalabini, Aijaloni, Itila, 43 Eloni, Timna, Ekroni, 44 Elteke, Gibetoni, Baalati, 45 Jehudu, Bene-Beraki, Gati-Rimoni, 46 Me Jakoni àti Rakkoni, pẹ̀lú ilẹ̀ tí ó kọjú sí Joppa.
47 (Ṣùgbọ́n àwọn ará Dani ní ìṣòro láti gba ilẹ̀ ìní wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n gòkè lọ, wọ́n sì kọlu Leṣemu, wọ́n sì gbà á, wọ́n sì fi idà kọlù ú, wọ́n sì ń gbé ibẹ̀. Wọ́n sì ń gbé ní Leṣemu, wọ́n sì pe orúkọ rẹ̀ ní Dani orúkọ baba ńlá wọn).
48 Àwọn ìlú wọ́n yí àti ìletò wọn ní ìní ẹ̀yà Dani, ní agbo ilé agbo ilé.
Ìpín fún ẹ̀yà Joṣua
49 Nígbà tí wọ́n ti parí pínpín ilẹ̀ náà ní ìpín ti olúkúlùkù, àwọn ará Israẹli fún Joṣua ọmọ Nuni ní ìní ní àárín wọn 50 Bí Olúwa ti pàṣẹ, wọ́n fún un ni ìlú tí ó béèrè fún—Timnati Serah ní ìlú òkè Efraimu. Ó sì kọ́ ìlú náà, ó sì ń gbé ibẹ̀.
51 Wọ̀nyí ni àwọn ilẹ̀ tí Eleasari àlùfáà, Joṣua ọmọ Nuni àti àwọn olórí ẹ̀yà agbo ilé Israẹli fi ìbò pín ní Ṣilo ní iwájú Olúwa ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé. Báyìí ni wọ́n parí pínpín ilẹ̀ náà.
Àwọn ìlú ààbò
20 Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Joṣua pé, 2 (A)“Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé kí wọn yan àwọn ìlú ààbò, gẹ́gẹ́ bí mo ti pàṣẹ fún ọ láti ẹnu Mose, 3 kí ẹni tí ó bá ṣèèṣì pa ènìyàn tàbí tí ó bá pa ènìyàn láìmọ̀-ọ́n-mọ̀ lè sálọ sí ibẹ̀, fún ààbò lọ́wọ́ olùgbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ ẹni tí ó pa. 4 Nígbà tí ó bá sálọ sí ọ̀kan nínú àwọn ìlú wọ̀nyí, yóò sì dúró ní ẹnu-ọ̀nà àtiwọ ibodè ìlú, kí ó sì ṣe àlàyé ara rẹ̀ ní iwájú àwọn àgbàgbà ìlú náà. Nígbà náà ni wọn yóò gbà á sí ìlú wọn, wọn yóò sì fun ní ibùgbé láàrín wọn. 5 Bí olùgbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ bá ń lépa rẹ̀, wọn kò gbọdọ̀ fi àwọn ọ̀daràn náà lé wọn lọ́wọ́, nítorí tí ó pa aládùúgbò rẹ̀ láìmọ̀, tí kò sì kórìíra rẹ̀ tẹ́lẹ̀ rí. 6 Òun ó sì máa gbé inú ìlú náà, títí yóò fi jẹ́jọ́ níwájú ìjọ ènìyàn àti títí ikú olórí àlùfáà tí ó ń ṣiṣẹ́ ìsìn nígbà náà. Nígbà náà ó lè padà sí ilé rẹ̀ ní ìlú tí ó ti sá wá.”
7 Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n yan Kedeṣi ní Galili ní ìlú òkè Naftali, Ṣekemu ní ìlú òkè Efraimu, àti Kiriati-Arba (tí í ṣe, Hebroni) ní ìlú òkè Juda. 8 Ní ìhà ìlà-oòrùn Jordani ti Jeriko, wọ́n ya Beseri ní aginjù ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ ní ẹ̀yà Reubeni, Ramoti ní Gileadi ní ẹ̀yà Gadi, àti Golani ní Baṣani ní ẹ̀yà Manase. 9 Ẹnikẹ́ni nínú àwọn ọmọ Israẹli tàbí àlejò tí ń gbé ní àárín wọn tí ó ṣèèṣì pa ẹnìkan lè sálọ sí àwọn ìlú tí a yà sọ́tọ̀ wọ̀nyí, kí olùgbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ má sì ṣe pa á kí ó to di àkókò tí yóò jẹ́jọ́ níwájú ìjọ ènìyàn.
Àwọn ìlú àwọn ọmọ Lefi
21 (B)Báyìí ni olórí ìdílé àwọn ọmọ Lefi lọ bá Eleasari àlùfáà, Joṣua ọmọ Nuni àti olórí ẹ̀yà àwọn ìdílé ẹ̀yà Israẹli 2 Ní Ṣilo, ní Kenaani, wọn sọ fún wọn pé, “Olúwa pàṣẹ nípasẹ̀ Mose pé kí wọn fún wa ní ìlú láti máa gbé àti ilẹ̀ pápá oko tútù fún ẹran ọ̀sìn wa.”
3 Àwọn ọmọ Israẹli sì fún àwọn ọmọ Lefi ní àwọn ìlú wọ̀nyí, àti ilẹ̀ pápá oko tútù lára ilẹ̀ ìní tiwọn gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.
4 Ìpín kìn-ín-ní wà fún àwọn ọmọ Kohati, ní agbo ilé, agbo ilé. Àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n jẹ́ ọmọ Aaroni àlùfáà ni a pín ìlú mẹ́tàlá fún láti ara ẹ̀yà Juda, Simeoni àti Benjamini.
5 Ìyókù àwọn ọmọ Kohati ni a pín ìlú mẹ́wàá fún láti ara ẹ̀yà Efraimu, Dani àti ìdajì Manase.
6 Àwọn ẹ̀yà Gerṣoni ni a pín ìlú mẹ́tàlá fún láti ara ẹ̀yà Isakari, Aṣeri, Naftali àti ìdajì ẹ̀yà Manase ní Baṣani.
7 Àwọn ọmọ Merari ní agbo ilé, agbo ilé ni wọ́n fún ní ìlú méjìlá láti ara ẹ̀yà Reubeni, Gadi àti Sebuluni.
8 Báyìí ni àwọn ọmọ Israẹli pín ìlú wọ̀nyí àti ilẹ̀ pápá oko tútù fún àwọn ọmọ Lefi gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ láti ẹnu Mose.
9 Láti ara ẹ̀yà Juda àti ẹ̀yà Simeoni ni wọ́n ti pín àwọn ìlú tí a dárúkọ wọ̀nyí, 10 (Ìlú wọ̀nyí ni a fún àwọn ọmọ Aaroni tí ó jẹ́ ọ̀kan nínú ìdílé Kohati tí í ṣe ọmọ Lefi, nítorí tí ìpín àkọ́kọ́ jẹ́ tiwọn).
11 Wọ́n fún wọn ní Kiriati-Arba (tí í ṣe, Hebroni), pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko tútù tí ó yí wọn ká, ní ilẹ̀ òkè Juda. (Arba ni baba ńlá Anaki.) 12 Ṣùgbọ́n àwọn oko àti àwọn abúlé ní agbègbè ìlú náà ni wọ́n ti fi fún Kalebu ọmọ Jefunne gẹ́gẹ́ bí ohun ìní rẹ̀. 13 Ní àfikún wọ́n sì fún àwọn ọmọ Aaroni tí í ṣe àlùfáà ní Hebroni (ọ̀kan nínú ìlú ààbò fún àwọn apànìyàn) pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko tútù rẹ̀, Libina, 14 Jattiri, Eṣitemoa, 15 Holoni àti Debiri, 16 Aini, Jutta àti Beti-Ṣemeṣi, pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko wọn. Ìlú mẹ́sàn-án láti ara ẹ̀yà méjì wọ̀nyí.
17 Láti ara ẹ̀yà Benjamini ni wọ́n ti fún wọn ní:
Gibeoni, Geba, 18 Anatoti àti Almoni, pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko wọn, wọ́n jẹ́ ìlú mẹ́rin.
19 Gbogbo ìlú àwọn àlùfáà, ìran Aaroni jẹ́ mẹ́tàlá pẹ̀lú ilẹ̀ pápá wọn.
20 Ìyókù ìdílé Kohati tí ó jẹ́ ọmọ Lefi ní a pín ìlú fún láti ara ẹ̀yà Efraimu.
21 Ní ilẹ̀ òkè Efraimu wọ́n fún wọn ní:
Ṣekemu (tí ó jẹ́ ìlú ààbò fún apànìyàn) àti Geseri, 22 Kibasaimu àti Beti-Horoni, pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko wọn jẹ́ ìlú mẹ́rin.
23 Láti ara ẹ̀yà Dani ni wọ́n ti fún wọn ní:
Elteke, Gibetoni, 24 Aijaloni àti Gati-Rimoni, pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko tútù wọn jẹ́ ìlú mẹ́rin.
25 Láti ara ìdajì ẹ̀yà Manase ni wọ́n ti fún wọn ní:
Taanaki àti Gati-Rimoni pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko wọn jẹ́ ìlú méjì.
26 Gbogbo ìlú mẹ́wẹ̀ẹ̀wá yìí àti ilẹ̀ pápá wọn ni a fi fún ìyókù ìdílé Kohati.
27 Àwọn ọmọ Gerṣoni ìdílé àwọn ọmọ Lefi ni wọ́n fún lára:
ìdajì ẹ̀yà Manase,
Golani ní Baṣani (ìlú ààbò fún apànìyàn) àti Be-Eṣterah pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko tútù wọ́n jẹ́ méjì;
28 Láti ara ẹ̀yà Isakari ni wọ́n ti fún wọn ní,
Kiṣioni Daberati, 29 Jarmatu àti Eni-Gannimu, pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko wọ́n jẹ́ ìlú mẹ́rin.
30 Láti ara ẹ̀yà Aṣeri ni wọ́n ti fún wọn ní
Miṣali, àti Abdoni, 31 Helikati àti Rehobu, pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko wọ́n jẹ́ ìlú mẹ́rin;
32 Láti ara ẹ̀yà Naftali ni a ti fún wọn ní:
Kedeṣi ní Galili (tí ó jẹ́ ìlú ààbò fún apànìyàn), Hamoti Dori àti Karitani, pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko wọ́n jẹ́ ìlú mẹ́ta.
33 Gbogbo ìlú tí ó jẹ́ ti ọmọ Gerṣoni jẹ́ mẹ́tàlá, pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko wọn.
34 Láti ara ẹ̀yà Sebuluni ni a ti fún ìdílé Merari (tí í ṣe ìyókù ọmọ Lefi) ní:
Jokneamu, Karta, 35 Dimina àti Nahalali, pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko wọn, wọ́n jẹ́ ìlú mẹ́rin.
36 Láti ara ẹ̀yà Reubeni ni wọ́n ti fún wọn ní
Beseri, àti Jahisa, 37 Kedemoti àti Mefaati, pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko wọ́n jẹ́ ìlú mẹ́rin.
38 Láti ara ẹ̀yà Gadi ni wọ́n ti fún wọn ní
Ramoti ní Gileadi (tí ó jẹ́ ìlú ààbò fún apànìyàn), Mahanaimu, 39 Heṣboni àti Jaseri, e pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko wọ́n jẹ́ ìlú mẹ́rin.
40 Gbogbo ìlú tí wọ́n pín fún àwọn ọmọ Merari tí wọ́n jẹ́ ìyókù àwọn ọmọ Lefi jẹ́ méjìlá.
41 Gbogbo ìlú àwọn ọmọ Lefi tó wà láàrín ara ilẹ̀ àwọn ọmọ Israẹli jẹ́ méjì-dínláádọ́ta lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko wọn. 42 Ọ̀kọ̀ọ̀kan ìlú wọ̀nyí ni ó ni ilẹ̀ pápá oko tí ó yí ì ká, bẹ́ẹ̀ náà ló rí fún gbogbo ìlú wọ̀nyí.
43 Báyìí ni Olúwa fún Israẹli ní gbogbo ilẹ̀ tí ó ṣèlérí láti fi fún àwọn baba ńlá wọn. Nígbà tí wọ́n sì gbà á tan wọ́n sì tẹ̀dó síbẹ̀. 44 Olúwa sì fún wọn ní ìsinmi ní gbogbo ọ̀nà, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí fún baba ńlá wọn. Kò sì sí ọ̀kankan nínú àwọn ọ̀tá wọn tí ó lè dojúkọ wọ́n. Olúwa sì fi gbogbo àwọn ọ̀tá wọn lé wọn ní ọwọ́. 45 Kò sí ọ̀kan nínú ìlérí rere tí Olúwa ṣe fún ilé Israẹli tí ó kùnà; Gbogbo rẹ̀ ni ó ṣe.
25 (A)Sì kíyèsi i, ọkùnrin kan wà ní Jerusalẹmu, orúkọ rẹ̀ a máa jẹ́ Simeoni; ọkùnrin náà sì ṣe olóòtítọ́ àti olùfọkànsìn, ó ń retí ìtùnú Israẹli: Ẹ̀mí mímọ́ sì bà lé e. 26 A sì ti fihàn án láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ náà wá pé, òun kì yóò rí ikú, kí ó tó rí Kristi Olúwa. 27 Ó sì ti ipa Ẹ̀mí wá sínú tẹmpili: nígbà tí àwọn òbí rẹ̀ sì gbé Jesu wá, láti ṣe fún un bí ìṣe òfin, 28 Nígbà náà ni Simeoni gbé e ní apá rẹ̀, ó fi ìbùkún fún Ọlọ́run, ó ní:
29 “Olúwa Olódùmarè, nígbà yìí ni ó tó jọ̀wọ́ ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ lọ́wọ́ lọ,
ní Àlàáfíà, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ:
30 (B)Nítorí tí ojú mi ti rí ìgbàlà rẹ ná,
31 Tí ìwọ ti pèsè sílẹ̀ níwájú ènìyàn gbogbo;
32 (C)ìmọ́lẹ̀ láti mọ́ sí àwọn aláìkọlà,
àti ògo Israẹli ènìyàn rẹ̀.”
33 Ẹnu sì ya Josẹfu àti ìyá rẹ̀ sí nǹkan tí a ń sọ sí i wọ̀nyí. 34 Simeoni sì súre fún wọn, ó sì wí fún Maria ìyá rẹ̀ pé: “Kíyèsi i, a gbé ọmọ yìí kalẹ̀ fún ìṣubú àti ìdìde ọ̀pọ̀ ènìyàn ní Israẹli; àti fún ààmì tí a ń sọ̀rọ̀-òdì sí; 35 (Idà yóò sì gún ìwọ náà ní ọkàn pẹ̀lú) kí á lè fi ìrònú ọ̀pọ̀ ọkàn hàn.”
36 (D)Ẹnìkan sì ń bẹ, Anna wòlíì, ọmọbìnrin Penueli, nínú ẹ̀yà Aṣeri: ọjọ́ ogbó rẹ̀ pọ̀, ó ti bá ọkọ gbé ní ọdún méje láti ìgbà wúńdíá rẹ̀ wá; 37 Ó sì ṣe opó títí ó fi di ẹni ọdún mẹ́rìnlélọ́gọ́rin, ẹni tí kò kúrò ní tẹmpili, ṣùgbọ́n ó ń fi àwẹ̀ àti àdúrà sin Ọlọ́run lọ́sàn án àti lóru. 38 Ó sì wólẹ̀ ní àkókò náà, ó sì dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run pẹ̀lú, ó sì sọ̀rọ̀ rẹ̀ fún gbogbo àwọn tí ó ń retí ìdáǹdè Jerusalẹmu.
39 Nígbà tí wọ́n sì ti ṣe nǹkan gbogbo tán gẹ́gẹ́ bí òfin Olúwa, wọ́n padà lọ sí Galili, sí Nasareti ìlú wọn. 40 (E)Ọmọ náà sì ń dàgbà, ó sì ń lágbára, ó sì kún fún ọgbọ́n: oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run sì ń bẹ lára rẹ̀.
Ọ̀dọ́mọkùnrin Jesu ni tẹmpili
41 (F)Àwọn òbí rẹ̀ a sì máa lọ sí Jerusalẹmu ní ọdọọdún sí àjọ ìrékọjá. 42 Nígbà tí ó sì di ọmọ ọdún méjìlá, wọ́n gòkè lọ sí Jerusalẹmu gẹ́gẹ́ bí ìṣe àjọ náà. 43 Nígbà tí ọjọ́ wọn sì pé bí wọ́n ti ń padà bọ̀, ọmọ náà, Jesu dúró lẹ́yìn ní Jerusalẹmu; Josẹfu àti ìyá rẹ̀ kò mọ̀. 44 Ṣùgbọ́n wọ́n ṣe bí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ èrò, wọ́n rin ìrìn ọjọ́ kan; wọ́n wá a kiri nínú àwọn ará àti àwọn ojúlùmọ̀ wọn. 45 Nígbà tí wọn kò sì rí i, wọ́n padà sí Jerusalẹmu, wọ́n ń wá a kiri. 46 Ó sì ṣe, lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta wọ́n rí i nínú tẹmpili ó jókòó ní àárín àwọn olùkọ́ni, ó ń gbọ́ tiwọn, ó sì ń bi wọ́n léèrè. 47 Ẹnu sì ya gbogbo àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ fún òye àti ìdáhùn rẹ̀. 48 (G)Nígbà tí wọ́n sì rí i, háà ṣe wọ́n: ìyá rẹ̀ sì bi í pé, “Ọmọ, èéṣe tí ìwọ fi ṣe wá bẹ́ẹ̀? Sá wò ó, baba rẹ̀ àti èmi ti ń fi ìbànújẹ́ wá ọ kiri.”
49 Ó sì dáhùn wí fún wọn pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń wá mi kiri, ẹ̀yin kò mọ̀ pé èmi kò lè ṣàìmá wà níbi iṣẹ́ Baba mi?” 50 Ọ̀rọ̀ tí o sọ kò sì yé wọn.
51 (H)Ó sì bá wọn sọ̀kalẹ̀ lọ sí Nasareti, sì fi ara balẹ̀ fún wọn: ṣùgbọ́n ìyá rẹ̀ pa gbogbo nǹkan wọ̀nyí mọ́ nínú ọkàn rẹ̀. 52 (I)Jesu sì ń pọ̀ ní ọgbọ́n, sì ń dàgbà, ó sì wà ní ojúrere ní ọ̀dọ̀ Ọlọ́run àti ènìyàn.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.