Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Chronological

Read the Bible in the chronological order in which its stories and events occurred.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Matiu 28

Àjíǹde rẹ̀

28 (A)(B) Ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kìn-ín-ní ọ̀sẹ̀, bí ilẹ̀ ti ń mọ́, Maria Magdalene àti Maria kejì lọ sí ibojì.

(C)Wọ́n rí i pé, ìṣẹ̀lẹ̀ ńlá ṣẹ̀ tí ó mú gbogbo ilẹ̀ mì tìtì. Nítorí angẹli Olúwa ti sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run. Ó ti yí òkúta ibojì kúrò. Ó sì jókòó lé e lórí. Ojú rẹ̀ tàn bí mọ̀nàmọ́ná. Aṣọ rẹ̀ sì jẹ́ funfun bí ẹ̀gbọ̀n òwú. (D)Ẹ̀rù ba àwọn olùṣọ́, wọ́n sì wárìrì wọn sì dàbí òkú.

Nígbà náà ni angẹli náà wí fún àwọn obìnrin náà pé, “Ẹ má ṣe bẹ̀rù. Mo mọ̀ pé ẹ̀yin ń wá Jesu tí a kàn mọ́ àgbélébùú. Ṣùgbọ́n kò sí níhìn-ín. Nítorí pé ó ti jíǹde, gẹ́gẹ́ bí òun ti wí. Ẹ wọlé wá wo ibi ti wọ́n tẹ́ ẹ sí. (E)Nísinsin yìí, Ẹ lọ kíákíá láti sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, ‘Ó ti jíǹde kúrò nínú òkú. Àti pé òun ń lọ sí Galili síwájú yín, níbẹ̀ ni ẹ̀yin yóò gbé rí i,’ wò ó, o ti sọ fún yin.”

Àwọn obìnrin náà sáré kúrò ní ibojì pẹ̀lú ìbẹ̀rù àti ayọ̀ ńlá. Wọ́n sáré láti sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn nípa ìròyìn tí angẹli náà fi fún wọn. (F)Bí wọ́n ti ń sáré lọ lójijì Jesu pàdé wọn. Ó wí pé, “Àlàáfíà” Wọ́n wólẹ̀ níwájú rẹ̀. Wọ́n gbá a ní ẹsẹ̀ mú. Wọ́n sì foríbalẹ̀ fún un. 10 Nígbà náà, Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ má ṣe bẹ̀rù. Ẹ lọ sọ fún àwọn arákùnrin mi pé, ‘Kí wọ́n lọ tààrà sí Galili níbẹ̀ ni wọn yóò gbé rí mi.’ ”

Àwọn olùṣọ́ ròyìn

11 (G)Bí àwọn obìnrin náà sì ti ń lọ sí ìlú, díẹ̀ nínú àwọn olùṣọ́ tí wọ́n ti ń ṣọ́ ibojì lọ sọ́dọ̀ àwọn olórí àlùfáà. 12 Wọ́n sì pe ìpàdé àwọn àgbàgbà Júù. Wọ́n sì fohùn ṣọ̀kan láti fi owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀ fún àwọn olùṣọ́. 13 Wọ́n wí pé, “Ẹ sọ fún àwọn ènìyàn pé, ‘Gbogbo yín sùn nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu wá lóru láti jí òkú rẹ̀.’ 14 Bí Pilatu bá sì mọ̀ nípa rẹ̀, àwa yóò ṣe àlàyé tí yóò tẹ́ ẹ lọ́rùn fún un, tí ọ̀rọ̀ náà kì yóò fi lè kó bá yín.” 15 Àwọn olùṣọ́ sì gba owó náà. Wọ́n sì ṣe gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti darí wọn. Ìtàn yìí sì tàn ká kíákíá láàrín àwọn Júù. Wọ́n sì gba ìtàn náà gbọ́ títí di òní yìí.

Jesu pín iṣẹ́ ńlá fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀

16 (H)Nígbà náà ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mọ́kànlá náà lọ sí Galili ní orí òkè níbi tí Jesu sọ pé wọn yóò ti rí òun. 17 Nígbà tí wọ́n sì rí i, wọ́n foríbalẹ̀ fún un. Ṣùgbọ́n díẹ̀ nínú wọn ṣe iyèméjì bóyá Jesu ni tàbí òun kọ́. 18 (I)Nígbà náà ni Jesu wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Gbogbo agbára ni ọ̀run àti ní ayé ni a ti fi fún mi. 19 Nítorí náà, Ẹ lọ, ẹ sọ wọ́n di ọmọ-ẹ̀yìn orílẹ̀-èdè gbogbo, ẹ máa bamitiisi wọn ní orúkọ Baba àti ti Ọmọ àti ti Ẹ̀mí Mímọ́. 20 Ẹ kọ́ wọn láti máa kíyèsi ohun gbogbo èyí tí mo ti pàṣẹ fún yín. Nítorí èmi wà pẹ̀lú yín ní ìgbà gbogbo títí tí ó fi dé òpin ayé.”

Marku 16

Àjíǹde

16 (A)(B) Nígbà tí ọjọ́ ìsinmi sì kọjá, Maria Magdalene, Maria ìyá Jakọbu, àti Salome mú òróró olóòórùn dídùn wá kí wọn bá à le fi kun Jesu lára. Ní kùtùkùtù ọjọ́ kìn-ín-ní ọ̀sẹ̀, wọ́n wá sí ibi ibojì nígbà tí oòrùn bẹ̀rẹ̀ sí yọ, wọn sì ń bi ara wọn léèrè pé, “Ta ni yóò yí òkúta náà kúrò ní ẹnu ibojì fún wa?”

Ṣùgbọ́n nígbà tí wọn sì wò ó, wọ́n rí i pé a ti yí òkúta tí ó tóbi gidigidi náà kúrò. Nígbà tí wọ́n sì wo inú ibojì náà, wọ́n rí ọ̀dọ́mọkùnrin kàn tí ó wọ aṣọ funfun, ó jókòó ní apá ọ̀tún, ẹnu sì yà wọn.

Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ má bẹ̀rù: Ẹ̀yin ń wá Jesu tí Nasareti, tí a kàn mọ́ àgbélébùú. Ó jíǹde! Kò sí níhìn-ín yìí mọ́, Ẹ wo ibi tí wọ́n gbé tẹ́ ẹ sí. (C)Ṣùgbọ́n ẹ lọ sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ títí kan Peteru wí pé, ‘Òun ti ń lọ síwájú yín sí Galili. Ibẹ̀ ni ẹ̀yin yóò ti rí i, gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ fún yín.’ ”

Wọ́n sáré jáde lọ kánkán, kúrò ní ibi ibojì náà, nítorí tí wọ́n wárìrì; ẹ̀rù sì bà wọn gidigidi; wọn kò wí ohunkóhun fún ẹnikẹ́ni, nítorí ẹ̀rù bá wọ́n.

[Àwọn àkọsílẹ̀ àtijọ́ àti àwọn ẹlẹ́rìí àtijọ́ kò ní ẹsẹ 9-20.]

Nígbà tí Jesu jíǹde ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ní ọjọ́ kìn-ín-ní ọ̀sẹ̀, ó kọ́ fi ara hàn fun Maria Magdalene, ni ara ẹni tí ó ti lé ẹ̀mí Èṣù méje jáde. 10 Òun sì lọ sọ fún àwọn tí ó ti ń bá a gbé, bí wọn ti ń gbààwẹ̀, tí wọ́n sì ń sọkún. 11 Àti àwọn, nígbà tí wọ́n sì gbọ́ pé Jesu wa láààyè, àti pé, òun ti rí i, wọn kò gbàgbọ́.

12 Lẹ́yìn èyí, ó sì fi ara hàn fún àwọn méjì ní ọ̀nà mìíràn, bí wọ́n ti ń rìn ní ọ̀nà, tí wọ́n sì ń lọ sí ìgbèríko. 13 Nígbà tí wọ́n sì mọ ẹni tí i ṣe, wọ́n sì lọ ròyìn fún àwọn ìyókù, síbẹ̀, àwọn ìyókù kò gbà wọ́n gbọ́.

14 Lẹ́yìn náà, Jesu fi ara rẹ̀ hàn fún àwọn mọ́kànlá níbi tí wọ́n ti ń jẹun papọ̀; Ó sì bá wọn wí fún àìgbàgbọ́ àti ọkàn líle wọn, nítorí wọn kò gba ẹ̀rí àwọn tí ó ti rí i lẹ́yìn àjíǹde rẹ̀ gbọ́.

15 Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ lọ sí gbogbo ayé, kí ẹ sì máa wàásù ìhìnrere mi fún gbogbo ẹ̀dá. 16 Ẹni tí ó bá gbàgbọ́, tí a sì tẹ̀bọmi yóò là. Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá kọ̀ tí kò gbàgbọ́ yóò jẹ̀bi. 17 Ààmì wọ̀nyí yóò sì máa bá àwọn tí ó gbàgbọ́ lọ. Ní orúkọ mi ni wọ́n yóò máa lé ẹ̀mí èṣù jáde. Wọn yóò máa fi èdè tuntun sọ̀rọ̀. 18 Wọn yóò sì gbé ejò lọ́wọ́, bí wọ́n bá sì jẹ májèlé kò nípa wọ́n lára rárá. Wọ́n yóò gbé ọwọ́ lé àwọn aláìsàn, ara wọn yóò sì dá.”

19 Nígbà tí Jesu Olúwa sì ti bá wọn sọ̀rọ̀ báyìí tan, á gbé e lọ sí ọ̀run, ó sì jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún Ọlọ́run. 20 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì jáde lọ. Wọ́n ń wàásù káàkiri. Ọlọ́run sì wà pẹ̀lú wọn, ó sì ń fi ìdí ọ̀rọ̀ rẹ̀ múlẹ̀ nípa àwọn ààmì tí ó tẹ̀lé e.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.