Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Old/New Testament

Each day includes a passage from both the Old Testament and New Testament.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
1 Kronika 1-3

Ìran Adamu títí de Abrahamu

Títí dé ọmọkùnrin Noa

(A)Adamu, Seti, Enoṣi,

Kenani, Mahalaleli, Jaredi,

Enoku, Metusela, Lameki,

Noa.

Àwọn ọmọ Noa: Ṣemu, Hamu àti Jafeti.

Àwọn Ọmọ Jafeti

Àwọn ọmọ Jafeti ni:

Gomeri, Magogu, Madai; Jafani, Tubali, Meṣeki àti Tirasi.

Àwọn ọmọ Gomeri ni:

Aṣkenasi, Rifàti àti Togarma.

Àwọn ọmọ Jafani ni:

Eliṣa, Tarṣiṣi, Kittimu, àti Dodanimu.

Àwọn ọmọ Hamu

Àwọn ọmọ Hamu ni:

Kuṣi, Misraimu, Puti, àti Kenaani.

Àwọn ọmọ Kuṣi ni:

Seba, Hafila, Sabta, Raama, àti Ṣabteka.

Àwọn ọmọ Raama:

Ṣeba àti Dedani.

10 Kuṣi sì bí Nimrodu:

Ẹni tí ó di alágbára jagunjagun ní ayé.

11 Misraimu sì bí

Ludimu, Anamimu, Lehabimu, Naftuhimu, 12 Patrusimu, Kasluhimu, (láti ọ̀dọ̀ ẹni tí àwọn ará Filistini ti wá) àti àwọn ará Kaftorimu.

13 Kenaani sì bí Sidoni àkọ́bí rẹ̀,

àti Heti, 14 Àti àwọn ará Jebusi, àti àwọn ará Amori, àti àwọn ará Girgaṣi, 15 àti àwọn ará Hifi, àti àwọn ará Arki, àti àwọn ará Sini, 16 àti àwọn ará Arfadi, àti àwọn ará Ṣemari, àti àwọn ará Hamati.

Àwọn ará Ṣemu.

17 Àwọn ọmọ Ṣemu ni:

Elamu, Aṣuri, Arfakṣadi, Ludi àti Aramu.

Àwọn ọmọ Aramu:

Usi, Huli, Geteri, àti Meṣeki.

18 Arfakṣadi sì bí Ṣela,

Ṣela sì bí Eberi.

19 Eberi sì bí ọmọ méjì:

ọ̀kan ń jẹ́ Pelegi, nítorí ní ìgbà ọjọ́ rẹ̀ ni ilẹ̀ ya; orúkọ arákùnrin rẹ̀ ni Joktani.

20 Joktani sì bí

Almodadi, Ṣelefi, Hasarmafeti, Jera. 21 Hadoramu, Usali, Dikla, 22 Ebali, Abimaeli, Ṣeba. 23 Ofiri, Hafila, àti Jobabu. Gbogbo àwọn wọ̀nyí ni ọmọ Joktani.

24 Ṣemu, Arfakṣadi, Ṣela,

25 Eberi, Pelegi. Reu,

26 Serugu, Nahori, Tẹra:

27 Àti Abramu (tí ń ṣe Abrahamu).

Ìdílé Abrahamu

28 Àwọn ọmọ Abrahamu: Isaaki àti Iṣmaeli.

Àwọn ọmọ Hagari

29 Èyí ni àwọn ọmọ náà:

Nebaioti àkọ́bí Iṣmaeli: Kedari, Adbeeli, Mibsamu, 30 Miṣima, Duma, Massa, Hadadi, Tema, 31 Jeturi, Nafiṣi, àti Kedema.

Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ Iṣmaeli.

Àwọn ọmọ Ketura

32 Àwọn ọmọ Ketura, obìnrin Abrahamu:

Simrani, Jokṣani Medani, Midiani Iṣbaki àti Ṣua.

Àwọn ọmọ Jokṣani:

Ṣeba àti Dedani.

33 Àwọn ọmọ Midiani:

Efani, Eferi, Hanoku, Abida àti Eldaa.

Gbogbo àwọn wọ̀nyí ni ìran Ketura.

Àwọn Ìran Sara

34 Abrahamu sì jẹ́ baba Isaaki:

Àwọn ọmọ Isaaki:

Esau àti Israẹli.

Àwọn ọmọ Esau

35 Àwọn ọmọ Esau:

Elifasi, Reueli, Jeuṣi, Jalamu, àti Kora.

36 Àwọn ọmọ Elifasi:

Temani, Omari, Sefi, Gatamu àti Kenasi;

láti Timna: Amaleki.

37 Àwọn ọmọ Reueli:

Nahati, Sera, Ṣamma àti Missa.

Àwọn ènìyàn Seiri ní Edomu

38 Àwọn ọmọ Seiri:

Lotani, Ṣobali, Sibeoni, Ana, Diṣoni, Eseri àti Diṣani.

39 Àwọn ọmọ Lotani:

Hori àti Homamu: Timna sì ni arábìnrin Lotani.

40 Àwọn ọmọ Ṣobali:

Afiani, Manahati, Ebali, Ṣefo àti Onamu.

Àwọn ọmọ Sibeoni:

Aiah àti Ana.

41 Àwọn ọmọ Ana:

Diṣoni.

Àwọn ọmọ Diṣoni:

Hemdani, Eṣbani, Itrani, àti Kerani.

42 Àwọn ọmọ Eseri:

Bilhani, Saafani àti Akani.

Àwọn ọmọ Diṣani:

Usi àti Arani.

Àwọn alákòóso Edomu

43 Àwọn wọ̀nyí ni ọba tí ó jẹ ní Edomu, kí ó tó di pé ọba kankan jẹ lórí Israẹli:

Bela ọmọ Beori, orúkọ ìlú rẹ̀ ni Dinhaba.

44 Nígbà tí Bela kú, Jobabu ọmọ Sera ti Bosra sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.

45 Nígbà tí Jobabu kú, Huṣamu láti ilẹ̀ Temani sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.

46 Nígbà tí Huṣamu kú, Hadadi ọmọ Bedadi tí ó kọlu Midiani ní ìgbẹ́ Moabu, ó sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀. Orúkọ ìlú rẹ̀ ni Afiti.

47 Nígbà tí Hadadi sì kú, Samla láti Masreka, ó sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.

48 Samla sì kú, Saulu ti Rehoboti létí odò sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀

49 Nígbà tí Saulu kú, Baali-Hanani, ọmọ Akbori jẹ ọba ní ipò rẹ̀.

50 Nígbà tí Baali-Hanani kú, Hadadi ni ó jẹ ọba ní ipò rẹ̀. Orúkọ ìlú rẹ̀ ni Pau; orúkọ ìyàwó sì ni Mehetabeeli ọmọbìnrin Matiredi, ọmọbìnrin Mesahabu. 51 Hadadi sì kú pẹ̀lú.

Àwọn baálẹ̀ Edomu ni:

baálẹ̀ Timna, baálẹ̀ Alfa, baálẹ̀ Jeteti 52 baálẹ̀ Oholibama, baálẹ̀ Ela, baálẹ̀ Pinoni. 53 baálẹ̀ Kenasi, baálẹ̀ Temani, baálẹ̀ Mibsari, 54 Magdieli àti Iramu.

Àwọn wọ̀nyí ni baálẹ̀ Edomu.

Àwọn ọmọ Israẹli

(B)Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Israẹli. Reubeni, Simeoni, Lefi, Juda, Isakari, Sebuluni, Dani, Josẹfu, Benjamini; Naftali, Gadi: àti Aṣeri.

Juda

Àwọn ọmọ Hesroni

(C)Àwọn ọmọ Juda:

Eri, Onani àti Ṣela, àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wọ̀nyí ni wọ́n bí fún un láti ọ̀dọ̀ arábìnrin Kenaani, ọmọbìnrin Ṣua.

Eri àkọ́bí Juda, ó sì burú ní ojú Olúwa; Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa sì pa á.

Tamari, aya ọmọbìnrin Juda, ó sì bí Peresi àti Sera sì ní ọmọ márùn-ún ní àpapọ̀.

(D)Àwọn ọmọ Peresi:

Hesroni àti Hamulu.

Àwọn ọmọ Sera:

Simri, Etani, Hemani, Kalkoli àti Dara, gbogbo wọn jẹ́ márùn-ún.

Àwọn ọmọ Karmi:

Akani, ẹni tí ó mú ìyọnu wá sórí Israẹli nípa ẹ̀ṣẹ̀ ìfibú lórí mímú ohun ìyàsọ́tọ̀.

Àwọn ọmọ Etani:

Asariah.

Àwọn ọmọ tí a bí fún Hesroni ni:

Jerahmeeli, Ramu àti Kalebu.

Láti ọ̀dọ̀ Ramu ọmọ Hesroni

10 Ramu sì ni baba Amminadabu,

àti Amminadabu baba Nahiṣoni olórí àwọn ènìyàn Juda.

11 Nahiṣoni sì ni baba Salmoni,

Salmoni ni baba Boasi,

12 Boasi baba Obedi

àti Obedi baba Jese.

13 Jese sì ni baba

Eliabu àkọ́bí rẹ̀; ọmọ ẹlẹ́kejì sì ni Abinadabu,

ẹlẹ́kẹta ni Ṣimea, 14 Ẹlẹ́kẹrin Netaneli,

ẹlẹ́karùnún Raddai, 15 ẹlẹ́kẹfà Osemu

àti ẹlẹ́keje Dafidi.

16 Àwọn arábìnrin wọn ni Seruiah àti Abigaili.

Àwọn ọmọ mẹ́ta Seruiah ni Abiṣai, Joabu àti Asaheli.

17 Abigaili ni ìyá Amasa, ẹni tí baba rẹ̀ sì jẹ́ Jeteri ará Iṣmaeli.

Kalebu ọmọ Hesroni

18 Kalebu ọmọ Hesroni ní ọmọ láti ọ̀dọ̀ ìyàwó rẹ̀ Asuba (láti ọ̀dọ̀ Jerioti). Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọ rẹ̀:

Jeṣeri, Ṣobabu àti Ardoni.

19 Nígbà tí Asuba sì kú, Kalebu sì fẹ́ Efrata ní aya, ẹni tí ó bí Huri fún un.

20 Huri ni baba Uri, Uri sì jẹ́ baba Besaleli.

21 Nígbà tí ó yá, Hesroni sì dùbúlẹ̀ pẹ̀lú ọmọbìnrin Makiri baba Gileadi (ó sì ti fẹ́ ní aya láti ìgbà tí ó ti wà ní ẹni ọgọ́ta ọdún) ó sì bí Segubu.

22 Segubu sì jẹ́ baba Jairi, ẹni tí ó jẹ́ olùdarí ìlú mẹ́tàlélógún ní ilẹ̀ Gileadi.

23 (Ṣùgbọ́n Geṣuri àti Aramu sì fi agbára gba Hafoti-Jairi, àti Kenati pẹ̀lú gbogbo agbègbè rẹ̀ tí wọn tẹ̀dó sí jẹ́ ọgọ́ta ìlú.)

Gbogbo wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Makiri Baba Gileadi.

24 Lẹ́yìn tí Hesroni sì kú ni Kalebu Efrata, Abijah ìyàwó rẹ̀ ti Hesroni sì bí Aṣihuri baba Tekoa fún un.

Jerahmeeli ọmọ Hesroni

25 Ọmọ Jerahmeeli àkọ́bí Hesroni:

Ramu ọmọ àkọ́bí rẹ̀ Buna, Oreni, Osemu àti Ahijah. 26 Jerahmeeli ní ìyàwó mìíràn, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Atara; ó sì jẹ́ ìyá fún Onamu.

27 Àwọn ọmọ Ramu àkọ́bí Jerahmeeli:

Maasi, Jamini àti Ekeri.

28 Àwọn ọmọ Onamu:

Ṣammai àti Jada.

Àwọn ọmọ Ṣammai:

Nadabu àti Abiṣuri. 29 Orúkọ ìyàwó Abiṣuri ni Abihaili ẹni tí ó bí Ahbani àti Molidi.

30 Àwọn ọmọ Nadabu

Ṣeledi àti Appaimu. Ṣeledi sì kú láìsí ọmọ.

31 Àwọn ọmọ Appaimu:

Iṣi, ẹni tí ó jẹ́ baba fún Ṣeṣani. Ṣeṣani sì jẹ́ baba fún Ahlai.

32 Àwọn ọmọ Jada, arákùnrin Ṣammai:

Jeteri àti Jonatani. Jeteri sì kú láìní ọmọ.

33 Àwọn ọmọ Jonatani:

Peleti àti Sasa.

Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ Jerahmeeli.

34 Ṣeṣani kò sì ní ọmọkùnrin àwọn ọmọbìnrin nìkan ni ó ní.

Ó sì ní ìránṣẹ́ ará Ejibiti tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jariha. 35 Ṣeṣani sì fi ọmọ obìnrin rẹ̀ ní aya fún ìránṣẹ́ rẹ̀ Jariha, ó sì bí ọmọ fún tí orúkọ rẹ̀ jẹ́ Attai.

36 Attai sì jẹ́ baba fún Natani,

Natani sì jẹ́ baba fún Sabadi,

37 Sabadi ni baba Eflali,

Eflali jẹ́ baba Obedi,

38 Obedi sì ni baba Jehu,

Jehu ni baba Asariah,

39 Asariah sì ni baba Helesi,

Helesi ni baba Eleasa,

40 Eleasa ni baba Sismai,

Sismai ni baba Ṣallumu,

41 Ṣallumu sì ni baba Jekamiah,

Jekamiah sì ni baba Eliṣama.

Ìdílé Kalebu

42 Àwọn ọmọ Kalebu arákùnrin Jerahmeeli:

Meṣa àkọ́bí rẹ̀, ẹni tí ó jẹ́ baba fún Sifi,

àti àwọn ọmọ rẹ̀ Meraṣa, ẹni tí ó jẹ́ baba fún Hebroni.

43 Àwọn ọmọ Hebroni:

Kora, Tapua, Rekemu, àti Ṣema.

44 Ṣema ni baba Rahamu,

Rahamu sì jẹ́ baba fún Jorkeamu.

Rekemu sì ni baba Ṣammai.

45 Àwọn ọmọ Ṣammai ni Maoni,

Maoni sì ni baba Beti-Suri.

46 Efani obìnrin Kalebu sì ni ìyá

Harani, Mosa àti Gasesi,

Harani sì ni baba Gasesi.

47 Àwọn ọmọ Jahdai:

Regemu, Jotamu, Geṣani, Peleti, Efani àti Ṣaafa.

48 Maaka obìnrin Kalebu sì ni ìyá

Seberi àti Tirhana.

49 Ó sì bí Ṣaafa baba Madmana,

Ṣefa baba Makbena àti baba Gibeah.

ọmọbìnrin Kalebu sì ni Aksa.

50 Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ Kalebu.

Àwọn ọmọ Huri, àkọ́bí Efrata:

Ṣobali baba Kiriati-Jearimu. 51 Salma baba Bẹtilẹhẹmu àti Harefu baba Beti-Gaderi.

52 Àwọn ọmọ Ṣobali baba Kiriati-Jearimu ni:

Haroe, ìdajì àwọn ará Manaheti. 53 Àti ìdílé Kiriati-Jearimu: àti àwọn ara Itri, àti àwọn ará Puti, àti àwọn ará Ṣumati àti àwọn ará Miṣraiti: láti ọ̀dọ̀ wọn ni àwọn ọmọ ará Sorati àti àwọn ará Eṣtaoli ti wá.

54 Àwọn ọmọ Salma:

Bẹtilẹhẹmu, àti àwọn ará Netofa, Atrotu Beti-Joabu, ìdajì àwọn ará Manahati, àti ará Sori, 55 Àti àwọn ìdílé àwọn akọ̀wé, ẹni tí ń gbé ní Jabesi: àti àwọn ọmọ Tirati àti àwọn ará Ṣimeati àti àwọn ará Sukati. Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ará Keni, ẹni tí ó wá láti ọ̀dọ̀ Hamati, baba ilé Rekabu.

Àwọn ọmọ Dafidi

(E)Àwọn wọ̀nyí sì ni ọmọ Dafidi tí a bí fún un ní Hebroni:

Àkọ́bí sì ni Amnoni ọmọ Ahinoamu ti Jesreeli;

èkejì sì ni Daniẹli ọmọ Abigaili ará Karmeli;

Ẹ̀kẹta sì ni Absalomu ọmọ Maaka ọmọbìnrin Talmai ọba Geṣuri bí fún un;

ẹ̀kẹrin sì ni Adonijah ọmọ Haggiti;

Ẹ̀karùnún ni Ṣefatia láti ọ̀dọ̀ Abitali;

àti ẹ̀kẹfà, Itreamu, láti ọ̀dọ̀ Egla aya rẹ̀.

(F)Àwọn mẹ́fà wọ̀nyí ni a bí fún Dafidi ni Hebroni, níbi tí ó ti jẹ ọba fún ọdún méje àti oṣù mẹ́fà.

Dafidi sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n (33). Wọ̀nyí ni ọmọ wẹ́wẹ́ tí a bí fún un ní Jerusalẹmu:

Ṣimea, Ṣobabu, Natani àti Solomoni. Àwọn mẹ́rin wọ̀nyí sì ni a bí láti ọ̀dọ̀ Bati-Ṣua ọmọbìnrin Ammieli.

Ibhari sì wà pẹ̀lú, Eliṣama, Elifeleti, Noga, Nefegi, Jafia, Eliṣama, Eliada àti Elifeleti mẹ́sàn-án ni wọ́n.

Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Dafidi yàtọ̀ sí àwọn ọmọ tí àlè bí fún un. Tamari sì ni arábìnrin wọn.

Àwọn ọba Juda

10 Ọmọ Solomoni ni Rehoboamu,

Abijah ọmọ rẹ̀,

Asa ọmọ rẹ̀,

Jehoṣafati ọmọ rẹ̀,

11 Jehoramu ọmọ rẹ̀,

Ahasiah ọmọ rẹ̀,

Joaṣi ọmọ rẹ̀,

12 Amasiah ọmọ rẹ̀,

Asariah ọmọ rẹ̀,

Jotamu ọmọ rẹ̀,

13 Ahasi ọmọ rẹ̀,

Hesekiah ọmọ rẹ̀,

Manase ọmọ rẹ̀,

14 Amoni ọmọ rẹ̀,

Josiah ọmọ rẹ̀.

15 Àwọn ọmọ Josiah:

Àkọ́bí ọmọ rẹ̀ ni Johanani,

èkejì ọmọ rẹ̀ ni Jehoiakimu,

ẹ̀kẹta ọmọ rẹ̀ ni Sedekiah,

ẹ̀kẹrin ọmọ rẹ̀ ni Ṣallumu.

16 Àwọn ìran ọmọ Jehoiakimu:

Jekoniah ọmọ rẹ̀,

àti Sedekiah.

Ìdílé ọba lẹ́yìn ìgbèkùn

17 Àwọn ọmọ Jekoniah tí a mú ní ìgbèkùn:

Ṣealitieli ọmọ rẹ̀ ọkùnrin, 18 Malkiramu, Pedaiah, Ṣenasari, Jekamiah, Hoṣama àti Nedabiah.

19 Àwọn ọmọ Pedaiah:

Serubbabeli àti Ṣimei.

Àwọn ọmọ Serubbabeli:

Meṣullamu àti Hananiah. Ṣelomiti ni arábìnrin wọn. 20 Àwọn márùn-ún mìíràn sì tún wà: Haṣuba, Oheli, Berekiah, Hasadiah àti Jusabhesedi.

21 Àwọn ọmọ Hananiah:

Pelatiah àti Jeṣaiah, àti àwọn ọmọ Refaiah, ti Arnani, ti Ọbadiah àti ti Ṣekaniah.

22 Àwọn ọmọ Ṣekaniah:

Ṣemaiah àti àwọn ọmọ rẹ̀: Hattusi, Igali, Bariah, Neariah àti Ṣafati, mẹ́fà ni gbogbo wọn.

23 Àwọn ọmọ Neariah:

Elioenai; Hesekiah, àti Asrikamu, mẹ́ta ni gbogbo wọn.

24 Àwọn ọmọ Elioenai:

Hodafiah, Eliaṣibu, Pelaiah, Akkubu, Johanani, Delaiah àti Anani, méje sì ni gbogbo wọn.

Johanu 5:25-47

25 (A)Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, wákàtí náà ń bọ̀, ó sì dé tán nísinsin yìí, nígbà tí àwọn òkú yóò gbọ́ ohùn ọmọ Ọlọ́run: àwọn tí ó bá gbọ́ yóò sì yè. 26 Nítorí pé gẹ́gẹ́ bí Baba ti ní ìyè nínú ara rẹ̀; gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni ó sì fi fún ọmọ láti ní ìyè nínú ara rẹ̀; 27 Ó sì fún un ní àṣẹ láti máa ṣe ìdájọ́ pẹ̀lú, nítorí tí òun jẹ́ ọmọ ènìyàn.

28 “Kí èyí má ṣe yà yín lẹ́nu; nítorí pé wákàtí ń bọ̀, nínú èyí tí gbogbo àwọn tí ó wà ní ibojì yóò gbọ́ ohun rẹ̀. 29 (B)Wọn ó sì jáde wá; àwọn tí ó ṣe rere, sí àjíǹde ìyè; àwọn tí ó sì ṣe búburú sí àjíǹde ìdájọ́. 30 (C)Èmi kò le ṣe ohun kan fún ara mi: bí mo ti ń gbọ́ ni, mo ń dájọ́: òdodo sì ni ìdájọ́ mi; nítorí èmi kò wá ìfẹ́ ti èmi fúnra mi, bí kò ṣe ìfẹ́ ti ẹni tí ó rán mi.

Àwọn ẹ̀rí nípa Jesu

31 (D)“Bí èmi bá ń jẹ́rìí ara mi, ẹ̀rí mi kì í ṣe òtítọ́. 32 Ẹlòmíràn ni ẹni tí ń jẹ́rìí mi; èmi sì mọ̀ pé, òtítọ́ ni ẹ̀rí mi tí ó jẹ́.

33 (E)“Ẹ̀yin ti ránṣẹ́ lọ sọ́dọ̀ Johanu, òun sì ti jẹ́rìí sí òtítọ́. 34 (F)Ṣùgbọ́n èmi kò gba jẹ́rìí lọ́dọ̀ ènìyàn: nǹkan wọ̀nyí ni èmi ń sọ, kí ẹ̀yin lè là. 35 Òun ni fìtílà tí ó ń jó, tí ó sì ń tànmọ́lẹ̀: ẹ̀yin sì fẹ́ fún sá à kan láti máa yọ̀ nínú ìmọ́lẹ̀ rẹ̀.

36 (G)“Ṣùgbọ́n èmi ní ẹ̀rí tí ó pọ̀jù ti Johanu lọ: nítorí iṣẹ́ tí Baba ti fi fún mi láti ṣe parí, iṣẹ́ náà pàápàá tí èmi ń ṣe náà ń jẹ́rìí mi pé, Baba ni ó rán mi. 37 Àti Baba tìkára rẹ̀ tí ó rán mi ti jẹ́rìí mi. Ẹ̀yin kò gbọ́ ohùn rẹ̀ nígbà kan rí, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò rí ìrísí rẹ̀. 38 Ẹ kò sì ní ọ̀rọ̀ rẹ̀ láti máa gbé inú yín: nítorí ẹni tí ó rán, òun ni ẹ̀yin kò gbàgbọ́. 39 (H)Ẹ̀yin ń wá ìwé mímọ́ nítorí ẹ̀yin rò pé nínú wọn ni ẹ̀yin ní ìyè tí kò nípẹ̀kun. Wọ̀nyí sì ni àwọn tí ó ń jẹ́rìí mi. 40 Ẹ̀yin kò sì fẹ́ láti wá sọ́dọ̀ mi, kí ẹ̀yin ba à lè ní ìyè.

41 “Èmi kò gba ògo lọ́dọ̀ ènìyàn. 42 Ṣùgbọ́n èmi mọ̀ pé, ẹ̀yin fúnrayín kò ní ìfẹ́ Ọlọ́run nínú yín. 43 (I)Èmi wá ní orúkọ Baba mi, ẹ̀yin kò sì gbà mí; bí ẹlòmíràn bá wá ní orúkọ ara rẹ̀, òun ni ẹ̀yin yóò gbà. 44 Ẹ̀yin ó ti ṣe lè gbàgbọ́, ẹ̀yin tí ń gba ògo lọ́dọ̀ ara yín tí kò wá ògo tí ó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run nìkan wá?

45 (J)“Ẹ má ṣe rò pé, èmi ó fi yín sùn lọ́dọ̀ Baba: ẹni tí ń fi yín sùn wà, àní Mose, ẹni tí ẹ̀yin gbẹ́kẹ̀lé. 46 Nítorí pé ẹ̀yin ìbá gba Mose gbọ́, ẹ̀yin ìbá gbà mí gbọ́: nítorí ó kọ ìwé nípa tèmi. 47 (K)Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin kò bá gba ìwé rẹ̀ gbọ́, ẹ̀yin ó ti ṣe gbà ọ̀rọ̀ mi gbọ́?”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.