Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Old/New Testament

Each day includes a passage from both the Old Testament and New Testament.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
2 Ọba 17-18

Hosea ọba tí ó gbẹ̀yìn ní Israẹli

17 Ní ọdún kejìlá ọba Ahasi ará Juda, Hosea ọmọ Ela jẹ ọba Israẹli ní Samaria, ó sì jẹ fún ọdún mẹsàn án. Ó sì ṣe búburú ní ojú Olúwa, ṣùgbọ́n kì í ṣe bí i ti ọba Israẹli ẹni tí ó ti wà ṣáájú rẹ̀.

Ṣalamaneseri ọba Asiria wá sókè láti mú Hosea, ẹni tí ó ti jẹ fún Ṣalamaneseri ó sì ti san owó òde fún un. Ṣùgbọ́n ọba Asiria rí i wí pé Hosea jẹ́ ọlọ́tẹ̀, nítorí ó ti rán oníṣẹ́ sọ́dọ̀ ọba Ejibiti, kò sì san owó òde mọ́ fún ọba Asiria, gẹ́gẹ́ bí o ti máa ń ṣe ní ọdọọdún. Nígbà náà ọba Asiria fi agbára mú-ún, ó sì fi sínú túbú. Ọba Asiria gòkè wá sí gbogbo ibi ilé náà, ó sì lọ sí Samaria, ó sì dúró tí ì fún ọdún mẹ́ta. Ní ọdún kẹsànán ti Hosea, ọba Asiria mú Samaria ó sì kó Israẹli lọ sí Asiria. Ó sì fi wọ́n sílẹ̀ ní Hala, ní Gosani ní etí odò Habori àti ní ìlú àwọn ará Media.

Israẹli sá kúrò ní ìlú nítorí ẹ̀ṣẹ̀

Gbogbo eléyìí ṣẹlẹ̀ nítorí àwọn ọmọ Israẹli ti dẹ́ṣẹ̀ sí Olúwa Ọlọ́run wọn, ẹni tí ó mú wọn jáde ní Ejibiti lábẹ́ agbára Farao ọba Ejibiti. Wọ́n sin ọlọ́run mìíràn Wọn si tẹ̀lé ìwà orílẹ̀-èdè tí Olúwa ti gbá kúrò níwájú wọn gẹ́gẹ́ bí ìwà ti ọba Israẹli tí ó ti paláṣẹ Àwọn ọmọ Israẹli ṣe ohun ìríra sí Olúwa Ọlọ́run wọn kọ́ láti ilé ìṣọ́ sí ìlú tí a dáàbò bò, wọ́n kọ́ ilé gíga fún ara wọn ní gbogbo ìlú wọn. 10 Wọ́n sì gbé àwọn òkúta tí a yà sọ́tọ̀ sókè àti ère òrìṣà Aṣerah lórí gbogbo igi tútù 11 Ní gbogbo ibi gíga, wọ́n sun tùràrí gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀-èdè tí Olúwa ti lé jáde níwájú wọn. Wọ́n ṣe ohun búburú tí ó rú ìbínú Olúwa sókè. 12 Wọ́n sìn òrìṣà, èyí tí Olúwa ti sọ pé, “Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe èyí.” 13 Olúwa kìlọ̀ fún Israẹli àti Juda nípa gbogbo àwọn wòlíì wọn àti aríran: “Ẹ yípadà kúrò ní ọ̀nà búburú yín. Kí ẹ ṣe òfin mi àti ìlànà mi, ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo òfin tí Èmi paláṣẹ fún àwọn baba yín láti tẹ̀lé àti èyí tí mo rán sí i yín nípa ìránṣẹ́ àwọn wòlíì mi.”

14 Ṣùgbọ́n wọn kò ní gbọ́, wọ́n sì ṣe gẹ́gẹ́ bí ọlọ́rùn líle gẹ́gẹ́ bí i ti baba wọn, ẹni tí kò gbà Olúwa Ọlọ́run wọn gbọ́. 15 Wọ́n kọ̀ ìlànà rẹ̀ àti májẹ̀mú tí ó ti ṣe pẹ̀lú baba wọn àti ìkìlọ̀ tí ó ti fi fún wọn. Wọ́n tẹ̀lé òrìṣà aláìníláárí, àwọn fún rara wọn sì jẹ́ aláìníláárí. Wọ́n tẹ̀lé orílẹ̀-èdè tí ó yí wọn ká bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Olúwa ti kìlọ̀ fún wọn pé, “Má ṣe ṣe gẹ́gẹ́ bí wọn tí ń ṣe,” wọ́n sì ṣe ohun tí Olúwa ti kà léèwọ̀ fún wọn láti ṣe.

16 Wọ́n kọ̀ gbogbo òfin Olúwa Ọlọ́run wọn sílẹ̀, wọ́n sì ṣe òrìṣà méjì fún ara wọn, wọ́n sì gbẹ́ ẹ ọ̀kan ní ère ẹgbọrọ màlúù, àti ọ̀kan ní ère òrìṣà Aṣerah. Wọ́n sì tẹrí wọn ba sí gbogbo ogun ọ̀run, wọ́n sì sin Baali. 17 Wọ́n sì fi àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin wọn rú ẹbọ nínú iná. Wọ́n sì ń fọ àfọ̀ṣẹ, wọ́n sì ń ṣe àlúpàyídà wọ́n sì ta ara wọn láti ṣe ohun búburú níwájú Olúwa, wọ́n sì mú un bínú.

18 Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa sì bínú gidigidi pẹ̀lú Israẹli ó sì mú wọn kúrò níwájú rẹ̀. Ẹ̀yà Juda nìkan ṣoṣo ni ó kù, 19 Àti pẹ̀lú, Juda kò pa òfin Olúwa Ọlọ́run wọn mọ́. Wọ́n tẹ̀lé ìhùwàsí àwọn Israẹli tí wọ́n ṣe. 20 Nítorí náà Olúwa kọ gbogbo àwọn ènìyàn Israẹli; ó sì jẹ wọ́n ní yà. Ó sì fi wọ́n lé ọwọ́ àwọn olè títí tí ó fi ta wọ́n nù kúrò níwájú rẹ̀.

21 Nígbà tí ó ta Israẹli kúrò láti ìdílé Dafidi, wọ́n sì mú Jeroboamu ọmọ Nebati jẹ ọba wọn. Jeroboamu sì mú kí àwọn ọmọ Israẹli yípadà kúrò ní títẹ̀lé Olúwa, ó sí mú kí wọn dẹ́ṣẹ̀ ńlá. 22 Àwọn ọmọ Israẹli forítì í nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ Jeroboamu kò sì yí padà kúrò lọ́dọ̀ wọn 23 Títí tí Olúwa fi mú wọn kúrò níwájú rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ó ti paláṣẹ láti ọ̀dọ̀ àwọn ìránṣẹ́ wòlíì. Bẹ́ẹ̀ ni a kó gbogbo ènìyàn Israẹli kúrò ní ilẹ̀ wọn lọ sí ìgbèkùn ni Asiria, títí di òní yìí.

Samaria tún fìdímúlẹ̀

24 Ọba Asiria mú àwọn ènìyàn láti Babeli, Kuta, Afa, Hamati àti Sefarfaimi, wọ́n sì fi wọ́n sínú ìlú Samaria láti rọ́pò àwọn ọmọ Israẹli. Wọ́n sì ń gbé ní ìlú náà. 25 Nígbà tí wọ́n gbé bẹ̀ ní àkọ́kọ́, wọn kò sì bẹ̀rù Olúwa, Bẹ́ẹ̀ ni ó rán kìnnìún sí àárín wọn. Wọ́n sì pa nínú wọn. 26 Wọ́n sì sọ fún ọba Asiria pé: “Àwọn ènìyàn tí ìwọ lé kúrò tí o sì fi sínú ìlú Samaria kò mọ ohun tí ọlọ́run ìlú náà béèrè. Ó sì ti rán kìnnìún sí àárín wọn, tí ó sì ń pa wọ́n run, nítorí ènìyàn wọn kò mọ ohun tí ó béèrè.”

27 Nígbà náà ọba Asiria pàṣẹ yìí wí pé, “Mú ọ̀kan lára àwọn àlùfáà tí ó mú láti Samaria lọ padà gbé níbẹ̀ kí ó sì kọ́ àwọn ènìyàn ní, ohun tí ọlọ́run ilẹ̀ náà béèrè.” 28 Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀kan lára àwọn àlùfáà tí ó ti kúrò ní Samaria wá gbé ní Beteli ó sì kọ́ wọn bí a ti ń sin Olúwa.

29 Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, olúkúlùkù orílẹ̀-èdè ṣe òrìṣà tirẹ̀ ní gbogbo ìlú níbi tí wọ́n gbé wà, wọ́n sì gbé wọn nínú ilé òrìṣà àti àwọn ènìyàn Samaria ó sì ṣe wọ́n sí ibi gíga wọ̀n-ọn-nì. 30 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọkùnrin láti Babeli ṣe àgọ́ àwọn wúńdíá, àwọn ènìyàn Kuti ṣe òrìṣà Nergali, àti àwọn ènìyàn Hamati ṣe ti Aṣima; 31 Àti àwọn ará Afa ṣe Nibhasi àti Tartaki, àti àwọn ará Sefarfaimi sun àwọn ọmọ wọn níná gẹ́gẹ́ bí ẹbọ sí Adrameleki àti Anameleki, àwọn òrìṣà Sefarfaimi. 32 Wọ́n sin Olúwa, ṣùgbọ́n wọ́n sì tún yan gbogbo ẹgbẹ́ tí ènìyàn wọn láti ṣe iṣẹ́ oyè fún wọn gẹ́gẹ́ bí àlùfáà ní ibi gíga. 33 Wọ́n sin Olúwa ṣùgbọ́n wọ́n sin òrìṣà wọn ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú àṣà orílẹ̀-èdè wọn láti ibi tí wọ́n ti gbé wọn wá.

34 Láti ìgbà náà wá àwọn àlùfáà wọn ṣe bí ti àtẹ̀yìnwá. Wọn kò sin Olúwa tàbí kí wọ́n fi ara mọ́ ìlànà àti àṣẹ àti òfin tí Olúwa fi fún ìránṣẹ́ Jakọbu, tí wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní Israẹli. 35 Nígbà tí Olúwa ṣe májẹ̀mú pẹ̀lú àwọn ọmọ Israẹli ó pàṣẹ fún wọn pé: “Ẹ má ṣe sin òrìṣà mìíràn tàbí tẹríba fún wọn, sìn wọ́n tàbí kí ẹ rú ẹbọ sí wọn. 36 Ṣùgbọ́n Olúwa, ẹni tí ó mú yín gòkè jáde wá láti ilẹ̀ Ejibiti pẹ̀lú agbára ńlá àti nínà apá, òun ni ẹni náà tí ó yẹ kí ẹ sìn. Òun ni ẹni tí ó yẹ kí ẹ tẹríba fún àti sí òun ni kí ẹ rú ẹbọ fún. 37 Ó yẹ kí ẹ̀yin kí ó máa kíyèsi ara yín gidigidi láti pa ìlànà àti àṣẹ, àti òfin tí ó kọ fún un yín mọ́. Ẹ má ṣe sin ọlọ́run mìíràn. 38 Ẹ má ṣe gbàgbé májẹ̀mú tí mo ti ṣe pẹ̀lú yín mọ́ àti kí ẹ má sin ọlọ́run mìíràn. 39 Kúkú sin Olúwa Ọlọ́run rẹ; Òun ni ẹni náà tí yóò gbà yín kúrò lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá a yín.”

40 Wọn kò ní gbọ́, bẹ́ẹ̀ ni, wọ́n sì ń ṣe iṣẹ́ wọ́n ti àtijọ́. 41 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ènìyàn wọn sin Olúwa, wọ́n sì ń sin òrìṣà wọn. Títí di ọjọ́ òní ọmọ wọn àti àwọn ọmọ ọmọ wọn sì ń ṣe bí àwọn baba wọn ti ń ṣe.

Hesekiah ọba Juda

18 (A)Ní ọdún kẹta Hosea ọmọ Ela ọba Israẹli, Hesekiah ọmọ Ahasi ọba Juda bẹ̀rẹ̀ ìjọba. Ó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n nígbà tí ó ti di ọba, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mọ́kàn-dínlọ́gbọ̀n. Orúkọ ìyá rẹ̀ a sì máa jẹ́ Abi ọmọbìnrin Sekariah. Ó sì ṣe ohun tí ó dára níwájú Olúwa, gẹ́gẹ́ bí i baba rẹ̀ Dafidi ti ṣe. Ó mú ibi gíga náà kúrò, ó sì fọ́ àwọn ère òkúta, ó sì gé àwọn ère Aṣerah lulẹ̀, ó sì fọ́ ejò idẹ tí Mose ti ṣe náà túútúú, títí di ọjọ́ tí àwọn ọmọ Israẹli ń sun tùràrí sí. (Wọ́n sì pè é ní Nehuṣitani.)

Hesekiah sì gbẹ́kẹ̀lé Olúwa Ọlọ́run Israẹli. Kò sì ṣí ẹnìkan tí ó dàbí tirẹ̀ lára gbogbo àwọn ọba Juda, bóyá kí ó tó jẹ tàbí lẹ́yìn rẹ̀. Ó súnmọ́ Olúwa, kò sì dẹ́kun láti tì í lẹ́yìn: ó sì pa òfin Olúwa mọ́ tí ó ti fi fún Mose. Olúwa sì wà pẹ̀lú rẹ̀; ó sì ń ṣe rere nínú gbogbo ohun tí ó dáwọ́lé. Ó ṣe ọ̀tẹ̀ sí ọba Asiria kò sì sìn ín. Láti ilé ìṣọ́ títí dé ìlú olódi, ó sì pa àwọn ará Filistini run, àti títí dé Gasa àti agbègbè rẹ̀.

Ní ọdún kẹrin ọba Hesekiah, nígbà tí ó jẹ́ ọdún keje Hosea ọmọ Ela ọba Israẹli. Ṣalamaneseri ọba Asiria yàn lára Samaria ó sì tẹ̀dó tì í. 10 Lẹ́yìn ọdún mẹ́ta Asiria gbé e. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n kó Samaria ní ọdún kẹfà Hesekiah tí ó sì jẹ́ ọdún kẹsànán Hosea ọba Israẹli. 11 Ọba Asiria lé Israẹli kúrò ní Asiria, wọ́n sì ṣe àtìpó wọn ní Hala, ní Gosani létí odò Habori àti ní ìlú àwọn ará Media. 12 Èyí ṣẹlẹ̀ nítorí wọn kò pa àṣẹ Olúwa Ọlọ́run wọn mọ́. Ṣùgbọ́n wọ́n ti dà májẹ̀mú rẹ̀ gbogbo èyí tí Mose ìránṣẹ́ Olúwa ti pàṣẹ. Wọn kò fi etí wọn sílẹ̀ sí òfin wọn kò sì gbé wọn jáde.

13 Ní ọdún kẹrìnlá tí Hesekiah jẹ ọba, Sennakeribu ọba Asiria kọlu gbogbo ìlú olódi ti Juda ó sì pa wọ́n run. 14 Bẹ́ẹ̀ ni Hesekiah ọba Juda sì ránṣẹ́ yìí sí ọba Asiria ní Lakiṣi, wí pé, “Mo ti ṣẹ̀, padà lẹ́yìn mi: èmi yóò sì san ohunkóhun tí ìwọ bá béèrè lọ́wọ́ mi.” Ọba Asiria sì bu fún Hesekiah ọba Juda ọ̀ọ́dúnrún tálẹ́ǹtì fàdákà àti ọgbọ̀n tálẹ́ǹtì wúrà. 15 Hesekiah fún un ní gbogbo fàdákà tí a rí nínú ilé Olúwa àti nínú ìṣúra ilé ọba.

16 Ní àkókò yìí Hesekiah ọba Juda ké wúrà tí ó wà ní ẹnu ìlẹ̀kùn ilé Olúwa, kúrò àti ti òpó tí Hesekiah ọba Juda ti gbéró ó sì fi fún ọba Asiria.

Sennakeribu halẹ̀ mọ́ Jerusalẹmu

17 Ọba Asiria rán alákòóso gíga jùlọ, ìjòyè pàtàkì àti àwọn adarí pápá pẹ̀lú àwọn ọmọ-ogun tí ó pọ̀, láti Lakiṣi sí ọba Hesekiah ní Jerusalẹmu. Wọ́n wá sí òkè Jerusalẹmu wọ́n sì dúró ní etí ìdarí omi àbàtà òkè, ní ojú ọ̀nà tó lọ sí òpópó pápá Alágbàfọ̀. 18 Wọ́n sì pe ọba; àti Eliakimu ọmọ Hilkiah ẹni tí í ṣe ilé olùtọ́jú, Ṣebna akọ̀wé, àti Joah ọmọkùnrin Asafu tí ó jẹ́ akọ̀wé ìrántí jáde pẹ̀lú wọn.

19 Olùdarí pápá wí fún wọn pé, “Sọ fún Hesekiah pé:

“ ‘Èyí ni ohun tí ọba ńlá, ọba Asiria sọ: kí ni ìgbẹ́kẹ̀lé yìí tí ìwọ gbẹ́kẹ̀lé? 20 Ìwọ wí pé ìwọ ni ìmọ̀ àti agbára láti jagun—ṣùgbọ́n ìwọ sọ̀rọ̀ òfìfo lásán. Ǹjẹ́ ta ni ìwọ gbẹ́kẹ̀ rẹ lé, tí ìwọ fi ń ṣe ọ̀tẹ̀ sí mi? 21 Wò ó, nísinsin yìí, ìwọ gbẹ́kẹ̀ rẹ lé Ejibiti, ẹ̀rún ọ̀pá pẹlẹbẹ ìyè fífọ́ yìí, èyí tí yóò wọ inú ọwọ́ ẹni tí ó sì bá fi ara tì í. Bẹ́ẹ̀ ni Farao ọba Ejibiti ṣe rí fún gbogbo àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀ wọn lé e. 22 Tí ìwọ bá sì sọ fún mi pé, “Àwa gbẹ́kẹ̀ wa lé Olúwa Ọlọ́run.” Òun ha kọ́ ní ẹnìkan náà tí ibi gíga àti àwọn pẹpẹ tí Hesekiah mú kúrò, tí ó wí fún Juda àti Jerusalẹmu pé, “O gbọdọ̀ sìn níwájú pẹpẹ yìí ní Jerusalẹmu”?

23 “ ‘Wá nísinsin yìí, ṣe àdéhùn pẹ̀lú ọ̀gá mi, ọba Asiria: Èmi yóò sì fún ọ ní ẹgbàá ẹṣin (2,000) tí ìwọ bá lè kó àwọn tí yóò gùn ún sí orí rẹ! 24 Báwo ni ìwọ yóò ha ti ṣe le yí ojú balógun kan tí ó kéré jùlọ padà nínú àwọn ìránṣẹ́ olúwa mi, tí ìwọ sì gbẹ́kẹ̀ rẹ lé Ejibiti fún àwọn kẹ̀kẹ́ àti ẹlẹ́ṣin? 25 Síwájú sí i, èmi ti wá láti mú àti láti parun ibí yìí láìsí ọ̀rọ̀ láti ọ̀dọ̀ Olúwa? Olúwa fún rara rẹ̀ sọ fún mi pé kí n yára láti yan lórí ìlú yìí, kí n sì pa á run.’ ”

26 Nígbà náà Eliakimu ọmọ Hilkiah, àti Ṣebna àti Joah sọ fún olùdarí pápá pé, “Jọ̀wọ́ sọ̀rọ̀ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ ní èdè Aramaiki, nítorí ti ó tí yé wa, má ṣe sọ̀rọ̀ fún wa pẹ̀lú èdè Heberu ní etí ìgbọ́ àwọn ènìyàn tí ń bẹ lórí odi.”

27 Ṣùgbọ́n aláṣẹ dáhùn pé, “Ṣé fún ọ̀gá rẹ àti ìwọ nìkan ní ọ̀gá mi rán mi sí láti sọ àwọn nǹkan wọ̀nyí kì í sì í ṣe fún àwọn ọkùnrin tí ó jókòó lórí odo-ta ni gẹ́gẹ́ bí ìwọ, ni yóò ní láti jẹ ìgbẹ́ ará wọn kí wọ́n sì mu ìtọ̀ ará wọn?”

28 Nígbà náà, aláṣẹ dìde, ó sì pè jáde ní èdè Heberu pé, “Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ ọba ńlá, ọba Asiria! 29 Èyí ni ohun tí ọba sọ: má ṣe jẹ́ kí Hesekiah tàn ọ́ jẹ kò le gbà ọ́ kúrò ní ọwọ́ mi 30 Ẹ má ṣe jẹ́ kí Hesekiah mú yín gbẹ́kẹ̀lé Olúwa nípa sísọ pé, ‘Olúwa yóò gbà wá nítòótọ́; ìlú yìí ni wọn kò ní fi lé ọba ìlú Asiria lọ́wọ́.’

31 “Má ṣe tẹ́tí sí Hesekiah. Èyí ni ohun tí ọba Asiria wí pé: ‘Fi ẹ̀bùn wá ojúrere mi, kí o sì jáde tọ̀ mí wá.’ Nígbà náà olúkúlùkù yín yóò jẹun láti inú àjàrà rẹ̀ àti igi ọ̀pọ̀tọ́, yóò sì mu omi láti inú àmù rẹ̀, 32 Títí tí èmi yóò fi wá mú ọ lọ sí ilé gẹ́gẹ́ bí i tìrẹ, ilẹ̀ ọkà àti ọtí wáìnì, ilẹ̀ oúnjẹ àti ọgbà àjàrà, ilẹ̀ òróró olifi àti ti ilẹ̀ oyin; yàn ìyè má sì ṣe yàn ikú!

“Kí ẹ má ṣe gbọ́ tí Hesekiah, nítorí ó ń tàn yín tí ó ba tí wí pé, ‘Olúwa yóò gbà wá?’ 33 Ṣé òrìṣà àwọn orílẹ̀-èdè kankan ti gba ilé rẹ lọ́wọ́ àwọn ọba Asiria? 34 Níbo ni àwọn òrìṣà Hamati àti Arpadi gbé wà? Níbo ni àwọn òrìṣà Sefarfaimi, Hena àti Iffa gbé wà? Wọ́n ha gba Samaria kúrò lọ́wọ́ mi bí? 35 Ta ni nínú gbogbo àwọn òrìṣà ilẹ̀ yìí tí ó ti gbìyànjú láti gba ilẹ̀ rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ mi? Báwo ni Olúwa yóò ṣe gba Jerusalẹmu kúrò lọ́wọ́ mi?”

36 Ṣùgbọ́n gbogbo àwọn ènìyàn náà dákẹ́ síbẹ̀ wọn kò sì sọ ohunkóhun, láti fi fèsì, nítorí ọba ti paláṣẹ, “Ẹ má ṣe dá a lóhùn.”

37 Nígbà náà Eliakimu ọmọ Hilkiah olùtọ́jú ààfin, Ṣebna akọ̀wé àti Joah ọmọ Asafu akọ̀wé ránṣẹ́ lọ sí ọ̀dọ̀ Hesekiah, pẹ̀lú aṣọ wọn yíya, ó sì wí fún un ohun tí olùdarí pápá ti sọ.

Johanu 3:19-36

19 (A)Èyí ni ìdájọ́ náà pé, ìmọ́lẹ̀ wá sí ayé, àwọn ènìyàn sì fẹ́ òkùnkùn ju ìmọ́lẹ̀ lọ, nítorí tí iṣẹ́ wọn burú. 20 Nítorí olúkúlùkù ẹni tí ó bá hùwà búburú ní ìkórìíra ìmọ́lẹ̀, kì í sì í wá sí ìmọ́lẹ̀, kí a má ṣe bá iṣẹ́ rẹ̀ wí. 21 (B)Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń sọ òtítọ́ ní í wá sí ìmọ́lẹ̀, kí iṣẹ́ rẹ̀ kí ó lè fi ara hàn pé a ṣe wọ́n nípa ti Ọlọ́run.”

Ẹ̀rí Johanu nípa Jesu

22 (C)Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, Jesu pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wá sí ilẹ̀ Judea; ó sì dúró pẹ̀lú wọn níbẹ̀ ó sì ń ṣe ìtẹ̀bọmi fún ni. 23 Johanu pẹ̀lú sì ń ṣe ìtẹ̀bọmi ní Aenoni, ní agbègbè Salimu, nítorí tí omi púpọ̀ wà níbẹ̀: wọ́n sì ń wá, a sì ń tẹ̀ ẹ́ wọn bọ omi. 24 (D)Nítorí tí a kò tí ì sọ Johanu sínú túbú. 25 Nígbà náà ni iyàn kan wà láàrín àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu àti Júù kan nípa ti ìwẹ̀nù. 26 (E)Wọ́n sì tọ Johanu wá, wọ́n sì wí fún un pé, “Rabbi, ẹni tí ó ti wà pẹ̀lú rẹ lókè odò Jordani, tí ìwọ ti jẹ́rìí rẹ̀, wò ó, òun tẹ àwọn ènìyàn bọ omi, gbogbo ènìyàn sì ń tọ̀ ọ́ wá.”

27 (F)Johanu dáhùn ó sì wí pé, “Ènìyàn kò le rí nǹkan kan gbà, bí kò ṣe pé a bá ti fi fún ún láti ọ̀run wá. 28 (G)Ẹ̀yin fúnrayín jẹ́rìí mi pé mo wí pé, ‘Èmi kì í ṣe Kristi náà, ṣùgbọ́n pé a rán mi síwájú rẹ̀.’ 29 (H)Ẹni tí ó bá ni ìyàwó ni ọkọ ìyàwó; ṣùgbọ́n ọ̀rẹ́ ọkọ ìyàwó tí ó dúró tí ó sì ń gbóhùn rẹ̀, ó ń yọ̀ gidigidi nítorí ohùn ọkọ ìyàwó; nítorí náà ayọ̀ mi yí di kíkún. 30 Òun kò lè ṣàì máa pọ̀ sí i, ṣùgbọ́n èmi kò lè ṣàìmá rẹlẹ̀.

31 (I)“Ẹni tí ó ti òkè wá ju gbogbo ènìyàn lọ; ẹni tí ó ti ayé wá ti ayé ni, a sì máa sọ ohun ti ayé. Ẹni tí ó ti ọ̀run wá ju gbogbo ènìyàn lọ. 32 (J)Ohun tí ó ti rí tí ó sì ti gbọ́ èyí náà sì ni òun ń jẹ́rìí rẹ̀; kò sì sí ẹni tí ó gba ẹ̀rí rẹ̀. 33 Ẹni tí ó gba ẹ̀rí rẹ̀ fi èdìdì dì í pé, olóòtítọ́ ni Ọlọ́run. 34 Nítorí ẹni tí Ọlọ́run ti rán ń sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: nítorí tí Ọlọ́run fi Ẹ̀mí fún un láìsí gbèdéke. 35 Baba fẹ́ Ọmọ, ó sì ti fi ohun gbogbo lé e lọ́wọ́ 36 (K)Ẹni tí ó bá gba Ọmọ gbọ́, ó ní ìyè àìnípẹ̀kun: ẹni tí kò bá sì gba Ọmọ gbọ́, kì yóò rí ìyè; nítorí ìbínú Ọlọ́run ń bẹ lórí rẹ̀.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.