Add parallel Print Page Options

Ikú Jesu

33 (A)Nígbà tí ó di wákàtí kẹfà, òkùnkùn bo gbogbo ilẹ̀ títí di wákàtí kẹsànán. 34 (B)Ní wákàtí kẹsànán ni Jesu kígbe sókè ní ohùn rara, ó ní, “Eli, Eli, Lama Sabakitani?” (ìtumọ̀ èyí tí í ṣe, “Ọlọ́run mi, Ọlọ́run mi, èéṣe tí ìwọ fi kọ̀ mí sílẹ̀?”).

35 Nígbà tí àwọn kan nínú àwọn tí wọ́n dúró níbẹ̀ gbọ́, wọ́n sì wí pé, “Wò ó ó ń pe Elijah.”

36 (C)Nígbà náà ni ẹnìkan sáré lọ ki kànìnkànìn bọ inú ọtí kíkan, ó fi lé orí ọ̀pá, ó sì nà án sí Jesu kí ó lè mu ún. Ó wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a máa wò ó, bóyá Elijah yóò wá sọ̀ ọ́ kalẹ̀ wa.”

37 Jesu sì tún kígbe sókè ni ohùn rara, ó jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀ lọ́wọ́.

38 (D)Aṣọ ìkélé tẹmpili sì fàya sí méjì láti òkè dé ìsàlẹ̀. 39 (E)Nígbà tí balógun ọ̀rún tí ó dúró lẹ́gbẹ̀ ọ̀dọ̀ Jesu rí i tí ó kígbe sókè báyìí, tí ó sì jọ̀wọ́ èmí rẹ̀ lọ́wọ́, ó wí pé, “Lóòótọ́ Ọmọ Ọlọ́run ni ọkùnrin yìí í ṣe.”

40 (F)Àwọn obìnrin kan wà níbẹ̀ pẹ̀lú, tí wọ́n ń wò ó láti òkèèrè. Maria Magdalene wà lára àwọn obìnrin náà, àti Maria ìyá Jakọbu kékeré àti ti Jose, àti Salome. 41 (G)Àwọn wọ̀nyí, nígbà tí ó wà ní Galili máa ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, wọ́n a sì máa ṣe ìránṣẹ́ fún un àti ọ̀pọ̀ obìnrin mìíràn tí wọ́n sì bá a gòkè wá sí Jerusalẹmu.

Read full chapter

Ikú Jesu

44 (A)Ó sì tó ìwọ̀n wákàtí kẹfà ọjọ́, òkùnkùn sì ṣú bo gbogbo ilẹ̀ títí ó fi di wákàtí kẹsànán ọjọ́. 45 (B)Òòrùn sì ṣú òòkùn, aṣọ ìkélé ti tẹmpili sì ya ní àárín méjì, 46 (C)Nígbà tí Jesu sì kígbe lóhùn rara, ó ní, “Baba, ní ọwọ́ rẹ ni mo fi ẹ̀mí mi lé!” Nígbà tí ó sì wí èyí tan, ó jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀.

47 Nígbà tí balógun ọ̀rún rí ohun tí ó ṣe, ó yin Ọlọ́run lógo, wí pé, “Dájúdájú olódodo ni ọkùnrin yìí!” 48 Gbogbo ìjọ ènìyàn tí ó péjọ láti rí ìran yìí, nígbà tí wọ́n rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀ wọ́n lu ara wọn ní oókan àyà, wọ́n sì padà sí ilé. 49 (D)Àti gbogbo àwọn ojúlùmọ̀ rẹ̀, àti àwọn obìnrin tí ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn láti Galili wá, wọ́n dúró lókèèrè, wọ́n ń wo nǹkan wọ̀nyí.

Ìsìnkú Jesu

50 (E)Sì kíyèsi i, ọkùnrin kan tí a ń pè ní Josẹfu, láti ìlú àwọn Júù kan tí ń jẹ́ Arimatea. Ó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ìgbìmọ̀, ènìyàn rere, àti olóòtítọ́. 51 Òun kò bá wọn fi ohùn sí ìmọ̀ àti ìṣe wọn; Ó wá láti Judea, ìlú àwọn ará Arimatea, òun pẹ̀lú ń retí ìjọba Ọlọ́run. 52 Ọkùnrin yìí tọ Pilatu lọ, ó sì tọrọ òkú Jesu. 53 Nígbà tí ó sì sọ̀ ọ́ kalẹ̀, ó sì fi aṣọ àlà dì í, ó sì tẹ́ ẹ sínú ibojì tí a gbẹ́ nínú Òkúta, níbi tí a kò tẹ́ ẹnikẹ́ni sí rí. 54 Ó sì jẹ́ ọjọ́ ìpalẹ̀mọ́: ọjọ́ ìsinmi sì kù sí dẹ̀dẹ̀.

Read full chapter

Ikú Jesu

28 (A)Lẹ́yìn èyí, bí Jesu ti mọ̀ pé, a ti parí ohun gbogbo tán, kí ìwé mímọ́ bà á lè ṣẹ, ó wí pé, “Òrùngbẹ ń gbẹ mí.” 29 Ohun èlò kan tí ó kún fún ọtí kíkan wà níbẹ̀, wọ́n tẹ kànìnkànìn tí ó kún fún ọtí kíkan bọ inú rẹ̀, wọ́n sì fi lé orí igi hísópù, wọ́n sì nà án sí i lẹ́nu. 30 Nígbà tí Jesu sì ti gba ọtí kíkan náà, ó wí pé, “Ó parí!” Ó sì tẹ orí rẹ̀ ba, ó jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀.

Read full chapter