Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Old/New Testament

Each day includes a passage from both the Old Testament and New Testament.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Joṣua 13-15

Ilẹ̀ tí ó kù láti gbà

13 Nígbà tí Joṣua sì darúgbó tí ọjọ́ orí rẹ̀ sì pọ̀ jọjọ, Olúwa sọ fún un pé, “Ìwọ ti darúgbó púpọ̀, bẹ́ẹ̀ ni ilẹ̀ sì kù lọ́pọ̀lọpọ̀ fún yín láti gbà.

“Èyí ni ilẹ̀ tí ó kù:

“gbogbo àwọn agbègbè àwọn Filistini, àti ti ara Geṣuri: láti odò Ṣihori ní ìlà-oòrùn Ejibiti sí agbègbè Ekroni ìhà àríwá, gbogbo rẹ̀ ni a kà kún Kenaani (agbègbè ìjòyè Filistini márùn-ún ní Gasa, Aṣdodu, Aṣkeloni, Gitti àti Ekroni;

ti àwọn ará Affimu); láti gúúsù;

gbogbo ilẹ̀ àwọn ará Kenaani, láti Arah ti àwọn ará Sidoni títí ó fi dé Afeki, agbègbè àwọn ará Amori;

Àti ilẹ̀ àwọn ará Gebali;

àti gbogbo àwọn Lebanoni dé ìlà-oòrùn, láti Baali-Gadi ní ìsàlẹ̀ Òkè Hermoni dé Lebo-Hamati.

“Ní ti gbogbo àwọn olùgbé agbègbè òkè, láti Lebanoni sí Misrefoti-Maimu, àní, gbogbo àwọn ará Sidoni, èmi fúnra mi ní yóò lé wọn jáde ní iwájú àwọn ará Israẹli. Kí o ri dájú pé o pín ilẹ̀ yí fún Israẹli ní ilẹ̀ ìní, gẹ́gẹ́ bí mo ṣe fi àṣẹ fún ọ, pín ilẹ̀ yìí ní ilẹ̀ ìní fún àwọn ẹ̀yà mẹ́sàn-án àti ìdajì ẹ̀yà Manase.”

Pínpín ilẹ̀ ìhà ìlà-oòrùn Jordani

Àwọn ìdajì ẹ̀yà Manase tí ó kù, àti àwọn Reubeni àti àwọn Gadi ti gba ilẹ̀ ìní, tí Mose ti fún wọn ní ìhà ìlà-oòrùn Jordani bí Mose ìránṣẹ́ Olúwa ti fi fún wọn.

Ó sì lọ títí láti Aroeri tí ń bẹ létí Àfonífojì Arnoni, àti láti ìlú náà tí ń bẹ ní àárín Àfonífojì náà, àti pẹ̀lú gbogbo pẹ̀tẹ́lẹ̀ Medeba títí dé Diboni. 10 Gbogbo ìlú Sihoni ọba àwọn Amori, tí ó ṣe àkóso ní Heṣboni, títí dé ààlà àwọn ará Ammoni.

11 Àti Gileadi, ní agbègbè àwọn ènìyàn Geṣuri àti Maakati, gbogbo Òkè Hermoni àti gbogbo Baṣani títí dé Saleka, 12 Ìyẹn, gbogbo ilẹ̀ ọba Ogu ní Baṣani, tí ó jẹ ọba ní Aṣtarotu àti Edrei, ẹni tí ó kù nínú àwọn Refaimu ìyókù. Mose ti ṣẹ́gun wọn, ó sì ti gba ilẹ̀ wọn. 13 Ṣùgbọ́n àwọn ará Israẹli kò lé àwọn ará Geṣuri àti Maakati jáde, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń gbé ní àárín àwọn ará Israẹli títí di òní yìí.

14 Ṣùgbọ́n àwọn ẹ̀yà Lefi ni kò fi ogún kankan fún, níwọ̀n ìgbà tí ó ti jẹ́ pé ọrẹ àfinásun sí Olúwa Ọlọ́run Israẹli ni ogún tiwọn, gẹ́gẹ́ bí o ti ṣèlérí fún wọn.

15 Èyí ni Mose fi fún ẹ̀yà Reubeni ni agbo ilé sí agbo ilé:

16 Láti agbègbè Aroeri ní etí Arnoni Jọ́ọ́jì àti láti ìlú tí ń bẹ láàrín Jọ́ọ́jì, àti gbogbo pẹ̀tẹ́lẹ̀ ní ìkọjá Medeba 17 sí Heṣboni àti gbogbo ìlú rẹ̀ ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, pẹ̀lú Diboni, Bamoti Baali, Beti-Baali-Mioni, 18 Jahisa, Kedemoti, Mefaati, 19 Kiriataimu, Sibma, Sereti Ṣahari lórí òkè ní àfonífojì. 20 Beti-Peori, gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Pisga, àti Beti-Jeṣimoti 21 gbogbo ìlú tí ó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ àti gbogbo agbègbè Sihoni ọba Amori, tí ó ṣe àkóso Heṣboni. Mose sì ti ṣẹ́gun rẹ̀ àti àwọn ọmọ ìjòyè Midiani, Efi, Rekemu, Suri, Huri àti Reba, àwọn ọmọ ọba pawọ́pọ̀ pẹ̀lú Sihoni tí ó gbé ilẹ̀ náà. 22 Ní àfikún àwọn tí a pa ní ogun, àwọn ọmọ Israẹli fi idà pa Balaamu ọmọ Beori alásọtẹ́lẹ̀.

23 Ààlà àwọn ọmọ Reubeni ni etí odò Jordani. Àwọn ìlú wọ̀nyí àti abúlé rẹ̀ ni ilẹ̀ ìní àwọn ọmọ Reubeni ní agbo ilé ní agbo ilé.

24 Èyí ni ohun tí Mose ti fi fún ẹ̀yà Gadi, ní agbo ilé ní agbo ilé:

25 Agbègbè ìlú Jaseri, gbogbo ìlú Gileadi àti ìdajì orílẹ̀-èdè àwọn ọmọ ará Ammoni títí dé Aroeri, ní ẹ̀bá Rabba; 26 àti láti Heṣboni lọ sí Ramati-Mispa àti Betonimu, àti láti Mahanaimu sí agbègbè ìlú Debiri, 27 àti ní Àfonífojì Beti-Haramu, Beti-Nimra, Sukkoti àti Safoni pẹ̀lú ìyókù agbègbè ilẹ̀ Sihoni ọba Heṣboni (ní ìhà ìlà-oòrùn Jordani, agbègbè rẹ̀ títí dé òpin Òkun Kinnereti).

28 Àwọn ìlú wọ̀nyí àti abúlé rẹ̀ jẹ́ ogún àwọn ọmọ Gadi, ní agbo ilé ní agbo ilé.

29 Èyí ni ohun tí Mose ti fi fún ìdajì ẹ̀yà Manase, èyí ni pé, fún ìdajì ìdílé irú-ọmọ Manase, ní agbo ilé ní agbo ilé:

30 Ilẹ̀ náà fẹ̀ dé Mahanaimu àti gbogbo Baṣani, gbogbo agbègbè ilẹ̀ Ogu ọba Baṣani, èyí tí í ṣe ibùgbé Jairi ní Baṣani, ọgọ́ta ìlú, 31 ìdajì Gileadi, àti Aṣtarotu àti Edrei (àwọn ìlú ọba Ogu ní Baṣani).

Èyí ni fún irú àwọn ọmọ Makiri ọmọ Manase fún ààbọ̀ àwọn ọmọ Makiri, ní agbo ilé ní agbo ilé.

32 Èyí ni ogún tí Mose fi fún wọn nígbà tí ó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu ní ìhà kejì Jordani ní ìlà-oòrùn Jeriko. 33 Ṣùgbọ́n fún ẹ̀yà Lefi, Mose kò fi ogún fún un; Olúwa, Ọlọ́run Israẹli, ní ogún wọn, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ìlérí fún wọn.

Pínpín ilẹ̀ ìhà ìwọ̀-oòrùn Jordani

14 Ìwọ̀nyí ni ilẹ̀ tí àwọn ọmọ Israẹli gbà gẹ́gẹ́ bí ogún ní ilẹ̀ Kenaani, tí Eleasari àlùfáà, Joṣua ọmọ Nuni àti olórí ẹ̀yà àwọn agbo ilé Israẹli pín fún wọn. Ìbò ni a fi pín ìní wọn fún àwọn ẹ̀yà mẹ́sàn-án ààbọ̀ gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ láti ọwọ́ Mose. Mose ti fún àwọn ẹ̀yà méjì àti ààbọ̀ ní ogún wọn ní ìlà-oòrùn Jordani, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Lefi ni kò fi ìní fún ní àárín àwọn tí ó kù. Àwọn ọmọ Josẹfu sì di ẹ̀yà méjì, Manase àti Efraimu. Àwọn ọmọ Lefi kò gba ìpín ní ilẹ̀ náà bí kò ṣe àwọn ìlú tí wọn yóò máa gbé, pẹ̀lú pápá oko tútù fún ọ̀wọ́ ẹran àti agbo ẹran wọn. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ará Israẹli pín ilẹ̀ náà, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

A fún Kalebu ní Hebroni

Àwọn ọkùnrin Juda wá sí ọ̀dọ̀ Joṣua ní Gilgali. Kalebu ọmọ Jefunne ti Kenissiti wí fún un pé, “Ìwọ rántí ohun tí Olúwa sọ fún Mose ènìyàn Ọlọ́run ní Kadeṣi-Barnea nípa ìwọ àti èmi. Mo jẹ́ ọmọ ogójì ọdún nígbà tí Mose ìránṣẹ́ Olúwa rán mi láti Kadeṣi-Barnea lọ rin ilẹ̀ náà wò. Mo sì mú ìròyìn wá fún un gẹ́gẹ́ bí o ti dá mi lójú, ṣùgbọ́n àwọn arákùnrin mi tí wọ́n bá mi lọ mú àyà àwọn ènìyàn já. Ṣùgbọ́n ní tèmi, èmi fi gbogbo ọkàn tẹ̀lé Olúwa Ọlọ́run mi. Ní ọjọ́ náà, Mose búra fún mi pé, ‘Ilẹ̀ tí ẹsẹ̀ rẹ ti rìn ni yóò jẹ́ ìní rẹ àti ti àwọn ọmọ rẹ láéláé, nítorí pé ìwọ fi tọkàntọkàn wà pẹ̀lú Olúwa Ọlọ́run mi.’

10 “Ǹjẹ́ nísinsin yìí, kíyèsi i Olúwa dá mi sí gẹ́gẹ́ bí ó ti wí, láti ọdún márùn-ún-dínláàádọ́ta yìí wá, láti ìgbà tí Olúwa ti sọ ọ̀rọ̀ yìí fún Mose, nígbà tí Israẹli ń rìn kiri nínú aginjù, sì kíyèsi i nísinsin yìí, èmi nìyìí lónìí, ọmọ àrùndínláàdọ́rùnún ọdún. 11 Síbẹ̀ èmi ní agbára lónìí, bí ìgbà tí Mose rán mi jáde. Èmi sì ní agbára láti jáde fún ogun nísinsin yìí gẹ́gẹ́ bí mo ti wà ní ìgbà náà. 12 Nísinsin yìí fi ìlú orí òkè fún mi èyí tí Olúwa ṣe ìlérí fún mi ní ọjọ́ náà. Ìwọ gbọ́ ní ìgbà náà pé àwọn ọmọ Anaki ti wà ní ibẹ̀, àti àwọn ìlú wọn tóbi, pé ó sì ṣe olódi, ṣùgbọ́n bí Olúwa ba fẹ́, èmi yóò lé wọn jáde, gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ.”

13 Bẹ́ẹ̀ ni Joṣua súre fun Kalebu ọmọ Jefunne ó si fun un ní Hebroni ni ilẹ̀ ìní 14 Bẹ́ẹ̀ ni Hebroni jẹ́ ti Kalebu ọmọ Jefunne ará Kenissiti láti ìgbà náà, nítorí tí ó tẹ̀lé Olúwa Ọlọ́run Israẹli tọkàntọkàn. 15 (Hebroni a sì máa jẹ́ Kiriati-Arba ní ẹ̀yìn Arba, èyí tí ó jẹ́ ènìyàn ńlá nínú àwọn ọmọ Anaki.)

Nígbà náà ni ilẹ̀ náà sinmi ogun.

Ìpín fún ẹ̀yà Juda

15 Ìpín fún ẹ̀yà Juda, ní agbo ilé agbo ilé, títí dé agbègbè Edomu, títí dé aginjù Sini ní òpin ìhà gúúsù.

Ààlà wọn ní ìhà gúúsù bẹ̀rẹ̀ láti etí òpin ìhà gúúsù Òkun Iyọ̀, Ó sì gba gúúsù Akrabbimu lọ, títí dé Sini àti sí iwájú ìhà gúúsù Kadeṣi-Barnea. Nígbà náà ó sì tún kọjá Hesroni lọ sí Adari, ó sì tún yípo yíká lọ sí Karka. Ó tún kọjá lọ sí Asmoni, ó sì papọ̀ mọ́ Wadi ti Ejibiti, ó parí sí Òkun. Èyí ni ààlà wọn ní ìhà gúúsù.

Ààlà wọn ní ìhà ìlà-oòrùn ní Òkun Iyọ̀ títí dé ẹnu Jordani.

Ààlà àríwá bẹ̀rẹ̀ láti etí Òkun ní ẹnu Jordani, ààlà náà sì tún dé Beti-Hogla, ó sì lọ sí ìhà àríwá Beti-Araba. Ààlà náà sì tún dé ibi Òkúta Bohani ti ọmọ Reubeni. Ààlà náà gòkè lọ títí dé Debiri láti Àfonífojì Akori, ó sì yípadà sí àríwá Gilgali, èyí tí ń bẹ ní iwájú òkè Adummimu, tí ń bẹ ní ìhà gúúsù odò náà. Ó sì tẹ̀síwájú sí apá omi En-Ṣemeṣi, ó sì jáde sí En-Rogeli. Ààlà náà sì tún gòkè lọ sí Àfonífojì Beni-Hinnomu ní ìhà gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ gúúsù ti Jebusi (tí í ṣe Jerusalẹmu). Ó sì gòkè lọ sí orí òkè tí ó wà lórí Àfonífojì Hinnomu tí ń bẹ ní ìpẹ̀kun Àfonífojì Refaimu ní ìhà àríwá. Ààlà náà sì lọ láti orí òkè lọ sí ìsun omi Nefitoa, ó sì jáde sí ìlú Òkè Efroni, ó sì lọ sí apá ìsàlẹ̀ Baalahi, (tí í ṣe, Kiriati-Jearimu). 10 Ààlà tí ó yípo láti Baalahi lọ sí ìhà ìwọ̀-oòrùn sí òkè Seiri, ó sì lọ sí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ àríwá òkè Jearimu (tí í ṣe, Kesaloni), ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí Beti-Ṣemeṣi, ó sì kọjá lọ sí Timna. 11 Ààlà náà sì lọ sí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ àríwá òkè Ekroni, ó sì yípadà lọ sí Ṣikkeroni, ó sì yípadà lọ sí Òkè Baalahi, ó sì dé Jabneeli, ààlà náà sì parí sí Òkun.

12 Ààlà ìwọ̀-oòrùn sì jẹ́ agbègbè Òkun ńlá.

Ìwọ̀nyí ni ààlà àyíká ènìyàn Juda ní agbo ilé wọn.

13 Gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí Olúwa pa fún Joṣua, ó fi ìpín fún Kalebu ọmọ Jefunne, ìpín ní Juda—Kiriati-Arba, tí í ṣe Hebroni. (Arba sì ní baba ńlá Anaki.) 14 (A)Kalebu sì lé àwọn ọmọ Anaki mẹ́ta jáde láti Hebroni; Ṣeṣai, Ahimani, àti Talmai, ìran Anaki. 15 Ó sì wọ́de ogun láti ibẹ̀ lọ bá àwọn ènìyàn tí ń gbé ní Debiri (tí à ń pè ní Kiriati-Seferi nígbà kan rí). 16 Kalebu sì wí pé, “Èmi yóò fi ọmọbìnrin mi Aksa fún ọkùnrin tí ó bá kọlu Kiriati-Seferi, tí ó sì gbà á ní ìgbéyàwó.” 17 Otnieli ọmọ Kenasi, arákùnrin Kalebu, sì gbà á, báyìí ni Kalebu sì fi ọmọbìnrin rẹ̀ Aksa fún un ní ìyàwó.

18 Ní ọjọ́ kan, nígbà tí Aksa lọ sí ọ̀dọ̀ Otnieli, ó rọ̀ ọ́ kí ó béèrè ilẹ̀ oko lọ́wọ́ baba rẹ̀. Nígbà nàà ni Aksa sọ̀kalẹ̀ ní orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, Kalebu sì béèrè pé, “Kí ni kí èmi ṣe fún ọ?”

19 Ó sì dáhùn pé, “Mo ń fẹ́ kí o ṣe ojúrere kan fún mi, nígbà ti o ti fún mi ní ilẹ̀ ní gúúsù, fún mi ní ìsun omi náà pẹ̀lú.” Kalebu sì fún un ní ìsun òkè àti ìsun ìsàlẹ̀.

20 Èyí ni ilẹ̀ ìní ẹ̀yà àwọn ọmọ Juda gẹ́gẹ́ bi ìdílé wọn:

21 Ìlú ìpẹ̀kun gúúsù ti ẹ̀yà Juda ní gúúsù ní ààlà Edomu nìwọ̀nyí:

Kabṣeeli, Ederi, Jaguri, 22 Kina, Dimona, Adada, 23 Kedeṣi, Hasori, Itina, 24 Sifi, Telemu, Bealoti, 25 Hasori Hadatta, Kerioti Hesroni (tí í ṣe Hasori), 26 Amamu, Ṣema, Molada, 27 Hasari Gada, Heṣmoni, Beti-Peleti, 28 Hasari-Ṣuali, Beerṣeba, Bisiotia, 29 Baalahi, Limu, Esemu, 30 Eltoladi, Kesili, Horma, 31 Siklagi, Madmana, Sansanna, 32 Leboati, Ṣilhimu, Aini àti Rimoni, àpapọ̀ ìlú mọ́kàn-dín-ní-ọgbọ̀n àti àwọn ìletò wọn.

33 Ní ìhà ìwọ̀-oòrùn ẹsẹ̀ òkè:

Eṣtaoli, Sora, Aṣna, 34 Sanoa, Eni-Gannimu, Tapua, Enamu, 35 Jarmatu, Adullamu, Soko, Aseka, 36 Ṣaaraimu, Adittaimu àti Gedera (tàbí Gederotaimu). Ìlú mẹ́rìnlá àti àwọn ìletò wọn.

37 Senani, Hadaṣa, Migdali Gadi, 38 Dileani, Mispa, Jokteeli, 39 Lakiṣi, Boskati, Egloni, 40 Kabboni, Lamasi, Kitlisi, 41 Gederoti, Beti-Dagoni, Naama àti Makkeda, ìlú mẹ́rìn-dín-ní-ogún àti ìletò wọn.

42 Libina, Eteri, Aṣani, 43 Hifita, Aṣna, Nesibu, 44 Keila, Aksibu àti Meraṣa: ìlú mẹ́sàn-án àti àwọn ìletò wọn.

45 Ekroni, pẹ̀lú ibùgbé àti àwọn ìletò rẹ̀ tó yí i ká, 46 ìwọ̀-oòrùn Ekroni, gbogbo èyí tí ń bẹ nítòsí Aṣdodu, pẹ̀lú àwọn ìletò wọn, 47 Aṣdodu, agbègbè ìlú rẹ̀ àti ìletò; àti Gasa, ìlú rẹ̀ àti ìletò, títí ó fi dé odò Ejibiti àti agbègbè Òkun ńlá (Òkun Mẹditarenia).

48 Ní ilẹ̀ òkè náà:

Ṣamiri, Jattiri, Soko, 49 Dannah, Kiriati-Sannnah (tí í ṣe Debiri), 50 Anabu, Eṣitemo, Animu, 51 Goṣeni, Holoni àti Giloni, ìlú mọ́kànlá àti ìletò wọn.

52 Arabu, Duma, Eṣani, 53 Janimu, Beti-Tapua, Afeka, 54 Hamuta, Kiriati-Arba (tí í ṣe, Hebroni) àti Ṣiori: ìlú mẹ́sàn-án àti àwọn ìletò rẹ̀

55 Maoni, Karmeli, Sifi, Jutta, 56 Jesreeli, Jokdeamu, Sanoa, 57 Kaini, Gibeah àti Timna: ìlú mẹ́wàá àti àwọn ìletò wọn.

58 Halhuli, Beti-Suri, Gedori, 59 Maarati, Beti-Anoti àti Eltekoni: ìlú mẹ́fà àti àwọn ìletò wọn.

60 Kiriati-Baali (tí í ṣe, Kiriati-Jearimu) àti Rabba ìlú méjì àti ìletò wọn.

61 Ní aginjù:

Beti-Araba, Middini, Sekaka, 62 Nibṣani, Ìlú Iyọ̀ àti En-Gedi: ìlú mẹ́fà àti ìletò wọn.

63 (B)Juda kò lè lé àwọn ọmọ Jebusi jáde, tí wọ́n ń gbé ní Jerusalẹmu. Àwọn ará Jebusi sì ń gbé pẹ̀lú àwọn ènìyàn Juda títí dí òní.

Luku 1:57-80

Ìbí Johanu onítẹ̀bọmi

57 Nígbà tí ọjọ́ Elisabeti pé tí yóò bí; ó sì bí ọmọkùnrin kan. 58 Àwọn aládùúgbò, àti àwọn ìbátan rẹ̀ gbọ́ bí Olúwa ti fi àánú ńlá hàn fún un, wọ́n sì bá a yọ̀.

59 (A)Ó sì ṣe, ní ọjọ́ kẹjọ wọ́n wá láti kọ ọmọ náà nílà; wọ́n sì fẹ́ sọ orúkọ rẹ̀ ní Sekariah, gẹ́gẹ́ bí orúkọ baba rẹ̀. 60 Ìyá rẹ̀ sì dáhùn, ó ní, “Bẹ́ẹ̀ kọ́! Johanu ni a ó pè é.”

61 Wọ́n sì wí fún un pé, “Kò sí ọ̀kan nínú àwọn ará rẹ̀ tí à ń pè ní orúkọ yìí.”

62 Wọ́n sì ṣe àpẹẹrẹ sí baba rẹ̀, bí ó ti ń fẹ́ kí a pè é. 63 Ó sì béèrè fún wàláà, ó sì kọ ọ wí pé, “Johanu ni orúkọ rẹ̀.” Ẹnu sì ya gbogbo wọn. 64 Ẹnu rẹ̀ sì ṣí lọ́gán, okùn ahọ́n rẹ̀ sì tú, ó sì sọ̀rọ̀, ó sì ń yin Ọlọ́run. 65 Ẹ̀rù sì ba gbogbo àwọn tí ń bẹ ní agbègbè wọn: a sì ròyìn gbogbo nǹkan wọ̀nyí ká gbogbo ilẹ̀ òkè Judea. 66 Ó sì jẹ́ ohun ìyanu fún gbogbo àwọn tí ó gbọ́ nípa rẹ̀, wọ́n sì tò ó sínú ọkàn wọn, wọ́n ń wí pé, “Irú-ọmọ kín ni èyí yóò jẹ́?” Nítorí tí ọwọ́ Olúwa wà pẹ̀lú rẹ̀.

Orin Ṣakariah

67 Sekariah baba rẹ̀ sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, ó sì sọtẹ́lẹ̀, ó ní:

68 “Olùbùkún ni Olúwa Ọlọ́run Israẹli;
    nítorí tí ó ti bojú wò, tí ó sì ti dá àwọn ènìyàn rẹ̀ nídè,
69 Ó sì ti gbé ìwo ìgbàlà sókè fún wa
    ní ilé Dafidi ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀;
70 (bí ó ti sọtẹ́lẹ̀ láti ẹnu àwọn wòlíì rẹ̀ mímọ́ tipẹ́tipẹ́),
71 Pé, a ó gbà wá là lọ́wọ́
    àwọn ọ̀tá wa àti lọ́wọ́ àwọn tí ó kórìíra wá.
72 Láti ṣe àánú tí ó ṣèlérí fún àwọn baba wa,
    àti láti rántí májẹ̀mú rẹ̀ mímọ́,
73 ìbúra tí ó ti bú fún Abrahamu baba wa,
74 láti gbà wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa,
    kí àwa kí ó lè máa sìn láìfòyà,
75     ni ìwà mímọ́ àti ní òdodo níwájú rẹ̀, ní ọjọ́ ayé wa gbogbo.

76 (B)“Àti ìwọ, ọmọ mi, wòlíì Ọ̀gá-ògo jùlọ ni a ó máa pè ọ́:
    nítorí ìwọ ni yóò ṣáájú Olúwa láti tún ọ̀nà rẹ̀ ṣe;
77 (C)láti fi ìmọ̀ ìgbàlà fún àwọn ènìyàn rẹ̀
    fún ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ wọn,
78 (D)nítorí ìyọ́nú Ọlọ́run wà;
    nípa èyí tí ìlà-oòrùn láti òkè wá bojú wò wá,
79 (E)Láti fi ìmọ́lẹ̀ fún àwọn tí ó jókòó ní
    òkùnkùn àti ní òjìji ikú,
àti láti fi ẹsẹ̀ wa lé ọ̀nà àlàáfíà.”

80 (F)Ọmọ náà sì dàgbà, ó sì le ní ọkàn, ó sì ń gbé ní ijù títí ó fi di ọjọ́ ìfihàn rẹ̀ fún Israẹli.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.