Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Old/New Testament

Each day includes a passage from both the Old Testament and New Testament.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
1 Kronika 4-6

Ìran Juda

Àwọn ọmọ Juda:

Peresi, Hesroni, Karmi, Huri àti Ṣobali.

Reaiah ọmọ Ṣobali ni baba Jahati, àti Jahati baba Ahumai àti Lahadi. Àwọn wọ̀nyí ni ẹ̀yà ará Sorati.

Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Etamu:

Jesreeli, Iṣima, Idbaṣi, orúkọ arábìnrin wọn sì ni Haseleponi Penueli sì ni baba Gedori, àti Eseri baba Huṣa.

Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ Huri, àkọ́bí Efrata àti baba Bẹtilẹhẹmu.

Aṣihuri baba Tekoa sì ní aya méjì, Hela àti Naara.

Naara sì bí Ahussamu, Heferi Temeni àti Haaṣtari. Àwọn wọ̀nyí sì ni àwọn ọmọ Naara.

Àwọn ọmọ Hela:

Sereti Sohari, Etani, Àti Kosi ẹni tí ó jẹ́ baba Anubu àti Sobeba àti ti àwọn ẹ̀yà Aharheli ọmọ Harumu.

Jabesi sì ní ọlá ju àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ọkùnrin lọ. Ìyá rẹ̀ sì sọ ọ́ ní Jabesi wí pé, “Mo bí i nínú ìpọ́njú.” 10 Jabesi sì kígbe sókè sí Ọlọ́run Israẹli wí pé, “Háà, Ìwọ yóò bùkún fún, ìwọ yóò sì mú agbègbè mi tóbi! Jẹ́ kí ọwọ́ rẹ kí ó wà pẹ̀lú mi kí o sì pa mi mọ́ kúrò nínú ibi; kí èmi kí ó le ní ìdáǹdè kúrò nínú ìrora.” Ọlọ́run sì gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ rẹ̀.

11 Kelubu arákùnrin Ṣuha, sì jẹ́ baba Mehiri, ẹni tí ó jẹ́ baba Eṣtoni. 12 Eṣtoni sì jẹ́ baba Beti-Rafa, Pasea àti Tehina ti baba ìlú Nahaṣi. Àwọn wọ̀nyí ni ọkùnrin Reka.

13 Àwọn ọmọ Kenasi:

Otnieli àti Seraiah.

Àwọn ọmọ Otnieli:

Hatati àti Meonotai. 14 Meonotai sì ni baba Ofira.

Seraiah sì jẹ́ baba Joabu,

baba Geharaṣinu. A pè báyìí nítorí àwọn ènìyàn àwọn oníṣọ̀nà ní ìwọ̀n.

15 Àwọn ọmọ Kalebu ọmọ Jefunne:

Iru, Ela, àti Naamu.

Àwọn ọmọ Ela:

Kenasi.

16 Àwọn ọmọ Jehaleeli:

Sifi, àti Sifa, Tiria àti Asareeli.

17 Àwọn ọmọ Esra:

Jeteri, Meredi, Eferi àti Jaloni.

Ọ̀kan lára àwọn aya Meredi sì bí Miriamu, Ṣammai àti Iṣba baba Eṣitemoa.

18 Aya rẹ̀ láti ẹ̀yà Juda sì bí Jaredi baba Gedori, àti Heberi baba Soko àti Jekutieli baba Sanoa. Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọ ọmọbìnrin Farao Bitia, ẹni ti Meredi ti fẹ́.

19 Àwọn ọmọ aya Hodiah arábìnrin Nahamu:

Baba Keila ará Garimu, àti Eṣitemoa àwọn ará Maakati.

20 Àwọn ọmọ Ṣimoni:

Amnoni, Rina, Beni-Hanani àti Tiloni.

Àwọn ọmọ Iṣi:

Soheti àti Beni-Soheti.

21 Àwọn ọmọ Ṣela ọmọ Juda:

Eri baba Leka, Lada baba Meraṣa àti àwọn ìdílé ilé àwọn tí ń hun aṣọ oníṣẹ́ ní Beti-Aṣibea.

22 Jokimu, ọkùnrin Koṣeba, àti Joaṣi àti Sarafi, olórí ní Moabu àti Jaṣubi Lehemu. (Àkọsílẹ̀ yìí sì wà láti ìgbà àtijọ́). 23 Àwọn sì ni amọ̀kòkò tí ń gbé ní Netaimu àti Gedera; wọ́n sì dúró níbẹ̀ wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ fún ọba.

Simeoni

24 (A)Àwọn Ọmọ Simeoni:

Nemueli, Jamini, Jaribi, Sera àti Saulu;

25 Ṣallumu sì jẹ́ ọmọ Saulu, Mibsamu ọmọ rẹ̀ Miṣima ọmọ rẹ̀.

26 Àwọn ọmọ Miṣima:

Hamueli ọmọ rẹ̀ Sakkuri ọmọ rẹ̀ àti Ṣimei ọmọ rẹ̀.

27 Ṣimei sì ní ọmọkùnrin mẹ́rìn-dínlógún àti ọmọbìnrin mẹ́fà, ṣùgbọ́n àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ọkùnrin kò ní ọmọ púpọ̀; Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ìdílé wọn kò sì pọ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn Juda. 28 (B)Wọ́n sì ń gbé ní Beerṣeba, Molada, Hasari-Ṣuali, 29 Àti ní Biliha, àti ní Esemu, àti ní Toladi, 30 Betueli, Horma, Siklagi, 31 Beti-Markaboti Hormah; Hasari Susimu, Beti-Biri àti Ṣaraimi. Àwọn wọ̀nyí ni ìlú wọn títí di ìgbà ọba Dafidi, 32 agbègbè ìlú wọn ni Etamu, Aini, Rimoni, Tokeni, Aṣani àwọn ìlú márùn-ún, 33 àti gbogbo ìletò wọn, tí ó wà yí ìlú náà ká, dé Baali. Àwọn wọ̀nyí ni ibùgbé wọn.

Àti ìtàn ìdílé wọ́n.

34 Meṣobabu àti Jamleki,

Josa ọmọ Amasiah, 35 Joeli,

Jehu ọmọ Josibiah, ọmọ Seraiah, ọmọ Asieli,

36 àti pẹ̀lú Elioenai, Jaakoba, Jeṣohaiah,

Asaiah, Adieli, Jesimieli, Benaiah,

37 àti Sisa ọmọ Ṣifi ọmọ Alloni, ọmọ Jedaiah, ọmọ Ṣimri ọmọ Ṣemaiah.

38 Àwọn ọkùnrin tí a dárúkọ lókè yìí àwọn ni ìjòyè ìdílé wọn.

Àwọn ìdílé sì pọ̀ sí i gidigidi, 39 Wọ́n sì lọ sí ojú ọ̀nà Gedori. Lọ títí dé ìlà-oòrùn àfonífojì láti wá koríko fún àwọn agbo ẹran wọn 40 Wọ́n sì rí koríko tútù tí ó dára ilẹ̀ náà gbòòrò ó sì ní àlàáfíà ó sì gbé jẹ́. Àwọn ọmọ Hamu ni ó ti ń gbé ibẹ̀ tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀.

41 Àwọn ọkùnrin tí a kọ orúkọ rẹ̀ sókè, dé ní ọjọ́ Hesekiah ọba Juda. Wọ́n sì kọlu àwọn ará Hamu ní àgọ́ wọn àti pẹ̀lú àwọn ará Mehuni tí a rí níbẹ̀ tí ó sì pa wọ́n run pátápátá títí di òní yìí. Wọ́n sì ń gbé ní ipò wọn, nítorí pé koríko ń bẹ níbẹ̀ fún agbo ẹran wọn. 42 Ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta nínú àwọn ará Simeoni, lábẹ́ ìdarí pẹ̀lú Pelatiah, Neariah, Refaiah àti Usieli, àwọn ọmọ Iṣi, gbógun sí àwọn òkè ìlú ti Seiri. 43 Wọ́n sì pa àwọn ará Amaleki tí ó kù, àwọn tí ó ti sálà, wọ́n sì ti ń gbé ibẹ̀ títí di òní yìí.

Rubeni

(C)Ǹjẹ́ àwọn ọmọ Reubeni, àkọ́bí Israẹli. (Nítorí òun ni àkọ́bí; ṣùgbọ́n, bí ó ti ṣe pé ó ba ibùsùn baba rẹ̀ jẹ́, a fi ogún ìbí rẹ̀ fún àwọn ọmọ Josẹfu ọmọ Israẹli: a kì yóò sì ka ìtàn ìdílé náà gẹ́gẹ́ bí ipò ìbí. Nítorí Juda borí àwọn arákùnrin rẹ̀, àti lọ́dọ̀ rẹ̀ ni aláṣẹ ti ń jáde wá; ṣùgbọ́n ogún ìbí jẹ́ ti Josẹfu), àwọn ọmọ Reubeni àkọ́bí Israẹli ni:

Hanoku àti Pallu, Hesroni àti Karmi.

Àwọn ọmọ Joeli:

Ṣemaiah ọmọ rẹ̀, Gogu ọmọ rẹ̀,

Ṣimei ọmọ rẹ̀. Mika ọmọ rẹ̀,

Reaiah ọmọ rẹ̀, Baali ọmọ rẹ̀.

Beera ọmọ rẹ̀, tí Tiglat-Pileseri ọba Asiria kó ní ìgbèkùn lọ. Ìjòyè àwọn ọmọ Reubeni ni Beera jẹ́.

Àti àwọn arákùnrin rẹ̀ nípa ìdílé wọn, nígbà tí a ń ka ìtàn ìdílé ìran wọn:

Jeieli àti Sekariah ni olórí, àti Bela ọmọ Asasi ọmọ Ṣema, ọmọ Joeli.

Wọ́n tí ń gbé Aroeri àní títí dé Nebo àti Baali-Meoni. Àti níhà àríwá, o tẹ̀dó lọ títí dé àtiwọ aginjù láti odò Eufurate; nítorí tí ẹran ọ̀sìn wọn pọ̀ sí i ní ilẹ̀ Gileadi.

10 Àti ní ọjọ́ Saulu, wọ́n bá àwọn ọmọ Hagari jagun, ẹni tí ó ṣubú nípa ọwọ́ wọn; wọ́n sì ń gbé inú àgọ́ wọn ní gbogbo ilẹ̀ àríwá Gileadi.

Ìdílé Gadi

11 Àti àwọn ọmọ Gadi ń gbé lékè wọn, ní ilẹ̀ Baṣani títí dé Saleka:

12 Joeli jẹ́ olórí, Ṣafamu ìran ọmọ, Janai, àti Ṣafati ni Baṣani,

13 Àti àwọn arákùnrin wọn ti ilẹ̀ àwọn baba wọn ní:

Mikaeli, Meṣullamu Ṣeba, Jorai, Jaka, Sia àti Eberi méje.

14 Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Abihaili, ọmọ Huri, ọmọ Jeroa, ọmọ Gileadi, ọmọ Mikaeli, ọmọ Jeṣiṣai, ọmọ Jado ọmọ Busi.

15 Ahi, ọmọ Adbeeli, ọmọ Guni, olórí ilé àwọn baba wọn.

16 Wọ́n sì ń gbé Gileadi ní Baṣani àti nínú àwọn ìlú rẹ̀, àti nínú gbogbo ìgbèríko Ṣaroni, ní agbègbè wọn.

17 Gbogbo wọ̀nyí ni a kà nípa ìtàn ìdílé, ní ọjọ́ Jotamu ọba Juda, àti ní ọjọ́ Jeroboamu ọba Israẹli.

18 Àwọn ọmọ Reubeni, àti àwọn ọmọ Gadi, àti ààbọ̀ ẹ̀yà Manase, nínú àwọn ọkùnrin alágbára tí wọ́n ń gbé asà àti idà, tí wọ́n sì ń fi ọrun tafà, tí wọ́n sì mòye ogun, jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì ènìyàn ó lé ẹgbẹ̀rìnlélógún dín ogójì, tí ó jáde lọ sí ogún náà. 19 Wọ́n sì bá àwọn ọmọ Hagari jagun, pẹ̀lú Jeturi, àti Nafiṣi àti Nadabu. 20 Nígbà tí wọ́n sì rí ìrànlọ́wọ́ gbà si, a sì fi àwọn ọmọ Hagari lé wọn lọ́wọ́, àti gbogbo àwọn tí ó wà pẹ̀lú wọn; nítorí tiwọn ké pe Ọlọ́run ní ogun náà, òun sì gbọ́ ẹ̀bẹ̀ wọn; nítorí tí wọ́n gbẹ́kẹ̀ wọn lé e. 21 Wọ́n sì kó ẹran ọ̀sìn wọn lọ; ìbákasẹ ẹgbàá-mẹ́dọ́gbọ̀n àti àgùntàn ọ̀kẹ́ méjìlá ó lé ẹgbàárùn-ún, àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ẹgbàá, àti ènìyàn ọ̀kẹ́ márùn-ún. 22 Nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ó ṣubú tí a pa, nítorí láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ogun náà, wọ́n sì jókòó ní ipò wọn títí di ìgbà ìkólọ sí ìgbèkùn.

Ààbọ̀ Ẹ̀yà Manase

23 Àwọn ọmọkùnrin ààbọ̀ ẹ̀yà Manase ń gbé ní ilẹ̀ náà: wọ́n bí sí i láti Baṣani títí dé Baali-Hermoni, àti Seniri àti títí dé òkè Hermoni.

24 Wọ̀nyí sì ni àwọn olórí ilé àwọn baba wọn. Eferi, Iṣi, Elieli, Asrieli, Jeremiah, Hodafiah àti Jahdieli àwọn alágbára akọni ọkùnrin, ọkùnrin olókìkí, àti olórí ilé àwọn baba wọn. 25 Wọ́n sì ṣẹ̀ sí Ọlọ́run àwọn baba wọn, wọ́n sì ṣe àgbèrè tọ àwọn ọlọ́run ènìyàn ilẹ̀ náà lẹ́yìn, tí Ọlọ́run ti parun ní iwájú wọn. 26 Nítorí náà Ọlọ́run Israẹli ru ẹ̀mí Pulu ọba Asiria sókè (ẹ̀mí Tiglat-Pileseri ọba Asiria), ó si kó wọn lọ, àní àwọn ọmọ Reubeni àti àwọn ọmọ Gadi, àti ààbọ̀ ẹ̀yà Manase lọ sí ìgbèkùn. Ó sì kó wọn wá sí Hala, àti Habori, àti Harani, àti sí etí odò Gosani; títí dí òní yìí.

Lefi

(D)Àwọn ọmọ Lefi:

Gerṣoni, Kohati àti Merari.

Àwọn ọmọ Kohati:

Amramu, Isari, Hebroni, àti Usieli.

Àwọn ọmọ Amramu:

Aaroni, Mose àti Miriamu.

Àwọn ọmọkùnrin Aaroni:

Nadabu, Abihu, Eleasari àti Itamari.

Eleasari jẹ́ baba Finehasi,

Finehasi baba Abiṣua

Abiṣua baba Bukki,

Bukki baba Ussi,

Ussi baba Serahiah,

Serahiah baba Meraioti,

Meraioti baba Amariah,

Amariah baba Ahitubu

Ahitubu baba Sadoku,

Sadoku baba Ahimasi,

Ahimasi baba Asariah,

Asariah baba Johanani,

10 Johanani baba Asariah.

(Òhun ni ó sìn gẹ́gẹ́ bí àlùfáà nínú ilé Olúwa tí Solomoni kọ́ sí Jerusalẹmu).

11 Asariah baba Amariah

Amariah baba Ahitubu

12 Ahitubu baba Sadoku.

Sadoku baba Ṣallumu,

13 Ṣallumu baba Hilkiah,

Hilkiah baba Asariah,

14 Asariah baba Seraiah,

pẹ̀lú Seraiah baba Josadaki

15 A kó Josadaki lẹ́rú nígbà tí Olúwa lé Juda àti Jerusalẹmu kúrò ní ìlú nípasẹ̀ Nebukadnessari.

16 Àwọn ọmọ Lefi:

Gerṣoni, Kohati àti Merari.

17 Wọ̀nyí ni àwọn orúkọ àwọn ọmọ Gerṣoni:

Libni àti Ṣimei.

18 Àwọn ọmọ Kohati:

Amramu, Isari, Hebroni àti Usieli.

19 Àwọn ọmọ Merari:

Mahili àti Muṣi.

Wọ̀nyí ni àwọn ìdílé ará Lefi tí a kọ ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé gẹ́gẹ́ bí baba wọn:

20 Ti Gerṣoni:

Libni ọmọkùnrin rẹ̀, Jahati

Ọmọkùnrin rẹ̀, Simma ọmọkùnrin rẹ̀, 21 Joah ọmọkùnrin rẹ̀,

Iddo ọmọkùnrin rẹ̀, Sera ọmọkùnrin rẹ̀

àti Jeaterai ọmọkùnrin rẹ̀.

22 Àwọn ìran ọmọ Kohati:

Amminadabu ọmọkùnrin rẹ̀, Kora ọmọkùnrin rẹ̀,

Asiri ọmọkùnrin rẹ̀. 23 Elkana ọmọkùnrin rẹ̀,

Ebiasafi ọmọkùnrin rẹ̀, Asiri ọmọkùnrin rẹ̀.

24 Tahati ọmọkùnrin rẹ̀, Urieli ọmọkùnrin rẹ̀,

Ussiah ọmọkùnrin rẹ̀ àti Saulu ọmọkùnrin rẹ̀.

25 Àwọn ìran ọmọ Elkana:

Amasai, Ahimoti

26 Elkana ọmọ rẹ̀, Sofai ọmọ rẹ̀

Nahati ọmọ rẹ̀, 27 Eliabu ọmọ rẹ̀,

Jerohamu ọmọ rẹ̀, Elkana ọmọ rẹ̀

àti Samuẹli ọmọ rẹ̀.

28 Àwọn ọmọ Samuẹli:

Joeli àkọ́bí

àti Abijah ọmọ ẹlẹ́ẹ̀kejì.

29 Àwọn ìran ọmọ Merari:

Mahili, Libni ọmọ rẹ̀.

Ṣimei ọmọ rẹ̀, Ussa ọmọ rẹ̀.

30 Ṣimea ọmọ rẹ̀, Haggiah ọmọ rẹ̀

àti Asaiah ọmọ rẹ̀.

Ilé ti a kọ́ fún àwọn Olórin

31 Èyí ní àwọn ọkùnrin Dafidi tí a fi sí ìdí orin nínú ilé Olúwa lẹ́yìn tí àpótí ẹ̀rí ti wá láti sinmi níbẹ̀. 32 Wọ́n jíṣẹ́ pẹ̀lú orin níwájú àgọ́ ìpàdé títí tí Solomoni fi kọ́ ilé Olúwa ní Jerusalẹmu. Wọ́n ṣe iṣẹ́ ìsìn wọn ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà tí a fi lélẹ̀ fún wọn.

33 Wọ̀nyí ni àwọn ọkùnrin tí ó sìn pẹ̀lú ọmọ wọn:

Láti ọ̀dọ̀ àwọn ará Kohati:

Hemani olùkọrin,

ọmọ Joeli, ọmọ Samuẹli,

34 Ọmọ Elkana ọmọ Jerohamu,

ọmọ Elieli, ọmọ Toha

35 Ọmọ Sufu, ọmọ Elkana,

ọmọ Mahati, ọmọ Amasai,

36 Ọmọ Elkana, ọmọ Joeli,

ọmọ Asariah, ọmọ Sefaniah

37 Ọmọ Tahati, ọmọ Asiri,

ọmọ Ebiasafi ọmọ Kora,

38 ọmọ Isari, ọmọ Kohati

ọmọ Lefi, ọmọ Israẹli;

39 Hemani sì darapọ̀ mọ́ Asafu, ẹni tí o sìn ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀:

Asafu ọmọ Bẹrẹkiah, ọmọ Ṣimea,

40 Ọmọ Mikaeli, ọmọ Baaseiah,

ọmọ Malkiah 41 Ọmọ Etini,

ọmọ Sera, ọmọ Adaiah,

42 Ọmọ Etani, ọmọ Simma,

ọmọ Ṣimei, 43 Ọmọ Jahati,

ọmọ Gerṣoni, ọmọ Lefi;

44 láti ìbákẹ́gbẹ́ wọn, àwọn ará Merari wà ní ọwọ́ òsì rẹ̀:

Etani ọmọ Kiṣi, ọmọ Abdi,

ọmọ Malluki, 45 Ọmọ Haṣabiah

ọmọ Amasiah, ọmọ Hilkiah,

46 Ọmọ Amisi ọmọ Bani,

ọmọ Ṣemeri, 47 Ọmọ Mahili,

ọmọ Muṣi, ọmọ Merari,

ọmọ Lefi.

48 Àwọn Lefi ẹgbẹ́ wọn ni wọn yan àwọn iṣẹ́ yòókù ti àgọ́ fún, èyí tí í ṣe ilé Ọlọ́run. 49 Ṣùgbọ́n Aaroni àti àwọn ìran ọmọ rẹ̀ jẹ́ àwọn tí ó gbé ọrẹ kalẹ̀ lórí pẹpẹ ẹbọ sísun àti lórí pẹpẹ tùràrí ní ìbátan pẹ̀lú gbogbo ohun tí a ṣe ní ibi mímọ́ jùlọ. Ṣíṣe ètùtù fún Israẹli, ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo ohun tí Mose ìránṣẹ́ Ọlọ́run ti pàṣẹ.

50 Wọ̀nyí ni àwọn ìránṣẹ́ Aaroni:

Eleasari ọmọ rẹ̀. Finehasi ọmọ rẹ̀,

Abiṣua ọmọ rẹ̀, 51 Bukki ọmọ rẹ̀,

Ussi ọmọ rẹ̀. Serahiah ọmọ rẹ̀,

52 Meraioti ọmọ rẹ̀, Amariah ọmọ rẹ̀,

Ahitubu ọmọ rẹ̀, 53 Sadoku ọmọ rẹ̀

àti Ahimasi ọmọ rẹ̀.

54 (E)Wọ̀nyí ni ibùgbé wọn tí a pín fún wọn gẹ́gẹ́ bí agbègbè wọn (tí a fi lé àwọn ìran ọmọ Aaroni lọ́wọ́ tí ó wá láti ẹ̀yà Kohati, nítorí kèké alákọ́kọ́ jẹ́ tiwọn):

55 A fún wọn ní Hebroni ní Juda pẹ̀lú àyíká pápá oko tútù ilẹ̀ rẹ̀. 56 Ṣùgbọ́n àwọn pápá àti ìletò tí ó yí ìlú ńlá náà ká ni a fi fún Kalebu ọmọ Jefunne. 57 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ìran ọmọ Aaroni ni a fún ní Hebroni (ìlú ti ààbò), àti Libina, Jattiri, Eṣitemoa, 58 Hileni, Debiri, 59 Aṣani, Jutta àti Beti-Ṣemeṣi lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ rẹ̀.

60 Àti láti inú ẹ̀yà Benjamini, a fún wọn ní Gibeoni, Geba, Alemeti àti Anatoti lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn.

Àwọn ìlú wọ̀nyí, tí a pín láàrín àwọn ẹ̀yà Kohati jẹ́ mẹ́tàlá ní gbogbo rẹ̀.

61 Ìyókù àwọn ìran ọmọ Kohati ní a pín ìlú mẹ́wàá fún láti àwọn ìdílé ní ti ààbọ̀ ẹ̀yà Manase.

62 Àwọn ìran ọmọ Gerṣoni, sí ìdílé ni a pín ìlú mẹ́tàlá fún láti ẹ̀yà àwọn ẹ̀yà Isakari, Aṣeri àti Naftali, àti láti apá ẹ̀yà Manase tí ó wà ní Baṣani.

63 Sebuluni Àwọn ìran ọmọ Merari, ìdílé sí ìdílé, ní a pín ìlú méjìlá fún láti ẹ̀yà Reubeni, Gadi àti Sebuluni.

64 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Israẹli fún àwọn ará Lefi ní ìlú wọ̀nyí pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn.

65 Láti ẹ̀yà Juda, Simeoni àti Benjamini ni a pín ìlú tí a ti dárúkọ wọn sẹ́yìn fún.

66 Lára àwọn ìdílé Kohati ni a fún ní ìlú láti ẹ̀yà Efraimu gẹ́gẹ́ bí ìlú agbègbè wọn.

67 Ní òkè orílẹ̀-èdè Efraimu, a fún wọn ní Ṣekemu (Ìlú ńlá ti ààbò), àti Geseri 68 Jokimeamu, Beti-Horoni. 69 Aijaloni àti Gati-Rimoni lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn.

70 Pẹ̀lú láti apá ààbọ̀ ẹ̀yà Manase àwọn ọmọ Israẹli fún Aneri àti Bileamu lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn, fún ìyókù àwọn ìdílé Kohati.

71 Àwọn ará Gerṣoni gbà nǹkan wọ̀nyí:

Láti ààbọ̀ ẹ̀yà ti Manase wọ́n gba Golani ní Baṣani àti pẹ̀lú Aṣtarotu, lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù wọn;

72 Láti ẹ̀yà Isakari wọ́n gba Kedeṣi, Daberati 73 Ramoti àti Anenu, lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn;

74 Láti ẹ̀yà Aṣeri wọ́n gba Maṣali, Abdoni, 75 Hukoki àti Rehobu lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn;

76 Pẹ̀lú láti ẹ̀yà Naftali wọ́n gba Kedeṣi ní Galili, Hammoni àti Kiriataimu, lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn.

77 Àwọn ará Merari (ìyókù àwọn ará Lefi) gbà nǹkan wọ̀nyí:

Láti ẹ̀yà Sebuluni wọ́n gba Jokneamu, Karta, Rimoni àti Tabori, lápapọ̀ pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko tútù wọn;

78 Láti ẹ̀yà Reubeni rékọjá Jordani ìlà-oòrùn Jeriko wọ́n gba Beseri nínú aginjù Jahisa, 79 Kedemoti àti Mefaati, lápapọ̀ pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko tútù wọn;

80 Pẹ̀lú láti ẹ̀yà Gadi wọ́n gba Ramoti ní Gileadi Mahanaimu, 81 Heṣboni àti Jaseri lápapọ̀ pẹ̀lú àwọn ilẹ̀ pápá oko tútù wọn.

Johanu 6:1-21

Jesu bọ́ ẹgbẹ̀rún márùn-ún

(A)Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, Jesu kọjá sí apá kejì Òkun Galili, tí í ṣe Òkun Tiberia. Ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, nítorí tí wọ́n rí iṣẹ́ ààmì rẹ̀ tí ó ń ṣe lára àwọn aláìsàn. Jesu sì gun orí òkè lọ, níbẹ̀ ni ó sì gbé jókòó pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. Àjọ ìrékọjá ọdún àwọn Júù sì súnmọ́ etílé.

(B)Ǹjẹ́ bí Jesu ti gbé ojú rẹ̀ sókè, tí ó sì rí ọ̀pọ̀ ènìyàn wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó wí fún Filipi pé, “Níbo ni a ó ti ra àkàrà, kí àwọn wọ̀nyí lè jẹ?” Ó sì sọ èyí láti dán an wò; nítorí tí òun fúnrarẹ̀ mọ ohun tí òun ó ṣe.

Filipi dá a lóhùn pé, “Àkàrà igba owó idẹ kò lè tó fún wọn, bí olúkúlùkù wọn kò tilẹ̀ ní í rí ju díẹ̀ bù jẹ.”

(C)Ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, Anderu, arákùnrin Simoni Peteru wí fún un pé, (D)“Ọmọdékùnrin kan ń bẹ níhìn-ín yìí, tí ó ní ìṣù àkàrà barle márùn-ún àti ẹja wẹ́wẹ́ méjì: ṣùgbọ́n kín ni ìwọ̀nyí jẹ́ láàrín ọ̀pọ̀ ènìyàn wọ̀nyí?”

10 Jesu sì wí pé, “Ẹ mú kí àwọn ènìyàn náà jókòó!” Koríko púpọ̀ sì wá níbẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọkùnrin náà jókòó; ìwọ̀n ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ènìyàn ní iye. 11 Jesu sì mú ìṣù àkàrà náà. Nígbà tí ó sì ti dúpẹ́, ó pín wọn fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì pín wọn fún àwọn tí ó jókòó; bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ sì ni ẹja ní ìwọ̀n bí wọ́n ti ń fẹ́.

12 Nígbà tí wọ́n sì yó, ó wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ẹ kó àjẹkù tí ó kù jọ, kí ohunkóhun má ṣe ṣòfò.” 13 Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n kó wọn jọ wọ́n sì fi àjẹkù ìṣù àkàrà barle márùn-ún náà kún agbọ̀n méjìlá, èyí tí àwọn tí ó jẹun jẹ kù.

14 (E)Nítorí náà nígbà tí àwọn ọkùnrin náà rí iṣẹ́ ààmì tí Jesu ṣe, wọ́n wí pé, “Lóòótọ́ èyí ni wòlíì náà tí ń bọ̀ wá sí ayé.” 15 (F)Nígbà tí Jesu sì wòye pé wọ́n ń fẹ́ wá fi agbára mú òun láti lọ fi jẹ ọba, ó tún padà lọ sórí òkè, òun nìkan.

Jesu rin lórí omi

16 (G)Nígbà tí alẹ́ sì lẹ́, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ lọ sí Òkun. 17 Wọ́n sì bọ́ sínú ọkọ̀ ojú omi, wọ́n sì rékọjá Òkun lọ sí Kapernaumu. Ilẹ̀ sì ti ṣú, Jesu kò sì tí ì dé ọ̀dọ̀ wọn. 18 Òkun sì ń ru nítorí ẹ̀fúùfù líle tí ń fẹ́. 19 Nígbà tí wọ́n wa ọkọ̀ ojú omi tó bí ìwọ̀n ibùsọ̀ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n tàbí ọgbọ̀n, wọ́n rí Jesu ń rìn lórí Òkun, ó sì súnmọ́ ọkọ̀ ojú omi náà; ẹ̀rù sì bà wọ́n. 20 Ṣùgbọ́n ó wí fún wọn pé, “Èmi ni; ẹ má bẹ̀rù.” 21 Nítorí náà wọ́n fi ayọ̀ gbà á sínú ọkọ̀; lójúkan náà ọkọ̀ náà sì dé ilẹ̀ ibi tí wọ́n ń lọ.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.