Chronological
Judasi lọ pokùnso
27 (A)Ní òwúrọ̀, gbogbo àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbàgbà Júù tún padà láti gbìmọ̀ bí wọn yóò ti ṣe pa Jesu. 2 Lẹ́yìn èyí, wọ́n fi ẹ̀wọ̀n dè é, wọ́n sì jọ̀wọ́ rẹ̀ fún Pilatu tí i ṣe gómìnà.
3 (B)(C) Nígbà tí Judasi, ẹni tí ó fi í hàn, rí i wí pé a ti dá a lẹ́bi ikú, ó yí ọkàn rẹ̀ padà, ó sì káàánú nípa ohun tí ó ṣe. Ó sì mú ọgbọ̀n owó fàdákà tí ó gba náà wá fún àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbàgbà Júù. 4 Ó wí pé, “Mo ti ṣẹ̀ nítorí tí mo ti ta ẹ̀jẹ̀ aláìlẹ́ṣẹ̀ sílẹ̀.”
Wọ́n dá a lóhùn pẹ̀lú ìbínú pé, “Èyí kò kàn wá! Wàhálà tìrẹ ni!”
5 Nígbà náà ni Judasi da owó náà sílẹ̀ nínú tẹmpili. Ó jáde, ó sì lọ pokùnso.
6 (D)Àwọn olórí àlùfáà sì mú owó náà. Wọ́n wí pé, “Àwa kò lè fi owó yìí sínú owó ìkójọpọ̀. Ní ìwọ̀n ìgbà tí ó lòdì sí òfin wa nítorí pé owó ẹ̀jẹ̀ ni.” 7 Wọ́n sì gbìmọ̀, wọ́n sì fi ra ilẹ̀ amọ̀kòkò, láti máa sin òkú àwọn àjèjì nínú rẹ̀. 8 Ìdí nìyìí tí à ń pe ibi ìsìnkú náà ní “Ilẹ̀ Ẹ̀jẹ̀” títí di òní. 9 (E)Èyí sì jẹ́ ìmúṣẹ èyí tí a ti sọtẹ́lẹ̀ láti ẹnu wòlíì Jeremiah wí pé, “Wọ́n sì mú ọgbọ̀n owó fàdákà tí àwọn ènìyàn Israẹli díye lé e. 10 Wọ́n sì fi ra ilẹ̀ kan lọ́wọ́ àwọn amọ̀kòkò gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ.”
Jesu níwájú Pilatu
11 (F)Nígbà náà ni Jesu dúró níwájú baálẹ̀ láti gba ìdájọ́. Baálẹ̀ sì béèrè pé, “Ṣe ìwọ ni ọba àwọn Júù?”
Jesu dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, nítorí tí ìwọ wí i.”
12 Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbàgbà Júù fi gbogbo ẹ̀sùn wọn kàn án, Jesu kò dáhùn kan. 13 Nígbà náà ni Pilatu, béèrè lọ́wọ́ Jesu pé, “Àbí ìwọ kò gbọ́ ẹ̀rí tí wọn ń wí nípa rẹ ni?” 14 (G)Jesu kò sì tún dáhùn kan. Èyí sì ya baálẹ̀ lẹ́nu.
15 Ó jẹ́ àṣà gómìnà láti dá ọ̀kan nínú àwọn ẹlẹ́wọ̀n Júù sílẹ̀ lọ́dọọdún, ní àsìkò àjọ̀dún ìrékọjá. Ẹnikẹ́ni tí àwọn ènìyàn bá ti fẹ́ ni. 16 Ní àsìkò náà ọ̀daràn paraku kan wà nínú ẹ̀wọ̀n tí à ń pè Jesu Baraba. 17 Bí ọ̀pọ̀ ènìyàn ti péjọ síwájú ilé Pilatu lówúrọ̀ ọjọ́ náà, ó béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Ta ni ẹ̀yin ń fẹ́ kí n dá sílẹ̀ fún yín, Baraba tàbí Jesu, ẹni tí ń jẹ́ Kristi?” 18 Òun ti mọ̀ pé nítorí ìlara ni wọn fi fà á lé òun lọ́wọ́.
19 (H)Bí Pilatu sì ti ṣe jókòó lórí ìtẹ́ ìdájọ́ rẹ̀, ìyàwó rẹ̀ ránṣẹ́ sí i pé, “Má ṣe ní ohun kankan ṣe pẹ̀lú ọkùnrin aláìṣẹ̀ náà. Nítorí mo jìyà ohun púpọ̀ lójú àlá mi lónìí nítorí rẹ̀.”
20 Ṣùgbọ́n àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbàgbà Júù rọ àwọn ènìyàn, láti béèrè kí a dá Baraba sílẹ̀, kí a sì béèrè ikú fún Jesu.
21 (I)Nígbà tí Pilatu sì tún béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Èwo nínú àwọn méjèèjì yìí ni ẹ̀ ń fẹ́ kí n dá sílẹ̀ fún yín?”
Àwọn ènìyàn sì kígbe padà pé, “Baraba!”
22 Pilatu béèrè pé, “Kí ni kí èmi ṣe sí Jesu ẹni ti a ń pè ní Kristi?”
Gbogbo wọn sì tún kígbe pé, “Kàn án mọ́ àgbélébùú!”
23 Pilatu sì béèrè pé, “Nítorí kí ni? Kí ló ṣe tí ó burú?”
Wọ́n kígbe sókè pé, “Kàn án mọ́ àgbélébùú! Kàn án mọ́ àgbélébùú!”
24 (J)Nígbà tí Pilatu sì rí i pé òun kò tún rí nǹkan kan ṣe mọ́, àti wí pé rògbòdìyàn ti ń bẹ̀rẹ̀, ó béèrè omi, ó sì wẹ ọwọ́ rẹ̀ níwájú ọ̀pọ̀ ènìyàn, ó wí pé, “Ọrùn mí mọ́ nípa ẹ̀jẹ̀ ọkùnrin yìí. Ẹ̀yin fúnrayín, ẹ bojútó o!”
25 (K)Gbogbo àgbájọ náà sì ké pé, “Kí ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wà lórí wa, àti ní orí àwọn ọmọ wa!”
26 Nígbà náà ni Pilatu dá Baraba sílẹ̀ fún wọn. Lẹ́yìn tí òun ti na Jesu tán, ó fi í lé wọn lọ́wọ́ láti mú un lọ kàn mọ́ àgbélébùú.
Àwọn ọmọ-ogun na Jesu
27 (L)Nígbà náà ni àwọn ọmọ-ogun gómìnà mú Jesu lọ sí gbọ̀ngàn ìdájọ́ wọ́n sì kó gbogbo ẹgbẹ́ ọmọ-ogun tì í 28 Wọ́n tú Jesu sì ìhòhò, wọ́n sì wọ̀ ọ́ ní aṣọ òdòdó, 29 Wọ́n sì hun adé ẹ̀gún. Wọ́n sì fi dé e lórí. Wọ́n sì fi ọ̀pá sí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀pá ọba. Wọ́n sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀, wọ́n fi í ṣe ẹlẹ́yà pé, “Kábíyèsí, ọba àwọn Júù!” 30 Wọ́n sì tu itọ́ sí i lójú àti ara, wọ́n gba ọ̀pá wọ́n sì nà án lórí. 31 Nígbà tí wọ́n fi ṣẹ̀sín tán, wọ́n bọ́ aṣọ ara rẹ̀. Wọ́n tún fi aṣọ tirẹ̀ wọ̀ ọ́. Wọ́n sì mú un jáde láti kàn án mọ́ àgbélébùú.
A kan Jesu mọ́ àgbélébùú
32 (M)Bí wọ́n sì ti ń jáde, wọ́n rí ọkùnrin kan ará Kirene tí à ń pè ní Simoni. Wọ́n sì mú ọkùnrin náà ní túláàsì láti ru àgbélébùú Jesu. 33 (N)Wọ́n sì jáde lọ sí àdúgbò kan tí à ń pè ní Gọlgọta, (èyí tí í ṣe Ibi Agbárí.) 34 Níbẹ̀ ni wọn ti fún un ni ọtí wáìnì tí ó ní egbòogi nínú láti mu. Ṣùgbọ́n nígbà tí ó tọ́ ọ wò, ó kọ̀ láti mu ún. 35 (O)Lẹ́yìn tí wọ́n sì ti kàn án mọ́ àgbélébùú, wọ́n dìbò láti pín aṣọ rẹ̀ láàrín ara wọn. 36 Nígbà náà ni wọ́n jókòó yí i ká. Wọ́n ń ṣọ́ ọ níbẹ̀. 37 Ní òkè orí rẹ̀, wọ́n kọ ohun kan tí ó kà báyìí pé:
“èyí ni jesu, ọba àwọn júù”
síbẹ̀. 38 Wọ́n kan àwọn olè méjì pẹ̀lú rẹ̀ ní òwúrọ̀ náà. Ọ̀kan ní ọwọ́ ọ̀tún, àti èkejì ní ọwọ́ òsì rẹ̀. 39 (P)Àwọn tí ń kọjá lọ sì ń bú u. Wọ́n sì ń mi orí wọn pé: 40 (Q)“Ìwọ tí yóò wó tẹmpili, ìwọ tí yóò sì tún un mọ ní ọjọ́ kẹta. Bí ó bá jẹ́ pé Ọmọ Ọlọ́run ni ìwọ, sọ̀kalẹ̀ láti orí igi àgbélébùú, kí ó sì gba ara rẹ là!”
41 Bákan náà àwọn olórí àlùfáà pẹ̀lú àwọn akọ̀wé òfin àti àwọn àgbàgbà Júù sì fi í ṣe ẹlẹ́yà. 42 Wọ́n kẹ́gàn rẹ̀ pé, “Ó gba àwọn ẹlòmíràn là, kò sí lè gba ara rẹ̀. Ìwọ ọba àwọn Israẹli? Sọ̀kalẹ̀ láti orí àgbélébùú nísinsin yìí, àwa yóò sì gbà ọ́ gbọ́. 43 Ó gba Ọlọ́run gbọ́, jẹ́ kí Ọlọ́run gbà á là ní ìsinsin yìí tí òun bá fẹ́ ẹ. Ǹjẹ́ òun kò wí pé, èmi ni Ọmọ Ọlọ́run?” 44 Bákan náà, àwọn olè tí a kàn mọ́ àgbélébùú pẹ̀lú rẹ̀ fi í ṣe ẹlẹ́yà.
Ikú Jesu
45 (R)Láti wákàtí kẹfà ni òkùnkùn fi ṣú bo gbogbo ilẹ̀ títí dé wákàtí kẹsànán ọjọ́ 46 (S)Níwọ̀n wákàtí kẹsànán ní Jesu sì kígbe ní ohùn rara wí pé, “Eli, Eli, Lama Sabakitani” (ní èdè Heberu). Ìtumọ̀ èyí tí í ṣe, “Ọlọ́run mi, Ọlọ́run mi, èéṣe tí ìwọ fi kọ̀ mí sílẹ̀?”
47 Ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò yé díẹ̀ nínú àwọn ẹni tí ń wòran, nígbà tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, Wọ́n wí pé ọkùnrin yìí ń pe Elijah.
48 (T)Lẹ́sẹ̀kan náà, ọ̀kan nínú wọn sáré, ó mú kànìnkànìn, ó tẹ̀ ẹ́ bọ inú ọtí kíkan. Ó fi lé orí ọ̀pá, ó gbé e sókè láti fi fún un mu. 49 Ṣùgbọ́n àwọn ìyókù wí pé, “Ẹ fi í sílẹ̀. Ẹ jẹ́ kí a wò ó bóyá Elijah yóò sọ̀kalẹ̀ láti gbà á là.”
50 Nígbà tí Jesu sì kígbe ní ohùn rara lẹ́ẹ̀kan sí i, ó jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀, ó sì kú.
51 (U)Lójúkan náà aṣọ ìkélé tẹmpili fàya, láti òkè dé ìsàlẹ̀. Ilẹ̀ sì mì tìtì. Àwọn àpáta sì sán. 52 Àwọn isà òkú sì ṣí sílẹ̀. Ọ̀pọ̀ òkú àwọn ẹni mímọ́ tí ó ti sùn sì tún jíǹde. 53 Wọ́n jáde wá láti isà òkú lẹ́yìn àjíǹde Jesu, wọ́n sì lọ sí ìlú mímọ́. Níbẹ̀ ni wọ́n ti fi ara han ọ̀pọ̀ ènìyàn.
54 (V)Nígbà tí balógun ọ̀run àti àwọn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ tí wọ́n ń sọ Jesu rí bí ilẹ̀ ṣe mì tìtì àti ohun tí ó ṣẹlẹ̀, ẹ̀rù bà wọn gidigidi, wọ́n wí pé, “Lóòótọ́ ọmọ Ọlọ́run ní í ṣe!”
55 Ọ̀pọ̀ obìnrin tí ó wá láti Galili pẹ̀lú Jesu láti tọ́jú rẹ̀ wọn ń wò ó láti òkèèrè. 56 (W)Nínú àwọn obìnrin ti ó wà níbẹ̀ ni Maria Magdalene, àti Maria ìyá Jakọbu àti Josẹfu, àti ìyá àwọn ọmọ Sebede méjèèjì wà níbẹ̀ pẹ̀lú.
A tẹ́ Jesu sínú ibojì
57 (X)Nígbà tí alẹ́ sì lẹ́, ọkùnrin ọlọ́rọ̀ kan láti Arimatea, tí à ń pè ní Josẹfu, ọ̀kan nínú àwọn tí ó jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn Jesu, 58 lọ sọ́dọ̀ Pilatu, ó sì tọrọ òkú Jesu. Pilatu sì pàṣẹ kí a gbé é fún un. 59 Josẹfu sì gbé òkú náà. Ó fi aṣọ funfun mímọ́ dì í. 60 Ó sì tẹ́ ẹ sínú ibojì òkúta tí ó gbẹ́ nínú àpáta fúnrarẹ̀. Ó sì yí òkúta ńlá dí ẹnu-ọ̀nà ibojì náà, ó sì lọ. 61 Maria Magdalene àti Maria kejì wà níbẹ̀, wọn jókòó òdìkejì ibojì náà.
Àwọn olùṣọ́ ní ibojì
62 Lọ́jọ́ kejì tí ó tẹ̀lé ọjọ́ ìpalẹ̀mọ́ àwọn olórí àlùfáà àti àwọn Farisi lọ sọ́dọ̀ Pilatu. 63 (Y)Wọ́n sọ fún un pé, “Alàgbà àwa rántí pé ẹlẹ́tàn nnì wí nígbà tí ó wà láyé pé, ‘Lẹ́yìn ọjọ́ kẹta èmi yóò tún jí dìde.’ 64 Nítorí náà, pàṣẹ kí a ti ibojì rẹ̀ gbọningbọnin títí ọjọ́ kẹta, kí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ má ṣe wá jí gbé lọ, wọn a sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ fún gbogbo ènìyàn pé, ‘Òun ti jíǹde,’ Bí èyí bá ní láti ṣẹlẹ̀, yóò burú fún wa púpọ̀ ju ti àkọ́kọ́ lọ.”
65 Pilatu sì pàṣẹ pé, “Ẹ lo àwọn olùṣọ́ yín kí wọn dáàbò bo ibojì náà bí ẹ bá ti fẹ́.” 66 (Z)Nítorí náà wọ́n lọ. Wọ́n sì ṣé òkúta ibojì náà dáradára. Wọ́n sì fi àwọn olùṣọ́ sí ibẹ̀ láti dáàbò bò ó.
Jesu jẹ́jọ́ níwájú Pilatu
15 (A)Ní kùtùkùtù òwúrọ̀, àwọn olórí àlùfáà, àwọn àgbàgbà, àwọn olùkọ́ òfin àti gbogbo àjọ ìgbìmọ̀ fi ẹnu kò lórí ohun tí wọn yóò ṣe. Wọ́n sì de Jesu, wọ́n mú un lọ, wọ́n sì fi lé Pilatu lọ́wọ́.
2 (B)Pilatu sì bi í léèrè, ó ni, “Ṣe ìwọ ni ọba àwọn Júù?”
Jesu sì dáhùn pé, “gẹ́gẹ́ bi ìwọ ti wí náà ni.”
3 Àwọn olórí àlùfáà fi ẹ̀sùn ohun púpọ̀ kàn án. 4 Pilatu sì tún bi í léèrè pé, “Ṣe ìwọ kò dáhùn ni? Wo gbogbo ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn ọ.”
5 Ṣùgbọ́n Jesu kò dalóhùn síbẹ̀, tó bẹ́ẹ̀ ti ẹnu fi ya Pilatu.
6 Ní báyìí, nígbà àjọ, gẹ́gẹ́ bí àṣà, òun a máa dá òǹdè kan sílẹ̀ fún wọn, ẹnikẹ́ni tí wọ́n bá béèrè fún. 7 Ọkùnrin kan wà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Baraba. Wọ́n ti ju òun àti àwọn ọlọ̀tẹ̀ ẹgbẹ́ rẹ̀ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n, nítorí wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí ìjọba, wọ́n sì pa ènìyàn nínú ìdìtẹ̀ wọn. 8 Ọ̀pọ̀ ènìyàn sì lọ bá Pilatu, wọ́n ní kí ó ṣe bí ó ti máa ń ṣe fún wọn ní ọdọọdún.
9 Pilatu béèrè lọ́wọ́ wọn wí pé, “Ṣe ẹ̀yin ń fẹ́ kí èmi dá ọba àwọn Júù sílẹ̀ fún yin?” 10 Òun mọ̀ pé nítorí ìlara ni àwọn olórí àlùfáà ṣe fà Jesu lé òun lọ́wọ́. 11 (C)Nígbà náà ni àwọn olórí àlùfáà ru ọ̀pọ̀ ènìyàn sókè pé, kí ó kúkú dá Baraba sílẹ̀ fún wọn.
12 Pilatu sì tún béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Kí ni ẹ̀yin ń fẹ́ kí èmi kí ó ṣe pẹ̀lú ẹni ti ẹ̀yin n pè ní ọba àwọn Júù?”
13 Wọ́n sì tún kígbe sókè pé, “Kàn án mọ àgbélébùú!”
14 Nígbà náà ni Pilatu bi wọn léèrè pé, “Èéṣe? Búburú kí ni ó ṣe?”
Wọ́n sì kígbe sókè gidigidi wí pé, “Kàn án mọ́ àgbélébùú!”
15 Pilatu sì ń fẹ́ ṣe èyí tí ó wu àwọn ènìyàn, ó dá Baraba sílẹ̀ fún wọn. Nígbà tí ó sì na Jesu tan o fà á lé wọn lọ́wọ́ láti kàn an mọ́ àgbélébùú.
Àwọn ọmọ-ogun fi Jesu ṣe ẹlẹ́yà
16 (D)Àwọn ọmọ-ogun sì fà á jáde lọ sínú ààfin (tí a ń pè ní Praetoriumus), wọ́n sì pe gbogbo ẹgbẹ́ àwọn ọmọ-ogun jọ. 17 Wọn sì fi aṣọ aláwọ̀ àlùkò wọ̀ ọ́, wọ́n hun adé ẹ̀gún, wọ́n sì fi dé e ní orí. 18 Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí i kí ì, wí pé Kábíyèsí, ọba àwọn Júù 19 Wọ́n sì fi ọ̀pá lù ú lórí, wọ́n sì tutọ́ sí i lára, wọ́n sì kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀, wọ́n sì foríbalẹ̀ fún un. 20 Nígbà tí wọ́n sì fi ṣẹ̀sín tan, wọ́n sì bọ aṣọ elése àlùkò náà kúrò lára rẹ̀, wọ́n sì fi aṣọ rẹ̀ wọ̀ ọ́, wọ́n sì mú un jáde lọ láti kàn án mọ́ àgbélébùú.
Wọ́n kan Jesu mọ́ àgbélébùú
21 (E)Wọ́n rí ọkùnrin kan tí ń kọjá lọ. Simoni ará Kirene. Òun ni baba Aleksanderu àti Rufusi. Wọ́n sì mú un ní tipátipá, pé kí ó rú àgbélébùú Jesu. 22 (F)Wọ́n sì mú Jesu wá sí Gọlgọta, (èyí tí ìtumọ̀ rẹ̀ ń jẹ́ Ibi Agbárí) 23 Wọ́n sì fi (myrri) wáìnì tí a dàpọ̀ mọ́ òjìá fún un mu, ṣùgbọ́n òun kò gbà á. 24 (G)Wọ́n sì kàn án mọ́ àgbélébùú. Wọ́n sì pín aṣọ rẹ̀ láàrín ara wọn, wọ́n dìbò lórí àwọn aṣọ náà ni kí wọn bá à lè mọ èyí tí yóò jẹ́ ti olúkúlùkù.
25 Ní wákàtí kẹta ọjọ́ ni wọ́n kàn án mọ́ àgbélébùú. 26 Àkọlé ìfisùn tí wọ́n kọ sókè orí rẹ̀ ni:
ọba àwọn júù.
27 Wọ́n sì kan àwọn olè méjì mọ́ àgbélébùú pẹ̀lú rẹ̀, ọ̀kan lọ́wọ́ ọ̀tún rẹ̀, èkejì lọ́wọ́ òsì rẹ̀. 28 Eléyìí mú àsọtẹ́lẹ̀ ìwé Mímọ́ ṣẹ wí pé, “Wọ́n kà á pọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn búburú.” 29 (H)Àwọn tí ń kọjá lọ sì ń fi ṣe ẹlẹ́yà, wọ́n ń mi orí wọn pẹ̀lú, wọ́n sì ké pé, “Háà! Ìwọ tí yóò wó tẹmpili tí yóò sì tún un kọ́ láàrín ọjọ́ mẹ́ta, 30 sọ̀kalẹ̀ láti orí àgbélébùú wá, kí o sì gba ara rẹ là!” 31 (I)Bákan náà ni àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùkọ́ òfin fi í ṣẹ̀sín láàrín ara wọn, wọ́n wí pé, “Ó gba àwọn ẹlòmíràn là ṣùgbọ́n, ara rẹ̀ ni kò lè gbàlà. 32 Jẹ́ kí Kristi, ọba Israẹli, sọ̀kalẹ̀ láti orí igi àgbélébùú wá nísinsin yìí kí àwa kí ó lè rí i, kí àwa kí ó sì lè gbàgbọ́.” Bákan náà, àwọn ti a kàn mọ́ àgbélébùú pẹ̀lú rẹ̀ sì ń kẹ́gàn rẹ̀.
Ikú Jesu
33 (J)Nígbà tí ó di wákàtí kẹfà, òkùnkùn bo gbogbo ilẹ̀ títí di wákàtí kẹsànán. 34 (K)Ní wákàtí kẹsànán ni Jesu kígbe sókè ní ohùn rara, ó ní, “Eli, Eli, Lama Sabakitani?” (ìtumọ̀ èyí tí í ṣe, “Ọlọ́run mi, Ọlọ́run mi, èéṣe tí ìwọ fi kọ̀ mí sílẹ̀?”).
35 Nígbà tí àwọn kan nínú àwọn tí wọ́n dúró níbẹ̀ gbọ́, wọ́n sì wí pé, “Wò ó ó ń pe Elijah.”
36 (L)Nígbà náà ni ẹnìkan sáré lọ ki kànìnkànìn bọ inú ọtí kíkan, ó fi lé orí ọ̀pá, ó sì nà án sí Jesu kí ó lè mu ún. Ó wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a máa wò ó, bóyá Elijah yóò wá sọ̀ ọ́ kalẹ̀ wa.”
37 Jesu sì tún kígbe sókè ni ohùn rara, ó jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀ lọ́wọ́.
38 (M)Aṣọ ìkélé tẹmpili sì fàya sí méjì láti òkè dé ìsàlẹ̀. 39 (N)Nígbà tí balógun ọ̀rún tí ó dúró lẹ́gbẹ̀ ọ̀dọ̀ Jesu rí i tí ó kígbe sókè báyìí, tí ó sì jọ̀wọ́ èmí rẹ̀ lọ́wọ́, ó wí pé, “Lóòótọ́ Ọmọ Ọlọ́run ni ọkùnrin yìí í ṣe.”
40 (O)Àwọn obìnrin kan wà níbẹ̀ pẹ̀lú, tí wọ́n ń wò ó láti òkèèrè. Maria Magdalene wà lára àwọn obìnrin náà, àti Maria ìyá Jakọbu kékeré àti ti Jose, àti Salome. 41 (P)Àwọn wọ̀nyí, nígbà tí ó wà ní Galili máa ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, wọ́n a sì máa ṣe ìránṣẹ́ fún un àti ọ̀pọ̀ obìnrin mìíràn tí wọ́n sì bá a gòkè wá sí Jerusalẹmu.
Ìsìnkú Jesu
42 (Q)(R) Ọjọ́ yìí jẹ́ ọjọ́ ìpalẹ̀mọ́ (èyí tí ṣe, ọjọ́ tó ṣáájú ọjọ́ ìsinmi). Nígbà tí ilẹ̀ ọjọ́ náà sì ṣú, 43 Josẹfu ará Arimatea wá, ọ̀kan pàtàkì nínú àwọn ọmọ ìgbìmọ̀, ẹni tí ń retí ìjọba Ọlọ́run, ó fi ìgboyà lọ sí iwájú Pilatu láti tọrọ òkú Jesu. 44 Ẹnu ya Pilatu láti gbọ́ pé Jesu ti kú. Nítorí náà ó pe balógun ọ̀rún, ó sì bí i léèrè bóyá Jesu ti kú nítòótọ́. 45 Nígbà tí balógun ọ̀rún náà sì fún Pilatu ni ìdánilójú pé Jesu ti kú, Pilatu jọ̀wọ́ òkú rẹ̀ fún Josẹfu. 46 Josẹfu sì ti ra aṣọ ọ̀gbọ̀ wá. Ó sọ òkú Jesu kalẹ̀: ó sì fi aṣọ ọ̀gbọ̀ náà dì í. Ó sì tẹ́ ẹ sí inú ibojì, tí wọ́n gbẹ́ sí ara àpáta. Ó wá yí òkúta dí ẹnu ibojì náà. 47 Maria Magdalene àti Maria ìyá Jose ń wò ó bi Josẹfu ti n tẹ́ Jesu sí ibojì.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.