Book of Common Prayer
ÌWÉ KÌN-ÍN-NÍ
Saamu 1–41
1 (A)Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà,
tí kò rìn ní ìmọ̀ àwọn ènìyàn búburú,
ti kò dúró ní ọ̀nà àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀,
tàbí tí kò sì jókòó ní ibùjókòó àwọn ẹlẹ́gàn.
2 Ṣùgbọ́n ayọ̀ inú rẹ̀ wà nínú òfin Olúwa
àti nínú òfin rẹ̀ ni ó ń ṣe àṣàrò ní ọ̀sán àti òru.
3 Ó dàbí igi tí a gbìn sí etí odò tí ń sàn,
tí ń so èso rẹ̀ jáde ní àkókò rẹ̀
tí ewé rẹ̀ kì yóò rẹ̀.
Ohunkóhun tí ó dáwọ́lé, ni yóò máa yọrí sí rere.
4 Kò le rí bẹ́ẹ̀ fún àwọn ènìyàn búburú!
Wọn yóò dàbí ìyàngbò ọkà
tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ dànù.
5 Nítorí náà àwọn ènìyàn búburú kì yóò le è dìde dúró ní ìdájọ́,
bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ kì yóò le è dúró ní àwùjọ àwọn olódodo.
6 Nítorí Olúwa ń ṣọ́ ọ̀nà àwọn olódodo,
ṣùgbọ́n ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú ni yóò ṣègbé.
2 (B)Èéṣe tí àwọn orílẹ̀-èdè fi ń dìtẹ̀,
àti tí àwọn ènìyàn ń ṣe rìkíṣí asán?
2 Àwọn ọba ayé péjọpọ̀
àti àwọn ìjòyè gbìmọ̀ pọ̀
sí Olúwa àti sí Ẹni ààmì òróró rẹ̀.
3 Wọ́n sọ pé, “Ẹ jẹ́ kí a fa ẹ̀wọ̀n wọn já,
kí a sì ju ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ wọn nù.”
4 Ẹni tí ó gúnwà lórí ìtẹ́ lọ́run rẹ́rìn-ín;
Olúwa fi wọ́n rẹ́rìn-ín ẹlẹ́yà.
5 Nígbà náà ni yóò bá wọn wí ní ìbínú rẹ̀
yóò sì dẹ́rùbà wọ́n ní ìrunú rẹ̀, ó wí pé,
6 “Èmi ti fi ọba mi sí ipò
lórí Sioni, òkè mímọ́ mi.”
7 (C)Èmi yóò sì kéde ìpinnu Olúwa:
Ó sọ fún mi pé, “Ìwọ ni ọmọ mi;
lónìí, èmi ti di baba rẹ.
8 (D)Béèrè lọ́wọ́ mi,
Èmi yóò jẹ́ kí orílẹ̀-èdè di ìní rẹ,
òpin ilé ayé yóò sì jẹ́ ogún rẹ.
9 Ìwọ yóò fi ọ̀pá irin ṣe àkóso wọn
ìwọ yóò sì rún wọn wómúwómú bí ìkòkò amọ̀.”
10 Nítorí náà, ẹ̀yin ọba, ẹ jẹ́ ọlọ́gbọ́n;
ẹ gbọ́ ìkìlọ̀ ẹ̀yin alákòóso ayé.
11 Ẹ sin Olúwa pẹ̀lú ìbẹ̀rù
ẹ sì máa yọ̀ pẹ̀lú ìwárìrì.
12 Fi ẹnu ko ọmọ náà ní ẹnu, kí ó má ba à bínú,
kí ó má ba à pa yín run ní ọ̀nà yín,
nítorí ìbínú rẹ̀ lè ru sókè ní ẹ̀ẹ̀kan.
Ìbùkún ni fún gbogbo àwọn tí ó fi í ṣe ibi ìsádi wọn.
Saamu ti Dafidi. Nígbà ti ó sá fún ọmọ rẹ̀ Absalomu.
3 Olúwa, báwo ni àwọn ọ̀tá mi ṣe pọ̀ tó báyìí!
Báwo ni àwọn ti ó dìde sí mi ṣe pọ̀ tó!
2 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ó ń sọ ní ti tèmi, pé
“Ọlọ́run kò nígbà á là.” Sela.
3 Ṣùgbọ́n ìwọ ni asà yí mi ká, Olúwa;
ìwọ fi ògo fún mi, ìwọ sì gbé orí mi sókè.
4 Olúwa ni mo kígbe sókè sí,
ó sì dá mi lóhùn láti orí òkè mímọ́ rẹ̀ wá. Sela.
5 Èmi dùbúlẹ̀, mo sì sùn;
mo sì tún padà jí, nítorí Olúwa ni ó ń gbé mi ró.
6 Èmi kì yóò bẹ̀rù ẹgbẹgbẹ̀rún ènìyàn
tí wọ́n rọ̀gbà yí mi ká.
7 Dìde, Olúwa!
Gbà mí, Ọlọ́run mi!
Lu gbogbo àwọn ọ̀tá mi ní àgbọ̀n;
kí o sì ká eyín àwọn ènìyàn búburú.
8 Láti ọ̀dọ̀ Olúwa ni ìgbàlà ti wá.
Kí ìbùkún rẹ wà lórí àwọn ènìyàn rẹ. Sela.
Fún adarí orin. Pẹ̀lú ohun èlò orin olókùn. Saamu ti Dafidi.
4 Dá mi lóhùn nígbà tí mo bá pè ọ́,
ìwọ Ọlọ́run òdodo mi,
Fún mi ní ìdáǹdè nínú ìpọ́njú mi;
ṣàánú fún mi, kí o sì gbọ́ àdúrà mi.
2 Báwo ni yóò ṣe pẹ́ tó, ẹ̀yin ọmọ ènìyàn, tí ẹ ó ṣe sọ ògo mi di ìtìjú?
Báwo ni yóò ṣe pẹ́ tó, tí ẹ̀yin yóò ṣe fẹ́ràn ìtànjẹ àti tí ẹ̀yin yóò fi máa wá ọlọ́run èké?
3 Ṣùgbọ́n kí ẹ mọ̀ pé, Olúwa ti ya ẹni olódodo sọ́tọ̀ fún ara rẹ̀;
Olúwa yóò gbọ́ nígbà tí mo bá pè é.
4 (E)Ẹ bínú ẹ má ṣe ṣẹ̀;
Nígbà tí ẹ bá wà lórí ibùsùn yín,
ẹ bá ọkàn yín sọ̀rọ̀, kí ó sì dákẹ́ jẹ́.
5 Ẹ rú ẹbọ òdodo
kí ẹ sì gbẹ́kẹ̀lé Olúwa.
6 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ló ń béèrè pé, “Ta ni yóò ṣe rere fún wa?”
Olúwa, Jẹ́ kí ojú rẹ mọ́lẹ̀ sí wa lára,
7 Ìwọ ti fi ayọ̀ púpọ̀ kún ọkàn mi
ju ìgbà tí hóró irúgbìn àti wáìnì tuntun wọ́n pọ̀ fún mi lọ.
8 Èmi yóò dùbúlẹ̀, èmi ó sì sùn ní àlàáfíà,
nítorí ìwọ nìkan, Olúwa, ni o
mú mi gbé láìléwu.
Ṣiggaioni ti Dafidi, èyí tí ó kọ sí Olúwa nípa Kuṣi, ará Benjamini.
7 Olúwa Ọlọ́run mi, ààbò mi wà nínú rẹ;
gba mí là kí o sì tú mi sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn tó ń lé mi,
2 kí wọn ó má ba à fa ọkàn mi ya gẹ́gẹ́ bí kìnnìún,
wọ́n á ya á pẹ́rẹpẹ̀rẹ láìsí ẹni tí yóò gbà mí.
3 Olúwa Ọlọ́run mi, tí èmi bá ṣe èyí
tí ẹ̀bi sì wà ní ọwọ́ mi
4 Bí èmi bá ṣe ibi sí ẹni tí ń wá àlàáfíà pẹ̀lú mi,
tí mo ja ọ̀tá mi lólè láìnídìí:
5 Nígbà náà, jẹ́ kí ọ̀tá mi lé mi kí wọn sì mú mi;
jẹ́ kí òun kí ó tẹ ọkàn mi mọ́lẹ̀
kí wọn sì mú mi sùn nínú eruku. Sela.
6 Dìde, Olúwa, nínú ìbínú rẹ;
dìde lòdì sí ìrunú àwọn ọ̀tá mi.
Jí, Ọlọ́run mi; kéde òdodo.
7 Kí ìpéjọ àwọn ènìyàn yíká.
Jọba lórí wọn láti òkè wá;
8 Jẹ́ kí Olúwa ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn.
Ṣe ìdájọ́ mi, Olúwa, gẹ́gẹ́ bí òdodo mi,
gẹ́gẹ́ bí ìwà òtítọ́, ẹni gíga jùlọ.
9 (A)Ọlọ́run Olódodo,
Ẹni tí ó ń wo inú àti ọkàn,
tí ó ń mú òpin sí ìwà ipá ẹni búburú
tí ó sì ń pa àwọn olódodo mọ́.
10 Ààbò mi ń bẹ lọ́dọ̀ Ọlọ́run,
ẹni tí ń ṣe ìgbàlà òtítọ́ ní àyà.
11 Ọlọ́run ni onídàájọ́ òtítọ́,
Ọlọ́run tí ń sọ ìrunú rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́.
12 Bí kò bá yípadà,
Òun yóò pọ́n idà rẹ̀ mú;
ó ti fa ọrun rẹ̀ le ná, ó ti múra rẹ̀ sílẹ̀.
13 Ó ti pèsè ohun ìjà ikú sílẹ̀;
ó ti pèsè ọfà iná sílẹ̀.
14 Ẹni tí ó lóyún ohun búburú,
tí ó sì lóyún wàhálà, ó bí èké jáde.
15 Ẹni tí ó gbẹ́ ọ̀fìn, tí ó kó o jáde
jì sí kòtò tí ó gbẹ́ sílẹ̀.
16 Wàhálà tí ó fà padà sórí rẹ̀;
Ìwà ipá rẹ̀ padà sórí ara rẹ̀.
17 Èmi ó fi ọpẹ́ fún Olúwa nítorí òdodo rẹ̀,
Èmi ó kọrin ìyìn sí Olúwa Ọ̀gá-ògo jùlọ.
5 Adonijah ẹni tí ìyá rẹ̀ ń ṣe Haggiti sì gbé ara rẹ̀ ga, ó sì wí pé, “Èmi yóò jẹ ọba.” Ó sì ṣètò kẹ̀kẹ́ ogun àti àwọn ẹlẹ́ṣin, pẹ̀lú àádọ́ta ọkùnrin láti máa sáré níwájú rẹ̀. 6 (Baba rẹ̀ kò bà á nínú jẹ́ rí nípa bíbéèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Èéṣe tí ìwọ fi hùwà báyìí?” Ó sì jẹ́ arẹwà ọkùnrin, òun ni a bí lé Absalomu.)
7 Adonijah sì gbèrò pẹ̀lú Joabu, ọmọ Seruiah àti Abiatari àlùfáà, wọ́n sì ṣe ìrànlọ́wọ́ fún un. 8 Ṣùgbọ́n Sadoku àlùfáà, Benaiah ọmọ Jehoiada, Natani wòlíì, Ṣimei àti ọ̀rẹ́ rẹ̀ Rei àti olórí ogun Dafidi ni kò darapọ̀ mọ́ Adonijah.
9 Nígbà náà ni Adonijah fi àgùntàn àti màlúù àti ẹran ọ̀sìn tí ó sanra rú ẹbọ níbi òkúta Soheleti tí ń bẹ lẹ́gbẹ̀ẹ́ En-Rogeli. Ó sì pe gbogbo àwọn arákùnrin rẹ̀, àwọn ọmọ ọba, àti gbogbo àwọn ọkùnrin Juda tí wọ́n jẹ́ ìránṣẹ́ ọba. 10 Ṣùgbọ́n kò pe Natani wòlíì tàbí Benaiah tàbí àwọn olórí tàbí Solomoni arákùnrin rẹ̀.
11 Nígbà náà ni Natani béèrè lọ́wọ́ Batṣeba, ìyá Solomoni pé, “Ǹjẹ́ ìwọ kò gbọ́ pé Adonijah, ọmọ Haggiti ti jẹ ọba láìjẹ́ pé Dafidi olúwa wa mọ̀ sí i? 12 Ǹjẹ́ nísinsin yìí, jẹ́ kí èmi gbà ọ́ ní ìmọ̀ràn bí ìwọ ṣe lè gba ẹ̀mí rẹ là àti ẹ̀mí ọmọ rẹ Solomoni. 13 Lọ sọ́dọ̀ Dafidi ọba, kí o sì wí fún un pé, ‘Olúwa mi ọba, ǹjẹ́ ìwọ kò búra fún ìránṣẹ́ rẹ pé, “Dájúdájú Solomoni ọmọ rẹ ni yóò Jọba lẹ́yìn mi, yóò sì jókòó lórí ìtẹ́ mi?” Èéṣe nígbà náà tí Adonijah fi jẹ ọba?’ 14 Níwọ́n ìgbà tí ìwọ sì wà níbẹ̀, tí o sì ń bá ọba sọ̀rọ̀ èmi yóò wá, láti wádìí ohun tí o ti sọ.”
15 Bẹ́ẹ̀ ni Batṣeba lọ rí ọba ní inú yàrá rẹ̀, ọba sì gbó gidigidi níbi tí Abiṣagi ará Ṣunemu ti ń ṣe ìránṣẹ́ fún ọba. 16 Batṣeba sì tẹríba, ó sì kúnlẹ̀ níwájú ọba.
Ọba sì béèrè pé, “Kí ni ìwọ ń fẹ́?”
17 Ó sì wí fún ọba pé, “Olúwa mi; ìwọ fúnrarẹ̀ fi Olúwa Ọlọ́run rẹ búra fún ìránṣẹ́ rẹ pé: ‘Solomoni ọmọ rẹ yóò jẹ ọba lẹ́yìn mi, yóò sì jókòó lórí ìtẹ́ mi.’ 18 Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, Adonijah ti di ọba, ìwọ, ọba olúwa mi kò sì mọ̀ nípa rẹ̀. 19 Òun sì ti fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ màlúù, àti ẹran tí ó ní ọ̀rá, àti àgùntàn rú ẹbọ, ó sì pe gbogbo àwọn ọmọ ọba, àti Abiatari àlùfáà àti Joabu Balógun, ṣùgbọ́n kò sì pe Solomoni ìránṣẹ́ rẹ. 20 Olúwa mi ọba, ojú gbogbo Israẹli ń bẹ lára rẹ, láti mọ ẹni tí yóò jókòó lórí ìtẹ́ olúwa mi ọba lẹ́yìn rẹ. 21 Bí kò ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà tí olúwa mi ọba bá sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀, wọn yóò sì ka èmi àti Solomoni sí ẹlẹ́ṣẹ̀.”
22 Bí ó sì ti ń bá ọba sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, Natani wòlíì sì wọlé. 23 Wọ́n sì sọ fún ọba pé, “Natani wòlíì wà níbí.” Ó sì lọ síwájú ọba, ó wólẹ̀, ó sì dojúbolẹ̀.
24 Natani sì wí pé, “Ǹjẹ́ ìwọ, olúwa mi ọba, ti sọ pé Adonijah ni yóò jẹ ọba lẹ́yìn rẹ àti pé òun ni yóò jókòó lórí ìtẹ́ rẹ? 25 Ó sì ti sọ̀kalẹ̀ lọ ní òní, ó sì ti rú ẹbọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ màlúù, àti ẹran ọlọ́ràá àti àgùntàn. Ó sì ti pe gbogbo àwọn ọmọ ọba, Balógun àti Abiatari àlùfáà. Ní ṣinṣin yìí, wọ́n ń jẹ, wọ́n ń mu pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n sì wí pé, ‘Kí Adonijah ọba kí ó pẹ́!’ 26 Ṣùgbọ́n èmi ìránṣẹ́ rẹ, àti Sadoku àlùfáà, àti Benaiah ọmọ Jehoiada, àti Solomoni ìránṣẹ́ rẹ ni kò pè. 27 Ṣé nǹkan yìí ni olúwa mi ọba ti ṣe láìjẹ́ kí àwọn ìránṣẹ́ rẹ mọ ẹni tí yóò jókòó lórí ìtẹ́ olúwa mi ọba lẹ́yìn rẹ?”
Dafidi fi Solomoni jẹ ọba
28 Nígbà náà ni Dafidi ọba wí pé, “Pe Batṣeba wọlé wá.” Ó sì wá síwájú ọba, ó sì dúró níwájú rẹ̀.
29 Ọba sì búra pé, “Dájúdájú bí Olúwa ti wà ẹni tí ó ti gbà mí kúrò nínú gbogbo wàhálà, 30 Lónìí dandan ni èmi yóò gbé ohun tí mo ti fi Olúwa Ọlọ́run Israẹli búra fún yọ pé: Solomoni ọmọ rẹ ni yóò jẹ ọba lẹ́yìn mi, àti pé yóò jókòó lórí ìtẹ́ mi ní ipò mi.”
31 Nígbà náà ni Batṣeba tẹríba, ó sì kúnlẹ̀ níwájú ọba pé, “Kí olúwa mi Dafidi ọba kí ó pẹ́!”
26 Agrippa sì wí fún Paulu pé, “A fún ọ láààyè láti sọ tí ẹnu rẹ.”
Nígbà náà ní Paulu ná ọwọ́, ó sì sọ ti ẹnu rẹ pé: 2 “Agrippa ọba, inú èmi tìkára mi dùn nítorí tí èmi yóò wí ti ẹnu mi lónìí níwájú rẹ, ní ti gbogbo ẹ̀sùn tí àwọn Júù fi kan mi, 3 pàápàá bí ìwọ tí mọ gbogbo àṣà àti ọ̀ràn tí ń bẹ́ láàrín àwọn Júù dájúdájú. Nítorí náà, èmi bẹ̀ ọ́ kí ìwọ fi sùúrù tẹ́tí gbọ́ tèmi.
4 “Àwọn Júù mọ irú ìgbé ayé tí mo ń gbé láti ìgbà èwe mi, láti ìbẹ̀rẹ̀ ayé mi ní orílẹ̀-èdè mi àti ní Jerusalẹmu. 5 Nítorí wọ́n mọ̀ mi láti ìpilẹ̀ṣẹ̀, bí wọ́n bá fẹ́ jẹ́rìí sí i, wí pé, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà ìsìn wa tí ó lè jùlọ, Farisi ni èmi. 6 Nísinsin yìí nítorí ìrètí ìlérí tí Ọlọ́run tí ṣe fún àwọn baba wa ni mo ṣe dúró níhìn-ín fún ìdájọ́. 7 Ìlérí èyí tí àwọn ẹ̀yà wa méjèèjìlá tí ń fi ìtara sin Ọlọ́run lọ́sàn án àti lóru tí wọ́n ń retí àti rí i gbà. Ọba Agrippa, nítorí ìrètí yìí ni àwọn Júù ṣe ń fi mi sùn. 8 Èéṣe tí ẹ̀yin fi rò o sí ohun tí a kò lè gbàgbọ́ bí Ọlọ́run bá jí òkú dìde?
9 (A)“Èmi tilẹ̀ rò nínú ará mi nítòótọ́ pé, ó yẹ ki èmi ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun lòdì sí orúkọ Jesu tí Nasareti. 10 Èyí ni mo sì ṣe ni Jerusalẹmu. Pẹ̀lú àṣẹ tí mo tí gba lọ́dọ̀ àwọn olórí àlùfáà, mo sọ àwọn púpọ̀ nínú àwọn ènìyàn mímọ́ sí inú túbú, nígbà tí wọ́n sí ń pa wọ́n, mo ní ohùn sí i. 11 Nígbà púpọ̀ ni mo ń fi ìyà jẹ wọ́n láti inú Sinagọgu dé inú Sinagọgu, mo ń fi tipá mú wọn láti sọ ọ̀rọ̀-òdì. Mo sọ̀rọ̀ lòdì sí wọn gidigidi, kódà mo wá wọn lọ sí ìlú àjèjì láti ṣe inúnibíni sí wọn.
12 “Nínú irú ìrìnàjò yìí ní mo ń bá lọ sí Damasku pẹ̀lú ọlá àti àṣẹ ikọ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn olórí àlùfáà. 13 Ni ọ̀sán gangan, ìwọ ọba Agrippa, bí mo ti wà ní ojú ọ̀nà, mo rí ìmọ́lẹ̀ kan láti ọ̀run wá, tí ó mọ́lẹ̀ ju oòrùn lọ, ó mọ́lẹ̀ yí mi ká, àti àwọn tí ń bá mi lọ sì àjò. 14 Gbogbo wa sì ṣubú lulẹ̀, mo gbọ́ ohùn tí ń fọ sì mi ni èdè Heberu pé, ‘Saulu, Saulu! Èéṣe tí ìwọ fi ń ṣe inúnibíni sí mi? Ohun ìrora ní fún ọ láti tàpá sí ẹ̀gún!’
15 “Èmi sì wí pé, ‘Ìwọ ta ni, Olúwa?’
“Olúwa sì wí pé, ‘Èmi ni Jesu tí ìwọ ń ṣe inúnibíni sí. 16 (B)Ṣùgbọ́n dìde, kí o sí fi ẹsẹ̀ rẹ tẹlẹ̀: nítorí èyí ni mo ṣe farahàn ọ́ láti yàn ọ́ ní ìránṣẹ́ àti ẹlẹ́rìí, fún ohun wọ̀nyí tí ìwọ tí rí nípa mi, àti àwọn ohun tí èmi yóò fi ara hàn fún ọ: 17 Èmi yóò gbà ọ lọ́wọ́ àwọn ènìyàn rẹ àti lọ́wọ́ àwọn aláìgbàgbọ́. Èmi rán ọ sí wọn nísinsin yìí 18 (C)láti là wọ́n lójú, kí wọn lè yípadà kúrò nínú òkùnkùn sí ìmọ́lẹ̀, àti kúrò lọ́wọ́ agbára Satani sí Ọlọ́run, kí wọn lè gba ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀, àti ogún pẹ̀lú àwọn tí a sọ di mímọ́ nípa ìgbàgbọ́ nínú mi.’
19 “Nítorí náà, Agrippa ọba, èmi kò ṣe àìgbọ́ràn sì ìran ọ̀run náà. 20 Ṣùgbọ́n mo kọ́kọ́ sọ fún àwọn tí ó wà ní Damasku, àti ní Jerusalẹmu, àti já gbogbo ilẹ̀ Judea, àti fún àwọn kèfèrí, kí wọn ronúpìwàdà, kí wọ́n sì yípadà sí Ọlọ́run, kí wọn máa ṣe iṣẹ́ tí ó yẹ sì ìrònúpìwàdà. 21 Nítorí nǹkan wọ̀nyí ni àwọn Júù ṣe gbá mi mú nínú tẹmpili, tí wọ́n sì ń fẹ́ pa mí. 22 Ṣùgbọ́n bí mo sì tí ri ìrànlọ́wọ́ gbà láti ọ́dọ̀ Ọlọ́run, mo dúró títí ó fi di òní, mo ń jẹ́rìí fún èwe àti àgbà, èmi kò sọ ohun mìíràn bí kò ṣe ohun tí àwọn wòlíì àti Mose tí wí pé, yóò ṣẹ: 23 Pé, Kristi yóò jìyà, àti pé òun ni yóò jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ láti jíǹde kúrò nínú òkú, òun ni yóò sí kéde ìmọ́lẹ̀ fún àwọn ènìyàn àti fún àwọn aláìgbàgbọ́.”
14 (A)“Ṣùgbọ́n nígba tí ẹ̀yin bá rí ìríra ìsọdahoro, tí ó dúró níbí tí kò yẹ, tí a tí ẹnu wòlíì Daniẹli sọ, (ẹnikẹ́ni tí ó bá kà á ki í ó yé e) nígbà náà ni kí àwọn tí ń bẹ ni Judea sálọ sí orí òkè. 15 Kí ẹni ti ń bẹ lórí ilé má ṣe sọ̀kalẹ̀ lọ sínú ilé, bẹ́ẹ̀ ni kí ó má sì ṣe wọ inú rẹ̀, láti mú ohunkóhun jáde nínú ilé rẹ̀. 16 Kí ẹni tí ó wà lóko má ṣe padà sẹ́yìn láti wá mú aṣọ rẹ̀. 17 (B)Ègbé ní fún àwọn tí ó lóyún, àti fún obìnrin tí ń fún ọ́mọ lọ́mú ní ọjọ́ wọ̀nyí. 18 Kí ẹ sì máa gbàdúrà pé èyí ṣẹlẹ̀ ní àkókò òtútù. 19 Nítorí ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì yóò jẹ́ àkókò ìpọ́njú, irú èyí tí kò ì ṣẹlẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀ ẹ̀dá Ọlọ́run. Irú rẹ̀ kò sì ni ṣẹlẹ̀ mọ́.
20 “Àfi tí Olúwa bá gé àkókò ìjìyà náà kúrú, ẹyọ ẹ̀mí kan ní ayé kì yóò là. Ṣùgbọ́n nítorí àwọn tí Ọlọ́run yàn, ni yóò ṣe dín àwọn ọjọ́ náà kù. 21 Nígbà náà, bí ẹnikẹ́ni bá sọ fún un yín pé, ‘Ẹ wò ó, Kristi wa níbi yìí!’ tàbí, sọ fún un yín pé, ‘Ẹ wò ó, ó wà lọ́hùn ún nì!’ Ẹ má ṣe gbà wọ́n gbọ́. 22 (C)Nítorí àwọn èké Kristi àti àwọn wòlíì èké ni yóò wá, wọn yóò sì fi iṣẹ́ ìyanu tí yóò tan ènìyàn jẹ hàn. Bí ó bá ṣe é ṣe, wọn yóò tan àwọn àyànfẹ́ pàápàá jẹ. 23 Nítorí náà, ẹ ṣọ́ra. Mo ti kìlọ̀ fún un yín ṣáájú tó!
24 “Ṣùgbọ́n ni ọjọ́ wọ̀nyí lẹ́yìn ìpọ́njú tí mo sọ yìí,
“ ‘oòrùn yóò ṣókùnkùn,
òṣùpá kò ní tan ìmọ́lẹ̀ rẹ̀.
25 Àwọn ìràwọ̀ pẹ̀lú yóò já lulẹ̀ láti ojú ọ̀run,
àti agbára tí ń bẹ ní ọ̀run ni a ó sì mì tìtì.’
26 (D)“Nígbà náà ni gbogbo ayé yóò sì rí i tí Èmi Ọmọ Ènìyàn yóò máa bọ̀ wá láti inú àwọsánmọ̀ pẹ̀lú agbára àti ògo ńlá. 27 Nígbà náà ni yóò sì rán àwọn angẹli rẹ̀ láti kó àwọn àyànfẹ́ ní gbogbo ayé jọ láti orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé láti ìkangun ayé títí dé ìkangun ọ̀run.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.