Chronological
Peteru ṣàlàyé nípa àwọn ìhùwàsí rẹ̀
11 Àwọn aposteli àti àwọn arákùnrin ti ó wà ni Judea sì gbọ́ pé àwọn aláìkọlà pẹ̀lú ti gba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. 2 Nígbà tí Peteru sì gòkè wá sí Jerusalẹmu, àwọn ti ìkọlà ń bá a wíjọ́ 3 wí pé, “Ìwọ wọlé tọ àwọn ènìyàn aláìkọlà lọ, ó sì bá wọn jẹun.”
4 (A)Ṣùgbọ́n Peteru bẹ̀rẹ̀ sí là á yé wọn lẹ́sẹẹsẹ, wí pé, 5 “Èmi wà ni ìlú Joppa, mo ń gbàdúrà, mo rí ìran kan lójúran. Ohun èlò kan sọ̀kalẹ̀ bí ewé tákàdá ńlá, tí a ti igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá; ó sì wá títí de ọ̀dọ̀ mi. 6 Mo tẹjúmọ́ ọn, mo sì fiyèsí i, mo sí rí ẹran ẹlẹ́ṣẹ̀ mẹ́rin, àti ẹranko igbó, àti ohun tí ń rákò, àti ẹyẹ ojú ọ̀run. 7 Mo sì gbọ́ ohùn kan ti ó fọ̀ sí mi pé, ‘Dìde, Peteru: máa pa, kí ó sì máa jẹ.’
8 “Ṣùgbọ́n mo dáhùn wí pé, ‘rara Olúwa! Nítorí ohun èèwọ̀ tàbí ohun aláìmọ́ kan kò wọ ẹnu mi rí láéláé.’
9 “Ṣùgbọ́n ohùn kan dáhùn nígbà ẹ̀ẹ̀kejì láti ọ̀run wá pé, ‘Ohun tí Ọlọ́run bá ti wẹ̀mọ́, kí ìwọ má ṣe pè é ní àìmọ́.’ 10 Èyí sì ṣẹlẹ̀ nígbà mẹ́ta; a sì tún fa gbogbo rẹ̀ sókè ọ̀run.
11 “Sì wò ó, lójúkan náà ọkùnrin mẹ́ta dúró níwájú ilé ti a gbé wà, ti a rán láti Kesarea sí mi. 12 Ẹ̀mí sì wí fún mi pé, kí èmi bá wọn lọ, ki èmi má ṣe kọminú ohunkóhun. Àwọn arákùnrin mẹ́fà wọ̀nyí sì bá mi lọ, a sì wọ ilé ọkùnrin náà: 13 Ó sì sọ fún wa bí òun ti rí angẹli kan tí ó dúró ní ilé rẹ̀, tí ó sì wí pé, ‘Ránṣẹ́ lọ sí Joppa, kí ó sì pe Simoni tí àpèlé rẹ̀ jẹ́ Peteru; 14 ẹni tí yóò sọ ọ̀rọ̀ fún ọ, nípa èyí tí a ó fi gba ìwọ àti gbogbo ilé rẹ là.’
15 “Bí mo sì ti bẹ̀rẹ̀ sì sọ, Ẹ̀mí Mímọ́ sì bà lé wọn, gẹ́gẹ́ bí ó ti bà lé wa ni àtètèkọ́ṣe. 16 (B)Nígbà náà ni mo rántí ọ̀rọ̀ Olúwa, bí ó ti wí pé, ‘Johanu fi omi bamitiisi nítòótọ́; ṣùgbọ́n a ó fi Ẹ̀mí Mímọ́ bamitiisi yín.’ 17 Ǹjẹ́ bí Ọlọ́run sì ti fi irú ẹ̀bùn kan náà fún wọn bí ó ti fi fún àwa pẹ̀lú nígbà tí a gba Jesu Kristi Olúwa gbọ́, ta ni èmi tí n ó fi rò pé mo le è de Ọlọ́run ní ọ̀nà?”
18 Nígbà tí wọ́n sì gbọ́ nǹkan wọ̀nyí, wọ́n sì pa ẹnu wọn mọ́, wọ́n sì yin Ọlọ́run ògo wí pé, “Ǹjẹ́ Ọlọ́run fi ìrònúpìwàdà sí ìyè fún àwọn aláìkọlà pẹ̀lú!”
Ìjọ ní Antioku
19 (C)Nítorí náà àwọn tí a sì túká kiri nípasẹ̀ inúnibíni tí ó dìde ní ti Stefanu, wọ́n rìn títí de Fonisia, àti Saipurọsi, àti Antioku, wọn kò sọ ọ̀rọ̀ náà fún ẹnìkan bí kò ṣe fún kìkì àwọn Júù. 20 Ṣùgbọ́n àwọn kan ń bẹ nínú wọn tí ó jẹ́ ará Saipurọsi àti Kirene; nígbà tí wọ́n dé Antioku, wọ́n sọ̀rọ̀ fún àwọn Helleni pẹ̀lú, wọ́n ń wàásù ìròyìn ayọ̀ nípa Jesu Olúwa. 21 Ọwọ́ Olúwa sì wà pẹ̀lú wọn: ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn sì gbàgbọ́, wọ́n sì yípadà sí Olúwa.
22 Ìròyìn nípa wọn sì dé etí ìjọ ti ó wà ni Jerusalẹmu; wọ́n sì rán Barnaba lọ títí dé Antioku; 23 Nígbà ti ó dé ti ó sì rí ẹ̀rí oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run, ó yọ̀, ó sì gba gbogbo wọn níyànjú pé, pẹ̀lú ìpinnu ọkàn ni kí wọn fi ara mọ́ Olúwa. 24 Nítorí òun jẹ́ ènìyàn rere, ó sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́ àti fún ìgbàgbọ́; ènìyàn púpọ̀ ni a sì kà kún Olúwa.
25 Barnaba sì jáde lọ sí Tarsu láti wá Saulu, 26 nígbà tí ó sì rí i, ó mú un wá sí Antioku. Fún ọdún kan gbáko ni wọ́n fi ń bá ìjọ péjọpọ̀, tí wọ́n sì kọ́ ènìyàn púpọ̀. Ní Antioku ni a sì kọ́kọ́ ti pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ni “Kristiani.”
27 Ní ọjọ́ wọ̀nyí ni àwọn wòlíì sì ti Jerusalẹmu sọ̀kalẹ̀ wá sí Antioku. 28 Nígbà tí ọ̀kan nínú wọn, ti a ń pè ni Agabu sí dìde, ó ti ipa Ẹ̀mí sọ pé, ìyàn ńlá yóò mú yíká gbogbo ilẹ̀ Romu. (Èyí sì ṣẹlẹ̀ nígbà ìṣèjọba Kilaudiu.) 29 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sì pinnu, olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí agbára rẹ̀ ti tó, láti rán ìrànlọ́wọ́ sí àwọn arákùnrin tí ó wà ní Judea. 30 Wọn sì ṣe bẹ́ẹ̀, wọn sì fi ẹ̀bùn ránṣẹ́ sí àwọn àgbà láti ọwọ́ Barnaba àti Saulu.
Peteru bọ́ kúrò ní ẹ̀wọ̀n pẹ̀lú ìyanu
12 Ní àkókò ìgbà náà ni Herodu ọba sì nawọ́ rẹ̀ mú àwọn kan nínú ìjọ, pẹ̀lú èrò láti pọ́n wọn lójú. 2 Ó sì fi idà pa Jakọbu arákùnrin Johanu. 3 Nígbà tí ó sì rí pé èyí dùn mọ́ àwọn Júù nínú, ó sì nawọ́ mú Peteru pẹ̀lú. Ó sì jẹ́ ìgbà àjọ àìwúkàrà. 4 Nígbà tí o sì mú un, ó fi i sínú túbú, ó fi lé àwọn ẹ̀ṣọ́ mẹ́rin ti ọmọ-ogun lọ́wọ́ láti máa ṣọ́ ọ. Herodu ń rò láti mú un jáde fún àwọn ènìyàn lẹ́yìn ìrékọjá fún ìdájọ́.
5 Nítorí náà wọn fi Peteru pamọ́ sínú túbú; ṣùgbọ́n ìjọ ń fi ìtara gbàdúrà sọ́dọ̀ Ọlọ́run fún un.
6 Ní òru náà gan an ti Herodu ìbá sì mú un jáde, Peteru ń sùn láàrín àwọn ọmọ-ogun méjì, a fi ẹ̀wọ̀n méjì dè é, ẹ̀ṣọ́ sí wà ní ẹnu-ọ̀nà, wọ́n ń ṣọ́ túbú náà. 7 Sì wò ó, angẹli Olúwa farahàn, ìmọ́lẹ̀ sì mọ́ nínú túbú; ó sì lu Peteru pẹ́pẹ́ lẹ́gbẹ̀ẹ́, ó jí i, ó ni, “Dìde kánkán!” Ẹ̀wọ̀n sí bọ́ sílẹ̀ kúrò ní ọwọ́ Peteru.
8 Angẹli náà sì wí fún un pé, “Di àmùrè rẹ̀, kí ó sì wọ sálúbàtà rẹ!” Peteru sì ṣe bẹ́ẹ̀. Ó sì wí fún un pé, “Da aṣọ rẹ́ bora, ki ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn!” 9 Peteru sì jáde, ó ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn; kò sí mọ̀ pé ohun tí a ṣe láti ọwọ́ angẹli náà jẹ́ òtítọ́, ṣùgbọ́n ó ṣe bí òun wà lójú ìran. 10 Nígbà tí wọ́n kọjá ìṣọ́ èkínní àti èkejì, wọ́n dé ẹnu-ọ̀nà ìlẹ̀kùn irin tí ó lọ sí ìlú. Ó sí tìkára rẹ̀ ṣí sílẹ̀ fún wọn: wọ́n sì jáde, wọ́n ń gba ọ̀nà ìgboro kan lọ; lójúkan náà angẹli náà sì fi í sílẹ̀ lọ.
11 Nígbà tí ojú Peteru sì wálẹ̀, ó ní, “Nígbà yìí ni mo tó mọ̀ nítòótọ́ pé, Olúwa rán angẹli rẹ̀, ó sì gbà mi lọ́wọ́ Herodu àti gbogbo ohun tí àwọn ènìyàn Júù ń retí!”
12 Nígbà tó sì rò ó, ó lọ sí ilé Maria ìyá Johanu, tí àpèlé rẹ̀ ń jẹ́ Marku; níbi tí àwọn ènìyàn púpọ̀ péjọ sí, tí wọn ń gbàdúrà. 13 Bí ó sì ti kan ìlẹ̀kùn ẹnu-ọ̀nà, ọmọbìnrin kan tí a n pè ní Roda wá láti dáhùn. 14 Nígbà tí ó sì ti mọ ohùn Peteru, kò ṣí ìlẹ̀kùn nítorí tí ayọ̀ kún ọkàn rẹ̀ gidigidi, ṣùgbọ́n ó súré wọ ilé, ó sísọ pé, Peteru dúró ní ẹnu-ọ̀nà.
15 Wọ́n sì wí fún un pé, “Ìwọ ń ṣe òmùgọ̀!” Ṣùgbọ́n ó tẹnumọ́ ọn gidigidi pé bẹ́ẹ̀ ni sẹ́. Wọn sì wí pé, “Angẹli rẹ̀ ni!”
16 Ṣùgbọ́n Peteru ń kànkùn síbẹ̀, nígbà tí wọn sì ṣí ìlẹ̀kùn, wọ́n rí i, ẹnu sì yá wọ́n. 17 Ṣùgbọ́n ó juwọ́ sí wọn pé kí wọn dákẹ́, ó sì ròyìn fún wọn bí Olúwa ti mú òun jáde kúrò nínú túbú. Ó sì wí pé “Ẹ ro èyí fún Jakọbu àti àwọn arákùnrin yòókù!” Ó sì jáde, ó lọ sí ibòmíràn.
18 Nígbà tí ilẹ̀ sì mọ́, ìrúkèrúdò díẹ̀ kọ́ ni ó wà láàrín àwọn ọmọ-ogun nípa ohun tí ó dé bá Peteru. 19 Nígbà tí Herodu sì wá a kiri, tí kò sì rí i, ó wádìí àwọn ẹ̀ṣọ́, ó pàṣẹ pé, kí a pa wọ́n.
Ikú Herodu
Herodu sì sọ̀kalẹ̀ láti Judea lọ sí Kesarea, ó sì wà níbẹ̀ fún ìgbà díẹ̀. 20 Herodu sí ń bínú gidigidi sí àwọn ará Tire àti Sidoni; ṣùgbọ́n wọ́n fi ìmọ̀ ṣọ̀kan wá sọ́dọ̀ rẹ̀, nígbà tí wọn sì ti tu Bilasitu ìwẹ̀fà ọba lójú, wọn ń bẹ̀bẹ̀ fún àlàáfíà, nítorí pé ìlú ọba náà ni ìlú tí wọ́n ti ń gba oúnjẹ.
21 Ni ọjọ́ àfiyèsí kan, Herodu sì wà nínú aṣọ ìgúnwà rẹ̀, ni orí ìtẹ́ rẹ̀, ó sì ń bá àwọn àjọ ènìyàn sọ̀rọ̀ ní gbangba. 22 Àwọn ènìyàn sì hó wí pé, “Ohùn ọlọ́run ni èyí, kì í sì í ṣe ti ènìyàn!” 23 Lójúkan náà, nítorí ti Herodu kò fi ògo fún Ọlọ́run, angẹli Olúwa lù ú, ó sì kú, ìdin sì jẹ ẹ́.
24 Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbilẹ̀, ó sì bí sí i.
25 Barnaba àti Saulu sì padà wá láti Jerusalẹmu, nígbà ti wọ́n sì parí iṣẹ́ ìránṣẹ́ wọn, wọn sì mú Johanu ẹni tí àpèlé rẹ̀ ń jẹ́ Marku wá pẹ̀lú wọn.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.