M’Cheyne Bible Reading Plan
4 Nígbà tí gbogbo orílẹ̀-èdè náà kọjá nínú odò Jordani tan, Olúwa sọ fún Joṣua pé, 2 “Yan ọkùnrin méjìlá (12) nínú àwọn ènìyàn, ẹnìkan nínú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan, 3 kí o sì pàṣẹ fún wọn pé Ẹ gbé òkúta méjìlá láti àárín odò Jordani ní ibi tí àwọn àlùfáà dúró sí, kí ẹ sì rù wọn kọjá, kí ẹ sì gbé wọn sí ibi tí ẹ̀yin yóò sùn ní alẹ́ yìí.”
4 Bẹ́ẹ̀ ni Joṣua pe àwọn ọkùnrin méjìlá tí ó ti yàn nínú àwọn ọmọ Israẹli, ẹnìkan nínú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan, 5 ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ kọjá lọ ní iwájú àpótí ẹ̀rí Olúwa Ọlọ́run yín sí àárín odò Jordani. Kí olúkúlùkù yín gbé òkúta kọ̀ọ̀kan lé èjìká a rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí iye ẹ̀yà àwọn ọmọ Israẹli, 6 kí ó sì jẹ́ ààmì láàrín yín. Ní ọjọ́ iwájú, nígbà tí àwọn ọmọ yín bá béèrè lọ́wọ́ yín pé, ‘Kí ni òkúta wọ̀nyí dúró fún?’ 7 Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò dá wọn lóhùn pé, nítorí a gé omi odò Jordani kúrò ní iwájú àpótí ẹ̀rí Olúwa. Nígbà tí a rékọjá a Jordani, a gé omi Jordani kúrò. Àwọn òkúta wọ̀nyí yóò sì jẹ́ ìrántí fún àwọn ọmọ Israẹli láéláé.”
8 Báyìí ni àwọn ọmọ Israẹli sì ṣe bí Joṣua ti pàṣẹ fún wọn. Wọ́n gbé òkúta méjìlá láti àárín odò Jordani gẹ́gẹ́ bí iye ẹ̀yà àwọn ọmọ Israẹli, bí Olúwa ti sọ fún Joṣua; wọ́n sì rù wọ́n kọjá lọ sí ibùdó, ní ibi tí wọ́n ti gbé wọn kalẹ̀. 9 Joṣua sì to òkúta méjìlá náà sí àárín odò Jordani fún ìrántí ní ọ̀kánkán ibi tí àwọn àlùfáà tí ó ru àpótí ẹ̀rí dúró sí. Wọ́n sì wà níbẹ̀ di òní yìí.
10 Àwọn àlùfáà tí ó ru àpótí náà dúró ní àárín Jordani títí gbogbo nǹkan tí Olúwa pàṣẹ fún Joṣua fi di ṣíṣe nípasẹ̀ àwọn ènìyàn, gẹ́gẹ́ bí Mose ti pàṣẹ fún Joṣua. Àwọn ènìyàn náà sì yára kọjá, 11 bí gbogbo wọn sì ti rékọjá tán, ni àpótí ẹ̀rí Olúwa àti àwọn àlùfáà wá sí òdìkejì. Bí àwọn ènìyàn sì ti ń wò wọ́n. 12 Àwọn ọkùnrin Reubeni, Gadi àti ìdajì ẹ̀yà Manase náà sì rékọjá ní ìhámọ́ra ogun níwájú àwọn ọmọ Israẹli, gẹ́gẹ́ bí Mose ti pàṣẹ fún wọn. 13 Àwọn bí ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogójì (40,000) tó ti múra fún ogun rékọjá lọ ní iwájú Olúwa sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jeriko láti jagun.
14 Ní ọjọ́ náà ni Olúwa gbé Joṣua ga ní ojú gbogbo àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n sì bẹ̀rù u rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ ayé e wọn, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti bẹ̀rù Mose.
15 Olúwa sì sọ fún Joṣua pé, 16 “Pàṣẹ fún àwọn àlùfáà tí o ń ru àpótí ẹ̀rí, kí wọn kí ó jáde kúrò nínú odò Jordani.”
17 Bẹ́ẹ̀ ni Joṣua pàṣẹ fún àwọn àlùfáà pé, “Ẹ jáde kúrò nínú odò Jordani.”
18 Àwọn àlùfáà náà jáde láti inú odò pẹ̀lú àpótí ẹ̀rí Olúwa ni orí wọn. Bí wọ́n ti fi ẹsẹ̀ ẹ wọn tẹ orí ilẹ̀ gbígbẹ ni omi Jordani náà padà sí ààyè e rẹ̀, o sì kún wọ bèbè bí i ti àtẹ̀yìnwá.
19 Ní ọjọ́ kẹwàá oṣù kìn-ín-ní àwọn ènìyàn náà lọ láti Jordani, wọ́n sì dúró ní Gilgali ní ìlà-oòrùn Jeriko. 20 Joṣua sì to àwọn òkúta méjìlá tí wọ́n mú jáde ní Jordani jọ ní Gilgali. 21 Ó sì sọ fún àwọn ará Israẹli, “Ní ọjọ́ iwájú nígbà tí àwọn ọmọ yín bá béèrè ní ọwọ́ baba wọn pé, ‘Kín ni òkúta wọ̀nyí dúró fún?’ 22 Nígbà náà ni ẹ ó jẹ́ kí àwọn ọmọ yín mọ̀ pé, ‘Israẹli rékọjá odò Jordani ní orí ilẹ̀ gbígbẹ.’ 23 Nítorí Olúwa Ọlọ́run yín mú Jordani gbẹ ní iwájú u yín títí ẹ̀yin fi kọjá. Olúwa Ọlọ́run yín ti ṣe sí Jordani gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe sí Òkun Pupa, nígbà tí ó mú un gbẹ ní iwájú wa títí àwa fi kọjá. 24 Ó ṣe èyí kí gbogbo ayé lè mọ̀ pé ọwọ́ Olúwa ní agbára, àti kí ẹ̀yin kí ó lè máa bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run yín ní ìgbà gbogbo.”
Orin fún ìgòkè.
129 “Ìgbà púpọ̀ ni wọ́n ti pọ́n mi lójú
láti ìgbà èwe mi wá”
ni kí Israẹli kí ó wí nísinsin yìí;
2 “Ìgbà púpọ̀ ni wọ́n ti pọ́n mi lójú
láti ìgbà èwe mi wá;
síbẹ̀ wọn kò tí ì borí mi.
3 Àwọn awalẹ̀ walẹ̀ sí ẹ̀yìn mi:
wọ́n sì la aporo wọn gígùn.
4 Olódodo ni Olúwa:
ó ti ké okùn àwọn ènìyàn búburú kúrò.”
5 Kí gbogbo àwọn tí ó kórìíra Sioni kí ó dààmú,
kí wọn kí ó sì yí ẹ̀yìn padà.
6 Kí wọn kí ó dàbí koríko orí ilẹ̀
tí ó gbẹ dànù kí ó tó dàgbàsókè:
7 Èyí tí olóko pípa kó kún ọwọ́ rẹ̀:
bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ń di ìtí, kó kún apá rẹ̀.
8 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn tí ń kọjá lọ kò wí pé,
ìbùkún Olúwa kí ó pẹ̀lú yín:
àwa ń súre fún yin ní orúkọ Olúwa.
Orin fún ìgòkè.
130 Láti inú ibú wá ni
èmi ń ké pè é ọ́ Olúwa
2 Olúwa, gbóhùn mi,
jẹ́ kí etí rẹ kí o tẹ́ sílẹ̀ sí ohùn ẹ̀bẹ̀ mi.
3 (A)Olúwa, ìbá ṣe pé kí ìwọ máa sàmì ẹ̀ṣẹ̀,
Olúwa, tá ni ìbá dúró.
4 Nítorí ìdáríjì wà lọ́dọ̀ rẹ,
kí a lè máa bẹ̀rù rẹ.
5 Èmi dúró de Olúwa, ọkàn mi dúró,
àti nínú ọ̀rọ̀ rẹ ni èmi ń ṣe ìrètí
6 Ọkàn mi dúró de Olúwa,
ju àwọn tí ń ṣọ́nà òwúrọ̀ lọ,
àní ju àwọn tí ń ṣọ́nà òwúrọ̀ lọ.
7 Israẹli, ìwọ ní ìrètí ní ti Olúwa:
nítorí pé lọ́dọ̀ Olúwa ni àánú wà,
àti lọ́dọ̀ rẹ̀ ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìdáǹdè wà.
8 Òun ó sì dá Israẹli ní ìdè
kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ gbogbo.
Orin fún ìgòkè. Ti Dafidi.
131 Olúwa àyà mi kò gbéga,
bẹ́ẹ̀ ni ojú mi kò gbé sókè:
bẹ́ẹ̀ ni èmi kò fi ọwọ́ mi lé ọ̀ràn ńlá,
tàbí lé ohun tí ó ga jù mí lọ
2 Nítòótọ́ èmi mú ọkàn mi sinmi,
mo sì mú un dákẹ́ jẹ́ẹ́,
bí ọmọ tí a ti ọwọ́ ìyá rẹ̀ gbà ní ẹnu ọmú:
ọkàn mi rí gẹ́gẹ́ bí ọmọ tí a já ní ẹnu ọmú.
3 Israẹli, ìwọ ní ìrètí ní ti Olúwa
láti ìsinsin yìí lọ àti láéláé.
64 Ìwọ ìbá fa ọ̀run ya kí o sì sọ̀kalẹ̀ wá,
tí àwọn òkè ńlá yóò fi wárìrì níwájú rẹ!
2 Gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí iná mú ẹ̀ka igi jó
tí ó sì mú kí omi ó hó,
sọ̀kalẹ̀ wá kí orúkọ rẹ le di mí mọ̀ fún àwọn ọ̀tá rẹ
kí o sì jẹ́ kí àwọn orílẹ̀-èdè kí ó wárìrì níwájú rẹ!
3 Nítorí nígbà tí o bá ṣe àwọn ohun ẹ̀rù tí àwa kò nírètí,
o sọ̀kalẹ̀ wá, àwọn òkè ńlá sì wárìrì níwájú rẹ̀.
4 (A)Láti ìgbà àtijọ́ kò sí ẹni tí ó gbọ́ rí
kò sí etí kan tí ó gbọ́ ọ,
kò sí ojú tí ó tí ì rí Ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn rẹ,
tí ó máa ń ṣe nǹkan lórúkọ àwọn tí ó dúró dè é.
5 Ìwọ a máa wá fún ìrànlọ́wọ́ àwọn tí wọn
ń fi ayọ̀ ṣe ohun tó tọ́,
tí ó rántí ọ̀nà rẹ.
Ṣùgbọ́n nígbà tí a bẹ̀rẹ̀ sí dẹ́ṣẹ̀ sí wọn,
inú bí ọ.
Báwo ni a ó ṣe gbà wá là?
6 Gbogbo wa ti dàbí ẹnìkan tí ó jẹ́ aláìmọ́,
gbogbo òdodo wa sì dàbí èkísà ẹlẹ́gbin;
gbogbo wa kákò bí ewé,
àti bí afẹ́fẹ́, ẹ̀ṣẹ̀ wa ti gbá wa lọ kúrò.
7 Ẹnikẹ́ni kò pe orúkọ rẹ
tàbí kí ó gbìyànjú láti dì ẹ́ mú;
nítorí ìwọ ti fi ojú rẹ pamọ́ fún wa
ó sì jẹ́ kí àwa ṣòfò dànù nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa.
8 Síbẹ̀síbẹ̀, Olúwa, ìwọ ni Baba wa.
Àwa ni amọ̀, ìwọ ni amọ̀kòkò;
gbogbo wa jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.
9 Má ṣe bínú kọjá ààlà, ìwọ Olúwa:
Má ṣe rántí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wa títí láé.
Jọ̀wọ́, bojú wò wá, ni a gbàdúrà,
nítorí ènìyàn rẹ ni gbogbo wa.
10 Àwọn ìlú mímọ́ rẹ ti di aṣálẹ̀;
Sioni pàápàá di aṣálẹ̀, Jerusalẹmu di ahoro.
11 Tẹmpili mímọ́ ológo wa, níbi tí àwọn baba wa ti yìn ọ́,
ni a ti fi iná sun,
àti ohun gbogbo tí í ṣe ìṣúra wa ti dahoro.
12 Lẹ́yìn gbogbo nǹkan wọ̀nyí, Olúwa, ìwọ
ó ha sì tún fi ara rẹ pamọ́ bí?
Ìwọ ó ha dákẹ́ kí o sì fìyà jẹ wá kọjá ààlà bí?
Olúwa ọjọ́ ìsinmi
12 (A)(B) Ní àkókò náà ni Jesu ń la àárín oko ọkà kan lọ ní ọjọ́ ìsinmi, ebi sì ń pa àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí i ya orí ọkà, wọ́n sì ń jẹ ẹ́. 2 Nígbà tí àwọn Farisi rí èyí. Wọ́n wí fún pé, “Wò ó! Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ ń ṣe ohun tí kò bá òfin mu ní ọjọ́ ìsinmi.”
3 (C)Jesu dáhùn pé, “Ẹ̀yin kò ha ka ohun tí Dafidi ṣe nígbà tí ebi ń pa á àti àwọn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀. 4 Ó wọ inú ilé Ọlọ́run, òun àti àwọn ènìyàn rẹ̀ jẹ àkàrà tí a yà sọ́tọ̀, èyí tí kò yẹ fún wọn láti jẹ, bí kò ṣe fún àwọn àlùfáà nìkan. 5 Tàbí ẹ̀yin kò ti kà á nínú òfin pé ní ọjọ́ ìsinmi, àwọn àlùfáà tí ó wà ní tẹmpili ń ba ọjọ́ ìsinmi jẹ́ tí wọ́n sì wà láìjẹ̀bi. 6 Ṣùgbọ́n mo wí fún yín, ẹni tí ó pọ̀ ju tẹmpili lọ wà níhìn-ín. 7 Bí ó bá jẹ́ pé ẹ mọ ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ yìí, ‘Àánú ni èmi ń fẹ́ kì í ṣe ẹbọ,’ ẹ̀yin kì bá tí dá aláìlẹ́ṣẹ̀ lẹ́bi. 8 Nítorí pé Ọmọ Ènìyàn jẹ́ Olúwa ọjọ́ ìsinmi.”
9 (D)Nígbà tí Jesu kúrò níbẹ̀ ó lọ sí Sinagọgu wọn, 10 ọkùnrin kan tí ọwọ́ rẹ̀ kan rọ wà níbẹ̀. Wọ́n ń wá ọ̀nà láti fi ẹ̀sùn kan Jesu, wọ́n béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Ǹjẹ́ ó tọ́ láti mú ènìyàn láradá ní ọjọ́ ìsinmi?”
11 (E)Ó dá wọn lóhùn pé, “Bí ó bá jẹ́ wí pé bí ẹnikẹ́ni nínú yín bá ní àgùntàn kan ṣoṣo, tí ó sì bọ́ sínú kòtò ní ọjọ́ ìsinmi, ǹjẹ́ kì yóò dìímú, kí ó sì fà á jáde. 12 Ǹjẹ́ mélòó mélòó ní ènìyàn ní iye lórí ju àgùntàn kan lọ! Nítorí náà ó yẹ láti ṣe rere ní ọjọ́ ìsinmi.”
13 Nígbà náà, ó sì wí fún ọkùnrin náà pé, “Na ọwọ́ rẹ,” bí òun sì ti nà án, ọwọ́ rẹ̀ sì bọ̀ sí ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọwọ́ èkejì. 14 (F)Síbẹ̀ àwọn Farisi jáde lọ pe ìpàdé láti dìtẹ̀ mú un àti bí wọn yóò ṣe pa Jesu.
Ìránṣẹ́ tí Ọlọ́run yàn
15 (G)Nígbà tí Jesu sì mọ̀, ó yẹra kúrò níbẹ̀. Ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn sì ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, ó sì mú gbogbo àwọn aláìsàn láradá. 16 Ṣùgbọ́n ó kìlọ̀ fún wọn pé kí wọ́n kí ó má ṣe fi òun hàn. 17 Èyí jẹ́ ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ èyí tí wòlíì Isaiah sọ nípa rẹ̀ pé:
18 (H)“Ẹ wo ìránṣẹ́ mi ẹni tí mo yàn.
Àyànfẹ́ mi ni ẹni tí inú mi dùn sí gidigidi;
èmi yóò fi ẹ̀mí mi fún un.
Òun yóò sì ṣe ìdájọ́ àwọn kèfèrí.
19 Òun kì yóò jà, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò kígbe;
ẹnikẹ́ni kì yóò gbọ́ ohùn rẹ ní ìgboro.
20 Koríko odò títẹ̀ kan ni òun kì yóò fọ́,
àti òwú-fìtílà tí ń jó tan an lọ lòun kì yóò fẹ́ pa.
Títí yóò fi mú ìdájọ́ dé ìṣẹ́gun.
21 Ní orúkọ rẹ̀ ni gbogbo kèfèrí yóò fi ìrètí wọn sí.”
Jesu àti Beelsebulu
22 (I)(J) Nígbà náà ni wọ́n mú ọkùnrin kan tó ni ẹ̀mí èṣù tọ̀ ọ́ wá, tí ó afọ́jú, tí ó tún ya odi. Jesu sì mú un láradá kí ó le sọ̀rọ̀, ó sì ríran. 23 Ẹnu sì ya gbogbo àwọn ènìyàn. Wọ́n wí pé, “Èyí ha lè jẹ́ Ọmọ Dafidi bí?”
24 (K)Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn Farisi gbọ́ èyí, wọ́n wí pé, “Nípa Beelsebulu nìkan, tí í ṣe ọba ẹ̀mí èṣù ni ọkùnrin yìí fi lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde.”
25 Jesu tí ó mọ èrò wọn, ó wí fún wọn pé, “Ìjọbakíjọba tí ó bá yapa sí ara rẹ̀ yóò parun, ìlúkílùú tàbí ilékílé tí ó bá yapa sí ara rẹ̀ kì yóò dúró. 26 Bí èṣù bá sì ń lé èṣù jáde, a jẹ́ wí pé, ó ń yapa sí ara rẹ̀. Ìjọba rẹ yóò ha ṣe le dúró? 27 Àti pé, bi èmi bá ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde nípa Beelsebulu, nípa ta ni àwọn ènìyàn yín fi ń lé wọn jáde? Nítorí náà ni wọn yóò ṣe má ṣe ìdájọ́ yín. 28 Ṣùgbọ́n bí ó bá jẹ́ pé nípa Ẹ̀mí Ọlọ́run ni èmi fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde, a jẹ́ pé ìjọba Ọlọ́run ti dé bá yín.
29 “Tàbí, báwo ni ẹnikẹ́ni ṣe lè wọ ilé alágbára lọ kí ó sì kó ẹrù rẹ̀, bí kò ṣe pé ó kọ́kọ́ di alágbára náà? Nígbà náà ni ó tó lè kó ẹrù rẹ̀ lọ.
30 (L)“Ẹni tí kò bá wà pẹ̀lú mi, òun lòdì sí mi, ẹni tí kò bá mi kójọpọ̀ ń fọ́nká. 31 Nítorí èyí, mo wí fún yín, gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ àti ọ̀rọ̀-òdì ni a yóò dárí rẹ̀ jí ènìyàn, ṣùgbọ́n ìṣọ̀rọ̀-òdì-sí Ẹ̀mí Mímọ́ kò ní ìdáríjì. 32 Ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ̀rọ̀-òdì sí Ọmọ ènìyàn, a ó dáríjì í, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá sọ ọ̀rọ̀-òdì sí ẹ̀mí mímọ́, a kì yóò dáríjì í, ìbá à ṣe ní ayé yìí tàbí ní ayé tí ń bọ̀.
33 (M)“E sọ igi di rere, èso rẹ̀ a sì di rere tàbí kí ẹ sọ igi di búburú, èso rẹ a sì di búburú, nítorí nípa èso igi ni a ó fi mọ̀ igi. 34 Ẹ̀yin ọmọ paramọ́lẹ̀, báwo ni ẹ̀yin tí ẹ jẹ búburú ṣe lè sọ̀rọ̀ rere? Ọkàn ènìyàn ni ó ń darí irú ọ̀rọ̀ tí ó lè jáde lẹ́nu rẹ̀. 35 Ẹni rere láti inú yàrá ìṣúra rere ọkàn rẹ̀ ní mú ohun rere jáde wá: àti ẹni búburú láti inú ìṣúra búburú ni; mu ohun búburú jáde wá. 36 Ṣùgbọ́n, mo sọ èyí fún yín, ẹ̀yin yóò jíyìn gbogbo ìsọkúsọ yín ní ọjọ́ ìdájọ́. 37 Nítorí nípa ọ̀rọ̀ ẹnu yín ni a fi dá yin láre, nípa ọ̀rọ̀ ẹnu yín sì ni a ó fi dá yin lẹ́bi.”
Ààmì Jona
38 (N)Nígbà náà ni, díẹ̀ nínú àwọn Farisi àti àwọn olùkọ́ òfin wí fún pé “Olùkọ́, àwa fẹ́ rí iṣẹ́ ààmì kan lọ́dọ̀ rẹ̀”.
39 Ó sì dá wọn lóhùn wí pé “Ìran búburú àti ìran panṣágà ń béèrè ààmì; ṣùgbọ́n kò sí ààmì tí a ó fi fún un, bí kò ṣe ààmì Jona wòlíì. 40 Bí Jona ti gbé inú ẹja ńlá fún ọ̀sán mẹ́ta àti òru mẹ́ta, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ẹ̀mí Ọmọ Ènìyàn yóò gbé ní inú ilẹ̀ fún ọ̀sán mẹ́ta àti òru mẹ́ta. 41 Àwọn ará Ninefe yóò dìde pẹ̀lú ìran yìí ní ọjọ́ ìdájọ́. Wọn yóò sì dá a lẹ́bi. Nítorí pé wọ́n ronúpìwàdà nípa ìwàásù Jona. Ṣùgbọ́n báyìí ẹni tí ó pọ̀jù Jona wà níhìn-ín yìí. 42 Ọbabìnrin gúúsù yóò sì dìde ní ọjọ́ ìdájọ́ sí ìran yìí yóò sì dá a lẹ́bi; nítorí tí ó wá láti ilẹ̀ ìkangun ayé láti gbọ́ ọ̀rọ̀ ọgbọ́n láti ẹnu Solomoni. Ṣùgbọ́n báyìí ẹni tí ó pọ̀jù Solomoni ń bẹ níhìn-ín yìí.
43 (O)“Nígbà tí ẹ̀mí búburú kan bá jáde lára ènìyàn, a máa rìn ní ibi gbígbẹ́, a máa wá ibi ìsinmi, kò sì ní rí i. 44 Nígbà náà ni ẹ̀mí náà yóò wí pé, ‘Èmi yóò padà sí ara ọkùnrin tí èmí ti wá.’ Bí ó bá sì padà, tí ó sì bá ọkàn ọkùnrin náà ni òfìfo, a gbà á mọ́, a sì ṣe é ní ọ̀ṣọ́. 45 Nígbà náà ni yóò lọ, yóò sì mú ẹ̀mí méje mìíràn pẹ̀lú ara rẹ̀, tí ó burú ju òun fúnra rẹ̀ lọ. Gbogbo wọn yóò sì wá sí inú rẹ̀, wọn yóò máa gbé ibẹ̀. Ìgbẹ̀yìn ọkùnrin náà a sì burú ju ìṣáájú rẹ̀ lọ; Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni yóò rí fún ìran búburú yìí pẹ̀lú.”
Ìyá Jesu àti àwọn arákùnrin rẹ̀
46 (P)(Q) Nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún àwọn ènìyàn, wò ó, ìyá rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ dúró lóde, wọ́n fẹ́ bá a sọ̀rọ̀. 47 Nígbà náà ni ẹnìkan wí fún un pé, “Ìyá rẹ àti àwọn arákùnrin rẹ ń dúró dè ọ́ lóde wọ́n ń fẹ́ bá ọ sọ̀rọ̀.”
48 Ó sì fún ni èsì pé, “Ta ni ìyá mi? Ta ni àwọn arákùnrin mi?” 49 Ó nawọ́ sí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó wí pé, “Wò ó, ìyá mi àti àwọn arákùnrin mi ni wọ̀nyí.” 50 (R)Nítorí náà, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe ìfẹ́ Baba mi tí ń bẹ ní ọ̀run, ni arákùnrin mi àti arábìnrin mi àti ìyá mi.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.