M’Cheyne Bible Reading Plan
6 Bẹ́ẹ̀ ni Joṣua ọmọ Nuni pe àwọn àlùfáà ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa náà kí àwọn àlùfáà méje tí ó ru fèrè ìwo wà ní iwájú u rẹ̀.” 7 Ó sì pàṣẹ fún àwọn ènìyàn náà pé, “Ẹ lọ, kí ẹ sì yí ìlú náà ká pẹ̀lú àwọn olùṣọ́ tí ó hámọ́ra kọjá ní iwájú àpótí ẹ̀rí Olúwa.”
8 Nígbà tí Joṣua ti bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ tán, àwọn àlùfáà méje tí wọ́n gbé fèrè méje ní iwájú Olúwa kọjá sí iwájú, wọ́n sì fọn fèrè wọn, àpótí ẹ̀rí Olúwa sì tẹ̀lé wọn. 9 Àwọn olùṣọ tí ó hámọ́ra sì lọ níwájú àwọn àlùfáà tí ń fọn fèrè, olùṣọ́ ẹ̀yìn sì tẹ̀lé àpótí ẹ̀rí náà. Ní gbogbo àsìkò yìí fèrè sì ń dún. 10 Ṣùgbọ́n Joṣua tí pàṣẹ fún àwọn ènìyàn pé, “Ẹ kò gbọdọ̀ kígbe ogun, ẹ kò gbọdọ̀ gbé ohùn yín sókè, ẹ má ṣe sọ ọ̀rọ̀ kan títí ọjọ́ tí èmi yóò sọ fún un yín pé kí ẹ hó. Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò sì hó!” 11 Bẹ́ẹ̀ ni ó mú kí àpótí ẹ̀rí Olúwa yí ìlú náà ká, ó sì yí i ká lẹ́ẹ̀kan. Nígbà náà ni àwọn ènìyàn náà padà sí ibùdó, wọ́n sì gbé ibẹ̀ fún alẹ́ náà.
12 Joṣua sì dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, àwọn àlùfáà sì gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa. 13 Àwọn àlùfáà méje tí ó gbé ìpè ìwo àgbò méje ń lọ níwájú àpótí ẹ̀rí Olúwa, wọ́n sì ń fọ́n àwọn ìpè: àwọn tí ó hámọ́ra ogun ń lọ níwájú u wọn; àwọn ọmọ tó wà lẹ́yìn sì ń tọ àpótí ẹ̀rí Olúwa lẹ́yìn, àwọn àlùfáà sì ń fọn ìpè bí wọ́n ti ń lọ. 14 Ní ọjọ́ kejì, wọ́n yí ìlú náà ká lẹ́ẹ̀kan wọ́n sì padà sí ibùdó. Wọ́n sì ṣe èyí fún ọjọ́ mẹ́fà.
15 Ní ọjọ́ keje, wọ́n dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ní àfẹ̀mọ́júmọ́, wọ́n sì wọ́de ogun yí ìlú náà ká ní ìgbà méje, gẹ́gẹ́ bí i ti ìṣáájú, ní ọjọ́ keje nìkan ṣoṣo ni wọ́n wọ́de ogun yí ìlú náà ká nígbà méje. 16 Ní ìgbà keje, nígbà tí àwọn àlùfáà fọn fèrè, Joṣua pàṣẹ fún àwọn ènìyàn pé, “Ẹ hó! Nítorí pé Olúwa ti fún un yín ní ìlú náà. 17 Ìlú náà àti gbogbo ohun tí ó wà níbẹ̀ ni yóò jẹ́ ìyàsọ́tọ̀ fún Olúwa. Rahabu tí ó jẹ́ panṣágà nìkan àti gbogbo àwọn tí ó wà pẹ̀lú u rẹ̀ ni a ó dá sí; nítorí tí ó pa àwọn ayọ́lẹ̀wò tí á rán mọ́. 18 Ẹ pa ara yín mọ́ kúrò nínú ohun ìyàsọ́tọ̀ fún ìparun, kí ẹ̀yin kí ó má ba à ṣojú kòkòrò nípa mímú nínú àwọn ohun ìyàsọ́tọ̀. Bí kò ṣe bẹ́ẹ̀ ẹ ó sọ ibùdó Israẹli di ìparun. Kí ẹ sì mú wàhálà wá sórí i rẹ̀. 19 Gbogbo fàdákà àti wúrà àti ohun èlò idẹ àti irin jẹ́ mímọ́ fún Olúwa, wọ́n yóò wá sínú ìṣúra Olúwa.”
20 Nígbà tí àwọn àlùfáà fọn ìpè, àwọn ènìyàn náà sì hó. Ó sì ṣe, bí àwọn ènìyàn ti gbọ́ ìró ìpè, tí àwọn ènìyàn sì hó ìhó ńlá, odi ìlú náà wó lulẹ̀ bẹẹrẹ; bẹ́ẹ̀ ni olúkúlùkù ya wọ inú ìlú náà lọ tààrà, wọ́n sì kó ìlú náà. 21 Wọ́n ya ìlú náà sọ́tọ̀ fún Olúwa àti fún ìparun, wọ́n sì fi idà run gbogbo ohun alààyè ní ìlú náà—ọkùnrin àti obìnrin, ọ́mọdé, àti àgbà, màlúù, àgùntàn àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.
22 Joṣua sì sọ fún àwọn ọkùnrin méjì tí wọ́n ti wá ṣe ayọ́lẹ̀wò ilẹ̀ náà pé, “Ẹ lọ sí ilé panṣágà nì, kí ẹ sì mu jáde àti gbogbo ohun tí í ṣe tirẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ tí búra fún un.” 23 Bẹ́ẹ̀ ní àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin tí ó lọ ṣe ayọ́lẹ̀wò wọlé lọ, wọ́n sì mú Rahabu jáde, baba rẹ̀, ìyá rẹ̀, àwọn arákùnrin rẹ̀ àti ohun gbogbo tí ó ní. Wọ́n sì mú gbogbo ìdílé rẹ̀ jáde, wọ́n sì fi wọ́n sí ibìkan ní ìta ibùdó àwọn ará Israẹli.
24 Nígbà náà ni wọ́n sun gbogbo ìlú náà àti gbogbo ohun tí ó wà nínú u rẹ̀, ṣùgbọ́n wọ́n fi fàdákà, wúrà ohun èlò idẹ àti irin sínú ìṣúra ilé Olúwa. 25 Ṣùgbọ́n Joṣua dá Rahabu panṣágà pẹ̀lú gbogbo ìdílé e rẹ̀ àti gbogbo ẹni tí í ṣe tirẹ̀ sí nítorí pé, ó pa àwọn ọkùnrin tí Joṣua rán gẹ́gẹ́ bí ayọ́lẹ̀wò sí Jeriko mọ́. Ó sì ń gbé láàrín ará Israẹli títí di òní yìí.
26 (A)Ní àkókò náà Joṣua sì búra pé; “Ègún ni fún ẹni náà níwájú Olúwa tí yóò dìde, tí yóò sì tún ìlú Jeriko kọ́:
“Pẹ̀lú ikú àkọ́bí ọmọ rẹ̀ ni
yóò fi pilẹ̀ rẹ̀;
ikú àbíkẹ́yìn rẹ̀ ní yóò fi
gbé ìlẹ̀kùn bodè rẹ̀ ró.”
27 Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa wà pẹ̀lú Joṣua; òkìkí rẹ̀ sì kàn ká gbogbo ilẹ̀ náà.
135 Ẹ yin Olúwa.
Ẹ yin orúkọ Olúwa;
ẹ yìn ín, ẹ̀yin ìránṣẹ́ Olúwa.
2 Ẹ̀yin tí ń dúró ní ilé Olúwa,
nínú àgbàlá ilé Ọlọ́run wa.
3 Ẹ yin Olúwa: nítorí tí Olúwa ṣeun;
ẹ kọrin ìyìn sí orúkọ rẹ̀; nítorí tí ó dùn.
4 Nítorí tí Olúwa ti yan Jakọbu fún ara rẹ̀;
àní Israẹli fún ìṣúra ààyò rẹ̀.
5 Nítorí tí èmi mọ̀ pé Olúwa tóbi,
àti pé Olúwa jù gbogbo òrìṣà lọ.
6 Olúwa ṣe ohunkóhun tí ó wù ú,
ní ọ̀run àti ní ayé,
ní Òkun àti ní ọ̀gbun gbogbo.
7 Ó mú ìkùùkuu gòkè láti òpin ilẹ̀ wá:
ó dá mọ̀nàmọ́ná fún òjò:
ó ń mú afẹ́fẹ́ ti inú ilẹ̀ ìṣúra rẹ̀ wá.
8 Ẹni tí ó kọlu àwọn àkọ́bí Ejibiti,
àti ti ènìyàn àti ti ẹranko.
9 Ẹni tí ó rán iṣẹ́ ààmì àti iṣẹ́ ìyanu sí àárín rẹ̀, ìwọ Ejibiti,
sí ara Farao àti sí ara àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ gbogbo.
10 Ẹni tí ó kọlu àwọn orílẹ̀-èdè púpọ̀,
tí ó sì pa àwọn alágbára ọba.
11 Sihoni, ọba àwọn ará Amori, àti Ogu,
ọba Baṣani, àti gbogbo ìjọba Kenaani:
12 Ó sì fi ilẹ̀ wọn fún ni ní ìní,
ìní fún Israẹli, ènìyàn rẹ̀.
13 Olúwa orúkọ rẹ dúró láéláé;
ìrántí rẹ Olúwa, láti ìrandíran.
14 (A)Nítorí tí Olúwa yóò ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀,
yóò sì ṣe ìyọ́nú sí àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀.
15 Fàdákà òun wúrà ni èrè àwọn aláìkọlà,
iṣẹ́ ọwọ́ ènìyàn ni.
16 Wọ́n ní ẹnu, ṣùgbọ́n wọn kò le sọ̀rọ̀;
wọ́n ní ojú, ṣùgbọ́n wọn kò fi ríran.
17 Wọ́n ní etí, ṣùgbọ́n wọn kò fi gbọ́rọ̀;
bẹ́ẹ̀ ni kò si èémí kan ní ẹnu wọn
18 Àwọn tí ń ṣe wọ́n dàbí wọn:
gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni olúkúlùkù ẹni tí ó gbẹ́kẹ̀ rẹ̀ lé wọn.
19 Ẹ̀yin ara ilé Israẹli, ẹ fi ìbùkún fún Olúwa,
ẹ̀yin ará ilé Aaroni, fi ìbùkún fún Olúwa.
20 Ẹ̀yin ará ilé Lefi, fi ìbùkún fún Olúwa;
ẹ̀yin tí ó bẹ̀rù Olúwa, fi ìbùkún fún Olúwa.
21 Olùbùkún ni Olúwa, láti Sioni wá,
tí ń gbé Jerusalẹmu.
Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.
136 Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa nítorí tí ó ṣeun;
nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
2 Ẹ fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run àwọn ọlọ́run:
nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
3 Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa àwọn olúwa,
nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
4 Fún Òun nìkan tí ń ṣiṣẹ́ ìyanu ńlá;
nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
5 Fún ẹni tí ó fi ọgbọ́n dá ọ̀run;
nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
6 (B)Fún ẹni tí ó tẹ́ ilẹ̀ lórí omi;
nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
7 (C)Fún ẹni tí ó dá àwọn ìmọ́lẹ̀ ńlá;
nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
8 Òòrùn láti jẹ ọba ọ̀sán;
nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
9 Òṣùpá àti ìràwọ̀ láti jẹ ọba òru;
nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
10 (D)Fún ẹni tí ó kọlu Ejibiti lára àwọn àkọ́bí wọn;
nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
11 (E)Ó sì mú Israẹli jáde kúrò láàrín wọn;
nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
12 Pẹ̀lú ọwọ́ agbára àti apá nínà;
nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
13 (F)Fún ẹni tí ó pín Òkun pupa ní ìyà;
nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
14 Ó sì mú Israẹli kọjá láàrín rẹ̀
nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
15 Ṣùgbọ́n ó bi Farao àti ogun rẹ̀ ṣubú nínú Òkun pupa;
nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
16 Fún ẹni tí ó sin àwọn ènìyàn rẹ̀ la aginjù já
nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
17 Fún ẹni tí ó kọlu àwọn ọba ńlá;
nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
18 Ó sì pa àwọn ọba olókìkí
nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
19 Sihoni, ọba àwọn ará Amori
nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
20 Àti Ogu, ọba Baṣani;
nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
21 Ó sì fi ilẹ̀ wọn fún ni ní ìní,
nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
22 Ìní fún Israẹli, ìránṣẹ́ rẹ̀,
nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
23 Ẹni tí ó rántí wa ní ìwà ìrẹ̀lẹ̀ wa;
nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
24 Ó sì dá wa ní ìdè lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa;
nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
25 Ẹni tí ó fi oúnjẹ fún àwọn ẹ̀dá gbogbo
nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
26 Ẹ fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run ọ̀run;
nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
Ìdájọ́ àti ìrètí
66 (A)Báyìí ni Olúwa wí:
“Ọ̀run ni ìtẹ́ mi,
ayé sì ni àpótí ìtìsẹ̀ mi,
Níbo ni ilé tí ẹ ó kọ́ fún mi wà?
Níbo ní ibi ìsinmi mi yóò gbé wà?
2 Kì í ha á ṣe ọwọ́ mi ló tí ṣe nǹkan wọ̀nyí,
bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì wà?”
ni Olúwa wí.
“Eléyìí ni ẹni tí mo kà sí:
ẹni náà tí ó rẹra rẹ̀ sílẹ̀ tí ó sì kẹ́dùn ní ọkàn rẹ̀,
tí ó sì wárìrì sí ọ̀rọ̀ mi.
3 Ṣùgbọ́n ẹni tí ó fi akọ màlúù rú ẹbọ
ó dàbí ẹni tí ó pa ènìyàn kan
àti ẹni tí ó bá fi ọ̀dọ́-àgùntàn kan tọrẹ,
dàbí ẹni tí ó bẹ́ ajá kan lọ́rùn;
ẹnikẹ́ni tí ó bá fi irúgbìn ìyẹ̀fun tọrẹ
dàbí ẹni tí ó mú ẹ̀jẹ̀ ẹlẹ́dẹ̀ wá,
ẹni tí ó bá sì sun tùràrí ìrántí,
dàbí ẹni tí ó súre fún òrìṣà.
Wọ́n ti yan ipa ọ̀nà tì wọ́n,
ọkàn wọn pẹ̀lú sì láyọ̀ nínú ohun ìríra wọn;
4 Fún ìdí èyí ni èmi pẹ̀lú yóò ṣe fi ọwọ́ líle mú wọn
n ó sì mú ohun tí wọ́n bẹ̀rù rẹ̀ wá sórí wọn.
Nítorí nígbà tí mo pè, kò sí ẹni tí ó dáhùn,
nígbà tí mo sọ̀rọ̀, ẹnikẹ́ni kò tẹ́tí sílẹ̀.
Wọ́n ṣe ohun búburú ní ojú mi
wọ́n sì yan ohun tí mo kórìíra rẹ̀.”
5 Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa,
Ẹ̀yin tí ẹ ń wárìrì nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀:
“Àwọn arákùnrin yín tí wọ́n kórìíra yín,
tí wọ́n ta yín nù nítorí orúkọ mi, wí pé,
‘Jẹ́ kí a yin Olúwa lógo,
kí a le rí ayọ̀ yín!’
Ṣùgbọ́n àwọn ni ojú yóò tì.
6 (B)Gbọ́ rògbòdìyàn láti ìlú wá,
gbọ́ ariwo náà láti tẹmpili wá!
Ariwo tí Olúwa ní í ṣe
tí ó ń san án fún àwọn ọ̀tá rẹ̀ ohun
tí ó tọ́ sí wọn.
7 (C)“Kí ó tó lọ sí ìrọbí,
ó ti bímọ;
kí ó tó di pé ìrora dé bá a,
ó ti bí ọmọkùnrin.
8 Ta ni ó ti gbọ́ irú nǹkan bẹ́ẹ̀ rí?
Ta ni ó ti rí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ rí?
Ǹjẹ́ a le bí orílẹ̀-èdè kan níjọ́ kan
tàbí kí orílẹ̀-èdè lalẹ̀hù ní ìṣẹ́jú kan?
Síbẹ̀síbẹ̀ Sioni bẹ̀rẹ̀ rírọbí
bẹ́ẹ̀ ni ó sì bí àwọn ọmọ rẹ̀.
9 Ǹjẹ́ èmi a ha máa mú wá sí ìrọbí
kí èmi má sì mú ni bí?”
ni Olúwa wí.
“Ǹjẹ́ èmi a ha máa ṣé ilé ọmọ
nígbà tí mo ń mú ìbí wá?”
Ni Ọlọ́run yín wí.
10 “Ẹ bá Jerusalẹmu yọ̀ kí inú yín kí ó sì dùn sí i,
gbogbo ẹ̀yin tí ẹ fẹ́ràn rẹ̀;
ẹ yọ̀ gidigidi pẹ̀lú rẹ̀,
gbogbo ẹ̀yin tí ó ti kẹ́dùn fún un.
11 Nítorí pé ẹ̀yin yóò mu ẹ o sì ní ìtẹ́lọ́rùn
nínú ọmú rẹ̀ tí ó tu ni lára;
Ẹ̀yin yóò mu àmuyó
ẹ ó sì gbádùn nínú àkúnwọ́sílẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ rẹ̀.”
12 Nítorí báyìí ni Olúwa wí:
“Èmi yóò fún un ní àlàáfíà gẹ́gẹ́ bí odò
àti ọrọ̀ orílẹ̀-èdè gẹ́gẹ́ bí ìṣàn omi;
ẹ̀yin yóò mu ọmú, a ó sì gbé yín ní apá rẹ̀
a ó bá yín ṣeré ní orúkún rẹ̀.
13 Gẹ́gẹ́ bí ìyá ti í tu ọmọ rẹ̀ nínú,
bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò tù yín nínú
a ó sì tù yín nínú lórí Jerusalẹmu.”
14 Nígbà tí ẹ bá rí èyí, inú yín yóò dùn
ẹ̀yin yóò sì gbilẹ̀ gẹ́gẹ́ bí i koríko;
ọwọ́ Olúwa ni a ó sọ di mí mọ̀ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀,
ṣùgbọ́n ìbínú rẹ̀ ni a ó fihàn fún àwọn ọ̀tá rẹ̀.
15 Kíyèsi i, Olúwa ń bọ̀ pẹ̀lú iná
àti kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ tí ó dàbí ìjì líle;
òun yóò mú ìbínú rẹ sọ̀kalẹ̀ pẹ̀lú ìrunú,
àti ìbáwí rẹ̀ pẹ̀lú ahọ́n iná.
16 Nítorí pẹ̀lú iná àti idà
ni Olúwa yóò ṣe ìdájọ́ lórí i gbogbo ènìyàn,
àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn tí Olúwa yóò pa.
17 “Gbogbo àwọn tí wọ́n ya ara wọn sí mímọ́ tí wọ́n sì sọ ara wọn di mímọ́ láti lọ sínú ọgbà, tí wọ́n tẹ̀lé ẹni tí ó wà láàrín àwọn tí ó jẹ ẹran ẹlẹ́dẹ̀ àti èkúté àti àwọn ohun ìríra mìíràn ni wọn yóò bá òpin wọn pàdé papọ̀,” ni Olúwa wí.
18 “Àti Èmi, nítorí ìgbésẹ̀ wọn àti èrò wọn, èmi ti múra tán láti wá kó àwọn orílẹ̀-èdè àti ahọ́n jọ, wọn yóò sì wá wo ògo mi.
19 “Èmi yóò sì gbé ààmì kan kalẹ̀ láàrín wọn, èmi yóò sì rán díẹ̀ nínú àwọn tí ó sálà lọ sí àwọn orílẹ̀-èdè Tarṣiṣi, sí àwọn ará Libia àti Ludi, sí Tubali àti ará Giriki, àti sí àwọn erékùṣù tí ó jìnnà réré tí kò tí ìgbọ́ nípa òkìkí mi tàbí kí ó rí ògo mi. Wọn yóò kéde ògo mi láàrín àwọn orílẹ̀-èdè. 20 Wọn yóò sì mú àwọn arákùnrin yín wá, láti gbogbo orílẹ̀-èdè, sí òkè mímọ́ mi ní Jerusalẹmu gẹ́gẹ́ bí ọrẹ sí Olúwa lórí ẹṣin, lórí kẹ̀kẹ́ ẹrù àti ọkọ-ẹṣin, àti lórí ìbáaka àti ìbákasẹ,” ni Olúwa wí. “Wọn yóò kó wọn wá, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ Israẹli ti mú ọrẹ oníhóró wọn wá, sínú Tẹmpili Olúwa nínú ohun èlò mímọ́. 21 Àti pé èmi yóò sì yan àwọn kan nínú wọn pẹ̀lú láti jẹ́ àlùfáà àti Lefi,” ni Olúwa wí.
22 (D)“Gẹ́gẹ́ bí àwọn ọ̀run tuntun àti ayé tuntun tí mo dá yóò ṣe wà níwájú mi títí láé,” ni Olúwa wí, “Bẹ́ẹ̀ ni orúkọ yín àti ìrandíran yín yóò pegedé. 23 Láti oṣù tuntun kan dé òmíràn àti láti ọjọ́ ìsinmi kan dé òmíràn, ni gbogbo ọmọ ènìyàn yóò wá, wọn yóò sì tẹríba níwájú mi,” ni Olúwa wí. 24 (E)“Wọn yóò sì jáde lọ wọn yóò sì lọ wo òkú àwọn tí wọ́n dìtẹ̀ sí mi; kòkòrò wọn kì yóò kú, bẹ́ẹ̀ ni iná wọn ni a kì yóò pa, bẹ́ẹ̀ ni wọn yóò sì jẹ́ ohun ìríra fún gbogbo ọmọ ènìyàn.”
A bẹ́ Johanu Onítẹ̀bọmi lórí
14 (A)Ní àkókò náà ni Herodu ọba tetrarki gbọ́ nípa òkìkí Jesu, 2 ó wí fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé, “Dájúdájú Johanu onítẹ̀bọmi ni èyí, ó jíǹde kúrò nínú òkú. Ìdí nìyí tí ó fi ní agbára láti ṣiṣẹ́ ìyanu wọ̀nyí.”
3 (B)Nísinsin yìí Herodu ti mú Johanu, ó fi ẹ̀wọ̀n dè é, ó sì fi sínú túbú, nítorí Herodia aya Filipi arákùnrin rẹ̀, 4 nítorí Johanu onítẹ̀bọmi ti sọ fún Herodu pé, “Kò yẹ fún ọ láti fẹ́ obìnrin náà.” 5 (C)Herodu fẹ́ pa Johanu, ṣùgbọ́n ó bẹ̀rù àwọn ènìyàn nítorí gbogbo ènìyàn gbàgbọ́ pé wòlíì ni.
6 Ní ọjọ́ àsè ìrántí ọjọ́ ìbí Herodu, ọmọ Herodia obìnrin jó dáradára, ó sì tẹ́ Herodu lọ́run gidigidi. 7 Nítorí náà ni ó ṣe fi ìbúra ṣe ìlérí láti fún un ní ohunkóhun ti ó bá béèrè fún. 8 Pẹ̀lú ìmọ̀ràn láti ọ̀dọ̀ ìyá rẹ̀, ó béèrè pé, “Fún mi ni orí Johanu onítẹ̀bọmi nínú àwopọ̀kọ́”. 9 Inú ọba bàjẹ́ gidigidi, ṣùgbọ́n nítorí ìbúra rẹ̀ àti kí ojú má ba à tì í níwájú àwọn àlejò tó wà ba jẹ àsè, ó pàṣẹ pé kí wọ́n fún un gẹ́gẹ́ bí o ti fẹ́. 10 Nítorí náà, a bẹ́ orí Johanu onítẹ̀bọmi nínú ilé túbú. 11 A sì gbé orí rẹ̀ jáde láti fi fún ọmọbìnrin náà nínú àwopọ̀kọ́, òun sì gbà á, ó gbé e tọ ìyá rẹ̀ lọ. 12 Lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu wá gba òkú rẹ̀, wọ́n sì sin ín. Wọ́n sì wá sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún Jesu.
Jesu bọ́ ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ènìyàn
13 (D)Nígbà tí Jesu gbọ́ ìròyìn ìṣẹ̀lẹ̀ náà, ó kúrò níbẹ̀, ó bá ọkọ̀ ojú omi lọ sí ibi kọ́lọ́fín kan ní èbúté láti dá wà níbẹ̀. Nígbà tí wọ́n gbọ́ èyí, ọ̀pọ̀ ènìyàn sì fi ẹsẹ̀ rìn tẹ̀lé e láti ọ̀pọ̀ ìlú wọn. 14 Nígbà ti Jesu gúnlẹ̀, tí ó sì rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, inú rẹ̀ yọ́ sí wọn, ó sì mú àwọn aláìsàn láradá.
15 Nígbà ti ilẹ̀ ń ṣú lọ, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá, wọ́n sì wí pé, “Ibi yìí jìnnà sí ìlú ilẹ̀ sì ń ṣú lọ. Rán àwọn ènìyàn lọ sí àwọn ìletò kí wọ́n lè ra oúnjẹ jẹ.”
16 Ṣùgbọ́n Jesu fèsì pé, “Kò nílò kí wọ́n lọ kúrò. Ẹ fún wọn ní oúnjẹ.”
17 Wọ́n sì dalóhùn pé, “Àwa kò ní ju ìṣù àkàrà márùn-ún àti ẹja méjì lọ níhìn-ín.”
18 Ó wí pé, “Ẹ mú wọn wá fún mi níhìn-ín yìí.” 19 (E)Lẹ́yìn náà, ó wí fún àwọn ènìyàn kí wọ́n jókòó lórí koríko. Lẹ́yìn náà, ó mú ìṣù àkàrà márùn-ún àti ẹja méjì. Ó gbé ojú rẹ̀ sí ọ̀run. Ó béèrè ìbùkún Ọlọ́run lórí oúnjẹ náà, Ó sì bù ú, ó sì fi àkàrà náà fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn láti pín in fún àwọn ènìyàn. 20 Gbogbo wọn sì jẹ àjẹyó. Lẹ́yìn náà àwọn ọmọ-ẹ̀yìn kó àjẹkù jọ, ó kún agbọ̀n méjìlá. 21 Iye àwọn ènìyàn ni ọjọ́ náà jẹ́ ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (5,000) ọkùnrin, Láìka àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé.
Jesu rìn lójú omi
22 (F)Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ lẹ́yìn èyí, Jesu wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ kí wọ́n bọ sínú ọkọ̀ wọn, àti kí wọ́n máa kọjá lọ ṣáájú rẹ̀ sí òdìkejì. Òun náà dúró lẹ́yìn láti tú àwọn ènìyàn ká lọ sí ilé wọn 23 Lẹ́yìn tí ó tú ìjọ ènìyàn ká tán, ó gun orí òkè lọ fúnrarẹ̀ láti lọ gba àdúrà. Nígbà tí ilẹ̀ ṣú, òun wà nìkan níbẹ̀, 24 (G)ní àkókò yìí ọkọ̀ ojú omi náà ti rin jìnnà sí etí bèbè Òkun, tí ìjì omi ń tì í síwá sẹ́yìn, nítorí ìjì ṣe ọwọ́ òdì sí wọn.
25 Ní déédé ago mẹ́rin òwúrọ̀, Jesu tọ̀ wọ́n wá, ó ń rìn lórí omi. 26 (H)Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rí i tí ó ń rìn lójú omi, ẹ̀rù ba wọn gidigidi, wọ́n rò pé “iwin ni” wọ́n kígbe tìbẹ̀rù tìbẹ̀rù.
27 Lójúkan náà, Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ mú ọkàn le! Èmi ni ẹ má ṣe bẹ̀rù.”
28 Peteru sì ké sí i pé, “Olúwa, bí ó bá jẹ́ pé ìwọ ni nítòótọ́, sọ pé kí n tọ̀ ọ́ wà lórí omi.”
29 (I)Jesu dá a lóhùn pé, “Ó dára, máa bọ̀ wá.”
Nígbà náà ni Peteru sọ̀kalẹ̀ láti inú ọkọ̀. Ó ń rìn lórí omi lọ sí ìhà ọ̀dọ̀ Jesu. 30 Nígbà tí ó rí afẹ́fẹ́ líle, ẹ̀rù bà á, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í rì. Ó kígbe lóhùn rara pé, “Gbà mí, Olúwa.”
31 (J)Lójúkan náà, Jesu na ọwọ́ rẹ̀, ó dìímú, ó sì gbà á. Ó sì wí fún un pé, “Èéṣe tí ìwọ fi ṣiyèméjì ìwọ onígbàgbọ́ kékeré?”
32 Àti pé, nígbà ti wọ́n sì gòkè sínú ọkọ̀, ìjì náà sì dúró jẹ́ẹ́. 33 (K)Nígbà náà ni àwọn to wà nínú ọkọ̀ náà foríbalẹ̀ fún un wọ́n wí pé, “Nítòótọ́ ọmọ Ọlọ́run ni ìwọ í ṣe.”
34 (L)Nígbà tí wọn rékọjá sí apá kejì wọ́n gúnlẹ̀ sí Genesareti. 35 Nígbà tiwọn mọ̀ pé Jesu ni, wọn sì ránṣẹ́ sí gbogbo ìlú náà yíká. Wọ́n sì gbé gbogbo àwọn aláìsàn tọ̀ ọ́ wá. 36 (M)Àwọn aláìsàn bẹ̀ ẹ́ pé kí ó gba àwọn láyè láti fi ọwọ́ kan ìṣẹ́tí aṣọ rẹ̀, gbogbo àwọn tí ó ṣe bẹ́ẹ̀ sì rí ìwòsàn.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.