Old/New Testament
22 Nígbà náà Dafidi wí pé, “Ilé Olúwa Ọlọ́run ni ó gbọdọ̀ wà níbí, àti pẹ̀lú pẹpẹ ẹbọ sísun fún Israẹli.”
Ìmúrasílẹ̀ fún ilé tí a kọ́ fún ìsìn Ọlọ́run
2 Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi pàṣẹ láti kó àwọn àjèjì tí ń gbé ní Israẹli jọ, àti wí pé lára wọn ni ó ti yan àwọn agbẹ́-òkúta láti gbé òkúta dáradára láti fi kọ́lé Ọlọ́run. 3 Dafidi sì pèsè ọ̀pọ̀lọpọ̀ iye irin láti fi ṣe ìṣó fún àwọn ìlẹ̀kùn ẹnu-ọ̀nà àti fún idẹ; àti fún òpó idẹ ni àìní ìwọ̀n. 4 Ó sì tún pèsè ọ̀pọ̀lọpọ̀ igi Kedari tí ó jẹ́ àìníye, nítorí pé àwọn ará Sidoni àti àwọn ará Tire mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ igi kedari wá fún Dafidi.
5 Dafidi wí pé, “Ọmọ mi Solomoni ọ̀dọ́mọdé ni ó sì jẹ́ aláìní ìrírí, ilé tí a ó kọ́ fún Olúwa gbọdọ̀ jẹ́ títóbi jọjọ, kí ó sì ní òkìkí àti ògo jákèjádò gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè. Nítorí náà ni èmi yóò ṣe pèsè sílẹ̀ fún un”. Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi sì ṣe ìpèsè sílẹ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ kí ó tó di wí pé ó kú.
6 Nígbà náà ó pe Solomoni ọmọ rẹ̀ ó sì sọ fun pé kí ó kọ́ ilé fún un Olúwa, Ọlọ́run Israẹli. 7 (A)Dafidi sì wí fún Solomoni pé, “Ọmọ mi, mo sì ní-in ní ọkàn mi láti kọ́ ilé fún orúkọ Olúwa Ọlọ́run mi. 8 Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé: ‘Ìwọ ti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀, o sì ti ja ọ̀pọ̀ ogun ńláńlá, kì í ṣe ìwọ ni yóò kọ́ ilé fún orúkọ mi, nítorí ìwọ ti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ púpọ̀ lórí ilẹ̀ ní ojú mi. 9 Ṣùgbọ́n ìwọ yóò ní ọmọ tí yóò sì jẹ́ ọkùnrin onírẹ̀lẹ̀ àti onísinmi, Èmi yóò sì fún un ní ìsinmi láti ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀ lórí gbogbo ilẹ̀ yíká. Orúkọ rẹ̀ yóò sì máa jẹ́ Solomoni, Èmi yóò sì fi àlàáfíà àti ìdákẹ́ jẹ́ẹ́ fún Israẹli lásìkò ìjọba rẹ̀. 10 Òun ni ẹni náà tí yóò kọ́ ilé fún orúkọ mi. Yóò sì jẹ́ ọmọ mi, èmi yóò sì jẹ́ baba rẹ̀ èmi yóò sì fi ìdí ìtẹ́ ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ lórí Israẹli láéláé.’
11 “Nísinsin yìí, ọmọ mi, kí Olúwa wà pẹ̀lú rẹ, kí ìwọ kí ó sì ní àṣeyọrí kí o sì kọ́ ilé Olúwa Ọlọ́run rẹ, àti gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ nípa rẹ. 12 Kí Olúwa kí ó fún ọ ni ọgbọ́n àti òye nígbà tí ó bá fi ọ́ ṣe aláṣẹ lórí Israẹli, Bẹ́ẹ̀ ni kí ìwọ kí ó lè pa òfin Olúwa Ọlọ́run mọ́. 13 Nígbà náà ìwọ yóò sì ní àṣeyọrí tí ìwọ bá ṣe àkíyèsí láti mú àṣẹ àti ìdájọ́ àti òfin ti Olúwa ti fi fún Mose fun Israẹli ṣe. Bẹ́ẹ̀ ni ki ìwọ jẹ́ alágbára àti onígboyà. Má ṣè bẹ̀rù tàbí kí àyà má sì ṣe fò ọ́.
14 “Èmi ti gba ìpọ́njú ńlá láti ṣe fún ilé Olúwa ọ̀kẹ́ márùn-ún tálẹ́ǹtì wúrà, àti ẹgbẹ̀rún ẹgbẹ̀rún tálẹ́ǹtì fàdákà, ìwọ̀n idẹ àti irin tí ó tóbi àìní ìwọ̀n, àti ìtì igi àti òkúta. Ìwọ sì tún le fi kún wọn. 15 Ìwọ sì ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn oníṣẹ́ ènìyàn: àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà, àti àwọn oníṣọ̀nà òkúta àti àwọn agbẹ́-òkúta, àti gẹ́gẹ́ bí onírúurú ọlọ́gbọ́n ènìyàn ní gbogbo onírúurú iṣẹ́. 16 Nínú wúrà, fàdákà àti idẹ àti irin oníṣọ̀nà tí kò ní ìwọ̀n. Nísinsin yìí bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́, kí Olúwa wà pẹ̀lú rẹ.”
17 Nígbà náà Dafidi pa á láṣẹ fún gbogbo àwọn àgbàgbà ní Israẹli láti ran Solomoni ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́. 18 Ó sì wí pé, “Ṣé kò sí Olúwa Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú rẹ? Òun kò ha ti fi ìsinmi fún ọ lórí gbogbo ilẹ̀? Nítorí ó sì ti fi àwọn tí ń gbé ní ilẹ̀ náà lé mi lọ́wọ́ ó sì ti fi ìṣẹ́gun fún ilẹ̀ náà níwájú Olúwa àti níwájú àwọn ènìyàn. 19 Nísinsin yìí, ẹ ṣí ọkàn yin páyà àti àyà yín sí àti wá Olúwa Ọlọ́run yín. Bẹ́ẹ̀ sì ni kọ́ ibi mímọ́ fún Olúwa Ọlọ́run. Bẹ́ẹ̀ ni kí ìwọ kí ó le gbé àpótí ẹ̀rí ti májẹ̀mú Olúwa àti ohun èlò mímọ́ tí ó jẹ́ ti Ọlọ́run, sínú ilé Olúwa tí a o kọ́ fún orúkọ Olúwa.”
Àwọn ará Lefi
23 Nígbà tí Dafidi sì dàgbà, tí ó sì di arúgbó, ó sì fi Solomoni ọmọ rẹ̀ jẹ ọba lórí Israẹli.
2 Ó sì kó gbogbo àgbàgbà Israẹli jọ, àti gẹ́gẹ́ bí àwọn àlùfáà àti àwọn ará Lefi. 3 Àwọn ọmọ Lefi láti ọgbọ̀n ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ni wọ́n kà àpapọ̀ iye àwọn ọkùnrin wọn sì jẹ́ ẹgbàá-mọ́kàn-dínlógún (38,000) 4 Dafidi sì wí pe, ní ti èyí, ẹgbàá-méjìlá (24,000) ni kí wọn jẹ́ alábojútó iṣẹ́ ilé fún Olúwa àti ẹgbàáta (6,000) ni kí ó ṣe olórí àti onídàájọ́. 5 Ẹgbàajì (4,000) ni kí ó jẹ́ olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà àti ẹgbàajì (4,000) ni kí o sì jẹ́ ẹni ti yóò máa yin Olúwa pẹ̀lú ohun èlò orin, mo ti ṣe èyí fún ìdí pàtàkì yìí.
6 Dafidi sì pín àwọn ọmọ Lefi sí ẹgbẹgbẹ́ láàrín àwọn ọmọ Lefi: Gerṣoni, Kohati àti Merari.
Àwọn ọmọ Gerṣoni
7 Àwọn tí ó jẹ́ ọmọ Gerṣoni:
Laadani àti Ṣimei.
8 Àwọn ọmọ Laadani
Jehieli ẹni àkọ́kọ́, Setamu àti Joeli, mẹ́ta ní gbogbo wọn.
9 Àwọn ọmọ Ṣimei:
Ṣelomiti, Hasieli àti Harani mẹ́ta ní gbogbo wọn.
Àwọn wọ̀nyí sì ni olórí àwọn ìdílé Laadani.
10 Àti ọmọ Ṣimei:
Jahati, Sina, Jeuṣi àti Beriah.
Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ Ṣimei mẹ́rin ni gbogbo wọn.
11 Jahati sì ni alákọ́kọ́ Sinah sì ni ẹlẹ́kejì, ṣùgbọ́n Jeuṣi àti Beriah kò ní àwọn ọmọ púpọ̀; bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì ka ara wọn sí ìdílé kan pẹ̀lú ìfilé lọ́wọ́ kan.
Àwọn ará Kohati
12 Àwọn ọmọ Kohati:
Amramu, Isari, Hebroni àti Usieli mẹ́rin ni gbogbo wọn.
13 (B)Àwọn ọmọ Amramu.
Aaroni àti Mose.
A sì ya Aaroni sọ́tọ̀ òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ títí láéláé, láti kọjú sí ohun mímọ́ jùlọ, láti fi rú ẹbọ sísun níwájú Olúwa, láti máa ṣe òjíṣẹ́ níwájú rẹ̀ àti láti kéde ìbùkún ní orúkọ rẹ̀ títí láéláé. 14 Àwọn ọmọ Mose ènìyàn Ọlọ́run ni wọ́n kà gẹ́gẹ́ bí apá kan ẹ̀yà Lefi.
15 Àwọn ọmọ Mose:
Gerṣomu àti Elieseri.
16 Àwọn ọmọ Gerṣomu:
Ṣubueli sì ni alákọ́kọ́.
17 Àwọn ọmọ Elieseri:
Rehabiah sì ni ẹni àkọ́kọ́.
Elieseri kò sì tún ní ọmọ mìíràn, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Rehabiah wọ́n sì pọ̀ níye.
18 Àwọn ọmọ Isari:
Ṣelomiti sì ni ẹni àkọ́kọ́.
19 Àwọn ọmọ Hebroni:
Jeriah sì ni ẹni àkọ́kọ́, Amariah sì ni ẹni ẹ̀ẹ̀kejì,
Jahasieli sì ni ẹ̀ẹ̀kẹ́ta àti Jekameamu ẹ̀ẹ̀kẹrin.
20 Àwọn ọmọ Usieli:
Mika ni àkọ́kọ́ àti Iṣiah ẹ̀ẹ̀kejì.
Àwọn ará Merari
21 Àwọn ọmọ Merari:
Mahili àti Muṣi.
Àwọn ọmọ Mahili:
Eleasari àti Kiṣi.
22 Eleasari sì kú pẹ̀lú Àìní àwọn ọmọkùnrin: Ó ní ọmọbìnrin nìkan. Àwọn ọmọ ẹ̀gbọ́n, àwọn ọmọ Kiṣi, sì fẹ́ wọn.
23 Àwọn ọmọ Muṣi:
Mahili, Ederi àti Jerimoti mẹ́ta ni gbogbo wọn.
24 Àwọn wọ̀nyí sì ni ọmọ Lefi bí ìdílé wọn. Olórí ìdílé gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti fi orúkọ sílẹ̀ lábẹ́ orúkọ wọn, ó sì kà wọn ní ẹyọ kọ̀ọ̀kan, wí pé, àwọn òṣìṣẹ́ tí ó jẹ́ ogún ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ tí ń ṣiṣẹ́ ìsìn nínú ilé Olúwa 25 Nítorí pé Dafidi ti sọ pé Ọlọ́run Israẹli, ti fi ìsinmi fún àwọn ènìyàn tí ó kù tí sì ń gbé Jerusalẹmu títí láéláé. 26 Àwọn ọmọ Lefi kò sì tún ru àgọ́ tàbí ọ̀kankan lára àwọn ohun èlò tí wọ́n ń lò níbi ìsìn rẹ̀. 27 Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ ìkẹyìn Dafidi sí, àwọn ọmọ Lefi, wọ́n sì kà wọ́n, bẹ̀rẹ̀ láti orí àwọn ọmọ ogún ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ.
28 Iṣẹ́ àwọn ọmọ Lefi ni láti ran àwọn ọmọ Aaroni lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ wọn fún ti ilé Olúwa: láti wà lábẹ́ ìkáwọ́ agbára ìlú, àti ẹ̀gbẹ́ ilé, àti ìwẹ̀nùmọ́ ti gbogbo ohun ìyàsọ́tọ̀ àti ṣíṣe ohun tí í ṣe iṣẹ́ ìsìn nínú ilé Olúwa. 29 Wọ́n sì wà ní ìkáwọ́ àkàrà tí wọ́n mú jáde láti orí tábìlì, àti ìyẹ̀fun fún ẹbọ, àti àkàrà aláìwú, àti fún púpọ̀ àti èyí tí a pòpọ̀, àti gbogbo onírúurú ìwọ̀n àti wíwọ̀n àti òṣùwọ̀n. 30 Wọ́n sì gbọdọ̀ dúró ní gbogbo òwúrọ̀ láti dúpẹ́ àti láti yin Olúwa. Wọ́n sì gbọdọ̀ ṣe irú kan náà ní àṣálẹ́. 31 Àti láti rú ẹbọ sísun fún Olúwa ní ọjọ́ ìsinmi àti ní àsìkò oṣù tuntun àti ní àjọ̀dún tí a yàn. Wọ́n gbọdọ̀ sìn níwájú Olúwa lójoojúmọ́ ní iye tó yẹ àti ní ọ̀nà tí a ti pàṣẹ fún wọn.
32 Bẹ́ẹ̀ ni nígbà náà, àwọn ọmọ Lefi gbé ìgbékalẹ̀ jáde fún ìpàdé àgọ́, fún ibi mímọ́ àti, lábẹ́ àwọn arákùnrin àwọn ọmọ Aaroni fún ìsìn ilé Olúwa.
Pínpín àwọn àlùfáà
24 Àwọn wọ̀nyí sì ni pínpín àwọn ọmọ Aaroni:
Àwọn ọmọ Aaroni ni Nadabu, Abihu, Eleasari àti Itamari. 2 Ṣùgbọ́n Nadabu àti Abihu kú kí ó tó di wí pé baba wọn kú, wọn kò sì ní àwọn ọmọ; bẹ́ẹ̀ ni Eleasari àti Itamari sì ṣe gẹ́gẹ́ bí àlùfáà. 3 Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Sadoku ọmọ Eleasari àti Ahimeleki ọmọ Itamari, Dafidi sì yà wọ́n nípa nínú ìpín fún ìyàsọ́tọ̀ àwọn iṣẹ́ ìsìn wọn. 4 A rí ọ̀pọ̀ àwọn olórí lára àwọn ọmọ Eleasari ju lára àwọn ọmọ Itamari lọ, wọ́n sì pín wọn lẹ́sẹ lẹ́sẹ: mẹ́rìn-dínlógún olórí láti ìdílé ọmọ Eleasari ìran wọn àti olórí méjọ ìdílé láti ara àwọn ọmọ Itamari. 5 Wọ́n sì pín wọn láìṣègbè nípa yíya ìpín, nítorí àwọn olórí ibi mímọ́ àti àwọn olórí ilé Ọlọ́run wà láàrín àwọn ọmọ méjèèjì Eleasari àti Itamari.
6 Ṣemaiah ọmọ Netaneli, akọ̀wé ọ̀kan lára àwọn ọmọ Lefi sì kọ orúkọ wọn níwájú ọba àti àwọn ìjòyè: Sadoku àlùfáà, Ahimeleki ọmọ Abiatari àti olórí ìdílé àwọn àlùfáà tí a mú láti ọ̀dọ̀ Eleasari àti ọ̀kan láti ọ̀dọ̀ Itamari.
7 Ìpín èkínní jáde sí Jehoiaribu,
èkejì sí Jedaiah,
8 Ẹlẹ́kẹta sì ni Harimu,
ẹ̀kẹrin sì ní Ṣeorimu,
9 Ẹ̀karùnún sì ni Malkiah,
ẹlẹ́kẹfà sì ni Mijamini,
10 Èkeje sì ni Hakosi,
ẹlẹ́kẹjọ sí ni Abijah,
11 Ẹ̀kẹsànán sì ni Jeṣua,
ẹ̀kẹwàá sì ni Ṣekaniah,
12 Ẹ̀kọkànlá sì ni Eliaṣibu,
ẹlẹ́kẹjìlá sì ni Jakimu,
13 Ẹ̀kẹtàlá sì ni Hupa,
ẹlẹ́kẹrìnlá sì ni Jeṣebeabu,
14 Ẹ̀kẹdógún sì ni Bilgah,
ẹ̀kẹrìn-dínlógún sì ni Immeri
15 Ẹ̀kẹtà-dínlógún sì ni Hesiri,
èkejì-dínlógún sì ni Hafisesi,
16 Ẹ̀kọkàndínlógún sì ni Petahiah,
ogún sì ni Jeheskeli,
17 Ẹ̀kọkànlélógún sì ni Jakini,
ẹ̀kẹrìnlélógún sì ni Gamuli,
18 Ẹ̀kẹtàlélógún sì ni Delaiah,
ẹ̀kẹrìnlélógún sì ni Maasiah.
19 Àwọn wọ̀nyí ni a yàn fún iṣẹ́ ìsìn nígbà tí wọ́n wọ ilé Olúwa, gẹ́gẹ́ bí ìlànà àti àṣẹ tí a ti fi fún wọn láti ọwọ́ baba ńlá wọn Aaroni gẹ́gẹ́ bí Olúwa, Ọlọ́run Israẹli, tí pàṣẹ fun un.
Ìyókù nínú àwọn ọmọ Lefi
20 Ìyókù àwọn ọmọ Lefi:
Láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Amramu: Ṣubaeli
láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Ṣubueli; Jehdeiah.
21 Àti gẹ́gẹ́ bí Rehabiah, láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Rehabiah, Iṣiah sì ni alákọ́kọ́.
22 Láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Isari: Ṣelomiti;
láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Ṣelomoti: Jahati.
23 Àwọn ọmọ Hebroni:
Jeriah alákọ́kọ́, Amariah ẹlẹ́kejì, Jahasieli ẹlẹ́kẹta àti Jekameamu ẹlẹ́kẹrin.
24 Àwọn ọmọ Usieli: Mika;
nínú àwọn ọmọ Mika: Ṣamiri.
25 Àwọn arákùnrin Mika: Iṣi;
nínú àwọn ọmọ Iṣiah: Sekariah.
26 Àwọn ọmọ Merari: Mahili àti Muṣi.
Àwọn ọmọ Jaasiah: Beno.
27 Àwọn ọmọ Merari:
Láti Jaasiah: Beno, Ṣohamu, Sakkuri àti Ibri.
28 Láti Mahili: Eleasari, ẹni tí kò ni àwọn ọmọ.
29 Láti Kiṣi: Àwọn ọmọ Kiṣi: Jerahmeeli.
30 Àti àwọn ọmọ Muṣi: Mahili, Ederi àti Jerimoti.
Èyí ni àwọn ọmọ Lefi, gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn.
31 Wọ́n sì ṣé kèké gẹ́gẹ́ bí àwọn arákùnrin wọn àwọn ọmọ Aaroni ṣe ṣẹ́, níwájú ọba Dafidi àti Sadoku, Ahimeleki, àti olórí ìdílé àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Lefi. Àwọn ìdílé àgbàgbà arákùnrin wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀ lórí àwọn arákùnrin wọn kéékèèkéé.
28 (A)Lẹ́yìn náà Jesu wí fún wọn pé, “Nígbà tí ẹ mọ̀ pé, nígbà tí ẹ bá gbé Ọmọ ènìyàn sókè, nígbà náà ni ẹ ó mọ̀ pé èmi ni àti pé èmi kò dá ohunkóhun ṣe fún ara mi; ṣùgbọ́n bí Baba ti kọ́ mi, èmí ń sọ nǹkan wọ̀nyí. 29 Ẹni tí ó rán mí sì ń bẹ pẹ̀lú mi: kò fi mí sílẹ̀ ní èmi nìkan; nítorí tí èmi ń ṣe ohun tí ó wù ú nígbà gbogbo.” 30 (B)Bí ó ti ń sọ nǹkan wọ̀nyí, ọ̀pọ̀ ènìyàn gbà á gbọ́.
Àwọn ọmọ Abrahamu
31 (C)Nítorí náà Jesu wí fún àwọn Júù tí ó gbà á gbọ́, pé, “Bí ẹ bá tẹ̀síwájú nínú ọ̀rọ̀ mi ẹ ó jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn mi nítòótọ́. 32 (D)Ẹ ó sì mọ òtítọ́, òtítọ́ yóò sì sọ yín di òmìnira.”
33 (E)Wọ́n dá a lóhùn pé, “Irú-ọmọ Abrahamu ni àwa jẹ́, àwa kò sì ṣe ẹrú fún ẹnikẹ́ni rí láé; ìwọ ha ṣe wí pé, ‘Ẹ ó di òmìnira’?”
34 (F)Jesu dá wọn lóhùn pé, “Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń dẹ́ṣẹ̀, ẹrú ẹ̀ṣẹ̀ ni. 35 (G)Ẹrú kì í sì í gbé ilé títí láé: ọmọ ní ń gbé ilé títí láé 36 Nítorí náà, bí Ọmọ bá sọ yín di òmìnira ẹ ó di òmìnira nítòótọ́. 37 Mo mọ̀ pé irú-ọmọ Abrahamu ni ẹ̀yin jẹ́; ṣùgbọ́n ẹ ń wá ọ̀nà láti pa mí nítorí ọ̀rọ̀ mi kò rí ààyè nínú yín. Jesu sọ ọ̀rọ̀-ìjìnlẹ̀ nípa ara rẹ̀. 38 Ohun tí èmi ti rí lọ́dọ̀ Baba ni mo sọ: ẹ̀yin pẹ̀lú sì ń ṣe èyí tí ẹ̀yin ti gbọ́ láti ọ̀dọ̀ baba yín.”
39 Wọ́n dáhùn, wọ́n sì wí fún un pé, “Abrahamu ni baba wa!”
Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ìbá ṣe iṣẹ́ Abrahamu 40 Ṣùgbọ́n nísinsin yìí ẹ̀yin ń wá ọ̀nà láti pa mí, ẹni tí ó sọ òtítọ́ fún yín, èyí tí mo ti gbọ́ lọ́dọ̀ Ọlọ́run: Abrahamu kò ṣe èyí. 41 (H)Ẹ̀yin ń ṣe iṣẹ́ baba yín.”
Nígbà náà ni wọ́n wí fún un pé, “a kò bí wa nípa panṣágà: a ní Baba kan, èyí sì ni Ọlọ́run.”
Àwọn ọmọ èṣù
42 (I)Jesu wí fún wọn pé, “Ìbá ṣe pé Ọlọ́run ni Baba yín, ẹ̀yin ìbá fẹ́ràn mi: nítorí tí èmi ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run jáde, mo sì wá; bẹ́ẹ̀ ni èmi kò sì wá fún ara mi, ṣùgbọ́n òun ni ó rán mi. 43 Èéṣe tí èdè mi kò fi yé yín? Nítorí ẹ kò lè gbọ́ ọ̀rọ̀ mi. 44 (J)Ti èṣù baba yin ni ẹ̀yin jẹ́, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ baba yín ni ẹ sì ń fẹ́ ṣe. Apànìyàn ni òun jẹ́ láti àtètèkọ́ṣe, kò sì dúró nínú òtítọ́; nítorí tí kò sí òtítọ́ nínú rẹ̀. Nígbà tí ó bá ń ṣèké, nínú ohun tirẹ̀ ni ó ń sọ nítorí èké ni, àti baba èké. 45 Ṣùgbọ́n nítorí tí èmi ń sọ òtítọ́ fún yín, ẹ̀yin kò sì gbà mí gbọ́. 46 Ta ni nínú yín tí ó ti dá mi lẹ́bi ẹ̀ṣẹ̀? Bí mo bá ń ṣọ òtítọ́, èéṣe tí ẹ̀yin kò fi gbà mí gbọ́? 47 Ẹni tí ń ṣe ti Ọlọ́run, a máa gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: nítorí èyí ni ẹ̀yin kò ṣe gbọ́, nítorí ẹ̀yin kì í ṣe ti Ọlọ́run.”
Jesu béèrè nípa ohun tí n ṣe ti ara rẹ̀
48 (K)Àwọn Júù dáhùn wọ́n sì wí fún un pé, “Àwa kò wí nítòótọ́ pé, ará Samaria ni ìwọ jẹ́, àti pé ìwọ ní ẹ̀mí èṣù?”
49 Jesu sì dáhùn pé, “Èmi kò ní ẹ̀mí èṣù, ṣùgbọ́n èmi ń bu ọlá fún Baba mi, ẹ̀yin kò sì bu ọlá fún mi. 50 Èmi kò wá ògo ara mi: Ẹnìkan ń bẹ tí ó ń wá a tí yóò sì ṣe ìdájọ́. 51 Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, bí ẹnìkan bá pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, kì yóò rí ikú láéláé.”
52 Àwọn Júù wí fún un pé, “Nígbà yìí ni àwa mọ̀ pé ìwọ ní ẹ̀mí èṣù. Abrahamu kú, àti àwọn wòlíì; ìwọ sì wí pé, ‘Bí ẹnìkan bá pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, kì yóò tọ́ ikú wò láéláé’ 53 (L)Ìwọ ha pọ̀ ju Abrahamu Baba wa lọ, ẹni tí ó kú? Àwọn wòlíì sì kú: ta ni ìwọ ń fi ara rẹ pè?”
54 Jesu dáhùn wí pé, “Bí mo bá yin ara mi lógo, ògo mi kò jẹ́ nǹkan; Baba mi ni ẹni tí ń yìn mí lógo, ẹni tí ẹ̀yin wí pé, Ọlọ́run yín ní i ṣe: 55 Ẹ kò sì mọ̀ ọ́n: ṣùgbọ́n èmi mọ̀ ọ́n: bí mo bá sì wí pé, èmi kò mọ̀ ọ́n, èmi yóò di èké gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin: ṣùgbọ́n èmi mọ̀ ọ́n, mo sì pa ọ̀rọ̀ rẹ̀ mọ́. 56 (M)Abrahamu baba yín yọ̀ láti rí ọjọ́ mi: ó sì rí i, ó sì yọ̀.”
57 (N)Nítorí náà, àwọn Júù wí fún un pé, “Ọdún rẹ kò ì tó àádọ́ta, ìwọ sì ti rí Abrahamu?”
58 (O)Jesu sì wí fún wọn pé, “Lóòótọ́ lóòótọ́ ni mo wí fún yín, kí Abrahamu tó wà, èmi ti wa.” 59 (P)Nítorí náà wọ́n gbé òkúta láti sọ lù ú: ṣùgbọ́n Jesu fi ara rẹ̀ pamọ́, ó sì jáde kúrò ní tẹmpili.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.