Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

M’Cheyne Bible Reading Plan

The classic M'Cheyne plan--read the Old Testament, New Testament, and Psalms or Gospels every day.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Onidajọ 2

Angẹli Olúwa ní Bokimu

Ní ọjọ́ kan angẹli Olúwa dìde kúrò láti Gilgali lọ sí Bokimu ó sì wí pé, “Èmi mú un yín gòkè láti ilẹ̀ Ejibiti wá, èmi sì síwájú yín wá sí ilẹ̀ tí mo ti búra láti fi fún àwọn baba ńlá yín. Èmi sì wí pé, ‘Èmi kì yóò yẹ májẹ̀mú mi pẹ̀lú yín, ẹ̀yin kò gbọdọ̀ bá àwọn ènìyàn ilẹ̀ yí dá májẹ̀mú àlàáfíà, ṣùgbọ́n ẹ̀yin yóò wó pẹpẹ ibi ìsin òrìṣà wọn lulẹ̀.’ Síbẹ̀ ẹ̀yin ṣe àìgbọ́ràn sí mi. Èéṣe tí ẹ̀yin fi ṣe èyí? Ní báyìí, èmi wí fún un yín pé, èmi kì yóò lé àwọn ènìyàn jáde kúrò níwájú yín; ṣùgbọ́n wọn yóò jẹ́ ẹ̀gún ní ìhà yín, àwọn òrìṣà wọn yóò sì jẹ́ ìdánwò fún un yín.”

Bí angẹli Olúwa sì ti sọ gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún àwọn ará Israẹli tan, àwọn ènìyàn náà sì gbé ohùn wọn sókè wọ́n sì sọkún kíkorò, wọ́n sì pe orúkọ ibẹ̀ ní Bokimu (ibi tí àwọn ènìyàn ti sọkún). Wọ́n sì rú ẹbọ sí Olúwa níbẹ̀.

Àìgbọ́ràn àti ìkùnà ní ogun

(A)Lẹ́yìn tí Joṣua ti tú àwọn ènìyàn Israẹli ká, àwọn ẹ̀yà Israẹli kọ̀ọ̀kan lọ sí ilẹ̀ tí a fi fún wọn láti lọ gbà á ní ìní wọn. Àwọn ènìyàn náà sin Olúwa ní gbogbo ìgbà ayé Joṣua àti ní gbogbo ọjọ́ àwọn àgbàgbà tí ó wà lẹ́yìn ikú rẹ̀ tí wọ́n sì rí gbogbo iṣẹ́ ńlá tí Olúwa ṣe fún Israẹli.

Joṣua ọmọ Nuni, ìránṣẹ́ Olúwa, kú ní ẹni àádọ́fà ọdún (110). Wọ́n sì sìnkú rẹ̀ sí ààlà ilẹ̀ ìní rẹ̀ ní Timnati-Hereki ní ilẹ̀ òkè Efraimu ní àríwá òkè Gaaṣi.

10 Ní ìgbẹ̀yìn, gbogbo ìran náà sì kú; àwọn ìran tí ó tẹ̀lé wọn kò sì sin Olúwa nítorí wọn kò mọ Olúwa, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò mọ ohun tí Olúwa ṣe fún Israẹli. 11 Àwọn ọmọ Israẹli sì ṣe ohun tí ó burú níwájú Olúwa, wọ́n sì ń sin òrìṣà Baali. 12 Wọ́n kọ Olúwa Ọlọ́run àwọn baba wọn sílẹ̀, ẹni tí ó mú wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti, wọ́n ń tọ àwọn òrìṣà lẹ́yìn, wọ́n sì ń sin àwọn oríṣìíríṣìí òrìṣà àwọn ará ilẹ̀ ibi tí wọ́n ń gbé, wọ́n sì mú Olúwa bínú, 13 nítorí tí wọ́n kọ̀ Olúwa sílẹ̀ àti nítorí pé wọ́n ń sin Baali àti Aṣtoreti. 14 Nínú ìbínú rẹ̀ sí àwọn ọmọ Israẹli Olúwa fi wọ́n lé àwọn akónisìn lọ́wọ́ tí ó kó wọn ní ẹrú, tí ó sì bà wọ́n jẹ́. Ó sì tà wọ́n fún àwọn ọ̀tá wọn tí ó yí wọn ká àwọn ẹni tí wọn kò le dúró dè láti kọ ojú ìjà sí. 15 Nígbàkígbà tí àwọn Israẹli bá jáde lọ sí ojú ogun láti jà, ọwọ́ Olúwa sì wúwo ní ara wọn, àwọn ọ̀tá a sì borí wọn, àní gẹ́gẹ́ bí ó ti búra fún wọn. Wọ́n sì wà nínú ìpọ́njú púpọ̀.

16 Olúwa sì gbé àwọn onídàájọ́ dìde tí ó gbà wọ́n sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn tí ń kó wọn lẹ́rú. 17 Síbẹ̀síbẹ̀ wọn kò fi etí sí ti àwọn onídàájọ́ wọn, ṣùgbọ́n wọ́n ṣe àgbèrè, wọ́n ń sin òrìṣà. Wọn kò dàbí àwọn baba wọn, kíákíá ni wọ́n yípadà kúrò lọ́nà tí àwọn baba wọ́n ń tọ̀, ọ̀nà ìgbọ́ràn sí àwọn òfin Olúwa. 18 Nígbà kí ìgbà tí Olúwa bá gbé onídàájọ́ dìde fún wọn, Olúwa máa ń wà pẹ̀lú onídàájọ́ náà, a sì gbà wọ́n kúrò ní ọwọ́ àwọn ọ̀tá wọn ní ìwọ̀n ìgbà tí onídàájọ́ náà bá wà láààyè nítorí àánú Olúwa wà ní ara wọn, nígbà tí wọ́n bá ké ìrora lábẹ́ àwọn tí ń tẹrí wọn ba, tí sì ń fi ìyà jẹ wọ́n. 19 Ṣùgbọ́n ní kété tí onídàájọ́ bá ti kú, àwọn ènìyàn náà a sì tún padà sí ọ̀nà ìbàjẹ́ àní ju ti àwọn baba wọn lọ, wọn a tẹ̀lé òrìṣà, wọ́n ń sìn wọ́n, wọn a sì foríbalẹ̀ fún wọn, wọ́n kọ̀ láti yàgò kúrò ní ọ̀nà ibi wọn àti agídí ọkàn wọn.

20 Ìbínú Olúwa yóò sì tún ru sí Israẹli a sì wí pé, “Nítorí tí orílẹ̀-èdè yìí ti yẹ májẹ̀mú tí mo fi lélẹ̀ fún àwọn baba ńlá wọn, tí wọn kò sì fetí sí mi, 21 Èmi kì yóò lé ọ̀kankan nínú àwọn orílẹ̀-èdè tí Joṣua fi sílẹ̀ nígbà tí ó kú jáde. 22 Ṣùgbọ́n dípò bẹ́ẹ̀ èmi yóò lo àwọn orílẹ̀-èdè yìí láti fi dán Israẹli wò, láti mọ̀ bóyá wọ́n yóò pa ọ̀nà Olúwa mọ́ àti pé bóyá wọn ó rìn nínú rẹ̀ bí àwọn baba ńlá wọn ti rìn.” 23 Nítorí náà Olúwa fi àwọn orílẹ̀-èdè náà sílẹ̀ ní ilẹ̀ náà kò sì lé wọn jáde, tàbí kí ó jẹ́ kí àwọn Israẹli pa wọ́n run, bẹ́ẹ̀ kò sì fi wọ́n lé Joṣua lọ́wọ́.

Ìṣe àwọn Aposteli 6

Yíyan àwọn méje

Ǹjẹ́ ní ọjọ́ wọ̀nyí, nígbà tí iye àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ń pọ̀ sí i, ìkùnsínú wà ní àárín àwọn Helleni tí ṣe Júù àti àwọn Heberu tí ṣe Júù, nítorí tí a gbàgbé nípa ti àwọn opó wọn nínú ìpín fún ni ojoojúmọ́. Àwọn méjìlá sì pe ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn jọ sọ́dọ̀, wọn wí pé, “Kò yẹ kí àwa ó fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sílẹ̀, kí a sì máa ṣe ìránṣẹ́ tábìlì. Nítorí náà, ará, ẹ wo ọkùnrin méje nínú yín, olórúkọ rere, tí ó kún fún Ẹ̀mí Mímọ́ àti fún ọgbọ́n, tí àwa lè yàn sí iṣẹ́ yìí. Ṣùgbọ́n àwa yóò dúró ṣinṣin nínú àdúrà gbígbà, àti nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ ọ̀rọ̀ náà.”

Ọ̀rọ̀ náà sì tọ́ lójú gbogbo ìjọ; wọ́n sì yan Stefanu, ọkùnrin tí ó kún fún ìgbàgbọ́ àti fún Ẹ̀mí Mímọ́ àti Filipi, àti Prokoru, àti Nikanoru, àti Timoni, àti Parimena, àti Nikolasi aláwọ̀ṣe Júù ará Antioku. Ẹni tí wọ́n mú dúró níwájú àwọn Aposteli; nígbà tí wọ́n sì gbàdúrà, wọ́n gbé ọwọ́ lé wọn.

Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sì gbilẹ̀, iye àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sì pọ̀ sí i gidigidi ni Jerusalẹmu, ọ̀pọ̀ nínú ẹgbẹ́ àwọn àlùfáà sí fetí sí tí ìgbàgbọ́ náà.

A mú Stefanu

Stefanu tí ó kún fún oore-ọ̀fẹ́ àti agbára, ó ṣe iṣẹ́ ìyanu, àti iṣẹ́ ààmì ńlá láàrín àwọn ènìyàn. Ṣùgbọ́n àwọn kan dìde nínú àwọn ti ń ṣe ara Sinagọgu, tí a ń pè ní Libataini. Àwọn Júù Kirene àti ti Alekisandiria àti ti Kilikia, àti ti Asia wá, wọ́n ń bá Stefanu jiyàn, 10 ṣùgbọ́n wọn kò sí lè ko ọgbọ́n àti Ẹ̀mí tí ó fi ń sọ̀rọ̀ lójú.

11 Nígbà náà ni wọ́n fún àwọn ọkùnrin kan ní àbẹ̀tẹ́lẹ̀, kí wọn ń wí pé, “Àwa gbọ́ tí Stefanu ń sọ ọ̀rọ̀-òdì sí Mose àti sí Ọlọ́run.”

12 Wọ́n sí ru àwọn ènìyàn sókè, àti àwọn alàgbà, àti àwọn olùkọ́ni ní òfin. Wọ́n dìde sí i, wọ́n gbá a mú, wọ́n sì mú un wá sí iwájú àjọ ìgbìmọ̀. 13 Wọ́n sí mú àwọn ẹlẹ́rìí èké wá, tiwọn wí pé, “Ọkùnrin yìí kò sinmi láti sọ ọ̀rọ̀-òdì sí ibi mímọ́ yìí, àti sí òfin. 14 Nítorí àwa gbọ́ o wí pé Jesu ti Nasareti yìí yóò fọ́ ibí yìí, yóò sì yí àṣà ti Mose fi fún wa padà.”

15 Gbogbo àwọn tí ó sì jókòó ni àjọ ìgbìmọ̀ tẹjúmọ́ Stefanu, wọ́n sì rí ojú rẹ̀ dàbí ojú angẹli.

Jeremiah 15

15 Nígbà náà ni Olúwa sọ fún mi pé: “Kódà kí Mose àti Samuẹli dúró níwájú mi, ọkàn mi kì yóò lọ sọ́dọ̀ àwọn ènìyàn wọ̀nyí. Mú wọn kúrò níwájú mi! Jẹ́ kí wọn ó lọ! (A)Tí wọ́n bá sì bi ọ́ pé, ‘Níbo ni kí a lọ?’ Sọ fún wọn pé, ‘Báyìí ni Olúwa wí:

“ ‘Àwọn tí a kọ ikú mọ́, sí ikú;
àwọn tí a kọ idà mọ́, sí idà;
àwọn tí a kọ ìyàn mọ́, sí ìyàn;
àwọn tí a kọ ìgbèkùn mọ́ sí ìgbèkùn.’

“Èmi yóò rán oríṣìí ìjìyà mẹ́rin láti kọlù wọ́n,” ni Olúwa wí, “Idà láti pa, àwọn ajá láti wọ́ wọn lọ, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run àti àwọn ẹranko orí ilẹ̀ láti jẹ àti láti parun. N ó sọ wọ́n di ẹni ìkórìíra níwájú gbogbo ìjọba ayé torí ohun tí Manase ọmọ Hesekiah ọba Juda ṣe ní Jerusalẹmu.

“Ta ni yóò ṣàánú rẹ, ìwọ Jerusalẹmu?
    Ta ni yóò dárò rẹ?
    Ta ni yóò dúró béèrè àlàáfíà rẹ?
O ti kọ̀ mí sílẹ̀,” ni Olúwa
    “Ìwọ sì wà nínú ìpadàsẹ́yìn.
Nítorí náà, Èmi yóò dáwọ́lé ọ, èmi ó sì pa ọ́ run;
    Èmi kò sì ní fi ojú àánú wò ọ́ mọ́.
Èmi kò tún lè fi ìfẹ́ hàn si ọ,
    Èmi yóò fi àtẹ fẹ́ wọn sí ẹnu-ọ̀nà ìlú náà.
Èmi yóò mú ìṣọ̀fọ̀ àti ìparun
    bá àwọn ènìyàn mi nítorí pé wọn
    kò tí ì yípadà kúrò lọ́nà wọn.
Èmi yóò jẹ́ kí àwọn opó wọn pọ̀ ju
    yanrìn Òkun lọ.
Ní ọjọ́-kanrí ni èmi ó mú apanirun
    kọlu àwọn ìyá ọmọkùnrin wọn.
    Lójijì ni èmi yóò mú
    ìfòyà àti ìbẹ̀rù bá wọn.
Ìyá ọlọ́mọ méje yóò dákú, yóò
    sì mí ìmí ìgbẹ̀yìn. Òòrùn rẹ
yóò wọ̀ lọ́sàn án gangan, yóò
    di ẹni ẹ̀tẹ́ òun àbùkù. Èmi
yóò fi àwọn tí ó bá yè síwájú
    àwọn ọ̀tá wọn tí idà wà lọ́wọ́ wọn,”
    ni Olúwa wí.

10 Háà! Ó ṣe tí ìyá mi bí mi:
    ọkùnrin tí gbogbo ilẹ̀ dojúkọ tí wọ́n sì bá jà,
èmi kò wínni, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò yá lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni
    síbẹ̀, gbogbo ènìyàn ló ń fi mí ré.

11 Olúwa sọ pé,

“Dájúdájú èmi ò dá ọ sí fún ìdí kan pàtó.
    Dájúdájú mo mú kí àwọn ọ̀tá rẹ
    tẹríba níwájú rẹ nígbà ibi àti ìpọ́njú.

12 “Ǹjẹ́ ẹnìkan lè fi ọwọ́ ṣẹ́ irin
    irin láti àríwá tàbí idẹ?

13 “Gbogbo ọlá àti ìṣúra rẹ
    ni èmi ó fi sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìkógun láìgba
nǹkan kan nítorí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ
    jákèjádò orílẹ̀-èdè rẹ.
14 Èmi yóò fi ọ́ ṣẹrú fún àwọn ọ̀tá rẹ
    ní ìlú tí ìwọ kò mọ̀ nítorí ìbínú
    mi yóò rán iná tí yóò jó ọ.”

15 Ó yé ọ, ìwọ Olúwa rántí mi kí o
    sì ṣe ìtọ́jú mi; gbẹ̀san mi lára
àwọn tó dìtẹ̀ mi. Ìwọ ti jìyà fún
    ìgbà pípẹ́, má ṣe mú mi lọ, nínú bí
    mo ṣe jìyà nítorí tìrẹ.
16 Nígbà tí ọ̀rọ̀ rẹ dé, mo jẹ wọ́n
    Àwọn ni ìdùnnú àti ayọ̀ ọkàn mi
Nítorí pé orúkọ rẹ ni a fi ń pè mí
    Ìwọ Olúwa Ọlọ́run Alágbára.
17 Èmi kò fìgbà kan jókòó láàrín àwọn ẹlẹ́gàn.
    N ko bá wọn yọ ayọ̀ pọ̀;
mo dá jókòó torí pé ọwọ́ rẹ wà
    lára mi, ìwọ sì ti fi ìbínú rẹ kún inú mi.
18 Èéṣe tí ìrora mi kò lópin,
    tí ọgbẹ́ mi kò sì ṣe é wòsàn?
Ní òtítọ́ ìwọ yóò dàbí kànga ẹ̀tàn sí mi,
    gẹ́gẹ́ bí ìsun tó kọ̀ tí kò sun?

19 Nítorí náà báyìí ni Olúwa wí:

“Tí o bá ronúpìwàdà, Èmi ó dá ọ padà
    wá kí o lè máa sìn mí. Tí ó bá
sọ ọ̀rọ̀ tó dára ìwọ yóò di agbẹnusọ
    mi. Jẹ́ kí àwọn ènìyàn yìí kọjú sí ọ;
    ṣùgbọ́n ìwọ kò gbọdọ̀ kọjú sí wọn
20 Èmi fi ọ́ ṣe odi idẹ tí ó lágbára
    sí àwọn ènìyàn wọ̀nyí. Wọn ó bá ọ jà
ṣùgbọ́n, wọn kò ní lè borí rẹ
    nítorí pé, mo wà pẹ̀lú rẹ láti gbà ọ́ là,
kí n sì dáàbò bò ọ́,”
    ni Olúwa wí.
21 “Èmi yóò gbà ọ́ sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn
    ìkà ènìyàn, Èmi yóò sì rà ọ́
    padà kúrò lọ́wọ́ àwọn ẹni búburú.”

Marku 1

Johanu onítẹ̀bọmi tún ọ̀nà ṣe sílẹ̀

Ìbẹ̀rẹ̀ ìhìnrere nípa Jesu Kristi, Ọmọ Ọlọ́run.

(A)(B) Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ nínú ìwé wòlíì Isaiah pé:

“Èmi yóò ran oníṣẹ́ mi síwájú rẹ,
    Ẹni tí yóò tún ọ̀nà rẹ ṣe.”
(C)“Ohùn ẹni tí ń kígbe ní ijù,
    ‘Ẹ tún ọ̀nà Olúwa ṣe,
    ẹ ṣe ojú ọ̀nà rẹ̀ kí ó tọ́.’ ”

(D)Johanu dé, ẹni tí ó ń tẹnibọmi ní aginjù, tí ó sì ń wàásù ìtẹ̀bọmi ìrònúpìwàdà fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀. Gbogbo àwọn tí ń gbé ní agbègbè Judea, àti gbogbo ènìyàn Jerusalẹmu jáde tọ̀ ọ́ lọ, a sì ti ọwọ́ rẹ̀ tẹ gbogbo wọn bọ omi ni odò Jordani, wọ́n ń jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Johanu sì wọ aṣọ irun ìbákasẹ. Ó sì di àmùrè awọ mọ́ ẹ̀gbẹ́ rẹ̀. Eṣú àti oyin ìgàn sì ni oúnjẹ rẹ̀. Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù wí pé, “Ẹnìkan tí ó tóbi jù mí lọ ń bọ̀ lẹ́yìn mi, okùn bàtà ẹsẹ̀ ẹni tí èmi kò tó ẹni tí ń tú. Èmi ń fi omi ṣe ìtẹ̀bọmi yín, ṣùgbọ́n Òun yóò fi Ẹ̀mí Mímọ́ ṣe ìtẹ̀bọmi yín.”

Ìtẹ̀bọmi àti ìdánwò Jesu

(E)Ó sì ṣe ní ọjọ́ kan Jesu ti Nasareti ti Galili jáde wá, a sì ti ọwọ́ Johanu ṣe ìtẹ̀bọmi fún ní odò Jordani. 10 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ tí Jesu ń ti inú omi jáde wá, ó rí ọ̀run tí ó ṣí sílẹ̀, Ẹ̀mí Mímọ́ bí àdàbà sọ̀kalẹ̀ lé e lórí. 11 (F)Ohùn kan sì ti ọ̀run wá wí pé, “Ìwọ ni àyànfẹ́ Ọmọ mi, ẹni tí inú mi dùn sí gidigidi.”

12 (G)Lẹ́sẹ̀kan náà, Ẹ̀mí Mímọ́ sì darí Jesu sí ijù, 13 Ó sì wà ní ogójì ọjọ́ ní aginjù. A sì ti ọwọ́ Satani dán an wò, ó sì wà pẹ̀lú àwọn ẹranko ìgbẹ́. Àwọn angẹli sì ń ṣe ìránṣẹ́ fún un.

Pípe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn àkọ́kọ́

14 (H)Lẹ́yìn ìgbà tí ọba Herodu ti fi Johanu sínú ẹ̀wọ̀n tan, Jesu lọ sí Galili, ó ń wàásù ìhìnrere ti ìjọba Ọlọ́run. 15 Ó sì kéde wí pé, “Àkókò náà dé wàyí, ìjọba Ọlọ́run kù sí dẹ̀dẹ̀. Ẹ yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ yín, kí ẹ sì gba ìhìnrere yìí gbọ́.”

16 (I)Ní ọjọ́ kan, bí Jesu ti ń rìn létí Òkun Galili, Ó rí Simoni àti Anderu arákùnrin rẹ̀, wọ́n ń fi àwọ̀n wọn pẹja torí pé apẹja ni wọ́n. 17 Jesu sì ké sí wọn wí pé, “Ẹ máa tọ̀ mí lẹ́yìn. Èmi yóò sì sọ yín di apẹja ènìyàn.” 18 Ní kánkán wọ́n fi àwọ̀n wọn sílẹ̀, wọ́n sì tọ̀ Ọ́ lẹ́yìn.

19 Bí Ó sì ti rìn síwájú díẹ̀, ní etí Òkun, Ó rí Jakọbu ọmọ Sebede àti Johanu arákùnrin rẹ̀ nínú ọkọ̀, wọ́n ń tún àwọ̀n wọn ṣe. 20 Ó sì ké sí àwọn náà lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, wọ́n fi Sebede baba wọn sílẹ̀ nínú ọkọ̀ pẹ̀lú àwọn alágbàṣe, wọ́n sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.

Jesu lé ẹ̀mí àìmọ́ jáde

21 (J)Lẹ́yìn náà, Jesu àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wọ ìlú Kapernaumu, nígbà tí ó di òwúrọ̀ ọjọ́ ìsinmi, ó lọ sínú Sinagọgu, ó sì ń kọ́ni. 22 Ẹnu sì ya ìjọ ènìyàn nítorí ìkọ́ni rẹ̀, nítorí pé ó ń kọ́ni bí ẹni tí ó ní àṣẹ, kì í ṣe bí àwọn olùkọ́ òfin ṣe ń kọ́ àwọn ènìyàn. 23 (K)Ní àsìkò náà gan an ni ọkùnrin kan tí ó wà nínú Sinagọgu wọn, tí ó ní ẹ̀mí àìmọ́, bẹ̀rẹ̀ sí í kígbe wí pé, 24 (L)“Kí ni ìwọ ń wá lọ́dọ̀ wa, Jesu ti Nasareti? Ṣé ìwọ wá láti pa wá run ni? Èmí mọ ẹni tí ìwọ í ṣe; Ìwọ ní ẹni Mímọ́ Ọlọ́run!”

25 Jesu si bá a wí, ó wí pé, “Pa ẹnu rẹ mọ́, kí ó sì jáde kúrò lára rẹ̀.” 26 Ẹ̀mí àìmọ́ náà sì gbé e ṣánlẹ̀ lógèdèǹgbé, ó ké ní ohùn rara, ó sì jáde kúrò lára ọkùnrin náà.

27 Ẹnu sì ya àwọn ènìyàn, tó bẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi ń sọ láàrín ara wọn ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀. Wọ́n béèrè pẹ̀lú ìgbóná ara, pé, “Kí ni èyí? Irú ẹ̀kọ́ tuntun wo ni èyí? Ó ń fi agbára pàṣẹ fún àwọn ẹ̀mí àìmọ́ pàápàá wọ́n sì gbọ́ tirẹ̀.” 28 Ìròyìn nípa rẹ̀ tàn ká gbogbo agbègbè Galili.

Jesu mú ọ̀pọ̀ ènìyàn láradá

29 (M)Nígbà tí wọn sì jáde kúrò nínú Sinagọgu, wọ́n lọ pẹ̀lú Jakọbu àti Johanu sí ilé Simoni àti Anderu. 30 Ìyá ìyàwó Simoni tí ó dùbúlẹ̀ àìsàn ibà, wọ́n sì sọ fún Jesu nípa rẹ̀. 31 Ó sì tọ̀ ọ́ lọ, ó fà á lọ́wọ́, ó sì gbé e dìde; lójúkan náà ibà náà fi sílẹ̀, ó sì ń ṣe ìránṣẹ́ fún wọn.

32 (N)Nígbà tí ó di àṣálẹ́, tí oòrùn wọ̀, wọ́n gbé gbogbo àwọn aláìsàn àti àwọn tó ni ẹ̀mí àìmọ́ tọ̀ ọ́ wá. 33 Gbogbo ìlú si péjọ ni ẹnu-ọ̀nà. 34 Jesu sì wo ọ̀pọ̀ tí wọ́n ní onírúurú ààrùn sàn. Bákan náà ni ó lé ọ̀pọ̀ ẹ̀mí àìmọ́ jáde, Ṣùgbọ́n kò sì jẹ́ kí àwọn ẹ̀mí àìmọ́ náà kí ó sọ̀rọ̀, nítorí tí wọ́n mọ ẹni tí òun í ṣe.

Jesu ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ láti gbàdúrà

35 (O)Ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, kí ilẹ̀ tó mọ́, Jesu nìkan jáde lọ sí aginjù kan, láti lọ gbàdúrà. 36 Simoni àti àwọn ènìyàn rẹ̀ yòókù lọ láti wá a. 37 Nígbà tí wọ́n sì rí I, wọ́n sọ fún wí pé, “Gbogbo ènìyàn ń wá ọ!”

38 Jesu sì dáhùn wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a lọ sí àwọn ìlú mìíràn, kí ń lè wàásù níbẹ̀ pẹ̀lú. Nítorí èyí ni èmi sá à ṣe wá.” 39 (P)Nítorí náà, ó ń kiri gbogbo agbègbè Galili, ó ń wàásù nínú Sinagọgu. Ó sì ń lé àwọn ẹ̀mí àìmọ́ jáde.

Ọkùnrin tí o ní ààrùn ẹ̀tẹ̀

40 (Q)Ọkùnrin adẹ́tẹ̀ kan tọ̀ ọ́ wá, ó sì kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀. Ó sì bẹ̀bẹ̀ fún ìmúláradá. Ó wí pé, “Bí ìwọ bá fẹ́, ìwọ lè mú mi láradá.”

41 Jesu kún fún àánú, ó na ọwọ́ rẹ̀, ó fi ọwọ́ rẹ̀ bà a, ó wí pé, “Èmí fẹ́. Di mímọ́.” 42 Lójúkan náà ẹ̀tẹ̀ náà fi sílẹ̀ lọ, ọkùnrin náà sì rí ìwòsàn.

43 Jesu sì kìlọ̀ fún un gidigidi 44 (R)Ó wí pé, “Lọ fi ara rẹ̀ hàn àlùfáà Júù fún àyẹ̀wò. Ṣùgbọ́n má ṣe dúró sọ ohunkóhun fún ẹnikẹ́ni ní ọ̀nà. Mú ẹ̀bùn lọ́wọ́, èyí tí Mose pàṣẹ fún adẹ́tẹ̀ tí a mú láradá. Èyí tí í ṣe ẹ̀rí pé, ó ti rí ìwòsàn.” 45 Ṣùgbọ́n ó jáde lọ, ó bẹ̀rẹ̀ sí í pòkìkí, ó ń tan ìròyìn kálẹ̀. Nítorí èyí, Jesu kò sì le wọ ìlú ní gbangba mọ́, ṣùgbọ́n ó wà lẹ́yìn odi ìlú ní aginjù. Síbẹ̀, àwọn ènìyàn tọ̀ ọ́ wá láti ibi gbogbo.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.